Àwọn Ìbùkún Ìjọba náà Lè Jẹ́ Tìrẹ
Àwọn Ìbùkún Ìjọba náà Lè Jẹ́ Tìrẹ
KRISTẸNI àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbọ́ mélòó kan lára àwọn lájorí èdè táwọn èèyàn ń sọ nígbà ayé rẹ̀. Ìwé tó kà bá tẹni tó jáde yunifásítì lóde òní dọ́gba. Gbogbo àǹfààní àti ẹ̀tọ́ táwọn ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù ní lòun náà ní. (Ìṣe 21:37-40; 22:3, 28) Àwọn nǹkan wọ̀nyí ì bá ti sọ ọ́ dọlọ́rọ̀ àti olókìkí. Àmọ́, ó sọ pé: “Àwọn ohun tí ó jẹ́ èrè fún mi, ìwọ̀nyí ni mo ti kà sí àdánù ní tìtorí Kristi . . . mo sì kà wọ́n sí ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ pàǹtírí, kí n lè jèrè Kristi.” (Fílípì 3:7, 8) Kí nìdí tí Pọ́ọ̀lù fi sọ irú ọ̀rọ̀ yìí?
Pọ́ọ̀lù, ẹni táa mọ̀ sí Sọ́ọ̀lù ará Tásù tẹ́lẹ̀, tó tún ṣe inúnibíni sáwọn “tí ó jẹ́ ti Ọ̀nà Náà,” wá di onígbàgbọ́ lẹ́yìn tó rí ìran Jésù táa jí dìde, táa sì ṣe lógo. (Ìṣe 9:1-19) Ohun tí Pọ́ọ̀lù rí lọ́nà nígbà tó ń lọ sí Damásíkù mú kí ó dá a lójú gbangba pé Jésù ni Mèsáyà, tàbí Kristi, táa ṣèlérí, ẹni tí yóò di alákòóso Ìjọba táa ṣèlérí náà lọ́jọ́ iwájú. Èyí tún fa ìyípadà tó kàmàmà nínú ìgbésí ayé Pọ́ọ̀lù, gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ gbígbàfiyèsí tó sọ lókè yìí ṣe fi hàn. Lọ́rọ̀ kan, Pọ́ọ̀lù ronú pìwà dà nítorí pé ó jẹ́ olóòótọ́ ọkàn.—Gálátíà 1:13-16.
Nínú Bíbélì, ọ̀rọ̀ ìṣe táa sábà máa ń tú sí “ronú pìwà dà,” Ìṣe 3:19; Ìṣípayá 2:5) Nínú ọ̀ràn ti Pọ́ọ̀lù, kò ka ìṣẹ̀lẹ̀ mériyìírí tó ṣẹlẹ̀ lójú ọ̀nà Damásíkù yẹn sí ohun tó wulẹ̀ jẹ́ ìrírí amóríyá, tàbí ohun tí wọ́n ń pè ní ìrírí tẹ̀mí lásán. Lójú rẹ̀, ó jẹ́ ìrírí títanijí, tó jẹ́ kó mọ̀ pé ìmúlẹ̀mófo ni ọ̀nà ìgbésí ayé rẹ̀ àtijọ́, nígbà tí kò mọ Kristi. Ó tún mọ̀ pé kí ohun tóun ṣẹ̀ṣẹ̀ mọ̀ nípa Kristi yìí tó lè ṣe òun láǹfààní, òun gbọ́dọ̀ ṣe ohun kan láti yí ìgbésí ayé òun padà.—Róòmù 2:4; Éfésù 4:24.
wá látinú ọ̀rọ̀ Gíríìkì tó túmọ̀ ní ṣangiliti sí “lẹ́yìn mímọ̀,” tó jẹ́ òdìkejì “mímọ̀ tẹ́lẹ̀.” Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ìrònúpìwàdà wé mọ́ yíyí èrò, ìṣarasíhùwà, tàbí ète ẹni padà, pípa ọ̀nà àtijọ́ tì, kí a kà á sí ohun tí kò bójú mu. (Ìyípadà Tó Mú Ọ̀pọ̀ Ìbùkún Wá
Mẹ́ńbà Farisí tí Pọ́ọ̀lù jẹ́ tẹ́lẹ̀ ló jẹ́ kó mọ ọ̀pọ̀ lára ohun tó mọ̀ nípa Ọlọ́run. Ìmọ̀ ọgbọ́n orí ènìyàn àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ pọ̀ lára ohun tí wọ́n gbà gbọ́. Nítorí ẹ̀tanú ìsìn yẹn, ìtara àti akitiyan òdì ni Pọ́ọ̀lù ní. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó rò pé Ọlọ́run lòun ń sìn, Ọlọ́run ló ń bá jà ní ti gidi.—Fílípì 3:5, 6.
Lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù gba ìmọ̀ pípéye nípa Kristi àti ipa tó kó nínú ète Ọlọ́run, ó wá rí i pé òun gbọ́dọ̀ yan ọ̀nà kan: Ṣé kó ṣì jẹ́ Farisí ni, kó lè máa gbádùn ipò ọlá àti iyì nìṣó, tàbí kó yí ìgbésí ayé rẹ̀ padà, kó sì bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ohun yòówù tó bá pọndandan láti jèrè ojú rere Ọlọ́run? Ó dùn mọ́ni nínú pé Pọ́ọ̀lù yan ohun tó tọ́, nítorí ó sọ pé: “Èmi kò tijú ìhìn rere; ní ti tòótọ́, ó jẹ́ agbára Ọlọ́run fún ìgbàlà sí gbogbo ẹni tí ó ní ìgbàgbọ́, fún Júù lákọ̀ọ́kọ́ àti pẹ̀lú fún Gíríìkì.” (Róòmù 1:16) Pọ́ọ̀lù wá di ẹni tí ń fìtara wàásù ìhìn rere nípa Kristi àti Ìjọba náà.
Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, Pọ́ọ̀lù sọ fáwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Èmi kò tíì ka ara mi sí ẹni tí ó ti gbá a mú nísinsìnyí; ṣùgbọ́n ohun kan wà nípa rẹ̀: Ní gbígbàgbé àwọn ohun tí ń bẹ lẹ́yìn àti nínàgà sí àwọn ohun tí ń bẹ níwájú, mo ń lépa góńgó náà nìṣó fún ẹ̀bùn eré ìje ti ìpè Ọlọ́run sí òkè nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 3:13, 14) Ìhìn rere náà ṣe Pọ́ọ̀lù láǹfààní nítorí pé ó fi tinútinú yọwọ́ kúrò nínú ohun tó yà á nípa sí Ọlọ́run, ó sì fi tọkàntọkàn lépa àwọn góńgó tó bá ète Ọlọ́run mu.
Kí Ni Wàá Ṣe?
Bóyá o ṣẹ̀ṣẹ̀ gbọ́ nípa ìhìn rere Ìjọba náà ni. Ǹjẹ́ ìrètí gbígbé títí láé nínú párádísè ẹlẹ́wà wù ọ́? Kò sí bí ò ṣe ní wù ọ́, nítorí pé gbogbo wa la ní ìfẹ́ àbínibí láti wà láàyè, ká sì máa gbádùn ìgbésí ayé nínú àlàáfíà àti ààbò. Bíbélì sọ pé Ọlọ́run ti fi “àkókò tí ó lọ kánrin” sínú ọkàn-àyà wa. (Oníwàásù 3:11) Nítorí náà ìwà ẹ̀dá ni láti máa retí àkókò tí yóò ṣeé ṣe fáwọn èèyàn láti máa gbé títí láé nínú àlàáfíà àti ayọ̀. Ohun tí ìhìn rere Ìjọba náà ń sọ sì nìyẹn.
Àmọ́ kí ọwọ́ rẹ bàa lè tẹ ìrètí náà, o gbọ́dọ̀ ṣèwádìí, kí o sì ṣàwárí ohun tí ìhìn rere náà dá lé. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣí wa létí pé: “Kí [o] . . . ṣàwárí fúnra [rẹ] ìfẹ́ Ọlọ́run tí ó dára, tí ó ṣe ìtẹ́wọ́gbà, tí ó sì pé.” (Róòmù 12:2) Nítorí náà, bíi Pọ́ọ̀lù, lẹ́yìn jíjèrè ìmọ̀ àti òye, o gbọ́dọ̀ pinnu ohun tóo máa ṣe.
