Ìsìn Kristẹni Tòótọ́ Ti Borí!
Ìsìn Kristẹni Tòótọ́ Ti Borí!
“Ọ̀rọ̀ Jèhófà ń bá a nìṣó ní gbígbilẹ̀ àti ní bíborí lọ́nà tí ó ní agbára ńlá.”—ÌṢE 19:20.
1. Ṣàpèjúwe bí ẹ̀sìn Kristẹni ṣe gbilẹ̀ tó ní ọ̀rúndún kìíní.
NÍPASẸ̀ agbára ẹ̀mí mímọ́, àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fi ìtara tó ga kéde ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Òpìtàn kan kọ̀wé pé: “Ìsìn Kristẹni ti tàn ká gbogbo ilẹ̀ Róòmù lọ́nà tó bùáyà. Nígbà tó fi máa di ọdún 100 [Sànmánìn Tiwa], bóyá ni kò fi jẹ́ pé gbogbo ẹkùn ilẹ̀ tó bá Mẹditaréníà pààlà ló ti ní àwùjọ àwọn Kristẹni tí ń gbé nínú rẹ̀.”
2. Báwo ni Sátánì ṣe gbìyànjú láti gbógun ti ìhìn rere náà, báwo la sì ṣe sọ èyí tẹ́lẹ̀?
2 Sátánì Èṣù kò lè pa àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ lẹ́nu mọ́. Dípò ìyẹn, ó lo ọ̀nà mìíràn láti gbógun ti ipa tí ìhìn rere náà ní—ohun tó lò ni ìpẹ̀yìndà. Jésù ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa èyí nínú àkàwé rẹ̀ nípa àlìkámà àti èpò. (Mátíù 13:24-30, 36-43) Àpọ́sítélì Pétérù tún kìlọ̀ pé àwọn olùkọ́ èké yóò dìde láàárín ìjọ, wọn ó sì mú àwọn ẹ̀ya ìsìn tí ń pani run wọlé. (2 Pétérù 2:1-3) Bákan náà ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dìídì kìlọ̀ pé ìpẹ̀yìndà yóò dé ṣáájú ọjọ́ Jèhófà.—2 Tẹsalóníkà 2:1-3.
3. Kí ló ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì?
3 Lẹ́yìn tí àwọn àpọ́sítélì ti kú tán, ẹ̀kọ́ àwọn kèfèrí àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí wá bo ìhìn rere náà mọ́lẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti sọ tẹ́lẹ̀, àwọn olùkọ́ èké sọ ojúlówó ìhìn òtítọ́ dìdàkudà, wọ́n sì sọ ọ́ dìbàjẹ́. Kẹ̀rẹ̀kẹ̀rẹ̀, ayédèrú Kristẹni tí wọ́n ń pè ní Kirisẹ́ńdọ̀mù wá bo ìsìn Kristẹni tòótọ́ mọ́lẹ̀. Ẹgbẹ́ àlùfáà kan wá dìde tó gbìyànjú láti sọ Bíbélì di ohun tí kò ní sí lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn gbáàtúù. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé iye àwọn tó pe ara wọn ní Kristẹni ń pọ̀ sí i, síbẹ̀ ìjọsìn wọn ti di eléèérí. Kirisẹ́ńdọ̀mù wá tàn dé ọ̀pọ̀ ilẹ̀, ó sì wá di àjọ tó lágbára, tó sì ní ipa lórí àṣà àwọn ará Ìwọ̀ Oòrùn ayé, ṣùgbọ́n kò ní ìbùkún Ọlọ́run, bẹ́ẹ̀ ni kò ní ẹ̀mí rẹ̀.
4. Èé ṣe tí ọgbọ́n tí Sátánì dá láti dojú ète Ọlọ́run dé kò fi kẹ́sẹ járí?
