Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Máa Yọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run Aláyọ̀

Ẹ Máa Yọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run Aláyọ̀

Ẹ Máa Yọ̀ Pẹ̀lú Ọlọ́run Aláyọ̀

“Lákòótán, ẹ̀yin ará, ẹ máa bá a lọ ní yíyọ̀, . . . Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín.”—2 KỌ́RÍŃTÌ 13:11.

1, 2. (a) Kí nídìí tí ọ̀pọ̀ èèyàn ò fi láyọ̀ nínú ìgbésí ayé wọn? (b) Kí ni ayọ̀, báwo la sì ṣe lè ní in?

 Ọ̀PỌ̀ èèyàn ni kò rídìí tó fi yẹ kí wọ́n máa yọ̀ láwọn ọjọ́ búburú wọ̀nyí. Nígbà tí ọ̀ràn ìbànújẹ́ kan bá dé bá wọn, tàbí tó dé bá ẹnì kan tí wọ́n fẹ́ràn, wọ́n lè ní irú ìmọ̀lára tí Jóòbù ìgbàanì ní, ẹni tó sọ pé: “Ènìyàn, tí obìnrin bí, ọlọ́jọ́ kúkúrú ni, ó sì kún fún ṣìbáṣìbo.” (Jóòbù 14:1) Àwọn Kristẹni kò bọ́ lọ́wọ́ másùnmáwo àti pákáǹleke “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò” wọ̀nyí, kò sì yani lẹ́nu pé àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lè rẹ̀wẹ̀sì nígbà mìíràn.—2 Tímótì 3:1.

2 Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn Kristẹni lè máa yọ̀, kódà nígbà tí wọ́n bá wà lábẹ́ àdánwò. (Ìṣe 5:40, 41) Láti lóye bí èyí ṣe lè ṣeé ṣe, kọ́kọ́ gbé ohun tí ayọ̀ jẹ́ yẹ̀ wò ná. A ti túmọ̀ ayọ̀ gẹ́gẹ́ bí “ìmọ̀lára téèyàn máa ń ní nígbà tó bá rí ohun tó dára gbà tàbí nígbà tó bá ń retí ohun tó dáa.” a Lójú ìwòye èyí, táa bá fara balẹ̀ wo ohun tí Ọlọ́run ti ṣe fún wa, táa sì tún ń ṣàṣàrò lórí ayọ̀ tó ń dúró dè wá nínú ayé tuntun Ọlọ́run, a lè máa yọ̀.

3. Ọ̀nà wo la fi lè sọ pé olúkúlùkù ló ní ìdí tó fi yẹ kó máa yọ̀?

3 Kò sẹ́ni tí kò ní ohun tó yẹ kó tìtorí rẹ̀ máa dúpẹ́. Iṣẹ́ lè bọ́ lọ́wọ́ olórí ìdílé kan. Gẹ́gẹ́ bí ìwà ẹ̀dá, ó lè bẹ̀rẹ̀ sí ṣàníyàn. Ó fẹ́ pèsè fún àwọn olólùfẹ́ rẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, tí ara rẹ̀ bá le, tí kò sí àìsàn kankan lára rẹ̀, ó yẹ kó máa dúpẹ́ fún ìyẹn. Nítorí pé nígbà tó bá ríṣẹ́ á láǹfààní àtifi gbogbo agbára rẹ̀ ṣe é. Ní ọwọ́ kejì ẹ̀wẹ̀, àìsàn tí ń sọni di hẹ́gẹhẹ̀gẹ lè ṣàdédé kọlu Kristẹni obìnrin kan. Síbẹ̀, ó lè máa dúpẹ́ fún ìtìlẹ́yìn àwọn ọ̀rẹ́ àtàwọn mẹ́ńbà ìdílé tó nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, tí wọ́n sì ń ràn án lọ́wọ́ láti kojú àìsàn náà láìbarajẹ́. Gbogbo Kristẹni tòótọ́ lè máa yọ̀, láìka ipòkípò tí wọ́n wà sí, nítorí àǹfààní tí wọ́n ní láti mọ Jèhófà, “Ọlọ́run aláyọ̀,” àti Jésù Kristi, “aláyọ̀ àti Ọba Alágbára Gíga kan ṣoṣo náà.” (1 Tímótì 1:11; 6:15) Bẹ́ẹ̀ ni o, inú Jèhófà Ọlọ́run àti ti Jésù Kristi ń dùn lọ́nà tó ga lọ́lá. Wọn kò jẹ́ kí ohunkóhun ba ayọ̀ àwọn jẹ́, bó tilẹ̀ jẹ́ pé bí ipò nǹkan ṣe rí lórí ilẹ̀ ayé yàtọ̀ pátápátá sí bí Jèhófà ṣe fẹ́ kó rí níbẹ̀rẹ̀. Àpẹẹrẹ wọ́n lè kọ́ wa ní ohun púpọ̀ nípa bí a kò ṣe ní jẹ́ kí ayọ̀ wa fò lọ.

Kò Sígbà Kan Tí Wọn Kò Láyọ̀ Rí

4, 5. (a) Kí ni Jèhófà ṣe nígbà tí àwọn ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́ ṣọ̀tẹ̀? (b) Ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà fi ẹ̀mí tó dára hàn sí ìran ènìyàn?

4 Ádámù àti Éfà ní ìlera pípé àti èrò inú tó yè kooro nígbà tí wọ́n wà nínú ọgbà Édẹ́nì. Iṣẹ́ tó ṣàǹfààní ni wọ́n ń ṣe, wọ́n sì ń ṣe é ní àyíká tó dára. Lékè gbogbo rẹ̀, wọ́n ní àǹfààní láti máa bá Jèhófà sọ̀rọ̀ déédéé. Ète Ọlọ́run ni pé kí wọ́n ní ọjọ́ ọ̀la aláyọ̀. Àmọ́, gbogbo ẹ̀bùn rere wọ̀nyí kò tẹ́ àwọn òbí wa àkọ́kọ́ lọ́rùn; wọ́n jí èso táa kà léèwọ̀ náà láti orí “igi ìmọ̀ rere àti búburú.” Àìgbọràn wọn yìí ló pilẹ̀ gbogbo àìláyọ̀ tí àwa, táa jẹ́ àtọmọdọ́mọ wọn ń nírìírí rẹ̀ lónìí.—Jẹ́nẹ́sísì 2:15-17; 3:6; Róòmù 5:12.

5 Àmọ́, Jèhófà kò jẹ́ kí ìwà àìmoore tí Ádámù àti Éfà hù yìí sọ òun di ẹni tí kò láyọ̀. Ó dá a lójú pé ọkàn àwọn kan lára àwọn àtọmọdọ́mọ wọn yóò sún wọn láti sin òun. Àní èyí dá a lójú débi pé kí Ádámù àti Éfà tó bí àkọ́bí ọmọ wọn pàápàá ló ti kéde ète rẹ̀ láti ra àwọn onígbọràn tó jẹ́ àtọmọdọ́mọ wọn padà! (Jẹ́nẹ́sísì 1:31; 3:15) Ní àwọn ọ̀rúndún tó tẹ̀ lé e, èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ìràn ènìyàn ló tẹ̀ lé ìṣísẹ̀ Ádámù àti Éfà, àmọ́ Jèhófà kò tìtorí ìyẹn kọ ìdílé aráyé sílẹ̀ nítorí àìgbọràn tó gbòde kan. Kàkà bẹ́ẹ̀, ó kúkú darí àfiyèsí rẹ̀ sí àwọn ọkùnrin àtàwọn obìnrin tí wọ́n ‘mú ọkàn-àyà rẹ̀ yọ̀,’ ìyẹn àwọn tí wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn láti wù ú, nítorí pé wọ́n nífẹ̀ẹ́ rẹ̀.—Òwe 27:11; Hébérù 6:10.

6, 7. Àwọn kókó wo ló ran Jésù lọ́wọ́ láti máa ní ayọ̀ nìṣó?

6 Jésù náà ńkọ́—báwo ni ayọ̀ rẹ̀ kò ṣe yingin? Gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí alágbára ní ọ̀run, Jésù ní àǹfààní tó pọ̀ láti kíyè sí ìgbòkègbodò tọkùnrin tobìnrin lórí ilẹ̀ ayé. Àìpé wọn kò fara sin rárá, síbẹ̀ Jésù nífẹ̀ẹ́ wọn. (Òwe 8:31) Níkẹyìn, nígbà tó wá sórí ilẹ̀ ayé, tó sì “gbé láàárín” àwọn ènìyàn, ojú tó fi ń wo ọmọ aráyé kò yí padà. (Jòhánù 1:14) Kí ló mú kó ṣeé ṣe fún ọmọ pípé ti Ọlọ́run láti ní èrò tó dára nípa ìdílé ènìyàn ẹlẹ́ṣẹ̀?

7 Lákọ̀ọ́kọ́ ná, Jésù kò retí ohun tó ga jù látọ̀dọ̀ ara rẹ̀ àti látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíràn. Ó mọ̀ pé òun ò lè yí gbogbo ayé padà. (Mátíù 10:32-39) Nítorí náà, inú rẹ̀ máa ń dùn nígbà tí ẹnì kan tó jẹ́ olóòótọ́ ọkàn bá tẹ́wọ́ gba ìhìn Ìjọba náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwà àti ìṣe àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ máa ń kù díẹ̀ káàtó nígbà mìíràn, Jésù mọ̀ pé nínú ọkàn wọn lọ́hùn-ún, wọ́n fẹ́ ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run lóòótọ́, ó sì nífẹ̀ẹ́ wọn fún ìdí yìí. (Lúùkù 9:46; 22:24, 28-32, 60-62) Lọ́nà tó gbàfiyèsí, nígbà tí Jésù ń gbàdúrà sí Baba rẹ̀ ọ̀run, ó ṣàlàyé ọ̀nà rere tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn òun ti tọ̀ títí di àkókò yẹn, ó ní: “Wọ́n sì ti pa ọ̀rọ̀ rẹ̀ mọ́.”—Jòhánù 17:6.

8. Dárúkọ àwọn ọ̀nà bíi mélòó kan táa fi lè fara wé Jèhófà àti Jésù nígbà tó bá kan ọ̀ràn nípa bí ayọ̀ wa kò ṣe ní yingin?

8 Láìsí àní-àní, gbogbo wa ló máa jàǹfààní nínú gbígbé àpẹẹrẹ tí Jèhófà Ọlọ́run àti Jésù Kristi fi lélẹ̀ yẹ̀ wò nínú ọ̀ràn yìí. Ǹjẹ́ a lè túbọ̀ fara wé Jèhófà bóyá nípa ṣíṣàì jẹ́ kí ara wa máa bù máṣọ nígbà tí nǹkan kò bá rí bí a ṣe fọkàn sí i gẹ́lẹ́? Ǹjẹ́ a lè túbọ̀ tẹ̀ lé àwọn ìṣísẹ̀ Jésù pẹ́kípẹ́kí nípa níní èrò tó dára nípa ipò táa wà báyìí, ká má sì máa gbé ohun tó ga jù ka iwájú ara wa àti àwọn ẹlòmíràn? Ẹ jẹ́ ká wo bí a ṣe lè mú lára àwọn ìlànà wọ̀nyí lò lọ́nà tó gbéṣẹ́ nínú apá tó ṣe pàtàkì lọ́kàn àwọn Kristẹni onítara níbi gbogbo—ìyẹn iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá.

Ní Èrò Tó Dára Nípa Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Náà

9. Báwo ni Jeremáyà ṣe jèrè ayọ̀ rẹ̀ padà, báwo sì ni àpẹẹrẹ rẹ̀ ṣe lè ràn wá lọ́wọ́?

9 Jèhófà fẹ́ ká máa láyọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn òun. Ayọ̀ wa kò gbọ́dọ̀ sinmi lórí kìkì àṣeyọrí táa bá ṣe. (Lúùkù 10:17, 20) Ọ̀pọ̀ ọdún ni wòlíì Jeremáyà fi wàásù ní ìpínlẹ̀ tí kò méso jáde. Ìgbà tó ń ronú ṣáá nípa bí àwọn èèyàn náà ṣe ń ṣàtakò ló di ẹni tí kò láyọ̀ mọ́. (Jeremáyà 20:8) Àmọ́, ìgbà tó wá ń ronú nípa bí iṣẹ́ ọ̀hún fúnra rẹ̀ ṣe dùn tó ni inú rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ wá dùn. Jeremáyà sọ fún Jèhófà pé: “A rí ọ̀rọ̀ rẹ, mo sì bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́; ọ̀rọ̀ rẹ sì di ayọ̀ ńláǹlà àti ayọ̀ yíyọ̀ ọkàn-àyà mi; nítorí a ti fi orúkọ rẹ pè mí, Jèhófà.” (Jeremáyà 15:16) Bó ṣe rí nìyẹn o, Jeremáyà yọ̀ nítorí àǹfààní tó ní láti wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwa náà lè ṣe bẹ́ẹ̀.

10. Báwo la ṣe lè máa ní ayọ̀ nìṣó nínú iṣẹ́ ìsìn náà, kódà bí ìpínlẹ̀ wa kò tilẹ̀ méso jáde báyìí?

10 Kódà bí ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn tiẹ̀ kọ̀ láti fetí sí ìhìn rere náà, ìdí wà fún wa láti máa yọ̀ báa ṣe ń kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Rántí pé ó dá Jèhófà lójú gbangba pé àwọn èèyàn kan yóò máa sin òun tọkàntọkàn. Bíi ti Jèhófà, a ò gbọ́dọ̀ sọ̀rètí nù láé pé bópẹ́ bóyá, ó kéré tán ọ̀ràn tó wà nílẹ̀ yóò wá yé àwọn kan, wọn á sì tẹ́wọ́ gba ìhìn Ìjọba náà. A ò sì gbọ́dọ̀ gbàgbé pé ipò àwọn èèyàn máa ń yí padà. Nígbà tí àjálù tàbí wàhálà bá dé lójijì, kódà ẹni tí nǹkan ṣẹnu re fún jù lọ pàápàá lè bẹ̀rẹ̀ sí ronú gan-an nípa ohun tí ìgbésí ayé túmọ̀ sí. Ṣé wàá wà níbẹ̀ láti ṣèrànwọ́ nígbà tí irú ẹni bẹ́ẹ̀ bá di ẹni tí ‘àìní rẹ̀ nípa tẹ̀mí ń jẹ lọ́kàn’? (Mátíù 5:3) Àní, ẹnì kan ní ìpínlẹ̀ rẹ ti lè múra tán láti fetí sí ìhìn rere náà nígbà mìíràn tóo bá padà débẹ̀!

11, 12. Kí ló ṣẹlẹ̀ ní ìlú kan, ẹ̀kọ́ wo la sì rí kọ́ níbẹ̀?

11 Bí ìpínlẹ̀ wa ṣe rí pàápàá lè yí padà. Gbé àpẹẹrẹ kan yẹ̀ wò. Àwùjọ àwọn ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ tọkọtaya tí wọ́n jọ máa ń ṣe nǹkan pọ̀, tí wọ́n sì láwọn ọmọ kéékèèké ń gbé ní ìlú kékeré kan. Nígbà táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bá ti wá síbẹ̀, ohun tí wọ́n máa ń gbọ́ lẹ́nu ilẹ̀kùn gbogbo tí wọ́n bá kàn ni pé, “A ò fẹ́ gbọ́!” Bí ẹnì kan bá tiẹ̀ fìfẹ́ hàn sí ìhìn Ìjọba náà, kíákíá làwọn aládùúgbò máa sọ fún un pé kò tún gbọ́dọ̀ fetí sí àwọn Ẹlẹ́rìí mọ́. Ó hàn gbangba pé ìṣòro ńlá ló jẹ́ láti wàásù níbẹ̀. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn Ẹlẹ́rìí náà kò juwọ́ sílẹ̀; wọ́n ń bá iṣẹ́ ìwàásù wọn nìṣó. Kí wá ni àbájáde rẹ̀?

