Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Yin Jèhófà Nítorí Àwọn Iṣẹ́ Àrà rẹ̀!

Ẹ Yin Jèhófà Nítorí Àwọn Iṣẹ́ Àrà rẹ̀!

Ẹ Yin Jèhófà Nítorí Àwọn Iṣẹ́ Àrà rẹ̀!

“Ọkàn mi gbé Jèhófà ga lọ́lá . . . nítorí pé Ẹni alágbára ti ṣe àwọn ìṣe ńláǹlà fún mi.”—LÚÙKÙ 1:46-49.

1. Àwọn iṣẹ́ àrà wo ló yẹ ká tìtorí wọn yin Jèhófà?

 JÈHÓFÀ yẹ fún ìyìn nítorí àwọn iṣẹ́ àrà rẹ̀. Nígbà tí wòlíì Mósè ń ròyìn dídá táa dá Ísírẹ́lì nídè kúrò ní Íjíbítì, ó kéde pé: “Ojú yín ni ó rí gbogbo iṣẹ́ ńlá Jèhófà.” (Diutarónómì 11:1-7) Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́, nígbà tí áńgẹ́lì Gébúrẹ́lì kéde ìbí Jésù tó kù sí dẹ̀dẹ̀ fún ọ̀dọ́bìnrin wúńdíá nì, Màríà, wúńdíá náà sọ pé: “Ọkàn mi gbé Jèhófà ga lọ́lá . . . nítorí pé Ẹni alágbára ti ṣe àwọn ìṣe ńláǹlà fún mi.” (Lúùkù 1:46-49) Àwa gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń gbé e lárugẹ nítorí àwọn iṣẹ́ àrà tó ṣe, bíi dídá Ísírẹ́lì nídè kúrò nínú ìgbèkùn Íjíbítì àti bí oyún Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n ṣe ṣẹlẹ̀ lọ́nà ìyanu.

2. (a) Kí ni “ète ayérayé” Ọlọ́run túmọ̀ sí fún aráyé onígbọràn? (b) Kí ni Jòhánù rí ní erékùṣù Pátímọ́sì?

2 Ọ̀pọ̀ lára iṣẹ́ àrà tí Jèhófà ṣe ló wé mọ́ “ète ayérayé” rẹ̀ láti bù kún aráyé onígbọràn nípasẹ̀ Mèsáyà náà àti ìṣàkóso Ìjọba rẹ̀. (Éfésù 3:8-13) Ète yẹn ń tẹ̀ síwájú ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé nígbà tí a jẹ́ kí àpọ́sítélì Jòhánù arúgbó gba ibi ilẹ̀kùn tí a ṣí sílẹ̀ rí ìran ohun tó ń ṣẹlẹ̀ ní ọ̀run. Ó gbọ́ ohùn kan tó dún bíi kàkàkí tó sọ pé: “Máa bọ̀ lókè níhìn-ín, èmi yóò sì fi àwọn ohun tí ó gbọ́dọ̀ ṣẹlẹ̀ hàn ọ́.” (Ìṣípayá 4:1) Nígbà tí ìjọba Róòmù há Jòhánù mọ́ erékùṣù Pátímọ́sì “nítorí sísọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti jíjẹ́rìí Jésù” ni a fún un ní “ìṣípayá láti ọ̀dọ̀ Jésù Kristi.” Ohun tí àpọ́sítélì náà rí àti ohun tó gbọ́ ṣí ohun púpọ̀ payá nípa ète ayérayé Ọlọ́run, ó sì tipa bẹ́ẹ̀ pèsè ìlàlóye tẹ̀mí àti ìṣírí tó bákòókò mu fún gbogbo Kristẹni tòótọ́.—Ìṣípayá 1:1, 9, 10.

3. Àwọn wo ni alàgbà mẹ́rìnlélógún tí Jòhánù rí nínú ìran dúró fún?

