Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Ẹ Wò Ó! Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Náà!’

‘Ẹ Wò Ó! Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Náà!’

Ẹ Dúró Lọ́nà Pípé Pẹ̀lú Ìgbàgbọ́ Tó Fìdí Múlẹ̀

‘Ẹ Wò Ó! Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Náà!’

ÌBÉÈRÈ tó rú àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà lójú fún ọ̀pọ̀ ọdún ni. Ó ti pẹ́ tí wọ́n ti sapá láti yanjú rẹ̀ lọ́nà tó bá Ìwé Mímọ́ mu. Kókó náà ti fa ọ̀pọ̀ ìjíròrò. Níkẹyìn, wọ́n rí ìdáhùn látinú Bíbélì, inú àwọn èrò tó wà ní àpéjọpọ̀ Washington, D.C., lọ́dún 1935 sì dùn dọ́ba.

Ìbéèrè kan náà ni gbogbo ìjíròrò náà dá lé: Àwọn wo ni “ògìdìgbó ńlá” (King James Version) tàbí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” (Ìwé Mímọ́ ní Ìtumọ̀ Ayé Tuntun) táa mẹ́nu kàn nínú Ìṣípayá 7:9? Ṣé ọ̀run ni ẹgbẹ́ àwọn onígbàgbọ́ yìí máa gbé?

Ìbéèrè Tó Ti Wà Tipẹ́

Láti àkókò àpọ́sítélì Jòhánù títí di ọjọ́ wa ni àwọn tí “ògìdìgbó ńlá” náà jẹ́ ti ń rú àwọn Kristẹni lójú. Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ka ogunlọ́gọ̀ ńlá sí ẹgbẹ́ kejì tí ń lọ sí ọ̀run, ìyẹn ẹgbẹ́ tó ní ìmọ̀ òtítọ́ Bíbélì, àmọ́ tí wọn kò fi bẹ́ẹ̀ tàn án kálẹ̀.

Àmọ́, àwọn kan lára alábàákẹ́gbẹ́ àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró di onítara gan-an nínú iṣẹ́ wíwàásù. Wọn ò nírètí àtilọ sí ọ̀run. Àní, ìrètí wọn wà ní ìbámu pẹ̀lú àsọyé fún gbogbo ènìyàn náà, “Àràádọ́ta Ọ̀kẹ́ Tó Wà Láàyè Nísinsìnyí Kò Ní Kú Láé,” èyí tí àwọn ènìyàn Jèhófà sọ láti ọdún 1918 sí 1922. A ó fi ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé jíǹkí irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀.

Ìwé ìròyìn The Watch Tower ti October 15, 1923, jíròrò òwe Jésù nípa àwọn àgùntàn àtàwọn ewúrẹ́, ó sì sọ pé: “Àwọn àgùntàn ṣàpẹẹrẹ gbogbo àwọn ènìyàn orílẹ̀-èdè, kì í ṣe àwọn tí a fi ẹ̀mí bí o, àmọ́ àwọn tí ọkàn wọn tẹ̀ sí òdodo, àwọn tí wọ́n fi èrò orí wọn gba Jésù Kristi gẹ́gẹ́ bí Olúwa, tí wọ́n ń wọ̀nà, tí wọ́n sì ń retí àkókò dídára jù lábẹ́ ìṣàkóso rẹ̀.”—Mátíù 25:31-46.

Ìmọ́lẹ̀ Túbọ̀ Ń Mọ́lẹ̀ Sí I

Ní ọdún 1931, Vindication, Ìwé Kìíní, jíròrò Ìsíkíẹ́lì orí kẹsàn-án, ó sì sọ pé àwọn tí a sàmì síwájú orí wọn fún dídá ẹ̀mí wọn sí nígbà òpin ayé ni àwọn àgùntàn tó wà nínú òwe Jésù. Vindication, Ìwé Kẹta (tó jáde ní 1932), ṣàpèjúwe ọkàn-àyà títọ́ tí Jèhónádábù, ọkùnrin tí kì í ṣe ọmọ Ísírẹ́lì ní, ẹni tó wọnú kẹ̀kẹ́ ẹṣin Jéhù Ọba Ísírẹ́lì tí a fòróró yàn, tó sì bá a lọ láti wo ìtara tí Jéhù fi ń pa àwọn olùjọsìn èké run. (2 Àwọn Ọba 10:15-28) Ìwé yìí sọ pé: “Jèhónádábù jẹ́ tàbí pé ó ń ṣàpẹẹrẹ ẹgbẹ́ àwọn ènìyàn tó wà lórí ilẹ̀ ayé báyìí [tí wọn] kò sí ní ìṣọ̀kan pẹ̀lú ètò Sátánì, tí wọ́n mú ìdúró wọn ní ìhà òdodo, àwọn sì ni Olúwa yóò pa mọ́ nígbà Amágẹ́dọ́nì, tí yóò mú wọn la gbogbo ìpọ́njú yẹn já, tí yóò sì fún wọn ní ìyè àìnípẹ̀kun lórí ilẹ̀ ayé. Àwọn wọ̀nyí ló pa pọ̀ jẹ́ ẹgbẹ́ ‘àgùntàn.’”