12 Bí àkókò ti ń lọ, ọ̀pọ̀ lára àwọn ọmọ wọn dàgbà, wọ́n gbéyàwó, wọ́n sì ń gbé níbẹ̀. Nígbà tí wọ́n wá rí i pé ọ̀nà ìgbésí ayé àwọn kò fún wọn ní ojúlówó ayọ̀, àwọn kan lára àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ dàgbà wọ̀nyí bẹ̀rẹ̀ sí wá òtítọ́ kiri. Wọ́n sì rí i nígbà tí wọ́n fetí sí ìhìn rere táwọn Ẹlẹ́rìí ń kéde rẹ̀. Tó fi wá ṣẹlẹ̀ pé lẹ́yìn ọ̀pọ̀ ọdún, ìjọ kékeré náà bẹ̀rẹ̀ sí ní ìbísí. Fojú inú wo bí ayọ̀ àwọn akéde Ìjọba náà, tí wọn kò juwọ́ sílẹ̀ ṣe máa pọ̀ tó! Ǹjẹ́ kí ṣíṣàì juwọ́ sílẹ̀ nínú wíwàásù ìhìn Ìjọba ológo náà máa fún àwa náà láyọ̀!

Àwọn Onígbàgbọ́ Ẹlẹgbẹ́ Rẹ Yóò Tì Ọ́ Lẹ́yìn

13. Ta ni a lè yíjú sí nígbà tí a bá ní ìrẹ̀wẹ̀sì?

13 Nígbà tí pákáǹleke bá dé, tàbí tí ìṣòro kan bá ń fòòró ẹ̀mí ẹ, ibo lo lè yíjú sí fún ìtùnú? Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà tó ti ya ara wọn sí mímọ́ ló kọ́kọ́ máa ń yíjú sí Jèhófà nínú àdúrà, lẹ́yìn náà wọ́n á wá yíjú sí àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wọn. Jésù alára mọyì ìtìlẹ́yìn àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ nígbà tó wà lórí ilẹ̀ ayé. Ní alẹ́ tó ṣáájú ikú rẹ̀, ó pè wọ́n ní àwọn tí ó “ti dúró tì mí gbágbáágbá nínú àwọn àdánwò mi.” (Lúùkù 22:28) Lóòótọ́, àwọn ọmọ ẹ̀yìn wọ̀nyẹn kì í ṣe ẹni pípé, àmọ́ ìdúróṣinṣin wọn jẹ́ ìtùnú fún Ọmọ Ọlọ́run. Àwa náà lè rí okun gbà látọ̀dọ̀ àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa.

14, 15. Kí ló ran tọkọtaya kan lọ́wọ́ láti kojú ikú ọmọkùnrin wọn, ẹ̀kọ́ wo lo sì rí kọ́ nínú ìrírí wọn?