4 Àmọ́, òtúbáńtẹ́ ni gbogbo ọgbọ́n tí Sátánì dá láti dojú ète Jèhófà dé já sí. Kódà láwọn igbà tí ìpẹ̀yìndà fẹsẹ̀ rinlẹ̀ gan-an, ìsìn Kristẹni tòótọ́ ṣì wà láàárín àwọn kan. Àwọn tó da Bíbélì kọ sa gbogbo ipá wọn láti ṣe bẹ́ẹ̀ lọ́nà tó péye. Nípa bẹ́ẹ̀, Bíbélì fúnra rẹ̀ kò yí padà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ àwọn tó sọ pé àwọn ní ọlá àṣẹ láti fi kọ́ni ló ṣì í túmọ̀. Jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún tó ti kọjá, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ bíi Jerome àti Tyndale ti fìgboyà túmọ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọ́n sì pín in kiri. Àràádọ́ta èèyàn ni ojú wọn wá là sí Bíbélì, tí wọ́n sì wá bẹ̀rẹ̀ sí ṣe irú ẹ̀sìn Kristẹni kan, bó tilẹ̀ jẹ́ pé ayédèrú ni.
5. Kí ni wòlíì Dáníẹ́lì sọ tẹ́lẹ̀ nípa “ìmọ̀ tòótọ́”?
5 Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, gẹ́gẹ́ bí àsọtẹ́lẹ̀ inú ìwé Dáníẹ́lì ti wí, ‘ìmọ̀ tòótọ́ wá pọ̀ yanturu.’ Èyí ti ṣẹlẹ̀ ní “àkókò òpin”—ìyẹn àkókò táa ń gbé nísinsìnyí. (Dáníẹ́lì 12:4) Ẹ̀mí mímọ́ ti ṣamọ̀nà àwọn olùfẹ́ òtítọ́ jákèjádò ayé sí ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run tòótọ́ àti ète rẹ̀. Kódà, lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún tí ẹ̀kọ́ ìpẹ̀yìndà ti wà, ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣì ń borí! Lóde òní, a ń kéde ìhìn rere náà níbi gbogbo, táa ń tọ́ka àwọn èèyàn sí ìrètí ayé tuntun tó kún fún ìdùnnú. (Sáàmù 37:11) Ẹ jẹ́ kí a wá gbé bí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe ń bí sí i lóde òní yẹ̀ wò.
Ìbísí Ọ̀rọ̀ Náà Lóde Òní
6. Òtítọ́ wo ni àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lóye rẹ̀ ní ọdún 1914?
6 Ní òpin ọ̀rúndún kọkàndínlógún, òtítọ́ Bíbélì ru ẹgbẹ́ kékeré tó jẹ́ Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì sókè, ìyẹn àwọn táa wá mọ̀ sí Ẹlẹ́rìí Jèhófà lóde òní. Nígbà tó fi máa di ọdún 1914, Bíbélì ti wá ṣe kedere sí wọn. Wọ́n lóye àwọn àgbàyanu òtítọ́ nípa ète Ọlọ́run. Ìfẹ́ tó mú kí Jèhófà rán Ọmọ rẹ̀ wá sórí ilẹ̀ ayé, tó sì tipa bẹ́ẹ̀ ṣí ọ̀nà ìyè àìnípẹ̀kun sílẹ̀ wú wọn lórí gan-an. Wọ́n tún ti wá mọ orúkọ Ọlọ́run àti àkópọ̀ ìwà rẹ̀, wọ́n sì tún mọyì rẹ̀ pẹ̀lú. Síwájú sí i, wọ́n mọ̀ pé “àkókò àwọn Kèfèrí” ti dópin, tó fi hàn pé àkókò ti sún mọ́lé tí Ìjọba Ọlọ́run yóò mú ìbùkún wá fún aráyé. (Lúùkù 21:24, Bíbélì Mímọ́) Ìhìn rere ológo mà lèyí o! Ó yẹ ká sọ òtítọ́ pàtàkì yìí fún gbogbo ènìyàn níbi gbogbo. Ẹ̀mí àwọn èèyàn wà nínú ewu!
7. Báwo ni òtítọ́ Bíbélì ṣe borí ní ayé òde òní?
7 Jèhófà bù kún ìwọ̀nba kéréje àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró yẹn. Lónìí, iye àwọn tó ti gba ẹ̀sìn Kristẹni tòótọ́ ti lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sì ti tàn dé ọ̀pọ̀ ilẹ̀, nítorí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà wà ní igba ó lé márùndínlógójì [235] ilẹ̀ báyìí. Síwájú sí i, òtítọ́ Bíbélì ti sa agbára, ó ti borí gbogbo ìdènà, ì báà jẹ́ ti ìsìn, tàbí ìdènà yòówù kó jẹ́. Ìwàásù ìhìn rere náà kárí ayé jẹ́rìí sí òtítọ́ tí kò ṣeé já ní koro náà pé Jésù ti wà nínú agbára Ìjọba.—Mátíù 24:3, 14.
