Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Àwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì—Ṣé Alágbàwí Òtítọ́ Bíbélì Ni Wọ́n?

Àwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì—Ṣé Alágbàwí Òtítọ́ Bíbélì Ni Wọ́n?

Àwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì—Ṣé Alágbàwí Òtítọ́ Bíbélì Ni Wọ́n?

Bóyá Kristẹni ni ọ́ tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ó ṣeé ṣe kí wọ́n ti ṣàkóbá fún ojú tóo fi ń wo Ọlọ́run tó ni Bíbélì, àti Jésù, àti ẹ̀sìn Kristẹni. Ẹnú-Dùn-Juyọ̀ lorúkọ táwọn èèyàn sọ ọ̀kan lára wọn, wọ́n sì sọ òmíràn ní Ẹni Ńlá. Wọ́n tiẹ̀ sọ pé lápapọ̀, “kò sí ìgbé ayé ẹlòmíì tó tún sún mọ́ ti Jésù tó tiwọn.” Ta ni wọ́n? Àwọn ni aláròjinlẹ̀ ayé ọjọ́un tí wọ́n jẹ́ ẹlẹ́sìn, òǹkọ̀wé, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn, àtàwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí tó ti sọ ẹ̀kọ́ “Kristẹni” dà bó ṣe dà lónìí—àwọn ni Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì.

Ọ̀JỌ̀GBỌ́N nípa ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti àwọn Gíríìkì tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Demetrios J. Constantelos sọ pé: “Inú Bíbélì nìkan kọ́ ni ọ̀rọ̀ Ọlọ́run wà. Ẹ̀mí Mímọ́ tó ń ṣí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run payá kò lè fi iṣẹ́ rẹ̀ mọ sínú kìkì ìwé kan ṣoṣo.” Ọ̀nà mìíràn tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé wo ló ṣeé ṣe kí Ọlọ́run tún máa lò láti ṣí nǹkan payá? Ohun tí Constantelos sọ nínú ìwé rẹ̀ Understanding the Greek Orthodox Church ni pé: “Iṣẹ́ kan náà ni Àṣà Àtọwọ́dọ́wọ́ Mímọ́ àti Ìwé Mímọ́ jọ ń jẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run.”

Ohun tí wọ́n gbé “Àṣà Àtọwọ́dọ́wọ́ Mímọ́” yẹn kà ni àwọn ẹ̀kọ́ àti ìwé àwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì. Àwọn ni lóókọlóókọ ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn àtàwọn “Kristẹni” onímọ̀ ọgbọ́n orí tí wọ́n gbé ayé láàárín ọ̀rúndún kejì sí ìkarùn-ún Sànmánì Tiwa. Ipa wo ni wọ́n ti ní lórí ìrònú àwọn “Kristẹni” òde òní? Ṣé ẹ̀kọ́ Bíbélì ni wọ́n fi kọ́ni? Kí ni lájorí ohun tó yẹ kí ọmọlẹ́yìn Jésù Kristi gbé òtítọ́ Kristẹni kà?

