Bíborí Àìpé Ẹ̀dá
Bíborí Àìpé Ẹ̀dá
“Gbígbé èrò inú ka ẹran ara túmọ̀ sí ikú.”—RÓÒMÙ 8:6.
1. Ojú wo làwọn kan fi ń wo ara ẹ̀dá ènìyàn, ìbéèrè wo ló sì yẹ ká gbé yẹ̀ wò?
“ÈMI yóò gbé ọ lárugẹ, nítorí pé lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu.” (Sáàmù 139:14) Ohun tí onísáàmù náà Dáfídì kọ lórin nìyẹn nígbà tó ń ronú nípa ọ̀kan lára iṣẹ́ ìṣẹ̀dá Jèhófà, èyíinì ni ara ẹ̀dá ènìyàn. Àmọ́ àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn kan ò fara mọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn tó bójú mu yìí, ńṣe ni wọ́n kà á sí pé ara jẹ́ ilé ẹ̀ṣẹ̀ àti irinṣẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Wọ́n pe ara ní “ibùgbé àìmọ̀kan, ìpìlẹ̀ ìwà abèṣe, oko ẹrú ìwà ìbàjẹ́, ìyẹ̀wù ìwà ibi, àgọ́ ìbànújẹ́, òkú òró, sàréè tí ń rìn kiri.” Lóòótọ́ sì ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Nínú ẹran ara mi, kò sí ohun rere tí ń gbé ibẹ̀.” (Róòmù 7:18) Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ èyí ha túmọ̀ sí pé a ti há sọ́wọ́ ẹran ara ẹ̀ṣẹ̀ nìyẹn bí?
2. (a) Kí ni “gbígbé èrò inú ka ẹran ara” túmọ̀ sí? (b) Ìforígbárí wo ló ń ṣẹlẹ̀ láàárín “ẹran ara” àti “ẹ̀mí” nínú àgọ́ ara àwọn tó ń fẹ́ wu Ọlọ́run?
2 Nígbà míì, Ìwé Mímọ́ máa ń lo èdè náà “ẹran ara” fún ipò àìpé tí ẹ̀dá bá ara rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí àtọmọdọ́mọ Ádámù ọlọ̀tẹ̀. (Éfésù 2:3; Sáàmù 51:5; Róòmù 5:12) Ohun táa jogún látọ̀dọ̀ rẹ̀ ti fa “àìlera ẹran ara.” (Róòmù 6:19) Pọ́ọ̀lù sì kìlọ̀ pé: “Gbígbé èrò inú ka ẹran ara túmọ̀ sí ikú.” (Róòmù 8:6) “Gbígbé èrò inú ka ẹran ara” lọ́nà yìí túmọ̀ sí kí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara àìpé máa tini ṣe nǹkan. (1 Jòhánù 2:16) Nítorí náà, bí a ti ń gbìyànjú láti wu Ọlọ́run, ìforígbárí máa ń ṣẹlẹ̀ ṣáá láàárín ipò tẹ̀mí wa àti ipò àìpé wa, tó ń gbìyànjú láti fagbára mú wa láti ṣe “àwọn iṣẹ́ ti ara.” (Gálátíà 5:17-23; 1 Pétérù 2:11) Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé ìfagagbága tí ń muni lómi, èyí tí ń lọ lọ́wọ́ nínú àgọ́ ara rẹ̀ yìí, ó wá kígbe pé: “Èmi abòṣì ènìyàn! Ta ni yóò gbà mí lọ́wọ́ ara tí ń kú ikú yìí?” (Róòmù 7:24) Ṣé Pọ́ọ̀lù ti wá kó sínú pańpẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ láìlè ja àjàbọ́ ni? Bíbélì dáhùn pé ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ rárá!
