Títẹ̀síwájú Lọ́nà Jèhófà Ló Ń fún Wa Lókun àti Ayọ̀
Ìtàn Ìgbésí Ayé
Títẹ̀síwájú Lọ́nà Jèhófà Ló Ń fún Wa Lókun àti Ayọ̀
GẸ́GẸ́ BÍ LUIGGI D. VALENTINO ṢE SỌ Ọ́
Jèhófà gbà wá níyànjú pé: “Èyí ni ọ̀nà. Ẹ máa rìn nínú rẹ̀.” (Aísáyà 30:21) Títẹ̀lé ìmọ̀ràn yìí ni góńgó mi látìgbà tí mo ti ṣe batisí ní ọgọ́ta ọdún sẹ́yìn. Ṣáájú ìgbà yẹn ni mo ti gbé góńgó yìí kalẹ̀ nítorí àpẹẹrẹ àwọn òbí mi, àwọn tó ti Ítálì ṣí wá sí ìlú Cleveland, ní Ìpínlẹ̀ Ohio, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, lọ́dún 1921. Ibẹ̀ ni wọ́n ti tọ́ ọmọ mẹ́ta dàgbà—ìyẹn Mike, ẹ̀gbọ́n mi ọkùnrin, àti Lydia, àbúrò mi obìnrin, àtèmi náà.
ÀWỌN òbí mi ṣe onírúurú ẹ̀sìn, ṣùgbọ́n ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, gbogbo rẹ̀ tojú sú wọn, wọ́n sì pa ọ̀ràn ẹ̀sìn tì. Nígbà tó wá dọjọ́ kan ní 1932, bàbá mi ń gbọ́ ètò kan lórí rédíò tí wọ́n ń ṣe lédè Italian. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ló ń ṣe ètò ọ̀hún, bàbá mi sì fẹ́ràn ohun tó gbọ́ gan-an. Ó kọ̀wé béèrè fún ìsọfúnni púpọ̀ sí i, Ẹlẹ́rìí kan tó jẹ́ ará Ítálì láti orílé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, New York, sì wá bẹ̀ wá wò. Lẹ́yìn ìjíròrò alárinrin tó ń bá a lọ títí ilẹ̀ ọjọ́ kejì fi mọ́, ó wá dá àwọn òbí mi lójú pé àwọn ti rí ẹ̀sìn tòótọ́.
Bàbá mi àti màmá mi bẹ̀rẹ̀ sí lọ sí àwọn ìpàdé Kristẹni, wọ́n sì ń fayọ̀ gba àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò sílé wọn. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọmọdé ni mí nígbà yẹn, àwọn ọkùnrin wọ̀nyí máa ń jẹ́ kí n bá wọn lọ sóde ìwàásù, wọ́n sì jẹ́ kí n bẹ̀rẹ̀ sí ronú nípa sísin Jèhófà fún àkókò kíkún. Ọ̀kan lára àwọn olùbẹ̀wò yẹn ni Carey W. Barber, tó
jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí. Láìpẹ́ láìjìnnà, mo ṣe batisí ní February 1941, lẹ́ni ọdún mẹ́rìnlá, nígbà tó sì di 1944, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní Cleveland. Mike àti Lydia pẹ̀lú tẹ́wọ́ gba òtítọ́. Mike sin Jèhófà títí dọjọ́ ikú rẹ̀, Lydia sì tẹ̀ lé ọkọ rẹ̀ fún ọdún méjìdínlọ́gbọ̀n nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ arìnrìn-àjò. Àmọ́ lónìí, wọ́n ń sìn gẹ̀gẹ̀ bí àkànṣe òjíṣẹ́ alákòókò kíkún.Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Jẹ́ Kí N Túbọ̀ Pinnu Láti Tẹ̀ Síwájú
