Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹgbẹ́ Tó Ń Bìkítà fún Ara Wọn Kárí Ayé

Ẹgbẹ́ Tó Ń Bìkítà fún Ara Wọn Kárí Ayé

Ẹgbẹ́ Tó Ń Bìkítà fún Ara Wọn Kárí Ayé

ÀWỌN èèyàn lọ bí ilẹ̀ bí ẹní. Ọ̀pọ̀ lára wọn ti darúgbó, àwọn kan lára wọn tiẹ̀ jẹ́ aláàbọ̀ ara tó jẹ́ pé agbára káká ni wọ́n fi ń rìn. Àwọn aboyún wà níbẹ̀ àtàwọn ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ tọkọtaya tí wọ́n láwọn ọmọ kéékèèké láti bójú tó. Olùwá-ibi-ìsádi ni gbogbo wọn—ìyẹn àwọn ọkùnrin, obìnrin, àtàwọn ọmọdé—tí ogun abẹ́lé, ìjábá, tàbí àwọn ipò mìíràn ti mú kí wọ́n sá kúrò ní ilé wọn láti wá ibi ìsádi lọ sí ọ̀kan lára àwọn orílẹ̀-èdè tí ń bẹ nítòsí wọn. Àwọn kan ti sá kúrò ní ibùgbé wọn láìmọye ìgbà. Nígbà tí wọ́n bá rí àmì pé ìjà ìgboro tàbí ìjábá kan fẹ́ ṣẹlẹ̀, wọ́n á mú díẹ̀ lára ohun ìní wọn, wọ́n á kó àwọn ọmọ wọn, wọ́n á sì forí lé ibi ààbò. Nígbà tí wọ́n bá sì rí i pé ipò nǹkan tún dára, ọ̀pọ̀ àwọn olùwá-ibi-ìsádi ló máa ń padà lọ tún ilé wọn kọ́, iyán á wá di àtúngún, ọbẹ̀ á sì di àtúnsè.

Láti àwọn ọdún wọ̀nyí wá ni Central African Republic ti ń gba àwọn olùwá-ibi-ìsádi tó wá láti àwọn orílẹ̀-èdè bíi mélòó kan mọ́ra. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn, títí kan ọ̀pọ̀ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló di dandan fún láti fi Orílẹ̀-èdè Olómìnira ti Kóńgò tí ogun ti fàya pẹ́rẹpẹ̀rẹ sílẹ̀, lọ sí ibi tí ààbò díẹ̀ wà ní Central African Republic.

Àwọn Ará Ràn Wọ́n Lọ́wọ́

Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ní Central African Republic gbà pé àǹfààní ńlá ló jẹ́ fáwọn láti ṣètò ìrànlọ́wọ́ fáwọn tó níṣòro. Wọ́n ṣètò ilé fáwọn Kristẹni arákùnrin tó ń dé. Wọ́n kọ́kọ́ wá yàrá sí àwọn ilé àdáni, àmọ́ bí iye àwọn olùwá-ibi-ìsádi náà ti ń pọ̀ sí i, ó wá hàn kedere pé wọ́n ní láti ṣètò tó túbọ̀ ṣe gúnmọ́. Wọ́n sọ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba kan di ilé gbígbé. Àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò fi gbogbo ara ṣiṣẹ́, wọ́n fa iná kún èyí tó wà níbẹ̀ tẹ́lẹ̀, wọ́n fa páìpù omi wá síbẹ̀, wọ́n sì rẹ́ ilẹ̀ ibẹ̀ kó lè rọrùn fáwọn tó máa gbébẹ̀. Ńṣe làwọn olùwá-ibi-ìsádi náà ń ṣiṣẹ́ ní ìfẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹ̀lú àwọn arákùnrin tó wà ládùúgbò náà kí iṣẹ́ lè parí lórí àwọn ilé gbígbé fúngbà díẹ̀ ọ̀hún. Wọ́n ṣètò ìtòlẹ́sẹẹsẹ gbogbo àwọn ìpàdé Kristẹni ní èdè Lingala kí àwọn tó ń dé náà lè rí oúnjẹ tẹ̀mí tí ń gbẹ́mìí ró jẹ. Ìfọwọ́sowọ́pọ̀ tó wà láàárín àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà ládùúgbò náà àtàwọn àlejò wọn fi hàn pé ẹgbẹ́ àwọn ará kárí ayé wà ní ti gidi.

