Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Ká Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Nítorí Òmìnira Ìsìn’

‘Ká Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Nítorí Òmìnira Ìsìn’

‘Ká Dúpẹ́ Lọ́wọ́ Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà Nítorí Òmìnira Ìsìn’

ÀPILẸ̀KỌ kan nínú ìwé ìròyìn USA Today, sọ pé: “Kó tó di pé o pa ilẹ̀kùn rẹ dé gbàgà mọ́ Ẹlẹ́rìí Jèhófà kan lójú, kọ́kọ́ sinmẹ̀dọ̀, kóo ronú lórí inúnibíni bíburú jáì tí wọ́n fojú winá rẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí, àti ipa bàǹtàbanta tí wọ́n kó nínú àwọn ọ̀ràn òmìnira tó wà nínú Àtúnṣe Kìíní nínú ìwé òfin, tí gbogbo wa wá ń gbádùn báyìí.” Wọ́n ṣe inúnibíni sí àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ní gbogbo àwọn ọdún 1940, nítorí àwọn ìdí kan tí kíkọ̀ láti kí àsíá wà lára wọn.—Ẹ́kísódù 20:4, 5.

Àwọn ẹjọ́ bí ọgbọ̀n tó ní í ṣe pẹ̀lú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ni wọ́n gbé wá síwájú Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà láàárín ọdún márùn-ún, ìyẹn láti 1938 sí 1943. Àpilẹ̀kọ náà sọ pé: “Léraléra làwọn Ẹlẹ́rìí ń gbé àwọn ìbéèrè gbankọgbì dìde lórí Àtúnṣe Kìíní náà débi pé Adájọ́ Harlan Fiske Stone ní láti kọ̀wé pé, ‘Ó yẹ káwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà gba ẹ̀bùn nítorí ipa tí wọ́n kó nínú yíyanjú àwọn ìṣòro tó jẹ mọ́ òfin òmìnira gbogbo gbòò.’”

Nípa bẹ́ẹ̀, nígbà tó kù díẹ̀ kí àpilẹ̀kọ náà parí, ó sọ pé: “Ó yẹ kí gbogbo ìsìn dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nítorí òmìnira [ìsìn] tí wọ́n mú gbòòrò sí i.”

[Àwọn àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 32]

Àwòrán tí a kọ ọ̀rọ̀ lé lórí, ilé kíkọ́: Josh Mathes ló ya fọ́tò yìí, látinú Àkójọ ti Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà; ìsàlẹ̀ lápá òsì, àwọn adájọ́: látinú Àkójọ ti Ilé Ẹjọ́ Gíga Jù Lọ Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà