Òṣùṣù Ọwọ̀ ni Wá
Ìtàn Ìgbésí Ayé
Òṣùṣù Ọwọ̀ ni Wá
GẸ́GẸ́ BÍ MELBA BARRY ṢE SỌ Ọ́
Ní July 2, 1999, èmi àti ọkọ mi wà níbi ìpàdé ńlá kan tó jẹ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, àìmọye ìgbà la kúkú ti lọ sírú ìpàdé yìí láàárín ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta táa ti ṣègbéyàwó. Ọ̀rọ̀ àsọparí ni Lloyd ń sọ lọ́wọ́ ní àpéjọpọ̀ àgbègbè náà ní Hawaii lọ́jọ́ Friday yẹn. Àfi bó ṣe ṣàdédé dìgbò lulẹ̀. Pẹ̀lú gbogbo bí wọ́n ṣe sá sókè sódò kí ó má bàa kú, síbẹ̀ ó kú o. a
ÁÀ, ẸNI bí ẹni, èèyàn bí èèyàn làwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin ní Hawaii, tí wọ́n jẹ́ adúrótini lọ́jọ́ ìṣòro, tí wọ́n jẹ́ alábàárò mi nígbà àjálù yìí! Ọ̀pọ̀ lára wọn, àti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn kárí ayé, ni Lloyd ti fún níṣìírí.
Ní ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọdún méjì lẹ́yìn ikú rẹ̀, mo ti ronú nípa àwọn ọdún tó mìrìngìndìn táa fi jọ wà pa pọ̀—ọ̀pọ̀ lára ọdún wọ̀nyí la lò nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní ilẹ̀ òkèèrè àti ní orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, New York. Mo tún ti ro ìgbésí ayé mi láti kékeré, nílùú Sydney ní Ọsirélíà, àtàwọn ìṣòro tí èmi àti Lloyd dojú kọ, kí a tó lè ṣègbéyàwó nígbà ìbẹ̀rẹ̀ Ogun Àgbáyé Kejì. Ṣùgbọ́n, ẹ jẹ́ kí n kọ́kọ́ sọ fún yín nípa bí mo ṣe dí Ẹlẹ́rìí àti bí mo ṣe bá Lloyd pàdé ní 1939.
Bí Mo Ṣe Di Ẹlẹ́rìí
James àti Henrietta Jones làwọn òbí mi àtàtà. Ọmọ ọdún mẹ́rìnlá péré ni mí nígbà tí mo parí iléèwé ní 1932. Ayé ti rì sínú Ìlọsílẹ̀ Gígadabú Nínú Ọrọ̀ Ajé nígbà yẹn. Mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣiṣẹ́ láti fi ran ìdílé wa lọ́wọ́, nítorí pé mo tún ní àbúrò obìnrin méjì. Láàárín ọdún díẹ̀, mo ti bẹ̀rẹ̀ sí gba owó gidi níbi iṣẹ́, mo sì di ọ̀gá fún àwọn ọ̀dọ́bìnrin mélòó kan pàápàá.
Láàárín àkókò yìí, ní 1935, màmá mi gba ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lọ́wọ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kò sì pẹ́ tó fi dá a lójú pé òun ti rí òtítọ́. Ńṣe ni àwa yòókù rò pé orí rẹ̀ ti yí ni. Àmọ́ lọ́jọ́ kan, mo rí ìwé pẹlẹbẹ kan tí wọ́n pe àkọlé rẹ̀ ní Where Are the Dead?, àkọlé náà sì wọ̀ mí lọ́kàn gan-an. Nítorí náà, mo rọra sá pa mọ́ ka ìwé yẹn. Ó tán o! Ojú ẹsẹ̀ ni mo bẹ̀rẹ̀ sí tẹ̀ lé màmá mi lọ sí ìpàdé àárín ọ̀sẹ̀ tí wọ́n ń pè ní Model Study [Àpẹẹrẹ Ìkẹ́kọ̀ọ́]. Ìwé pẹlẹbẹ náà Model Study ní ìbéèrè àti ìdáhùn nínú, ó tún ní àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tó ti ìdáhùn wọ̀nyẹn lẹ́yìn, oríṣi mẹ́ta irú rẹ̀ ni wọ́n tẹ̀ jáde nígbà tó yá.
Láàárín àkókò yẹn, ìyẹn ní April 1938, Joseph F. Rutherford, tí í ṣe aṣojú láti orílé iṣẹ́ àgbáyé ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wá sí Sydney. Àsọyé tó sọ fún gbogbo èèyàn ni àsọyé àkọ́kọ́ tí mo lọ. Gbọ̀ngàn Ìlú Sydney ni wọ́n ti kọ́kọ́ fẹ́ sọ àsọyé ọ̀hún, ṣùgbọ́n àwọn alátakò kò jẹ́ kí a rí ibẹ̀ lò. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé Pápá Ìṣiré Sydney, tó fẹ̀ gan-an jù ú lọ, ni àsọyé náà ti wáyé. Nítorí ìkéde tí àwọn alátakò tún bá wa ṣe, nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́wàá èèyàn ló wá, iye yìí sì pọ̀ gan-an nítorí pé ẹ̀ẹ́dégbèje [1,300] péré ni iye àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Ọsirélíà nígbà yẹn.
Àìpẹ́ lẹ́yìn ìyẹn ni mo jáde iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá fún ìgbà àkọ́kọ́—láìsí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ kankan. Nígbà tí àwùjọ tiwa dé ìpínlẹ̀ táa ti fẹ́ wàásù, ńṣe lẹni tó kó wa wá kàn sọ fún mi pé, “Lọ ṣe ilé yẹn.” Àyà mi já débi pé nígbà tí obìnrin onílé ṣílẹ̀kùn, ohun tí mo bi í ni pé, “Ẹ jọ̀ọ́, aago mélòó ló lù?” Ó wọlé lọ wo aago, ó sì wá sọ fún mi. Bí mo ṣe yí ẹ̀yìn padà nìyẹn. Mo sì padà sídìí ọkọ̀.
Ṣùgbọ́n mi ò jáwọ́, kò pẹ́ tí mo bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ìhìn rere Ìjọba náà fáwọn ẹlòmíràn. (Mátíù 24:14) March 1939 ni mo fi ẹ̀rí ìyàsímímọ́ mi fún Jèhófà hàn, a sì batisí mi nínú ọpọ́n ìwẹ̀ alámùúlégbè wa tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dorothy Hutchings. Níwọ̀n bí kò ti sí àwọn arákùnrin lárọ̀ọ́wọ́tó, láìpẹ́ lẹ́yìn tí mo ṣe batisí ni wọ́n fún mi láwọn ẹrù iṣẹ́ nínú ìjọ, àwọn ẹrù iṣẹ́ tó wà fún kìkì àwọn Kristẹni ọkùnrin.
Inú ilé àwọn èèyàn la ti máa ń ṣèpàdé, àmọ́ nígbà míì a máa ń háyà gbọ̀ngàn táa bá fẹ́ sọ àsọyé fún gbogbo èèyàn. Ọ̀dọ́kùnrin arẹwà kan láti Bẹ́tẹ́lì, ìyẹn ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa, wá sọ àsọyé nínú ìjọ wa kékeré. Mi ò mọ̀ rárá pé ó tún bá nǹkan míì wá—àṣé ó tún fẹ́ wá mọ̀ mí délédélé ni. Tóò, bí mo ṣe mọ Lloyd nìyẹn o.
Bí Mo Ṣe Mọ Ìdí lé Lloyd
Láìpẹ́, mo ní ìfẹ́ láti sin Jèhófà fún àkókò kíkún. Ṣùgbọ́n nígbà tí mo fọwọ́ síwèé aṣáájú ọ̀nà (iṣẹ́ ìwàásù alákòókò kíkún), wọ́n béèrè bóyá màá fẹ́ sìn ní Bẹ́tẹ́lì. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ní September 1939, ní oṣù tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀, mo di mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì ní Strathfield, ní àgbègbè Sydney.
Ní December 1939, mo lọ ṣe àpéjọpọ̀ ní New Zealand. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé New Zealand ni Lloyd ti wá, òun náà fẹ́ lọ síbẹ̀. Ọkọ̀ òkun kan la jọ wọ̀, a sì wá túbọ̀ mọ ara wa. Lloyd rí i dájú pé mo dé ọ̀dọ̀ bàbá àti màmá òun àtàwọn àbúrò òun obìnrin ní àpéjọpọ̀ náà ní Wellington, ó sì rí i dájú pé mo délé wọn ní Christchurch lẹ́yìn náà.
Wọ́n Fòfin De Iṣẹ́ Wa
Ní Saturday, January 18, 1941, àwọn aláṣẹ àjọ Kájọlà gbé ọkọ̀ limousine bíi mẹ́fà wá sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa, láti wá gbẹ́sẹ̀ lé gbogbo dúkìá wa. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ilé ẹ̀ṣọ́ kékeré tó wà ní àbáwọ Bẹ́tẹ́lì ni mo ti ń ṣiṣẹ́, èmi ni mo kọ́kọ́ rí wọn. Nǹkan bíi wákàtí méjìdínlógún kí wọ́n tó dé, la ti gbọ́ pé wọ́n fẹ́ fòfin de iṣẹ́ wa, nítorí náà a ti palẹ̀ àwọn ìwé àti fáìlì mọ́ kúrò ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa. Lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, wọ́n wá mú márùn-ún lára mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì, títí kan Lloyd, wọ́n sì lọ tì wọ́n mọ́lé.
Mo mọ̀ pé oúnjẹ tẹ̀mí làwọn arákùnrin tó wà látìmọ́lé nílò jù lọ. Láti fún Lloyd níṣìírí, mo pinnu pé màá máa kọ “àwọn lẹ́tà ìfẹ́” sí i. Mo máa ń bẹ̀rẹ̀ lẹ́tà mi bíi lẹ́tà ìfẹ́, àmọ́ màá wá ṣe àdàkọ odindi àwọn àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ sínú rẹ̀, màá sì wá parí rẹ̀ gẹ́gẹ́ bíi lẹ́tà látọ̀dọ̀ olólùfẹ́ rẹ̀. Ẹ̀yìn oṣù mẹ́rin ààbọ̀ ni wọ́n tú Lloyd sílẹ̀.
Ìgbéyàwó àti Bíbá Iṣẹ́ Ìsìn Nìṣó
Ní 1940, màmá Lloyd ṣèbẹ̀wò sí Ọsirélíà, Lloyd sì sọ fún un pé a ń ronú àtiṣe ìgbéyàwó. Ó sọ fún un pé kí ó má ṣe gbéyàwó báyìí o, nítorí pé òpin ètò àwọn nǹkan ti dé tán. (Mátíù 24:3-14) Lloyd tún sọ fáwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ pé òun fẹ́ ṣègbéyàwó, àmọ́ kò sígbà tó sọ fún wọn tí kì í ṣe pé ńṣe ni wọ́n ń sọ fún un pé kó máà tíì ṣe é. Nígbà tó wá yá, lọ́jọ́ kan ní February 1942, Lloyd rọra mú èmi àtàwọn Ẹlẹ́rìí mẹ́rin, ó sì ti sọ fún wọn tẹ́lẹ̀ pé etí mìíràn kò gbọ́dọ̀ gbọ́ o—gbogbo wa wá jọ lọ síbi tí wọ́n ti ń forúkọ ìgbéyàwó sílẹ̀, báa ṣe ṣègbéyàwó nìyẹn. Láyé ọjọ́un, wọn ò fún àwọn òjíṣẹ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Ọsirélíà láṣẹ láti darí ayẹyẹ ìgbéyàwó.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò yọ̀ǹda fún wa láti máa bá iṣẹ́ ìsìn wa nìṣó ní Bẹ́tẹ́lì lẹ́yìn ìgbéyàwó, wọ́n béèrè lọ́wọ́ wa bóyá a fẹ́ ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe. Tayọ̀tayọ̀ la fi lọ sí ibi tí wọ́n rán wa lọ ní ìlú kan tó wà ní ìgbèríko, orúkọ ìlú náà ni Wagga Wagga. Wọ́n ṣì fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa, a ò sì rí ìrànlọ́wọ́ kankan gbà ní ti ọ̀ràn ìnáwó, nítorí náà kò sóhun táa lè ṣe ju pé ká gbé ẹrù wa lọ sọ́dọ̀ Jèhófà.—Sáàmù 55:22.
A máa ń gun kẹ̀kẹ́ lọ sáwọn abúléko, a máa ń pàdé àwọn ọmọlúwàbí, a sì máa ń bá wọn sọ̀rọ̀ fún àkókò gígùn. Àwọn èèyàn díẹ̀ ló ń tẹ́wọ́ gba ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́ òǹtajà kan mọrírì iṣẹ́ wa tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi ń fún wa ní èso àti ewébẹ̀ lọ́sọ̀ọ̀sẹ̀. Lẹ́yìn táa ti lo oṣù mẹ́fà ní Wagga Wagga, wọ́n ní ká máa padà bọ̀ ní Bẹ́tẹ́lì.
Ìdílé Bẹ́tẹ́lì ti kó kúrò ní ọ́fíìsì tó wà ní
Strathfield ní May 1942, wọ́n ti kó lọ sáwọn ilé àdáni. Nǹkan bí ọ̀sẹ̀ méjì-méjì ni wọ́n fi ń ṣí láti ilé kan sí òmíràn kí wọ́n má bàa rí wọn mú. Nígbà tí èmi àti Lloyd padà sí Bẹ́tẹ́lì ní August, ọ̀kan lára ilé wọ̀nyí la ti lọ bá wọn. Àwọn ibi ìtẹ̀wé tó wà lábẹ́lẹ̀ la ti ń ṣiṣẹ́ lójú mọmọ. Níkẹyìn, wọ́n gbẹ́sẹ̀ kúrò lórí iṣẹ́ wa ní June 1943.Ìpalẹ̀mọ́ fún Iṣẹ́ Ìsìn ní Ilẹ̀ Òkèèrè
Ní April 1947, wọ́n fún wa ní fọ́ọ̀mù tí a óò kọ́kọ́ fọwọ́ sí fún lílọ sí Watchtower Bible School of Gilead, tó wà ní South Lansing New York, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Kí ìdáhùn tó dé, wọ́n ní ká máa bẹ àwọn ìjọ wò ní Ọsirélíà, ká máa fún wọn lókun nípa tẹ̀mí. Lẹ́yìn oṣù díẹ̀, wọ́n ní ká máa bọ̀ ní kíláàsì kọkànlá ti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì. Ọ̀sẹ̀ mẹ́ta péré ló kù láti fi palẹ̀ mọ́. A sọ pé ó dìgbóṣe fáwọn ẹbí àti ọ̀rẹ́ ní December 1947, àwa àtàwọn mẹ́ẹ̀ẹ́dógún mìíràn tí wọ́n pè fún kíláàsì kan náà láti Ọsirélíà sì forí lé New York.
Kíá ni oṣù díẹ̀ táa lò ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì pé, wọ́n sì ní ká lọ ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní Japan. Níwọ̀n bí ìwé àṣẹ láti wọ Japan kò ti tètè bọ́ sí i, wọ́n ní kí Lloyd ṣì máa ṣe iṣẹ́ alábòójútó arìnrìn-àjò ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ná. Àwọn ìjọ tí wọ́n ní ká máa bẹ̀ wò nasẹ̀ láti ìlú Los Angeles títí lọ dé ààlà ilẹ̀ Mẹ́síkò. A ò ní ọkọ̀, nítorí náà ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí ń fi tìfẹ́tìfẹ́ gbé wa láti ìjọ kan lọ sí ìjọ tó kàn. Àyíká kan ṣoṣo, tó lọ salalu nígbà yẹn, ti di apá kan àgbègbè mẹ́ta tí ń sọ èdè Gẹ̀ẹ́sì àti àgbègbè mẹ́ta tí ń sọ èdè Spanish báyìí, nǹkan bí àyíká mẹ́wàá ló sì wà nínú àgbègbè kọ̀ọ̀kan!
Bí eré bí àwàdà, October 1949 wọlé dé wẹ́rẹ́, a sì ti wà lọ́nà Japan, nínú ọkọ̀ òkun kan tí wọ́n fi ń kó ọmọ ogun tẹ́lẹ̀ rí. Apá kan ọkọ̀ náà wà fáwọn ọkùnrin, apá kejì sì wà fáwọn obìnrin àtàwọn ọmọdé. Nígbà tó ku ọ̀la táa máa dé Yokohama ni ìjì líle kan dé. Ńṣe ni ìjì líle yìí gbá ojú ọjọ́ mọ́ kedere, nítorí pé nígbà tí oòrùn yọ lọ́jọ́ kejì, ìyẹn October 31, kedere kèdèrè la ń wo Òkè Fuji, òkè àrímáleèlọ. Ohun táa kọ́kọ́ rí yẹn mà jẹ́ kí ibi iṣẹ́ wa tuntun wù wá o!
