Ẹ Wá Wo Olùṣe Àwọn Ohun Àgbàyanu!
Ẹ Wá Wo Olùṣe Àwọn Ohun Àgbàyanu!
“Dúró jẹ́ẹ́, kí o sì fi ara rẹ hàn ní olùfiyèsílẹ̀ sí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run.”—JÓÒBÙ 37:14.
1, 2. Ní 1922, kí ni nǹkan àgbàyanu táa ṣàwárí, báwo ló sì ṣe rí lára àwọn tó rí i?
Ọ̀PỌ̀ ọdún ni awalẹ̀pìtàn kan àti ọlọ́lá ọmọ ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kan fi jọ ń wá ìṣúra náà kiri. Níkẹyìn, ní November 26, 1922, ní ibi ìsìnkú àwọn fáráò ọba Íjíbítì tó wà ní àfonífojì olókìkí táa ń pè ní Àfonífojì Àwọn Ọba, awalẹ̀pìtàn náà Howard Carter àti Ọlọ́lá Carnarvon rí ohun tí wọ́n ń wá—wọ́n rí sàréè Fáráò Tutankhamen. Nígbà tí wọ́n débi ilẹ̀kùn kan tó wà ní títì pa, wọ́n luhò sí i. Carter tan àbẹ́là kan, ó fi wo inú rẹ̀.
2 Carter sọ lẹ́yìn náà pé: “Nígbà tí Ọlọ́lá Carnarvon ti dúró títí tára ẹ̀ ò gbà á mọ́, ló bá fi ìháragàgà béèrè pé, ‘Ǹjẹ́ o rí nǹkan kan?’ gbogbo ohun tí mo lè sọ kò ju pé, ‘Bẹ́ẹ̀ ni, mo rí ohun àgbàyanu.’” Lára ẹgbẹẹgbẹ̀rún ìṣúra tó wà nínú sàréè náà ni pósí kan tí wọ́n fi ògidì wúrà ṣe. Ó ṣeé ṣe kóo ti rí àwòrán díẹ̀ lára “ohun àgbàyanu” wọ̀nyẹn, tàbí kóo ti rí wọn níbi tí wọ́n kó wọn sí níbi ìkóhun-ìṣẹ̀ǹbáyé-sí. Ṣùgbọ́n bí àwọn ohun tí wọ́n tẹ́ fádà rẹ̀ wọ̀nyẹn ti jẹ́ àgbàyanu tó, wọ́n lè máà ní nǹkan kan ṣe pẹ̀lú ìgbésí ayé rẹ. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká wá sọ̀rọ̀ báyìí nípa àwọn ohun àgbàyanu tó kàn ọ́ dájúdájú, tó sì máa wúlò fún ọ.
3. Ibo la óò ti rí ìsọfúnni nípa àwọn ohun àgbàyanu tó máa wúlò fún wa?
3 Fún àpẹẹrẹ, ronú nípa ọkùnrin kan tó gbé ayé ní ọgọ́rọ̀ọ̀rún ọdún sẹ́yìn, ìyẹn ọkùnrin kan tó yẹ fún àfiyèsí ju gbajúmọ̀ òṣèré, tàbí akọni eléré ìdárayá, tàbí olóyè èyíkéyìí. Wọ́n ní òun ló tóbi lọ́lá jù lọ nínú gbogbo àwọn Ará Ìlà-Oòrùn ayé. Ẹni tí o máa mọ orúkọ rẹ̀ ni—Jóòbù ló ń jẹ́. Odindi ìwé kan nínú Bíbélì ló dá lórí ọ̀rọ̀ rẹ̀. Àmọ́, ọ̀dọ́kùnrin kan tí ń jẹ́ Élíhù, tóun náà wà láyé nígbà yẹn, rí i pé ó pọndandan láti tọ́ Jóòbù sọ́nà. Ní ṣókí, Élíhù sọ pé àfiyèsí tí Jóòbù ń pè sí ara rẹ̀ àti sí àwọn tó yí i ká ti pọ̀ jù. Nínú Jóòbù orí 37, a rí àwọn ìmọ̀ràn mìíràn tó jẹ́ ti ọlọgbọ́n, tó sọjú abẹ níkòó, tó lè wúlò gidigidi fún ẹnì kọ̀ọ̀kan wa níbẹ̀.—Jóòbù 1:1-3; 32:1-33:12.