3 Bí Jòhánù ṣe ń gba ibi ilẹ̀kùn táa ṣí sílẹ̀ ní ọ̀run yẹn wòran, ó rí àwọn alàgbà mẹ́rìnlélógún, tí wọ́n gúnwà sórí ìtẹ́, tí wọ́n sì dé adé gẹ́gẹ́ bí ọba. Wọ́n wólẹ̀ níwájú Ọlọ́run, wọ́n sì sọ pé: “Jèhófà, àní Ọlọ́run wa, ìwọ ni ó yẹ láti gba ògo àti ọlá àti agbára, nítorí pé ìwọ ni ó dá ohun gbogbo, àti nítorí ìfẹ́ rẹ ni wọ́n ṣe wà, tí a sì dá wọn.” (Ìṣípayá 4:11) Àwọn alàgbà wọ̀nyẹn dúró fún gbogbo àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tí a ti jí dìde, tí wọ́n wà ní ipò gíga tí Ọlọ́run ṣèlérí fún wọn. Àwọn iṣẹ́ àrà tí Jèhófà ṣe nínú ìṣẹ̀dá ń sún wọn láti yìn ín. Ẹ̀rí ‘agbára ayérayé Jèhófà àti jíjẹ́ Ọlọ́run rẹ̀,’ ń mú kí àwa náà ṣe háà. (Róòmù 1:20) Bí a sì ṣe túbọ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà tó, bẹ́ẹ̀ ni a túbọ̀ ń rí ìdí tó fi yẹ ká máa yìn ín nítorí àwọn iṣẹ́ àrà rẹ̀.

Máa Kéde Àwọn Iṣẹ́ Jèhófà Tó Yẹ fún Ìyìn!

4, 5. Mẹ́nu kan àwọn àpẹẹrẹ bí Dáfídì ṣe yin Jèhófà.

4 Onísáàmù náà Dáfídì yin Ọlọ́run nítorí àwọn iṣẹ́ àrà Rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, Dáfídì kọ ọ́ lórin pé: “Ẹ kọ orin atunilára sí Jèhófà, ẹni tí ń gbé Síónì; ẹ sọ àwọn ìṣe rẹ̀ láàárín àwọn ènìyàn. Fi ojú rere hàn sí mi, Jèhófà; rí ìṣẹ́ tí àwọn tí ó kórìíra mi fi ń ṣẹ́ mi, ìwọ tí ń gbé mi sókè láti àwọn ẹnubodè ikú, kí n lè polongo gbogbo àwọn iṣẹ́ rẹ tí ó yẹ fún ìyìn ní àwọn ẹnubodè ọmọbìnrin Síónì.” (Sáàmù 9:11, 13, 14) Lẹ́yìn tí Dáfídì fún Sólómọ́nì ọmọ rẹ̀ ní àwòrán tí wọ́n á fi kọ́ tẹ́ńpìlì, ó fi ìbùkún fún Ọlọ́run, ó sì yìn ín, ó ní: “Tìrẹ, Jèhófà, ni títóbi àti agbára ńlá àti ẹwà àti ìtayọlọ́lá àti iyì . . . Tìrẹ ni ìjọba, Jèhófà, ìwọ Ẹni tí ń gbé ara rẹ sókè ṣe olórí pẹ̀lú lórí ohun gbogbo. . . . Wàyí o, Ọlọ́run wa, àwa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ, a sì ń yin orúkọ rẹ alẹ́wàlógo.”—1 Kíróníkà 29:10-13.

5 Léraléra ni Ìwé Mímọ́ ké sí wa—àní tó tún ń rọ̀ wá pàápàá—pé ká máa yin Ọlọ́run, gẹ́gẹ́ bí Dáfídì ti ṣe. Ìwé Sáàmù kún fún ọ̀rọ̀ ìyìn sí Ọlọ́run, wọ́n sì sọ pé Dáfídì ló kọ nǹkan bí ìdajì nínú orín ìyìn wọ̀nyẹn. Gbogbo ìgbà ló máa ń yin Jèhófà tó sì máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀. (Sáàmù 69:30) Láfikún sí i, láti ìgbà ìjímìjí ni wọ́n ti ń lo àwọn orin tí Dáfídì àtàwọn ẹlòmíràn kọ lábẹ́ ìmísí láti fi yin Jèhófà.