Bíbá Àwọn Ará Japan Ṣiṣẹ́ Pọ̀
Nígbà táa sún mọ́ èbúté, ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn èèyàn tó nírun dúdú la kàn ń rí. Báa ṣe ń gbọ́ tí wọ́n ń sọ̀rọ̀ fatafata, a sọ pé: ‘Ariwo àwọn aráabí mà pọ̀ o!’ Gbogbo wọn wọ bàtà onípákó tó ń dún koo-koo-kà lórí pákó tí wọ́n tẹ́ sí ilẹ̀ èbúté náà. Lẹ́yìn táa sun oorun ọjọ́ kan ní Yokohama, a wọ ọkọ̀ ojú irin lọ síbi iṣẹ́ míṣọ́nnárì wa ní Kobe. Ọmọ kíláàsì wa kan ní Gílíádì, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Don Haslett, tó ti dé sí Japan ní oṣù mélòó kan ṣáájú wa, ti wá ilé kan háyà níbẹ̀ fáwọn míṣọ́nnárì. Ilé ńlá ni, alájà méjì ni, ó tún jojú ní gbèsè, wọ́n sì kọ́ ọ bí ilé àwọn ará Amẹ́ríkà—àmọ́ o, kò sí gá, kò sí go nínú rẹ̀!
Ká lè rí nǹkan fi sùn, a lọ gé koríko lẹ́yìnkùlé, a tẹ́ ẹ sí ilẹ̀ pẹ̀pẹ̀. Báa ṣe bẹ̀rẹ̀ ìgbésí ayé wa gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì nìyẹn, láìsí nǹkan míì yàtọ̀ sí ẹrù táa kó wá. A lọ ra sítóòfù eléèédú, tí wọ́n ń pè ní hibachi, kí ilé lè móoru, kí a sì lè rí nǹkan fi dáná oúnjẹ. Lálẹ́ ọjọ́ kan, Lloyd bá Percy àti Ilma Iszlaub, míṣọ́nnárì ẹlẹgbẹ́ wa méjì, tí wọ́n dákú sílẹ̀ nítorí èéfín tó kó sí wọn nímú. Ó mú wọn sọjí nípa ṣíṣí fèrèsé, kí atẹ́gùn àlàáfíà, tó tutù, lè ráyè wọlé. Ìgbà kan wà témi náà dákú nígbà tí mo ń fi sítóòfù eléèédú náà se oúnjẹ. Àwọn ohun kan ò tètè mọ́ra ṣá!
Èdè gbígbọ́ ṣe pàtàkì, fún ìdí yìí wákàtí mọ́kànlá lóòjọ́ la fi ń kọ́ èdè Japanese fún oṣù kan gbáko. Lẹ́yìn náà, a wá bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ pẹ̀lú gbólóhùn kan tàbí méjì táa kọ sílẹ̀. Lọ́jọ́ àkọ́kọ́ tí mo jáde, mo pàdé obìnrin àtàtà kan, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Miyo Takagi, tó gbà mí tọwọ́tẹsẹ̀. Nígbà ìpadàbẹ̀wò, a ń sọ ìwọ̀nba táátààtá táa gbọ́ nínú èdè ara wa pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ìwé atúmọ̀ èdè Japanese àti èdè Gẹ̀ẹ́sì, títí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì yẹn fi fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa. Ní 1999, nígbà tí mo lọ sí Japan fún ìyàsímímọ́ ẹ̀ka iléeṣẹ́ tí wọ́n
mú gbòòrò, mo rí Miyo lẹ́ẹ̀kan sí i, àtàwọn ẹni ọ̀wọ́n mìíràn tí mo bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́. Àádọ́ta ọdún ti kọjá, ṣùgbọ́n wọ́n ṣì ń fi ìtara polongo Ìjọba náà, wọ́n ń ṣe gbogbo ohun tí apá wọ́n ká nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.Ní Kobe, ní April 1, 1950, nǹkan bí ọgọ́sàn-án [180] ló wá síbi ayẹyẹ Ìṣe Ìrántí ikú Kristi. Ìyàlẹ́nu ló jẹ́ láàárọ̀ ọjọ́ kejì nígbà tí àwọn èèyàn márùndínlógójì dé, tí wọ́n sọ pé àwọn fẹ́ bá wa jáde iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Míṣọ́nnárì kọ̀ọ̀kan mú èèyàn mẹ́ta tàbí mẹ́rin dání lọ sóde lára àwọn ẹni tuntun wọ̀nyí. Àwọn tí à ń bá pàdé kò bá mi sọ̀rọ̀—èmi àjèjì aláìgbédè—kàkà bẹ́ẹ̀ àwọn ará Japan tó wá sí Ìṣe Ìrántí tó bá mi jáde ni wọ́n ń bá sọ̀rọ̀. Ìjíròrò wọn máa ń gùn gan-an, èmi sì rèé, mi ò mọ ohun tí wọ́n ń sọ. Inú mi dùn ṣá, pé àwọn kan lára àwọn ẹni tuntun wọ̀nyẹn tẹ̀ síwájú nínú ìmọ̀, wọ́n sì ń bá iṣẹ́ ìwàásù nìṣó títí di òní olónìí.