4. Kí ló fà á tí Élíhù fi sọ ọ̀rọ̀ ìyànjú tó wà nínú Jóòbù 37:14?
4 Àwọn mẹ́ta tí wọ́n pera wọn lọ́rẹ̀ẹ́ Jóòbù sáà rinkinkin mọ́ ọn pé àwọn àṣìṣe kan wà tí Jóòbù ti ní láti ṣe, yálà nínú èrò tàbí nínú ìṣe. (Jóòbù 15:1-6, 16; 22:5-10) Élíhù jẹ́ kí kálukú wọ́n sọ gbogbo tẹnu ẹ̀. Ìgbà yẹn ló wá gbẹ́nu lé ọ̀rọ̀, ọ̀rọ̀ ọgbọ́n àti òye. Kò sí èyí tó ṣeé kó dà nù nínú gbogbo ohun tó sọ, ṣùgbọ́n, ṣàkíyèsí kókó ọ̀rọ̀ tó sọ yìí, ó ní: “Fi etí sí èyí, Jóòbù; dúró jẹ́ẹ́, kí o sì fi ara rẹ hàn ní olùfiyèsílẹ̀ sí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run.”—Jóòbù 37:14.
Ẹni Tó Ṣe Àwọn Iṣẹ́ Náà
5. Kí ni “àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run” tí Élíhù tọ́ka sí wé mọ́?
5 Ṣàkíyèsí pé Élíhù kò sọ pé kí Jóòbù fiyè sí ara rẹ̀, tàbí sí Élíhù alára, tàbí sí ọmọ aráyé mìíràn. Ṣe ni Élíhù fi ọgbọ́n rọ Jóòbù—àti àwa náà—láti fiyè sí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Jèhófà Ọlọ́run. Kí ni o rò pé gbólóhùn náà, “àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run,” wé mọ́? Síwájú sí i, pẹ̀lú gbogbo bí ọ̀ràn ìlera, àtijẹ-àtimu, ọjọ́ ọ̀la rẹ, ọ̀ràn ìdílé rẹ, àti tàwọn tí ẹ jọ ń ṣiṣẹ́, àti tàwọn aládùúgbò rẹ ṣe ń jẹ ọ́ lọ́kàn tó, èé ṣe tó fi yẹ kóo fiyè sí àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run? Dájúdájú, àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Jèhófà Ọlọ́run ṣàfihàn ọgbọ́n rẹ̀ àti agbára rẹ̀ lórí àwọn ìṣẹ̀dá tó ṣeé fojú rí tó yí wa ká. (Nehemáyà 9:6; Sáàmù 24:1; 104:24; 136:5, 6) Kí èyí lè yé wa yékéyéké, ẹ jẹ́ ká wo kókó kan nínú ìwé Jóṣúà.
6, 7. (a) Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu wo ni Jèhófà ṣe nígbà ayé Mósè àti Jóṣúà? (b) Ká ní èyíkéyìí lára iṣẹ́ wọ̀nyẹn tó ṣẹlẹ̀ nígbà ayé Mósè àti Jóṣúà ṣojú rẹ ni, báwo ni ì bá ti rí lára rẹ?
6 Jèhófà mú àwọn ìyọnu bá Íjíbítì àtijọ́, ó sì pín Òkun Pupa níyà kí Mósè lè kó àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kúrò lóko ẹrú. (Ẹ́kísódù 7:1–14:31; Sáàmù 106:7, 21, 22) A tún ròyìn irú ìṣẹ̀lẹ̀ yẹn nínú Jóṣúà orí kẹta. Ńṣe ni Jóṣúà tó rọ́pò Mósè fẹ́ kó àwọn èèyàn Ọlọ́run sọdá odò kan pẹ̀lú, kí wọ́n lè wọ Ilẹ̀ Ìlérí. Jóṣúà sọ pé: “Ẹ sọ ara yín di mímọ́, nítorí ní ọ̀la, Jèhófà yóò ṣe àwọn ohun àgbàyanu láàárín yín.” (Jóṣúà 3:5) Àwọn ohun àgbàyanu wo nìyẹn?
