Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbẹ́mìílò àti Wíwá Ipò Tẹ̀mí Tòótọ́ Kiri

Ìbẹ́mìílò àti Wíwá Ipò Tẹ̀mí Tòótọ́ Kiri

Ìbẹ́mìílò àti Wíwá Ipò Tẹ̀mí Tòótọ́ Kiri

GBOGBO wa la ní àwọn àìní nípa tẹ̀mí àti nípa tara. Ìdí nìyẹn tí ọ̀pọ̀ èèyàn fi ń béèrè àwọn ìbéèrè bíi, Kí ni ète ìgbésí ayé, èé sì ti ṣe táwọn èèyàn fi ń jìyà, àti pé kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà tí a bá kú? Ọ̀pọ̀ olóòótọ́ èèyàn ló ń wá ìdáhùn sí ìbéèrè wọ̀nyí àti àwọn ìbéèrè mìíràn tó fara pẹ́ ẹ lọ́dọ̀ àwọn adáhunṣe níbi tí wọ́n ti ń kàn sí àwọn ẹ̀mí àìrí, ní ìrètí pé àwọn ń bá ẹ̀mí àwọn òkú sọ̀rọ̀. Àṣà yìí ni wọ́n ń pè ní ìbẹ́mìílò.

Àwọn tó ń lọ́wọ́ nínú ìbẹ́mìílò wà ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè, wọ́n sì máa ń kóra wọn jọ sínú àwọn ìjọ àtàwọn ṣọ́ọ̀ṣì. Fún àpẹẹrẹ, ní Brazil, ó tó mílíọ̀nù mẹ́rin àwọn abẹ́mìílò tí wọ́n ń tẹ̀ lé àdììtú ẹ̀kọ́ Hyppolyte Léon Denizard Rivail, ọmọ ilẹ̀ Faransé kan tó jẹ́ olùkọ́ni àti onímọ̀ ọgbọ́n orí tó fi orúkọ Allan Kardec kọ̀wé ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún. Ọdún1854 ni Kardec kọ́kọ́ di ẹni tó nífẹ̀ẹ́ sí àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mérìíyìírí tó ń tinú ìbẹ́mìílò jáde. Ó wá ń béèrè ìbéèrè lọ́wọ́ àwọn adáhunṣe tí wọ́n wà ní ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀, ó sì kọ àwọn ìdáhùn tó rí gbà sínú ìwé The Book of Spirits tí wọ́n tẹ̀ jáde ní ọdún 1857. Àwọn ìwé méjì mìíràn tó kọ ni The Mediums’ Book àti The Gospel According to Spiritism.

Ara ohun tí ìbẹ́mìílò wé mọ́ ni àwọn àṣà ìsìn bíi fúdù, iṣẹ́ àjẹ́, idán pípa, tàbí ìjọsìn Sátánì. Àmọ́, àwọn tó ń tẹ̀ lé ẹ̀kọ́ Allan Kardec sọ pé ìgbàgbọ́ tiwọn yàtọ̀. Àwọn ìtẹ̀jáde wọn sábà máa ń ṣàyọlò ọ̀rọ̀ inú Bíbélì, wọ́n sì máa ń tọ́ka sí Jésù gẹ́gẹ́ bí “amọ̀nà àti àpẹẹrẹ fún gbogbo ènìyàn.” Wọ́n ní ẹ̀kọ́ Jésù ló “gbé òfin àtọ̀runwá jáde lọ́nà tí ó dára jù lọ.” Allan Kardec wo ìwé àwọn abẹ́mìílò bí ọ̀nà kẹta tí Ọlọ́run gbà ṣí òfin rẹ̀ payá fún ìran ènìyàn, àwọn ọ̀nà méjì tó ṣáájú ni ẹ̀kọ́ Mósè àti ti Jésù.

