Àwọn Onígboyà Olùpàwàtítọ́mọ́ Borí Inúnibíni Ìjọba Násì
Ẹ Dúró Lọ́nà Pípé Pẹ̀lú Ìgbàgbọ́ Tó Fìdí Múlẹ̀
Àwọn Onígboyà Olùpàwàtítọ́mọ́ Borí Inúnibíni Ìjọba Násì
“ỌMỌ mi, jẹ́ ọlọ́gbọ́n, kí o sì mú ọkàn-àyà mi yọ̀, kí n lè fún ẹni tí ń ṣáátá mi lésì.” (Òwe 27:11) Ọ̀rọ̀ ìyànjú tí ń wúni lórí yìí fi hàn pé àwọn ẹ̀dá onílàákàyè tí Ọlọ́run dá lè mú inú Jèhófà dùn nípa jíjẹ́ olóòótọ́ sí i, kí wọ́n sì dúró ṣinṣin tì í. (Sefanáyà 3:17) Àmọ́ o, Sátánì, olùṣáátá náà, ti pinnu pé òun máa ba ìwà títọ́ àwọn tí ń sin Jèhófà jẹ́.—Jóòbù 1:10, 11.
Ìbínú Sátánì ti lékenkà sáwọn èèyàn Jèhófà, pàápàá jù lọ láti ìgbà tí a fi í sọ̀kò láti ọ̀run sí sàkáání ilẹ̀ ayé ní apá ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún ogún. (Ìṣípayá 12:10, 12) Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni tòótọ́ ti ‘dúró lọ́nà pípé pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tó fìdí múlẹ̀,’ wọ́n sì ti pa ìwà títọ́ wọn mọ́ sí Ọlọ́run. (Kólósè 4:12) Ní ráńpẹ́, ẹ jẹ́ ká ṣàgbéyẹ̀wò àpẹẹrẹ títayọ kan nípa irú pípa ìwà títọ́ mọ́ bẹ́ẹ̀—ìyẹn ni ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní orílẹ̀-èdè Jámánì, ṣáájú àti nígbà Ogun Àgbáyé Kejì.
Ìgbòkègbodò Onítara Fa Ìdánwò Ìwà Títọ́
Ní àwọn ọdún 1920 àti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1930, àwọn Bibelforscher, ìyẹn orúkọ táa mọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sí nígbà yẹn ní Jámánì, pín ọ̀pọ̀ ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní ìpíndọ́gba, láàárín ọdún 1919 sí 1933, wọ́n pín àwọn ìwé ńlá, ìwé kéékèèké, tàbí ìwé ìròyìn mẹ́jọ-mẹ́jọ fún ìdílé kọ̀ọ̀kan ní Jámánì.
Nígbà yẹn lọ́hùn-ún, Jámánì wà lára ibi tí àwọn ẹni àmì òróró ọmọ ẹ̀yìn Kristi pọ̀ sí jù lọ. Àní, lára 83,941 èèyàn tó jẹ Oúnjẹ Alẹ́ Olúwa kárí ayé ní 1933, àwọn tó ń gbé ní Jámánì lára wọn fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ìpín ọgbọ̀n nínú ọgọ́rùn-ún. Kò pẹ́ rárá tí àwọn Ẹlẹ́rìí ará Jámánì wọ̀nyí fi bẹ̀rẹ̀ sí fojú winá ìdánwò rírorò nítorí ìwà títọ́ wọn. (Ìṣípayá 12:17; 14:12) Wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí lé wọn kúrò lẹ́nu iṣẹ́, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí túlé wọn wò, wọ́n sì ń lé wọn kúrò níléèwé. Nígbà tíyẹn ò sì ràn án, wọ́n wá bẹ̀rẹ̀ sí lù wọ́n, wọ́n ń fọlọ́pàá mú wọn, wọ́n sì ń sọ wọ́n sẹ́wọ̀n. (Àwòrán 1) Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ní àwọn ọdún tó ṣáájú Ogun Àgbáyé Kejì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà jẹ́ ìdá márùn-ún sí mẹ́wàá nínú ọgọ́rùn-ún lára àwọn tí wọ́n fi sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́.
Ìdí Tí Ìjọba Násì Fi Ṣe Inúnibíni Sáwọn Ẹlẹ́rìí
Àmọ́ kí ló dé tí inú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ń bí ìjọba Násì? Nínú ìwé rẹ̀, Hitler—1889-1936: Hubris, ọ̀jọ̀gbọ́n ẹ̀kọ́ nípa ìtàn tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ian Kershaw sọ pé wọ́n dojú inúnibíni kọ àwọn Ẹlẹ́rìí nítorí pé wọ́n kọ̀ “láti ṣe gbogbo ohun tí ìjọba Násì ń fẹ́.”