Ìdẹwò àti Ẹ̀ṣẹ̀ Ń Bẹ Lóòótọ́
3. Ojú wo lọ̀pọ̀ èèyàn fi ń wo ẹ̀ṣẹ̀ àti ìdẹwò, àmọ́ ìkìlọ̀ wo ni Bíbélì fún wa nípa irú ojú ìwòye bẹ́ẹ̀?
3 Lójú ọ̀pọ̀ èèyàn lónìí, kò sí nǹkan kan tó ń jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀. Àwọn kan ń lo ọ̀rọ̀ náà “ẹ̀ṣẹ̀” lọ́nà ẹ̀fẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ ayé àtijọ́ láti fi ṣàpèjúwe kùdìẹ̀-kudiẹ ẹ̀dá. Wọn ò gbà pé “a gbọ́dọ̀ fi gbogbo wa hàn kedere níwájú ìjókòó ìdájọ́ Kristi, kí olúkúlùkù lè gba ìpín èrè tirẹ̀ fún àwọn ohun tí ó ti ṣe nínú ara, gẹ́gẹ́ bí àwọn ohun tí ó ti fi ṣe ìwà hù, yálà ó jẹ́ rere tàbí búburú.” (2 Kọ́ríńtì 5:10) Àwọn míì tiẹ̀ lè sọ pé àwọn ò ka ìdẹwò sí nǹkan bàbàrà. Níbi táwọn kan ń gbé, ìgbádùn ojú ẹsẹ̀ nìkan ni wọ́n mọ̀, ì báà jẹ́ ní ti jíjẹ, tàbí ní ti ìbálòpọ̀, tàbí ní ti fàájì, tàbí ní ti kí nǹkan ṣẹnuure. Kì í ṣe pé gbogbo nǹkan ń wọ̀ wọ́n lójú nìkan ni, ṣùgbọ́n wọ́n tún ń fẹ́ kó tẹ àwọn lọ́wọ́ kíákíá! (Lúùkù 15:12) Fàájì ojú ẹsẹ̀ yẹn nìkan ni wọ́n mọ̀, kò séyìí tó kàn wọ́n nípa ayọ̀ ọjọ́ iwájú ti “ìyè tòótọ́.” (1 Tímótì 6:19) Àmọ́ Bíbélì kọ́ wa pé ká máa ronú jinlẹ̀, ká máa ríran rí ọ̀ọ́kán, kí igi ganganran kankan má bàa gún wa lójú, bóyá nípa tẹ̀mí tàbí lọ́nà míì. Òwe kan táa mí sí sọ pé: “Afọgbọ́nhùwà tí ó ti rí ìyọnu àjálù ti fi ara rẹ̀ pa mọ́; aláìní ìrírí tí ó ti gba ibẹ̀ kọjá ti jìyà àbájáde rẹ̀.”—Òwe 27:12.
4. Ọ̀rọ̀ ìṣítí tó wà nínú 1 Kọ́ríńtì 10:12, 13 wo ni Pọ́ọ̀lù sọ?
4 Nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sáwọn Kristẹni tí ń gbé ní Kọ́ríńtì—tó jẹ́ ìlú tí gbogbo èèyàn kà sí ìlú tó kún fún ìwàkiwà—ó fún wọn ní ìkìlọ̀ tó yẹ nípa ìdẹwò àti agbára ẹ̀ṣẹ̀. Ó sọ pé: “Kí ẹni tí ó bá rò pé òun dúró kíyè sára kí ó má bàa ṣubú. Kò sí ìdẹwò kankan tí ó ti bá yín bí kò ṣe ohun tí ó wọ́pọ̀ fún àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́, kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.” (1 Kọ́ríńtì 10:12, 13) Gbogbo wa—lọ́mọdé lágbà, lọ́kùnrin àti lóbìnrin—là ń rí ọ̀pọ̀ ìdẹwò níléèwé, níbi iṣẹ́, tàbí níbòmíì. Torí náà, ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀rọ̀ Pọ́ọ̀lù yẹ̀ wò, ká sì wo ẹ̀kọ́ táa lè rí kọ́ nínú rẹ̀.