7 Láìfa ọ̀rọ̀ gùn, ìtàn yẹn fi hàn pé Jèhófà tún mú kí ọ̀nà là gba inú odò kan, ìyẹn Odò Jọ́dánì, kí ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọkùnrin, obìnrin, àtàwọn ọmọdé lé gba orí ilẹ̀ gbígbẹ kọjá. (Jóṣúà 3:7-17) Ká ní a wà níbẹ̀ ni, tí odò náà pínyà níṣojú wa, tí gbogbo àwọn èèyàn yẹn sì sọdá wọ́ọ́rọ́wọ́, kò sí ni, àṣeyọrí yẹn ì bá yà wá lẹ́nu ṣáá ni! Ìṣẹ̀lẹ̀ ọ̀hún fi agbára tí Ọlọ́run ní lórí ìṣẹ̀dá hàn. Síbẹ̀, ní lọ́wọ́lọ́wọ́ yìí, àní nígbà ayé tiwa yìí, irú àwọn ohun ìyanu bẹ́ẹ̀ ń ṣẹlẹ̀. Láti lè mọ díẹ̀ lára àwọn nǹkan wọ̀nyẹn àti ìdí tó fi yẹ ká fiyè sí wọn, gbé Jóòbù 37:5-7 yẹ̀ wò.
8, 9. Àwọn iṣẹ́ àgbàyanu wo ni Jóòbù 37:5-7 tọ́ka sí, ṣùgbọ́n èé ṣe tó fi yẹ ká ronú nípa nǹkan wọ̀nyí?
8 Élíhù sọ pé: “Ọlọ́run ń fi ohùn rẹ̀ sán ààrá lọ́nà àgbàyanu, ó ń ṣe àwọn ohun ńlá tí a kò lè mọ̀.” Kí ni Élíhù ní lọ́kàn tó fi sọ pé Ọlọ́run ń ṣe àwọn nǹkan “lọ́nà àgbàyanu”? Élíhù mẹ́nu kan ìrì dídì àti eji wọwọ òjò. Ìwọ̀nyí máa ń jẹ́ kí àgbẹ̀ ṣíwọ́ iṣẹ́ lóko, kí ó lè ráyè ronú lórí àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run. Bí a kì í tilẹ̀ í ṣe àgbẹ̀, òjò àti ìrì dídì lè máa nípa lórí wa. Ìrì dídì àti òjò lè máa dá àwa náà dúró lẹ́nu iṣẹ́ wa, ó sinmi lórí ibi táa bá ń gbé ṣáá o. Ǹjẹ́ a tiẹ̀ máa ń sinmẹ̀dọ̀, ká ronú nípa ẹni tí ń bẹ nídìí àwọn ohun àrà wọ̀nyí àti ohun tí èyí túmọ̀ sí? Ǹjẹ́ o ti ṣe bẹ́ẹ̀ rí?
9 Ó yẹ fún àfiyèsí pé, Jèhófà Ọlọ́run fúnra rẹ̀ gbé irú èrò bẹ́ẹ̀ kalẹ̀ ní Jóòbù orí 38, bó ṣe ń bi Jóòbù ní àwọn ìbéèrè tó gbèrò. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jóòbù ni Ẹlẹ́dàá wa bi ní ìbéèrè wọ̀nyí, ó kan ìhùwàsí wa, ìgbésí ayé wa, àti ọjọ́ ọ̀la wa. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká gbọ́ àwọn ìbéèrè tí Ọlọ́run béèrè, ká sì ronú nípa àwọn ohun tó wé mọ́ ọn, àní sẹ́, ẹ jẹ́ ká ṣe ohun tí Jóòbù 37:14 rọ̀ wá láti ṣe.
10. Ipa wo ló yẹ kí Jóòbù orí 38 ní lórí wa, àwọn ìbéèrè wo ló sì gbé dìde?
10 Orí 38 bẹ̀rẹ̀ báyìí pé: “Jèhófà sì bẹ̀rẹ̀ sí dá Jóòbù lóhùn láti inú ìjì ẹlẹ́fùúùfù, ó sì wí pé: ‘Ta nìyí tí ń ṣú òkùnkùn bo ìmọ̀ràn nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ láìní ìmọ̀? Jọ̀wọ́, di abẹ́nú rẹ lámùrè bí abarapá ọkùnrin, sì jẹ́ kí n bi ọ́ léèrè, kí o sì sọ fún mi.’” (Jóòbù 38:1-3) Èyí ló nasẹ̀ àwọn ohun tó tẹ̀ lé e. Ó mú kí iyè Jóòbù sọ kìjí pé iwájú Ẹlẹ́dàá ọ̀run òun ayé, tí òun yóò jíhìn fún, lòun mà wà yìí. Àwa àtàwọn táa jọ ń gbé ayé lónìí pẹ̀lú lè fèyí kọ́gbọ́n. Ọlọ́run wá mẹ́nu ba irú àwọn nǹkan tí Élíhù ti mẹ́nu kàn ṣáájú. Ó ní: “Ibo ni ìwọ wà nígbà tí mo fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé sọlẹ̀? Sọ fún mi, bí o bá mòye. Ta ní fi ìwọ̀n rẹ̀ lélẹ̀, bí ó bá ṣẹlẹ̀ pé ìwọ mọ̀, tàbí ta ní na okùn ìdiwọ̀n sórí rẹ̀? Inú kí ni a ri ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀ sí, tàbí ta ní fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀?”—Jóòbù 38:4-6.