Ní ìbẹ̀rẹ̀ ọdún 1945, mo bá ara mi ní Ọgbà Ẹ̀wọ̀n Ìjọba Àpapọ̀ tó wà nílùú Chillicothe ní Ohio, torí pé ẹ̀rí ọkàn mi tí mo ti fi Bíbélì kọ́ mú kí n ṣègbọràn sí ohun tó wà nínú Aísáyà 2:4, tó sọ pé ká fi idà wa rọ abẹ ohun ìtúlẹ̀. Nígbà kan, ìwọ̀nba díẹ̀ lára àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì táwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde làwọn aláṣẹ ọgbà ẹ̀wọ̀n jẹ́ kó tẹ àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà lẹ́wọ̀n lọ̀wọ́. Ṣùgbọ́n àwọn Ẹlẹ́rìí tó wà nínú ìjọ kan tí ń bẹ nítòsí ṣèrànwọ́. Nígbà míì, wọ́n máa ń kó ìwé díẹ̀ wá sí pápá tó wà nítòsí ọgbà ẹ̀wọ̀n. Tó bá wá di àárọ̀ ọjọ́ kejì, bí wọn ṣe ń kó àwọn ẹlẹ́wọ̀n lọ sẹ́nu iṣẹ́, wọ́n á máa wá ìtẹ̀jade wọ̀nyẹn, wọn á sì dọ́gbọ́n kó wọn wá sínú ọgbà ẹ̀wọ̀n. Ìgbà tí èmi máa fi dé ọgbà ẹ̀wọ̀n náà, wọ́n ti yọ̀ǹda fún wa láti ní ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ púpọ̀ sí i. Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, mo kẹ́kọ̀ọ́ pé a gbọ́dọ̀ máa fojú ribiribi wo oúnjẹ tẹ̀mí tí Jèhófà ń pèsè—mi ò jẹ́ gbàgbé ẹ̀kọ́ yìí títí di báa ti ń wí yìí, ní gbogbo ìgbà tí mo bá gba ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ tàbí Jí! tuntun.
Bí o tilẹ jẹ́ pé wọ́n gbà wá láyè láti máa ṣe àwọn ìpàdé ìjọ lọ́gbà ẹ̀wọ̀n, wọn ò gbà kí àwọn tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí dara pọ̀ mọ́ wa. Àmọ́, àwọn òṣìṣẹ́ ọgbà ẹ̀wọ̀n àtàwọn ẹlẹ́wọ̀n bíi mélòó kan máa ń yọ́ wá, àwọn díẹ̀ lára wọn tiẹ̀ tẹ́wọ́ gba òtítọ́. (Ìṣe 16:30-34) Àwọn ìbẹ̀wò tí Arákùnrin A. H. Macmillan ṣe sọ́dọ̀ wa jẹ́ orísun ìtùnú tí kò lẹ́gbẹ́. Gbogbo ìgbà ló máa ń mú un dá wa lójú pé àkókò táa lò lọ́gbà ẹ̀wọ̀n kò já sásán nítorí pé ṣe ni ó múra wa sílẹ̀ fún àwọn iṣẹ́ tí a óò gbé lé wa lọ́wọ́ lọ́jọ́ iwájú. Ọ̀rọ̀ arákùnrin àgbàlagbà ẹni ọ̀wọ́n yìí wọ̀ mí lọ́kàn gan-an, ó sì jẹ́ kí ìpinnu mi láti máa tọ ọ̀nà Jèhófà nìṣó túbọ̀ lágbára sí i.
Mo Ní Ẹnì Kejì
Ogun Àgbáyé Kejì parí, wọ́n tú wa sílẹ̀ lẹ́wọ̀n, mo sì padà sẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà, ìyẹn iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ṣùgbọ́n bàbá mi kú lọ́dún 1947. Kí n lè gbọ́ bùkátà ìdílé, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ oúnjẹ òòjọ́, mo tún kọ́ ọ̀nà ìtọ́jú tó jẹ mọ́ wíwọ́nilára—iṣẹ́ tó wá wúlò fún mi ní ọgbọ̀n ọdún lẹ́yìn náà ní sáà tí èmi àti ìyàwó mi dojú kọ ìṣòro. Ẹ dákun, ìparí ọ̀rọ̀ ni mo ti lọ mú un jàre. Ẹ jẹ́ kí n kọ́kọ́ sọ fún yín nípa ìyàwó mi.
