Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ó Máa Ń Dà Bíi Pé Wọ́n Ṣì Ọ́ Lóye?

Ǹjẹ́ Ó Máa Ń Dà Bíi Pé Wọ́n Ṣì Ọ́ Lóye?

Ǹjẹ́ Ó Máa Ń Dà Bíi Pé Wọ́n Ṣì Ọ́ Lóye?

Ọ̀RÀN náà kó ìrònú bá Antonio gan-an ni. Lójijì ni Leonardo, tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ bẹ̀rẹ̀ sí í dákẹ́ tí kò sọ̀rọ̀ sí i mọ́. a Ọ̀pọ̀ ìgbà ni ọ̀rẹ́ rẹ̀ kì í dáhùn nígbà tí Antonio bá kí i, nígbà táwọn méjèèjì bá sì wà pa pọ̀, ó máa ń dà bí ẹni pé nǹkan kan ò pa wọ́n pọ̀ mọ́. Antonio wá bẹ̀rẹ̀ sí ronú pé òun ti ní láti ṣe nǹkan kan tàbí kí òun ti sọ nǹkan kan tí ọ̀rẹ́ òun ṣì lóye. Àmọ́, kí ni nǹkan náà?

Èdè àìyedè wọ́pọ̀ gan-an ni. Àwọn kan ò tó nǹkan, kò sì ṣòro láti yanjú wọn. Àwọn kan máa ń fẹ́rẹ̀ẹ́ pinni lẹ́mìí, àgàgà nígbà tí èrò òdì bá ti wọ̀ ọ́ láìka gbogbo ìsapá láti mú un kúrò sí. Kí ló tiẹ̀ máa ń fa èdè àìyedè? Báwo ló ṣe máa ń nípa lórí àwọn tí ọ̀ràn kàn? Kí lo lè ṣe bí àwọn mìíràn bá ṣi ohun tóo ṣe lóye? Ǹjẹ́ ohun táwọn ẹlòmíràn ń rò nípa rẹ tiẹ̀ já mọ́ nǹkan kan?

Ohun Tí Kò Ṣeé Sá fún Ni

Níwọ̀n bí àwọn èèyàn kò ti lè mọ èrò inú àti ète ọkàn wa, bópẹ́ bóyá, ẹnì kan á ṣi àwọn ọ̀rọ̀ tàbí ìṣe wa lóye ṣáá ni. Ohun tó lè fa èdè àìyedè pọ̀ rẹpẹtẹ. Nígbà mìíràn, ohun tó máa ń fà á ò ju àìṣàlàyé èrò wa lọ́nà tó ṣe kedere, tó sì yéni. Ariwo táwọn èèyàn ń pa nítòsí àtàwọn nǹkan mìíràn tí ń pín ọkàn níyà lè máà jẹ́ kó rọrùn fáwọn mìíràn láti fetí sí ọ̀rọ̀ wa dáadáa.

Àwọn ọ̀nà àti ìṣesí mìíràn tún wà táwọn èèyàn máa ń ṣì lóye. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n lè rò pé ńṣe ni ẹnì kan tó jẹ́ onítìjú kò fẹ́ báni dọ́rẹ̀ẹ́, tí kò kani sí, tàbí kí wọ́n tiẹ̀ rò pé ìgbéraga ló ń dà á láàmú. Àwọn ìrírí téèyàn ti ní tẹ́lẹ̀ lè mú kí ẹnì kan fara ya nítorí nǹkan kan dípò tí ì bá fi bomi sùúrù mu. Àṣà àti èdè tó yàtọ̀ síra lè máà jẹ́ káwọn èèyàn lóye ara wọn bó ṣe yẹ. Ìyẹn nìkan kọ́ o, àwọn ìròyìn tí kì í ṣòótọ́ àti òfófó tún máa ń fa ìṣòro, kò sì ní yà wá lẹ́nu pé báa ṣe lóye ohun tẹ́nì kan sọ tàbí ohun tẹ́nì kan ṣe máa ń yàtọ̀ pátápátá sí ohun tí onítọ̀hún ní lọ́kàn nígbà mìíràn. Àmọ́ o, ìwọ̀nba ìtùnú díẹ̀ ni gbogbo èyí lè jẹ́ fún àwọn tí wọ́n rí i pé àwọn èèyàn ti ṣi ohun táwọn ní lọ́kàn lóye.