8. Kí làwọn kan ti sọ nípa pípọ̀ tí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń pọ̀ sí i?
8 Gan-an gẹ́gẹ́ bí àwọn òpìtàn ṣe sọ̀rọ̀ lórí ìbísí kíkọyọyọ tí ẹ̀sìn Kristẹni ní ní ọ̀rúndún kìíní, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀pọ̀ ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ ṣe ń sọ̀rọ̀ lórí pípọ̀ tí àwọn èèyàn Jèhófà ń pọ̀ sí i ní àkókò táa wà yìí. Ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, àwọn ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ méjì pawọ́ pọ̀ kọ̀wé pé: “Láàárín ọdún márùnléláàádọ́rin tó kọjá, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ti ní ìbísí lọ́nà àrà ọ̀tọ̀ . . . ìbísí yìí sì ti wáyé kárí ayé.” Ìwé àtìgbàdégbà kan ní Ìlà Oòrùn Áfíríkà pe àwọn Ẹlẹ́rìí ní “ọ̀kan lára àwọn ìsìn tí ń yára gbèrú, tí a sì bọ̀wọ̀ fún jù lọ lágbàáyé, tí a mọ̀ kárí ayé nítorí bó ṣe ń rọ̀ tímọ́tímọ́ mọ́ àwọn ẹ̀kọ́ Bíbélì.” Ìwé àtìgbàdégbà Kátólíìkì kan tó sábà máa ń rọ̀ mọ́ ohun àbáláyé, tí wọ́n ń tẹ̀ jáde ní ilẹ̀ Yúróòpù, tọ́ka sí “bí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe pọ̀ sí i lọ́nà tó gadabú.” Kí ló fa irú ìbísí yìí?
Ẹ̀mí Mímọ́ Ń Ṣiṣẹ́ Lónìí
9. (a) Kí ni lájorí ohun tó mú kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́rùn borí lóde òní? (b) Báwo ni Jèhófà ṣe ń fa àwọn èèyàn sọ́dọ̀ ara rẹ̀?
9 Lájorí ohun tó mú kí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run borí lóde òní ni pé ẹ̀mí Jèhófà wà lẹ́nu iṣẹ́ lọ́nà tó lágbára, gẹ́gẹ́ bó ti ṣe ní ọ̀rúndún kìíní. Jésù sọ pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” (Jòhánù 6:44) Àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fi hàn pé Ọlọ́run ń fi pẹ̀lẹ́pẹ̀lẹ́ fa àwọn tó ní ìtẹ̀sí ọkàn títọ́ mọ́ra, ó ń fa ọkàn-àyà wọn mọ́ra. Jèhófà ń lo iṣẹ́ ìwàásù tí àwọn Ẹlẹ́rìí rẹ̀ ń ṣe láti fa “àwọn ohun fífani-lọ́kàn-mọ́ra tí ń bẹ nínú gbogbo orílẹ̀-èdè”—ìyẹn àwọn ọlọ́kàn tútù, àwọn ẹni bí àgùntàn nínú ayé, jáde fún iṣẹ́ ìsìn rẹ̀.—Hágáì 2:6, 7.
10. Irú àwọn èèyàn wo ló ti fìfẹ́ hàn sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run?
10 Kì í ṣe pé ẹ̀mí mímọ́ ń fún àwọn èèyàn Ọlọ́run lágbára láti mú ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lọ sí àwọn apá ibi jíjìnnà réré nìkan ni; ó tún ti mú kí onírúurú èèyàn tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà. Ní ti tòótọ́, àwọn tó ti fayọ̀ tẹ́wọ́ gbà ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ti wá láti “inú gbogbo ẹ̀yà àti ahọ́n àti àwọn ènìyàn àti orílẹ̀-èdè.” (Ìṣípayá 5:9; 7:9, 10) A lè rí wọn láàárín àwọn olówó àtàwọn tálákà, láàárín àwọn tó kàwé àtàwọn tí kò kàwé. Àwọn kan ti tẹ́wọ́ gba ọ̀rọ̀ náà nígbà tí ogun ń jà lọ́wọ́ tàbí lábẹ́ inúnibíni gbígbóná janjan, nígbà táwọn mìíràn ti ṣe bẹ́ẹ̀ lákòókò àlàáfíà àti aásìkí. Lábẹ́ onírúurú ìjọba, nínú gbogbo àṣà ìbílẹ̀, láti inú àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ títí dé ààfin ni tọkùnrin tobìnrin ti fìfẹ́ hàn sí ìhìn rere náà.