Bí mo ti wà nínú Gbọ̀ngàn Ìjọba lọ́sàn-án ọjọ́ kan lọ́dún 1949, ni fóònù dún. Mo gbé e, mo sì gbọ́ ohùn dídùn kan tó sọ pé: “Orúkọ mi ni Christine Genchur. Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni mí. Iṣẹ́ ni mo wá wá sí Cleveland, mo sì ń wá ìjọ tí màá dara pọ̀ mọ́.” Gbọ̀ngàn Ìjọba wa jìnnà síbi tó ń gbé, ṣùgbọ́n ohùn rẹ̀ tí mo gbọ́ yẹn wù mí gan-an ni, nítorí náà mo júwe bó ṣe máa dé gbọ̀ngàn wa fún un, mo sì rọ̀ ọ́ pé kó wá lọ́jọ́ Sunday yẹn—èmi ni màá kúkú sọ àsọyé lọ́jọ́ yẹn. Lọ́jọ́ Sunday ọ̀hún, èmi lẹni tó kọ́kọ́ dé Gbọ̀ngàn Ìjọba, ṣùgbọ́n kò sí arábìnrin kankan tó jẹ́ ojú tuntun. Gbogbo bí mo ṣe ń sọ àsọyé ni mo ń wo ẹnu ọ̀nà fẹ̀rẹ̀, àmọ́ kò sẹ́ni tó wọlé. Ní ọjọ́ tó tẹ̀ lé e, mo ké sí i lórí fóònù, ó sì sọ pé ṣe ni òun ò mọ bí òun ṣe máa wọ bọ́ọ̀sì débẹ̀. Ìyẹn ló jẹ́ kí n yọ̀ǹda pé mo ń bọ̀ wá júwe ọ̀nà fún un dáadáa.
Mo wá mọ̀ pé àwọn òbí rẹ̀, tí wọ́n ṣí wá láti Czechoslovakia, ti bẹ̀rẹ̀ sí dara pọ̀ mọ́ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì lẹ́yìn tí wọ́n ka ìwé pẹlẹbẹ náà, Where Are the Dead? Wọ́n sì ṣe batisí lọ́dún 1935. Ní 1938, bàbá Christine di ìránṣẹ́ ẹgbẹ́ (táa ń pè ní alábòójútó olùṣalága báyìí) nínú ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nílùú Clymer, ní Pennsylvania, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, Christine sì ṣe batisí lọ́dún 1947 lẹ́ni ọdún mẹ́rìndínlógún. Kò pẹ́ tí ìfẹ́ òrékelẹ́wà arábìnrin, tó jẹ́ ẹni tẹ̀mí yìí fi kó sí mi lórí. June 24, 1950, la ṣègbéyàwó, látìgbà yẹn sì ni Christine ti jẹ́ aya tó dúró tì mí gbágbáágbá, tó múra tán nígbà gbogbo láti fi ire Òwe 31:10.
Ìjọba Ọlọ́run sípò kìíní. Mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà pé alábàákẹ́gbẹ́ mi tó dáńgájíá yìí gbà pé kí àwa méjèèjì jọ di ọ̀kan.—Ohun Ìyanu Ńlá Kan
November 1, 1951, la bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà pa pọ̀. Ọdún méjì lẹ́yìn náà, nígbà àpéjọpọ̀ kan ní Toledo, Ohio, àwọn Arákùnrin náà, Hugo Riemer àti Albert Schroeder bá àwọn aṣáájú ọ̀nà kan tó nífẹ̀ẹ́ sí iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì sọ̀rọ̀. A wà lára àwùjọ yẹn. Wọ́n fún wa níṣìírí pé ká máa bá iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà wa nìṣó ní Cleveland, ṣùgbọ́n lóṣù tó tẹ̀ lé e gan-an, a rí ohun ìyanu ńlá kan gbà—ìyẹn ni ìkésíni láti wá sí kíláàsì kẹtàlélógún ti Watchtower Bible School of Gilead, tó bẹ̀rẹ̀ ní February 1954!