6. Báwo ni àwọn Sáàmù táa mí sí ṣe wúlò fún wa?

6 Ìwé Sáàmù mà kúkú wúlò fáwọn tó ń sin Jèhófà o! Nígbà táa bá fẹ́ dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run fún gbogbo iṣẹ́ àrà tó ń ṣe fún wa, ọkàn wa lè sọ sí àwọn ọ̀rọ̀ amóríwú tó wà nínú ìwé Sáàmù. Fún àpẹẹrẹ, jíjí táa bá jí láàárọ̀ ọjọ́ kan, ọkàn wa lè sún wa láti sọ irú ọ̀rọ̀ bí: “Ó dára láti máa fi ọpẹ́ fún Jèhófà àti láti máa kọ orin atunilára sí orúkọ rẹ, ìwọ Ẹni Gíga Jù Lọ; láti máa sọ̀rọ̀ nípa inú rere rẹ onífẹ̀ẹ́ ní òwúrọ̀ àti nípa ìṣòtítọ́ rẹ ní òròòru, . . . nítorí pé ìwọ, Jèhófà, ti mú kí n máa yọ̀ nítorí ìgbòkègbodò rẹ; mo ń fi ìdùnnú ké jáde nítorí àwọn iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.” (Sáàmù 92:1-4) Nígbà táa bá borí ohun kan tó fẹ́ dènà ìtẹ̀síwájú wa nípa tẹ̀mí, inú wa lè dùn, ká sì gba àdúrà ìdúpẹ́, àní gẹ́gẹ́ bí onísáàmù náà ti ṣe nígbà tó kọ ọ́ lórin pé: “Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a fi ìdùnnú ké jáde sí Jèhófà! Ẹ jẹ́ kí a kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun sí Àpáta ìgbàlà wa. Ẹ jẹ́ kí a wá sí iwájú rẹ̀ ti àwa ti ìdúpẹ́; ẹ jẹ́ kí a fi àwọn orin atunilára kígbe nínú ayọ̀ ìṣẹ́gun sí i.”—Sáàmù 95:1, 2.

7. (a) Kí ló yẹ fún àfiyèsí nípa ọ̀pọ̀ lára àwọn orin táwa Kristẹni ń kọ? (b) Kí ni ọ̀kan lára ìdí tó fi yẹ ká máa tètè dé sípàdé, ká sì dúró títí tó fi máa parí?

7 A sábà máa ń kọ orin ìyìn sí Jèhófà ní àwọn ìpàdé ìjọ, ní àwọn àpéjọ, àti ní àwọn àpéjọpọ̀. Ó yẹ fún àfiyèsí pé ọ̀pọ̀ lára orin wọ̀nyí la gbé ka àwọn ọ̀rọ̀ táa mí sí, tó wà nínú ìwé Sáàmù. Ẹ wo bí inú wa ṣe dùn tó pé a ní àkójọ àwọn orin òde òní, tí ń múni lórí wú, táa fi ń yin Jèhófà! Kíkọrin ìyìn sí Ọlọ́run jẹ́ ọ̀kan lára ìdí gúnmọ́ tó fi yẹ ká máa tètè dé sípàdé, ká sì dúró títí tó fi máa parí, ká lè bá àwọn olùjọsìn ẹlẹgbẹ́ wa kópa nínú fífi orin àti àdúrà yin Jèhófà.

“Ẹ Yin Jáà!”

8. Kí ló fara hàn nínú ọ̀rọ̀ náà “Alelúyà,” báwo la sì ṣe máa ń túmọ̀ rẹ̀?

8 Yíyin Jèhófà fara hàn nínú ọ̀rọ̀ náà “Alelúyà,” tí a mú wá látinú ọ̀rọ̀ Hébérù tó túmọ̀ sí “Ẹ yin Jáà.” Fún àpẹẹrẹ, a rí ìkésíni ọlọ́yàyà, tó dún ketekete yìí nínú Sáàmù 135:1-3, tó sọ pé: “Ẹ yin Jáà! Ẹ yin orúkọ Jèhófà, ẹ mú ìyìn wá, ẹ̀yin ìránṣẹ́ Jèhófà, ẹ̀yin tí ń dúró nínú ilé Jèhófà, nínú àwọn àgbàlá ilé Ọlọ́run wa. Ẹ yin Jáà, nítorí tí Jèhófà jẹ́ ẹni rere. Ẹ kọ orin atunilára sí orúkọ rẹ̀, nítorí tí ó dùn mọ́ni.”