Ọ̀pọ̀ Àǹfààní àti Ọ̀pọ̀ Iṣẹ́ Ìsìn
A ń bá iṣẹ́ míṣọ́nnárì lọ ní Kobe títí di 1952, ìgbà yẹn ni wọ́n ní ká kọjá sílùú Tokyo, níbi tí wọ́n ti ní kí Lloyd máa bójú tó ẹ̀ka iléeṣẹ́. Nígbà tó yá, iṣẹ́ rẹ̀ gbé e dé igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin Japan àtàwọn orílẹ̀-èdè mìíràn. Lẹ́yìn náà, nígbà kan tí Nathan H. Knorr, wá sí Tokyo láti orílé iṣẹ́ wa lágbàáyé, ó sọ fún mi pé: “Tiẹ̀ gbọ́ ná, ǹjẹ́ o mọ ibi tí ọkọ rẹ ti máa lọ ṣe ìbẹ̀wò ẹlẹ́kùnjẹkùn tí ń bọ̀? Ọsirélíà àti New Zealand mà ni.” Ó wá fi kún un pé: “Ìwọ náà lè bá a lọ, bóo bá lówó ọkọ̀ lọ́wọ́.” Ayọ̀ abara tín-ń-tín! Ó kúkú ti pé ọdún mẹ́sàn-án táa ti fi ilé sílẹ̀.
Kíá ni lẹ́tà bẹ̀rẹ̀ sí pe lẹ́tà rán níṣẹ́. Màmá mi sanwó ọkọ̀ mi. A ò kúkú lówó táa fi lè wọkọ̀ lọ wo àwọn ẹbí wa, iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún wa lèmi àti Lloyd gbájú mọ́. Bí àdúrà mi ṣe gbà nìyẹn o. Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yin náà ti lè fojú inú wò ó, inú màmá mi dùn gan-an láti rí mi. Ó sọ pé, “Kò burú, èmi yóò tu owó jọ kóo tún lè padà wá lọ́dún mẹ́ta òní.” Ohun táa ní lọ́kàn nìyẹn nígbà táa ya ara wa, ṣùgbọ́n ó dùn mí gan-an pé oṣù July ọdún tó tẹ̀ lé e ló kú. Ẹ wo bí inú mi yóò ti dùn tó nígbà tí mo bá padà rí i nínú ayé tuntun!
Kó tó di 1960, iṣẹ́ míṣọ́nnárì nìkan ni wọ́n yàn fún mi, ṣùgbọ́n mo wá rí lẹ́tà kan gbà tó sọ pé: “Ètò táa ṣe láti òní yìí lọ ni pé wàá máa bá gbogbo mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì fọ aṣọ wọn, wàá sì máa lọ̀ ọ́.” Ìdílé Bẹ́tẹ́lì ìgbà yẹn kò ju nǹkan bí èèyàn méjìlá péré, ìyẹn ló fi jẹ́ pé mo ń bójú tó iṣẹ́ yìí ní àfikún sí iṣẹ́ míṣọ́nnárì mi.
Ní 1962, wọ́n wó ilé wa tí wọ́n kọ́ bíi ti àwọn ará Japan, wọ́n sì kọ́ Ilé Bẹ́tẹ́lì tuntun tó jẹ́ alájà mẹ́fà sórí ilẹ̀ náà lọ́dún tó tẹ̀ lé e. Iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún mi ni pé kí n máa bá àwọn arákùnrin ọ̀dọ́ tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dé sí Bẹ́tẹ́lì tún yàrá wọn ṣe, kí n sì máa palẹ̀ ẹrù wọn mọ́. Gẹ́gẹ́ bí àṣà, àwọn ọ̀dọ́kùnrin ní Japan kì í ṣe iṣẹ́ ilé kankan. Ìwé kíkà nìkan ni wọ́n gbájú mọ́, ìyá wọn ló ń ṣe gbogbo nǹkan fún wọn. Kò pẹ́ tí wọ́n fi mọ̀ pé mi ò lè máa bá wọn ṣe gbogbo nǹkan tí ìyá wọ́n ń bá wọn ṣe. Bí àkókò ti ń lọ, ọ̀pọ̀ nínú wọ́n tẹ̀ síwájú, wọ́n sì tẹ́wọ́ gba ẹrù iṣẹ́ tuntun nínú ètò àjọ yìí.