Báa ti ń wakọ̀ lọ sí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, tó wà ní South Lansing, New York nígbà yẹn, àyà Christine ń já tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi ń sọ fún mi ṣáá pé, “Rọra máa sáré!” Mo wá dá a lóhùn pé, “Christine, báa bá tún rọra rìn ju báa ṣe ń lọ yìí, a ò mà ní kúrò lójú kan mọ́.” Bó ti wù kí ó rí, ọkàn wa balẹ̀ nígbà táa dé ọgbà ilé ẹ̀kọ́ náà. Arákùnrin Nathan Knorr ló kí àwa ọmọ ilé ẹ̀kọ́ káàbọ̀, ó sì mú wa rìn kiri. Ó tún ṣàlàyé báa ṣe lè rọra máa lo omi àti iná mànàmáná, ó tẹnu mọ́ ọn pé ìwà tó dáa ni pé kéèyàn kọ́ ṣíṣún nǹkan lò, pàápàá jù lọ nígbà táa bá ń bójú tó ire Ìjọba náà. Ìmọ̀ràn yẹn wọ̀ wá lọ́kàn ṣinṣin. A ṣì ń tẹ̀ lé e dòní.
A Wọ Ọkọ̀ Òfuurufú Lọ Sílùú Rio
Kò pẹ́ táa fi kẹ́kọ̀ọ́ yege, nígbà tó sì di December 10, 1954, a wọ ọkọ̀ òfuurufú nígbà òtútù ní New York City, ara wa sì wà lọ́nà pé ká tètè dé ibi iṣẹ́ wa tuntun nílùú tí oòrùn ti mú gan-an tí wọ́n ń pè ní Rio de Janeiro, lórílẹ̀-èdè Brazil. Tọkọtaya Peter àti Billie Carrbello, táa jọ jẹ́ míṣọ́nnárì, la jọ rìnrìn àjò. Wákàtí mẹ́rìnlélógún ló yẹ kí ìrìn àjò náà gbà, torí pé a óò dúró díẹ̀ ní Puerto Rico, Venezuela, àti Belém ní àríwá Brazil. Àmọ́, nítorí ẹ́ńjìnnì ọkọ̀ òfuurufú náà tó yọnu, wákàtí mẹ́rìndínlógójì kọjá ká tó fojú kan ìlú Rio de Janeiro. Àmọ́, ìlú náà ti lọ wà jù! Ńṣe làwọn iná ìgboro mọ́lẹ̀ rokoṣo bí àwọn dáyámọ́ńdì tí ń tàn yinrin lórí kápẹ́ẹ̀tì dúdú, ìmọ́lẹ̀ òṣùpá tó mọ́lẹ̀ roro sì ràn sórí omi Guanabara Bay.
Àwọn mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì bíi mélòó kan ti ń dúró dè wá ní pápákọ̀ òfuurufú. Lẹ́yìn tí wọ́n kí wa káàbọ̀ tọ̀yàyà-tọ̀yàyà, wọ́n wà wá lọ sí ẹ̀ka iléeṣẹ́, ó sì tó nǹkan bí aago mẹ́ta òru ká tó fẹ̀yìn lélẹ̀. Wákàtí díẹ̀ lẹ́yìn náà ni aago tó ń dún gban-un gban-un jí wa, tó rán wa létí pé ọjọ́ àkọ́kọ́ iṣẹ́ míṣọ́nnárì wa ti bẹ̀rẹ̀!
Ẹ̀kọ́ Àríkọ́gbọ́n Táa Kọ́kọ́ Kọ́
Kò pẹ́ rárá táa fi kọ́ ẹ̀kọ́ àríkọ́gbọ́n pàtàkì kan. A lọ kí ìdílé Ẹlẹ́rìí kan nírọ̀lẹ́ ọjọ́ kan. Nígbà táa fẹ́ máa rìn padà sí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa, ẹni táa lọ kí kò gbà, ó ní, “Rárá o, ẹ ò lè lọ; òjò ń rọ̀,” ó sì rọ̀ wá pé kí á má lọ, ká kúkú sùn mọ́jú. Mo kàn fi ọ̀rọ̀ rẹ̀ rẹ́rìn-ín ni, mo ní: “Òjò máa ń rọ̀ níbi táwa náà ti wá.” Báa ṣe lọ nìyẹn o.