11. Báwo ni ẹ̀mí mímọ́ ṣe ń ṣiṣẹ́ nínú ìgbésí ayé àwọn èèyàn Ọlọ́run, ìyàtọ̀ wo ló sì hàn kedere?
11 Pẹ̀lú bí àwọn èèyàn Ọlọ́run ṣe jẹ́ onírúurú tó yẹn, síbẹ̀ wọ́n jùmọ̀ ń gbé pa pọ̀ ní ìṣọ̀kan. (Sáàmù 133:1-3) Èyí ló túbọ̀ fi ẹ̀rí hàn pé ẹ̀mí mímọ́ ń ṣiṣẹ́ nínú ìgbésí ayé àwọn tó ń sin Ọlọ́run. Ẹ̀mí Rẹ̀ lágbára láti súnni ṣe rere, tó fi ń mú kí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ fi àwọn ànímọ́ bí ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, inú rere, àti àwọn ànímọ́ fífani mọ́ra mìíràn ṣe ìwà hù. (Gálátíà 5:22, 23) Lóde òní, a ti wá rí ohun tí wòlíì Málákì ti sọ tẹ́lẹ̀ tipẹ́ ní kedere pé: “Ẹ ó sì . . . rí ìyàtọ̀ láàárín olódodo àti ẹni burúkú, láàárín ẹni tí ń sin Ọlọ́run àti ẹni tí kò sìn ín.”—Málákì 3:18.
Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run Ti Borí Nínú Ọkàn Àwọn Òṣìṣẹ́ Onítara
12. Báwo ni iṣẹ́ ìjíhìnrere náà ṣe rí lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àwọn ìṣarasíhùwà wo ni wọ́n sì retí láti rí lẹ́nu iṣẹ́ ìwàásù wọn?
12 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà kì í ṣe àwọn tó kàn lọ ń mú ìjókòó gbóná nílé ìjọsìn. Wọ́n ń kó ipa tó ga nínú iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere náà. Bíi ti àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀, wọ́n yọ̀ǹda ara wọn tinútinú láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, wọ́n ń gbìyànjú láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kọ́ nípa àwọn ìlérí Ìjọba Jèhófà. Wọ́n jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run, tó jẹ́ pé ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ẹ̀mí mímọ́, wọ́n ń kó àwọn mìíràn jọ sínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n ń fi àánú àti ìfẹ́ tí Jèhófà ní fún ìran ènìyàn aláìgbàgbọ́ hàn. Wọ́n ń ṣe bẹ́ẹ̀ láìka ẹ̀mí ìdágunlá, ìfiniṣẹ̀sín, àti inúnibíni tí wọ́n ń bá pàdé sí. Jésù ti múra àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ sílẹ̀ de onírúurú ìhà táwọn èèyàn máa kọ sí ìhìn rere náà. Ó sọ pé: “Ẹrú kò tóbi ju ọ̀gá rẹ̀ lọ. Bí wọ́n bá ti ṣe inúnibíni sí mi, wọn yóò ṣe inúnibíni sí yín pẹ̀lú; bí wọ́n bá ti pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, wọn yóò pa tiyín mọ́ pẹ̀lú.”—Jòhánù 15:20.
