Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà

Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà

Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Jèhófà

“Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo nínú Olúwa. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ṣe ni èmi yóò wí pé, Ẹ máa yọ̀!”—FÍLÍPÌ 4:4.

1, 2. Báwo ló ṣe ṣeé ṣe fún arákùnrin kan àti ìdílé rẹ̀ láti máa yọ̀, láìka bí wọ́n ṣe pàdánù gbogbo ohun tí wọ́n ní sí?

 JAMES, Kristẹni kan tó ti pé ẹni àádọ́rin ọdún, tó ń gbé ní Sierra Leone, ti fi gbogbo ìgbésí ayé rẹ̀ ṣiṣẹ́ àṣekára. Fojú inú wo bí ayọ̀ rẹ̀ ṣe pọ̀ tó nígbà tó tu owó jọ, tó wá fi ra ilé oníyàrá mẹ́rin tó mọ níwọ̀n! Àmọ́, láìpẹ́ púpọ̀ lẹ́yìn tí James àti ìdílé rẹ̀ kó sínú ilé náà, ogun abẹ́lé bẹ̀rẹ̀ sí jà ní orílẹ̀-èdè wọn, ilé wọn sì jó kanlẹ̀. Wọ́n pàdánù ilé wọn, àmọ́ wọn ò pàdánù ayọ̀ wọn. Kí nìdí?

2 James àti ìdílé rẹ̀ pa ọkàn wọn pọ̀, kì í ṣe sórí ohun tí wọ́n pàdánù o, bí kò ṣe sórí ohun tó ṣẹ́ kù fún wọn. James ṣàlàyé pé: “Kódà ní àkókò àjálù náà, a ń ṣèpàdé, a ń ka Bíbélì, a ń gbàdúrà pa pọ̀, a sì ń ṣàjọpín ohun díẹ̀ táa ní pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn. Ó ṣeé ṣe fún wa láti máa yọ̀, nítorí pé a pọkàn pọ̀ sórí àjọṣe pàtàkì táa ní pẹ̀lú Jèhófà.” Nípa ríronú lórí àwọn ìbùkún tí wọ́n ní, tí èyí tó ga jù lọ níbẹ̀ sì jẹ́ níní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà, ó ṣeé ṣe fún àwọn Kristẹni olóòótọ́ wọ̀nyí láti “máa bá a lọ ní yíyọ̀.” (2 Kọ́ríńtì 13:11) Ká sọ tòótọ́, wàhálà tó bá wọn kì í ṣe ohun tó rọrùn láti fara dà. Àmọ́, wọn ò dẹ́kun láti máa yọ̀ nínú Jèhófà.

3. Báwo ni àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ kan ko ṣe jẹ́ kí ayọ̀ wọn yingin?

3 Àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ dojú kọ irú àwọn àdánwò tó dé bá James àti ìdílé rẹ̀. Síbẹ̀, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sí àwọn Kristẹni tó jẹ́ Hébérù pé: “[Ẹ̀yin] sì fi ìdùnnú gba pípiyẹ́ àwọn nǹkan ìní yín.” Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni Pọ́ọ̀lù wá ṣàlàyé orísun ayọ̀ wọn pé: “Ní mímọ̀ pé ẹ̀yin fúnra yín ní ohun ìní dídárajù àti èyí tí ó wà lọ títí.” (Hébérù 10:34) Dájúdájú, àwọn Kristẹni ọ̀rúndún kìíní wọ̀nyẹn ní ìrètí tó lágbára. Wọ́n fi ìgbẹ́kẹ̀lé wọ̀nà fún gbígba ohun kan tí kò lè ṣeé piyẹ́—ìyẹn ni “adé ìyè” tí kò lè díbàjẹ́ nínú Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run. (Ìṣípayá 2:10) Lónìí, ìrètí Kristẹni táa ní—ì báà ṣe ní ọ̀run tàbí lórí ilẹ̀ ayé—lè ràn wá lọ́wọ́ láti má ṣe jẹ́ kí ayọ̀ wa yingin, kódà nígbà táa bá dojú kọ ìpọ́njú pàápàá.

“Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Ìrètí”

4, 5. (a) Èé ṣe tí ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù láti “máa yọ̀ nínú ìrètí” fi bọ́ sí àkókò gẹ́ẹ́ fún àwọn ará Róòmù? (b) Kí ló lè mú kí Kristẹni kan gbàgbé ìrètí rẹ̀?

4 Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù gba àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tó wà ní Róòmù níyànjú láti “máa yọ̀ nínú ìrètí” ìyè àìnípẹ̀kun. (Róòmù 12:12) Ìmọ̀ràn tó bọ́ sí àkókò gẹ́ẹ́ nìyẹn jẹ́ fún àwọn ará Róòmù. Kò tíì pé ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí wọn, tí wọ́n fi wá dojú kọ inúnibíni líle koko, Olú Ọba Nero tiẹ̀ pàṣẹ pé kí wọ́n fi ikú oró pa àwọn kan lára wọn. Ó dájú pé ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní pé Ọlọ́run yóò fún wọn ní adé ìyè tó ti ṣèlérí rẹ̀ ló mẹ́sẹ̀ wọn dúró nígbà tí wọ́n ń jìyà. Àwa náà ńkọ́ lónìí?

5 Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, àwa náà retí pé a ó ṣe inúnibíni sí wa. (2 Tímótì 3:12) Síwájú sí i, a mọ̀ pé “ìgbà àti ìṣẹ̀lẹ̀ tí a kò rí tẹ́lẹ̀” ń ṣẹlẹ̀ sí gbogbo wa. (Oníwàásù 9:11) Jàǹbá ọkọ̀ lè gbẹ̀mí ẹnì kan táa fẹ́ràn. Àìsàn líle koko lè gba ẹ̀mí òbí kan tàbí ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ kan. Àyàfi táa bá jẹ́ kí ìrètí Ìjọba táa ní wà lọ́kàn wa digbí la ò fi ní kó sínú ewu nípa tẹ̀mí nígbà tí irú àwọn àdánwò bẹ́ẹ̀ bá ṣẹlẹ̀. Nítorí ìdí èyí, ì bá dára ká máa bí ara wa léèrè pé, ‘Ǹjẹ́ mo “máa ń yọ̀ nínú ìrètí”? Ìgbà mélòó ni mo máa ń wá àkókò láti ṣàṣàrò lé e lórí? Ǹjẹ́ Párádísè tó ń bọ̀ náà jẹ́ òótọ́ lójú mi? Ǹjẹ́ mò ń wo ara mi níbẹ̀? Ṣé mo ṣì ń hára gàgà pé kí ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí wá sópin bí mo ṣe ń hára gàgà nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́?’ Ìbéèrè tó kẹ́yìn yìí gba ìrònú jinlẹ̀ gan-an. Kí nìdí? Nítorí pé, bí ara wa bá yá gágá, tí nǹkan ṣẹnu re fún wa, tí ogun kò sì jà ní apá ibi tí a ń gbé lórí ilẹ̀ ayé, tí kò sí ọ̀wọ́n oúnjẹ, tàbí ìjábá èyíkéyìí, a lè gbàgbé nísinsìnyí pé a fẹ́ kí ayé tuntun ti Ọlọ́run tó ń bọ̀ náà tètè dé.

6. (a) Nígbà tí Pọ́ọ̀lù àti Sílà wà nínú ìpọ́njú, orí kí ni wọ́n gbé èrò inú wọn kà? (b) Báwo ni àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù àti ti Sílà ṣe lè fún wa níṣìírí lóde òní?

6 Pọ́ọ̀lù tún gba àwọn ará Róòmù nímọ̀ràn láti “máa ní ìfaradà lábẹ́ ìpọ́njú.” (Róòmù 12:12) Ìpọ́njú kì í ṣe ohun àjèjì sí Pọ́ọ̀lù. Nígbà kan, ó rí ìran ọkùnrin kan tó ké sí i láti “rékọjá wá sí Makedóníà” kí ó lè wá ran àwọn ènìyàn ibẹ̀ lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. (Ìṣe 16:9) Nítorí ìdí èyí, Pọ́ọ̀lù, pẹ̀lú Lúùkù, Sílà, àti Tímótì, forí lé Yúróòpù. Kí ló ń dúró de àwọn míṣọ́nnárì onítara wọ̀nyẹn? Ìpọ́njú ni! Lẹ́yìn tí wọ́n wàásù tán ní ìlú Fílípì tó wà ní ilẹ̀ Makedóníà, àwọn èèyàn na Pọ́ọ̀lù àti Sílà, wọ́n sì sọ wọ́n sínú túbú. Ó hàn gbangba pé kì í ṣe pé àwọn kan lára àwọn ará ìlú Fílípì wulẹ̀ dágunlá sí ìhìn Ìjọba náà nìkan ni—wọ́n ṣe àtakò líle koko pẹ̀lú. Ǹjẹ́ bí nǹkan ṣe wá rí yìí mú kí àwọn míṣọ́nnárì onítara náà banú jẹ́? Ó tì o. Lẹ́yìn tí wọ́n ti nà wọ́n tán, tí wọ́n sì sọ wọ́n sínú túbú, “ní nǹkan bí àárín òru, Pọ́ọ̀lù àti Sílà ń gbàdúrà, wọ́n sì ń fi orin yin Ọlọ́run.” (Ìṣe 16:25, 26) Ní ti tòótọ́, ìrora nínà tí wọ́n na Pọ́ọ̀lù àti Sílà kò lè mú ayọ̀ wá, ṣùgbọ́n ìyẹn kọ́ ni àwọn míṣọ́nnárì méjèèjì náà gbé ka iwájú ara wọn. Ọ̀dọ̀ Jèhófà àti àwọn ọ̀nà tó gbà ń bù kún wọn ni wọ́n gbé èrò inú wọn kà. Nípa fífi tayọ̀tayọ̀ ‘fara dà á lábẹ́ ìpọ́njú,’ Pọ́ọ̀lù àti Sílà jẹ́ àpẹẹrẹ rere fún àwọn arákùnrin wọn ní Fílípì àti ní ibòmíràn.

7. Èé ṣe tó fi yẹ kí a máa dúpẹ́ nínú àdúrà wa?

7 Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ máa ní ìforítì nínú àdúrà.” (Róòmù 12:12) Ǹjẹ́ o máa ń gbàdúrà nígbà tí hílàhílo bá bá ọ? Kí lo máa ń gbàdúrà fún? Ó ṣeé ṣe kóo mẹ́nu kan ìṣòro rẹ ní pàtó, kí o sì sọ pé kí Jèhófà ràn ọ́ lọ́wọ́. Àmọ́, o tún lè dúpẹ́ fún àwọn ìbùkún tí o ń gbádùn. Nígbà tí ìṣòro bá dé, ríronú lórí àwọn ohun rere tí Jèhófà ń ṣe fún wa lè ràn wá lọ́wọ́ láti “máa yọ̀ nínú ìrètí.” Dáfídì, tí ìgbésí ayé rẹ̀ kún fún wàhálà, kọ̀wé pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣe, Ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, àní àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti ìrònú rẹ sí wa; kò sí ẹnì kankan tí a lè fi ọ́ wé. Ká ní mo fẹ́ máa wí, kí n sì máa sọ nípa wọn ni, wọ́n pọ̀ níye ju èyí tí mo lè máa ròyìn lẹ́sẹẹsẹ.” (Sáàmù 40:5) Bí àwa náà bá ń ṣe àṣàrò déédéé lórí àwọn ìbùkún táa ń rí gbà lọ́dọ̀ Jèhófà, bí Dáfídì ti ṣe, kò sí bí a ò ṣe ní láyọ̀.