Nítorí àwọn òkè ńláńlá tó yí Rio ká, kíákíá ni omi òjò máa ń gbára jọ, táá sì ṣàn wá sínú ìlú, ó sì máa ń fa omíyalé. Ká tó mọ ohun tó ń ṣẹlẹ̀, a ti bẹ̀rẹ̀ sí wọ́sẹ̀ nínú omi tó dé orúnkún wa. Ìgbà táa fi máa dé itòsí ẹ̀ka iléeṣẹ́ wa, omi ti ń ṣàn gbàrá-gbùrú ní gbogbo ojú títì, ó sì ti mù wá dé àyà. Gbogbo ara wa ló rin gbingbin nígbà táa jàjà dé Bẹ́tẹ́lì. Lọ́jọ́ tó tẹ̀ lé e, Christine ò gbádùn rárá, ibà jẹ̀funjẹ̀fun mú un, ó sì dá a wó fún àkókò gígùn. Láìṣẹ̀ṣẹ̀ máa sọ, gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì tuntun, à bá ti gba ìmọ̀ràn tí àwọn Ẹlẹ́rìí tó jẹ́ ọmọ onílẹ̀ fún wa.
Àwọn Ìgbésẹ̀ Àkọ́kọ́ Nínú Iṣẹ́ Míṣọ́nnárì àti Iṣẹ́ Arìnrìn-Àjò
Lẹ́yìn ìbẹ̀rẹ̀ tí kò bára dé yìí, a fi ìháragàgà bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá wa. Àwọn
ọ̀rọ̀ táa kọ sílẹ̀ lédè Potogí la máa ń kà fún ẹnikẹ́ni táa bá bá pàdé, ó sì jọ pé àwa méjèèjì ò gbọ́ èdè ọ̀hún ju ara wa lọ. Nígbà míì, onílé á sọ fún Christine pé, “Ohun tóo sọ yé mi, ṣùgbọ́n tiẹ̀ ò yé mi,” èmi ni wọ́n ń bá wí yẹn o. Onílé míì á sì sọ fún mi pé, “Mo gbọ́ ọ̀rọ̀ tìẹ, ṣùgbọ́n mi ò gbọ́ tiẹ̀.” Bó tilẹ̀ rí bẹ́ẹ̀, inú wa dùn láti rí àwọn èèyàn tó lé ní ọgọ́rùn-ún tó forúkọ sílẹ̀ pé àwọn fẹ́ máa gba Ilé Ìṣọ́ láàárín ọ̀sẹ̀ díẹ̀ àkọ́kọ́ wọ̀nyẹn. Àní, àwọn mélòó kan lára àwọn táa kọ́ lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ló ṣe batisí láàárín ọdún àkọ́kọ́ táa dé Brazil, èyí sì jẹ́ ká mọ bí iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì yìí yóò ti sèso tó.Láàárín àwọn ọdún 1950, ọ̀pọ̀ ìjọ ní Brazil làwọn alábòójútó àyíká kì í bẹ̀ wò déédéé nítorí pé àwọn arákùnrin tó tóótun láti ṣe iṣẹ́ yìí kò tó nǹkan. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé, bó tiẹ̀ jẹ́ pé mo ṣẹ̀ṣẹ̀ ń kọ́ èdè yẹn ni, tí mi ò sì tíì sọ àsọyé fún gbogbo èèyàn lédè Potogí rí, wọ́n yàn mí sẹ́nu iṣẹ́ àyíká ní ìpínlẹ̀ São Paulo ní 1956.