Ìtàn Bí Wọ́n Ṣe Bẹ̀rẹ̀

Láàárín ọ̀rúndún kejì Sànmánì Tiwa, àwọn tí wọ́n pè ní Kristẹni nígbà yẹn ń gbèjà ìgbàgbọ́ wọn lójú inúnibíni táwọn ará Róòmù ń ṣe àti ogun táwọn aládàámọ̀ ń gbé tì wọ́n. Ṣùgbọ́n ní sáà yẹn, oníkálukú ló ń gbé èrò tirẹ̀ kalẹ̀ nípa ẹ̀sìn. Nínú ìsìn, iyàn jíjà wá pọ̀ rẹ́kẹrẹ̀kẹ nípa bóyá “ọlọ́run” ni Jésù tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́, wọ́n tún ń jiyàn nípa ohun tí ẹ̀mí mímọ́ jẹ́ gan-an àti bó ṣe ń ṣiṣẹ́, ìyapa tí ìjiyàn wọ̀nyí dá sílẹ̀ sì kúrò ní kèrémí. Èdèkòyédè tó di họ́ùhọ́ù àti ìyapa tó di iṣu-ata-yán-anyàn-an lórí ẹ̀kọ́ “Kristẹni” wá ràn bí iná ọyẹ́ wọnú ọ̀ràn ìṣèlú àti àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀, nígbà mìíràn ó fa rúkèrúdò, ọ̀tẹ̀, ìjà ìgboro, àti ogun pàápàá. Òpìtàn nì, Paul Johnson, kọ̀wé pé: “Ẹ̀sìn Kristẹni [apẹ̀yìndà] bẹ̀rẹ̀ nínú ìdàrúdàpọ̀ àti àríyànjiyàn àti ìyapa, bó sì ṣe ń bá a lọ nìyẹn. . . . Ní ọ̀rúndún kìíní àti ìkejì Sànmánì Tiwa, àárín gbùngbùn àti ìlà oòrùn Mẹditaréníà kún fún àìmọye ẹ̀kọ́ ìsìn, tí gbogbo wọn sì ń wá ọ̀nà láti tàn kálẹ̀. . . . Nítorí náà, láti ìbẹ̀rẹ̀ pàá ni oríṣiríṣi ẹ̀sìn Kristẹni tó jẹ́ bàbá-ò-bá-ìyá-tan ti wà.”

Ní sáà yẹn, àwọn òǹkọ̀wé àtàwọn aláròjinlẹ̀ tó ronú pé ó pọndandan láti túmọ̀ àwọn ẹ̀kọ́ tí wọ́n pè ní ti “Kristẹni” lọ́nà ìmọ̀ ọgbọ́n orí wá bẹ̀rẹ̀ sí pọ̀ rẹpẹtẹ. Kí wọ́n lè tẹ́ àwọn kèfèrí tó jẹ́ ọ̀mọ̀wé, tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ di “Kristẹni” lọ́rùn, irú àwọn òǹkọ̀wé ẹlẹ́sìn bẹ́ẹ̀ wá gbájú mọ́ àwọn ìwé Gíríìkì àti ti Júù táwọn èèyàn ti kọ ṣáájú. Bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú Justin Martyr (tó gbé ayé ní nǹkan bí ọdún 100 sí 165 Sànmánì Tiwa), tó kọ̀wé lédè Gíríìkì, àwọn tó pera wọn ní Kristẹni wá dojú nǹkan rú pátápátá nítorí wọ́n ri ara wọn bọnú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Gíríìkì èyí táwọn onímọ̀ ọgbọ́n orí tó ṣáájú wọn ti gbé kalẹ̀.

Ìtẹ̀sí yìí wá fara hàn kedere nínú àwọn ìwé Origen (tó gbé ayé ní nǹkan bí ọdún 185 sí 254 Sànmánì Tiwa), tí í ṣe òǹkọ̀wé lédè Gíríìkì, tó sì jẹ́ ọmọ ìlú Alẹkisáńdíríà. Àlàyé Origen nínú ìwé On First Principles ni ìsapá àkọ́kọ́ tó fẹsẹ̀ múlẹ̀, ní ti ṣíṣàlàyé àwọn lájorí ẹ̀kọ́ “Kristẹni” níbàámu pẹ̀lú ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì. Àpérò Niséà (tí wọ́n ṣe lọ́dún 325 Sànmánì Tiwa), tó gbìyànjú láti ṣàlàyé pé “ọlọ́run” ni Kristi, kí ó sì fìdí kókó yìí múlẹ̀, ni ìgbésẹ̀ pàtàkì tó tún súnná sí fífi ìtumọ̀ sáwọn ẹ̀kọ́ “Kristẹni.” Àpérò náà sàmì sí ìbẹ̀rẹ̀ sáà kan nígbà tí àwọn àpérò gbogbo gbòò ti ṣọ́ọ̀ṣì ń wá ọ̀nà láti ṣàlàyé àwọn ẹ̀kọ́ lọ́nà tó túbọ̀ gún régé.