14 Kristẹni tọkọtaya kan tórúkọ wọn ń jẹ́ Michel àti Diane rí bí ìtìlẹ́yìn àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin wọn ṣe níye lórí tó. Àyẹ̀wò fi hàn pé kókó kan wà nínú ọpọlọ Jonathan, ọmọ wọn tó jẹ́ ẹni ogún ọdún, tó sì jẹ́ Kristẹni kan tí ara rẹ̀ yá gágá tó sì ń wọ̀nà fún ọjọ́ ọ̀la tó dára. Àwọn dókítà ṣe gudugudu méje láti gba ẹ̀mí rẹ̀ là, ṣùgbọ́n ńṣe ni àìsàn burúkú tó ń ṣe Jonathan túbọ̀ ń burú sí i títí di ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan, tó fi sùn nínú ikú. Ayé wá sú Michel àti Diane. Wọ́n rí i pé Ìpàdé Iṣẹ́ Ìsìn tí wọ́n máa ń ṣe lálẹ́ ọjọ́ yẹn ti fẹ́rẹ̀ẹ́ parí. Síbẹ̀, nítorí pé wọ́n nílò ìtùnú gan-an, wọ́n ní kí alàgbà tó wà lọ́dọ̀ wọn tẹ̀ lé wọn lọ sí Gbọ̀ngàn Ìjọba. Bí wọ́n ṣe ń fi tó ìjọ létí gẹ́ẹ́ pé Jonathan ti kú ni wọ́n débẹ̀. Bí ìpàdé ṣe ń parí ni àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin pé jọ ti àwọn òbí tó ń da omi lójú pẹ̀rẹ̀pẹ̀rẹ̀ náà, tí wọ́n ń dì mọ́ wọn, tí wọ́n sì ń tù wọ́n nínú. Diane rántí pé: “Ìbànújẹ́ dorí wa kodò nígbà táa dé gbọ̀ngàn náà, àmọ́ ẹ wo ìtùnú táwọn ará fún wa—ẹ wo bí wọ́n ṣe gbé wa ró tó! Bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn ò lè bá wa mú ẹ̀dùn ọkàn wa kúrò, síbẹ̀ wọ́n ràn wá lọ́wọ́ láti fara da ìṣòro náà!”—Róòmù 1:11, 12; 1 Kọ́ríńtì 12:21-26.

15 Àjálù mú kí Michel àti Diane túbọ̀ sún mọ́ àwọn arákùnrin wọn. Ó sì tún jẹ́ kí wọ́n túbọ̀ sún mọ́ ara wọn pẹ̀lú. Michel sọ pé: “Mo ti kẹ́kọ̀ọ́ láti túbọ̀ mọyì aya mi ọ̀wọ́n. Láwọn àkókò táa bá rẹ̀wẹ̀sì, a máa ń bá ara wa sọ̀rọ̀ nípa òtítọ́ Bíbélì àti bí Jèhófà ṣe mẹ́sẹ̀ wa dúró.” Diane fi kún un pé: “Ìsinsìnyí gan-an ní ìrètí Ìjọba náà wá nítumọ̀ gidi sí wa.”

16. Èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì láti jẹ́ kí àwọn arákùnrin wa mọ àwọn àìní wa?

16 Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin wa lè jẹ́ “àrànṣe afúnnilókun” fún wa láwọn àkókò ìṣòro, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ ràn wá lọ́wọ́ láti má pàdánù ayọ̀ wa. (Kólósè 4:11) Àmọ́ wọn ò lè mọ ohun tó wà lọ́kàn wa. Nítorí náà, ó dáa ká máa jẹ́ kí wọ́n mọ̀ nígbà táa bá nílò ìtìlẹ́yìn wọn. A sì wá lè fi ìmọrírì jíjinlẹ̀ hàn fún ìtùnú tí àwọn arákùnrin wa bá fún wa, a ó wò ó bí ẹni pé ọ̀dọ̀ Jèhófà ló ti wá.—Òwe 12:25; 17:17.

Wo Inú Ìjọ Rẹ

17. Àwọn ìpèníjà wo ni ìyá kan tó jẹ́ anìkàntọ́mọ ń dojú kọ, ojú wo la sì fi ń wo irú àwọn èèyàn bíi tirẹ̀?