Àwọn ìdílé àwọn olùwá-ibi-ìsádi ọ̀hún kì í sábà dé lẹ́ẹ̀kan náà. Lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, wọ́n máa ń dé ibi tí wọ́n ń lọ kí àwọn mẹ́ńbà ìdílé tó ti fọ́n ká tó lè wà pa pọ̀. Wọ́n máa ń to orúkọ àwọn tó ti gúnlẹ̀ láyọ̀ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba kọ̀ọ̀kan. Wọ́n ṣètò bí wọ́n ṣe máa wá àwọn tó sọnù rí. Ọkọ̀ mẹ́ta ni ẹ̀ka ilé iṣẹ́ tó ń bójú tó iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lórílẹ̀-èdè náà máa ń rán jáde lójoojúmọ́ láti ran àwọn Ẹlẹ́rìí tó ṣì wà lọ́nà lọ́wọ́, àti láti wá ẹnikẹ́ni tó bá sọnù lára wọn rí. Àkọlé gàdàgbà tó kà pé, “WATCHTOWER—Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà” ni wọ́n fi ń dá àwọn ọkọ̀ náà mọ̀.

Fojú inú wo bí àwọn ọmọ kéékèèké méje tí wọ́n jẹ́ olùwá-ibi-ìsádi, tí wọ́n sì ti pínyà kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn, ṣe láyọ̀ tó nígbà tí wọ́n rí ọkọ̀ kan tó jẹ́ ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Kíá ni wọ́n sáré lọ sídìí ọkọ̀ náà, tí wọ́n sì sọ pé Ẹlẹ́rìí làwọn. Àwọn ará kó wọn sínú ọkọ̀ náà, wọ́n sì kó wọn wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba kan, níbi tí wọ́n ti wá dara pọ̀ mọ́ àwọn ìdílé wọn níkẹyìn.

Kí ló ran àwọn Kristẹni olóòótọ́ wọ̀nyí lọ́wọ́ láti kojú àwọn ipò wọ̀nyí, tí kì í ṣe ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo, àmọ́ tó jẹ́ léraléra? Ó dá wọn lójú hán-únhán-ún pé àwọn ọjọ́ ìkẹyìn là ń gbé gẹ́gẹ́ bí Ìwé Mímọ́ ti sọ tẹ́lẹ̀.—2 Tímótì 3:1-5; Ìṣípayá 6:3-8.

Nítorí ìdí èyí, wọ́n mọ̀ pé Jèhófà Ọlọ́run yóò fòpin sí ogun, ìkórìíra, ìwà ipá àti gbọ́nmi-si omi-ò-to láìpẹ́. Ìṣòro àwọn olùwá-ibi-ìsádi yóò di ohun àtijọ́. Ní báyìí ná, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ ìyànjú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù nínú 1 Kọ́ríńtì 12:14-26, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń tiraka láti ṣaájò ara wọn. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé odò, ààlà orílẹ̀-èdè, àti ọ̀nà jíjìn pín wọ́n níyà, síbẹ̀ wọ́n bìkítà nípa ara wọn, ìdí nìyẹn tí wọ́n fi máa ń gbégbèésẹ̀ kíákíá nígbà tí ẹnì kan bá ń fẹ́ ìrànlọ́wọ́.—Jákọ́bù 1:22-27.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 30]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÁFÍRÍKÀ

Central African Republic

Orílẹ̀-Èdè Olómìnira ti Kóńgò

[Credit Line]

Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Gbọ̀ngàn Ìjọba mẹ́ta ni wọ́n sọ di ibùdó ìgbàlejò

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ojú ẹsẹ̀ ni wọ́n ṣe àwọn ilé ìdáná

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Àwọn púpọ̀ sí i tún ń dé

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Àwọn ọmọ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bí, tí wọ́n sì ti di olùwá-ibi-ìsádi