Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ O Lè Ní Ayọ̀ Tòótọ́?

Ǹjẹ́ O Lè Ní Ayọ̀ Tòótọ́?

Ǹjẹ́ O Lè Ní Ayọ̀ Tòótọ́?

GEORGE máa ń kí gbogbo èèyàn pẹ̀lú ẹ̀rín músẹ́. Lójú tirẹ̀, ẹ̀bùn tó níye lórí tó yẹ kéèyàn gbádùn ni ìwàláàyè jẹ́. Ayọ̀ àti ẹ̀mí nǹkan-yóò-dára tó ní làwọn èèyàn fi ń dá a mọ̀—pàápàá jù lọ nígbà tó bẹ̀rẹ̀ sí di hẹ́gẹhẹ̀gẹ nítorí ọjọ́ ogbó. Títí di ọjọ́ ikú George làwọn èèyàn fi mọ̀ ọ́n sẹ́ni tínú rẹ̀ máa ń dùn. Ǹjẹ́ o máa ń láyọ̀ bíi ti George? Ǹjẹ́ o máa ń wo ọjọ́ kọ̀ọ̀kan bí ẹ̀bùn tó yẹ kóo gbádùn? Àbí ìrònú pé ojú ọjọ́ míì tún ti mọ́ máa ń mú ọ dágunlá tàbí kí ó tiẹ̀ máa já ọ láyà pàápàá? Ṣé ohun kan wà tí kì í múnú rẹ dùn ni?

Ayọ̀ túmọ̀ sí ipò àlàáfíà, tí kì í sábà yí padà. Ó jẹ́ ohun tí ìmọ̀lára ẹni máa ń fi hàn, tó ń bẹ̀rẹ̀ látorí níní ìtẹ́lọ́rùn títí dórí níní ayọ̀ tó jinlẹ̀, tó sì pọ̀ àti níní ìfẹ́ tí a dá mọ́ni pé kí irú ipò yẹn máa bá a lọ bẹ́ẹ̀. Ǹjẹ́ irú ayọ̀ báyẹn tiẹ̀ wà ní ti gidi?

Lóde òní, èrò tí ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà ń gbé lárugẹ ni pé àwọn èèyàn á láyọ̀ bí wọ́n bá lówó débi tó tẹ́ wọn lọ́rùn. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn ló máa ń forí ṣe fọrùn ṣe níbi tí wọ́n ti ń ṣe kìtàkìtà láti dọlọ́rọ̀. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, ọ̀pọ̀ ló máa ń ba àjọṣe wọn pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn jẹ́, tí wọ́n sì ń fi àwọn nǹkan pàtàkì mìíràn nínú ìgbésí ayé du ara wọn. Báwọn èèrà ṣe máa ń ṣe lórí ọ̀gán ni irú àwọn èèyàn bẹ́ẹ̀ ṣe máa ń sá sókè sá sódò, tí wọn ò sì ní àkókò láti ronú nípa ohun tí wọ́n ń ṣe tàbí láti gbọ́ tàwọn ẹlòmíràn. Abájọ tí ìròyìn kan nínú ìwé ìròyìn Los Angeles Times fi sọ pé: “Ńṣe ni iye èèyàn táa ṣàyẹ̀wò pé wọ́n sorí kọ́ túbọ̀ ń pọ̀ sí i, tí àwọn èèyàn sì ń ní [ìsoríkọ́] ní ọjọ́ orí tó túbọ̀ ń kéré sí i. . . . Àwọn oògùn tí ń pẹ̀rọ̀ sí ìdààmú ọkàn ni ilé iṣẹ́ oògùn sọ pé àwọn èèyàn ń rà jù lọ.” Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ ló ń lo àwọn oògùn tí kò bófin mu tàbí tí wọ́n ń gbìyànjú àtifi ọtí líle bo ìrònú mọ́lẹ̀. Àwọn kan wà tí wọ́n kàn máa ń náwó ní ìná àpà nígbà tí wọ́n bá ní ẹ̀dùn ọkàn. Nínú ìwádìí kan tí wọ́n ṣe, ìwé ìròyìn kan tó ń jẹ́ The Guardian ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì sọ pé: “Àwọn obìnrin ló pọ̀ jù lọ nínú àwọn tó máa ń fi nǹkan rírà láìbojúwẹ̀yìn pàrònú rẹ́. Nǹkan bí ìlọ́po mẹ́ta ìgbà ni tàwọn obìnrin fi ju tàwọn ọkùnrin lọ nínú ká máa rajà nígbà téèyàn bá sorí kọ́.”

Àmọ́ ṣá o, ayọ̀ tòótọ́ kì í ṣe ohun táa lè rí nílé ìtajà, kò sí nínú ìgò ọtí, a ò lè rí i nínú oògùn, kì í ṣe ohun táa lè rí nínú ike abẹ́rẹ́ tàbí nínú àkáǹtì ẹni ní báńkì. Ayọ̀ kì í ṣe ohun títà; ọ̀fẹ́ ni. Ibo la ti lè rí ẹ̀bùn tó níye lórí yẹn? A óò jíròrò ìyẹn nínú àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e.