Má Ṣe Dá Ara Rẹ Lójú Jù
5. Èé ṣe tí ewu fi wà nínú dídá ara ẹni lójú jù?
5 Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Kí ẹni tí ó bá rò pé òun dúró kíyè sára kí ó má bàa ṣubú.” Ewu ńlá ń bẹ nínú fífọwọ́sọ̀yà pé mìmì kan ò lè mì wá tó bá kan ọ̀ràn ìwà rere. Irú ẹ̀mí yẹn fi hàn pé a ò mọ ohun tí wọ́n ń pè ní ẹ̀ṣẹ̀ àti bó ṣe lágbára tó. Níwọ̀n bí àwọn èèyàn bíi Mósè, Dáfídì, Sólómọ́nì, àti àpọ́sítélì Pétérù ti kó sínú pańpẹ́ ẹ̀ṣẹ̀, ǹjẹ́ ó yẹ ká máa ronú pé ẹ̀ṣẹ̀ ò lè lé wa bá? (Númérì 20:2-13; 2 Sámúẹ́lì 11:1-27; 1 Àwọn Ọba 11:1-6; Mátíù 26:69-75) Ìwé Òwe 14:16 sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n bẹ̀rù, ó sì yí padà kúrò nínú ìwà búburú, ṣùgbọ́n arìndìn ń bínú kíkankíkan, ó sì ní ìgbọ́kànlé nínú ara rẹ̀.” Síwájú sí i, Jésù sọ pé: “Ẹ̀mí ń háragàgà, ṣùgbọ́n ẹran ara ṣe aláìlera.” (Mátíù 26:41) Níwọ̀n bí kò ti sí ẹ̀dá aláìpé tó mórí bọ́ pátápátá lọ́wọ́ ìtẹ̀sí láti hùwà ìbàjẹ́, ó yẹ ká fọwọ́ pàtàkì mú ìkìlọ̀ Pọ́ọ̀lù, ká sì kọjú ìjà sí ìdẹwò, àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, a lè bá ara wa níbi tí kò yẹ.—Jeremáyà 17:9.
6. Ìgbà wo ló yẹ ká múra sílẹ̀ de ìdẹwò, lọ́nà wo sì ni?
6 Ó bọ́gbọ́n mu láti múra sílẹ̀ de wàhálà tó lè dé bá wa lójijì. Ásà Ọba rí i pé sáà àlàáfíà ni àkókò yíyẹ láti mọ odi. (2 Kíróníkà 14:2, 6, 7) Ó mọ̀ pé á ti pẹ́ jù láti ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí múra sílẹ̀ nígbà tí ogun bá dé. Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, ìgbà tí ọkàn balẹ̀ pẹ̀sẹ̀, tí kò sí gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n kankan, ló dáa jù kéèyàn ṣe àwọn ìpinnu nípa ohun tó yẹ ní ṣíṣe nígbà tí ìdẹwò bá dé. (Sáàmù 63:6) Dáníẹ́lì àtàwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ olùbẹ̀rù Ọlọ́run ti pinnu láti rọ̀ mọ́ òfin Jèhófà kó tó di pé wọ́n fẹ́ fagbára mú wọn jẹ àwọn oúnjẹ adùnyùngbà ọba. Ìyẹn ni kò fi sí ọ̀ràn lọ-ká-bọ̀ kí wọ́n tó pinnu láti rọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ wọn, tí wọ́n sì kọ̀ jálẹ̀ lójú ẹsẹ̀ pé àwọn ò ní jẹ oúnjẹ àìmọ́ náà. (Dáníẹ́lì 1:8) Kí àwọn ipò tó lè mú ká juwọ́ sílẹ̀ tó dé, ló yẹ ká ti pinnu láìyẹsẹ̀ láti rọ̀ mọ́ ìwà mímọ́ wa. Ìyẹn la fi lè ní agbára láti dènà ẹ̀ṣẹ̀.
