Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bí A Ṣe Lè Borí Èrò Òdì

Bí A Ṣe Lè Borí Èrò Òdì

Bí A Ṣe Lè Borí Èrò Òdì

● Ásáfù ṣàròyé pé: “Dájúdájú, lásán ni mo wẹ ọkàn-àyà mi mọ́, tí mo sì wẹ ọwọ́ mi ní àìmọwọ́mẹsẹ̀. Ìyọnu sì ń bá mi láti òwúrọ̀ ṣúlẹ̀, mo sì ń gba ìbáwí àfitọ́nisọ́nà ní òròòwúrọ̀.”—Sáàmù 73:13, 14.

● Bárúkù kérora pé: “Mo gbé wàyí, nítorí pé Jèhófà ti fi ẹ̀dùn-ọkàn kún ìrora mi! Agara ti dá mi nítorí ìmí ẹ̀dùn mi, èmi kò sì rí ibi ìsinmi kankan.”—Jeremáyà 45:3.

● Náómì kédàárò pé: “Olódùmarè ti mú kí ó korò gan-an fún mi. Mo kún nígbà tí mo lọ, ní ọwọ́ òfo sì ni Jèhófà mú kí n padà. Èé ṣe tí ẹ̀yin yóò fi máa pè mí ní Náómì, nígbà tí ó jẹ́ pé Jèhófà ni ó tẹ́ mi lógo, Olódùmarè ni ó sì mú ìyọnu àjálù bá mi?”—Rúùtù 1:20, 21.

BÍBÉLÌ kún fún onírúurú àpẹẹrẹ àwọn olóòótọ́ olùjọsìn Jèhófà tí ìrẹ̀wẹ̀sì ti fìgbà kan dorí wọn kodò. Òkodoro òtítọ́ ibẹ̀ ni pé, gẹ́gẹ́ bí ènìyàn aláìpé, gbogbo wa ló máa ń ní irú ìmọ̀lára bẹ́ẹ̀ lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan. Àwọn kan lára wa máa ń ní ìrẹ̀wẹ̀sì ju àwọn mìíràn lọ—bóyá kí wọ́n tiẹ̀ máa káàánú ara wọn pàápàá—nítorí àwọn ìrírí bíbani nínú jẹ́ tí wọ́n ti ní.

Àmọ́, tí a kò bá ṣàkóso rẹ̀, irú ìrẹ̀wẹ̀sì bẹ́ẹ̀ lè ba àjọṣe wa pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn àti Jèhófà Ọlọ́run jẹ́. Kristẹni obìnrin kan tó máa ń káàánú ara rẹ̀ sọ pé: “Mo ti kọ ọ̀pọ̀ ìkésíni síbi àpèjẹ sílẹ̀ nítorí mo rò pé mi ò yẹ lẹ́ni tí àwọn tó wà nínú ìjọ ń bá kẹ́gbẹ́.” Ẹ wo ipa bíbani nínú jẹ́ tí irú èrò bẹ́ẹ̀ lè ní lórí ìgbésí ayé ẹnì kan! Kí lo lè ṣe láti borí rẹ̀?

Sún Mọ́ Jèhófà

Nínú Sáàmù kẹtàléláàádọ́rin, Ásáfù fi òtítọ́ inú kọ̀wé nípa ìdààmú tó dé bá a. Nígbà tó fi bí nǹkan ṣe rí fún òun wé ti àwọn ẹni ibi tó ń gbé ìgbésí ayé tó rọ̀ṣọ̀mù, ó bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìlara wọn. Ó rí i pé àwọn aláìnáání Ọlọ́run ń gbéra ga, wọ́n ń hu ìwà ipá, ó sì jọ pé àṣegbé ni wọ́n ń ṣe é. Ásáfù wá ń ṣiyèméjì nípa títọ̀ tí òun ń tọ ipa ọ̀nà ìdúróṣánṣán nínú ìgbésí ayé òun.—Sáàmù 73:3-9, 13, 14.

Bíi ti Ásáfù, ǹjẹ́ o ti kíyè sí bó ṣe jọ pé àwọn ẹni ibi, tí wọ́n ń fi ìwà àìtọ́ wọn ṣe fọ́rífọ́rí, ń kẹ́sẹ járí? Báwo ni Ásáfù ṣe borí èrò òdì tó ní? Ó ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Mo sì ń gbèrò ṣáá láti mọ èyí; ó jẹ́ ìdààmú ní ojú mi, títí mo fi wá sínú ibùjọsìn títóbi lọ́lá ti Ọlọ́run. Mo fẹ́ láti fi òye mọ ọjọ́ ọ̀la wọn.” (Sáàmù 73:16, 17) Ásáfù gbé ìgbésẹ̀ tó dára nípa yíyíjú sí Jèhófà nínú àdúrà. Táa bá sọ ọ́ lọ́nà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gbà sọ ọ́ lẹ́yìn náà, Ásáfù tẹ “ènìyàn ti ara” rì nípa jíjí “ènìyàn ti ẹ̀mí” tó wà nínú rẹ̀. Pẹ̀lú àkọ̀tun èrò tẹ̀mí tó wá ní, ó lóye pé Jèhófà kórìíra ìwà búburú àti pé láìpẹ́ àwọn ẹni ibi yóò jìyà.—1 Kọ́ríńtì 2:14, 15.