17 Bí o bá ṣe túbọ̀ fara balẹ̀ kíyè sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ tó, lo ṣe máa túbọ̀ mọyì wọn, tí wàá sí máa láyọ̀ nínú bíbá wọn kẹ́gbẹ́. Wo inú ìjọ rẹ. Kí lo rí? Ǹjẹ́ o rí òbí anìkàntọ́mọ tó ń tiraka láti tọ́ àwọn ọmọ rẹ̀ dàgbà ní ọ̀nà òtítọ́? Ǹjẹ́ o ti ronú lórí àpẹẹrẹ rere tó ń fi lélẹ̀? Gbìyànjú láti fojú inú wo díẹ̀ lára àwọn ìṣòro tó ń dojú kọ. Ìyá kan tó jẹ́ òbí anìkàntọ́mọ mẹ́nu kan díẹ̀ lára ìwọ̀nyí: ìnìkanwà, kí àwọn ọkùnrin máa fi ìbálòpọ̀ lọni níbi iṣẹ́, ṣíṣọ́ owó ná gan-an. Ó wá sọ pé èyí tó ga ju gbogbo rẹ̀ lọ ni ti bíbójútó ìmọ̀lára àwọn ọmọ òun, níwọ̀n bó ti jẹ́ pé ọmọ kọ̀ọ̀kan ló ní ìmọ̀lára tirẹ̀. Jeanine tún mẹ́nu kan ìṣòro mìíràn, ó ní: “Ó lè jẹ́ ìpèníjà gidi láti yẹra fún èrò náà pé kí o fi ọmọkùnrin rẹ̀ ṣe olórí ìdílé kí ó bàa lè dí ipò tó yẹ kí ọkọ wà. Mo ní ọmọbìnrin kan, ó sì máa ń ṣòro fún mi láti rántí pé kò yẹ kí n di ẹrù ìṣòro mi rù ú nípa fífi í ṣe alábàárò mi.” Bíi ti ẹgbẹẹgbẹ̀rún àwọn òbí anìkàntọ́mọ tó jẹ́ olùbẹ̀rù Ọlọ́run, Jeanine ń ṣiṣẹ́ látàárọ̀ ṣúlẹ̀, ó sì ń gbọ́ bùkátà agbo ilé rẹ̀. Ó tún máa ń fi Bíbélì kọ́ àwọn ọmọ rẹ̀, ó ń kó wọn lọ sóde ẹ̀rí, ó sì ń mú wọn wá sí àwọn ìpàdé ìjọ. (Éfésù 6:4) Ẹ ò rí i bí inú Jèhófà ṣe máa dùn tó bó ṣe ń fi ojoojúmọ́ kíyè sí ìsapá tí ìdílé yìí ń ṣe láti pa ìwà títọ́ mọ́! Ǹjẹ́ inú wa ò dùn pé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ wà láàárín wa? Inú wa dùn gan-an ni o.

18, 19. Ṣàpèjúwe báa ṣe lè túbọ̀ fi hàn pé a mọyì àwọn mẹ́ńbà ìjọ sí i.

18 Tún wo inú ìjọ rẹ lẹ́ẹ̀kan sí i. O lè rí àwọn opó tàbí àwọn ọkùnrin tí aya wọ́n ti kú tí wọn “kì í pa” ìpàdé “jẹ.” (Lúùkù 2:37) Ǹjẹ́ wọ́n máa ń wà láwọn nìkan nígbà mìíràn? Bẹ́ẹ̀ ni o. Wọn a máa ronú nípa ẹnì kejì wọn gan-an ni! Ṣùgbọ́n wọ́n ń jẹ́ kí ọwọ́ wọn dí nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, wọ́n sì ní ìfẹ́ sí àwọn ẹlòmíràn. Ẹ̀mí rere tí wọ́n ní, tí wọ́n sì ń bá a lọ bẹ́ẹ̀ ń fi kún ayọ̀ ìjọ! Kristẹni kan tó ti sìn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún fún ohun tó lé ní ọgbọ̀n ọdún sọ pé: “Ọ̀kan lára ohun tó máa ń fún mi láyọ̀ jù lọ ni rírí tí mò ń rí àwọn àgbà ọkùnrin àtàwọn àgbà obìnrin tí wọ́n ti la ọ̀pọ̀ àdánwò kọjá, síbẹ̀ tí wọ́n ṣì ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà!” Bẹ́ẹ̀ ni o, ìṣírí ńlá ni àwọn Kristẹni tó ti dàgbà láàárín wa jẹ́ fún àwọn tí kò dàgbà tó wọn.