Fún àpẹẹrẹ, Anna sọ̀rọ̀ kan tí kì í ṣe ti ìbanilórúkọjẹ́ nípa bí ọ̀rẹ́ rẹ̀ kan ṣe gbajúmọ̀ tó, nígbà tí ọ̀rẹ́ náà kò sí níbẹ̀. Ẹnì kan wá lọ tún ọ̀rọ̀ yẹn sọ, láìṣe àlàyé nípa bí ọ̀rọ̀ yẹn ṣe wáyé. Ó ya Anna lẹ́nu, ó sì dùn ún gan-an, nígbà tí ọ̀rẹ́ náà wá fi ìbínú sọ̀rọ̀ sí i níbi táwọn èèyàn pọ̀ sí, tó sọ pé ńṣe ni Anna ń jowú òun nítorí pé ọkùnrin kan ń f ìfẹ́ hàn sí òun. Ó ti ṣì ohun tí Anna sọ lóye pátápátá, gbogbo ìsapá tó ṣe láti jẹ́ kí ọ̀rẹ́ rẹ̀ mọ̀ pé bẹ́ẹ̀ kọ́ lọ̀rọ̀ rí sì já sí pàbó. Ohun tó ṣẹlẹ̀ yẹn fa ẹ̀dùn ọkàn tó pọ̀, ó sì pẹ́ kí Anna tó lè yanjú èdè àìyedè náà.

Ojú táwọn èèyàn fi ń wò ọ́ sábà máa ń sinmi lórí bí wọ́n ṣe lóye èrò ọkàn rẹ. Nítorí náà, kò sẹ́ni tí kì í dùn nígbà táwọn èèyàn bá ṣi ohun táa ní lọ́kàn lóye. O lè máa bínú, kóo máa rò pé kò sí ìdí kankan tó fi yẹ kí ẹnikẹ́ni ṣì ọ́ lóye. Lójú tìẹ, irú àṣìlóye bẹ́ẹ̀ fi ẹ̀tanú hàn, ó ti le koko jù, tàbí pé ó tiẹ̀ lòdì pátápátá, ó sì lè bani nínú jẹ́ gan-an—àgàgà tó bá jẹ́ pé àwọn tóo bọ̀wọ̀ fún ló wá lọ ṣì ọ́ lóye.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ojú táwọn èèyàn fi ń wò ọ́ lè bí ọ nínú, síbẹ̀síbẹ̀ kò yẹ kóo tẹ́ńbẹ́lú ojú táwọn ẹlòmíràn fi ń wo nǹkan. Kì í ṣe ìwà Kristẹni láti fojú tín-ínrín ohun táwọn ẹlòmíràn ń rò, a ò sì ní fẹ́ kí àwọn ọ̀rọ̀ àti ìṣe wa nípa tí kò dára lórí àwọn ẹlòmíràn. (Mátíù 7:12; 1 Kọ́ríńtì 8:12) Nítorí náà, láwọn ìgbà mìíràn, ó lè pọndandan pé kí o sapá láti tún èrò òdì tí ẹnì kan ní nípa rẹ ṣe. Àmọ́ ṣá o, téèyàn bá tún ń ṣàníyàn jù nípa báwọn èèyàn ṣe máa gba tòun, àbájáde rẹ̀ lè máà dára, ó lè yọrí sí fífi ara ẹni wọ́lẹ̀ tàbí kéèyàn wá ka ara rẹ̀ sí ẹni tí wọ́n ti pa tì. Ó ṣe tán, kì í ṣe ohun táwọn ẹlòmíràn ń rò nípa rẹ ló ń fi bóo ṣe jẹ́ gan-an hàn.

Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, o lè rí i pé òótọ́ lohun táwọn èèyàn ń sọ nípa rẹ. Ìyẹn náà lè bani nínú jẹ́, àmọ́ tóo bá fi tinútinú àti tọkàntọkàn gba àwọn àṣìṣe rẹ, irú àwọn ìrírí bẹ́ẹ̀ lè wá ṣe ọ́ láǹfààní, kó sún ọ láti ṣe àwọn àtúnṣe tó yẹ ní ṣíṣe.

Àwọn Àbájáde Búburú

Àìgbọ́ra ẹni yé lè dá wàhálà sílẹ̀, ó si lè máà dá a sílẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, tóo bá gbọ́ tí ẹnì kan ń pariwo sọ̀rọ̀ nílé àrójẹ, o lè parí èrò sí pé ẹni tó túra ká ni tàbí ẹnì kan tó ń hùwà ṣekárími. Ọ̀rọ̀ sì lè máà rí bẹ́ẹ̀ rárá. Ó lè jẹ́ pé ẹni tétí ń dùn ló ń bá sọ̀rọ̀. Tàbí bóyá akọ̀wé ilé ìtajà kan fajú ro, ó lè jẹ́ pé ara rẹ̀ ni kò yá. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé irú àṣìlóye bẹ́ẹ̀ lè fa èrò òdì, kì í sábàá dá wàhálà sílẹ̀ tàbí kó fa nǹkan tí kò ní tán nílẹ̀ bọ̀rọ̀. Àmọ́, ìgbà mìíràn wà tí àṣìlóye lè fa wàhálà o. Gbé àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ méjì yẹ̀ wò nínú ìtàn Ísírẹ́lì ayé ìgbàanì.

Nígbà tí Náháṣì ọba Ámónì kú, Dáfídì rán àwọn ońṣẹ́ láti lọ tu Hánúnì, ọmọ rẹ̀ tó ti bẹ̀rẹ̀ sí ṣàkóso nípò baba rẹ̀, nínú. Àmọ́ wọ́n ṣi ìbẹ̀wò àwọn ońṣẹ́ náà lóye pé ńṣe ni wọ́n wá ṣe amí ìpínlẹ̀ àwọn Ámónì. Èyí mú kí Hánúnì, tẹ́ àwọn ońṣẹ́ náà lógo, ó sì tún gbé ogun dìde sí Ísírẹ́lì. Àbájáde rẹ̀ ni pé, ó kéré tán ẹgbẹ̀rún mẹ́tàdínláàádọ́ta [47,000] ènìyàn ló kú—ohun tó sì fa gbogbo èyí ni pé wọ́n ṣi èrò rere lóye.—1 Kíróníkà 19:1-19.

Ṣáájú àkókò yẹn nínú ìtàn Ísírẹ́lì, wọ́n yanjú èdè àìyedè kan lọ́nà tó yàtọ̀ síyẹn. Ẹ̀yà Rúbẹ́nì àti ti Gáàdì àti ààbọ̀ ẹ̀yà Mánásè kọ́ pẹpẹ kan síbi tí gbogbo èèyàn ti lè rí i lẹ́bàá Odò Jọ́dánì. Ìyókù àwọn ọmọ Ísírẹ́lì ka èyí sí ìwà àìṣòótọ́, wọ́n kà á sí ìṣọ̀tẹ̀ sí Jèhófà. Bí wọ́n ṣe kóra wọn jọ nìyẹn, tí wọ́n fẹ́ jagun. Àmọ́ kí wọ́n tó gbé ìgbésẹ̀ kankan, àwọn ọmọ Ísírẹ́lì yòókù wọ̀nyí kọ́kọ́ rán ońṣẹ́ lọ láti lọ sọ fún wọn pé inú bí àwọn gan-an sóhun tí wọ́n kà sí ìwà àìṣòótọ́ yìí. Ó dára tí wọ́n ṣe bẹ́ẹ̀, nítorí pé àwọn tó kọ́ pẹpẹ náà fèsì pé àwọn ò lérò àtifi ìjọsìn mímọ́gaara sílẹ̀ rárá. Kàkà bẹ́ẹ̀, ńṣe làwọ́n kọ́ pẹpẹ náà kí ó lè máa rán àwọn létí ìṣòtítọ́ àwọn sí Jèhófà. Àṣìlóye yìí ì bá fa ìpànìyàn nípakúpa, àmọ́ ọgbọ́n gbà wọ́n lọ́wọ́ àbájáde búburú bẹ́ẹ̀.—Jóṣúà 22:10-34.