11. Ẹ̀kọ́ wo ló yẹ ká rí kọ́ nínú ohun tó wà nínú Jóòbù 38:4-6?
11 Ibo ni Jóòbù, tàbí èyíkéyìí lára wa pàápàá wà, nígbà dídá ilẹ̀ ayé? Ṣé àwa ni olùyàwòrán tó ya bí ilẹ̀ ayé ṣe máa rí, táa sì wá ti ara àwòrán yẹn bẹ̀rẹ̀ sí fi ohun táa lè pè ní ọ̀pá ìdíwọ̀n díwọ̀n igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ilẹ̀ ayé? Àwa kọ́! Kò tiẹ̀ tíì sí ohun tó ń jẹ́ ènìyàn nígbà yẹn. Ọlọ́run wá fi ayé wa wé ilé, ó sì béèrè pé: “Ta ní fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀?” A mọ̀ pé ọ̀gangan ibi tó yẹ kí ayé wà gẹ́lẹ́ ló wà, kò sún mọ́ oòrùn jù, bẹ́ẹ̀ ni kò jìnnà sí i jù, ìyẹn layé fi ṣeé gbé, táa sì ń gbá yìn-ìn nínú rẹ̀. Kò tóbi jù, bẹ́ẹ̀ ni kò kéré jù pẹ̀lú. Ká ní ilé ayé wa lọ tóbi ju báyìí lọ ni, afẹ́fẹ́ hydrogen kò ní lè fẹ́ jáde kúrò nínú àyíká ayé, ayé wa ò sì ní ṣeé gbé. Ó dájú pé ẹnì kan ló “fi òkúta igun rẹ̀ lélẹ̀” síbi tó tọ́. Ṣé Jóòbù ló ṣe é ni? Àbí àwa ni? Tàbí Jèhófà Ọlọ́run?— Òwe 3:19; Jeremáyà 10:12.
Èèyàn Wo Ló Lè Dáhùn?
12. Ìbéèrè inú Jóòbù 38:6 jẹ́ ká ronú nípa kí ni?
12 Ọlọ́run tún béèrè pé: “Inú kí ni a ri ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ rẹ̀ sí?” Gbankọgbì ìbéèrè nìyẹn o, àbí? Ó ṣeé ṣe kí a mọ ohun tí a ń pè ní òòfà, èyí tí Jóòbù kò mọ̀. Ọ̀pọ̀ jù lọ lára wa mọ̀ pé agbára òòfà tó ń wá láti ara oòrùn tó tóbi ràbàtà ló ń mú kí ayé wa má ṣeé ṣí nípò padà, bí ẹni pé ó dúró sán-ún lórí ìtẹ́lẹ̀ oníhò ìtẹ̀bọ̀ tó wọlẹ̀ ṣinṣin. Síbẹ̀, ta ni òye agbára òòfà yé yékéyéké?
13, 14. (a) Kí ni a gbọ́dọ̀ jẹ́wọ́ nípa òòfà? (b) Kí ló yẹ kó jẹ́ ìṣarasíhùwà wa sí ọ̀rọ̀ tó wà nínú Jóòbù 38:6?
13 Ìwé kan tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí, tí wọ́n pè ní The Universe Explained, gbà pé ‘nínú gbogbo ipá ìṣẹ̀dá, èyí táa ń rí jù lọ ni agbára òòfà, síbẹ̀ òun náà ló rú wa lójú jù lọ.’ Ìwé yìí fi kún un pé: “Ó dà bíi pé ká tó ṣẹ́jú pẹ́, agbára òòfà ti gba inú òfuurufú kọjá, láìsí ohun tó hàn nípa bó ṣe ń rìn ín. Àmọ́, lẹ́nu ọdún àìpẹ́ yìí, àwọn onímọ̀ físíìsì ti bẹ̀rẹ̀ sí dábàá pé ó ní láti jẹ́ àwọn ìgbì táa ń pè ní gravitons ló máa ń jẹ́ nígbà tó bá ń lọ . . . Ṣùgbọ́n, kò sẹ́ni tó lè fọwọ́ sọ̀yà pé ohun tó ń jẹ́ gravitons wà lóòótọ́.” Ẹ gba ọ̀rọ̀ yẹn yẹ̀ wò.
14 Ìtẹ̀síwájú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ti ń bá a bọ̀ fún ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọdún lẹ́yìn ìgbà tí Jèhófà ti bi Jóòbù ní ìbéèrè wọ̀nyẹn. Síbẹ̀síbẹ̀, àti àwa o, àtàwọn ògbógi nínú ìmọ̀ físíìsì ni o, kò tíì sẹ́ni tó lè ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa òòfà tó ń jẹ́ kí ayé wa lè wà lójú òpó tó ń tọ̀, kó sì wà ní ọ̀gangan ibi tó yẹ kó wà, ká lè máa gbádùn ìgbésí ayé wa níhìn-ín. (Jóòbù 26:7; Aísáyà 45:18) Pé a mẹ́nu kan ọ̀ràn nípa òòfà kò wá túmọ̀ sí pé a ní kí gbogbo wa lọ bẹ̀rẹ̀ sí wá ojútùú sí gbogbo ohun tó ta kókó nípa òòfà o. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni pípe àfiyèsí sí apá kan ṣoṣo yìí nínú àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run yẹ kó nípa lórí irú ojú táa fi ń wo Ọlọ́run. Ṣé ó fi kún ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ tóo ní fún ọgbọ́n àti ìmọ̀ rẹ̀, ṣé ó sì túbọ̀ jẹ́ kóo rí bó ṣe ṣe pàtàkì tó láti mọ̀ sí i nípa ohun tí ìfẹ́ rẹ̀ jẹ́?
15-17. (a) Kí ni Jóòbù 38:8-11 pe àfiyèsí sí, àwọn ìbéèrè wo ni èyí sì gbé dìde? (b) Kí ni a gbọ́dọ̀ gbà ní ti ìmọ̀ nípa òkun àti bí wọ́n ṣe wà ní ẹlẹ́kùnjẹkùn káàkiri ayé?
15 Ẹlẹ́dàá béèrè síwájú sí i pé: “Ta sì ni ó fi àwọn ilẹ̀kùn ṣe odi ìdènà òkun, èyí tí ó bẹ̀rẹ̀ sí jáde lọ bí ìgbà tí ó ya jáde láti inú ilé ọlẹ̀; nígbà tí mo fi àwọsánmà ṣe ẹ̀wù rẹ̀ àti ìṣúdùdù nínípọn ṣe ọ̀já ìwémọ rẹ̀, mo sì tẹ̀ síwájú láti fọ́ ìlànà mi sórí rẹ̀, mo sì ṣe ọ̀pá ìdábùú àti àwọn ilẹ̀kùn, mo sì ń bá a lọ láti sọ pé, ‘Ìhín yìí ni o lè dé mọ, má sì ṣe ré kọjá; ìhín yìí sì ni kí ìgbì rẹ tí ń ru gùdù mọ’?”—Jóòbù 38:8-11.
16 Fífi ilẹ̀kùn ṣe odi ìdènà òkun tí ibí yìí ń sọ, kan àwọn àgbáálá ilẹ̀, agbami òkun àti ìṣa òun ìyọ omi. Báwo ló ti pẹ́ tó tí àwọn èèyàn ti ń ṣàkíyèsí tí wọ́n sì ń ṣèwádìí nípa ìwọ̀nyí? Ó ti tó ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún, ìwádìí tí wọ́n ṣe ní ọ̀rúndún tó kọjá yìí sì kúrò ní kékeré. O lè máa ronú pé ní báyìí, àwọn èèyàn á ti mọ tìfuntẹ̀dọ̀ gbogbo ohun tó yẹ ní mímọ̀ nípa wọn. Àmọ́, ní ọdún 2001 táa wà yìí, tóo bá ṣèwádìí lórí kókó yìí nínú àwọn ibi ìkówèésí ńláńlá tàbí tóo lọ ń wá inú àwọn ìsọfúnni rẹpẹtẹ tó wà nínú Íńtánẹ́ẹ̀tì kí o lè rí àwọn ìsọfúnni tó dé gbẹ̀yìn, kí lo máa bá?
