Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Cyril àti Methodius—Àwọn Olùtumọ̀ Bíbélì Tó Hùmọ̀ Irú Ááfábẹ́ẹ̀tì Kan

Cyril àti Methodius—Àwọn Olùtumọ̀ Bíbélì Tó Hùmọ̀ Irú Ááfábẹ́ẹ̀tì Kan

Cyril àti Methodius—Àwọn Olùtumọ̀ Bíbélì Tó Hùmọ̀ Irú Ááfábẹ́ẹ̀tì Kan

“Orílẹ̀-èdè wa ti ṣe batisí, síbẹ̀ a ò lólùkọ́. A ò gbọ́ èdè Gíríìkì, a ò sì gbọ́ Látìn. . . . A ò lè ka ohun tí wọ́n kọ sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ la ò sì lóye wọn; nítorí náà ẹ rán àwọn olùkọ́ tí yóò ṣàlàyé àwọn ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ àti ohun tí wọ́n túmọ̀ sí fún wa.” —Rastislav, ọmọ ọba Moravia, 862 Sànmánì Tiwa.

LÓNÌÍ, àwọn tó lé ní òjì lé nírínwó ó dín márùn-ún [435] mílíọ̀nù èèyàn tí ń sọ àwọn èdè àdúgbò Slavic ló ní ẹ̀dà Bíbélì tí wọ́n kọ ní èdè ìbílẹ̀ wọn lọ́wọ́. a Òjì dín nírínwó [360] mílíọ̀nù lára wọn ló ń lo ááfábẹ́ẹ̀tì Cyrillic. Bẹ́ẹ̀ sì rèé, ní ọ̀rúndún méjìlá sẹ́yìn, kò sí èdè kankan tó wà lákọsílẹ̀ tàbí ááfábẹ́ẹ̀tì kan nínú gbogbo èdè àdúgbò tí àwọn baba ńlá wọn sọ. Àwọn ọkùnrin méjì tórúkọ wọn ń jẹ́ Cyril àti Methodius, tí wọ́n jẹ́ tẹ̀gbọ́n tàbúrò, ló bá wọn yanjú ìṣòro yẹn. Àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run yóò rí i pé ìsapá onígboyà tí àwọn tẹ̀gbọ́n tàbúrò wọ̀nyí dánú ṣe kó ipa pàtàkì nínú bí a ṣe pa Bíbélì mọ́ àti bó ṣe tàn kálẹ̀. Àwọn wo làwọn ọkùnrin wọ̀nyí, kí sì làwọn ìṣòro tí wọ́n dojú kọ?

“Onímọ̀ Ọgbọ́n Orí” àti Gómìnà

Inú ilé ọlá nílùú Tẹsalóníkà, nílẹ̀ Gíríìsì ni wọ́n ti bí Cyril (827 sí 869 Sànmánì Tiwa, òun ni wọ́n ń pè ní Kọnsitatáìnì tẹ́lẹ̀) àti Methodius (825 sí 885 Sànmánì Tiwa). Tẹsalóníkà ṣì jẹ́ ìlú tí wọ́n ti ń sọ èdè méjì nígbà yẹn; àwọn tó ń gbé ibẹ̀ máa ń sọ èdè Gíríìkì àti èdè kan tó jẹ́ ẹ̀yà èdè Slavic. Pípọ̀ tí àwọn Slav pọ̀ níbẹ̀ àti àjọṣe tímọ́tímọ́ tó wà láàárín àwọn ará ibẹ̀ àtàwọn àwùjọ tó ń sọ èdè Slavic láyìíká wọn, ló ní láti fún Cyril àti Methodius láǹfààní láti gbọ́ ìjìnlẹ̀ èdè àwọn Slav tó wà ní ìhà gúúsù. Ẹnì kan tó jẹ́ òpìtàn nípa Methodius tiẹ̀ sọ pé ọmọ ìbílẹ̀ Slav ni ìyá rẹ̀.

Lẹ́yìn ikú baba rẹ̀, Cyril lọ sí Kọnsitantinópù, tó jẹ́ olú ìlú Ilẹ̀ Ọba Byzantine. Ibẹ̀ ló ti kẹ́kọ̀ọ́ ní yunifásítì ìjọba tó sì bá àwọn olùkọ́ni tó tayọ lọ́lá níbẹ̀ kẹ́gbẹ́. Ó di alábòójútó ibi ìkówèésí Hagia Sophia, tó jẹ́ ilé ìjọsìn tó gbajúmọ̀ jù lọ ní Ìlà Oòrùn, ó sì wá di ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ìmọ̀ ọgbọ́n orí níkẹyìn. Àní, Cyril gba orúkọ àpèlé náà Onímọ̀ Ọgbọ́n Orí, nítorí àwọn àṣeyọrí tó ṣe nínú ìmọ̀ ẹ̀kọ́.

Láàárín àkókò kan náà, Methodius ń tọ ọ̀nà tí baba rẹ̀ tọ̀—ó ń kọ́ ẹ̀kọ́ nípa ìṣèlú. Ó di alága (gómìnà) àgbègbè kan tó wà lẹ́bàá ààlà Byzantine, tí ọ̀pọ̀ àwọn tó ń sọ èdè Slavic ń gbé. Síbẹ̀síbẹ̀, ó fi ibẹ̀ sílẹ̀, ó sì lọ sílé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé ní Bìtíníà, Éṣíà Kékeré. Cyril wá bá a níbẹ̀ ní ọdún 855 Sànmánì Tiwa.

Ní ọdún 860 Sànmánì Tiwa, bíṣọ́ọ̀bù Kọnsitantinópù rán tẹ̀gbọ́n-tàbúrò náà lọ fún iṣẹ́ ìsìn nílẹ̀ òkèèrè. Wọ́n rán wọn lọ sáàárín àwọn Khazar, àwọn èèyàn tó ń gbé ní àríwá ìlà oòrùn Òkun Dúdú, tí wọn kò mọ èyí tí wọ́n máa ṣe nínú Ìsìláàmù, ìsìn àwọn Júù, àti ìsìn Kristẹni. Nígbà tí Cyril ń lọ síbẹ̀, ó dúró fúngbà díẹ̀ ní Chersonese, ní Crimea. Àwọn ọ̀mọ̀wé kan gbà pé ibẹ̀ ló ti kọ́ èdè Hébérù àti ti Samáríà, tó sì túmọ̀ ìwé gírámà èdè Hébérù sí èdè tí àwọn Khaza ń sọ.

Ìpè Láti Moravia

Ní 862 Sànmánì Tiwa, Rostislav, ọmọ ọba Moravia (tó wà ní ìhà ìlà oòrùn Czechia, ìwọ̀ oòrùn Slovakia, àti ìwọ̀ oòrùn Hungary lóde òní), fi ẹ̀bẹ̀ tó wà ní ìpínrọ̀ àkọ́kọ́ nínú àpilẹ̀kọ yìí ránṣẹ́ sí Michael Kẹta, tó jẹ́ Olú Ọba Byzantine—pé kí ó rán àwọn tí ń fi Ìwé Mímọ́ kọ́ni sáwọn. Àwọn míṣọ́nnárì tó wá láti ìjọba Ìlà Oòrùn Ẹ̀yà Frank (ìyẹn Jámánì àti Austria òde òní) ti kọ́kọ́ fi ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì kọ́ àwọn tó ń sọ èdè Slavic ní Moravia. Àmọ́, ohun tó ká Rostislav lára ni ipa tí àwọn ẹ̀yà Jámánì ti ní lórí òṣèlú àti ṣọ́ọ̀ṣì. Ó retí pé bí ìsìn bá da òun àti Ilẹ̀ Ọba Kọnsitantinópù pọ̀, ìyẹn yóò ran orílẹ̀-èdè òun lọ́wọ́ láti dòmìnira nínú ọ̀ràn ìṣèlú àti ìsìn.

Olú Ọba náà pinnu àtirán Methodius àti Cyril lọ sí Moravia. Ìwé tí tẹ̀gbọ́n-tàbúrò yìí ti kà, ìmọ̀ ẹ̀kọ́ tí wọ́n ní, àti ọ̀pọ̀ èdè tí wọ́n gbọ́ mú kí wọ́n tóótun láti ṣe irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀. Akọ̀tàn kan ní ọ̀rúndún kẹsàn-án sọ fún wa pé nígbà tí olú ọba náà ń rọ̀ wọ́n láti lọ sí Moravia, ó sọ pé: “Ọmọ ìbílẹ̀ Tẹsalóníkà lẹ̀yin méjèèjì, gbogbo àwọn ará Tẹsalóníkà ló sì ń sọ èdè Slavic tó jíire.”

