Àyè Tí Ọlọ́run Fi Gba Ìjìyà Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dópin
Àyè Tí Ọlọ́run Fi Gba Ìjìyà Ti Fẹ́rẹ̀ẹ́ Dópin
GBOGBO ibi tóo bá yíjú sí ni ìjìyà wà. Àfọwọ́fà ni ti àwọn kan. Wọ́n ń kó àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta látaré tàbí kí oògùn líle, ọtí àmupara, tàbí sìgá mímu wá fàbọ̀ sí wọn lára. Tàbí kí wọ́n di aláìlera nítorí àìjẹunre kánú. Àmọ́ ṣá o, ọ̀pọ̀ ìjìyà ló jẹ́ àbájáde àwọn nǹkan tàbí ìṣẹ̀lẹ̀ tó kọjá agbára ẹ̀dá: ogun, ìwà ipá kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ìwà ọ̀daràn, ipò òṣì, ìyàn, àrùn. Ohun mìíràn táwọn èèyàn ò rí ọgbọ́n kankan dá sí ni ìjìyà tó ń bá ọjọ́ ogbó àti ikú rìn.
Bíbélì mú un dá wa lójú pé “Ọlọ́run jẹ́ ìfẹ́.” (1 Jòhánù 4:8) Kí ló wá dé tí Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ fi jẹ́ kí gbogbo ìjìyà yìí máa bá a lọ fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún? Ìgbà wo ló máa yanjú ìṣòro náà? Ká tó lè dáhùn irú àwọn ìbéèrè bẹ́ẹ̀, a ní láti gbé ète tí Ọlọ́run ní fún ẹ̀dá ènìyàn yẹ̀ wò. Èyí yóò ràn wá lọ́wọ́ láti lóye ìdí tí Ọlọ́run fi fàyè gba ìjìyà àti ohun tí yóò ṣe nípa rẹ̀.
Ẹ̀bùn Òmìnira Láti Ṣe Ohun Tó Wuni
Nígbà tí Ọlọ́run dá ẹ̀dá ènìyàn àkọ́kọ́, ohun tó dá kì í kàn-án ṣe ara àti ọpọlọ nìkan. Síwájú sí i, Ọlọ́run kò dá Ádámù àti Éfà gẹ́gẹ́ bíi róbọ́ọ̀tì aláìní làákàyè. Ó dá wọn pẹ̀lú òmìnira láti ṣe ohun tó wù wọ́n. Ẹ̀bùn tó dára gan-an sì ni, nítorí “Ọlọ́run rí ohun gbogbo tí ó ti ṣe, sì wò ó! ó Jẹ́nẹ́sísì 1:31) Dájúdájú, “pípé ni ìgbòkègbodò rẹ̀.” (Diutarónómì 32:4) Gbogbo wa ló mọrírì ẹ̀bùn òmìnira láti ṣe ohun tó wuni yìí nítorí pé a kò fẹ́ kó jẹ́ pé gbogbo èrò àti ìṣe wa ló máa jẹ́ èyí tẹ́nì kan ń darí láìsí pé a láǹfààní láti dánú ṣe ohunkóhun.
dára gan-an ni.” (Àmọ́, ṣé ó wá yẹ ká lo ẹ̀bùn àtàtà ti òmìnira láti ṣe ohun tó wuni yìí láìní ààlà ni? Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run dáhùn rẹ̀ nínú àwọn ìlànà táa fún àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ pé: “Ẹ wà gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹni òmìnira, síbẹ̀ kí ẹ di òmìnira yín mú, kì í ṣe gẹ́gẹ́ bí bojúbojú fún ìwà búburú, bí kò ṣe gẹ́gẹ́ bí ẹrú Ọlọ́run.” (1 Pétérù 2:16) Fún àǹfààní gbogbo gbòò, ààlà gbọ́dọ̀ wà. Nípa bẹ́ẹ̀, òmìnira láti ṣe ohun tó wuni gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí tí òfin tí a là sílẹ̀ ń dárí. Bí bẹ́ẹ̀ kọ́, rúgúdù á ṣẹlẹ̀.