19 Àwọn ẹni tuntun tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ ìjọ ńkọ́? Ǹjẹ́ orí wa kì í wú nígbà tí wọ́n bá ń sọ ohun tí wọ́n gbà gbọ́ jáde láwọn ìpàdé? Ronú nípa bí wọ́n ti ṣe ń tẹ̀ síwájú látìgbà tí wọ́n ti bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Wọ́n ti ní láti mú inú Jèhófà dùn gan-an. Àwa náà ńkọ́? Ǹjẹ́ a máa ń fi hàn pé inú wa dùn sí wọn, nípa yíyìn wọ́n fún ìsapá wọn?

20. Èé ṣe táa fi lè sọ pé mẹ́ńbà ìjọ kọ̀ọ̀kan ló ń kó ipa pàtàkì nínú ìjọ?

20 Ṣé o ti gbéyàwó, àbí àpọ́n ni ọ́, tàbí òbí anìkàntọ́mọ? Ṣé ọmọ aláìníbaba (tàbí aláìní ìyá) ni ọ́, ṣé opó ni ọ́ ni, tàbí ọkùnrin tí aya rẹ̀ ti kú? Ṣé ó ti pẹ́ tó ti ń dara pọ̀ mọ́ ìjọ, àbí o ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ ni? Mọ̀ dájú pé àpẹẹrẹ ìṣòtítọ́ rẹ ń fún gbogbo wa níṣìírí. Nígbà tóo bá sì kópa nínú kíkọrin Ìjọba náà, nígbà tóo bá ń dáhùn tàbí tóo ṣe iṣẹ́ akẹ́kọ̀ọ́ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìṣàkóso Ọlọ́run, ipa tí o ń kó ń fi kún ayọ̀ wa. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ó ń mú ọkàn Jèhófà yọ̀.

21. Kí la ní ọ̀pọ̀ ìdí láti ṣe, àmọ́ àwọn ìbéèrè wo ló dìde?

21 Bẹ́ẹ̀ ni o, kódà ní àkókò búburú yìí, a lè láyọ̀ nínú jíjọ́sìn Ọlọ́run wa aláyọ̀. Ìdí púpọ̀ ló wà fún wa láti tẹ́wọ́ gba ìṣírí tí Pọ́ọ̀lù fúnni pé: “Ẹ máa bá a lọ ní yíyọ̀, . . . Ọlọ́run ìfẹ́ àti àlàáfíà yóò sì wà pẹ̀lú yín.” (2 Kọ́ríńtì 13:11) Tó bá wá ṣẹlẹ̀ pé àjálù kan dé bá wa ńkọ́, tàbí inúnibíni, tàbí kí ọ̀nà àtijẹ àtimu di èyí tí kò rọgbọ mọ́ rárá? Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe ká ṣì máa ní ayọ̀ lábẹ́ irú ipò bẹ́ẹ̀? Dáhùn àwọn ìbéèrè náà fúnra rẹ bí o ṣe ń gbé àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yẹ̀ wò.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Wo ìwé Insight on the Scriptures, Apá Kejì, ojú ìwé 119, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.

Ṣé O Lè Dáhùn?

• Báwo la ṣe ṣàpèjúwe ayọ̀?

• Báwo ni níní ẹ̀mí tó dára ṣe lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa yọ̀?

• Kí ló lè ràn wá lọ́wọ́ láti ní èrò tó dára nípa ìpínlẹ̀ ìjọ wa?

• Àwọn ọ̀nà wo lo gbà mọyì àwọn arákùnrin àtàwọn arábìnrin tó wà nínú ìjọ rẹ?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Àwọn èèyàn tó wà ní ìpínlẹ̀ wa lè yí padà

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12]

Àwọn ìpèníjà wo làwọn tó wà nínú ìjọ rẹ dojú kọ?