17 Nínú ọ̀kan lára ìwé ìṣèwádìí kan tí àwọn èèyàn ò kóyán ẹ̀ kéré, o lè rí i kà níbi tó ti gbà pé: “Ọ̀nà tí àwọn àgbáálá ilẹ̀ àti ìsàlẹ̀ agbami òkun gbà pín sí ẹlẹ́kùnjẹkùn káàkiri ayé àti bí àwọn òkè àti pẹ̀tẹ́lẹ̀ ṣe pín sí onírúurú kárí ayé, jẹ́ ara àwọn ìṣòro títa kókó tí àwọn onímọ̀ ìjìnlẹ̀ máa ń fẹ́ láti ṣèwádìí kí wọ́n sì gbé àbá kalẹ̀ nípa rẹ̀.” Lẹ́yìn tí ìwé gbédègbẹ́yọ̀ náà sọ èyí tán ló wá ṣe àlàyé oríṣi ọ̀nà mẹ́rin tó ṣeé ṣe kó jẹ́, àmọ́, ó ní ìwọ̀nyí jẹ́ “ara ọ̀pọ̀lọpọ̀ àbá tí àwọn èèyàn ti gbé kalẹ̀.” Ìwọ náà kúkú mọ̀ pé ọ̀rọ̀ náà àbá “sábàá máa ń fi hàn pé kò tíì sí ẹ̀rí tó kún tó láti lè fi ṣe àlàyé tó fẹsẹ̀ múlẹ̀.”
18. Kí ni ohun tóo kà nínú Jóòbù 38:8-11 wá mú kí o parí èrò sí?
18 Ǹjẹ́ ìyẹn kò jẹ́ kó túbọ̀ hàn pé àwọn ìbéèrè táa kà nínú Jóòbù 38:8-11 bá àkókò wa mu gan-an? Ní tòdodo, àwa kọ́ la ṣètò gbogbo bí ayé wa ṣe rí. Àwa kọ́ la gbé òṣùpá síbi tó wà yìí, kí òòfà rẹ̀ fi lè máa fa ìṣa àti ìyọ omi, èyí tí kì í sábà fa ìnira fún olúkúlùkù wa àti àyíká wa. O mọ̀ pé Olùṣe àwọn ohun àgbàyanu ló ṣe nǹkan wọ̀nyí.—Sáàmù 33:7; 89:9; Òwe 8:29; Ìṣe 4:24; Ìṣípayá 14:7.
Fún Jèhófà Ní Ìyìn Tó Yẹ Ẹ́
19. Àwọn ọ̀rọ̀ tó dún bí ewì, tó wà nínú Jóòbù 38:12-14, darí àfiyèsí wa sí àwọn nǹkan tó ṣeé fojú rí wo?
19 Ọmọ aráyé ò lè sọ pé àwọn làwọ́n mú kí ayé máa yí bíríbírí, gẹ́gẹ́ báa ti tọ́ka sí i nínú Jóòbù 38:12-14. Yíyí tí ilẹ̀ ayé sì ń yí bíríbírí yìí ló ń mú kí ọ̀yẹ̀ là, tí ẹwà rẹ̀ sì sábà máa ń fani mọ́ra gan-an ni. Bí oòrùn ṣe ń yọ ni ìrísí àwọn nǹkan tí ń bẹ nílé ayé wa túbọ̀ ń ṣe kedere sí i, bí ìgbà tí bátànì kan túbọ̀ ń hàn sí i. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé àkókò ráńpẹ́ la fi ń fiyè sí bí ayé ṣe ń yí bíríbírí, ìyàlẹ́nu ló máa ń jẹ́ fún wa pé ayé kò sáré àsápajúdé bó ṣe ń yí, àwa náà mọ̀ pé tó bá sáré jù, ó léwu. Bẹ́ẹ̀ sì ni yíyí rẹ̀ kò falẹ̀ jù débi pé ọ̀sán àti òru á wá gùn ju bó ṣe wà yìí, ìyẹn ì bá sì fa àpọ̀jù ooru àti òtútù tí èèyàn ò fi ní lè gbé inú ayé yìí. Ní tòdodo, ó yẹ ká dúpẹ́ pé Ọlọ́run ló díwọ̀n bí ayé yóò ṣe máa yí bíríbírí, pé kì í ṣe àwọn ọmọ aráyé kan ló kóra jọ pọ̀ ṣe é.—Sáàmù 148:1-5.