Ní Ẹ̀mí Tó Dára

8. Kí ló ń ran Kristẹni kan lọ́wọ́ láti jẹ́ aláyọ̀ nígbà tó bá dojú kọ inúnibíni?

8 Jésù gba àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ níyànjú láti ní ẹ̀mí tó dára nígbà tí wọ́n bá dojú kọ onírúurú àdánwò. Ó sọ pé: “Aláyọ̀ ni yín nígbà tí àwọn ènìyàn bá gàn yín, tí wọ́n sì ṣe inúnibíni sí yín, tí wọ́n sì fi irọ́ pípa sọ gbogbo onírúurú ohun burúkú sí yín nítorí mi.” (Mátíù 5:11) Kí nìdí táa ní láti máa yọ̀ lábẹ́ irú àwọn ipò bẹ́ẹ̀? Agbára táa ní láti kojú àtakò fi hàn pé ẹ̀mí Jèhófà wà lára wa. Àpọ́sítélì Pétérù sọ fún àwọn Kristẹni ọjọ́ ayé rẹ̀ pé: “Bí a bá ń gàn yín nítorí orúkọ Kristi, ẹ̀yin jẹ́ aláyọ̀, nítorí pé ẹ̀mí ògo, àní ẹ̀mí Ọlọ́run, ti bà lé yín.” (1 Pétérù 4:13, 14) Nípasẹ̀ ẹ̀mí rẹ̀, Jèhófà yóò tún ràn wá lọ́wọ́ láti fara dà á, kí a sì tipa bẹ́ẹ̀ máa ní ayọ̀ nìṣó.

9. Kí ló ran àwọn arákùnrin kan lọ́wọ́ láti rí ìdí tó fi yẹ kí wọ́n máa yọ̀ nígbà tí wọ́n wà lọ́gbà ẹ̀wọ̀n nítorí ìgbàgbọ́ wọn?

9 Kódà nígbà táa bá wà lábẹ́ ipò tó burú jáì, a ṣì lè rí ìdí tó fi yẹ ká máa yọ̀. Kristẹni kan tó ń jẹ́ Adolf rí i pé bí ọ̀ràn ṣe rí nìyẹn. Ó ń gbé ní orílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fún ọ̀pọ̀ ọdún. Wọ́n mú Adolf àti àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ bíi mélòó kan, wọ́n sì fi wọ́n sẹ́wọ̀n ọlọ́jọ́ gbọọrọ nítorí pé wọ́n kọ̀ láti kọ ìgbàgbọ́ wọn táa gbé ka Bíbélì sílẹ̀. Nǹkan ò fara rọ rárá lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, àmọ́ bíi ti Pọ́ọ̀lù àti Sílà, Adolf àtàwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ rí ìdí láti máa dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run. Wọ́n kíyè sí pé, ìrírí táwọn ní lọ́gbà ẹ̀wọ̀n ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fún ìgbàgbọ́ wọn lókun àti láti mú àwọn ànímọ́ Kristẹni tó níye lórí dàgbà, irú bí ìwà ọ̀làwọ́, ẹ̀mí ìfọ̀rọ̀rora-ẹni-wò, àti ìfẹ́ ará. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí ẹlẹ́wọ̀n kan bá rí ẹ̀bùn gbà láti ilé, ó máa ń ṣàjọpín ohun tó wà níbẹ̀ pẹ̀lú àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tó ka àwọn ìpèsè wọ̀nyí sí ohun tó wá látọ̀dọ̀ Jèhófà, ẹni tó jẹ́ olórí Olùfúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” Irú ìwà inú rere bẹ́ẹ̀ ń mú ayọ̀ wá fún ẹni tó fúnni àti ẹni tó gbà á. Nípa bẹ́ẹ̀, ìyà tí wọ́n fi jẹ wọ́n kí wọ́n bàa sẹ́ ìgbàgbọ́ wọn wá di èyí tó mú wọn lágbára sí i nípa tẹ̀mí!—Jákọ́bù 1:17; Ìṣe 20:35.

10, 11. Báwo ni arábìnrin kan ṣe kojú ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nu-wò láìsinmi, àti ẹ̀wọ̀n tó gùn gbọ̀ọ̀rọ̀-gbọọrọ lẹ́yìn náà?

10 Ella, tí òun náà ń gbé ní orílẹ̀-èdè kan tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ Ìjọba náà tipẹ́ ni wọ́n mú nítorí pé ó ń sọ nípa ìrètí tó ní gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni fún àwọn ẹlòmíràn. Fún oṣù mẹ́jọ gbáko ni wọ́n fi ń fọ̀rọ̀ wá obìnrin yìí lẹ́nu wo láìsinmi. Nígbà tí wọ́n wá gbọ́ ẹjọ́ rẹ̀ níkẹyìn, wọ́n dá a lẹ́jọ́ ẹ̀wọ̀n ọdún mẹ́wàá nínú ọgbà ẹ̀wọ̀n tí kò ti sí ẹlòmíràn tó jẹ́ olùjọsìn Jèhófà. Ẹni ọdún mẹ́rìnlélógún péré ni Ella nígbà yẹn.