Òfin Ta Ni?
Òfin ti ta ló yẹ kó pinnu ibi tó yẹ kí òmìnira dé? Ìdáhùn sí ìbéèrè yìí ní í ṣe pẹ̀lú ohun tó fà á gan-an tí Ọlọ́run fàyè gba ìjìyà. Nítorí pé Ọlọ́run ló dá ènìyàn, ó mọ òfin tó dára jù lọ tó yẹ kí wọ́n ṣègbọràn sí fún àǹfààní ara wọn àti tàwọn ẹlòmíràn. Bíbélì sọ ọ́ báyìí pé: “Èmi, Jèhófà, ni Ọlọ́run rẹ, Ẹni tí ń kọ́ ọ kí o lè ṣe ara rẹ láǹfààní, Ẹni tí ń mú kí o tọ ọ̀nà tí ó yẹ kí o máa rìn.”—Aísáyà 48:17.
Ní kedere, kókó pàtàkì kan nìyí: A ò dá ènìyàn láti wà láìjẹ́ pé Ọlọ́run ń darí wọn. Ó dá wọn lọ́nà tó jẹ́ pé àṣeyọrí wọn àti ayọ̀ wọ́n sinmi lórí ṣíṣe ìgbọràn sí àwọn òfin òdodo rẹ̀. Jeremáyà, wòlíì Ọlọ́run sọ pé: “Mo mọ̀ dáadáa, Jèhófà, pé ọ̀nà ará ayé kì í ṣe tirẹ̀. Kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.”—Jeremáyà 10:23.
Ọlọ́run dá ènìyàn láti ṣègbọràn sí àwọn òfin rẹ̀ tí ń ṣàkóso àwọn ohun táa lè fojú rí, irú bí òfin òòfà. Bákan náà ló tún dá ènìyàn láti ṣègbọràn sí àwọn òfin ìwà rere rẹ̀, tí ó ṣe láti jẹ́ kí nǹkan máa lọ geere láwùjọ. Abájọ tí Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run fi rọ̀ wá pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ.”—Òwe 3:5.
Nítorí ìdí èyí, ìdílé ènìyàn kò lè kẹ́sẹ járí láé ní dídarí ara rẹ̀ láìsí lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run. Níbi táwọn èèyàn ti ń gbìyànjú láti wà ní òmìnira kúrò lọ́dọ̀ rẹ̀, wọ́n á hùmọ̀ ètò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ti ìṣúnná owó, ti ìṣèlú, àti ti ìsìn tí yóò tako ara wọn, tí ‘ènìyàn á sì máa jọba lórí ènìyàn sí ìṣeléṣe rẹ̀.’—Oníwàásù 8:9.
Kí Ló Ṣẹlẹ̀?
Ọlọ́run ṣe gbogbo nǹkan lọ́nà pípé nígbà tó dá àwọn òbí wa àkọ́kọ́, Ádámù àti Éfà. Wọ́n ní ara àti èrò inú pípé àti ọgbà Párádísè kan tí wọ́n ń gbé. Ká ní wọ́n fi ara wọn sábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run ni, wọ́n ì bá wà ní pípé, tí wọn yóò sì jẹ́ aláyọ̀. Bí àkókò ti ń lọ, wọn ì bá di òbí fún gbogbo ìdílé ẹ̀dá ènìyàn tó kún fún àwọn ẹni pípé, tí wọ́n jẹ́ ìdílé aláyọ̀ tó Jẹ́nẹ́sísì 1:27-29; 2:15.
ń gbé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Ète tí Ọlọ́run ní fún ìran ènìyàn nìyẹn.—Àmọ́, àwọn òbí wa àkọ́kọ́ ṣi òmìnira láti ṣe ohun tó wù wọ́n lò. Wọ́n fi àṣìṣe rò pé àwọn lè kẹ́sẹ járí láìsí lábẹ́ ìṣàkóso Ọlọ́run. Wọ́n mọ̀ọ́mọ̀ tàpá sí àwọn òfin rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì, orí kẹta) Nítorí pé wọ́n kọ ìṣàkóso rẹ̀ sílẹ̀, ọ̀ràn bí wọn ò ṣe ní pàdánù ìjẹ́pípé wọn kò kàn án mọ́. ‘Wọ́n gbé ìgbésẹ̀ tí ń fa ìparun níhà ọ̀dọ̀ àwọn fúnra wọn, àbùkù náà sì jẹ́ tiwọn.’—Diutarónómì 32:5.