Àwọn Òǹkọ̀wé àti Sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀

Eusebius ará Kesaréà, tó kọ̀wé nígbà Àpérò Niséà àkọ́kọ́, fọwọ́ sowọ́ pọ̀ pẹ̀lú Olú Ọba Kọnsitatáìnì. Ohun tó fi díẹ̀ lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún lẹ́yìn àpérò Niséà làwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn, tí ọ̀pọ̀ jù lọ lára wọn ń kọ̀wé lédè Gíríìkì, fi ń jiyàn tí wọ́n sì ń tutọ́ síra wọn lójú, níbi tí wọ́n ti ń wá bí wọ́n ṣe máa ṣàlàyé lájorí ẹ̀kọ́ Kirisẹ́ńdọ̀mù, ìyẹn ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan. Ògúnnágbòǹgbò lára wọn ni Athanaisus, bíṣọ́ọ̀bù ará Alẹkisáńdíríà tó lẹ́nu ọ̀rọ̀, àtàwọn aṣáájú ṣọ́ọ̀ṣì mẹ́ta mìíràn láti ìlú Kapadókíà, ní Éṣíà Kékeré—ìyẹn Basil Ńlá, àti àbúrò rẹ̀ Gregory ti ìlú Nyssa àti ọ̀rẹ́ wọn tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Gregory ti ìlú Nazianzus.

Akọ̀wé-kọwúrà, tí ọ̀rọ̀ yọ̀ mọ́ lẹ́nu làwọn òǹkọ̀wé àti oníwàásù sànmánì yẹn. Gregory ti ìlú Nazianzus àti John Chrysostom (tó túmọ̀ sí “Ẹnú-Dùn-Juyọ̀”) tí ń sọ èdè Gíríìkì àti Ambrose ti ìlú Milan àti Augustine ti ìlú Hippo tí ń sọ èdè Látìn jẹ́ sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀ tó dáńtọ́, ọ̀gá ni wọ́n lágbo àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n ìgbà yẹn. Òǹkọ̀wé táwọn èèyàn gba tiẹ̀ jù ní sáà yẹn ni Augustine. Ìwé tó fi ṣe àtúpalẹ̀ ẹ̀kọ́ ìsìn ló ń darí ìrònú àwọn tí ń pera wọn ní “Kristẹni” lóde òní. Jerome, tó jẹ́ onígègé àrà ní sáà táà ń sọ yìí, ni ẹni pàtàkì tó ṣiṣẹ́ lórí ìtumọ̀ Bíbélì Latin Vulgate látinú àwọn èdè ìpilẹ̀ṣẹ̀.

Àmọ́ o, àwọn ìbéèrè pàtàkì ni pé: Ǹjẹ́ àwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì wọ̀nyẹn rọ̀ mọ́ Bíbélì tímọ́tímọ́? Nínú ẹ̀kọ́ wọn, ǹjẹ́ wọ́n fi ọwọ́ pàtàkì mú ọ̀rọ̀ inú Ìwé Mímọ́ táa mí sí? Ǹjẹ́ àwọn ìwé wọn lè ṣamọ̀nà wa sí ìmọ̀ pípéye nípa Ọlọ́run?

Ṣé Ẹ̀kọ́ Ọlọ́run Ni Tàbí Ẹ̀kọ́ Èèyàn?

Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, Olórí Ìjọ Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì ti ilẹ̀ Gíríìkì, ìyẹn Methodius ti ìlú Písídíà, kọ ìwé náà, The Hellenic Pedestal of Christianity, láti fi hàn pé inú àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì ni àwọn èròǹgbà tí wọ́n ń pè ní ti “Kristẹni” ti jáde wá. Ó là á mọ́lẹ̀ nínú ìwé náà pé: “Ó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ gbogbo àwọn sàràkí-sàràkí Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì ló ka àwọn èròǹgbà Gíríìkì sóhun tó wúlò gan-an, wọ́n sì nawọ́ gán èròǹgbà wọ̀nyí látinú àwọn ẹ̀kọ́ Gíríìkì ayé ọjọ́un, wọ́n kà á sí ohun tí yóò fi kún ìmọ̀ wọn, tí yóò sì jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti ṣàlàyé àwọn òtítọ́ Kristẹni.”

Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa èròǹgbà náà pé Baba, Ọmọ, àti ẹ̀mí mímọ́ para pọ̀ jẹ́ Mẹ́talọ́kan. Ọ̀pọ̀ àwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì ló di ògúnnágbòǹgbò onígbàgbọ́ Mẹ́talọ́kan lẹ́yìn Àpérò Niséà. Àwọn ìwé wọn àti àwíyé tí wọ́n sọ wà lára ohun náà gan-an tó sọ Mẹ́talọ́kan di ẹ̀kọ́ pàtàkì ní Kirisẹ́ńdọ̀mù. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ Mẹ́talọ́kan wà nínú Bíbélì? Rárá o. Ibo wá làwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì ti rí i? Ìwé náà, A Dictionary of Religious Knowledge ṣàlàyé pé ọ̀pọ̀ èèyàn ń sọ pé Mẹ́talọ́kan jẹ́ ẹ̀kọ́ “àdàmọ̀dì tí wọ́n mú látinú ẹ̀sìn àwọn abọgibọ̀pẹ̀, tí wọ́n sì wá sọ di ti ẹ̀sìn Kristẹni.” Ìwé náà, The Paganism in Our Christianity, sì là á mọ́lẹ̀ pé: “Ọ̀dọ̀ àwọn kèfèrí gan-an ni [Mẹ́talọ́kan] ti wá.” aJòhánù 3:16; 14:28.

Tàbí kẹ̀, gbé ẹ̀kọ́ àìleèkú ọkàn yẹ̀ wò, ìyẹn ìgbàgbọ́ pé nǹkan kan wà nínú èèyàn tó máa ń wà láàyè nìṣó lẹ́yìn tí ara bá ti kú. Lẹ́ẹ̀kan sí i, bí ẹ̀kọ́ yìí ṣe dé inú ẹ̀sìn kan tí kò kọ́ni ní nǹkan kan nípa pé ọkàn ń wà láàyè lẹ́yìn ikú kò ṣẹ̀yìn àwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì. Bíbélì fi hàn kedere pé ọkàn máa ń kú, ó ní: “Ọkàn tí ń dẹ́ṣẹ̀—òun gan-an ni yóò kú.” (Ìsíkíẹ́lì 18:4) Orí kí ni àwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì gbé ìgbàgbọ́ nínú àìleèkú ọkàn kà? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà, New Catholic Encyclopedia, sọ pé: “Èròǹgbà Kristẹni pé Ọlọ́run dá ọkàn tí kò ṣeé fojú rí, tó sì fi í sínú ara nígbà oyún, láti sọ èèyàn di odindi alààyè ẹ̀dá, wá látinú ìmọ̀ ọgbọ́n orí tó rọra ń yọ́ wọnú ẹ̀sìn Kristẹni látọjọ́ pípẹ́. Kìkì Origen tó wà ní Ìlà Oòrùn ayé àti Augustine Mímọ́ tó wà ní Ìwọ̀ Oòrùn ayé nìkan ló fi gbogbo ara gbà pé ohun tí kò ṣeé fojú rí ni ọkàn jẹ́, àwọn nìkan ló sì fi gbogbo ara gba ìmọ̀ ọgbọ́n orí tó tàn kálẹ̀ nípa ọkàn gbọ́. . . . Inú Àkọ̀tun Ẹ̀kọ́ Plato ni èyí tó pọ̀ jù lọ nínú [ẹ̀kọ́ Augustine] . . . ti wá (títí kan àwọn àbùkù kan tó wà nínú ẹ̀kọ́ náà).” Ìwé ìròyìn náà Presbyterian Life sì sọ pé: “Àìleèkú ọkàn jẹ́ èròǹgbà Gíríìkì tó wá látinú àwọn ẹgbẹ́ awo ìgbàanì, tí onímọ̀ ọgbọ́n orí nì Plato sì wá fi ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé tirẹ̀ kun un.” b

