Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Kí ni Ìhìn Rere Ìjọba Náà?

Kí ni Ìhìn Rere Ìjọba Náà?

Kí ni Ìhìn Rere Ìjọba Náà?

Lọ́dún tó kọjá, 6,035,564 àwọn èèyàn, lọ́mọdé lágbà ló fi 1,171,270,425 wákàtí bá àwọn ẹlòmíràn sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní nǹkan bí igba ó lé márùndínlógójì [235] ilẹ̀ yí ká ayé. Láfikún sí sísọ̀rọ̀ nípa nǹkan náà, wọ́n tún fún àwọn èèyàn ní àwọn ìtẹ̀jáde tó lé ní ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rin [700] mílíọ̀nù, láti fi polongo àti láti fi ṣàlàyé nǹkan náà. Wọ́n tún pín ẹgbẹẹgbẹ̀rún kásẹ́ẹ̀tì àfetígbọ́ àti fídíò láti kéde nǹkan náà. Kí ni “nǹkan” ọ̀hún?

“ÌHÌN rere Ìjọba Ọlọ́run ni “nǹkan” náà. Ní tòótọ́, kò sígbà tí ìwàásù “ìhìn rere ìjọba yìí” tàn kálẹ̀ tó bó ṣe rí lónìí yìí rí nínú ìtàn ẹ̀dá ènìyàn.—Mátíù 24:14.

Àwọn tó yọ̀ǹda ara wọn ni gbogbo àwọn tó ń ṣe iṣẹ́ ìwàásù àti kíkọ́ni yìí kárí ayé. Táa bá fi ojú tayé wò ó, ó lè jọ pé wọn ò tóótun fún iṣẹ́ náà. Kí wá ni ìdí tí wọ́n fi nígboyà tí wọ́n sì ń kẹ́sẹ járí? Agbára ìhìn rere Ìjọba náà ni ọ̀kan lára ohun pàtàkì tó fà á, nítorí pé ó jẹ́ ìhìn rere nípa àwọn ìbùkún tí ń bọ̀ wá fún aráyé. Èyíinì ni àwọn ìbùkún tí gbogbo èèyàn ti ń yán hànhàn fún—bí ayọ̀, bíbọ́ lọ́wọ́ àìríjẹ àìrímu, níní ìjọba rere, àlàáfíà àti ààbò, àti nǹkan kan tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò gbà pé ó ṣeé ṣe—ìyẹn ni ìyè àìnípẹ̀kun! Láìsí àní-àní, ìhìn rere nìyí fáwọn tí ń wá bí ìgbésí ayé wọn ṣe máa ní ìtumọ̀ àti ète. Àní sẹ́, gbogbo ìbùkún wọ̀nyí àti jù bẹ́ẹ̀ lọ lè jẹ́ tìrẹ bóo bá fetí sí ìpolongo ìhìn rere Ìjọba náà, tóo sì tẹ́wọ́ gbà á.

Kí Ni Ìjọba Náà?

Kí tilẹ̀ ni Ìjọba táa ń polongo gẹ́gẹ́ bí ìhìn rere? Èyí ni Ìjọba tí a ti kọ́ àràádọ́ta ọ̀kẹ́ èèyàn láti máa gba àdúrà táa mọ bí ẹní mọwó yìí nípa rẹ̀, pé: “Baba wa tí ń bẹ ní ọ̀run, kí orúkọ rẹ di sísọ di mímọ́. Kí ìjọba rẹ dé. Kí ìfẹ́ rẹ ṣẹ, gẹ́gẹ́ bí ti ọ̀run, lórí ilẹ̀ ayé pẹ̀lú.”—Mátíù 6:9, 10.

Èyí ni Ìjọba tí Dáníẹ́lì, wòlíì Hébérù nì, sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ ní ohun tó lé ní ọ̀rúndún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n sẹ́yìn, nígbà tó kọ̀wé pé: “Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dáníẹ́lì 2:44.