9. Kí ló ń mú ká máa yin Jèhófà?

9 Báa ti ń ronú nípa àwọn iṣẹ́ àgbàyanu tí Ọlọ́run ṣe nínú ìṣẹ̀dá àti gbogbo ohun tó ń ṣe fún wa, ìmọrírì àtọkànwá ń sún wa láti yìn ín. Nígbà táa bá ronú nípa àwọn ohun ìyanu tí Jèhófà ṣe fáwọn èèyàn rẹ̀ ìgbàanì, ọkàn wa ń sún wa láti gbé e lárugẹ. Báa sì ṣe ń ṣàṣàrò lórí àwọn ìlérí àwọn ohun ńlá tí Jèhófà fẹ́ ṣe, a ń wá ọ̀nà láti fi ìyìn àti ọpẹ́ fún un.

10, 11. Báwo ni wíwà táa wà láàyè ṣe jẹ́ ìdí fún yíyin Ọlọ́run?

10 Ti pé a wà láyé, a tún wà láàyè, jẹ́ ìdí gúnmọ́ fún yíyin Jáà. Dáfídì kọ ọ́ lórin pé: “Èmi yóò gbé ọ [Jèhófà] lárugẹ, nítorí pé lọ́nà amúnikún-fún-ẹ̀rù ni a ṣẹ̀dá mi tìyanu-tìyanu. Àgbàyanu ni àwọn iṣẹ́ rẹ, bí ọkàn mi ti mọ̀ dáadáa.” (Sáàmù 139:14) Òótọ́ kúkú ni pé ‘tìyanu-tìyanu ni a ṣẹ̀dá wa,’ a sì ní àwọn ẹ̀bùn iyebíye bíi ti ìríran, ìgbọ́rọ̀, àti agbára láti ronú. Nítorí náà, kò ha yẹ ká lo ìgbésí ayé wa lọ́nà tí a óò fi lè yin Ẹlẹ́dàá wa? Ohun tí Pọ́ọ̀lù ní lọ́kàn nìyẹn, nígbà tó kọ̀wé pé: “Yálà ẹ ń jẹ tàbí ẹ ń mu tàbí ẹ ń ṣe ohunkóhun mìíràn, ẹ máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Ọlọ́run.”—1 Kọ́ríńtì 10:31.

11 A óò máa ṣe ohun gbogbo fún ògo Jèhófà tó bá jẹ́ pé lóòótọ́ la nífẹ̀ẹ́ rẹ̀. Jésù sọ pé àṣẹ èkíní ni pé: “Kí ìwọ . . . nífẹ̀ẹ́ Jèhófà Ọlọ́run rẹ pẹ̀lú gbogbo ọkàn-àyà rẹ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ àti pẹ̀lú gbogbo èrò-inú rẹ àti pẹ̀lú gbogbo okun rẹ.” (Máàkù 12:30; Diutarónómì 6:5) Dájúdájú, ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ Jèhófà, ká sì máa yìn ín gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá wa àti Olùfúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé.” (Jákọ́bù 1:17; Aísáyà 51:13; Ìṣe 17:28) Ó ṣe tán, làákàyè wa, àwọn ànímọ́ tẹ̀mí táa ní, àti okun wa—àní gbogbo ẹ̀bùn àti ànímọ́ wa—ọ̀dọ̀ Jèhófà ló ti wá. Gẹ́gẹ́ bí Ẹlẹ́dàá wa, ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ká sì máa yìn ín.