Lọ́jọ́ kan tí ooru mú gan-an nígbà ẹ̀ẹ̀rùn kan báyìí, akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan wá wo ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa, ó rí mi níbi tí mo ti ń fọ ara ògiri ilé ìwẹ̀. Ohun tí obìnrin náà sọ ni pé, “Jọ̀ọ́, sọ fún ẹnikẹ́ni tó wù kó jẹ́ alábòójútó ibí yìí pé mo ṣe tán láti sanwó
ọmọ ọ̀dọ̀ kan táá wá máa bá ọ ṣiṣẹ́ yìí.” Mo sọ fún un pé mo mọrírì ẹ̀mí ìgbatẹnirò rẹ̀, ṣùgbọ́n tinútinú ni mo fi ń ṣe ohunkóhun tí wọ́n bá ní kí n ṣe nínú ètò àjọ Jèhófà.Kò pẹ́ sígbà yẹn ni èmi àti Lloyd rí lẹ́tà gbà pé ká máa bọ̀ ní kíláàsì kọkàndínlógójì ti Gílíádì! Ẹ wo àǹfààní ńlá tí èyí jẹ́ fún wa láti padà síléèwé ní 1964, lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínláàádọ́ta! Ohun tí ẹ̀kọ́ náà wà fún ní pàtàkì ni láti ran àwọn tí ń sìn ní àwọn ẹ̀ka iléeṣẹ́ lọ́wọ́ láti bójú tó ẹrù iṣẹ́ wọn. Lẹ́yìn ẹ̀kọ́ tó gba oṣù mẹ́wàá náà, wọ́n ní ká padà sí Japan. Nígbà yẹn, àwọn akéde Ìjọba náà ní Japan ti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́ta.
Ìbísí ń ya wọlé débi pé, ní 1972, iye àwọn Ẹlẹ́rìí ti lé ní ẹgbẹ̀rún mẹ́rìnlá, a sì kọ́ ẹ̀ka iléeṣẹ́ alájà márùn-ún tuntun kan sí Numazu, ní gúúsù Tokyo. Àrímáleèlọ ni ìran Òkè Fuji táa máa ń rí láti ilé wa. A bẹ̀rẹ̀ sí tẹ ìwé ìròyìn tó lé ní mílíọ̀nù kan lóṣooṣù lédè Japanese nínú ẹ̀rọ ìtẹ̀wé ńlá wa tuntun. Ṣùgbọ́n ó dà bíi pé nǹkan fẹ́ yí padà.
Ní apá ìparí 1974, Lloyd gba lẹ́tà kan láti orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, wọ́n ní kó wá di ara Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso. Èrò tó kọ́kọ́ wá sí mi lọ́kàn ni pé: ‘Tóò, ó parí nìyẹn o. Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ìrètí tọ̀run ni Lloyd ní, tí tèmi sì jẹ́ tayé, kò sígbà tá ò kúkú ní ya ara wa, bópẹ́ bóyá. Á dára kí Lloyd máa dá lọ sí Brooklyn, kí èmi dúró.’ Ṣùgbọ́n kíá ni mo tún èrò mi ṣe, mo sì fi tọkàntọkàn tẹ̀ lé Lloyd lọ ní March 1975.
Ọ̀pọ̀ Ìbùkún ní Orílé Iṣẹ́
Kódà nígbà táa dé Brooklyn, ọkàn Lloyd kò kúrò ní Japan rárá, gbogbo ìgbà ló máa ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ìrírí táa ní níbẹ̀. Ṣùgbọ́n àǹfààní tún wà báyìí láti bá àwọn ẹlòmíràn ṣiṣẹ́. Láàárín ọdún mẹ́rìnlélógún tó gbẹ̀yìn ìgbésí ayé Lloyd, wọ́n lò ó gan-an fún iṣẹ́ ìbẹ̀wò ẹlẹ́kùnjẹkùn, èyí sì wé mọ́ rírin ìrìn àjò jákèjádò ayé. Mo bá a rin ayé já ní ìgbà mélòó kan.