11 Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ, nǹkan ayọ̀ kọ́ ló jẹ́ fún Ella pé inú ọgbà ẹ̀wọ̀n ló ti máa lo èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ìgbà ọ̀dọ́ rẹ̀. Àmọ́, níwọ̀n bí kò ti lè yí ipò tó bá ara rẹ̀ padà, ó kúkú pinnu láti yí èrò tó ní padà. Láìfọ̀rọ̀gùn, ó bẹ̀rẹ̀ sí wo ọgbà ẹ̀wọ̀n náà gẹ́gẹ́ bí ìpínlẹ̀ ìjẹ́rìí. Ó sọ pé: “Iṣẹ́ ìwàásù pọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe, tó fi jẹ́ pé kíá làwọn ọdún náà kọjá lọ.” Lẹ́yìn ohun tó lé ní ọdún márùn-ún, wọ́n tún fi ọ̀rọ̀ wá Ella lẹ́nu wò lẹ́ẹ̀kan sí i. Nígbà tí wọ́n rí i pé ọgbà ẹ̀wọ̀n kò ba ìgbàgbọ́ rẹ̀ jẹ́, àwọn tó ń fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò sọ fún un pé: “A ò lè fi ọ́ sílẹ̀; nítorí pé o ò tíì yí padà.” Ella dá wọn lóhùn láìṣojo pé: “Ṣùgbọ́n mo ti yí padà! Ọkàn mi balẹ̀ nísinsìnyí ju ti ìgbà tí mo kọ́kọ́ lọ sí ọgbà ẹ̀wọ̀n, ìgbàgbọ́ mi sì ti lágbára gan-an jù ti tẹ́lẹ̀ lọ!” Ó sì fi kún un pé: “Bí ẹ kò bá fẹ́ tú mí sílẹ̀, màá wà níbẹ̀ títí tó fi máa tó àkókò lójú Jèhófà láti dá mi nídè.” Ọdún márùn-ún ààbọ̀ nínú àhámọ́ kò sọ Ella di aláìláyọ̀! Ó kọ́ láti ní ìtẹ́lọ́rùn nínú ipòkípò tí ó bá bá ara rẹ̀. Ǹjẹ́ o rí nǹkan kan kọ́ nínú àpẹẹrẹ rẹ̀?—Hébérù 13:5.

12. Kí ló lè mú kí Kristẹni kan ní ìbàlẹ̀ ọkàn lábẹ́ ipò líle koko?

12 Máà ronú pé Ella ní ẹ̀bùn àrà ọ̀tọ̀ kan tó fi lè kojú irú ìṣòro bẹ́ẹ̀. Nígbà tí Ella ń sọ̀rọ̀ nípa àkókò tí wọ́n ń fọ̀rọ̀ wá a lẹ́nu wò láwọn oṣù tó ṣáájú ìgbà tí wọ́n ṣèdájọ́ rẹ̀, ó ní: “Mo rántí bí mo ṣe ń payín keke, tí mò ń gbọ̀n jìnnìjìnnì bí ọmọ ẹyẹ tí òtútù ń mú.” Àmọ́, Ella ní ìgbàgbọ́ tó lágbára nínú Jèhófà. Ó ti kẹ́kọ̀ọ́ láti ní ìgbẹ́kẹ̀lé nínú rẹ̀. (Òwe 3:5-7) Nípa bẹ́ẹ̀, Ọlọ́run túbọ̀ jẹ́ ẹni gidi sí i ju ti àtẹ̀yìnwá lọ. Ó ṣàlàyé pé: “Gbogbo ìgbà tí mo bá ti wọnú yàrá ìfọ̀rọ̀wáni-lẹ́nu-wò náà ló máa ń dà bí ẹni pé mo ní àlàáfíà àrà ọ̀tọ̀ kan. . . . Bí ipò náà bá ṣe ń le sí i ni àlàáfíà náà ń pọ̀ sí i.” Jèhófà ni orísun àlàáfíà yẹn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run; àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà yín àti agbára èrò orí yín nípasẹ̀ Kristi Jésù.”—Fílípì 4:6, 7.