7. Èé ṣe tó fi ń tuni nínú láti mọ̀ pé àwọn èèyàn ti bá ìdẹwò jà, wọ́n sì ti borí?
7 Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ, pé: “Kò sí ìdẹwò kankan tí ó ti bá yín bí kò ṣe ohun tí ó wọ́pọ̀ fún àwọn ènìyàn” mà tù wá nínú o! (1 Kọ́ríńtì 10:13) Àpọ́sítélì Pétérù kọ̀wé pé: “Ẹ mú ìdúró yín lòdì sí [Èṣù], ní dídúró gbọn-in nínú ìgbàgbọ́, ní mímọ̀ pé àwọn ohun kan náà ní ti ìyà jíjẹ ní ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo ẹgbẹ́ àwọn ará yín nínú ayé.” (1 Pétérù 5:9) Bẹ́ẹ̀ ni o, ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti bá irú ìdẹwò bẹ́ẹ̀ jà, tí wọ́n sì borí pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ Ọlọ́run, àwa náà lè borí. Àmọ́ o, gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tòótọ́ tí ń gbé nínú ayé oníwàkiwà yìí, gbogbo wa lè retí láti rí ìdẹwò, bó pẹ́ bó yá. Báwo wá ni a ṣe lè ní ìdánilójú pé a lè borí àìpé ẹ̀dá àti ìtẹ̀sí láti dẹ́ṣẹ̀?
A Lè Bá Ìdẹwò Jà!
8. Kí ni ọ̀nà kan pàtàkì táa fi lè yẹra fún ìdẹwò?
8 Ọ̀nà kan pàtàkì táa fi lè já ara wa gbà lọ́wọ́ “jíjẹ́ ẹrú ẹ̀ṣẹ̀” ni yíyẹra fún ìdẹwò nígbà tó bá ṣeé ṣe. (Róòmù 6:6) Ìwé Òwe 4:14, 15 rọ̀ wá pé: “Má wọ ipa ọ̀nà àwọn ẹni burúkú, má sì rìn tààrà lọ sínú ọ̀nà àwọn ẹni búburú. Yẹra fún un, má gbà á kọjá; yà kúrò nínú rẹ̀, kí o sì kọjá lọ.” A sábà máa ń mọ̀ ṣáájú àkókò pé ó ṣeé ṣe kí àwọn ipò kan tó yí wa ká yọrí sí ẹ̀ṣẹ̀. Fún ìdí yìí, ohun tó yẹ ká yáa ṣe ni pé ká “kọjá lọ,” ìyẹn ni pé ká yàgò fún ẹnikẹ́ni àti ohunkóhun àti ibikíbi tó lè súnná sí èròkérò, kí ó sì wá tanná ran ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ nínú wa.
9. Báwo ni Ìwé Mímọ́ ṣe tẹnu mọ́ sísá fún àwọn ipò tó lè múni juwọ́ sílẹ̀?
9 Sísá fún ipò kan tó lè súnni dẹ́sẹ̀ tún ni ìgbésẹ̀ pàtàkì míì láti borí ìdẹwò. Ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù ni pé: “Ẹ máa sá fún àgbèrè.” (1 Kọ́ríńtì 6:18) Ó tún kọ̀wé pé: “Ẹ sá fún ìbọ̀rìṣà.” (1 Kọ́ríńtì 10:14) Àpọ́sítélì náà tún kìlọ̀ fún Tímótì pé kí ó sá fún ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì àti “àwọn ìfẹ́-ọkàn tí ó máa ń bá ìgbà èwe rìn.”—2 Tímótì 2:22; 1 Tímótì 6:9-11.
10. Àpẹẹrẹ méjì tí wọ́n yàtọ̀ síra wo ló fi hàn pé ó ṣe pàtàkì fún wa láti máa sá fún ìdẹwò?
10 Ẹ jẹ́ ká gbé ohun tó ṣẹlẹ̀ sí Dáfídì Ọba Ísírẹ́lì yẹ̀ wò. Bó ti ń najú lórí òrùlé ààfin rẹ̀, ó rí arẹwà obìnrin kan tó ń wẹ̀, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sì kún inú ọkàn-àyà rẹ̀. Ṣebí ńṣe ló yẹ kó kúrò lórí òrùlé náà, kó sá fún ìdẹwò. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe ló lọ ń wádìí bí obìnrin tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Bátí-ṣébà yìí ti jẹ́, níkẹyìn, ọ̀ràn náà di iṣu ata yán-an yàn-an. (2 Sámúẹ́lì 11:1–12:23) Yàtọ̀ pátápátá sí èyí, kí ni ìgbésẹ̀ tí Jósẹ́fù gbé nígbà tí aya oníṣekúṣe tí ọ̀gá rẹ̀ fẹ́ sílé ń yọ ọ́ lẹ́nu ṣáá, tó ní kó bá òun ṣe? Àkọsílẹ̀ náà sọ fún wa pé: “Bí ó ti ń bá Jósẹ́fù sọ̀rọ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́, òun kò fetí sílẹ̀ sí i láé láti sùn tì í, láti máa bá a lọ pẹ̀lú rẹ̀.” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé Òfin Mósè kò tíì sí nígbà yẹn, Jósẹ́fù dá a lóhùn pé: “Báwo ni èmi ṣe lè hu ìwà búburú ńlá yìí, kí n sì dẹ́ṣẹ̀ sí Ọlọ́run ní ti gidi?” Nígbà tó wá dọjọ́ kan, obìnrin yìí rá a mú, ó sì sọ pé: “Sùn tì mí!” Ṣé ńṣe ni Jósẹ́fù wá dúró síbẹ̀ tó ń bá obìnrin náà ṣàròyé? Ó tì o. Ńṣe ló “fẹsẹ̀ fẹ, ó sì bọ́ síta.” Kójú máà ríbi ni Jósẹ́fù fi ọ̀ràn náà ṣe, kò jẹ́ kí ìdẹwò nípa ìbálòpọ̀ lé òun bá. Ó feré gé e ni!—Jẹ́nẹ́sísì 39:7-16.
11. Ọgbọ́n wo la lè rí dá sí i bí ìdẹwò kan bá ń ṣẹlẹ̀ sí wa lemọ́lemọ́?
11 Àwọn kan lè sọ pé ìwà ojo ni kéèyàn sá, àmọ́ bíbá ẹsẹ̀ wa sọ̀rọ̀ ni ìgbésẹ̀ tó bọ́gbọ́n mu jù. Bóyá à ń rí ìdẹwò kan lemọ́lemọ́ níbi iṣẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a lè máà ríṣẹ́ míì, àwọn ọ̀nà míì lè wà táa lè gbà yẹra fún àwọn ipò tó lè mú ká juwọ́ sílẹ̀. A gbọ́dọ̀ sá fún ohunkóhun táa bá mọ̀ pé kò dáa, ká sì pinnu láti máa ṣe kìkì ohun tó dáa. (Ámósì 5:15) Nínú àwọn ipò míì, sísá fún ìdẹwò yóò béèrè pé ká yàgò fún ibi tí wọ́n ń kó àwọn nǹkan tí ń ru ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ sókè sí lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì àtàwọn ibi eré ìnàjú tí ń kọni lóminú. Ó tún lè kan yíya ìwé ìròyìn kan sọnù tàbí ká wá àwọn ọ̀rẹ́ tuntun—ìyẹn, àwọn tó fẹ́ràn Ọlọ́run, tí wọ́n á sì lè ràn wá lọ́wọ́. (Òwe 13:20) Á dáa ká yàgò pátápátá fún ohunkóhun tó bá lè sún wa dẹ́ṣẹ̀.—Róòmù 12:9.
Bí Àdúrà Ṣe Lè Ṣèrànwọ́
12. Kí ni à ń sọ pé kí Ọlọ́run ṣe fún wa nígbà táa bá gbàdúrà pé: ‘Máà mú wa wá sínú ìdẹwò’?
12 Pọ́ọ̀lù sọ ọ̀rọ̀ ìfinilọ́kànbalẹ̀ yìí pé: “Ọlọ́run jẹ́ olùṣòtítọ́, kì yóò sì jẹ́ kí a dẹ yín wò ré kọjá ohun tí ẹ lè mú mọ́ra, ṣùgbọ́n pa pọ̀ pẹ̀lú ìdẹwò náà, òun yóò tún ṣe ọ̀nà àbájáde kí ẹ lè fara dà á.” (1 Kọ́ríńtì 10:13) Ọ̀nà kan tí Jèhófà gbà ń ràn wá lọ́wọ́ ni dídáhùn àdúrà táa bá gbà pé kí ó ràn wá lọ́wọ́ láti kojú ìdẹwò. Jésù Kristi kọ́ wa láti gbàdúrà pé: “Má sì mú wa wá sínú ìdẹwò, ṣùgbọ́n dá wa nídè kúrò lọ́wọ́ ẹni burúkú náà.” (Mátíù 6:13) Jèhófà yóò dáhùn irú àdúrà àtọkànwá bẹ́ẹ̀, ní ti pé kò ní dá wa dá ìdẹwò náà; yóò gbà wá lọ́wọ́ Sátánì àti ìwà àrékérekè rẹ̀. (Éfésù 6:11, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, New World Translation of the Holy Scriptures, With References.) A óò máa bẹ Ọlọ́run pé kó jọ̀ọ́ jẹ́ ká mọ̀ nígbà tí ìdẹwò bá dé, kí ó sì fún wa lókun láti kọjú ìjà sí i. Bí a bá rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí i pé kí ó máà jẹ́ ká ṣubú nígbà tí ìdẹwò bá dé, òun yóò ràn wá lọ́wọ́ kí ọwọ́ Sátánì, “ẹni burúkú náà,” má bàa tẹ̀ wá.
13. Kí ló yẹ ká ṣe bí ìdẹwò kan bá kọ̀ tí kò dẹ̀yìn lẹ́yìn wa?
13 Ní pàtàkì, ó tún yẹ ká máa fi taratara gbàdúrà nígbà tí ìdẹwò kan bá kọ̀ tí kò dẹ̀yìn lẹ́yìn wa. Àwọn ìdẹwò kan wà tó máa ń bá èrò inú àti ìṣesí wa wọ̀yá ìjà, wọ́n sì ń fi hàn pé aláìpé ni wá lóòótọ́. (Sáàmù 51:5) Fún àpẹẹrẹ, kí la lè ṣe bí àwọn ìwàkiwà kan táa ti hù sẹ́yìn bá ń wá síni lọ́kàn ṣáá? Bí ó bá ń ṣe wá bíi pé ká tún padà sẹ́nu irú ìwà ọ̀hún ńkọ́? Dípò tí àwa nìkan yóò máa bá irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ yí, ẹ jẹ́ ká mú ọ̀ràn náà tọ Jèhófà lọ nínú àdúrà—ká gbàdúrà ní àgbàtúngbà tó bá pọndandan. (Sáàmù 55:22) Ó lè fi agbára Ọ̀rọ̀ rẹ̀ àti ẹ̀mí mímọ́ rẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti fọ àwọn èrò àìmọ́ kúrò lọ́kàn wa.—Sáàmù 19:8, 9.
14. Èé ṣe tí àdúrà fi ṣe pàtàkì láti kojú ìdẹwò?