Bíbẹ àwọn Kristẹni arákùnrin wa wò ní àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn jẹ́ kí n mọ ipò tí ọ̀pọ̀ nínú wọn ń gbé, tí wọ́n sì ti ń ṣiṣẹ́. Mi ò jẹ́ gbàgbé ojú Entellia ọmọ ọdún mẹ́wàá, ọmọbìnrin tí mo pàdé ní àríwá Áfíríkà. Ó fẹ́ràn orúkọ Ọlọ́run, ó sì máa ń rin ìrìn wákàtí kan àtààbọ̀ wá sí àwọn ìpàdé Kristẹni á sì tún rin wákàtí kan àtààbọ̀ padà sílé. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àwọn ẹbí Entellia ń ṣe inúnibíni gbígbóná janjan sí i, ó ya ara rẹ̀ sí mímọ́ fún Jèhófà. Nígbà táa bẹ ìjọ rẹ̀ wò, gílóòbù iná mànàmáná kan ṣoṣo tí kò mọ́lẹ̀ dáadáa ló wà níbi tí olùbánisọ̀rọ̀ gbé ìwé rẹ̀ sí—àìjẹ́ bẹ́ẹ̀, inú òkùnkùn biribiri ni ibi ìpàdé yẹn ì bá wà. Nínú gbogbo òkùnkùn náà ńkọ́, háà ṣe wá nígbà táa gbọ́ ohùn iyọ̀ táwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wa fi ń kọrin.
Ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé kan ṣẹlẹ̀ nínú ìgbésí ayé wa ní December 1998, nígbà yẹn, èmi àti Lloyd wà lára àwọn aṣojú tó lọ sí Àwọn Àpéjọpọ̀ Àgbègbè “Ọ̀nà Ìgbésí Ayé Tí Ọlọ́run Fẹ́,” táa ṣe ní Cuba. Ìmọrírì àti ayọ̀ tí àwọn arákùnrin àti arábìnrin níbẹ̀ ní nítorí pé àwa kan láti orílé iṣẹ́ ní Brooklyn wá bẹ̀ wọ́n wò mà wú wa lórí o! Mi ò jẹ́ gbàgbé àwọn ẹni ọ̀wọ́n tí mo bá pàdé, tí wọ́n ń fi ìtara hó ìhó ìyìn sí Jèhófà.
Ara Mi Ti Mọlé Láàárín Àwọn Èèyàn Ọlọ́run
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ọmọ Ọsirélíà ni mí, mo máa ń nífẹ̀ẹ́ àwọn èèyàn tó bá wà ní ibi yòówù tí ètò àjọ Jèhófà bá rán mi lọ. Bó ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn ní Japan, bákan náà ló rí báyìí látìgbà tí mo ti wà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ní ohun tó ti lé ní ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n. Nígbà tí ọkọ mi kú, kò tiẹ̀ wá sí mi lọ́kàn rárá láti padà sí Ọsirélíà, bí kò ṣe láti dúró sí Bẹ́tẹ́lì ní Brooklyn, níbi tí Jèhófà sọ pé kí n ti máa ṣiṣẹ́.
Mo ti lé ní ẹni ọgọ́rin ọdún báyìí. Lẹ́yìn ọdún mọ́kànlélọ́gọ́ta nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún, mo ṣì múra tán láti máa sin Jèhófà níbikíbi tó bá fẹ́. Ó ti tọ́jú mi gan-an ni. Oyin mọmọ ni ọdún mẹ́tàdínlọ́gọ́ta tí èmi àti olólùfẹ́ mi ọ̀wọ́n tó nífẹ̀ẹ́ Jèhófà fi wà pa pọ̀. Ó dá mi lójú pé ìbùkún Jèhófà yóò máa wà lórí wa nìṣó, mo sì mọ̀ pé Òun kò ní gbàgbé iṣẹ́ wa àti ìfẹ́ táa fi hàn fún orúkọ rẹ̀.—Hébérù 6:10.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Wo Ilé Ìṣọ́, October 1, 1999, ojú ìwé 16 àti 17.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Èmi àti ìyá mi ní 1956
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Èmi àti Lloyd àti àwùjọ àwọn akéde ará Japan ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn ọdún 1950
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Èmi àti Miyo Takagi, ẹni àkọ́kọ́ tí mo bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní Japan, àwa rèé ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1950 àti ní 1999
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Èmi àti Lloyd lẹ́nu iṣẹ́ ìwé ìròyìn ní Japan