Ọ̀pọ̀ èèyàn ló nífẹ̀ẹ́ sí ìbẹ́mìílò nítorí wọ́n sọ pé ó ń gbé ìfẹ́ aládùúgbò àti iṣẹ́ àánú lárugẹ. Ọ̀kan lára ìgbàgbọ́ àwọn abẹ́mìílò ni pé: “Láìsí ọrẹ àánú, kò sí ìgbàlà.” Ọ̀pọ̀ àwọn abẹ́mìílò ló jẹ́ ògbóṣáṣá nínú iṣẹ́ afẹ́nifẹ́re, nínú dídá ilé ìwòsàn, ilé ìwé àti àwọn àjọ mìíràn sílẹ̀. Àwọn ìsapá wọ̀nyẹn dára gan-an ni. Àmọ́ ṣá o, báwo ni ìgbàgbọ́ àwọn abẹ́mìílò ṣe rí ní ìfiwéra pẹ̀lú ẹ̀kọ́ Jésù bí a ṣe kọ ọ́ sínú Bíbélì? Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn àpẹẹrẹ méjì yẹ̀ wò: ìrètí tó wà fún àwọn òkú àti ìdí táwọn èèyàn fi ń jìyà.

Ìrètí Wo Ló Wà fún Àwọn Òkú?

Ọ̀pọ̀ lára àwọn abẹ́mìílò ló gba àtúnwáyé gbọ́. Ìwé àwọn abẹ́mìílò kan sọ pé: “Àtúnwáyé nìkan ni ẹ̀kọ́ tó kúnjú ìwọ̀n èrò táa ní nípa ìdájọ́ Ọlọ́run; òun nìkan ni ẹ̀kọ́ tó lè ṣàlàyé ọjọ́ iwájú fúnni, tó sì lè fún ìrètí wa lókun.” Àwọn abẹ́mìílò ṣàlàyé pé nígbà táwọn èèyàn bá kú, “wọ́n á di ẹ̀dá ẹ̀mí” tí yóò máa wà láàyè nìṣó láìsí ara. Wọ́n gbà gbọ́ pé àwọn ẹ̀mí wọ̀nyí yóò wá padà wá sáyé bí ènìyàn kí wọ́n lè ṣe ìwẹ̀nùmọ́ gbogbo ẹ̀ṣẹ̀ tí wọ́n dá nígbà tí wọ́n kọ́kọ́ wá sáyé. Àmọ́ kò sí bí wọ́n ṣe fẹ́ rántí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ àkọ́kọ́ wọ̀nyẹn. Ìwé The Gospel According to Spiritism sọ pé: “Ọlọ́run gbà pé ohun tó bójú mu ni láti gbójú fo ohun tó ti kọjá.”

Allan Kardec kọ̀wé pé: “Tẹ́nì kan bá sọ pé òun ò gbà pé àtúnwáyé wà, a jẹ́ pé onítọ̀hún ò gba ọ̀rọ̀ Kristi gbọ́ nìyẹn.” Àmọ́, Jésù kò sọ ọ̀rọ̀ náà “àtúnwáyé” rí, kò sí mẹ́nu kan irú èrò yẹn rí. (Wo “Bíbélì Ha Fi Àtúnwáyé Kọ́ni Bí?” ojú ìwé 22.) Dípò ìyẹn, àjíǹde àwọn òkú ni Jésù fi kọ́ni. Àwọn èèyàn mẹ́ta ló jí dìde nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé—àwọn ni ọmọkùnrin opó Náínì, ọmọbìnrin alága sínágọ́gù, àti Lásárù tó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́. (Máàkù 5:22-24, 35-43; Lúùkù 7:11-15; Jòhánù 11:1-44) Ẹ jẹ́ kí a gbé ọ̀kan lára àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé wọ̀nyẹn yẹ̀ wò, ká sì rí ohun tí Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa “àjíǹde.”