Ní ọdún 1934, Ilé Ìṣọ́ mú un ṣe kedere pé àwọn Kristẹni tó ní ìrètí ilẹ̀ ayé gbọ́dọ̀ ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà, kí wọ́n sì ṣe batisí. Láìsí àní-àní, ìmọ́lẹ̀ nípa àwọn ẹgbẹ́ ti orí ilẹ̀ ayé yìí túbọ̀ ń mọ́lẹ̀ sí i!—Òwe 4:18.

Ìmọ́lẹ̀ Tí Ń Lani Lóye Tàn Yòò

Ìmọ́lẹ̀ tí ń lani lóye nípa ìwé Ìṣípayá 7:9-17 ti fẹ́ bẹ̀rẹ̀ sí kọ mànà. (Sáàmù 97:11) Ilé Ìṣọ́ ti fi hàn pé àpéjọpọ̀ tí wọ́n ṣètò fún May 30 sí June 3, 1935, ní Washington, D.C., Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà yóò jẹ́ “ojúlówó ìtùnú àti àǹfààní” fún àwọn táa pè ní ẹgbẹ́ Jèhónádábù. Ohun tó sì wá jẹ́ gan-an nìyẹn!

Nínú ọ̀rọ̀ títanijí kan lórí “Ògìdìgbó Ńlá,” èyí táa sọ fún àwọn alápèéjọpọ̀ tó jẹ́ nǹkan bí ọ̀kẹ́ kan [20,000], olùbánisọ̀rọ̀ náà, J. F. Rutherford, fi ẹ̀rí Ìwé Mímọ́ tì í lẹ́yìn pé “àwọn àgùntàn mìíràn” òde òní kò fi bẹ́ẹ̀ yàtọ̀ sí “ogunlọ́gọ̀ ńlá” inú Ìṣípayá 7:9. (Jòhánù 10:16) Ní òtéńté àsọyé yìí, olùbánisọ̀rọ̀ náà béèrè pé: “Ǹjẹ́ gbogbo àwọn tó nírètí gbígbé lórí ilẹ̀ ayé títí láé lè jọ̀wọ́ dìde dúró?” Bí àwọn tó pọ̀ jù nínú àwùjọ náà ṣe dìde dúró ni Rutherford kéde pé: “Ẹ Wò ó! Ògìdìgbó ńlá náà!” Àwọn èèyàn kọ́kọ́ pa rọ́rọ́, lẹ́yìn náà ni wọ́n wá hó yèè. Ní ọjọ́ kejì, àwọn òjì lé lẹ́gbẹ̀rin [840] Ẹlẹ́rìí tuntun fún Jèhófà ló ṣe batisí, ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn wọ̀nyí ló si sọ pé ara ogunlọ́gọ̀ ńlá làwọn wà.

Ogunlọ́gọ̀ Ńlá Náà Pẹtẹrí

Ṣáájú ọdún 1935, àwọn tí iye wọn túbọ̀ ń pọ̀ sí i, tí wọ́n tẹ́wọ́ gba ìhìn Bíbélì, tí wọ́n sì ń fi ìtara wàásù ìhìn rere náà nífẹ̀ẹ́ sí wíwàláàyè títí láé nínú Párádísè orí ilẹ̀ ayé. Wọn ò fọkàn sí lílọ sí ọ̀run rárá, nítorí pé Ọlọ́run kò fún wọn ní ìrètí ìyè ti ọ̀run. Fífi tí wọ́n fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí ogunlọ́gọ̀ ńlá ti àwọn àgùntàn mìíràn fi hàn pé àfàìmọ̀ ni ìpè ọ̀kẹ́ méje, ó lé ẹgbàajì àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró kò ti parí ní 1935.—Ìṣípayá 7:4.

Nígbà tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ́ sílẹ̀, Sátánì Èṣù sapá gan-an láti fòpin sí kíkó àwọn tí yóò para pọ̀ jẹ́ ogunlọ́gọ̀ ńlá náà jọ. Wọ́n fòfin de iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà ní ọ̀pọ̀ orílẹ̀-èdè. Láwọn ọjọ́ tí nǹkan ò rọgbọ wọ̀nyẹn, àti kété ṣáájú ikú J. F. Rutherford ní January 1942, ó sọ pé: “Ó dà bí ẹni pé ‘ògìdìgbó ńlá’ náà kò ní fi bẹ́ẹ̀ pọ̀ lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn.”

Àmọ́, nítorí ìbùkún àtọ̀runwá, nǹkan ti yí padà pátápátá. Nípa ‘dídúró lọ́nà pípé pẹ̀lú ìgbàgbọ́ tó fìdí múlẹ̀,’ àwọn ẹni àmì òróró àtàwọn alábàákẹ́gbẹ́ wọn, ìyẹn àwọn àgùntàn mìíràn, ti ń ṣe bẹbẹ nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn táa gbé lé wọn lọ́wọ́. (Kólósè 4:12; Mátíù 24:14; 28:19, 20) Ní ọdún 1946, iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó ń wàásù jákèjádò ayé jẹ́ 176,456—ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn wọ̀nyí ló sì jẹ́ ara ogunlọ́gọ̀ ńlá. Ní ọdún 2000, ó lé ní mílíọ̀nù mẹ́fà [6,000,000] Ẹlẹ́rìí tó ń fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà ní igba ó lé márùndínlógójì [235] ilẹ̀—ogunlọ́gọ̀ ńlá ni wọ́n lóòótọ́! Iye náà sì túbọ̀ ń pọ̀ sí i ni.