12. Báwo ni àwọn iṣẹ́ àrà Jèhófà àti ọ̀rọ̀ tó wà nínú Sáàmù 40:5 ṣe rí lára rẹ?

12 Àwọn iṣẹ́ àrà Jèhófà jẹ́ kí a ní àìmọye ìdí láti nífẹ̀ẹ́ rẹ̀, ká sì máa yìn ín! Dáfídì kọ ọ́ lórin pé: “Ọ̀pọ̀ nǹkan ni ìwọ fúnra rẹ ti ṣe, ìwọ Jèhófà Ọlọ́run mi, àní àwọn iṣẹ́ àgbàyanu rẹ àti ìrònú rẹ sí wa; kò sí ẹnì kankan tí a lè fi ọ́ wé. Ká ní mo fẹ́ máa wí, kí n sì máa sọ nípa wọn ni, wọ́n pọ̀ níye ju èyí tí mo lè máa ròyìn lẹ́sẹẹsẹ.” (Sáàmù 40:5) Dáfídì kò lè ka gbogbo iṣẹ́ àgbàyanu Jèhófà tán, àwa náà ò sì lè kà á tán. Ṣùgbọ́n ẹ jẹ́ ká máa yin Ọlọ́run ní gbogbo ìgbà tí a bá rí èyíkéyìí nínú iṣẹ́ àrà wọ̀nyí.

Àwọn Iṣẹ́ Tó Tan Mọ́ Ète Ayérayé Ọlọ́run

13. Báwo ni ìrètí wa ṣe wé mọ́ àwọn iṣẹ́ àrà Ọlọ́run?

13 Ìrètí wa fún ọjọ́ ọ̀la wé mọ́ àwọn iṣẹ́ àrà, iṣẹ́ tó yẹ fún ìyìn tó ní í ṣe pẹ̀lú ète ayérayé Ọlọ́run. Lẹ́yìn ọ̀tẹ̀ tó wáyé nínú ọgbà Édẹ́nì ni Jèhófà sọ àsọtẹ́lẹ̀ àkọ́kọ́ tó kún fún ìrètí. Nígbà tí Ọlọ́run ń dá ejò náà lẹ́jọ́, ó wí pé: “Èmi yóò sì fi ìṣọ̀tá sáàárín ìwọ àti obìnrin náà àti sáàárín irú-ọmọ rẹ àti irú-ọmọ rẹ̀. Òun yóò pa ọ́ ní orí, ìwọ yóò sì pa á ní gìgísẹ̀.” (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ìrètí nínú Irú-Ọmọ obìnrin táa ṣèlérí náà wà láìyingin nínú ọkàn àwọn olóòótọ́ ènìyàn lẹ́yìn tí Jèhófà ṣe iṣẹ́ àrà nípa pípa Nóà àti ìdílé rẹ̀ mọ́ la Ìkún Omi kárí ayé náà já, èyí tó gbá àwọn olubi lọ. (2 Pétérù 2:5) Àwọn ìlérí táa sọ àsọtẹ́lẹ̀ rẹ̀ fún àwọn ọkùnrin onígbàgbọ́ bí Ábúráhámù àti Dáfídì túbọ̀ là wá lóye nípa ohun tí Jèhófà yóò ṣe láṣeparí nípasẹ̀ Irú-Ọmọ náà.—Jẹ́nẹ́sísì 22:15-18; 2 Sámúẹ́lì 7:12.

14. Kí ni àpẹẹrẹ gíga jù lọ nínú àwọn iṣẹ́ àrà Jèhófà fún aráyé?

14 Fífi tí Jèhófà fi ara rẹ̀ hàn lọ́nà gíga jù lọ gẹ́gẹ́ bí oníṣẹ́ àrà fún aráyé ṣẹlẹ̀ nígbà tó fi Ọmọ bíbí rẹ̀ kan ṣoṣo fúnni—ìyẹn, Jésù Kristi, Irú-Ọmọ táa ṣèlérí náà—gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìràpadà. (Jòhánù 3:16; Ìṣe 2:29-36) Ìràpadà náà ló jẹ́ kó ṣeé ṣe láti tún padà bá Ọlọ́run rẹ́. (Mátíù 20:28; Róòmù 5:11) Jèhófà kó àwọn tó kọ́kọ́ mú padà bá ara rẹ̀ rẹ́ jọpọ̀ sínú ìjọ Kristẹni, táa dá sílẹ̀ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ẹ̀mí mímọ́, wọ́n wàásù ìhìn rere jákèjádò, wọ́n fi hàn bí ikú àti àjíǹde Jésù yóò ṣe jẹ́ kó ṣeé ṣe fún aráyé onígbọràn láti gbádùn àwọn ìbùkún ayérayé lábẹ́ àkóso Ìjọba Ọlọ́run ní ọ̀run.