Àjíǹde Lásárù

Jésù gbọ́ pé ọ̀rẹ́ rẹ̀ Lásárù ń ṣàìsàn. Ọjọ́ méjì lẹ́yìn náà, ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Lásárù ọ̀rẹ́ wa ti lọ sinmi, ṣùgbọ́n mo ń rìnrìn àjò lọ sí ibẹ̀ láti jí i kúrò lójú oorun.” Àwọn ọmọ ẹ̀yìn kò lóye ohun tí Jésù sọ, nítorí náà ó là á mọ́lẹ̀ pé: “Lásárù ti kú.” Nígbà tí Jésù wá dé ibojì Lásárù níkẹyìn, ọkùnrin náà ti kú fún ọjọ́ mẹ́rin gbáko. Síbẹ̀ Jésù pàṣẹ pé kí wọ́n gbé òkúta tí wọ́n fi dí ẹnu ibojì náà kúrò. Lẹ́yìn náà ó ké jáde pé: “Lásárù, jáde wá!” Nígbà náà ni ohun àgbàyanu kan ṣẹlẹ̀. “Ọkùnrin tí ó ti kú náà jáde wá pẹ̀lú ẹsẹ̀ àti ọwọ́ rẹ̀ tí a fi àwọn aṣọ ìdìkú dì, ojú rẹ̀ ni a sì fi aṣọ dì yí ká. Jésù wí fún wọn pé: ‘Ẹ tú u, ẹ sì jẹ́ kí ó máa lọ.’”—Jòhánù 11:5, 6, 11-14, 43, 44.

Ó hàn gbangba pé èyí kì í ṣe àtúnwáyé. Jésù sọ pé Lásárù tó ti kú ń sùn ni, láìmọ ohunkóhun. Bí Bíbélì ṣe sọ ọ́, ‘èrò inú rẹ̀ ti ṣègbé.’ Kò “mọ nǹkan kan rárá.” (Sáàmù 146:4; Oníwàásù 9:5) Lásárù táa jí dìde náà kì í ṣe ẹlòmíràn tó ní ẹ̀mí àtúnwáyé. Ó ní àkópọ̀ ìwà kan náà, ọjọ́ orí rẹ̀ kò yàtọ̀, kò sì gbàgbé àwọn ohun tó ṣe sẹ́yìn. Ó tún bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìgbésí ayé rẹ̀ lọ bó ṣe ń bá a bọ̀ kó tó di pé ikú dá ẹ̀mí rẹ̀ légbodò, ó sì tún padà sọ́dọ̀ àwọn olólùfẹ́ tó ṣọ̀fọ̀ ikú rẹ̀.—Jòhánù 12:1, 2.

Lẹ́yìn náà, Lásárù tún kú. Kí wá làǹfààní jíjí táa jí i dìde? Jíjí tí Jésù jí òun àtàwọn mìíràn dìde fún ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú ìlérí Ọlọ́run lágbára pé yóò jí àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Rẹ̀ dìde kúrò nínú ikú nígbà tó bá tó àkókò lójú Rẹ̀. Àwọn iṣẹ́ ìyanu tí Jésù ṣe wọ̀nyẹn túbọ̀ fi ìjẹ́pàtàkì ọ̀rọ̀ rẹ̀ hàn pé: “Èmi ni àjíǹde àti ìyè. Ẹni tí ó bá ń lo ìgbàgbọ́ nínú mi, bí ó tilẹ̀ kú, yóò yè.”—Jòhánù 11:25.

Jésù sọ nípa àjíǹde ọjọ́ iwájú yẹn pé: “Wákàtí náà ń bọ̀, nínú èyí tí gbogbo àwọn tí wọ́n wà nínú ibojì ìrántí yóò gbọ́ ohùn [mi], wọn yóò sì jáde wá, àwọn tí wọ́n ṣe ohun rere sí àjíǹde ìyè, àwọn tí wọ́n sọ ohun búburú dàṣà sí àjíǹde ìdájọ́.” (Jòhánù 5:28, 29) Gẹ́gẹ́ bó ṣe rí nínú ọ̀ràn ti Lásárù, ìyẹn yóò jẹ́ àjíǹde àwọn èèyàn tó ti kú. Kì í ṣe síso àwọn ẹ̀mí tí kò kú mọ́ àwọn ara táa jí dìde, èyí tó ti jẹrà, tó tiẹ̀ ti lè wà lára àwọn ohun ẹlẹ́mìí mìíràn pàápàá. Jíjí àwọn òkú dìde kò kọjá agbára Ẹlẹ́dàá ọ̀run àti ayé, ẹni tí ọgbọ́n àti agbára rẹ̀ kò lópin.