Ááfábẹ́ẹ̀tì Kan àti Ìtumọ̀ Bíbélì Kan Yọjú

Láàárín àwọn oṣù díẹ̀ kí wọ́n tó gbéra, Cyril múra iṣẹ́ náà nípa híhùmọ̀ ọ̀nà ìkọ̀wé kan fún àwọn tó ń sọ èdè Slavic. Wọ́n sọ pé ọ̀gá ni nínú mímọ ìyàtọ̀ láàárín ìró ohùn. Nítorí ìdí èyí, nípa lílo àwọn lẹ́tà inú èdè Gíríìkì àti ti Hébérù, ó gbìyànjú láti ṣe lẹ́tà kan fún ìró ohùn kọ̀ọ̀kan nínú èdè Slavic. b Àwọn olùwádìí kan gbà gbọ́ pé ó ti lo ọ̀pọ̀ ọdún nídìí mímúra irú ááfábẹ́ẹ̀tì bẹ́ẹ̀ sílẹ̀. Àti pé, bí ááfábẹ́ẹ̀tì tí Cyril mú jáde yẹn ṣe rí gan-an ṣì ń rú àwọn èèyàn lójú.—Wo àpótí náà, “Ṣé Cyrillic ni Tàbí Glagolitic?”

Ní àkókò kan náà, Cyril bẹ̀rẹ̀ ìtòlẹ́sẹẹsẹ ojú ẹsẹ̀ fún títúmọ̀ Bíbélì. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn ti sọ, ó bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú títú gbólóhùn àkọ́kọ́ nínú ìwé Ìhìn Rere Jòhánù láti èdè Gíríìkì sí èdè Slavic, ó lo ááfábẹ́ẹ̀tì tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣe: “Ní ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ni Ọ̀rọ̀ náà wà . . . ” Cyril tẹ̀ síwájú láti túmọ̀ àwọn ìwé Ìhìn Rere mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, àwọn lẹ́tà Pọ́ọ̀lù, àti ìwé Sáàmù.

Ṣé ó dá nìkan ṣiṣẹ́ ọ̀hún ni? Ó jọ pé Methodius ràn án lọ́wọ́. Síwájú sí i, ìwé The Cambridge Medieval History sọ pé: “Ó rọrùn láti fojú inú wò ó pé [Cyril] ní àwọn mìíràn tó ràn án lọ́wọ́, ìyẹn àwọn tí wọ́n ní láti jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Slav gan-an tí wọ́n sì ní ìmọ̀ ẹ̀kọ́ Gíríìkì. Bí a bá wo ìtumọ̀ tó lọ́jọ́ lórí jù lọ, . . . a óò rí ẹ̀rí tó fi hàn pé ìjìnlẹ̀ èdè Slavic ni wọ́n fi kọ ọ́, èyí tó jẹ́ pé àwọn tó mú kó ṣeé ṣe ni àwọn alájọṣe, táwọn fúnra wọn jẹ́ ọmọ ìbílẹ̀ Slav gan-an.” Methodius ló wá parí apá tó ṣẹ́ kù nínú Bíbélì náà, bí a ó ṣe rí i.

“Bí Àwọn Kannakánná Ṣe Ń Ṣù Bo Àwòdì”

Ní 863 Sànmánì Tiwa, Cyril àti Methodius bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ wọn ní Moravia, níbi tí wọ́n ti gbà wọ́n tọwọ́ tẹsẹ̀. Ara iṣẹ́ wọn ni pé kí wọ́n kọ́ àwùjọ èèyàn ibẹ̀ ní ọ̀nà ìkọ̀wé tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ hùmọ̀ ní èdè Slavic, èyí jẹ́ ní àfikún sí títúmọ̀ Bíbélì àtàwọn ìwé ìlànà ìsìn.