13. Kí ló mú un dá wa lójú pé bí ìpọ́njú bá dé, a óò ní okun láti fara dà á?

13 Ella, tí wọ́n ti dá nídè báyìí, ní ayọ̀ láìka ìyà sí. Kì í ṣe agbára ti ara rẹ̀ ló fi ṣe èyí, bí kò ṣe agbára tí Jèhófà fún un. Bákan náà ni ọ̀ràn ti Pọ́ọ̀lù ṣe rí, ẹni tó kọ̀wé pé: “Nítorí náà, ṣe ni èmi yóò kúkú máa fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ gan-an ṣògo nípa àwọn àìlera mi, kí agbára Kristi lè wà lórí mi bí àgọ́. . . . Nítorí nígbà tí èmi bá jẹ́ aláìlera, nígbà náà ni mo di alágbára.”—2 Kọ́ríńtì 12:9, 10.

14. Ṣàpèjúwe bí Kristẹni kan ṣe lè ní èrò rere nípa ipò kan tí ń dánni wò àti ohun tí àbájáde rẹ̀ lè jẹ́.

14 Àwọn pákáǹleke tóo ń dojú kọ lónìí lè yàtọ̀ sí àwọn táa gbé yẹ̀ wò wọ̀nyẹn. Síbẹ̀, ohunkóhun tó wù kí wọ́n jẹ́, kò rọrùn láti kojú hílàhílo. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀gá rẹ lè máa ṣe lámèyítọ́ iṣẹ́ rẹ—kó máa ṣe é gan-an ju bó ti ń ṣe sí iṣẹ́ àwọn òṣìṣẹ́ yòókù tí wọ́n jẹ́ mẹ́ńbà ẹ̀sìn mìíràn. Ó lè máà ṣeé ṣe fún ọ láti rí iṣẹ́ mìíràn. Báwo ni wàá ṣe máa ní ayọ̀ nìṣó? Rántí Adolf àtàwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀, tí ìrírí tí wọ́n ní lọ́gbà ẹ̀wọ̀n kọ́ wọ́n ní àwọn ànímọ́ tó ṣe pàtàkì. Tóo bá fi tọkàntọkàn sapá láti tẹ́ ọ̀gá rẹ lọ́rùn—bó tilẹ̀ jẹ́ ẹnì kan “tí ó ṣòro láti tẹ́ lọ́rùn”—wàá mú àwọn ànímọ́ Kristẹni bí ìfaradà àti ìpamọ́ra dàgbà. (1 Pétérù 2:18) Síwájú sí i, o lè wá túbọ̀ di òṣìṣẹ́ tó dáńgájíá, èyí tó lè fún ọ láǹfààní láti rí iṣẹ́ tó máa tẹ́ ọ lọ́rùn lọ́jọ́ kan. Ẹ jẹ́ ká wá jíròrò àwọn ọ̀nà mìíràn táa fi lè máa yọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà.

Mímú Nǹkan Rọrùn Ń Máyọ̀ Wá

15-17. Kí ni tọkọtaya kan rí i pé ó lè dín másùnmáwo kù, bí wọn ò tiẹ̀ lè mú ohun tó ń fà á kúrò pátápátá?

15 Ó lè jẹ́ oríṣi iṣẹ́ kan tàbí méjì lo mọ̀ ọ́n ṣe, ó sì lè máà rọrùn fún ọ láti rí iṣẹ́ mìíràn, ṣùgbọ́n àwọn apá ibòmíràn lè wà nínú ìgbésí ayé rẹ tóo lè wá nǹkan ṣe sí. Gbé àpẹẹrẹ tó tẹ̀ lé e yìí yẹ̀ wò.

16 Tọkọtaya kan ké sí alàgbà kan wá sílé wọn láti wá bá wọn jẹun. Arákùnrin náà àti aya rẹ̀ wá sọ fún alàgbà náà lálẹ́ ọjọ́ yẹn pé pákáǹleke ìgbésí ayé kò jẹ́ kí àwọn rójú ráyè mọ́ báyìí. Àwọn méjèèjì ló níṣẹ́ tó ń gba èyí tó pọ̀ jù nínú àkókò wọn, wọn ò sì láǹfààní láti wá iṣẹ́ mìíràn. Wọ́n wá ń ronú nípa báwọn ṣe lè máa fara da ipò náà lọ.

17 Nígbà tí wọ́n sọ pé kí alàgbà náà fún àwọn nímọ̀ràn, ohun tó sọ fún wọn ni pé, “Ẹ mú nǹkan rọrùn.” Bíi báwo? Tọkọtaya náà ń lo nǹkan bíi wákàtí mẹ́ta láti dé ibi iṣẹ́ wọn àti láti padà wálé lójoojúmọ́. Alàgbà náà, tó mọ àwọn tọkọtaya náà dáadáa, dámọ̀ràn pé kí wọ́n ronú nípa kíkó lọ sí ibi tó sún mọ́ ibi iṣẹ́ wọn, kí wọ́n lè dín àkókò tí wọ́n fi ń rin ìrìn àjò lọ sí ibi iṣẹ́ àti èyí tí wọ́n fi ń padà wá sílé lójoojúmọ́ kù. Wọ́n lè lo àkókò tó ṣẹ́ kù yẹn fún àwọn nǹkan mìíràn tó ṣe pàtàkì—tàbí kí wọ́n tiẹ̀ fi sinmi. Bí àwọn pákáǹleke ìgbésí ayé bá fẹ́ ba ayọ̀ rẹ jẹ́, o ò ṣe gbé ipò rẹ yẹ̀ wò bóyá o lè dín ìṣòro náà kù nípa ṣíṣe àwọn àtúnṣe bíi mélòó kan?

18. Kí nìdí tó fi ṣe pàtàkì láti ronú dáadáa ká to ṣe àwọn ìpinnu?

18 Ọ̀nà mìíràn láti dín pákáǹleke kù ni pé kéèyàn ronú dáadáa kó tó ṣe ìpinnu èyíkéyìí. Fún àpẹẹrẹ, Kristẹni kan pinnu láti kọ́ ilé kan. Ó wá lọ yan ilé tó máa gba iṣẹ́ tó pọ̀ gan-an, bẹ́ẹ̀ kò kọ́ ilé kan rí. Ó wá rí i báyìí pé òun ì bá ti yẹra fún àwọn ìṣòro tó ṣeé yẹ̀ sílẹ̀ tó bá jẹ́ pé ‘òun ti ronú nípa àwọn ìṣísẹ̀ òun’ kí òun tó yan irú ilé tí òun fẹ́ kọ́. (Òwe 14:15) Kristẹni mìíràn gbà láti ṣe onídùúró fún onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kan tó fẹ́ yáwó. Àdéhùn tí wọ́n ṣe ni pé, bí ẹni tó yáwó náà kò bá lè san owó ọ̀hún, ẹni tó dúró fún un ni yóò san án. Lákọ̀ọ́kọ́, gbogbo nǹkan ń lọ déédéé, àmọ́ nígbà tó yá, ẹni tó yáwó náà kò lè mú àdéhùn rẹ̀ ṣẹ mọ́. Bí ẹni tó ni owó ṣe fa ìbínú yọ nìyẹn tó ní kí ẹni tó dúró fún un gbé gbogbo gbèsè náà san. Ìyẹn sì kó ẹni tó dúró fúnni náà sínú wàhálà ńlá. Ǹjẹ́ èyí ì bá ṣẹlẹ̀ ká ní ó ti gbé gbogbo ohun tó lè tẹ̀yìn rẹ̀ jáde yẹ̀ wò kó tó di pé ó gbà láti ṣe onídùúró fún gbèsè náà?—Òwe 17:18.

19. Àwọn ọ̀nà wo la lè gbà dín másùnmáwo kù nínú ìgbésí ayé wa?