Máa Fìfẹ́ Yanjú Ọ̀ràn

Ẹ̀kọ́ ńlá la kọ́ nínú àwọn ìtàn táa gbé yẹ̀ wò yìí. Ó dájú pé líla ọ̀ràn náà kí ó yé ara wa ni ohun tó dára jù lọ láti ṣe. Nínú ìtàn táa sọ kẹ́yìn yìí, ta ló mọ iye ẹ̀mí táa dáàbò bò, kìkì nítorí pé àwọn apá méjèèjì jọ sọ̀rọ̀ pọ̀? Nínú ọ̀pọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀, ẹ̀mí àwọn èèyàn lè máà sí nínú ewu bí o bá kùnà láti lóye ohun tí ẹlòmíràn ní lọ́kàn, àmọ́ ìbádọ́rẹ̀ẹ́ lè wà nínú ewu. Nítorí náà, tóo bá gbà pé ẹnì kan ti ṣe ohun tí kò dára sí ọ, ṣé ó dá ọ lójú pé o lóye bí nǹkan ṣe rí gan-an, àbí ńṣe lo wulẹ̀ ń méfò? Kí ni ẹnì kejì ní lọ́kàn? Béèrè lọ́wọ́ rẹ̀. Ṣé o lérò pé a ṣì ọ́ lóye ni? Jíròrò nípa rẹ̀. Máà jẹ́ kí ìgbéraga dí ọ lọ́wọ́ láti ṣe bẹ́ẹ̀.

Jésù sọ ohun pàtàkì tó yẹ kó sún wa láti yanjú èdè àìyedè, ó ní: “Nígbà náà, bí ìwọ bá ń mú ẹ̀bùn rẹ bọ̀ níbi pẹpẹ, tí o sì rántí níbẹ̀ pé arákùnrin rẹ ní ohun kan lòdì sí ọ, fi ẹ̀bùn rẹ sílẹ̀ níbẹ̀ níwájú pẹpẹ, kí o sì lọ; kọ́kọ́ wá àlàáfíà, ìwọ pẹ̀lú arákùnrin rẹ, àti lẹ́yìn náà, nígbà tí o bá ti padà wá, fi ẹ̀bùn rẹ rúbọ.” (Mátíù 5:23, 24) Nítorí náà, ohun tó dára jù lọ láti ṣe ni pé kí o lọ bá ẹni náà ní ìwọ nìkan, láìsí pé o pe ẹlòmíràn síbẹ̀. Ńṣe ni ọ̀ràn náà máa túbọ̀ dojú rú bí ẹni tó ṣẹ̀ ọ́ bá kọ́kọ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ náà lọ́dọ̀ ẹlòmíràn. (Òwe 17:9) Góńgó rẹ gbọ́dọ̀ jẹ́ láti wá àlàáfíà nínú ẹ̀mí ìfẹ́. Ẹ fara balẹ̀ ṣàlàyé ìṣòro náà lọ́nà tó ṣe kedere, tó rọrùn láti lóye, láìsí pé ẹ ń dá ara yín lẹ́bi. Ṣàlàyé bí ohun tó ṣẹlẹ̀ náà ṣe rí lára rẹ. Wá fetí sí ohun tí ẹnì kejì ní lọ́kàn dáadáa. Máà máa tètè ní èrò òdì sí ẹlòmíràn. Múra tán láti gbà pé òótọ́ ni ohun tí ẹni yẹn sọ. Rántí pé ìfẹ́ “a máa gba ohun gbogbo gbọ́.”—1 Kọ́ríńtì 13:7.