20. Báwo lo ṣe máa dáhùn àwọn ìbéèrè tó wà nínú Jóòbù 38:16, 18?
20 Wàyí o, fojú inú wò ó pé ìwọ ni Ọlọ́run wá ń bi ní ọ̀wọ́ àwọn ìbéèrè yìí síwájú sí i, pé: “Ìwọ ha ti rìnnà dé àwọn orísun òkun, tàbí ìwọ ha ti rìn káàkiri ní wíwá ibú omi ká?” Ẹni tó jẹ́ aṣèwádìí nípa òkun pàápàá ò mà lè fi gbogbo ara sọ pé bẹ́ẹ̀ ni o! “Ìwọ ha ti fi làákàyè ronú nípa àwọn àyè fífẹ̀ ilẹ̀ ayé? Sọ, bí ìwọ bá ti wá mọ gbogbo rẹ̀.” (Jóòbù 38:16, 18) Ǹjẹ́ o ti rin gbogbo ayé já, tàbí ǹjẹ́ o tiẹ̀ ti dé apá tó pọ̀ nínú rẹ̀? Táa bá ní ká máa ṣèbẹ̀wò sí àwọn ibi ẹlẹ́wà àti ibi ìyanu gbogbo lórí ilẹ̀ ayé, báwo ni iye ọdún tí yóò gbà wá láti fi ṣe ìyẹn yóò ṣe gùn tó? Ẹ sì wo bí ọdún wọ̀nyẹn yóò ṣe lárinrin tó!
21. (a) Àwọn ìbéèrè inú Jóòbù 38:19 lè múni ronú nípa àwọn kókó wo nínú ìmọ̀ ìjìnlẹ̀? (b) Kí ló yẹ kí àwọn ohun táa mọ̀ nípa ìmọ́lẹ̀ sún wa láti ṣe?
21 Tún wo àwọn gbankọgbì ìbéèrè tó wà nínú Jóòbù 38:19, ó kà pé: “Ibo wá ni ọ̀nà sí ibi tí ìmọ́lẹ̀ ń gbé? Ní ti òkùnkùn, ibo wá ni ipò rẹ̀ wà?” Ó ṣeé ṣe kóo mọ̀ pé, fún ìgbà pípẹ́ ni wọ́n fi gbà pé bí ìgbì ṣe máa ń bì, bẹ́ẹ̀ náà ni ìmọ́lẹ̀ máa ń bì, ìyẹn bí ojú omi ṣe máa ń bì síwá-sẹ́yìn. Àmọ́ lọ́dún 1905, Albert Einstein ṣàlàyé pé, ńṣe ni ìmọ́lẹ̀ máa ń ṣe bí ìdìpọ̀ tàbí àwọn egunrín ohun àmúṣagbára. Ṣé àlàyé yẹn yanjú ọ̀ràn náà? Ìwé gbédègbẹ́yọ̀ kan tó jáde lẹ́nu àìpẹ́ yìí béèrè pé: “Ṣé ìgbì ni ìmọ́lẹ̀ ni tàbí egunrín?” Ó dáhùn pé: “Ó jọ pé, [ìmọ́lẹ̀] kò lè jẹ́ méjèèjì, nítorí pé ohun méjèèjì yẹn [ìgbì àti egunrín] yàtọ̀ síra pátápátá. Ìdáhùn tó ti dára jù ni pé ìmọ́lẹ̀ kì í ṣe ìkankan nínú méjèèjì.” Síbẹ̀, ìmọ́lẹ̀ oòrùn ń bá a lọ láti mú ara wa móoru (ní tààràtà tàbí láìṣe tààràtà), bó tiẹ̀ jẹ́ pé kò tíì sẹ́ni tó lè ṣe ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé nípa iṣẹ́ Ọlọ́run yìí. Ìmọ́lẹ̀ oòrùn tí àwọn ewéko ń gbà sára tí wọ́n sì ń lò la fi ń rí oúnjẹ àti afẹ́fẹ́ ọ́síjìn gbà sára. A ń ríran kàwé, a lè rí ojú àwọn olólùfẹ́ wa, a lè rí bí oòrùn ṣe ń wọ̀ àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Bí a ṣe ń ṣe èyí, ǹjẹ́ kò yẹ ká mọyì àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run?—Sáàmù 104:1, 2; 145:5; Aísáyà 45:7; Jeremáyà 31:35.