Lódìkejì ẹ̀wẹ̀, ó lè jẹ́ ọ̀tọ̀ lohun tóo gbà gbọ́ nípa ọjọ́ ọ̀la rẹ. Rántí pé kí Sọ́ọ̀lù tó di àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, ó ti kọ́kọ́ ní àwọn èrò kan nípa ohun tó kà sí ìfẹ́ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n dípò ríretí ìṣípayá lọ́nà ìyanu látọ̀dọ̀ Ọlọ́run, èé ṣe tí o ò kúkú fojú ṣùnnùkùn wo ọ̀ràn yìí? Bi ara rẹ léèrè pé: ‘Ṣé lóòótọ́ ni mo mọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ Ọlọ́run fún aráyé àti ilẹ̀ ayé? Ẹ̀rí wo ni mo ní láti fi ti ìgbàgbọ́ mi lẹ́yìn? Ṣé ẹ̀rí tí mo ní yóò rẹ́sẹ̀ dúró báa bá fi ìmọ́lẹ̀ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, gbé e yẹ̀ wò?’ O ò ní pàdánù rárá, tóo bá ṣàyẹ̀wò ohun tí ẹ̀sìn rẹ gbà gbọ́ lọ́nà yìí. Ńṣe ló tilẹ̀ yẹ kóo fẹ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀ nítorí Bíbélì rọ̀ wá pé: “Ẹ máa wádìí ohun gbogbo dájú; ẹ di 1 Tẹsalóníkà 5:21) Àbí, ṣé kì í ṣe ojú rere Ọlọ́run ló ṣe pàtàkì jù ni?—Jòhánù 17:3; 1 Tímótì 2:3, 4.
ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ mú ṣinṣin.” (Àwọn aṣáájú ìsìn lè ṣèlérí ìwàláàyè ayérayé fún wa. Ṣùgbọ́n bí wọn kò bá gbé ìlérí yẹn ka ẹ̀kọ́ tí Bíbélì fi kọ́ni, kò lè ràn wá lọ́wọ́ láti jèrè àwọn ìbùkún Ìjọba Ọlọ́run. Nínú Ìwàásù olókìkí tí Jésù ṣe Lórí Òkè, ó ṣe kìlọ̀kìlọ̀ pé: “Kì í ṣe olúkúlùkù ẹni tí ń wí fún mi pé, ‘Olúwa, Olúwa,’ ni yóò wọ ìjọba ọ̀run, bí kò ṣe ẹni tí ń ṣe ìfẹ́ Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run ni yóò wọ̀ ọ́.”—Mátíù 7:21.
Ṣàkíyèsí bí Jésù ṣe tẹnu mọ́ ọn pé ṣíṣe ìfẹ́ Baba òun ni yóò mú kí ó ṣeé ṣe láti rí àwọn ìbùkún Ìjọba Ọlọ́run gbà. Lédè mìíràn, ohun tó jọ ìfọkànsin Ọlọ́run kò fi dandan ṣe ìtẹ́wọ́gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Àní Jésù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ọ̀pọ̀ ènìyàn yóò wí fún mi ní ọjọ́ yẹn pé, ‘Olúwa, Olúwa, àwa kò ha sọ tẹ́lẹ̀ ní orúkọ rẹ, tí a sì lé àwọn ẹ̀mí èṣù jáde ní orúkọ rẹ, tí a sì ṣe ọ̀pọ̀ iṣẹ́ agbára ní orúkọ rẹ?’ Síbẹ̀síbẹ̀, ṣe ni èmi yóò jẹ́wọ́ fún wọn pé: Èmi kò mọ̀ yín rí! Ẹ kúrò lọ́dọ̀ mi, ẹ̀yin oníṣẹ́ ìwà àìlófin.” (Mátíù 7:22, 23) Ó ṣe kedere pé ohun tó jà jù ni pé ká rí i dájú pé a ní òye kíkún nípa ìhìn rere Ìjọba náà, ká sì gbégbèésẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú òye yẹn.—Mátíù 7:24, 25.
Ìrànlọ́wọ́ Ń Bẹ Lárọ̀ọ́wọ́tó
Ó ti lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún báyìí táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ń wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Nípasẹ̀ ìwé tí wọ́n ń tẹ̀ jáde àti ọ̀rọ̀ ẹnu, wọ́n ń ran àwọn èèyàn yí ká ayé lọ́wọ́ láti jèrè ìmọ̀ pípéye nípa ohun tí Ìjọba náà jẹ́, nípa àwọn ìbùkún tí yóò mú wá, àti nípa ohun tó yẹ kéèyàn ṣe kí ó lè jèrè àwọn ìbùkún náà.
A rọ̀ ọ́ pé kí o tẹ́wọ́ gba ìhìn táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù rẹ̀. Bí o bá tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà, tóo sì ṣiṣẹ́ lé e lórí, o lè gba àwọn ìbùkún yabuga-yabuga, kì í ṣe nísinsìnyí nìkan, ṣùgbọ́n ní ọjọ́ iwájú pẹ̀lú, nígbà tí Ìjọba Ọlọ́run bá ń ṣàkóso gbogbo ilẹ̀ ayé pátá.—1 Tímótì 4:8.
Ṣe nǹkan kan nísinsìnyí, nítorí pé àwọn ìbùkún Ìjọba Ọlọ́run ti dé tán!
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń fi ìwé tí wọ́n ń tẹ̀ jáde àti ọ̀rọ̀ ẹnu wàásù ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run