Ìpìlẹ̀ Tó Dúró Sán-ún Tí A Gbé Òtítọ́ Kristẹni Kà

Àní lẹ́yìn àyẹ̀wò ráńpẹ́ táa ṣe yìí nípa ìtàn àwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì, àti bí ẹ̀kọ́ wọn ṣe pilẹ̀, ó ṣì yẹ ká béèrè pé, Ǹjẹ́ ó yẹ kí Kristẹni olóòótọ́ inú gbé ìgbàgbọ́ rẹ̀ karí ẹ̀kọ́ àwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì? Kí á jẹ́ kí Bíbélì dáhùn.

Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Jésù Kristi alára fagi lé lílo orúkọ òye bíi “Baba” nínú ẹ̀sìn, nígbà tó sọ pé: “Ẹ má pe ẹnikẹ́ni ní baba yín lórí ilẹ̀ ayé, nítorí ọ̀kan ni Baba yín, Ẹni ti ọ̀run.” (Mátíù 23:9) Fífi orúkọ oyè náà “Baba” pe ẹnikẹ́ni nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn kò bá ẹ̀sìn Kristẹni mu, kò sì bá Ìwé Mímọ́ mu. Ìwé àpọ́sítélì Jòhánù la fi parí àkọsílẹ̀ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, ní nǹkan bí ọdún 98 Sànmánì Tiwa. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé àwọn Kristẹni tòótọ́ kò ṣẹ̀ṣẹ̀ máa wojú ẹ̀dá ènìyàn èyíkéyìí fún ìṣípayá onímìísí. Wọ́n wà lójúfò láti má ṣe “sọ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run di aláìlẹ́sẹ̀nílẹ̀” nítorí àṣà àtọwọ́dọ́wọ́. Fífi àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ rọ́pò Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run lè múni kàgbákò nípa tẹ̀mí. Jésù kìlọ̀ pé: “Bí afọ́jú bá wá ń fi afọ́jú mọ̀nà, àwọn méjèèjì yóò já sínú kòtò.”—Mátíù 15:6, 14.

Ǹjẹ́ Kristẹni nílò ìṣípayá èyíkéyìí ní àfikún sí ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí í ṣe Bíbélì? Rárá o. Ìwé Ìṣípayá kìlọ̀ pé kí a má ṣe fi ohunkóhun kún àkọsílẹ̀ onímìísí yìí, ó ní: “Bí ẹnikẹ́ni bá ṣe àfikún kan sí nǹkan wọ̀nyí, Ọlọ́run yóò fi àwọn ìyọnu àjàkálẹ̀ tí a kọ sínú àkájọ ìwé yìí kún ẹni náà.”—Ìṣípayá 22:18.

Inú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run táa kọ sílẹ̀ ni òtítọ́ Kristẹni wà. (Jòhánù 17:17; 2 Tímótì 3:16; 2 Jòhánù 1-4) Ìmọ̀ ọgbọ́n orí kọ́ ló máa là á yé wa lọ́nà tó tọ́. Nítorí ti àwọn èèyàn tó ń gbìyànjú láti fi ọgbọ́n ènìyàn ṣàlàyé ìṣípayá Ọlọ́run, á dáa ká tún ìbéèrè àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù béèrè, pé: “Ibo ni ọlọ́gbọ́n ènìyàn náà wà? Ibo ni akọ̀wé òfin náà wà? Ibo ni olùjiyàn ọ̀rọ̀ ètò àwọn nǹkan yìí wà? Ọlọ́run kò ha ti sọ ọgbọ́n ayé di òmùgọ̀?”—1 Kọ́ríńtì 1:20.

Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìjọ Kristẹni tòótọ́ ni “ọwọ̀n àti ìtìlẹyìn òtítọ́.” (1 Tímótì 3:15) Àwọn alábòójútó ìjọ máa ń pa ìjẹ́mímọ́ ẹ̀kọ́ wọn mọ́ láàárín ìjọ, wọn kì í jẹ́ kí ẹ̀kọ́ èké kankan yọ́ wọlé. (2 Tímótì 2:15-18, 25) Wọ́n kì í jẹ́ kí ‘àwọn wòlíì èké, olùkọ́ èké, àti ẹ̀ya ìsìn tí ń pani run’ wọnú ìjọ. (2 Pétérù 2:1) Lẹ́yìn ikú àwọn àpọ́sítélì, àwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì lajú wọn sílẹ̀ títí “àwọn àsọjáde onímìísí tí ń ṣini lọ́nà àti àwọn ẹ̀kọ́ ẹ̀mí èṣù” fi ráyè ta gbòǹgbò nínú ìjọ Kristẹni.—1 Tímótì 4:1.

Ohun tí ìpẹ̀yìndà yìí dá sílẹ̀ là ń rí lónìí nínú Kirisẹ́ńdọ̀mù. Àwọn ẹ̀kọ́ àti àṣà rẹ̀ jìnnà pátápátá sí òtítọ́ Bíbélì.

[Àwọ̀n Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A lè rí ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ ìjíròrò nípa ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan nínú ìwé pẹlẹbẹ náà Iwọ Ha Nilati Gbàgbọ́ Ninu Mẹtalọkan Bí?, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

b Fún ìjíròrò tó kún rẹ́rẹ́ lórí ẹ̀kọ́ Bíbélì nípa ọkàn, jọ̀wọ́ wo ojú ìwé 98 sí 104 àti 375 sí 380 nínú ìwé Reasoning From the Scriptures, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 18]

ÀWỌN BÀBÁ ÌJỌ LẸ́YÌN ÀKÓKÒ ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ NÍ KAPADÓKÍÀ

Òǹkọ̀wé náà Kallistos, tó jẹ́ ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìnìkàngbé, sọ pé: “Ṣọ́ọ̀ṣì Ọ́tọ́dọ́ọ̀sì . . . ti fẹ́rẹ̀ẹ́ sọ àwọn òǹkọ̀wé ọ̀rúndún kẹrin di òrìṣà àkúnlẹ̀bọ, pàápàá jù lọ àwọn tó pè ní ‘Àwọn Aláṣẹ Gíga mẹ́ta,’ ìyẹn Gregory ti Nazianzus, Basil Ńlá, àti John Chrysostom.” Ǹjẹ́ Ìwé Mímọ́ táa mí sí ni àwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì wọ̀nyí gbé ẹ̀kọ́ wọn kà? Ìwé náà, The Fathers of the Greek Church, sọ nípa Basil Ńlá pé: “Àwọn ìwé rẹ̀ fi hàn pé jálẹ̀ ìgbésí ayé rẹ̀ ló fi tẹ̀ síhà ìrònú Plato, Homer, àtàwọn òpìtàn àtàwọn sọ̀rọ̀sọ̀rọ̀, ó sì dájú pé wọ́n nípa lórí ọ̀nà ìkọ̀wé rẹ̀. . . . ‘Ọmọ Gíríìkì’ ni Basil títí dọjọ́ ikú rẹ̀.” Bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́ ni ọ̀ràn Gregory ti Nazianzus rí. “Lójú tirẹ̀, gbígbà tí Ṣọ́ọ̀ṣì bá tẹ́wọ́ gba gbogbo àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ayé ìgbà yẹn ni yóò jẹ́ kó ṣẹ́gun kí ó sì gbégbá orókè.”