Ǹjẹ́ ẹ̀kọ́ nípa àjíǹde gẹ́gẹ́ bí Jésù Kristi ṣe fi kọ́ni kò fi ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Ọlọ́run ní sí ẹ̀dá ènìyàn lẹ́nì kọ̀ọ̀kan hàn? Àmọ́ ìbéèrè kejì táa mẹ́nu kàn ṣáájú ńkọ́?

Kí Nìdí Táwọn Èèyàn Fi Ń Jìyà?

Nǹkan táwọn òmùgọ̀, àwọn tí kò nírìírí, tàbí àwọn ẹni ibi ń ṣe ló ń fa ọ̀pọ̀ jù lọ ìyà tó ń jẹ àwọn èèyàn. Àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ búburú tí a kò lè dá àwọn èèyàn lẹ́bi rẹ̀ ńkọ́? Fún àpẹẹrẹ, kí ló ń fa àwọn jàǹbá àti àjálù? Èé ṣe tí wọ́n fi ń bí àwọn ọmọ kan ní alábùkù ara? Allan Kardec ka irú nǹkan bẹ́ẹ̀ sí ìfìyàjẹni. Ó kọ̀wé pé: “Tí a bá ń fìyà jẹ wá, ó túmọ̀ sí pé a ti ní láti dẹ́ṣẹ̀ nìyẹn. Bi kì í bá ṣe ayé táa wá yìí la ti dẹ́ṣẹ̀ yẹn, á jẹ́ pé ayé àkọ́wá la ti dá ẹ̀ṣẹ̀ ọ̀hún.” Wọ́n kọ́ àwọn abẹ́mìílò láti máa gbàdúrà báyìí pé: “Olúwa, ìdájọ́ òdodo ni gbogbo ọ̀nà rẹ. Àìsàn tí o yàn láti fi ṣe mí ní láti jẹ́ èyí tí ó tọ́ sí mi . . . Mo gbà á gẹ́gẹ́ bí ìwẹ̀nùmọ́ ohun tí mo ṣe sẹ́yìn àti gẹ́gẹ́ bí ìdánwò ìgbàgbọ́ mi àti ìtẹríba fún ìfẹ́ mímọ́ Rẹ.”—The Gospel According to Spiritism.

Ǹjẹ́ Jésù fi irú nǹkan báyẹn kọ́ni? Rárá o. Jésù mọ gbólóhùn inú Bíbélì yẹn dáadáa pé: “Ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀ ni ó ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wọn.” (Oníwàásù 9:11) Ó mọ̀ pé àwọn nǹkan búburú wúlẹ̀ máa ń ṣẹlẹ̀ nígbà mìíràn. Kò túmọ̀ sí pé wọ́n jẹ́ ìyà ẹ̀ṣẹ̀.

Gbé ìṣẹ̀lẹ̀ yìí yẹ̀ wò nínú ìgbésí ayé Jésù: “Bí [Jésù] ti ń kọjá lọ, ó rí ọkùnrin kan tí ó fọ́jú láti ìgbà ìbí. Àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ sì béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ pé: ‘Rábì, ta ni ó ṣẹ̀, ọkùnrin yìí ni tàbí àwọn òbí rẹ̀, tí a fi bí i ní afọ́jú?’” Ìdáhùn Jésù jẹ́ èyí tó lani lóye dáadáa: “Kì í ṣe ọkùnrin yìí ni ó ṣẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni kì í ṣe àwọn òbí rẹ̀, ṣùgbọ́n ó jẹ́ kí a lè fi àwọn iṣẹ́ Ọlọ́run hàn kedere nínú ọ̀ràn rẹ̀. Lẹ́yìn tí ó sọ nǹkan wọ̀nyí tán, ó tutọ́ sí ilẹ̀, ó sì fi itọ́ náà ṣe amọ̀, ó sì fi amọ̀ rẹ̀ sí ojú ọkùnrin náà, ó sì wí fún un pé: ‘Lọ wẹ̀ ní odò adágún Sílóámù.‘ . . . Nítorí náà, ó lọ, ó wẹ̀, ó sì padà wá, ó ń ríran.”—Jòhánù 9:1-3, 6, 7.