Ìwé náà Betrayal—German Churches and the Holocaust, tí Robert P. Ericksen, tí í ṣe ọ̀jọ̀gbọ́n nínú ẹ̀kọ́ ìtàn àti Susannah Heschel, tí í ṣe ọ̀jọ̀gbọ́n nínú àṣà àwọn Júù, ṣe olóòtú rẹ̀, ṣàlàyé pé àwọn Ẹlẹ́rìí “kọ̀ láti lọ́wọ́ sí ìwà ipá tàbí ogun jíjà. . . . Àìdásí-tọ̀tún-tòsì nínú ọ̀ràn ìṣèlú ni ìdúró
àwọn Ẹlẹ́rìí, èyí sì túmọ̀ sí pé wọn ò ní dìbò fún Hitler, wọn ò sì ní júbà Hitler.” Ìwé kan náà fi kún un pé èyí mú inú bí ìjọba Násì, wọ́n sì ṣe tán láti fojú àwọn Ẹlẹ́rìí han èèmọ̀, nítorí pé “Ìjọba Násì kò gba kí ẹnikẹ́ni kọ ọ̀rọ̀ sáwọn lẹ́nu.”Wọ́n Fẹ̀hónú Hàn Kárí Ayé, Nìjọba Bá Koná Mọ́ Inúnibíni Wọn
Ní February 9, 1934, Joseph F. Rutherford, tó ń bójú tó iṣẹ́ náà nígbà yẹn, fi lẹ́tà ẹ̀hónú rán ońṣẹ́ pàtàkì kan sí Hitler nítorí ìwà òǹrorò tí ìjọba Násì ń hù. (Àwòrán 2) Ní October 7, 1934, lẹ́yìn lẹ́tà Rutherford, iye àwọn lẹ́tà àti wáyà ẹ̀hónú tó pọ̀ tó ọ̀kẹ́ kan [20,000] làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní àádọ́ta orílẹ̀-èdè, títí kan Jámánì, fi ránṣẹ́ sí Hitler.
Bí ìjọba Násì ṣe tutọ́ sókè tó fojú gbà á nìyẹn o, tó wá koná mọ́ inúnibíni náà. Ní April 1, 1935, wọ́n fòfin de àwọn Ẹlẹ́rìí jákèjádò orílẹ̀-èdè yẹn. Nígbà tó sì di August 28, 1936, Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Gestapo wá bá wọn tẹsẹ̀ bọ ṣòkòtò kan náà. Ṣùgbọ́n àwọn Ẹlẹ́rìí “ń pín ìwé ìléwọ́ wọn nìṣó, wọ́n sì di ìgbàgbọ́ wọn mú láìfọ̀tápè,” gẹ́gẹ́ bí ìwé Betrayal—German Churches and the Holocaust ti wí.
Fún àpẹẹrẹ, pẹ̀lú gbogbo gìràgìrà Àjọ Ọlọ́pàá Ọ̀tẹlẹ̀múyẹ́ Gestapo, ní December 12, 1936, àwọn Ẹlẹ́rìí tó pọ̀ tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta [3,500] pín ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà mẹ́wàá-mẹ́wàá ẹ̀dà ìpinnu kan táa tẹ̀ jáde, èyí tó sọ̀rọ̀ nípa bí wọ́n ṣe ń hàn wọ́n léèmọ̀. Ilé Ìṣọ́ ròyìn nípa ìgbòkègbodò yìí pé: “Ó jẹ́ ìṣẹ́gun ńláǹlà tó mú kí ọkàn àwọn ọ̀tá gbọgbẹ́ gidigidi, àmọ́ ó jẹ́ ayọ̀ ńláǹlà fáwọn òṣìṣẹ́ olóòótọ́.”—Róòmù 9:17.
Inúnibíni Ò Ràn Án!
Ìjọba Násì ń dọdẹ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nìṣó. Nígbà tó fi máa di 1939, wọ́n ti sọ ẹgbẹ̀rún mẹ́fà lára wọn sẹ́wọ̀n, wọ́n sì ti kó ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ sáwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́. (Àwòrán 3) Báwo ni nǹkan ṣe rí nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì parí? Àwọn bí ẹgbẹ̀rún méjì lára àwọn Ẹlẹ́rìí tí wọ́n fi sẹ́wọ̀n ti kú, pípa ni wọ́n pa àwọn tó lé ní àádọ́ta lé rúgba [250] lára wọn. Àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n náà, Ericksen àti Heschel kọ̀wé pé, síbẹ̀síbẹ̀ “lápapọ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà di ìgbàgbọ́ wọn mú lójú wàhálà yìí.” Ìyẹn ló fi jẹ́ pé nígbà tí ìjọba Hitler dojú dé, àwọn Ẹlẹ́rìí tó lé ní ẹgbẹ̀rún kan ló jáde wá gẹ́gẹ́ bí aṣẹ́gun látinú àwọn àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́.—Àwòrán 4; Ìṣe 5:38, 39; Róòmù 8:35-37.
Kí ló fún àwọn èèyàn Jèhófà lókun láti fara da inúnibíni? Adolphe Arnold, tó lọ sí àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tó sì bọ̀, ṣàlàyé pé: “Kódà bí okun inú rẹ bá tilẹ̀ ti tán pátápátá, Jèhófà rí ọ, ó mọ ohun tójú rẹ ń rí, yóò sì fún ọ ní okun tóo nílò láti fàyà rán ìṣòro náà, kí o sì dúró gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́. Ọwọ́ rẹ̀ kò kúrú rárá.”
Ọ̀rọ̀ wòlíì Sefanáyà mà kúkú bá àwọn Kristẹni olóòótọ́ wọ̀nyẹn mu o! Ó kéde pé: “Jèhófà Ọlọ́run rẹ wà ní àárín rẹ. Bí Ẹni tí ó ní agbára ńlá, òun yóò gbà là. Òun yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà lórí rẹ pẹ̀lú ayọ̀ yíyọ̀.” (Sefanáyà 3:17) Ǹjẹ́ kí gbogbo àwọn olùjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ lónìí fara wé ìgbàgbọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí olóòótọ́ wọ̀nyẹn, tí wọ́n pa ìwà títọ́ mọ́ lójú gbogbo inúnibíni tí ìjọba Násì ṣe sí wọ́n, kí àwọn náà sì múnú Jèhófà dùn.—Fílípì 1:12-14.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]
Państwowe Muzeum Oświȩcim-Brzezinka, nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda the USHMM Photo Archives