Àtìgbà tí wọ́n ti ṣàìgbọràn sí Ọlọ́run ni ara àti èrò inú Ádámù àti Éfà ti bẹ̀rẹ̀ sí bà jẹ́. Ọ̀dọ̀ Jèhófà ni orísun ìyè wà. (Sáàmù 36:9) Nítorí náà, níwọ̀n bí wọ́n ti ya ara wọn kúrò lọ́dọ̀ Jèhófà, àwọn tọkọtaya àkọ́kọ́ di aláìpé, wọ́n sì kú ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 3:19) Ní ìbámu pẹ̀lú òfin ànímọ́ àbímọ́ni, ohun tí àwọn òbí wọ́n ní nìkan làwọn ọmọ wọn lè rí jogún. Kí sì ni nǹkan náà? Àìpé àti ikú ni. Ìdí nìyẹn tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi kọ̀wé pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ . . . tipasẹ̀ ènìyàn kan [Ádámù] wọ ayé àti ikú nípasẹ̀ ẹ̀ṣẹ̀, ikú sì tipa báyìí tàn dé ọ̀dọ̀ gbogbo ènìyàn nítorí pé gbogbo wọn ti dẹ́ṣẹ̀.”—Róòmù 5:12.
Kókó Pàtàkì Náà—Ipò Ọba Aláṣẹ
Nígbà tí Ádámù àti Éfà ṣọ̀tẹ̀ sí Ọlọ́run, wọ́n gbéjà ko ipò ọba aláṣẹ rẹ̀, ìyẹn ni ẹ̀tọ́ rẹ̀ láti ṣàkóso. Jèhófà ì bá ti pa wọ́n run, kó sì dá tọkọtaya mìíràn, àmọ́ ìyẹn ì bá má yanjú ọ̀ràn nípa ẹni tí ìṣàkóso rẹ̀ tọ́, tó sì dára jù lọ fún àwọn èèyàn. Nípa fífún wọn ní àkókò láti ṣètò àwùjọ wọn bí wọ́n ti fẹ́, àwọn èèyàn yóò fi hàn láìsí iyè méjì kankan bóyá ìṣàkóso láìsí pé Ọlọ́run dá sí ọ̀ràn wọn lè kẹ́sẹ járí.
Kí ni ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ìtàn ẹ̀dá ènìyàn fi hàn? Gbogbo ọ̀rúndún wọ̀nyẹn làwọn èèyàn ti fi gbìyànjú onírúurú ètò ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ti ìṣúnná owó, ti ìṣèlú, àti ti ìsìn. Àmọ́, ìwà ibi àti ìjìyà kò dáwọ́ dúró. Àní, ‘àwọn ènìyàn burúkú ti tẹ̀ síwájú láti inú búburú sínú búburú jù,’ àgàgà lákòókò tiwa.—2 Tímótì 3:13.
Àwọn èèyàn ṣe bẹbẹ ní ọ̀rúndún ogún tó ṣẹ̀ṣẹ̀ kọjá yìí nínú ìmọ̀ sáyẹ́ǹsì àti ìmọ̀ ẹ̀rọ. Àmọ́ ọ̀rúndún kan náà ni ìjìyà pọ̀ jù nínú ìtàn ìran ènìyàn. Bó sì ti wù kí ìmọ̀ ìṣègùn tẹ̀ síwájú tó, òfin Ọlọ́run ò tíì yí padà pé: Àwọn èèyàn tó ya ara wọn kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run—tó jẹ́ orísun ìyè—ń ṣàìsàn, wọ́n ń darúgbó, wọ́n sì ń kú. Ẹ ò rí i bó ti ṣe kedere tó pé ẹ̀dá ènìyàn kò lè ‘darí ìṣísẹ̀ ara wọn’!