Ọ̀rọ̀ Jésù fi hàn pé kì í ṣe ọkùnrin náà tàbí àwọn òbí rẹ̀ ló fa bíbí tí wọ́n bí i ní afọ́jú. Nítorí náà, Jésù kò fara mọ́ èrò pé ìyà ẹ̀ṣẹ̀ tí ọkùnrin náà ṣẹ̀ nígbà ayé àkọ́wá ló ń jẹ. Lóòótọ́, Jésù mọ̀ pé gbogbo èèyàn ni ó jogún ẹ̀ṣẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù ni wọ́n jogún, kì í ṣe èyí tí wọ́n ṣẹ̀ kí a tó bí wọn. Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Ádámù, gbogbo ènìyàn la bí ní aláìpé, tó ń ṣàìsàn tó sì ń kú. (Jóòbù 14:4; Sáàmù 51:5; Róòmù 5:12; 9:11) Ká sọ tòótọ́, nítorí ipò yẹn gan-an la ṣe rán Jésù wá, kó lè wá ṣàtúnṣe rẹ̀. Jòhánù olùbatisí sọ pé Jésù ni “Ọ̀dọ́ Àgùntàn Ọlọ́run, tí ó kó ẹ̀ṣẹ̀ ayé lọ!”—Jòhánù 1:29. a

Tún kíyè sí i pé, Jésù kò sọ pé Ọlọ́run mọ̀ọ́mọ̀ jẹ́ kí a bí ọkùnrin náà ní afọ́jú kí Jésù lè wá mú un lára dá lọ́jọ́ kan. Ẹ ò rí i pé ìwà òǹrorò, àní ìwà ìkà gbáà nìyẹn ì bá jẹ́! Ǹjẹ́ ìyẹn ì bá mú ìyìn bá Ọlọ́run? Ó tì o. Dípò ìyẹn, ọ̀nà ìyanu táa fi la ojú ọkùnrin afọ́jú náà ṣiṣẹ́ fún ‘fífi iṣẹ́ Ọlọ́run hàn.’ Bíi ti ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn tí Jésù mú lára dá, irú iṣẹ́ bẹ́ẹ̀ fi ìfẹ́ àtọkànwá tí Ọlọ́run ní fún ìran ènìyàn tó ń jìyà hàn, ó sì tún fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé a lè gbẹ́kẹ̀ lé ìlérí Rẹ̀ láti mú gbogbo àìsàn àti ìyà ẹ̀dá ènìyàn wá sópin ní àkókò tí ó tọ́ lójú Rẹ̀.—Aísáyà 33:24.

Ǹjẹ́ kò tù wá nínú láti rí i pé dípò fífi ìyà jẹ wá, ńṣe ni Baba wa ọ̀run ń fi “àwọn ohun rere fún àwọn tí ń béèrè lọ́wọ́ rẹ̀”? (Mátíù 7:11) Ẹ ò rí i bí ògo tó máa mú bá Ẹni Gíga Jù Lọ náà yóò ṣe pọ̀ tó, nígbà tí ojú àwọn afọ́jú bá là, tí etí àwọn adití bá ṣí, tí àwọn arọ ń rìn, tí wọ́n ń tọ sókè, tí wọ́n sì ń sáré!—Aísáyà 35:5, 6.

Títẹ́ Àìní Wa Nípa Tẹ̀mí Lọ́rùn

Jésù sọ pé: “Ènìyàn kì yóò wà láàyè nípasẹ̀ oúnjẹ nìkan ṣoṣo, bí kò ṣe nípasẹ̀ gbogbo àsọjáde tí ń jáde wá láti ẹnu Jèhófà.” (Mátíù 4:4) Bẹ́ẹ̀ ni o, a ń tẹ́ àìní wa nípa tẹ̀mí lọ́rùn nígbà táa bá ka Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, táa sì ń gbé ìgbésí ayé wa lọ́nà tó bá a mu. Lílọ sọ́dọ̀ àwọn abẹ́mìílò kò lè tẹ́ àìní wa nípa tẹ̀mí lọ́rùn ní ti tòótọ́. Àní, a ka irú àṣà bẹ́ẹ̀ léèwọ̀ pátápátá nínú ohun tí Allan Kardec pè ní èkíní nínú ìṣípayá òfin Ọlọ́run.—Diutarónómì 18:10-13.