Àmọ́ ṣá o, gbogbo ẹ̀ kọ́ ló rọrùn. Àwùjọ àlùfáà ẹ̀yà Frank tó wà ní Moravia ṣàtakò líle koko sí lílo èdè Slavic. Wọ́n rọ̀ mọ́ àbá náà pé èdè mẹ́ta péré ló wà, wọ́n sọ pé kìkì èdè Látìn, Gíríìkì, àti Hébérù nìkan làwọn tẹ́wọ́ gbà fún ìjọsìn. Àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò náà lọ sí Róòmù ní 867 Sànmánì Tiwa, kí póòpù lè ti èdè tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí kọ sílẹ̀ náà lẹ́yìn.

Lójú ọ̀nà, ní Venice, Cyril àti Methodius tún pàdé àwùjọ àwọn àlùfáà tí ń sọ èdè Látìn, táwọn náà tún ń sọ pé èdè mẹ́ta péré ló wà. Ẹnì kan tó kọ ìtàn nípa Cyril ní sànmánì agbedeméjì sọ fún wa pé àwọn bíṣọ́ọ̀bù, àwọn àlùfáà, àtàwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tó wà ládùúgbò náà gbéjà kò ó “bí àwọn kannakánná ṣe ń ṣù bo àwòdì.” Gẹ́gẹ́ bí ohun tí ìtàn náà sọ, Cyril fèsì nípa títọ́ka sí 1 Kọ́ríńtì 14:8, 9, tó kà pé: “Nítorí lóòótọ́, bí kàkàkí bá mú ìpè tí kò dún ketekete jáde, ta ni yóò gbára dì fún ìjà ogun? Lọ́nà kan náà pẹ̀lú, láìjẹ́ pé ẹ sọ ọ̀rọ̀ tí ó rọrùn láti lóye jáde nípasẹ̀ ahọ́n, báwo ni a ó ṣe mọ ohun tí ẹ ń sọ? Ní ti tòótọ́, ẹ óò máa sọ̀rọ̀ sínú afẹ́fẹ́.”

Nígbà tí àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò náà wá dé Róòmù níkẹyìn, Póòpù Adrian Kejì fọwọ́ sí i pé kí wọ́n máa lo èdè Slavic. Lẹ́yìn oṣù bíi mélòó kan, nígbà tí wọ́n ṣì wà ní Róòmù, àìsàn burúkú kan ṣe Cyril. Kò pé oṣù méjì lẹ́yìn náà tó fi kú ní ẹni ọdún méjìlélógójì.

Póòpù Adrian Kejì gba Methodius níyànjú pé kó padà sẹ́nu iṣẹ́ rẹ̀ ní Moravia àti ní àyíká ìlú Nitra, táa wá mọ̀ sí Slovakia báyìí. Kí ọlá àṣẹ póòpù lè túbọ̀ rinlẹ̀ ní àgbègbè yẹn, ó fún Methodius ní lẹ́tà tó fi fọwọ́ sí lílo èdè Slavic, ó sì yàn án sípò bíṣọ́ọ̀bù àgbà. Àmọ́, ní 870 Sànmánì Tiwa, Hermanrich, bíṣọ́ọ̀bù kan tó wá látinú ẹ̀yà Frank, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọmọ Ọba Svatopluk ti Nitra, mú Methodius. Wọ́n tì í mọ́lé fún ọdún méjì ààbọ̀ ní ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé tó wà ní gúúsù ìlà oòrùn Jámánì. Níkẹyìn, Póòpù John Kẹjọ, tó rọ́pò Adrian Kejì, pàṣẹ pé kí wọ́n tú Methodius sílẹ̀, kí wọ́n dá a padà sí àgbègbè rẹ̀, ó sì tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé òun fọwọ́ sí lílo èdè Slavic nínú ìjọsìn.