15. Kí ni ohun àgbàyanu tí Jèhófà ti ṣe lọ́jọ́ wa?

15 Ní ọjọ́ wa, Jèhófà ti ṣe ohun àgbàyanu láti kó àwọn tó kẹ́yìn lára àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró jọ. A ti dáwọ́ ẹ̀fúùfù ìparun dúró títí a óò fi fèdìdì di ìyókù àwọn ọ̀kẹ́ méje ó lé ẹgbàajì, tí yóò jọba pẹ̀lú Kristi lọ́run. (Ìṣípayá 7:1-4; 20:6) Ọlọ́run rí sí i pé a dá àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró nídè kúrò nínú ìgbèkùn tẹ̀mí ti “Bábílónì Ńlá,” ìyẹn ilẹ̀ ọba ìsìn èké àgbáyé. (Ìṣípayá 17:1-5) Ìdáǹdè tó wáyé ní 1919 àti bí Ọlọ́run ṣe ń dáàbò bò wọ́n látìgbà yẹn ti jẹ́ kí ìyókù àwọn ẹni àmì òróró ṣe kí ni? Ó ti jẹ́ kí wọ́n máa tàn gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ bí wọ́n ti ń ṣe iṣẹ́ ìjẹ́rìí àṣekágbá kí Jèhófà tó mú òpin dé bá ètò àwọn nǹkan búburú ti Sátánì nígbà “ìpọ́njú ńlá” tó ti dé tán yìí.—Mátíù 24:21; Dáníẹ́lì 12:3; Ìṣípayá 7:14.

16. Kí ló ń ṣẹlẹ̀ nítorí iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà jákèjádò ayé lóde òní?

16 Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tí wọ́n jẹ́ ẹni àmì òróró ti mú ipò iwájú tìtara-tìtara nínú iṣẹ́ wíwàásù Ìjọba náà kárí ayé. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé àwọn púpọ̀ sí i lára “àwọn àgùntàn mìíràn” ti ń di olùjọsìn Jèhófà báyìí. (Jòhánù 10:16) Inú wa dùn pé àǹfààní ṣì ṣí sílẹ̀ fún àwọn ọlọ́kàn tútù ayé láti dara pọ̀ mọ́ wa nínú yíyin Jèhófà. Àwọn tó bá dáhùn sí ìkésíni láti “máà bọ̀” náà yóò ní àǹfààní láti la ìpọ́njú ńlá já, pẹ̀lú ìrètí yíyin Jèhófà títí ayé fáàbàdà.—Ìṣípayá 22:17.

Ẹgbẹẹgbẹ̀rún Ń Wọ́ Tìrítìrí Wá Sínú Ìjọsìn Tòótọ́

17. (a) Báwo ni Jèhófà ṣe ń ṣe àwọn iṣẹ́ àrà nínú iṣẹ́ ìwàásù wa? (b) Báwo ni Sekaráyà 8:23 ṣe ń nímùúṣẹ nísinsìnyí?

