“Oore Tí Jèhófà Ṣe fún Mi Mà Pọ̀ O!”
“Oore Tí Jèhófà Ṣe fún Mi Mà Pọ̀ O!”
NÍ ALẸ́ alárinrin kan ní March 1985, tọkùnrin tobìnrin tí ń ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Ìwé Kíkọ ní orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní New York, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ṣe àṣeyẹ pàtàkì kan. Ìgbà yẹn ni Karl F. Klein pé ọgọ́ta ọdún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Arákùnrin Klein fi tọ̀yàyà-tọ̀yàyà sọ pé: “Oore tí Jèhófà ṣe fún mi mà pọ̀ o!” Ó sọ pé ọ̀kan lára ẹsẹ Bíbélì tóun fẹ́ràn jù lọ ni Sáàmù 37:4. Lẹ́yìn náà ló wá fi gìtá olóhùn fífẹ̀ rẹ̀ dá gbogbo àwọn tó wà níbẹ̀ lára yá.
Ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lẹ́yìn náà, Arákùnrin Klein ń ṣiṣẹ́ nìṣó gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára àwọn òǹkọ̀wé, ó sì ń sìn gẹ́gẹ́ bíi mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àmọ́ ní January 3, 2001, lẹ́ni ọdún márùndínlọ́gọ́rùn-ún [95], Karl Klein fi ìṣòtítọ́ parí iṣẹ́ rẹ̀ lórí ilẹ̀ ayé.
Orílẹ̀-èdè Jámánì la ti bí Karl. Ìdílé rẹ̀ ṣí lọ sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, Karl sì dàgbà nítòsí Chicago, Illinois. Nígbà tí Karl ṣì wà ní kékeré lòun àti Ted àbúrò rẹ̀ ọkùnrin ti ní ìfẹ́ jíjinlẹ̀ sí Bíbélì. Karl ṣe batisí lọ́dún 1918, àwọn ohun amóríyá tó sì gbọ́ ní àpéjọpọ̀ kan táwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe lọ́dún 1922 jẹ́ kó nífẹ̀ẹ́ tí kò lópin fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá. Kì í fẹ́ kí ọ̀sẹ̀ kan kọjá láìkópa nínú iṣẹ́ ìwàásù, àní ó ń bá iṣẹ́ ọ̀hún lọ títí di àwọn ọ̀sẹ̀ tó gbẹ̀yìn ìgbésí ayé rẹ̀ pàápàá.
Ọdún 1925 ni Karl di ọ̀kan lára òṣìṣẹ́ orílé iṣẹ́, ó kọ́kọ́ ń ṣiṣẹ́ nídìí ẹ̀rọ ìtẹ̀wé. Ó fẹ́ràn orin gan-an, ọ̀pọ̀ ọdún ló sì fi ń ta gìtá olóhùn fífẹ̀ nínú ẹgbẹ́ akọrin tó máa ń kọrin lórí rédíò táwọn Kristẹni dá sílẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Iṣẹ́ Ìsìn, òun àti T. J. Sullivan tó ń bójú tó ẹ̀ka iṣẹ́ yẹn sì mọwọ́ ara wọn gan-an. Nígbà tó yá, Ted gbéyàwó, òun àti Doris aya rẹ̀ sì tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì ní Puerto Rico.
Àádọ́ta ọdún ni Karl Klein fi ṣiṣẹ́ ní Ẹ̀ka Ìwé Kíkọ, ó sì ṣe bẹbẹ níbẹ̀ nítorí pé ó fẹ́ràn àtimáa ṣe ìwádìí, ó sì ní ìmọ̀ jíjinlẹ̀ nípa Bíbélì. Ní 1963, Karl fẹ́ Margareta, míṣọ́nnárì ará Jámánì kan tó ń sìn ní Bolivia. Pẹ̀lú ìtìlẹyìn onífẹ̀ẹ́ rẹ̀, àgàgà nígbà tí Karl bẹ̀rẹ̀ sí ṣàìsàn, Karl ṣì ń bá a lọ láti ṣiṣẹ́ kódà nígbà tí ọjọ́ orí rẹ̀ ti kọjá ọjọ́ orí tí ọ̀pọ̀ èèyàn ti máa ń fẹ̀yìn tì. Nítorí pé Karl jẹ́ ẹni tí kì í fọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ, tó sì jẹ́ onítara bíi tàwọn olórin, àwọn àsọyé rẹ̀ nínú ìjọ àti ní àpéjọpọ̀ sábà máa ń jẹ́ mánigbàgbé. Láìpẹ́ sígbà ikú rẹ̀, ó darí ìjíròrò ẹ̀kọ́ ojoojúmọ́ láàárọ̀ ọjọ́ kan láàárín ìdílé Bẹ́tẹ́lì ńlá tó wà ní New York, gbogbo wọn ló gbádùn rẹ̀, tí wọ́n sì rí ẹ̀kọ́ kọ́.
Ọ̀pọ̀ àwọn tó ń ka Ilé Ìṣọ́ déédéé yóò rántí ìtàn ìgbésí ayé Arákùnrin Klein, tó jẹ́ ìtàn tó wúni lórí nípa àwọn ìrírí rẹ̀, èyí táa tẹ̀ jáde nínú ẹ̀dà April 15, 1985. Wàá gbádùn kíka ìtàn yẹn tàbí kíkà á ní àkàtúnkà, pàápàá tóo bá rántí pé ẹni tó kọ ìtàn yẹn tún lo ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún sí i gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni olóòótọ́ àti olùfọkànsìn.
Gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ẹni àmì òróró Olúwa, ohun tí Arákùnrin Klein fọkàn fẹ́ jù lọ ni láti bá Kristi jọba ní ọ̀run. A ní ìdí láti gbà gbọ́ pé Jèhófà ti mú ìfẹ́ ọkàn yẹn ṣẹ báyìí.—Lúùkù 22:28-30.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Karl ní 1943 pẹ̀lú T. J. Sullivan àti Ted àti Doris
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]
Karl àti Margareta, October 2000