Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìyà Tó Ń jẹ Ẹ̀dá Èèyàn Tojú Súni

Ìyà Tó Ń jẹ Ẹ̀dá Èèyàn Tojú Súni

Ìyà Tó Ń jẹ Ẹ̀dá Èèyàn Tojú Súni

“ÌWỌ ỌLỌ́RUN, KÍ LÓ DÉ?” Àkọlé gàdàgbà yẹn ló wà níwájú ìwé ìròyìn kan tó gbajúmọ̀ lẹ́yìn ìsẹ̀lẹ̀ runlé rùnnà tó wáyé ní Éṣíà Kékeré. Àwòrán kan tí wọ́n yà síbẹ̀ fi bàbá kan tọ́kàn rẹ̀ ti dà rú hàn níbi tó ti ń gbé ọmọbìnrin rẹ̀ tó fara pa jáde nínú ilé wọn tó ti wó lulẹ̀.

Ogun, ìyàn, àjàkálẹ̀ àrùn, àti ìjábá ti fa ìrora tí kò ṣeé fẹnu sọ, omijé tó ń ṣàn bí ọ̀gbàrá, àti àwọn òkú tó sùn lọ bẹẹrẹ. Ní àfikún sí èyí ni ìyà tó ń jẹ àwọn tí wọ́n fipá bá lòpọ̀, àwọn ọmọ tí wọ́n hùwà àìdáa sí, àti àwọn ìwà ọ̀daràn mìíràn. Ronú nípa ọ̀pọ̀ rẹpẹtẹ àwọn tó ń fara pa àtàwọn tó ń kú nínú jàǹbá ọkọ̀. Bẹ́ẹ̀ náà ni làásìgbò ń bá ọ̀kẹ́ àìmọye ènìyàn nítorí àìsàn, ọjọ́ ogbó, àti ikú àwọn olólùfẹ́ wọn.

Ìyà ti ọ̀rúndún ogún ló peléke jù lọ. Láti ọdún 1914 sí 1918, Ogun Àgbáyé Kìíní pa ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó mílíọ̀nù mẹ́wàá sójà. Àwọn òpìtàn kan sọ pé àwọn aráàlú tó kú pọ̀ tó iye yẹn. Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì, nǹkan bí àádọ́ta mílíọ̀nù àwọn jagunjagun àtàwọn aráàlú ló kú, títí kan àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn obìnrin, àwọn ọmọdé, àtàwọn arúgbó tí wọn kò ní olùgbèjà. Jákèjádò ọ̀rúndún tó kọjá ni àwọn àràádọ́ta ọ̀kẹ́ mìíràn tún ń pàdánù ẹ̀mí wọn nítorí ìpẹ̀yàrun, ìyípadà tegbòtigaga, ìwà ipá kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà, ebi, àti ipò òṣì. Ìwé Historical Atlas of the Twentieth Century fojú bù ú pé àwọn èèyàn tó lé ní ọgọ́sàn-án [180] mílíọ̀nù ló kú nítorí irú “àwọn ohun bíburú jáì” bẹ́ẹ̀.

Àrùn gágá tó jà ní 1918 sí 1919 pa ogún mílíọ̀nù ènìyàn. Ní ogún ọdún sẹ́yìn, nǹkan bíi mílíọ̀nù mọ́kàndínlógún ni àrùn éèdì pa, àwọn bíi mílíọ̀nù márùndínlógójì ló sì ní kòkòrò fáírọ́ọ̀sì tó ń kó àrùn náà ranni báyìí. Àràádọ́ta ọ̀kẹ́ àwọn ọmọdé ni kò lóbìí mọ́—àrùn éèdì ti pa òbí wọ́n. Àìníye àwọn ọmọ ọwọ́ ló ń kú nítorí àrùn éèdì tí wọ́n kó ràn wọ́n nígbà tí wọ́n ṣì wà nínú ilé ọlẹ̀.

Ìyà tún ń jẹ àwọn ọmọdé láwọn ọ̀nà mìíràn. Nígbà tí ìwé ìròyìn Manchester Guardian Weekly ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì ń ṣàyọlò ìsọfúnni tí Àjọ Tí Ń Bójú Tó Àkànlò Owó Tí Ìparapọ̀ Àwọn Orílẹ̀-Èdè fún Àwọn Ọmọdé (UNICEF), gbé jáde ní òpin ọdún 1995, ó sọ pé: “Nínú àwọn ogun tó jà ní ẹ̀wádún tó kọjá, mílíọ̀nù méjì àwọn ọmọdé ló kú, mílíọ̀nù mẹ́rin sí márùn-ún ló di aláàbọ̀ ara, mílíọ̀nù méjìlá ni kò rílé gbé, àwọn tó lé ní mílíọ̀nù kan ló di ọmọ òrukàn tàbí tí wọ́n yà nípa kúrò lọ́dọ̀ àwọn òbí wọn, àwọn mílíọ̀nù mẹ́wàá ni àròdùn ti dà lórí rú.” Ní àfikún sí èyí ni ogójì sí nǹkan bí àádọ́ta mílíọ̀nù oyún tí wọ́n ń ṣẹ́ jákèjádò ayé—lọ́dọọdún!

Kí Ni Yóò Ṣẹlẹ̀ Lọ́jọ́ Iwájú?

Ọ̀pọ̀ ló ń wo ọjọ́ iwájú tẹ̀rùtẹ̀rù. Àwùjọ àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì kan sọ pé: “Ìgbòkègbodò ẹ̀dá ènìyàn . . . lè yí ayé tí àwọn ohun abẹ̀mí ń gbé padà débi tí kò ti ní lè gbé ẹ̀mí ró mọ́.” Wọ́n fi kún un pé: “Kódà nísinsìnyí pàápàá, ẹnì kan nínú ẹni márùn-ún ló wà nínú ipò òṣì paraku láìní oúnjẹ tí ó tó láti jẹ, ẹnì kan nínú mẹ́wàá ni kò sì rí oúnjẹ aṣaralóore jẹ.” Àwọn onímọ̀ sáyẹ́ǹsì lo àǹfààní náà láti fi “kìlọ̀ ohun tó ń bọ̀ lọ́jọ́ iwájú fún gbogbo aráyé,” wọ́n sì sọ pé: “Ìyípadà ńlá gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ sí bí a ṣe ń bójú tó ilẹ́ ayé àti àwọn ẹ̀dá inú rẹ̀, bí ẹ̀dá ènìyàn ò bá fẹ́ kàgbákò, tí a ò sì fẹ́ kí ibùgbé wa orí ilẹ̀ ayé yìí di èyí tó bàjẹ́ kọjá àtúnṣe.”

Èé ṣe tí Ọlọ́run fàyè gba ìjìyà àti ìwà ibi tó pọ̀ tó bẹ́ẹ̀? Kí ni ète Ọlọ́run láti yanjú ìṣòro náà? Ìgbà wo sì ni?

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 3]

Òkè, àga onítáyà: Fọ́tò UN/DPI 186410C tí P.S. Sudhakaran yà; àárín, àwọn ọmọ tí ebi ti fẹ́rẹ̀ẹ́ lù pa: WHO/OXFAM; ìsàlẹ̀, ọkùnrin kan tó rù kan egungun: Fọ́tò FAO/B. Imevbore