Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Bíbélì Wà Ní Ìdìpọ̀ Kan Ṣoṣo

Bíbélì Wà Ní Ìdìpọ̀ Kan Ṣoṣo

Bíbélì Wà Ní Ìdìpọ̀ Kan Ṣoṣo

KÍ Ọ̀PỌ̀ ẹ̀dà Bíbélì lè wà, àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ló kọ́kọ́ lo ìwé àfọwọ́kọ alábala—ìwé alábala là ń wí o, kì í ṣe àkájọ ìwé. Àmọ́ kì í ṣe ojú ẹsẹ̀ làwọn Kristẹni bẹ̀rẹ̀ sí di gbogbo ìwé inú Bíbélì pọ̀ sójú kan ṣoṣo. Ọ̀rúndún kẹfà ni Flavius Cassiodorus gbé ìgbésẹ̀ pàtàkì tó jẹ́ kí àwọn Bíbélì onídìpọ̀ kan ṣoṣo tàn kálẹ̀.

Nǹkan bí ọdún 485 sí 490 Sànmánì Tiwa ni wọ́n bí Flavius Magnus Aurelius Cassiodorus, ìdílé tó rí jájẹ ni wọ́n sì bí i sí nílùú Calabria, ní ìpẹ̀kun gúúsù orílẹ̀-èdè Ítálì òde òní. Ó gbé ayé ní sáà rúkèrúdò nínú ìtàn Ítálì, nígbà tí ilẹ̀ tó wà létí omi yìí kọ́kọ́ wà lábẹ́ àwọn táa ń pè ní Goth, àti lẹ́yìn náà lábẹ́ àwọn Byzantine. Nǹkan bí ẹni ọgọ́ta tàbí àádọ́rin ọdún ni Cassiodorus nígbà tó dá ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé ti Vivarium sílẹ̀, ó tún kọ́ ibi ìkówèésí kan sítòsí ilé rẹ̀ ní Squillace, Calabria.

Ọkùnrin Kan Tó Fìṣọ́ra Ṣàdàkọ Bíbélì

Ara ohun tó jẹ Cassiodorus lógún ni bí Bíbélì yóò ṣe tẹ àwọn èèyàn lọ́wọ́. Òpìtàn nì, Peter Brown, kọ̀wé pé: “Bó bá jẹ́ bó ṣe rí lọ́kàn Cassiodorus ni, gbogbo mẹ̀bẹ́mẹ̀yẹ̀ èdè Látìn ló yẹ ní lílò nínú iṣẹ́ mímú kí Ìwé Mímọ́ wà lárọ̀ọ́wọ́tó àwọn èèyàn. Gbogbo ohun tí wọ́n ń lò tẹ́lẹ̀ fún kíkẹ́kọ̀ọ́ àti ṣíṣe àdàkọ àwọn ìwé ìtàn àdììtú ló yẹ ní lílò láti lè lóye Ìwé Mímọ́, kí wọ́n sì dà á kọ lọ́nà tó ṣe kedere. Gẹ́gẹ́ bí àwọn pílánẹ́ẹ̀tì táa ṣẹ̀ṣẹ̀ ṣètò, ńṣe ló yẹ ká lo gbogbo mẹ̀bẹ́mẹ̀yẹ̀ èdè Látìn yípo-yípo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bí àwọn pílánẹ́ẹ̀tì ṣe ń lọ yí po oòrùn títóbi.”

Cassiodorus kó àwọn atúmọ̀ èdè àtàwọn onímọ̀ gírámà jọ sí ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé tó wà ní Vivarium, kí wọ́n lè ṣe àkójọ odindi Bíbélì, òun ló sì darí iṣẹ́ takuntakun ṣíṣe àdàkọ Bíbélì. Ìwọ̀nba àwọn ògbógi díẹ̀ ló gbé iṣẹ́ náà lé lọ́wọ́. Àwọn wọ̀nyí kò gbọ́dọ̀ fi ìwàǹwára ṣàtúnṣe ohunkóhun tó bá jọ àṣìṣe lójú tiwọn. Bí nǹkan kan nípa gírámà bá rú wọn lójú, àwọn Bíbélì àfọwọ́kọ tó ti wà tipẹ́tipẹ́ ni wọ́n gbọ́dọ̀ tẹ̀ lé dípò ìlànà gírámà èdè Látìn. Cassiodorus pàṣẹ pé: “A ò gbọ́dọ̀ sọ pé èdè kan ṣàjèjì . . . ká wá tìtorí ìyẹn mú un kúrò, níwọ̀n bí ọ̀rọ̀ táa mí sí kò ti lè ní àbààwọ́n. . . . A ò gbọ́dọ̀ da ọ̀nà tí Bíbélì gbà gbọ́rọ̀ kalẹ̀ rú, a ò gbọ́dọ̀ yí àfiwé ẹlẹ́lọ̀ọ́ àti àkànlò èdè rẹ̀ padà, àní bí kò bá tilẹ̀ bá ọ̀nà táa gbà ń sọ̀rọ̀ lédè Látìn mu, bẹ́ẹ̀ náà la ò gbọ́dọ̀ yí ọ̀nà táa gba kọ àwọn orúkọ lédè ‘Hébérù’ padà.”—The Cambridge History of the Bible.