Níwọ̀n bí ìjọ táa wá bẹ̀ wò kò tíì ní ìbẹ̀wò alábòójútó àyíká fún ọdún méjì, ara gbogbo wọn wà lọ́nà láti gbọ́ àsọyé fún gbogbo ènìyàn. Nígbà tí mo ń múra àsọyé yẹn sílẹ̀, mo gé àwọn ìpínrọ̀ látinú àwọn àpilẹ̀kọ Ilé Ìṣọ́ lédè Potogí, mo sì lẹ̀ wọ́n mọ́ abala bébà. Gbọ̀ngàn Ìjọba kún dẹ́múdẹ́mú lọ́jọ́ Sunday táà ń wí yìí. Kódà àwọn èèyàn jókòó sórí pèpéle, tí wọ́n ń retí kí àsọyé pàtàkì náà bẹ̀rẹ̀. Ni àsọyé, tàbí kí n kúkú sọ pé ìwé kíkà náà, bá bẹ̀rẹ̀ o. Mo ń wòkè lẹ́ẹ̀kọ̀ọ̀kan, ìyàlẹ́nu ló sì jẹ́ fún mi pé kò sẹ́ni tó ń rìn kiri, títí kan àwọn ọmọdé pàápàá. Èmi ni gbogbo wọn tẹjú mọ́. Mo wá ń sọ lọ́kàn ara mi pé: ‘Káì, Valentino, ìwọ náà lò ń da èdè Potogí bolẹ̀ báyìí! Ọ̀rọ̀ rẹ mà kúkú ń wọ àwọn aráabí lára o.’ Ọdún mélòó kan lẹ́yìn náà, nígbà tí mo tún bẹ ìjọ yẹn wò, arákùnrin kan tó wà níbẹ̀ nígbà ìbẹ̀wò àkọ́kọ́ yẹn sọ pé: “Ǹjẹ́ o rántí àsọyé tóo sọ yẹn? A ò gbọ́ áá nínú gbogbo ohun tóo sọ.” Mo jẹ́wọ́ pé èmi alára ò fi bẹ́ẹ̀ lóye àsọyé náà.
Ní ọdún àkọ́kọ́ yẹn nínú iṣẹ́ àyíká, mo sábà máa ń ka Sekaráyà 4:6. Àwọn ọ̀rọ̀ náà, ‘Kì í ṣe nípasẹ̀ agbára, bí kò ṣe nípasẹ̀ ẹ̀mí mi,’ rán mi létí pé ẹ̀mí Jèhófà nìkan ló ń jẹ́ kí iṣẹ́ Ìjọba náà máa tẹ̀ síwájú. Ó sì tẹ̀ síwájú lóòótọ́, láìfi àwọn kùdìẹ̀-kudiẹ wa pè.
Àwọn Ìṣòro àti Ìbùkún Táa Rí
Iṣẹ́ àyíká túmọ̀ sí lílọ jákèjádò orílẹ̀-èdè yẹn pẹ̀lú ríru ẹ̀rọ ìtẹ̀wé, ọ̀pọ̀ páálí ìwé, àwọn àpótí ẹrù, àti àpò ìfàlọ́wọ́ kiri. Ṣe ni Christine máa ń dọ́gbọ́n sí i, ó máa ń kọ nọ́ńbà sáwọn ẹrù wọ̀nyí lára kí a má bàa gbàgbé ìkankan nígbà táa bá ń sáré bọ́ọ́lẹ̀ nínú bọ́ọ̀sì kan láti wọ òmíràn. Ọ̀pọ̀ ìgbà la máa ń rin ìrìn àjò wákàtí mẹ́ẹ̀ẹ́dógún nínú bọ́ọ̀sì lójú ọ̀nà eléruku ká tó dé ibi tí à ń lọ. Nígbà míì, àyà wa a sì já pàrà, àgàgà nígbà tí bọ́ọ̀sì méjì bá dojú kọ ara wọn, táwọn méjèèjì ń du ọ̀nà mọ́ra wọn lọ́wọ́ lórí afárá tó ń mì jẹ̀gẹ̀jẹ̀gẹ̀, á wá ku ṣín-ń-ṣín báyìí kí wọ́n fẹ̀gbẹ́ gbára. A tún wọ ọkọ̀ ojú irin, ọkọ̀ òkun, a sì gun ẹṣin.
Ní 1961, a bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iṣẹ́ àgbègbè, a ń rin ìrìn àjò láti àyíká dé àyíká, dípò lílọ láti ìjọ dé ìjọ. Ní àwọn alẹ́ mélòó kan láàárín ọ̀sẹ̀, a máa ń fi àwọn fíìmù tí ètò àjọ Jèhófà ṣe han àwọn èèyàn—ibi ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ la sì ti ń ṣe é. A gbọ́dọ̀ gbégbèésẹ̀ kíá, kí a lè gbọ́n já àwọn àlùfáà àdúgbò, tí kò fẹ́ káwọn èèyàn wo fíìmù wọ̀nyẹn. Ní ìlú kan, àlùfáà lọ halẹ̀ mọ́ ẹni tó ni gbọ̀ngàn táa fẹ́ lò, ó ní kó fagi lé àdéhùn tó bá wa ṣe. Lẹ́yìn wíwá ibòmíràn fún ọ̀pọ̀ ọjọ́, a rí ibì kan, ṣùgbọ́n a ò sọ fún ẹnikẹ́ni, a ṣì ń sọ fáwọn èèyàn pé ibi ti tẹ́lẹ̀ yẹn náà ni. Kí ètò náà tó bẹ̀rẹ̀, Christine lọ sí gbọ̀ngàn yẹn, ó sì rọra sọ fáwọn tó fẹ́ wo fíìmù náà pé kí wọ́n máa bọ̀ ní ibi táa ṣẹ̀ṣẹ̀ rí. Lálẹ́ ọjọ́ yẹn, àádọ́jọ [150] èèyàn ló wá wo fíìmù ọ̀hún, èyí tó ní àkọlé tó bá a mu náà, The New World Society in Action.
Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ṣíṣe iṣẹ́ arìnrìn-àjò ní àwọn ibi àdádó ń muni lómi gan-an nígbà mìíràn, àwọn ará tó jẹ́ ẹni rírẹlẹ̀ tí ń gbé ibi wọ̀nyí máa ń mọrírì ìbẹ̀wò wa, wọ́n sì ní ẹ̀mí aájò àlejò gan-an, àní wọ́n á gbà wá tọwọ́-tẹsẹ̀ sínú ilé mọ́ńbé wọn, a sì máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà nígbà gbogbo pé a láǹfààní láti wà pẹ̀lú wọn. Bíbá wọn dọ́rẹ̀ẹ́ yọrí sí àwọn ìbùkún tí ń mú wa lọ́kàn Òwe 19:17; Hágáì 2:7) Ìyẹn ló jẹ́ kó dùn wá gan-an, pé lẹ́yìn táa ti sìn fún ohun tó lé ní ọdún mọ́kànlélógún ní Brazil, a dágbére fún iṣẹ́ míṣọ́nnárì!
yọ̀. (Jèhófà Tọ́ Wa Sọ́nà Nígbà Ìpọ́njú
Ní 1975, wọ́n ṣe iṣẹ́ abẹ fún Christine. A padà sẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò, ṣùgbọ́n Christine ò gbádùn mọ́. Ó jọ pé á dáa ká padà sí Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, kí ó lè rí ìtọ́jú gbà. Ní April 1976, a dé Long Beach, California, a sì dé sọ́dọ̀ ìyá mi. Lẹ́yìn táa ti gbé lẹ́yìn odi fún ogún ọdún, gbogbo nǹkan dàrú mọ́ wa lójú, a ò mọ ohun tí à bá ṣe. Mo bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iṣẹ́ wíwọ́ra fáwọn èèyàn, a sì ń fi owó tó ń wọlé látinú iṣẹ́ yẹn gbọ́ bùkátà ara wa. Ìpínlẹ̀ California ṣètò ibì kan fún Christine ní ọsibítù kan, àmọ́ ojoojúmọ́ ni àìsàn ọ̀hún túbọ̀ ń wọ̀ ọ́ lára níbẹ̀ nítorí pé àwọn dókítà kọ̀ láti tọ́jú rẹ̀ láìfa ẹ̀jẹ̀ sí i lára. A wá sún kan ògiri, fún ìdí yìí a rawọ́ ẹ̀bẹ̀ sí Jèhófà pé kó jọ̀ọ́ tọ́ wa sọ́nà.
Lọ́sàn-án ọjọ́ kan nígbà tí mo jáde iṣẹ́ ìsìn pápá, mo tajú kán rí ọ́fíìsì dókítà kan, ọkàn kan sì sọ pé kí n wọbẹ̀ lọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé dókítà náà ti ń múra àtilọ sílé, ó jẹ́ kí n wọ ọ́fíìsì òun, a sì jọ sọ̀rọ̀ fún wákàtí méjì. Ó wá sọ pé: “Mo mọrírì iṣẹ́ míṣọ́nnárì tí ẹ̀ ń ṣe, màá tọ́jú ìyàwó ẹ láìgbowó, mi ò sì ní fa ẹ̀jẹ̀ sí i lára.” Àfi bí ẹni pé àlá ni mò ń lá.