14 Nígbà tí Jésù kíyè sí i pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ń tòògbé nínú ọgbà Gẹtisémánì, ó rọ̀ wọ́n pé: “Ẹ máa bá a nìṣó ní ṣíṣọ́nà, kí ẹ sì máa gbàdúrà nígbà gbogbo, kí ẹ má bàa bọ́ sínú ìdẹwò. Ní tòótọ́, ẹ̀mí ń háragàgà, ṣùgbọ́n ẹran ara ṣe aláìlera.” (Mátíù 26:41) Ọ̀nà kan táa fi lè ṣẹ́gun ìdẹwò ni láti wà lójúfò sí onírúurú ọ̀nà tí ìdẹwò lè gbà yọjú, ká sì mọ àpadé-àludé rẹ̀. Ó tún ṣe pàtàkì pé ká tètè bẹ̀rẹ̀ sí gbàdúrà nípa ìdẹwò náà kí a lè gbára dì nípa tẹ̀mí láti kọjú ìjà sí i. A ò lè dá kọjú ìjà sí ìdẹwò nítorí pé ibi táa ti kù díẹ̀ káàtó ló máa ń dojú sọ. Àdúrà ṣe pàtàkì nítorí pé agbára tí Ọlọ́run ń fi fúnni lè fún wa lókun láti borí Sátánì. (Fílípì 4:6, 7) A tún lè nílò ìrànlọ́wọ́ tẹ̀mí àti àdúrà “àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ.”—Jákọ́bù 5:13-18.
Fi Taratara Kọjú Ìjà sí Ìdẹwò
15. Kí ni àwọn ohun táa lè ṣe láti kọjú ìjà sí ìdẹwò?
15 Yàtọ̀ sí yíyàgò fún ìdẹwò nígbà tó bá ṣeé ṣe, a gbọ́dọ̀ fi taratara kọjú ìjà sí i títí yóò fi kọjá lọ tàbí títí ipò àwọn nǹkan yóò fi yí padà. Nígbà tí Sátánì dán Jésù wò, ńṣe ló kọjú ìjà sí Èṣù títí tó fi lọ. (Mátíù 4:1-11) Jákọ́bù ọmọ ẹ̀yìn kọ̀wé pé: “Ẹ kọ ojú ìjà sí Èṣù, yóò sì sá kúrò lọ́dọ̀ yín.” (Jákọ́bù 4:7) A lè bẹ̀rẹ̀ nípa fífún èrò inú wa lókun nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ká sì pinnu láìyẹhùn pé a ó rọ̀ mọ́ àwọn ìlànà rẹ̀. Yóò dára táa bá há àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ pàtàkì sórí, àwọn èyí tó ní í ṣe pẹ̀lú àìlera wa gan-an, ká sì máa ṣe àṣàrò lé wọn lórí. Yóò bọ́gbọ́n mu láti wá Kristẹni kan tó dàgbà dénú—bóyá alàgbà—tí a lè fi ọ̀ràn náà lọ̀, tí a sì lè pè fún ìrànlọ́wọ́ nígbà tí ìdẹwò bá dé lójijì.—Òwe 22:17.
16. Báwo la ṣe lè jẹ́ oníwà mímọ́?
16 Ìwé Mímọ́ rọ̀ wá pé ká gbé àkópọ̀ ìwà tuntun wọ̀. (Éfésù 4:24) Èyí túmọ̀ sí jíjẹ́ kí Jèhófà mọ wá, kí ó sì yí wa padà. Nígbà tí Pọ́ọ̀lù ń kọ̀wé sí Tímótì tí wọ́n jọ ń ṣiṣẹ́, ó sọ pé: “Máa lépa òdodo, fífọkànsin Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, ìfaradà, inú tútù. Ja ìjà àtàtà ti ìgbàgbọ́, di ìyè àìnípẹ̀kun mú gírígírí èyí tí a torí rẹ̀ pè ọ́.” (1 Tímótì 6:11, 12) A lè “máa lépa òdodo” nípa fífi aápọn kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run kí a lè túbọ̀ mọ àkópọ̀ ìwà rẹ̀ dunjú àti nípa ṣíṣe àwọn ohun tó fẹ́. Ríri ara wa bọnú ìgbòkègbodò Kristẹni, bíi wíwàásù ìhìn rere náà àti lílọ sáwọn ìpàdé, tún ṣe kókó. Sísúnmọ́ Ọlọ́run àti lílo gbogbo nǹkan tó pèsè nípa tẹ̀mí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti máa dàgbà nípa tẹ̀mí kí a sì jẹ́ oníwà mímọ́.—Jákọ́bù 4:8.