Ọ̀pọ̀ èèyàn, títí kan àwọn abẹ́mìílò, gbà pé Ọlọ́run ni Ẹni Gíga Jù Lọ, ẹni ayérayé, ẹni pípé pérépéré, onínúure, ẹni rere, àti onídàájọ́ òdodo. Ṣùgbọ́n Bíbélì tún ṣí ohun tó ju ìyẹn lọ payá. Ó fi hàn pé ó ní orúkọ tó ń jẹ́, ìyẹn ni Jèhófà, èyí tí a gbọ́dọ̀ bọlá fún gẹ́gẹ́ bí Jésù ti ṣe. (Mátíù 6:9; Jòhánù 17:6) Ó fi Ọlọ́run hàn pé ó jẹ́ ẹni gidi tí àwọn èèyàn lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú rẹ̀. (Róòmù 8:38, 39) Nípa kíka Bíbélì, a kẹ́kọ̀ọ́ pé Ọlọ́run jẹ́ aláàánú, àti pé òun “kì í ṣe sí wa àní gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa; bẹ́ẹ̀ ni òun kì í mú ohun tí ó yẹ wá wá sórí wa gẹ́gẹ́ bí àwọn ìṣìnà wa.” (Sáàmù 103:10) Jèhófà, Olúwa Ọba Aláṣẹ fi ìfẹ́, àjùlọ, àti ìfòyebánilò rẹ̀ hàn nípasẹ̀ Ọ̀rọ̀ rẹ̀ tó wà ní àkọsílẹ̀. Òun ni Ẹni tí ó ń tọ́ àwọn ẹ̀dá ènìyàn onígbọràn sọ́nà, tó sì ń dáàbò bò wọ́n. Mímọ Jèhófà àti Jésù Kristi, Ọmọ rẹ̀ ni yóò “túmọ̀ sí ìyè àìnípẹ̀kun.”—Jòhánù 17:3.

Bíbélì fún wa ní gbogbo ìsọfúnni táa nílò nípa àwọn ète Ọlọ́run, ó sì sọ ohun táa gbọ́dọ̀ ṣe fún wa táa bá fẹ́ múnú rẹ̀ dùn. Yíyẹ Bíbélì wò kínníkínní yóò jẹ́ kí a rí ìdáhùn tòótọ́, tó sì tẹ́ wa lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè wa. Bíbélì tún fún wa ní ìtọ́ni nípa ohun tí ó tọ́ àti èyí tí kò tọ́, ó sì fún wa ní ìrètí tó lágbára. Ó mú un dá wa lójú pé ní ọjọ́ iwájú tí kò jìnnà mọ́, Ọlọ́run “yóò . . . nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú [ọmọ aráyé], ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ [yóò] ti kọjá lọ.” (Ìṣípayá 21:3, 4) Nípasẹ̀ Jésù Kristi, Jèhófà yóò sọ ìran ènìyàn di òmìnira kúró nínú ẹ̀ṣẹ̀ àti àìpé tí ó jogún bá, àwọn ènìyàn onígbọràn yóò sì jogún ìyè ayérayé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Gbogbo àìní wọn nípa tara àti nípa tẹ̀mí ni a ó sì tẹ́ lọ́rùn pátápátá ní àkókò yẹn.—Sáàmù 37:10, 11, 29; Òwe 2:21, 22; Mátíù 5:5.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Fún ìjíròrò lórí bí ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú ṣe bẹ̀rẹ̀, wo orí kẹfà ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 22]

ǸJẸ́ BÍBÉLÌ FI ÀTÚNWÁYÉ KỌ́NI?