A Mú Ipò Ọba Aláṣẹ Ti Ọlọ́run Dáni Lójú
Ìrírí bíbanilọ́kànjẹ́ táa ti ní nípa gbígba òmìnira kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run ti fi hàn pé ìṣàkóso ènìyàn láìsí pé Ọlọ́run dá sí ọ̀ràn wọn kò lè kẹ́sẹ járí láé. Ìṣàkóso Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló lè mú ayọ̀, ìṣọ̀kan, ìlera, àti ìyè wá. Síwájú sí i, Bíbélì Mímọ́, Ọ̀rọ̀ Jèhófà Ọlọ́run tí kò lè ṣàṣìṣe fi hàn pé à ń gbé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn” ìṣàkóso ẹ̀dá ènìyàn tó yapa kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. (2 Tímótì 3:1-5) Gbígbà tí Jèhófà gba èyí àti ìwà ibi àti ìjìyà láyè ti ń sún mọ́ òpin rẹ̀.
Ọlọ́run yóò dá sí ọ̀ràn ẹ̀dá ènìyàn láìpẹ́. Ìwé Mímọ́ sọ fún wa pé: “Ní ọjọ́ àwọn ọba wọ̀nyẹn [ìṣàkóso ènìyàn tó wà báyìí], Ọlọ́run ọ̀run yóò gbé ìjọba kan kalẹ̀ [ní ọ̀run] èyí tí a kì yóò run láé. Ìjọba náà ni a kì yóò sì gbé fún àwọn ènìyàn èyíkéyìí mìíràn [àwọn ènìyàn kò ní ṣàkóso ilẹ̀ ayé mọ́ láé]. Yóò fọ́ ìjọba wọ̀nyí [ìyẹn ìṣàkóso ìsinsìnyí] túútúú, yóò sì fi òpin sí gbogbo wọn, òun fúnra rẹ̀ yóò sì dúró fún àkókò tí ó lọ kánrin.”—Dáníẹ́lì 2:44.
Ìdáláre ipò ọba aláṣẹ Jèhófà Ọlọ́run nípasẹ̀ Ìjọba ọ̀run ni àkòrí Bíbélì. Èyí ni Jésù fi ṣe olórí ẹ̀kọ́ rẹ̀. Ó sọ pé: “A ó sì wàásù ìhìn rere ìjọba yìí ní gbogbo ilẹ̀ ayé tí a ń gbé, láti ṣe ẹ̀rí fún gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè; nígbà náà ni òpin yóò sì dé.”—Mátíù 24:14.
Nígbà tí ìṣàkóso ti Ọlọ́run bá dípò ti ẹ̀dá Òwe 2:21, 22 pé: “Àwọn adúróṣánṣán [tó gbé ìṣàkóso Ọlọ́run lárugẹ] ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀. Ní ti àwọn ẹni burúkú [tí wọn kò gbé ìṣàkóso Ọlọ́run lárugẹ], a óò ké wọn kúrò lórí ilẹ̀ ayé gan-an.” Onísáàmù tí Ọlọ́run mí sí náà kọ ọ́ lórin pé: “Ní ìgbà díẹ̀ sí i, ẹni burúkú kì yóò sì sí mọ́ . . . Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́kàn tútù ni yóò ni ilẹ̀ ayé, ní tòótọ́, wọn yóò sì rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà. Àwọn olódodo ni yóò ni ilẹ̀ ayé, wọn yóò sì máa gbé títí láé lórí rẹ̀.”—Sáàmù 37:10, 11, 29.
