Íńdíà—“Ìṣọ̀kan Láàárín Onírúurú”
Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn
Íńdíà—“Ìṣọ̀kan Láàárín Onírúurú”
“ÌṢỌ̀KAN láàárín onírúurú” jẹ́ ọ̀rọ̀ amóríwú tí wọ́n sábà fi máa ń ṣàpèjúwe àjọṣe tó wà ní Íńdíà. Wíwà ní ìṣọ̀kan ní orílẹ̀-èdè ńlá tó kún fún onírúurú àṣà, èdè, ìsìn, ẹ̀yà, ọ̀nà ìwọṣọ, àti onírúurú oúnjẹ yìí kì í ṣe ohun tó rọrùn rárá. Àmọ́, a rí irú ìṣọ̀kan bẹ́ẹ̀ ní ọ́fíìsì táa ti ń bójú tó iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Íńdíà, bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn láti máa gbébẹ̀, tí wọ́n sì ń ṣiṣẹ́ níbẹ̀ wá láti ọ̀pọ̀ ìpínlẹ̀ àti àgbègbè, wọ́n sì ń sọ àwọn èdè bíi mélòó kan tó yàtọ̀ síra wọn.
• Ẹ jẹ́ ká gbé ọ̀rọ̀ Rajrani yẹ̀ wò—ìyẹn ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan tó wá láti Punjab, ní ìkángun apá àríwá ìwọ̀ oòrùn Íńdíà. Nígbà tí Rajrani wà nílé ìwé, ọ̀kan lára àwọn ọmọ kíláàsì rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́dọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ọ̀dọ́mọbìnrin yìí gbìyànjú láti mú kí Rajrani nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé èdè Gẹ̀ẹ́sì tọ́mọ kíláàsì rẹ̀ náà gbọ́ kò tó nǹkan, tó sì jẹ́ pé Ilé Ìṣọ́ kò tíì bẹ̀rẹ̀ sí jáde ní èdè Punjabi nígbà yẹn, ó wá bẹ Rajrani pé kí ó jọ̀wọ́ máa túmọ̀ ohun tó wà nínú ìwé ìròyìn náà fún òun. Ohun tí Rajrani kà nínú Ilé Ìṣọ́ bẹ̀rẹ̀ sí nípa lórí rẹ̀ gan-an tó fi jẹ́ pé ó kẹ́kọ̀ọ́ débi tó fi ya ìgbésí ayé rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run láìka gbogbo àtakò táwọn òbí rẹ̀ gbé dìde sí. Ó ti ń sìn ní Bẹ́tẹ́lì tó wà ní Íńdíà báyìí, ohun kan náà tó fi ojú rẹ̀ mọ òtítọ́ ló sì ń ṣe. Ó ń túmọ̀ àwọn ìtẹ̀jáde Kristẹni sí èdè Punjabi!
• Tún gbé ọ̀rọ̀ Bijoe yẹ̀ wò, ẹni tó wá láti apá ibòmíràn ní Íńdíà—ìyẹn ní gúúsù ìwọ̀ oòrùn ìpínlẹ̀ Kerala. Wọ́n lé Bijoe kúrò nílé ìwé nítorí pé ó mú ìdúró aláìdásí-tọ̀tún-tòsì nígbà tí wọ́n ń ṣe àwọn ayẹyẹ onífẹ̀ẹ́ orílẹ̀-èdè. Àmọ́, ọ̀ràn náà wá di ẹjọ́ ńlá tí wọ́n fà-fà-fà nílé ẹjọ́, lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn Bijoe padà sílé ìwé lẹ́yìn tí wọ́n dá ìjọsìn mímọ́ láre lọ́nà kíkọyọyọ. a Ó tún lọ sí yunifásítì. Àmọ́ ìṣekúṣe tí wọ́n ń ṣe níbẹ̀ ń da ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ láàmù, ló bá fibẹ̀ sílẹ̀. Nísinsìnyí tó ti lo ọdún mẹ́wàá ní Bẹ́tẹ́lì, ó rí i pé òun ti jàǹfààní tó pọ̀ gan-an gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ìdílé Bẹ́tẹ́lì tí wọ́n jẹ́ onírúurú èèyàn àmọ́ tí wọ́n wà ní ìṣọ̀kan, àǹfààní ọ̀hún sì pọ̀ ju bí ì bá ṣe rí fún un tó bá jẹ́ pé ẹ̀kọ́ ìwé gíga ló ń lépa.
• Norma àti Lily ti lé ní ẹni àádọ́rin ọdún báyìí, wọ́n sì ti jẹ́ opó fún ọ̀pọ̀ ọdún. Ọ̀kọ̀ọ̀kan wọn ti lo ogójì ọdún nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Ó ti tó ogún ọdún tí Lily ti ń ṣiṣẹ́ gẹ́gẹ́ bí olùtumọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì sí èdè Tamil ní ẹ̀ka náà. Ọdún kẹtàlá sẹ́yìn ni Norma wá sí Bẹ́tẹ́lì, lẹ́yìn ikú ọkọ rẹ̀. Yàtọ̀ sí bí wọ́n ṣe jẹ́ àpẹẹrẹ àtàtà nínú fífi aápọn àti tọkàntọkàn ṣiṣẹ́, wọ́n tún ní ipa tó dára lórí ìṣọ̀kan gbogbo ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Wọ́n nífẹ̀ẹ́ àlejò ṣíṣe, wọ́n sì máa ń kó àwọn tó kéré sí wọn nínú mẹ́ńbà ìdílé náà mọ́ra, tí wọ́n á máa ròyìn àwọn ayọ̀ tí wọ́n ti ní nínú gbígbé ìgbé ayé Kristẹni fún ọ̀pọ̀ ọdún. Àwọn ọ̀dọ́ náà máa ń ṣe ipa tiwọn nípa pípè wọ́n wá sí yàrá tiwọn láti bá wọn kẹ́gbẹ́ àti láti ràn wọ́n lọ́wọ́ nígbà tó bá yẹ. Àwọn àpẹẹrẹ yìí mà dára o!
Níwọ̀n bí wọ́n ti borí ìyàtọ̀ tó máa ń fa gbọ́nmi-si omi-ò-to àti àìfohùnṣọ̀kan ní àwọn ibi púpọ̀, àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn wọ̀nyí ń fi tayọ̀tayọ̀ ṣiṣẹ́ pa pọ̀ láti sin àwọn ẹlòmíràn gẹ́gẹ́ bí mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì tó wà ní ìṣọ̀kan ní Íńdíà.—Sáàmù 133:1.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Ilé Ìṣọ́ November 1, 1987, ojú ìwé 21.
[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 8]
Àwòrán Ìsàlẹ̀: Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.