13. Kí ni àwọn ànímọ́ tí Kirisẹ́ńdọ̀mù ò ní táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́?
13 Kò sí bí kò ṣe ní wú wa lórí láti rí ìjọra tó wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà òde òní àtàwọn tó tẹ́wọ́ gba ìsìn Kristẹni tòótọ́ ní ọ̀rúndún kìíní. Ohun tó tún gbàfiyèsí ni ìyàtọ̀ tó wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà àtàwọn Kirisẹ́ńdọ̀mù òde òní. Lẹ́yìn tí ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan kọ̀wé nípa ìtara tí àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fi ṣe iṣẹ́ ìjíhìnrere náà, ó wá kédàárò pé: “Bí a kò bá yí báa ṣe ń ṣe nǹkan nínú ṣọ́ọ̀ṣì padà, kí iṣẹ́ ìjíhìnrere wá di àìgbọdọ̀máṣe lẹ́ẹ̀kan sí i fún gbogbo Kristẹni tó ti ṣe batisí, ká sì tún máa gbé ìgbé ayé tó dára ju èyí tí àwọn aláìgbàgbọ́ lè gbé, bóyá la fi lè ní ìlọsíwájú.” Àwọn ànímọ́ tí Kirisẹ́ńdọ̀mù ò ní gan-an làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́! Wọ́n ní ìgbàgbọ́ tó múná dóko, ojúlówó ìgbàgbọ́, àti ìgbàgbọ́ táa gbé ka òtítọ́ Bíbélì tí wọ́n máa ń fẹ́ láti bá gbogbo ẹni tí yóò bá fetí sílẹ̀ sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.—1 Tímótì 2:3, 4.
14. Ojú wo ni Jésù fi wo iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀, ẹ̀mí wo sì ni àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ń fi hàn lónìí?
14 Jésù kò fọwọ́ yẹpẹrẹ mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ rárá, iṣẹ́ tó gbà á lọ́kàn nìyẹn. Ó sọ fún Pílátù pé: “Nítorí èyí ni a ṣe bí mi, nítorí èyí sì ni mo ṣe wá sí ayé, kí n lè jẹ́rìí sí òtítọ́.” (Jòhánù 18:37) Bó ṣe rí lára Jésù náà ló ṣe rí lára àwọn èèyàn Ọlọ́run. Nítorí pé òtítọ́ Bíbélì wà lọ́kàn wọn, wọ́n ń gbìyànjú láti wá àwọn ọ̀nà tí wọ́n máa gbà bá ọ̀pọ̀ èèyàn tó bá ṣeé ṣe fún wọn láti rí sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀. Àwọn kan lára àwọn ọ̀nà wọ̀nyí fi ọgbọ́n tó pabanbarì hàn.
15. Báwo làwọn kan ṣe lo ọgbọ́n nínú wíwàásù ìhìn rere náà?
15 Ní orílẹ̀-èdè kan ní Gúúsù Amẹ́ríkà, àwọn Ẹlẹ́rìí máa ń rin ìrìn àjò gba inú odò kan tó ṣàn wọnú Odò Amazon kọjá láti mú òtítọ́ dé ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn. Àmọ́, nígbà tí ogun abẹ́lé wá bẹ́ sílẹ̀ ní 1995, wọ́n ò gbà kí àwọn tí kì í ṣe ológun gba odò náà kọjá mọ́. Níwọ̀n bí àwọn Ẹlẹ́rìí ti pinnu láti máa fi àwọn ìtẹ̀jáde táa gbé karí Bíbélì ránṣẹ́ sí àwọn olùfìfẹ́hàn, wọ́n wá pinnu láti mú kí ìhìn náà léfòó gba orí omi kọjá. Wọ́n kọ àwọn lẹ́tà, wọ́n sì kó àwọn ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! pẹ̀lú lẹ́tà náà sínú àwọn òfìfo ìgò oníke. Wọ́n wá ju àwọn ìgò ọ̀hún sínú odò náà. Wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀ fún ọdún mẹ́rin ààbọ̀ gbáko, kó tó di pé wọ́n tún padà fún àwọn tí kì í ṣe ológun láyè láti gba odò náà kọjá. Gbogbo àwọn tó yí odò náà ká ló ń dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí fún àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà. Obìnrin kan tó jẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì gbá wọn mọ́ra pẹ̀lú omijé lójú, ó sì sọ pé: “Mo ro pé mi ò tún ní fojú gán-án-ní yín mọ́ ni. Àmọ́, nígbà tí mo bẹ̀rẹ̀ sí gba àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ náà nínú ìgò, mo mọ̀ pé ẹ ò tíì gbàgbé mi!” Àwọn kan tó ń gbé ní àyíká odò náà sọ pé àwọn ti ka àwọn ìwé ìròyìn náà léraléra. Ọ̀pọ̀ ibùdó ló ní “ilé ìfìwéránṣẹ́”—ìyẹn ibi tí omi ti ń ṣàn padà tí wọ́n ti lè kó àwọn nǹkan tó léfòó sójú omi fúngbà díẹ̀. Ibẹ̀ làwọn olùfìfẹ́hàn máa ń lọ láti wo bóyá àwọn ní “ìwé” kankan tó wá láti òdìkejì odò.