ènìyàn, àwọn wo ni yóò là á já, àwọn wo ni kò sì ní là á já? A mú un dá wa lójú nínúAyé Tuntun Àgbàyanu
Lábẹ́ ìṣàkóso Ìjọba Ọlọ́run, àwọn tó bá la òpin ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí já ni a óò mú wọnú ayé kan níbi tí kò ti ní sí ìwà ibi àti ìjìyà. Ìtọ́ni Ọlọ́run ni yóò wà fún ìran ènìyàn, bí àkókò sì ti ń lọ “ṣe ni ilẹ̀ ayé yóò kún fún ìmọ̀ Jèhófà bí omi ti bo òkun.” (Aísáyà 11:9) Ẹ̀kọ́ tó ń gbéni ró, tó sì ń ṣeni láǹfààní yìí yóò sọ àwùjọ ẹ̀dá ènìyàn di èyí tó wà ní ìṣọ̀kan, tó sì wà ní àlááfíà ní ti tòótọ́. Nípa bẹ́ẹ̀, kò ní sí ogun, ìpànìyàn, ìwà ipá, ìfipábáni-lòpọ̀, olè jíjà, tàbí àwọn ìwà ọ̀daràn mìíràn mọ́.
Àwọn àǹfààní àgbàyanu yóò wà fún àwọn ènìyàn onígbọràn tó ń gbé nínú ayé tuntun ti Ọlọ́run. A óò mú gbogbo àbájáde búburú tí ìṣọ̀tẹ̀ sí ìṣàkóso Ọlọ́run ti fà kúrò pátápátá. Àìpé, àìsàn, ọjọ́ ogbó, àti ikú yóò di ohun àtijọ́. Bíbélì mú un dá wa lójú pé: “Kò sì sí olùgbé kankan tí yóò sọ pé: ‘Àìsàn ń ṣe mí.’” Síwájú sí i, Ìwé Mímọ́ ṣèlérí pé: “Ní àkókò yẹn, ojú àwọn afọ́jú yóò là, etí àwọn adití pàápàá yóò sì ṣí. Ní àkókò yẹn, ẹni tí ó yarọ yóò gun òkè gan-an gẹ́gẹ́ bí akọ àgbọ̀nrín ti ń ṣe, ahọ́n ẹni tí kò lè sọ̀rọ̀ yóò sì fi ìyọ̀ṣẹ̀ṣẹ̀ ké jáde.” (Aísáyà 33:24; 35:5, 6) Ẹ wo bó ṣe máa múnú wa dùn tó láti ní ara tó jí pépé lójoojúmọ́—àní títí láé!
Lábẹ́ ìdarí onífẹ̀ẹ́ ti Ọlọ́run, àwọn tó ń gbé inú ayé tuntun yẹn yóò lo agbára àti òye wọn láti sọ gbogbo ilẹ̀ ayé di Párádísè. Ipò òṣì, ebi, àti àìrílégbé yóò kásẹ̀ nílẹ̀ pátápátá, nítorí àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà sọ pé: “Dájúdájú, wọn yóò kọ́ ilé, wọn yóò sì máa gbé inú wọn; dájúdájú, wọn yóò gbin ọgbà àjàrà, wọn yóò sì máa jẹ èso wọn. Wọn kì yóò kọ́lé fún ẹlòmíràn gbé; wọn kì yóò gbìn fún ẹlòmíràn jẹ.” (Aísáyà 65:21, 22) Àní, “wọn yóò sì jókòó ní ti tòótọ́, olúkúlùkù lábẹ́ àjàrà rẹ̀ àti lábẹ́ igi ọ̀pọ̀tọ́ rẹ̀, kì yóò sì sí ẹnì kankan tí yóò máa mú wọn wárìrì.”—Míkà 4:4.
Ilẹ̀ ayé yóò yọ̀ sí àbójútó onífẹ̀ẹ́ ti Ọlọ́run àti ti àwọn ènìyàn onígbọràn. Ìwé Mímọ́ mú un dá wa lójú pé: “Aginjù àti ẹkùn ilẹ̀ aláìlómi yóò yọ ayọ̀ ńláǹlà, pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀ yóò sì kún fún ìdùnnú, yóò sì yọ ìtànná gẹ́gẹ́ bí sáfúrónì. . . . Aísáyà 35:1, 6) “Ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ ọkà yóò wá wà lórí ilẹ̀; àkúnwọ́sílẹ̀ yóò wà ní orí àwọn òkè ńlá.”—Sáàmù 72:16.