Ká sọ tòótọ́, kódà nígbà táa bá ti yanjú èdè àìyedè tán, ẹ̀dùn ọkàn ṣì lè wà tàbí àwọn àbájáde kan tí kò bára dé tí kò ní tán nílẹ̀ bọ̀rọ̀. Kí la lè ṣe? Níbi tó bá ti pọndandan, ó dára láti bẹ̀bẹ̀ látọkànwá, ká sì tún ṣe àwọn nǹkan mìíràn táa bá mọ̀ pé a lè ṣe láti yanjú àwọn ìṣòro náà. Nínú gbogbo irú ipò bẹ́ẹ̀, yóò dára bí ẹni táa ṣẹ̀ náà bá lè tẹ̀ lé ìmọ̀ràn onímìísí náà pé: “Ẹ máa bá a lọ ní fífaradà á fún ara yín lẹ́nì kìíní-kejì, kí ẹ sì máa dárí ji ara yín fàlàlà lẹ́nì kìíní-kejì bí ẹnikẹ́ni bá ní ìdí fún ẹjọ́ lòdì sí ẹlòmíràn. Àní gẹ́gẹ́ bí Jèhófà ti dárí jì yín ní fàlàlà, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin pẹ̀lú máa ṣe. Ṣùgbọ́n, yàtọ̀ sí gbogbo nǹkan wọ̀nyí, ẹ fi ìfẹ́ wọ ara yín láṣọ, nítorí ó jẹ́ ìdè ìrẹ́pọ̀ pípé.”—Kólósè 3:13, 14; 1 Pétérù 4:8.

Níwọ̀n ìgbà tí a bá ṣì jẹ́ aláìpé, kò sí bí èdè àìyedè àti ìbínú kò ṣe ní máa wà. Kò sẹ́ni tí kò lè ṣe àṣìṣe tàbí kó sọ̀rọ̀ lọ́nà kan tó dà bí pé kò gba tẹni rò. Bíbélì là á mọ́lẹ̀ pé: “Gbogbo wa ni a máa ń kọsẹ̀ lọ́pọ̀ ìgbà. Bí ẹnì kan kò bá kọsẹ̀ nínú ọ̀rọ̀, ẹni yìí jẹ́ ènìyàn pípé, tí ó lè kó gbogbo ara rẹ̀ pẹ̀lú níjàánu.” (Jákọ́bù 3:2) Níwọ̀n bí Jèhófà Ọlọ́run ti mọ èyí, ó ti pèsè àwọn ìtọ́ni wọ̀nyí fún wa pé: “Má ṣe kánjú nínú ẹ̀mí rẹ láti fara ya, nítorí pé fífara ya sinmi ní oókan àyà àwọn arìndìn. Pẹ̀lúpẹ̀lù, má fi ọkàn-àyà rẹ sí gbogbo ọ̀rọ̀ tí àwọn ènìyàn lè máa sọ, kí o má bàa gbọ́ tí ìránṣẹ́ rẹ ń pe ibi wá sórí rẹ. Nítorí ọkàn-àyà ìwọ fúnra rẹ mọ̀ dáadáa, àní ní ọ̀pọ̀ ìgbà pé ìwọ, àní ìwọ, ti pe ibi wá sórí àwọn ẹlòmíràn.”—Oníwàásù 7:9, 21, 22.

“Jèhófà Ni Ó Ń Díwọ̀n Àwọn Ọkàn-Àyà”