Nípa báyìí, ìhìn rere náà jẹ́ nípa Ìjọba, tàbí àkóso, látọwọ́ Ọlọ́run, èyí tí yóò mú gbogbo ìwà ibi kúrò, tí yóò sì máa ṣàkóso ilẹ̀ ayé lọ́nà àlàáfíà. Ìjọba yìí ni yóò jẹ́ kí ète ìpilẹ̀ṣẹ̀ tí Ẹlẹ́dàá ní fún aráyé àti fún ilẹ̀ ayé ní ìmúṣẹ.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28.

“Ìjọba Ọ̀run Ti Sún Mọ́lé”

Ọkùnrin olùfọkànsìn kan tí ìrísí àti ìṣesí rẹ̀ gbàfiyèsí ló kọ́kọ́ polongo ìhìn rere Ìjọba náà ní gbangba, ní ohun tó dín díẹ̀ ní ẹgbẹ̀rún ọdún méjì sẹ́yìn. Ọkùnrin náà ni Jòhánù Oníbatisí, ọmọ Sekaráyà àlùfáà tí í ṣe Júù àti Èlísábẹ́tì aya rẹ̀. Jòhánù a máa wọ aṣọ táa fi irun ràkúnmí ṣe, a sì máa di àmùrè awọ yí ká abẹ́nú rẹ̀, bíi ti wòlíì Èlíjà, tí ó ṣàpẹẹrẹ rẹ̀. Àmọ́ iṣẹ́ tó wá jẹ́ ló gba àfiyèsí ọ̀pọ̀ èèyàn. Ó ń kéde pé: “Ẹ ronú pìwà dà, nítorí ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.”—Mátíù 3:1-6.

Àwọn Júù, tí wọ́n sọ pé Jèhófà, Ọlọ́run tòótọ́, làwọn ń sìn ni Jòhánù ń wàásù fún. Gẹ́gẹ́ bí orílẹ̀-èdè kan, wọ́n ti gba májẹ̀mú Òfin nípasẹ̀ Mósè ní nǹkan bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀jọ [1,500] ọdún ṣáájú àkókò yẹn. Tẹ́ńpìlì gàgàrà náà, níbi tí wọ́n ti ń rú àwọn ẹbọ níbàámu pẹ̀lú Òfin, ṣì wà ní Jerúsálẹ́mù nígbà yẹn. Àwọn Júù ń fọwọ́ sọ̀yà pé ìjọsìn àwọn tọ́ lójú Ọlọ́run.

Àmọ́, ọ̀rọ̀ táwọn èèyàn kan ń gbọ́ lẹ́nu Jòhánù wá jẹ́ kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí rí i pé ẹ̀sìn wọn kò tọ̀nà, kò rí bí wọ́n ti rò pé ó rí. Àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì ti yọ́ wọnú ẹ̀kọ́ ìsìn àwọn Júù. Wọ́n ti wá fi àwọn àdábọwọ́ ìgbàgbọ́ àti àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ṣe àbùlà òfin tí Mósè gbà lọ́dọ̀ Ọlọ́run, wọ́n tilẹ̀ wá fi nǹkan wọ̀nyí sọ òfin ọ̀hún di aláìlẹ́sẹ̀nílẹ̀. (Mátíù 15:6) Àwọn tó pọ̀ jù lọ lára àwọn èèyàn náà kò sin Ọlọ́run lọ́nà tó tọ́ mọ́, nítorí pé àwọn aṣáájú ìsìn wọn tó jẹ́ olóríkunkun àti aláìlójú-àánú ti ṣì wọ́n lọ́nà. (Jákọ́bù 1:27) Wọ́n gbọ́dọ̀ ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n ṣẹ Ọlọ́run àti májẹ̀mú Òfin náà tí wọ́n rú.

Nígbà yẹn, ọ̀pọ̀ Júù ló ń retí dídé Mèsáyà, tàbí Kristi táa ṣèlérí, àwọn kan tiẹ̀ ń ronú nípa Jòhánù pé: “Àbí òun ni Kristi náà ni?” Ṣùgbọ́n Jòhánù sọ pé òun kọ́, kàkà bẹ́ẹ̀ ńṣe ló ń darí wọn sí ẹlòmíràn, ó sọ nípa onítọ̀hún pé: ‘Èmi kò tó láti tú okùn sálúbàtà rẹ̀.’ (Lúùkù 3:15, 16) Nígbà tí Jòhánù ń fi Jésù han àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, ó kéde pé: “Wò ó, Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ!”—Jòhánù 1:29.