17. Báwo la ṣe mọ̀ pé Ọlọ́run kò ní pa wá tì nígbà táa bá wà nínú ìdẹwò?
17 Pọ́ọ̀lù fi wá lọ́kàn balẹ̀ pé a kò ní rí ìdẹwò tí yóò ré kọjá agbára tí Ọlọ́run fún wa láti fi kojú rẹ̀. Jèhófà yóò ‘ṣe ọ̀nà àbájáde kí a lè fara dà á.’ (1 Kọ́ríńtì 10:13) Àní sẹ́, bí a bá gbára lé Ọlọ́run, kò ní jẹ́ kí ìdẹwò le débi pé a ò ní rí okun tẹ̀mí táa nílò láti fi pa ìwà títọ́ mọ́. Ó fẹ́ ká kẹ́sẹ járí nínú fífi taratara kọjú ìjà sí ìdẹwò láti ṣe ohun tí kò tọ́ lójú rẹ̀. Síwájú sí i, a lè ní ìgbàgbọ́ nínú ìlérí rẹ̀ pé: “Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.”—Hébérù 13:5.
18. Èé ṣe táa fi lè ní ìdánilójú pé a lè borí àìpé ẹ̀dá?
18 Ogun tí àbájáde rẹ̀ dá Pọ́ọ̀lù lójú ló ń bá àìpé ẹ̀dá jà. Kò ka ara rẹ̀ sí ẹni tí ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ara ti mú lẹ́rú, tí kò lè já ara rẹ̀ gbà mọ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó sọ pé: “Bí mo ti ń sáré kì í ṣe láìní ìdánilójú; bí mo ti ń darí àwọn ẹ̀ṣẹ́ mi jẹ́ láti má ṣe máa gbá afẹ́fẹ́; ṣùgbọ́n mo ń lu ara mi kíkankíkan, mo sì ń darí rẹ̀ bí ẹrú, pé, lẹ́yìn tí mo bá ti wàásù fún àwọn ẹlòmíràn, kí èmi fúnra mi má bàa di ẹni tí a kò tẹ́wọ́ gbà lọ́nà kan ṣáá.” (1 Kọ́ríńtì 9:26, 27) Àwa náà lè bá ẹran ara àìpé jà, ká sì ṣẹ́gun. Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ ń tipasẹ̀ Ìwé Mímọ́, àwọn ìwé táa gbé ka Bíbélì, àwọn ìpàdé Kristẹni, àtàwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa tó dàgbà dénú pèsè àwọn ìránnilétí ìgbà gbogbo tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti máa tọ ipa ọ̀nà títọ́. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ rẹ̀, a lè borí àìpé ẹ̀dá!
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Kí ni “gbígbé èrò inú ka ẹran ara” túmọ̀ sí?
• Báwo la ṣe lè múra sílẹ̀ de ìdẹwò?
• Kí la lè ṣe láti kojú ìdẹwò?
• Ipa wo ni àdúrà ń kó nínú kíkojú ìdẹwò?
• Báwo la ṣe mọ̀ pé ó ṣeé ṣe láti borí àìpé ẹ̀dá?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]
Bíbélì kò fi kọ́ wa pé a kò lè já ara wa gbà lọ́wọ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ ẹran ara
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]
Sísá fún ìdẹwò jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ọ̀nà pàtàkì táa fi lè yẹra fún ẹ̀ṣẹ̀