O ò rí i bó ti ṣe pàtàkì tó pé kí o jẹ́ kí Bíbélì ràn ọ́ lọ́wọ́, kí o lè ní èrò tó tọ́ nínú ìgbésí ayé! Jèhófà rán wa létí pé òun rí ohun tí àwọn ẹni ibi ń ṣe. Bíbélì kọ́ni pé: “Ẹ má ṣe jẹ́ kí a ṣì yín lọ́nà: Ọlọ́run kì í ṣe ẹni tí a lè fi ṣe ẹlẹ́yà. Nítorí ohun yòówù tí ènìyàn bá ń fúnrúgbìn, èyí ni yóò ká pẹ̀lú . . . Nítorí náà, ẹ má ṣe jẹ́ kí a juwọ́ sílẹ̀ ní ṣíṣe ohun tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀.” (Gálátíà 6:7-9) Jèhófà yóò gbé àwọn ẹni ibi lé “orí ilẹ̀ yíyọ̀bọ̀rọ́”; yóò jẹ́ kí wọ́n “ṣubú ní rírún wómúwómú.” (Sáàmù 73:18) Ìdájọ́ Ọlọ́run ni yóò máa borí ṣáá níkẹyìn.

Jíjẹ oúnjẹ tẹ̀mí déédéé lórí tábìlì Jèhófà àti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tó gbámúṣé pẹ̀lú àwọn èèyàn Ọlọ́run yóò ràn ọ́ lọ́wọ́ láti fún ìgbàgbọ́ rẹ lókun, àti láti borí ìrẹ̀wẹ̀sì tàbí àwọn èrò òdì mìíràn. (Hébérù 10:25) Bíi ti Ásáfù, nípa sísún mọ́ Ọlọ́run pẹ́kípẹ́kí, o lè rí ìtìlẹ́yìn onífẹ̀ẹ́ gbà lọ́dọ̀ rẹ̀. Ásáfù ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ, ó ní: “Èmi wà pẹ̀lú rẹ nígbà gbogbo; ìwọ ti di ọwọ́ ọ̀tún mi mú. Ìmọ̀ràn rẹ ni ìwọ yóò fi ṣamọ̀nà mi, lẹ́yìn ìgbà náà, ìwọ yóò sì mú mi wọnú ògo pàápàá.” (Sáàmù 73:23, 24) Kristẹni kan tí wọ́n bá ṣèṣekúṣe nígbà tó wà lọ́mọdé rí i pé ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ni ọ̀rọ̀ yìí. Ó ní: “Níní ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tímọ́tímọ́ pẹ̀lú ìjọ jẹ́ kí n tún rí ìgbésí ayé lọ́nà mìíràn. Mo wá rí i kedere pé àwọn Kristẹni alàgbà jẹ́ onífẹ̀ẹ́, pé wọn kì í ṣe ọlọ́pàá bí kò ṣe olùṣọ́ àgùntàn.” Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn Kristẹni alàgbà tí í ṣe oníyọ̀ọ́nú ń kó ipa pàtàkì nínú mímú àwọn èrò òdì tí ń pani lára kúrò.—Aísáyà 32:1, 2; 1 Tẹsalóníkà 2:7, 8.

Tẹ́wọ́ Gba Ìmọ̀ràn Jèhófà

Bárúkù, akọ̀wé Jeremáyà wòlíì, banú jẹ́ nítorí másùnmáwo ti iṣẹ́ rẹ ń fún un. Àmọ́, Jèhófà fi tìfẹ́tìfẹ́ darí àfiyèsí Bárúkù sí ohun tó jẹ́ ìṣòro rẹ̀ gan-an. “‘Ní tìrẹ, ìwọ ń wá àwọn ohun ńláńlá fún ara rẹ. Má ṣe wá wọn mọ́. Nítorí kíyè sí i, èmi yóò mú ìyọnu àjálù wá sórí gbogbo ẹran ara,’ ni àsọjáde Jèhófà, ‘èmi yóò sì fi ọkàn rẹ fún ọ bí ohun ìfiṣèjẹ ní gbogbo ibi tí ìwọ bá lọ.’”—Jeremáyà 45:2-5.

Láìfọ̀rọ̀ bọpobọyọ̀, Jèhófà ṣàlàyé pé ẹ̀mí ìmọtara ẹni nìkan Bárúkù ni ohun tó fa ìrẹ̀wẹ̀sì fún un. Kò sí bí Bárúkù ṣe lè láyọ̀ nínú iṣẹ́ tí Ọlọ́run yàn fún un tó bá ń wá ohun ńláńlá fún ara rẹ̀ lẹ́sẹ̀ kan náà. Ìwọ náà lè rí i pé ìgbésẹ̀ tó gbéṣẹ́ jù lọ láti borí ìrẹ̀wẹ̀sì ni pé kéèyàn yẹra fún ìpínyà ọkàn, kí ó sì fara mọ́ ìbàlẹ̀ ọkàn tó ń wá látinú ìtẹ́lọ́rùn tí Ọlọ́run ń fi fúnni.—Fílípì 4:6, 7.