Omi yóò ti ya jáde ní aginjù, àti ọ̀gbàrá ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ aṣálẹ̀.” (Àìmọye bílíọ̀nù ènìyàn tó ti kú ńkọ́? Àwọn tó wà ní ìrántí Ọlọ́run yóò padà wá sí ìyè, nítorí pé “àjíǹde àwọn olódodo àti àwọn aláìṣòdodo yóò wà.” (Ìṣe 24:15) Bẹ́ẹ̀ ni o, àwọn òkú yóò padà di alààyè. A óò kọ́ wọn ní àgbàyanu òtítọ́ nípa ìṣàkóso Ọlọ́run, a ó sì fún wọn láǹfààní láti máa gbé nínú Párádísè títí ayé fáàbàdà.—Jòhánù 5:28, 29.
Nípasẹ̀ àwọn ọ̀nà wọ̀nyí, Jèhófà Ọlọ́run yóò ṣàtúnṣe gbogbo ipò búburú ti ìjìyà, àìsàn, àti ikú tó ti fojú aráyé gbolẹ̀ fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún. Kò ní sí àìsàn mọ́! Kò ní sí ààbọ̀ ara mọ́! Kò ní sí ikú mọ́! Ọlọ́run “yóò sì nu omijé gbogbo nù kúrò ní ojú wọn, ikú kì yóò sì sí mọ́, bẹ́ẹ̀ ni kì yóò sí ọ̀fọ̀ tàbí igbe ẹkún tàbí ìrora mọ́. Àwọn ohun àtijọ́ [á] ti kọjá lọ.”—Ìṣípayá 21:3, 4.
Bí Ọlọ́run yóò ṣe mú ìjìyà wá sópin nìyẹn. Yóò pa ayé tó ti dómùkẹ̀ yìí run, yóò sì mú ètò àwọn nǹkan tuntun pátápátá wá, nínú èyí tí “òdodo yóò sì máa gbé.” (2 Pétérù 3:13) Ìròyìn rere mà lèyí o! A nílò ayé tuntun yẹn gan-an ni. Kò sì ní pẹ́ sígbà táa wà yìí kó tó dé. Látinú ìmúṣẹ àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì, a mọ̀ pé ayé tuntun náà ti dé tán, àyè tí Ọlọ́run sì fi gba ìjìyà ti fẹ́rẹ̀ẹ́ dópin.—Mátíù 24:3-14.
[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 8]
Ìkùnà Ìṣàkóso Ẹ̀dá Ènìyàn
Helmut Schmidt tó jẹ́ Olórí Ìjọba ilẹ̀ Jámánì tẹ́lẹ̀, sọ nípa ìṣàkóso ẹ̀dá ènìyàn pé: “Ìwọ̀nba apá kan ayé làwa èèyàn . . . máa ń ṣàkóso, ọ̀pọ̀ ìgbà la sì ń ṣe àkóso ọ̀hún lọ́nà tó burú jáì. . . . A ò tíì ṣàkóso rẹ̀ nínú ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàáfíà rí.” Ìwé Human Development Report 1999 sọ pé: “Gbogbo orílẹ̀-èdè ló ròyìn bí ìwà àwọn èèyàn tó wà láwùjọ wọn ṣe ń burú sí i, ṣe ni rògbòdìyàn láàárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ìwà ọ̀daràn túbọ̀ ń pọ̀ sí i, tí ìwà ipá sì ń peléke sí i nínú ilè. . . . Ńṣe ni ewu ń pọ̀ sí i kárí ayé, ó kọjá ohun tí ìjọba orílẹ̀-èdè kọ̀ọ̀kan lè gbógun tì, ó sì kọjá ohun tí gbogbo orílẹ̀-èdè lè rọ́gbọ́n dá sí.”
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]
“Ní tòótọ́, wọn yóò . . . rí inú dídùn kíkọyọyọ nínú ọ̀pọ̀ yanturu àlàáfíà.”—Sáàmù 37:11
[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 5]
Ìkẹ́ta láti òkè, ìyá àti ọmọ: Fọ́tò FAO/B. Imevbore; ìsàlẹ̀, ìbúgbàù: Fọ́tò U.S. National Archives