Bíbélì Àfọwọ́kọ Alábala Fífẹ̀

Iṣẹ́ tí wọ́n yàn fún àwọn adàwékọ tó wà ní ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé Vivarium ni pé ó kéré tán kí wọ́n ṣàdàkọ ẹ̀dà Bíbélì mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lédè Látìn. Ó jọ pé ọ̀kan lára ìwọ̀nyí, tó jẹ́ ìdìpọ̀ mẹ́sàn-án, ní Bíbélì Èdè Látìn Àtijọ́ nínú, ìtumọ̀ tí wọ́n gbé jáde ní apá ìparí ọ̀rúndún kejì. Ẹ̀dà kejì ni Vulgate lédè Látìn, èyí tí Jerome parí ní nǹkan bí ìbẹ̀rẹ̀ ọ̀rúndún karùn-ún. Ẹ̀kẹta ni èyí táa pè ní Bíbélì Àfọwọ́kọ Alábala Fífẹ̀, tó túmọ̀ sí “ìwé àfọwọ́kọ alábala tó tóbi,” èyí tí wọ́n kó jọ látinú Bíbélì mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀. Àwọn ẹ̀dà méjèèjì táa mẹ́nu kàn gbẹ̀yìn yìí fi gbogbo ìwé Bíbélì ṣe ìdìpọ̀ kan ṣoṣo.

Ó jọ pé Cassiodorus lẹni àkọ́kọ́ tó mú àwọn Bíbélì èdè Látìn jáde ní ìdìpọ̀ kan ṣoṣo, tó sì pè wọ́n ní pandectae. a Láìsí àní-àní, ó rí i pé ó bọ́gbọ́n mu pé kí gbogbo ìwé Bíbélì jẹ́ ìdìpọ̀ kan ṣoṣo, kéèyàn lè bọ́ lọ́wọ́ fífàkókò ṣòfò nídìí ṣíṣí ọ̀kan-ò-jọ̀kan ìdìpọ̀.

Láti Gúúsù Ítálì Dé Àwọn Erékùṣù Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì

Láìpẹ́ lẹ́yìn ikú Cassiodorus (bóyá ní nǹkan bí ọdún 583 Sànmánì Tiwa), ni ìrìn àjò Bíbélì Àfọwọ́kọ Alábala Fífẹ̀ bẹ̀rẹ̀. A gbọ́ pé nígbà yẹn ni wọ́n kó lára ìwé tó wà ní Vivarium lọ síbi ìkówèésí Lateran ní Róòmù. Ní ọdún 678 Sànmánì Tiwa, ọ̀gbẹ́ni Ceolfrith, tó jẹ́ olórí ilé àwọn ajẹ́jẹ̀ẹ́ ìsìn, ẹni tí í ṣe ọmọ ilẹ̀ Jámánì tó wá tẹ̀ dó sí ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ló mú Bíbélì yìí dání wá sí àwọn Erékùṣù Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì nígbà tó ń darí bọ̀ wálé láti Róòmù. Báyìí ni Bíbélì náà ṣe dé ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàngbé méjì, èyí tó wà nílùú Wearmouth àti ti Jarrow, tó wà ní ibi táa ń pè ní Northumbria báyìí ní Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, àwọn méjèèjì wà lábẹ́ ìdarí Ceolfrith nígbà yẹn.

Ó dájú pé Bíbélì Cassiodorus tó jẹ́ ìdìpọ̀ kan ṣoṣo wu Ceolfrith àtàwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ tó jẹ́ ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàngbé, pàápàá jù lọ nítorí pé ó rọrùn-ún lò. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé lẹ́yìn ẹ̀wádún díẹ̀ péré, wọ́n ṣe àdàkọ odindi Bíbélì mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ sí ìdìpọ̀ kọ̀ọ̀kan. Ọ̀kan ṣoṣo tó ṣẹ́ kù lára ẹ̀dà ìpilẹ̀ṣẹ̀ wọ̀nyí ni Bíbélì àfọwọ́kọ gbẹ̀ǹgbẹ̀ kan tí wọ́n pè ní Bíbélì Àfọwọ́kọ Alábala ti Amiatinus. Ó ní ẹgbẹ̀rún méjì ó lé ọgọ́ta [2060] ojú ìwé táa fi awọ àgùntàn ṣe, ojú ìwé kọ̀ọ̀kan sì jẹ́ nǹkan bíi sẹ̀ǹtímítà mọ́kànléláàádọ́ta níbùú àti sẹ̀ǹtímítà mẹ́tàlélọ́gbọ̀n lóròó. Pẹ̀lú èèpo táa fi bò ó lẹ́yìn, ó nípọn tó sẹ̀ǹtímítà mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n, ìwọ̀n rẹ̀ sì lé ní kìlógíráàmù mẹ́rìnlélọ́gbọ̀n. Èyí ni Bíbélì èdè Látìn onídìpọ̀ kan ṣoṣo tó lọ́jọ́ lórí jù lọ tó ṣì wà lárọ̀ọ́wọ́tó. Gbajúmọ̀ onímọ̀ nípa Bíbélì ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún nì, Fenton J. A. Hort, ló fi Bíbélì àfọwọ́kọ alábala náà hàn sójú táyé lọ́dún 1887. Hort sọ pé: “Àní [Bíbélì àfọwọ́kọ] àrà ọ̀tọ̀ yìí kò ní ṣàìjẹ́ ìyàlẹ́nu ńláǹlà fún ẹni tó ń gbé láyé ní ọ̀rúndún kọkàndínlógún yìí pàápàá.”