19 Nígbà tó bá rẹ̀ wá, ẹ má ṣe jẹ́ ká parí èrò sí pé a lè dín pákáǹleke táa ní kù, kí ayọ̀ wa sí padà wá nípa dídín àkókò táa fi ń dá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, tàbí èyí táa fi ń lọ sí òde ẹ̀rí, àti ìpàdé kù láé. Họ́wù, ṣebí àwọn ọ̀nà pàtàkì táa fi ń rí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà gbà nìyẹn, ayọ̀ sì jẹ́ ọ̀kan lára àwọn èso rẹ̀. (Gálátíà 5:22) Àwọn ìgbòkègbodò Kristẹni máa ń tuni lára, kì í sì í jẹ́ kó rẹni lárẹ̀jù. (Mátíù 11:28-30) Ohun tó ṣeé ṣe kó máa fa àárẹ̀ jù lọ ni iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́ tàbí ìgbòkègbodò eré ìtura, kì í ṣe àwọn nǹkan tẹ̀mí rárá. Fífi títètè sùn kọ́ra tún máa ń ṣèrànwọ́ láti jẹ́ kí ara wa le. Ìsinmi ráńpẹ́ téèyàn bá ní lè ṣàǹfààní tó pọ̀. Arákùnrin N. H. Knorr, tó sìn gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà títí dọjọ́ ikú rẹ̀, máa ń sọ fún àwọn míṣọ́nnárì pé: “Nígbà tí ẹ bá fẹ́ rẹ̀wẹ̀sì, ohun tí ẹ gbọ́dọ̀ kọ́kọ́ ṣe ni pé kí ẹ sinmi. Yóò yà yín lẹ́nu bí ìṣòro èyíkéyìí tẹ́ẹ bá ní ṣe máa kéré tó lójú yín nígbà tí ẹ bá ti sùn dáadáa lóru!”

20. (a) Sọ àwọn ọ̀nà bíi mélòó kan tí a fi lè máa yọ̀. (b) Kí ni àwọn nǹkan tí o lè ronú kàn, tó lè mú kóo máa yọ̀? (Wo àpótí tó wà lójú ìwé 17.)

20 Àǹfààní ńlá làwọn Kristẹni ní láti sin “Ọlọ́run aláyọ̀.” (1 Tímótì 1:11) Gẹ́gẹ́ báa ti rí i, a lè máa yọ̀, kódà nígbà tí àwọn ìṣòro líle koko bá dojú kọ wá. Ẹ jẹ́ kí a gbé ìrètí Ìjọba náà ka iwájú wa, kí a tún ojú ìwòye wa ṣe nígbà tó bá yẹ, kí a sì mú kí ìgbésí ayé wa rọrùn. Nígbà náà, ipòkípò tí a bá bá ara wa, a ó máa ṣe ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa yọ̀ nígbà gbogbo nínú Olúwa. Lẹ́ẹ̀kan sí i, ṣe ni èmi yóò wí pé, Ẹ máa yọ̀!”—Fílípì 4:4.

Ronú Jinlẹ̀ Lórí Àwọn Ìbéèrè Wọ̀nyí:

• Èé ṣe táwọn Kristẹni fi gbọ́dọ̀ jẹ́ kí ìrètí Ìjọba náà wà digbí lọ́kàn wọn?

• Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa yọ̀ nínú ipò ìṣòro?

• Èé ṣe tó fi yẹ ká gbìyànjú láti mú kí ìgbésí ayé wa rọrùn?

• Àwọn ọ̀nà wo làwọn kan ti gbà mú kí ìgbésí ayé wọn rọrùn?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àpótí/Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

Àwọn Ìdí Mìíràn Tó Fi Yẹ Ka Máa Yọ̀

Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, a ní ọ̀pọ̀ ìdí láti máa yọ̀. Gbé àwọn tó tẹ̀ lé e wọ̀nyí yẹ̀ wò:

1. A mọ Jèhófà.

2. A ti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run.

3. A lè rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ wa gbà nípasẹ̀ ìgbàgbọ́ nínú ẹbọ Jésù.

4. Ìjọba Ọlọ́run ti ń ṣàkóso—ayé tuntun yóò dé láìpẹ́!

5. Jèhófà ti mú wa wá sínú Párádísè tẹ̀mí.

6. A ń gbádùn ìbákẹ́gbẹ́ Kristẹni tó gbámúṣé.

7. A ní àǹfààní kíkópa nínú iṣẹ́ ìwàásù náà.

8. A wà láàyè, a sì ní okun dé àyè kan.

Àwọn ìdí mìíràn wo tó fi yẹ ká máa yọ lo lè mẹ́nu kàn?

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Pọ́ọ̀lù àti Sílà ń yọ̀ nínú túbú pàápàá

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Ǹjẹ́ o ń wọ̀nà fún ìrètí aláyọ̀ ti ayé tuntun Ọlọ́run?