22. Ojú wo ni Dáfídì ìgbàanì fi wo àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run?
22 Ṣé torí kí háà lè ṣe wá, kí itọ́ sì fẹ́rẹ̀ẹ́ máa já bọ́ lẹ́nu wa, la ṣe ń ṣàṣàrò lórí àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Jèhófà ni? Ó tì o. Dáfídì, onísáàmù ìgbàanì gbà pé kò ṣeé ṣe láti mọ kúlẹ̀kúlẹ̀ gbogbo iṣẹ́ Ọlọ́run, ká sì lè ròyìn gbogbo rẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ. Dáfídì kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣe, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, àní àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ . . . Ká ní mo fẹ́ máa wí, kí n sì máa sọ nípa wọn ni, wọ́n pọ̀ níye ju èyí tí mo lè máa ròyìn lẹ́sẹẹsẹ.” (Sáàmù 40:5) Àmọ́, ó dájú pé kì í ṣe ohun tó ń sọ ni pé òun kò ní sọ̀rọ̀ nípa iṣẹ́ àrà wọ̀nyí. Dáfídì fi èyí hàn gbangba nípasẹ̀ ìpinnu tó sọ jáde nínú Sáàmù 9:1, pé: “Ṣe ni èmi yóò máa fi gbogbo ọkàn-àyà mi gbé ọ lárugẹ, Jèhófà; èmi yóò máa polongo gbogbo iṣẹ́ àgbàyanu rẹ.”
23. Ojú wo lo fi ń wo àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run, báwo lo sì ṣe lè ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́?
23 Ṣé kò yẹ kí ó gbún àwa náà ní kẹ́sẹ́ ni? Ǹjẹ́ kò yẹ kí ìyàlẹ́nu tó ń dé bá wa nítorí àwọn iṣẹ́ àrà Ọlọ́run sún wa láti máa sọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run, nípa ohun tó ti ṣe, àti nípa àwọn ohun tó ṣì fẹ́ ṣe? Ìdáhùn náà ṣe kedere—ó yẹ ká “máa polongo ògo rẹ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ̀ láàárín gbogbo ènìyàn.” (Sáàmù 96:3-5) Dájúdájú, a lè fi hàn tìrẹ̀lẹ̀-tìrẹ̀lẹ̀ pé a mọrírì àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run nípa sísọ fáwọn ẹlòmíì nípa àwọn ohun táa ti kọ́ nípa rẹ̀. Àní ká tiẹ̀ sọ pé àwùjọ táwọn èèyàn ò ti gba Ẹlẹ́dàá gbọ́ ni wọ́n ti tọ́ wọn dàgbà, ọ̀rọ̀ tó mọ́gbọ́n dání, tí ń wọni lọ́kàn ṣinṣin táa bá ń bá wọn sọ lè wá jẹ́ kí wọ́n gbà pé Ọlọ́run wà. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó lè sún wọn kí àwọn náà fẹ́ kẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n sì wá sin ẹni tó “dá ohun gbogbo,” èyíinì ni Jèhófà, Olùṣe àwọn iṣẹ́ àgbàyanu.—Ìṣípayá 4:11.
Báwo Ni Wàá Ṣe Fèsì?
• Àwọn iṣẹ́ tí Ọlọ́run ṣe wo ni ọ̀rọ̀ ìyànjú tó wà nínú Jóòbù 37:14 ń mú kí o ronú nípa rẹ̀?
• Kí ni díẹ̀ lára àwọn ohun táa sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀ nínú Jóòbù orí 37 àti 38, tí àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kò tíì lè ṣàlàyé lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́?
• Ojú wo lo fi ń wo àwọn iṣẹ́ àgbàyanu Ọlọ́run, kí sì ni èyí ń sún ọ láti ṣe?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ta ló sé òkun mọ́, tí kò fi kọjá àyè rẹ̀?
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]
Ta ló ti lọ sí gbogbo ibi ẹlẹ́wà tí Ọlọ́run dá sáyé?