Ǹjẹ́ a rí ẹsẹ Bíbélì èyíkéyìí tí ó ti ẹ̀kọ́ àtúnwáyé lẹ́yìn? Ẹ jẹ́ ká wo díẹ̀ lára àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ tí àwọn tó gba ẹ̀kọ́ náà gbọ́ ń lò:

“Nítorí pé gbogbo wọn, àwọn Wòlíì àti Òfin, sọ tẹ́lẹ̀ títí di ìgbà Jòhánù . . . Òun fúnra rẹ̀ ni ‘Èlíjà tí a yàn tẹ́lẹ̀ láti wá.’”—Mátíù 11:13, 14.

Ṣé Èlíjà tí a tún bí ni Jòhánù Olùbatisí? Nígbà táwọn èèyàn béèrè pe: “Ìwọ ni Èlíjà bí?” Jòhánù dáhùn ní kedere pé: “Èmi kọ́.” (Jòhánù 1:21) Àmọ́, a ti sọ tẹ́lẹ̀ pé Jòhánù yóò dé ṣáájú Mèsáyà náà “pẹ̀lú ẹ̀mí àti agbára Èlíjà.” (Lúùkù 1:17; Málákì 4:5, 6) Ní ọ̀rọ̀ mìíràn, Èlíjà ni Jòhánù Olùbatisí ní ti pé ó ṣe iṣẹ́ kan tó jọ ti Èlíjà.

“Láìjẹ́ pé a tún ẹnikẹ́ni bí, kò lè rí ìjọba Ọlọ́run. Kí ẹnu má ṣe yà ọ́ nítorí mo sọ fún ọ pé, A gbọ́dọ̀ tún yín bí.”—Jòhánù 3:3, 7.

Ọ̀kan nínú àwọn àpọ́sítélì kọ̀wé lẹ́yìn náà pé: “Olubukún li Ọlọrun ati Baba Jesu Kristi Oluwa wa, Ẹniti o tún wa bí, gẹgẹ bi ọ̀pọlọpọ ãnu rẹ̀, sinu ireti ãye nipa ajinde Jesu Kristi kuro ninu okú.” (1 Pétérù 1:3, 4, Bíbélì Mímọ́; Jòhánù 1:12, 13) Ní kedere, àtúnbí tí Jésù tọ́ka sí jẹ́ ìrírí tẹ̀mí tí àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ yóò ní nígbà tí wọ́n ṣì wà láàyè, kì í ṣe àtúnwáyé lọ́jọ́ iwájú.

“Nígbà tí ẹnì kan bá kú, ó wà láàyè títí láé: nígbà tí àwọn ọjọ́ tí mo máa fi wà láàyè bá parí, èmi yóò dúró, nítorí pé mo ṣì ń padà bọ̀.”—Bí “Bíbélì èdè Gíríìkì” kan ṣe túmọ̀ Jóòbù 14:14 tí a ṣàyọlò rẹ̀ nínú The Gospel According to Spiritism.

Bíbélì Mímọ́ túmọ̀ ẹsẹ yẹn báyìí pé: “Bi enia ba kú yio si tun yè bi? gbogbo ọjọ igba ti a là silẹ fun mi li emi o duro dè, titi amudọtun mi yio fi de.” Ka àyíká ọ̀rọ̀ ẹsẹ yẹn. Wàá rí i pé àwọn òkú ń dúró nínú ibojì de “amudọtun” wọn. (Ẹsẹ 13) Wọn ò mọ ohunkóhun ní gbogbo àkókò tí wọ́n fi ń dúró yẹn. “Ẹni tí ó bá kú ti lọ pátápátá; nígbà tí ẹni kíkú bá sì fò ṣánlẹ̀, ó ti di aláìsí nìyẹn.”—Jóòbù 14:10, ìtumọ̀ Septuagint ti Bagster.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 21]

Ìrètí àjíǹde fi ìfẹ́ jíjinlẹ̀ tí Ọlọ́run ní sí wa gẹ́gẹ́ bí ẹnì kọ̀ọ̀kan hàn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 23]

Ọlọ́run yóò fòpin sí gbogbo ìyà tó ń jẹ aráyé