Tó bá wá dà bíi pé kò sí bóo ṣe lè tún èrò òdì tí ẹnì kan ní sí ọ ṣe ńkọ́? Má ṣe bọ́hùn. Ṣáà máa bá a lọ láti mú àwọn ànímọ́ Kristẹni dàgbà, kí o sì máa fi wọ́n hàn bí o bá ṣe lè ṣe é tó. Bẹ Jèhófà pé kí ó ràn ọ́ lọ́wọ́ láti ṣàtúnṣe níbi tó bá ti yẹ ní ṣíṣe. Àwọn ẹlòmíràn kọ́ ló máa sọ irú èèyàn tóo jẹ́ gan-an. Jèhófà nìkan ṣoṣo ló lè “díwọ̀n àwọn ọkàn-àyà” lọ́nà tó péye. (Òwe 21:2) Àní àwọn èèyàn tẹ́ńbẹ́lú Jésù pàápàá, wọn ò tiẹ̀ kà á sí rárá, síbẹ̀ ìyẹn ò nípa kankan lórí ojú tí Jèhófà fi wò ó. (Aísáyà 53:3) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn kan lè ṣì ọ́ lóye, o lè ‘tú ọkàn-àyà rẹ jáde’ sí Jèhófà, pẹ̀lú ìgbẹ́kẹ̀lé pé ó lóye rẹ, “nítorí kì í ṣe ọ̀nà tí ènìyàn gbà ń wo nǹkan [ni Ọlọ́run gbà ń wo nǹkan], nítorí pé ènìyàn lásán-làsàn ń wo ohun tí ó fara hàn sí ojú; ṣùgbọ́n ní ti Jèhófà, ó ń wo ohun tí ọkàn-àyà jẹ́.” (Sáàmù 62:8; 1 Sámúẹ́lì 16:7) Bí o bá ń tẹra mọ́ ṣíṣe ohun tó dára, nígbà tó bá yá, àwọn tí wọ́n ti ní èrò òdì nípa rẹ lè wá mọ àṣìṣe wọn, kí wọ́n sì yí èrò tí wọ́n ní sí ọ padà.—Gálátíà 6:9; 2 Tímótì 2:15.

Ṣé o rántí Antonio, táa mẹ́nu kàn níbẹ̀rẹ̀ àpilẹ̀kọ yìí? Ó lo ìgboyà láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Ìwé Mímọ́, ó lọ bá ọ̀rẹ́ rẹ̀ Leonardo sọ̀rọ̀, ó béèrè ohun tí òun ṣe tó bí i nínú. Kí ni àbájáde rẹ̀? Ẹnu ya Leonardo gan-an. Ó fèsì pé Antonio ò ṣe ohunkóhun tó lè mú inú bí òun rárá, ó sì jẹ́ kó mọ̀ pé òun ò ní in lọ́kàn rárá láti yí bí òun ṣe máa ń ṣe sí i padà. Ó ní tó bá dà bíi pé òun dákẹ́ tí òun kò sọ̀rọ̀, ó lè ní nǹkan tí òun ń rò. Leonardo bẹ̀bẹ̀ pé òun ti kó ẹ̀dùn ọkàn bá ọ̀rẹ́ òun láìmọ̀, ó sì dúpẹ́ pé ó pe ọ̀ràn náà wá sí àfiyèsí òun. Ó fi kún un pé, òun á túbọ̀ máa ṣọ́ra lọ́jọ́ iwájú kí àwọn ẹlòmíràn má bàá ní irú èrò kan náà nípa òun. Bí gbogbo ìṣòro náà ṣe kásẹ̀ nílẹ̀ nìyẹn, tí àwọn méjèèjì sì ń bára wọn ṣọ̀rẹ́ bíi ti àtẹ̀yìnwá.

Kì í múnú ẹni dùn rárá láti rí i pé a ṣì wá lóye. Àmọ́, bí o bá gbé gbogbo ìgbésẹ̀ tó yẹ kí o gbé láti yanjú àwọn ọ̀ràn, tí o si tẹ̀ lé àwọn ìlànà Bíbélì lórí ìfẹ́ àti ìdáríjì, àfàìmọ̀ ni ìwọ náà kò ní rí irú àbájáde rere bẹ́ẹ̀.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí àwọn orúkọ kan padà nínú àpilẹ̀kọ yìí.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Yíyanjú àwọn ọ̀ràn pẹ̀lú ẹ̀mí ìfẹ́ àti ìdáríjì lè ní àbájáde aláyọ̀