Àmọ́ àtakò látọ̀dọ̀ àwọn àlùfáà ẹ̀yà Frank kò dáwọ́ dúró. Methodius gbèjà ara rẹ̀ dáadáa lórí ẹ̀sùn àdámọ̀ tí wọ́n fi kàn án, ó sì wá rí ìwé àṣẹ kan tí wọ́n lù lóòtẹ̀ gbà látọ̀dọ̀ Póòpù John Kẹjọ, èyí tó fi hàn kedere pé ó ti tẹ́wọ́ gbà lílo èdè Slavic nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Gẹ́gẹ́ bí ohun tí póòpù John Paul Kejì, tó wà lórí oyè báyìí sọ, Methodius lo ìgbésí ayé rẹ̀ “nínú rírìn láti ibì kan sí ibòmíràn, nínú fífi nǹkan du ara rẹ̀, nínú ìyà, ìkóguntini, àti inúnibíni, . . . ó tiẹ̀ lo àkókò kan nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tó burú jáì.” Ó ṣeni láàánú pé, àwọn bíṣọ́ọ̀bù àtàwọn ọmọ ọba tí wọ́n jẹ́ alátìlẹyìn Róòmù ló wà nídìí èyí.

A Túmọ̀ Odindi Bíbélì

Láìfi àtakò lọ́tùn-ún lósì náà pè, Methodius parí títúmọ̀ apá tó ṣẹ́ kù nínú Bíbélì sí èdè Slavic, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn òǹkọ̀wé bíi mélòó kan, tí wọ́n mọ bí a ṣe ń fi àmì kọ̀wé. Gẹ́gẹ́ bí ìtàn táa gbọ́, ó parí iṣẹ́ bàǹtàbanta yìí láàárín oṣù mẹ́jọ péré. Àmọ́, kò túmọ̀ àwọn ìwé àpókírífà ti àwọn Maccabee o.

Kò rọrùn láti ṣàyẹ̀wò bí ìtumọ̀ tí Cyril àti Methodius ṣe ṣe jẹ́ ojúlówó tó lóde òní. Ìwọ̀nba àwọn ẹ̀dà díẹ̀ ló ṣẹ́ kù lára àwọn ìwé àfọwọ́kọ tí déètì wọ́n sún mọ́ àkókò tí wọ́n kọ́kọ́ ṣe ìtumọ̀ yẹn pàá. Nígbà tí wọ́n ṣàyẹ̀wò ìwọ̀nba díẹ̀ tó ṣẹ́ kù, àwọn onímọ̀ èdè rí i pé ìtumọ̀ náà kúnjú ìwọ̀n, ó sì rọrùn láti lóye. Ìwé Our Slavic Bible sọ pé àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò náà “ní láti fúnra wọn ṣẹ̀dá ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọ̀rọ̀ àti àwọn gbólóhùn tuntun . . . Wọ́n sì ṣe gbogbo èyí lọ́nà tó ṣe rẹ́gí [tó sì] mú kí èdè Slavic di èyí tó ní ọ̀rọ̀ kíkún rẹ́rẹ́ ju ti ìgbàkígbà rí lọ.”

Ogún Kan Tó Wà Pẹ́ Títí

Lẹ́yìn tí Methodius kú ní 885 Sànmánì Tiwa, àwọn ẹ̀yà Frank alátakò wọn lé àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ jáde ní Moravia. Wọ́n wá forí pa mọ́ sí Bohemia, gúúsù Poland, àti Bulgaria. Nípa bẹ́ẹ̀, iṣẹ́ Cyril àti Methodius ń tẹ̀ síwájú, ó sì ń tàn kálẹ̀. Èdè Slavic, tí àwọn tẹ̀gbọ́n-tàbúrò yẹn sọ di èyí tí wọ́n ń kọ sílẹ̀, tó sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ ti wá gbilẹ̀, ó ti gbòòrò, ó sì ti wà ní onírúurú. Lónìí, àwọn èdè tó tan mọ́ Slavic ti pọ̀ tó èdè mẹ́tàlá ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ àti ọ̀pọ̀ èdè àdúgbò.