Ìhìn rere gidi lèyí jẹ́ lóòótọ́, nítorí pé ọ̀nà tí Jòhánù ń tọ́ka gbogbo èèyàn sí ni ọ̀nà ìyè àti ayọ̀—ìyẹn Jésù, ẹni “tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ.” Gẹ́gẹ́ bí àtọmọdọ́mọ Ádámù àti Éfà, gbogbo èèyàn la bí sábẹ́ ìyà ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú. Róòmù 5:19 ṣàlàyé pé: “Gan-an gẹ́gẹ́ bí ó ti jẹ́ pé nípasẹ̀ àìgbọràn ènìyàn kan [Ádámù] ọ̀pọ̀ ènìyàn ni a sọ di ẹlẹ́ṣẹ̀, bákan náà pẹ̀lú ni ó jẹ́ pé nípasẹ̀ ìgbọràn ènìyàn kan [Jésù], ọ̀pọ̀ ènìyàn ni a ó sọ di olódodo.” Gẹ́gẹ́ bí ọ̀dọ́ àgùntàn táa fi rúbọ, ńṣe ni Jésù yóò ‘kó ẹ̀ṣẹ̀ lọ,’ tí yóò sì mú ipò ìbànújẹ́ táráyé wà kúrò. Bíbélì ṣàlàyé pé: “Owó ọ̀yà tí ẹ̀ṣẹ̀ máa ń san ni ikú, ṣùgbọ́n ẹ̀bùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni ni ìyè àìnípẹ̀kun nípasẹ̀ Kristi Jésù Olúwa wa.”—Róòmù 6:23.

Gẹ́gẹ́ bí ọkùnrin pípé—ìyẹn ọkùnrin atóbilọ́lá jù lọ tó tíì gbé ayé rí—Jésù bẹ̀rẹ̀ sí wàásù ìhìn rere náà. Àkọsílẹ̀ Bíbélì nínú Máàkù 1:14, 15 sọ fún wa pé: “Wàyí o, lẹ́yìn tí a ti fi àṣẹ ọba mú Jòhánù, Jésù lọ sí Gálílì, ó ń wàásù ìhìn rere Ọlọ́run, ó sì ń wí pé: ‘Àkókò tí a yàn kalẹ̀ ti pé, ìjọba Ọlọ́run sì ti sún mọ́lé. Ẹ ronú pìwà dà, kí ẹ sì ní ìgbàgbọ́ nínú ìhìn rere.’”

Àwọn tó tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ tí Jésù jẹ́, tí wọ́n sì gba ìhìn rere náà gbọ́ rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà. Jòhánù 1:12 sọ pé: “Gbogbo àwọn tí wọ́n gba [Jésù], àwọn ni ó fún ní ọlá àṣẹ láti di ọmọ Ọlọ́run, nítorí pé wọ́n ń lo ìgbàgbọ́ nínú orúkọ rẹ̀.” Jíjẹ́ tí wọ́n jẹ́ ọmọ Ọlọ́run jẹ́ kí wọ́n ní ìrètí jíjèrè ìyè àìnípẹ̀kun.—1 Jòhánù 2:25.

Ṣùgbọ́n àǹfààní rírí àwọn ìbùkún Ìjọba náà gbà kò mọ sọ́dọ̀ àwọn èèyàn tó gbé ayé ní ọ̀rúndún kìíní. Gẹ́gẹ́ báa ti sọ ṣáájú, gbogbo ilẹ̀ ayé táwọn èèyàn ń gbé la ti ń polongo ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run lónìí. Fún ìdí yìí, àwọn ìbùkún Ìjọba náà ṣì ń bẹ lárọ̀ọ́wọ́tó. Kí ni o gbọ́dọ̀ ṣe láti lè rí àwọn ìbùkún náà gbà? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò ṣàlàyé.