Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ewu Tó Dojú Kọ Ìlera Gbogbo Ènìyàn”

“Ewu Tó Dojú Kọ Ìlera Gbogbo Ènìyàn”

“Ewu Tó Dojú Kọ Ìlera Gbogbo Ènìyàn”

ÌYÀLẸ́NU ńlá ló jẹ́ pé ìdámẹ́ta lára àwọn àgbà tó ń lo kọ̀ǹpútà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ló ti lọ ṣí àwọn apá bíi mélòó kan tí ọ̀rọ̀ nípa ìbálòpọ̀ wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì, ohun tí ìwádìí kan tí wọ́n ṣe lẹ́nu àìpẹ́ yìí nípa ọ̀ràn ìbálòpọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì fi hàn nìyẹn. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló ti wá ń tẹ́ ìfẹ́ ìbálòpọ̀ wọn lọ́rùn báyìí nípasẹ̀ Íńtánẹ́ẹ̀tì. Dókítà Al Cooper, afìṣemọ̀rònú, tó ṣe ìwádìí náà, sọ pé: “Ewu tó dojú kọ ìlera gbogbo ènìyàn nìyí, nítorí pé àwọn díẹ̀ kéréje ló mọ̀ pé ewu ni, tàbí tí wọ́n kà á sí bàbàrà.”

Àwọn wo ló tètè ń kó sínú irú ewu ìbálòpọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì bẹ́ẹ̀? Dókítà Cooper sọ pé: “Àwọn tí wọ́n ti kára wọn lọ́wọ́ kò lórí ọ̀ràn ìbálòpọ̀ ní gbogbo ìgbésí ayé wọn, tí wọn ò sì kúndùn rẹ̀” àmọ́ tí wọ́n “wá ṣàdédé rí àìmọye àǹfààní láti máa wo ìbálòpọ̀” lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ni.

Àmọ́, ọ̀pọ̀ jù lọ lára àwọn tó máa ń lọ síbi tí ìsọfúnni nípa ìbálòpọ̀ wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì ló gbà pé irú àṣà bẹ́ẹ̀ kò lè pani lára. Ṣé bẹ́ẹ̀ ni? Gan-an gẹ́gẹ́ bí ara ajoògùnyó kì í ti í kọ oògùn líle tó ti di bára kú fún un, bẹ́ẹ̀ náà ni ọ̀pọ̀ lára àwọn tí ìbálòpọ̀ orí Íńtánẹ́ẹ̀tì ti di bára kú fún ṣe máa ń wá bí àwọn ṣe máa fi kún “iye” ìbálòpọ̀ tí wọ́n ń wò lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì kí wọ́n lè tẹ́ ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ wọn lọ́rùn. Àní, wọ́n tiẹ̀ lè pàdánù iṣẹ́ wọn, kí wọ́n sì fi àjọṣe wọn pẹ̀lú aya tàbí ọkọ wọn sínú ewu!

Àmọ́ ṣá o, àwọn tó fẹ́ múnú Ọlọ́run dùn tún nídìí mìíràn tó fi yẹ kí wọ́n yẹra fún ṣíṣí àwọn ibi tí àwòrán ìbálòpọ̀ wà lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ṣíni létí pé: “Nítorí náà, ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti àgbèrè, ìwà àìmọ́, ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo, ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà. Ní tìtorí nǹkan wọnnì ni ìrunú Ọlọ́run fi ń bọ̀.” (Kólósè 3:5, 6) Kí ẹnì kan tó lè ‘sọ àwọn ẹ̀yà ara rẹ̀ di òkú’ lórí ọ̀ràn ìdálọ́rùn fún ìbálòpọ̀ takọtabo oníwà àìmọ́, ó ní láti ní ìfẹ́ tó lágbára fún Jèhófà Ọlọ́run. (Sáàmù 97:10) Bí ẹnì kan bá rí i pé ìran ìbálòpọ̀ lórí Íńtánẹ́ẹ̀tì tó jẹ́ ewu fún ìlera gbogbo ènìyàn fẹ́ dẹkùn mú òun, ó yẹ kí ó mú kí ìfẹ́ tóun ní fún Jèhófà túbọ̀ lágbára sí i nípa kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ gbígbámúṣé pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Gbọ̀ngàn Ìjọba tó wà ládùúgbò lè ṣèrànwọ́ púpọ̀ fún ẹnì kan láti ṣe ìpinnu aláìyẹsẹ̀ pé òun yóò máa ṣe ohun tó múnú Ọlọ́run dùn.