Síwájú sí i, ìsapá onígboyà tí Cyril àti Methodius ṣe láti túmọ̀ Bíbélì so èso rere nínú onírúurú èdè Slavic tí wọ́n fi túmọ̀ Ìwé Mímọ́ tó wà lárọ̀ọ́wọ́tó wa lóde òní. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ tó ń sọ àwọn èdè wọ̀nyí ń jàǹfààní nípa níní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní èdè ìbílẹ̀ wọn. Láìfi àtakò líle koko pè, ẹ wo bí ọ̀rọ̀ náà ṣe jóòótọ́ tó pé: ‘Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wa yóò wà fún àkókò tí ó lọ kánrin’!—Aísáyà 40:8.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Àwọn èdè Slavic ni wọ́n ń sọ ní Ìhà Ìlà Oòrùn àti Àárín Gbùngbùn Yúróòpù, títí kan èdè Russian, Ukrainian, Serbian, Polish, Czech, Bulgarian, àtàwọn èdè tó fara pẹ́ ẹ.

b “Èdè Slavic,” bí a ṣe lò ó nínú àpilẹ̀kọ yìí, tọ́ka sí èdè ìbílẹ̀ Slavic tí Cyril àti Methodius lò fún iṣẹ́ tí wọ́n wá ṣe àti ìwé tí wọ́n kọ. Àwọn kan lónìí máa ń lo ọ̀rọ̀ náà “Èdè Slavic Àtijọ́” tàbí “Èdè Slavic Àtijọ́ Tí Ṣọ́ọ̀ṣì Lò.” Àwọn onímọ̀ èdè gbà pé àwọn Slav ò ní èdè àjọsọ kankan ní ọ̀rúndún kẹsàn-án Sànmánì Tiwa.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 29]

Ṣé Cyrillic ni Tàbí Glagolitic?

Irú ááfábẹ́ẹ̀tì tí Cyril hùmọ̀ rẹ̀ tí fa ọ̀pọ̀ àríyànjiyàn, níwọ̀n bí àwọn onímọ̀ èdè ò ti mọ irú ááfábẹ́ẹ̀tì tó jẹ́ dájú. Ááfábẹ́ẹ̀tì tí wọ́n ń pè ní Cyrillic ni wọ́n gbé ka ááfábẹ́ẹ̀tì Gíríìkì, pẹ̀lú lẹ́tà bíi méjìlá tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ tí wọ́n hùmọ̀ láti dúró fún ìró èdè Slavic tí kò sí nínú ti Gíríìkì. Àmọ́, wọ́n lo ọ̀nà ìkọ̀wé mìíràn tó yàtọ̀ pátápátá, èyí táa mọ̀ sí Glagolitic, láti kọ àwọn kan lára ìwé àfọwọ́kọ èdè Slavic ìjímìjí, èyí sì ni ọ̀nà ìkọ̀wé tí ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé gbà pé Cyril hùmọ̀ rẹ̀. Díẹ̀ lára àwọn lẹ́tà Glagolitic náà fara hàn bí ìkọ̀wé alákọpọ̀ ti Gíríìkì tàbí Hébérù. Wọ́n sì lè ti mú àwọn kan wá látinú àwọn lẹ́tà alásopọ̀ ti sànmánì agbedeméjì, ṣùgbọ́n èyí tó pọ̀ jù níbẹ̀ ló jẹ́ àkọ́ṣe irú rẹ̀, tó sì díjú. Glagolitic dà bí èyí tó yàtọ̀ pátápátá, tó sì jẹ́ àkọ́ṣe irú rẹ̀. Àmọ́, ọ̀nà ìkọ̀wé Cyrillic ni èyí tó wá di ọ̀nà ìkọ̀wé ní èdè Russian, Ukrainian, Serbian, Bulgarian, àti Makedóníà lóde òní, yàtọ̀ sí èdè méjìlélógún mìíràn, tí àwọn kan lára wọn kì í ṣe èdè Slavic.

[Artwork—Cyrillic and Glagolitic characters]

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 31]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Òkun Baltic

(Poland)

Bohemia (Czechia)

Moravia (E. Czechia, W. Slovakia, W. Hungary)

Nitra

ÌJỌBA ÌLÀ OÒRÙN Ẹ̀YÀ FRANK (Jámánì àti Austria)

ÍTÁLÌ

Venice

Róòmù

Òkun Mẹditaréníà

BULGARIA

GÍRÍÌSÌ

Tẹsalóníkà

(Crimea)

Òkun Dúdú

Bítíníà

Kọnsitantinópù (Istanbul)

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Bíbélì kan ní èdè Slavic tí wọ́n fi ọ̀nà ìkọ̀wé Cyrillic kọ láti 1581

[Credit Line]

Bíbélì: Narodna ní univerzitetna knjiz̆nica-Slovenija-Ljubljana