17 Lọ́wọ́ táa wà yìí, Jèhófà ń ṣe àwọn iṣẹ́ àrà tó yẹ fún ìyìn nínú iṣẹ́ ìwàásù wa. (Máàkù 13:10) Lẹ́nu àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, ó ti ‘ṣí àwọn ilẹ̀kùn ńlá tí ń ṣamọ̀nà sí ìgbòkègbodò sílẹ̀.’ (1 Kọ́ríńtì 16:9) Èyí ti jẹ́ kó ṣeé ṣe láti polongo ìhìn rere náà jákèjádò àwọn ìpínlẹ̀ tó lọ salalu tí àwọn ọ̀tá òtítọ́ ò ti jẹ́ ká rọ́wọ́ mú tẹ́lẹ̀. Ọ̀pọ̀ tó wà nínú òkùnkùn nípa tẹ̀mí tẹ́lẹ̀ ló ti ń dáhùn sí ìkésíni náà láti wá sin Jèhófà báyìí. Wọ́n ń mú àsọtẹ́lẹ̀ náà ṣẹ, tó sọ pé: “Èyí ni ohun tí Jèhófà àwọn ẹgbẹ́ ọmọ ogun wí, ‘Yóò sì ṣẹlẹ̀ ní ọjọ́ wọnnì pé ọkùnrin mẹ́wàá láti inú gbogbo èdè àwọn orílẹ̀-èdè yóò dì í mú, bẹ́ẹ̀ ni, ní ti tòótọ́, wọn yóò di ibi gbígbárìyẹ̀ lára aṣọ ọkùnrin kan tí ó jẹ́ Júù mú, pé: “Àwa yóò bá yín lọ, nítorí a ti gbọ́ pé Ọlọ́run wà pẹ̀lú yín.”’” (Sekaráyà 8:23) Júù tẹ̀mí, èyíinì ni ìyókù àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró tòde òní, làwọn tí àwọn “ọkùnrin mẹ́wàá” wọ̀nyẹn ń darí ọ̀rọ̀ wọn sí. Níwọ̀n bí mẹ́wàá ti máa ń dúró fún pípé pérépéré àwọn nǹkan ti ilẹ̀ ayé, “ọkùnrin mẹ́wàá” wọnnì dúró fún “ogunlọ́gọ̀ ńlá” tí a mú wá sínú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ pẹ̀lú “Ísírẹ́lì Ọlọ́run,” tí gbogbo wọn sì jọ di “agbo kan.” (Ìṣípayá 7:9, 10; Gálátíà 6:16) Ẹ wo bí inú wa ti dùn tó láti rí àwọn tó pọ̀ tó báyìí nísinsìnyí tí wọ́n jùmọ̀ ń ṣe iṣẹ́ ìsìn mímọ́ gẹ́gẹ́ bí olùjọsìn Jèhófà Ọlọ́run!

18, 19. Ẹ̀rí wo ló wà pé Jèhófà ń bù kún iṣẹ́ ìwàásù náà?

18 Inú wa dùn pé ẹgbẹẹgbàárùn-ún—àní ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún—ló ń tẹ́wọ́ gba ìjọsìn tòótọ́ ní àwọn ilẹ̀ tí ẹ̀sìn èké ti gbilẹ̀ gidigidi nígbà kan rí tó fi jọ pé wọn ò ní lè tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà láé. Ìwọ sáà ṣí ìwé Yearbook of Jehovah’s Witnesses kan tó jẹ́ ti lọ́ọ́lọ́ọ́, kí o sì ka iye ilẹ̀ tí àwọn akéde Ìjọba tó ń ròyìn níbẹ̀ báyìí ti tó ẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rùn-ún [100,000] sí iye tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó àádọ́ta ọ̀kẹ́ [1,000,000]. Èyí jẹ́ ẹ̀rí lílágbára pé Jèhófà ń bù kún iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà.—Òwe 10:22.

