Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Mú Ẹ̀gàn Kúrò Lórí Orúkọ Ọlọ́run

A Mú Ẹ̀gàn Kúrò Lórí Orúkọ Ọlọ́run

Àwọn Olùpòkìkí Ìjọba Ròyìn

A Mú Ẹ̀gàn Kúrò Lórí Orúkọ Ọlọ́run

BÍBÉLÌ, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, sọ pé: “Ẹ tọ́jú ìwà yín kí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ láàárín àwọn orílẹ̀-èdè, pé, nínú ohun náà tí wọ́n ti ń sọ̀rọ̀ lòdì sí yín gẹ́gẹ́ bí aṣebi, kí wọ́n lè tipa àwọn iṣẹ́ yín àtàtà tí wọ́n fojú rí, yin Ọlọ́run lógo ní ọjọ́ náà fún àbẹ̀wò rẹ̀.” (1 Pétérù 2:12) Nítorí ìdí èyí, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń sapá láti hùwà tó dára, kí wọ́n lè yẹra fún mímú ẹ̀gàn bá orúkọ Jèhófà.

Wọ́n jí rédíò olùkọ́ kan ní ilé rẹ̀ tó wà ní àgbègbè àdádó kan tó ń jẹ́ Senanga ní Zambia. Nítorí pé àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń wàásù lágbègbè yẹn, ọkùnrin náà sọ pé àwọn ló jí i. Ọkùnrin náà fi ọ̀ràn náà tó àwọn ọlọ́pàá létí, pé àwọn Ẹlẹ́rìí ti jí rédíò òun. Kí ó lè fi ẹ̀rí hàn pé àwọn Ẹlẹ́rìí wá sílé òun, ó fi ìwé àṣàrò kúkúrú kan tó rí nílẹ̀ hàn wọ́n. Àmọ́, àwọn ọlọ́pàá kọ̀ láti gbà á gbọ́. Wọ́n ní kó túbọ̀ lọ wádìí ọ̀ràn náà dáadáa.

Ẹgbẹ́ àwọn alàgbà gba àwọn Ẹlẹ́rìí tó ṣiṣẹ́ ládùúgbò tí olùkọ́ náà ń gbé níyànjú láti lọ síbẹ̀, kí wọ́n sì bá olùkọ́ ọ̀hún sọ̀rọ̀ nípa ọ̀ràn náà. Àwọn arákùnrin mélòó kan lọ láti bá a sọ̀rọ̀, wọ́n sì ṣàlàyé pé àwọn fẹ́ mú ẹ̀gàn tó mú bá orúkọ Jèhófà kúrò. Ìgbà tí wọ́n jọ ń jíròrò ni wọ́n sọ fún un pé ọ̀dọ́mọkùnrin kan tí wọ́n bá nílé rẹ̀ làwọn mú ìwé àṣàrò kúkúrú náà fún. Olùkọ́ náà sì mọ ọkùnrin ọ̀hún nígbà tí wọ́n júwe rẹ̀. Àní, ṣọ́ọ̀ṣì kan náà ni wọ́n tiẹ̀ jọ ń lọ. Olùkọ́ náà béèrè lọ́wọ́ ọ̀dọ́mọkùnrin ọ̀hún, àmọ́ ó sẹ́. Olùkọ́ náà wá lọ bá àwọn òbí ọmọkùnrin náà jíròrò ọ̀ràn náà, ó sì padà sílé. Láàárín wákàtí kan, ìyá ọmọkùnrin ọ̀hún dá rédíò tí wọ́n jí náà padà.

Nítorí pé ọ̀rọ̀ náà dun olùkọ́ náà gan-an, ó lọ bá ẹgbẹ́ àwọn alàgbà, ó sì sọ pé kí wọ́n jọ̀wọ́ dárí ji òun nítorí ẹ̀sùn èké tí òun fi kàn wọ́n. Àwọn alàgbà tẹ́wọ́ gba ẹ̀bẹ̀ rẹ̀, àmọ́ wọ́n ní kó jẹ́ kí gbogbo èèyàn mọ bí ọ̀ràn náà ṣe rí, kí wọ́n lè mọ̀ pé àwọn Ẹlẹ́rìí kò mọ ohunkóhun nípa rẹ̀. Wọ́n kéde ọ̀rọ̀ náà nílé ìwé, wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ mú ẹ̀gàn kúrò lórí orúkọ Jèhófà. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lè máa bá a nìṣó ní wíwàásù fàlàlà lágbègbè náà.

[Àwọn àwòrán ilẹ̀/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 19]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

ÁFÍRÍKÀ

Zambia

[Credit Line]

Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.