16. Báwo ni yíyọ̀ǹda ara wa ṣe máa ń ṣí ọ̀nà sílẹ̀ fún sísọni di ọmọ ẹ̀yìn nígbà mìíràn?
16 Jèhófà Ọlọ́run àtàwọn áńgẹ́lì rẹ̀ alágbára ló ń darí iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere náà, àwọn ló sì ń tì í lẹ́yìn. (Ìṣípayá 14:6) Táa bá ṣáà ti lè yọ̀ǹda ara wa, àwọn àǹfààní láti sọni di ọmọ ẹ̀yìn máa ń yọjú láìròtẹ́lẹ̀ nígbà mìíràn. Ní Nairobi, Kẹ́ńyà, àwọn Kristẹni obìnrin méjì tí wọ́n wà lóde ẹ̀rí ti ṣe àwọn ilé tí wọ́n yàn fún wọn tán. Bí ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan ṣe yọ sí wọn lójijì nìyẹn tó fi tayọ̀tayọ̀ sọ pé: “Mo ti ń gbàdúrà pé kí n bá irú ẹ̀yin èèyàn yìí pàdé.” Ó wá bẹ àwọn Ẹlẹ́rìí náà pé kí wọ́n jọ̀wọ́ máa bọ̀ nílé báyìíbáyìí fún ìjíròrò, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú rẹ̀ lọ́jọ́ yẹn gan-an. Kí ló mú kí obìnrin náà wá bá àwọn Kristẹni méjì ọ̀hún ní kánjúkánjú bẹ́ẹ̀? Ọmọ rẹ̀ kékeré kú ní nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì ṣáájú àkókò yẹn. Nígbà tó wá rí ìwé àṣàrò kúkúrú náà “Ireti Wo ni Ó Wà fun Awọn Ololufẹ Tí wọn Ti Kú?” lọ́wọ́ ọmọ kékeré kan, ó wù ú láti kà á gan-an ni, ó sì bẹ ọmọkùnrin náà pé kí ó fún òun. Ọmọ náà kọ̀ jálẹ̀, dípò ìyẹn, ó tọ́ka sí àwọn Ẹlẹ́rìí tó fún un ní ìwé àṣàrò kúkúrú náà. Láìpẹ́, obìnrin náà tẹ̀ síwájú nípa tẹ̀mí, ó sì túbọ̀ rọrùn fún un láti kojú ìbànújẹ́ ikú ọmọ rẹ̀.
Ìfẹ́ Ọlọ́run Gbọ́dọ̀ Borí
17-19. Irú ìfẹ́ wo ni Jèhófà fi hàn sí ìran ènìyàn nípasẹ̀ ìràpadà?
17 Ìbísí tí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń ní ní gbogbo ayé wé mọ́ ẹbọ ìràpadà Kristi Jésù gan-an ni. Bíi ti ìràpadà ọ̀hún, iṣẹ́ ìwàásù jẹ́ àmì ìfẹ́ Jèhófà fún àwọn ènìyàn níbi gbogbo. A mí sí àpọ́sítélì Jòhánù láti kọ̀wé pé: “Ọlọ́run nífẹ̀ẹ́ ayé tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tí ó fi fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni, kí olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀ má bàa pa run, ṣùgbọ́n kí ó lè ní ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 3:16.
18 Ronú nípa ìfẹ́ tí Jèhófà fi hàn ní pípèsè ìràpadà náà. Fún àìmọye ọdún ni Ọlọ́run ti gbádùn àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo, tó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n, “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá láti ọwọ́ Ọlọ́run.” (Ìṣípayá 3:14) Jésù nífẹ̀ẹ́ Baba rẹ̀ gan-an, Jèhófà náà sì nífẹ̀ẹ́ Ọmọ rẹ̀ “ṣáájú ìgbà pípilẹ̀ ayé.” (Jòhánù 14:31; 17:24) Jèhófà jẹ́ kí Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n kú kí ẹ̀dá ènìyàn lè rí ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ ò rí i pé ọ̀nà tó gadabú láti fi ìfẹ́ hàn sí ìran ènìyàn lèyí!