19 Gẹ́gẹ́ bí àwọn èèyàn Jèhófà, a ń yin Baba wa ọ̀run, a sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ rẹ̀ pé ó mú kí ìgbésí ayé wa ní ojúlówó ète, pé ó fún wa ní iṣẹ́ tó lérè nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀, àti pé ó mú kí a ní ìrètí aláyọ̀ fún ọjọ́ ọ̀la. A ń fi ìháragàgà fojú sọ́nà fún ìmúṣẹ gbogbo ìlérí tí Ọlọ́run ṣe, a sì ti pinnu pé a ó ‘pa ara wa mọ́ nínú ìfẹ́ Ọlọ́run, pẹ̀lú ìyè àìnípẹ̀kun níwájú.’ (Júúdà 20, 21) Ẹ wo bí inú wa ti dùn tó láti rí i pé iye ogunlọ́gọ̀ ńlá tí ń yin Ọlọ́run báyìí ti tó nǹkan bíi mílíọ̀nù mẹ́fà! Pẹ̀lú ìbùkún Jèhófà tó hàn kedere, a ti ṣètò àwọn àṣẹ́kù ẹni àmì òróró àti àwọn àgùntàn mìíràn alábàákẹ́gbẹ́ wọn sínú àwọn ìjọ tó tó ẹgbẹ̀rún mọ́kànléláàádọ́rùn-ún [91,000], ní igba ó lé márùndínlógójì [235] ilẹ̀. A ń bọ́ gbogbo wa yó nípa tẹ̀mí nípasẹ̀ ìsapá tí “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà ń ṣe láìṣàárẹ̀. (Mátíù 24:45) Ètò àjọ ìṣàkóso Ọlọ́run tó ń tẹ̀ síwájú, tó sì ń fi ìfẹ́ bójú tó wa, ló ń darí ìgbòkègbodò Ìjọba náà ní àádọ́fà [110] ẹ̀ka iléeṣẹ́ ti àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà. A dúpẹ́ pé Jèhófà ti ru àwọn èèyàn rẹ̀ lọ́kàn sókè láti ‘fi ohun ìní wọn tó níye lórí bọlá fún un.’ (Òwe 3:9, 10) Ìdí nìyẹn tí iṣẹ́ ìwàásù wa kárí ayé fi ń bá a lọ, tí à ń ra àwọn ẹ̀rọ ìtẹ̀wé, tí à ń kọ́ àwọn Bẹ́tẹ́lì àti ilé míṣọ́nnárì, tí à ń kọ́ àwọn Gbọ̀ngàn Ìjọba àti Gbọ̀ngàn Àpéjọ táa nílò.

20. Kí ló yẹ ká ṣe lẹ́yìn ríronú lórí àwọn iṣẹ́ àrà Jèhófà tó yẹ fún ìyìn?

20 A ò lè mẹ́nu kan gbogbo iṣẹ́ àrà tó yẹ fún ìyìn tí Baba wa ọ̀run ti ṣe tán. Ṣùgbọ́n ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni tó ní ọkàn títọ́ lè sọ pé òun kò ní dara pọ̀ mọ́ ẹgbẹ́ àwọn olùyin Jèhófà? Rárá o! Nítorí náà, kí gbogbo àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run fi ayọ̀ ké jáde pé: “Ẹ yin Jáà! Ẹ yin Jèhófà láti ọ̀run, ẹ yìn ín ní àwọn ibi gíga. Ẹ yìn ín, gbogbo ẹ̀yin áńgẹ́lì rẹ̀ . . . , ẹyin ọ̀dọ́kùnrin àti ẹ̀yin wúńdíá pẹ̀lú, ẹyin arúgbó pa pọ̀ pẹ̀lú ẹ̀yin ọmọdékùnrin. Kí wọ́n máa yin orúkọ Jèhófà, nítorí pé orúkọ rẹ̀ nìkan ṣoṣo ni ó ga ré kọjá ibi tí ó ṣeé dé. Iyì rẹ̀ ń bẹ lókè ilẹ̀ ayé àti ọ̀run.” (Sáàmù 148:1, 2, 12, 13) Àní sẹ́, ẹ jẹ́ ká máa yin Jèhófà nítorí àwọn iṣẹ́ àrà rẹ̀, láti ìsinsìnyí lọ àti láéláé!

Báwo Lo Ṣe Máa Dáhùn?

• Kí ni díẹ̀ lára àwọn iṣẹ́ Jèhófà tó yẹ fún ìyìn?

• Èé ṣe tó fi wù ọ́ látọkànwá láti máa yin Jèhófà?

• Báwo ni ìrètí wa ṣe tan mọ́ àwọn iṣẹ́ àrà Ọlọ́run?

• Báwo ni Jèhófà ṣe ń ṣe àwọn iṣẹ́ tó yẹ fún ìyìn nínú iṣẹ́ ìwàásù Ìjọba náà?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ǹjẹ́ o máa ń fi tọkàntọkàn kópa nínú kíkọ orin ìyìn sí Jèhófà?

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Inú wa dùn pé àǹfààní ṣì ṣí sílẹ̀ fáwọn ọlọ́kàn tútù láti dara pọ̀ mọ́ wa nínú yíyin Jèhófà