Náómì tó jẹ́ opó kò jẹ́ kí ìrora ọkàn sọ òun di akúrẹtẹ̀ ní Móábù nígbà tí ọkọ rẹ̀ àti àwọn ọmọ rẹ̀ méjèèjì kú. Àmọ́ ṣá o, àmì fi hàn pé ó banú jẹ́ gan-an láwọn àkókò kan nítorí ọ̀ràn ara rẹ̀ àtàwọn aya ọmọ rẹ̀ méjèèjì. Nígbà tí Náómì ń dágbére fún wọn, ó ní: “Ó korò gan-an fún mi nítorí tiyín, pé ọwọ́ Jèhófà jáde lòdì sí mi.” Nígbà tó tún dé Bẹ́tílẹ́hẹ́mù, ó kọ̀ jálẹ̀ pé: “Ẹ má pè mí ní Náómì [“Adùn mi”]. Márà [“Ìkorò”] ni kí ẹ máa pè mí, nítorí Olódùmarè ti mú kí ó korò gan-an fún mi.”—Rúùtù 1:13, 20.

Àmọ́, Náómì kò wá bẹ̀rẹ̀ sí í ká gúọ́gúọ́ sínú ilé níbi tó ti ń ṣọ̀fọ̀—kí ó wá jìnnà sí Jèhófà àtàwọn èèyàn rẹ̀. Móábù ló ti gbọ́ pé “Jèhófà ti yí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn ènìyàn rẹ̀ nípa fífún wọn ní oúnjẹ.” (Rúùtù 1:6) Ó mọ̀ pé ibi tó dára jù lọ kí òun wà ni ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn Jèhófà. Náómì àti Rúùtù, aya ọmọ rẹ̀, padà sí Júdà níkẹyìn, ó sì fọgbọ́n tọ́ Rúùtù sọ́nà tí yóò gbà hùwà sí Bóásì, ìbátan wọn, tó jẹ́ olùràpadà rẹ̀.

Bákan náà ni lónìí, àwọn adúróṣinṣin tí ọkọ tàbí aya wọn ti kú ń borí másùnmáwo nípa mímú kí ọwọ́ wọn dí nínú ìjọ Kristẹni. Bíi ti Náómì, wọn ò fi nǹkan tẹ̀mí ṣeré rárá, ojoojúmọ́ ni wọ́n ń ka Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

Àwọn Àǹfààní Látinú Fífi Ọgbọ́n Ọlọ́run Sílò

Àwọn ìtàn inú Bíbélì wọ̀nyí jẹ́ ká lóye bí ẹnì kan ṣe lè kojú ohun tí èrò òdì ń dá sílẹ̀. Ásáfù wá ìrànlọ́wọ́ lọ sínú ibùjọsìn Jèhófà, ó sì fi sùúrù dúró de Jèhófà. Bárúkù tẹ́wọ́ gba ìmọ̀ràn, ó sì yẹra fún ìfẹ́ ọrọ̀ àlùmọ́ọ́nì tó ń pín ọkàn níyà. Náómì forí ṣe ó fọrùn ṣe láàárín àwọn èèyàn Jèhófà, ó múra ọmọbìnrin náà, Rúùtù sílẹ̀ de àwọn àǹfààní rẹ̀ nínú jíjọ́sìn Ọlọ́run òtítọ́.—1 Kọ́ríńtì 4:7; Gálátíà 5:26; 6:4.

O lè borí ìrẹ̀wẹ̀sì àtàwọn èrò òdì mìíràn nípa ríronú lórí àwọn ìṣẹ́gun àtọ̀runwá tí Jèhófà ti fún àwọn èèyàn rẹ̀, yálà lẹ́nì kọ̀ọ̀kan tàbí lápapọ̀. Láti ṣe èyí, máa ṣàṣàrò lórí ìfẹ́ gíga jù lọ tí Jèhófà fi hàn, èyíinì ni ìràpadà tí ó pèsè fún ọ. Mọrírì ojúlówó ìfẹ́ tí ń bẹ láàárín ẹgbẹ́ àwọn ará ti Kristẹni. Jẹ́ kí gbígbé nínú ayé tuntun Ọlọ́run tó ti dé tán yìí wà ní góńgó ẹ̀mí rẹ. Ǹjẹ́ kí ìwọ náà fèsì bíi ti Ásáfù pé: “Ní tèmi, sísúnmọ́ Ọlọ́run dára fún mi. Jèhófà Olúwa Ọba Aláṣẹ ni mo fi ṣe ibi ìsádi mi, láti máa polongo gbogbo iṣẹ́ rẹ.”—Sáàmù 73:28.