Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àṣeyẹ Kan Tí Kò Yẹ Kí O Máà Sí Níbẹ̀

Àṣeyẹ Kan Tí Kò Yẹ Kí O Máà Sí Níbẹ̀

Àṣeyẹ Kan Tí Kò Yẹ Kí O Máà Sí Níbẹ̀

“Gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé” ń wá látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, Bàbá wa ọ̀run. —Jákọ́bù 1:17.

Ẹ̀BÙN tó tóbi jù lọ tí Ọlọ́run fi fún aráyé ẹlẹ́ṣẹ̀ ni ètò tó ṣe láti rà wọ́n padà nípasẹ̀ Jésù Kristi, Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo. Ikú Jésù, Olùràpadà wa, mú kí ìyè àìnípẹ̀kun nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé ṣeé ṣe. A pàṣẹ fún wa ní Lúùkù 22:19 láti máa ṣèrántí ikú rẹ̀.

Àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi tọ̀yàyàtọ̀yàyà ké sí ọ pé kí o wá kí a jùmọ̀ ṣe ohun tí Jésù pa láṣẹ. Ayẹyẹ ọdọọdún yìí yóò wáyé lẹ́yìn tí oòrùn bá wọ̀ ní ọjọ́ tó bọ́ sí Nísàn 14 lórí kàlẹ́ńdà olóṣùpá ti Bíbélì—ìyẹn ni Sunday, April 8, 2001. Kọ ọjọ́ yìí sílẹ̀ kí o má bàa gbàgbé. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní àgbègbè rẹ lè sọ àkókò tí a ó ṣe é gan-an àti ibi tí a ó ti ṣe é fún ọ.