Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Iṣẹ́ Abẹ Láìlo Ẹ̀jẹ̀—“Ìtọ́jú Ìṣègùn Tọ́kàn Àwọn Èèyàn Ń Fà sí Báyìí”

Iṣẹ́ Abẹ Láìlo Ẹ̀jẹ̀—“Ìtọ́jú Ìṣègùn Tọ́kàn Àwọn Èèyàn Ń Fà sí Báyìí”

Iṣẹ́ Abẹ Láìlo Ẹ̀jẹ̀—“Ìtọ́jú Ìṣègùn Tọ́kàn Àwọn Èèyàn Ń Fà sí Báyìí”

LÁBẸ́ àkọlé náà, “Iṣẹ́ abẹ ‘Láìlo Ẹ̀jẹ̀,’” ìwé ìròyìn Maclean’s ròyìn pé àwọn oníṣègùn jákèjádò Kánádà ti “ní ìlànà ìtọ́jú tuntun tó jẹ́ pé láti ohun tó lé ní ọdún márùn-ún sẹ́yìn ló ti sọ ohun tí wọ́n ń pè ní iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ di ìtọ́jú ìṣègùn tọ́kàn àwọn èèyàn ń fà sí báyìí.” Brian Muirhead tó jẹ́ oníṣègùn apàmọ̀lárakú ní Ilé Ìṣètọ́jú Àrùn ní Winnipeg jẹ́ ọ̀kan lára wọn. Kí ló dé tó fi ń wá ọ̀nà ìtọ́jú mìíràn tí kò la lílo ẹ̀jẹ̀ lọ?

Ní 1986, Dókítà Muirhead tẹ́wọ́ gba ìpèníjà ṣíṣe iṣẹ́ abẹ fún ọkùnrin kan tó jẹ́ ẹni àádọ́rin ọdún, tó ní ọgbẹ́ inú tó ń ṣẹ̀jẹ̀. Ìgbàgbọ́ ọkùnrin yìí táa gbé ka Bíbélì gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ti mú kó sọ pé kí wọ́n tọ́jú òun láìfa ẹ̀jẹ̀ sóun lára. (Ìṣe 15:28, 29) Ìwé ìròyìn Maclean’s ròyìn pé, Dókítà Muirhead “fàbọ̀ sórí lílo àṣà tí wọn kì í sábà lò, ìyẹn ni àṣà fífa àpòpọ̀ oníyọ̀ sí aláìsàn náà lára kí ìwọ̀n ìfúnpá rẹ̀ má bàa lọ sílẹ̀. Ìtọ́jú náà kẹ́sẹ járí, ó sì túbọ̀ fìdí ohun tí Muirhead ń rò lọ́kàn tẹ́lẹ̀ múlẹ̀ pé ‘a ti ń fa ẹ̀jẹ̀ sáwọn èèyàn lára jù. Mo rò pé àkókò ti tó wàyí láti wá ọgbọ́n mìíràn dá.’”

Ohun tó fa wíwá ọ̀nà láti ṣe iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ kiri ni “àníyàn nípa bí wọn ó ṣe máa rí ẹni fi ẹ̀jẹ̀ sílẹ̀ lọ́jọ́ iwájú—àti nítorí ẹ̀rù tó ń ba ọ̀pọ̀ aláìsàn pé àwọn lè kó fáírọ́ọ̀sì àrùn níbi táwọn ti ń gbẹ̀jẹ̀ sára.” Ọpẹ́lọpẹ́ ìwádìí tí àwọn dókítà tó mọwọ́ yí padà ṣe, yàtọ̀ sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti jàǹfààní rẹ̀ pẹ̀lú. Ìwé ìròyìn Maclean’s sọ pé: “Yàtọ̀ sí pé iṣẹ́ abẹ láìlo ẹ̀jẹ̀ kì í jẹ́ kí wọ́n fàjẹ̀ síni lára, ó tún ń dín ewu kíkó àrùn látinú ẹ̀jẹ̀ tó lárùn kù, bó ti wù kí àrùn náà kéré tó.” Síbẹ̀ ẹ̀jẹ̀ “tí kò lárùn” pàápàá lè ṣokùnfà ewu àkóràn nípa sísọ agbára ìdènà àrùn aláìsàn náà di aláìlágbára fúngbà díẹ̀.

Kí ló fà á táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń yàgò pátápátá fún ìtọ́jú èyíkéyìí tó bá la lílo ẹ̀jẹ̀ lọ? O lè fẹ́ láti ka ìwé pẹlẹbẹ How Can Blood Save Your Life? Inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yóò dùn láti fún ọ.