Dókítà onínúure yìí, tí mo wá mọ̀ pé ó jẹ́ akọ́ṣẹ́mọṣẹ́ dókítà tó gbayì, gbé Christine lọ sí ọsibítù tó ti ń ṣiṣẹ́. Nítorí ìtọ́jú tó jíire tó fún un, kíá ni ara rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí kọ́fẹ. A mà dúpẹ́ o, pé Jèhófà tọ́ wa sọ́nà nígbà ìṣòro!
A Gba Iṣẹ́ Tuntun
Bí ara Christine ti ń mókun sí i, a bẹ̀rẹ̀ sí ṣe aṣáájú ọ̀nà, inú wa sì dùn pé a ran àwọn èèyàn mélòó kan lọ́wọ́ láti di olùjọsìn Jèhófà ní Long Beach. Ní 1982, wọ́n ní ká bẹ̀rẹ̀ sí ṣe iṣẹ́ àyíká ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Ojoojúmọ́ là ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà fún lílò wá lẹ́ẹ̀kan sí i nínú iṣẹ́ arìnrìn-àjò—ìyẹn iṣẹ́ òjíṣẹ́ táa fẹ́ràn gan-an. A sìn ní California àti lẹ́yìn náà ní New England, nínú àyíká tí àwọn ìjọ tó ń sọ èdè Potogí wà. Nígbà tó ṣe, iṣẹ́ wa nasẹ̀ dé Bermuda.
Lẹ́yìn ọdún mẹ́rin tó lárinrin, a gba iṣẹ́ mìíràn. Wọ́n ní ká lọ máa ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe níbikíbi táa bá fẹ́. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé inú wa ò dùn pé a fẹ́ fi iṣẹ́ arìnrìn-àjò sílẹ̀, síbẹ̀ ìpinnu wa ni láti máa tẹ̀ síwájú nínú iṣẹ́ wa tuntun. Ṣùgbọ́n níbo? Nígbà táa wà lẹ́nu iṣẹ́ arìnrìn-àjò, mo ti ṣàkíyèsí pé Ìjọ tí ń sọ èdè Potogí tó wà ní New Bedford, Massachusetts, nílò ìrànlọ́wọ́—fún ìdí yìí, a forí lé New Bedford.
Nígbà táa débẹ̀, ìjọ náà se àsè rẹpẹtẹ láti fi kí wa káàbọ̀. Wọ́n mà kúkú yẹ́ wa sí o! Omi kàn bẹ̀rẹ̀ sí dà lójú wa ni. Tọkọtaya kan tí kò tíì dàgbà púpọ̀, tí wọ́n ní ọmọ kékeré méjì, gbà wá sílé ká tó rí ilé tiwa. Lóòótọ́, Jèhófà bù kún iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe yìí kọjá ohun táa retí. Láti 1986, a ti ran nǹkan bí ogójì èèyàn ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lọ́wọ́ ní ìlú yìí láti di Ẹlẹ́rìí. Àwọn ni ẹbí wa nípa tẹ̀mí. Láfikún sí i, mo ti ní ayọ̀ rírí arákùnrin márùn-ún ládùúgbò wa tí wọ́n ti tẹ̀ síwájú di olùṣọ́ àgùntàn tó mọ agboó tọ́jú. Kò yàtọ̀ sí sísìn lẹ́nu iṣẹ́ míṣọ́nnárì tí ìbísí ti ń ya wọlé.
Báa ti ń wo ẹ̀yìn wò, inú wa ń dùn pé a ti sin Jèhófà láti ìgbà èwe wa, táa sì sọ òtítọ́ di ọ̀nà ìgbésí ayé wa. Òótọ́ kúkú ni pé ọjọ́ ogbó ti dé, ara sì ti di ara àgbà báyìí, ṣùgbọ́n títẹ̀síwájú lọ́nà Jèhófà ṣì ni ohun tó ń fún wa lókun àti ayọ̀.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Nígbà táa ṣẹ̀ṣẹ̀ gúnlẹ̀ sí Rio de Janeiro
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 28]
Àwọn ẹbí wa nípa tẹ̀mí ní New Bedford, Massachusetts