Nípa àwọn ọkùnrin mẹ́tẹ̀ẹ̀ta wọ̀nyí, Ọ̀jọ̀gbọ́n Panagiotis K. Christou kọ̀wé pé: “Bó tiẹ̀ jẹ́ pé lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan wọ́n kìlọ̀ lòdì sí ‘ìmọ̀ ọgbọ́n orí àti ẹ̀tàn òfìfo’ [Kólósè 2:8]—kí ó bàa lè ṣeé ṣe láti tẹ̀ lé òfin Májẹ̀mú Tuntun—àmọ́ lẹ́sẹ̀ kan náà, wọ́n ń fi ìháragàgà kẹ́kọ̀ọ́ ìmọ̀ ọgbọ́n orí àtàwọn ẹ̀kọ́ míì tó tan mọ́ ọn, àní wọ́n tún ń rọ àwọn ẹlòmíì pé kí wọ́n máa kọ́ irú ẹ̀kọ́ bẹ́ẹ̀.” Dájúdájú, èrò irú àwọn olùkọ́ni ṣọ́ọ̀ṣì bẹ́ẹ̀ ni pé Bíbélì nìkan kò tóó fi ti àwọn èròǹgbà wọn lẹ́yìn. Ṣé kì í ṣe pé wíwá tí wọ́n ń wá ọlá àṣẹ míì láti fi ṣètìlẹyìn jẹ́ ẹ̀rí pé ẹ̀kọ́ wọn kò bá Bíbélì mu? Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ fáwọn Kristẹni tí í ṣe Hébérù pé: “Kí a má ṣe fi onírúurú àti àjèjì ẹ̀kọ́ gbé yín lọ.”—Hébérù 13:9.

[Credit Line]

© Archivo Iconografico, S.A./CORBIS

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 20]

CYRIL TI ÌLÚ ALẸKISÁŃDÍRÍÀ BÀBÁ ÌJỌ LẸ́YÌN ÀKÓKÒ ÀWỌN ÀPỌ́SÍTÉLÌ TÍ Ọ̀RÀN RẸ̀ Ń FA ÀRÍYÀNJIYÀN

Ọ̀kan lára àwọn Bàbá Ìjọ Lẹ́yìn Àkókò Àwọn Àpọ́sítélì tí ọ̀ràn rẹ̀ ń dá àríyànjiyàn sílẹ̀ jù lọ ni Cyril ti ìlú Alẹkisáńdíríà (tó gbé ayé ní nǹkan bí ọdún 375 sí 444 Sànmánì Tiwa). Ọ̀gbẹ́ni Hans von Campenhausen, tí í ṣe òpìtàn nípa ṣọ́ọ̀ṣì pè é ní “apàṣẹwàá, ìkà ènìyàn, àti oníbékebèke, ẹni tí ipò ńlá àti ipò iyì tó wà ń gùn gàràgàrà,” ó sì fi kún un pé “kò sí nǹkan tó tọ́ lójú rẹ̀ rí, àfi tí nǹkan ọ̀hún bá máa fi kún agbára àti ọlá rẹ̀ . . . Ìwà òkú òǹrorò àti ìwà apanilẹ́kún-jayé tó ń hù kò sì bà á lọ́kàn jẹ́ rí.” Nígbà tí Cyril jẹ́ bíṣọ́ọ̀bù Alẹkisáńdíríà, ó fáwọn èèyàn ní rìbá, ó sọ̀rọ̀ tó bani lórúkọ jẹ́, ó sì purọ́ kí ó bàa lè yẹ àga mọ́ bíṣọ́ọ̀bù Kọnsitantinópù nídìí. Wọ́n ní òun ló wà nídìí pípa tí wọ́n pa gbajúmọ̀ onímọ̀ ọgbọ́n orí nì, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Hypatia, ní ìpa-ìkà lọ́dún 415 Sànmánì Tiwa. Nípa àwọn ìwé ìsìn tí Cyril kọ, Campenhausen sọ pé: “Òun ló bẹ̀rẹ̀ àṣà gbígbé ìpinnu nípa àwọn ìbéèrè tó jẹ mọ́ ìgbàgbọ́ ka àwọn orísun mìíràn yàtọ̀ sí Bíbélì, ó máa ń lo àwọn àyọlò ọ̀rọ̀ àti àkójọ àyọlò ọ̀rọ̀ tó bá yẹ látinú ọ̀rọ̀ àwọn ògbógi tó gbajúmọ̀.”

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

Jerome

[Credit Line]

Garo Nalbandian