Ó Padà sí Ítálì

Bíbélì Àfọwọ́kọ Alábala Fífẹ̀ tí Cassiodorus ṣàdàkọ rẹ̀ gan-an ti sọnù báyìí. Àmọ́ Bíbélì Àfọwọ́kọ Alábala ti Amiatinus, tí àwọn ará Jámánì tó wá tẹ̀ dó sí Ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì kọ lédè Látìn lẹ́yìn àkókò náà, gbéra padà wá sí Ítálì láìpẹ́ lẹ́yìn tí wọ́n parí rẹ̀. Kété ṣáájú ikú Ceolfrith, ó pinnu pé òun máa padà sí Róòmù. Ó mú ọ̀kan lára Bíbélì mẹ́ta tó fọwọ́ kọ lédè Látìn dání gẹ́gẹ́ bí ẹ̀bùn fún Póòpù Gregory Kejì. Ẹnu ìrìn àjò yẹn ni Ceolfrith wà nígbà tó kú lọ́dún 716 Sànmánì Tiwa, ní Langres, nílẹ̀ Faransé. Ṣùgbọ́n àwọn tí wọ́n jọ ń rin ìrìn àjò náà mú Bíbélì náà dání bí wọ́n ti ń bá ìrìn àjò náà lọ. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, wọ́n wá fi Bíbélì àfọwọ́kọ alábala náà sí ibi ìkówèésí ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ anìkàngbé ti Òkè Amiata, ní àárín gbùngbùn Ítálì, ibẹ̀ ló sì ti wá gba orúkọ náà Bíbélì Àfọwọ́kọ Alábala ti Amiatinus. Lọ́dún 1782, wọ́n gbé Bíbélì àfọwọ́kọ náà lọ sí Ibi Ìkówèésí Medicean-Laurentian nílùú Florence, Ítálì, níbi tó ti jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó ṣeyebíye jù lọ níbi ìkówèésí náà.

Báwo ni Bíbélì Àfọwọ́kọ Alábala Fífẹ̀ náà ṣe kàn wá? Láti ìgbà ayé Cassiodorus ni àwọn adàwékọ àtàwọn tẹ̀wétẹ̀wé ti túbọ̀ ń fẹ́ láti máa ṣe àwọn Bíbélì onídìpọ̀ kan ṣoṣo. Títí di òní olónìí, wíwà tí Bíbélì wà ní ìdìpọ̀ kan ṣoṣo ti jẹ́ kó túbọ̀ rọrùn fáwọn èèyàn láti kà, kí wọ́n sì tipa bẹ́ẹ̀ jàǹfààní nínú agbára tó ń sà nínú ìgbésí ayé wọn.—Hébérù 4:12.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a Ó jọ pé odindi Bíbélì lédè Gíríìkì ti dóde láti ọ̀rúndún kẹrin tàbí ìkarùn-ún.

[Àwòrán ilẹ̀ tó wà ní ojú ìwé 29]

(Láti rí bá a ṣe to ọ̀rọ̀ sójú ìwé, wo ìtẹ̀jáde náà gan-an)

Ìrìn Àjò Bíbélì Àfọwọ́kọ Alábala Fífẹ̀

Ilé àwọn ọkùnrin ajẹ́jẹ̀ẹ́ ànìkàngbé ti Vivarium

Róòmù

Jarrow

Wearmouth

Ìrìn Àjò Bíbélì Àfọwọ́kọ Alábala ti Amiatinus

Jarrow

Wearmouth

Òkè Amiata

Florence

[Credit Line]

Mountain High Maps® Copyright © 1997 Digital Wisdom, Inc.

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 30]

Lókè: Bíbélì Àfọwọ́kọ Alábala ti Amiatinus Apá Òsì: Àwòrán Ẹ́sírà nínú Bíbélì Àfọwọ́kọ Alábala ti Amiatinus

[Credit Line]

Biblioteca Medicea Laurenziana, Firenze