19 Jòhánù 3:17 sọ pé: “Ọlọ́run rán Ọmọ rẹ̀ jáde sí ayé, kì í ṣe kí ó lè ṣèdájọ́ ayé, bí kò ṣe kí a lè gba ayé là nípasẹ̀ rẹ̀.” Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà rán Ọmọ rẹ̀ níṣẹ́ ìgbàlà tó jẹ́ ti onífẹ̀ẹ́, kì í ṣe ti ìdájọ́ tàbí ti ìdálẹ́bi. Èyí bá ọ̀rọ̀ Pétérù mu pé: “[Jèhófà] kò fẹ́ kí ẹnikẹ́ni pa run ṣùgbọ́n ó fẹ́ kí gbogbo ènìyàn wá sí ìrònúpìwàdà.”—2 Pétérù 3:9.
20. Báwo ni ìgbàlà ṣe tan mọ́ wíwàásù ìhìn rere?
20 Níwọ̀n bí Jèhófà ti fi nǹkan bàǹtàbanta du ara rẹ̀ láti pèsè ìpìlẹ̀ tó tọ̀nà fún ìgbàlà, ó fẹ́ kí gbogbo èèyàn tó bá fẹ́ wá jàǹfààní rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “‘Olúkúlùkù ẹni tí ó bá ń ké pe orúkọ Jèhófà ni a ó gbà là.’ Àmọ́ ṣá o, báwo ni wọn yóò ṣe ké pe ẹni tí wọn kò ní ìgbàgbọ́ nínú rẹ̀? Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe ní ìgbàgbọ́ nínú ẹni tí wọn kò gbọ́ nípa rẹ̀? Báwo, ẹ̀wẹ̀, ni wọn yóò ṣe gbọ́ láìsí ẹnì kan láti wàásù?”—Róòmù 10:13, 14.
21. Ojú wo ló yẹ ká máa fi wo àǹfààní táa ní láti kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà?
21 Ẹ wo irú àgbàyanu àǹfààní tó jẹ́ láti kópa nínú iṣẹ́ wíwàásù àti kíkọ́ni kárí ayé yìí! Iṣẹ́ ọ̀hún ò rọrùn, àmọ́ ẹ wo bí inú Jèhófà ṣe ń dùn tó nígbà tí àwọn èèyàn rẹ̀ bá fi tinútinú wà nínú òtítọ́, tí wọ́n sì ń sọ ìhìn rere náà fáwọn ẹlòmíràn! Nítorí náà, ipòkípò tóo bá wà, jẹ́ kí ẹ̀mí Ọlọ́run àti ìfẹ́ tó wà lọ́kàn rẹ sún ọ láti kópa nínú iṣẹ́ yìí. Sì rántí pé àwọn ohun táa rí tó ń ṣẹlẹ̀ jákèjádò ayé fi ẹ̀rí tí kò ṣeé já ní koro hàn pé Jèhófà Ọlọ́run yóò mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ láìpẹ́ láti mú “ọ̀run tuntun àti ilẹ̀ ayé tuntun” ológo wá, nínú èyí tí “òdodo yóò sì máa gbé.”—2 Pétérù 3:13.
Ǹjẹ́ O Rántí?
• Èé ṣe tí ìpẹ̀yìndà kò fi lè pa àwọn oníwàásù ìhìn rere náà lẹ́nu mọ́?
• Báwo ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣe borí ni ọjọ́ wa?
• Ní ọ̀nà wo ni ẹ̀mí Ọlọ́run fi wà lẹ́nu iṣẹ́ lónìí?
• Báwo ni ìràpadà ṣe tan mọ́ wíwàásù ìhìn rere náà?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Graph/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]
(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)
Ìbísí nínú iye àwọn olùpòkìkí Ìjọba náà ní ọ̀rúndún ogún
Ìpíndọ́gba iye akéde (lọ́nà mílíọ̀nù)
6.0
5.5
5.0
4.5
4.0
3.5
3.0
2.5
2.0
1.5
1.0
0.5
1900 1910 1920 1930 1940 1950 1960 1970 1980 1990 2000
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
JEROME
TYNDALE
GUTENBERG
HUS
[Credit Line]
Gutenberg àti Hus: Láti inú ìwé The Story of Liberty, 1878
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]
Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ń pòkìkí ìhìn rere náà láwọn ọdún 1920
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16, 17]
Àwọn èèyàn ń tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà káàkiri ayé
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]
Iṣẹ́ ìwàásù náà ń gbé ìfẹ́ Ọlọ́run ga, bíi ti ẹbọ ìràpadà Jésù Kristi