Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Nípasẹ̀ Ọgbọ́n Ni Ọjọ́ Wa Yóò Fi Di Púpọ̀’

‘Nípasẹ̀ Ọgbọ́n Ni Ọjọ́ Wa Yóò Fi Di Púpọ̀’

‘Nípasẹ̀ Ọgbọ́n Ni Ọjọ́ Wa Yóò Fi Di Púpọ̀’

TA LÓ lè sẹ́ pe ọgbọ́n kò wúlò nígbà tó bá kan yíyanjú àwọn ìṣòro ìgbésí ayé? Ọgbọ́n tòótọ́ jẹ́ mímọ bí a ṣe ń lo ìmọ̀ àti òye lọ́nà gbígbéṣẹ́. Òun gan-an ni òdìkejì ìwà òmùgọ̀, ìwà òpònú, àti ìwà wèrè. Ìdí nìyẹn tí Ìwé Mímọ́ fi gbà wá níyànjú pé ká ní ọgbọ́n. (Òwe 4:7) Àní sẹ́, ìdí pàtàkì táa fi kọ ìwé Òwe inú Bíbélì ni láti gbin ọgbọ́n àti ìbáwí síni lọ́kàn. Ohun tó fi bẹ̀rẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀ kà báyìí: “Òwe Sólómọ́nì ọmọkùnrin Dáfídì, ọba Ísírẹ́lì, fún ènìyàn láti mọ ọgbọ́n àti ìbáwí.”—Òwe 1:1, 2.

Ẹ jẹ́ ká gbé àwọn ẹ̀kọ́ yíyèkooro tó wà nínú díẹ̀ lára àwọn orí tó bẹ̀rẹ̀ ìwé Òwe yẹ̀ wò. Bí ìgbà tí baba onífẹ̀ẹ́ kan bá ń rọ àwọn ọmọ rẹ̀ ni Sólómọ́nì ṣe ń pàrọwà sí àwọn òǹkàwé rẹ̀ láti gba ìbáwí, kí wọ́n sì fiyè sí ọgbọ́n. (Orí 1 àti 2) Ó fi bí a ṣe lè ní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Jèhófà àti bí a ṣe lè pa ọkàn wa mọ́ hàn wá. (Orí 3 àti 4) Ó gbà wá níyànjú láti jẹ́ oníwà mímọ́. (Orí 5 àti 6) Bẹ́ẹ̀ ni o, ìsọfúnni náà wúlò fún wa gan-an ni bó ṣe táṣìírí ọgbọ́nkọ́gbọ́n tí oníwà pálapàla kan máa ń dá. (Orí 7) Ọ̀nà tí ọgbọ́n tí a sọ̀rọ̀ rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ènìyàn fi ń pàrọwà síni mà fa gbogbo ènìyàn mọ́ra o! (Orí 8) Kó tó di pé Sólómọ́nì Ọba bẹ̀rẹ̀ sí sọ̀rọ̀ nípa àwọn òwe kọ̀ọ̀kan tó pa nínú àwọn orí tó wà níwájú, ó ṣe àkópọ̀ àwọn ohun tó ti jíròrò láti ìbẹ̀rẹ̀ lọ́nà tó tani jí.—Orí 9.

‘Ẹ Wá, Ẹ Fi Oúnjẹ Mi Bọ́ Ara Yín, Kí Ẹ sì Mu Nínú Wáìnì Mi’

Ìparí apá àkọ́kọ́ ìwé Òwe kì í ṣe àkópọ̀ wuuruwu, tó wulẹ̀ to àwọn ìmọ̀ràn tó ti mẹ́nu kan tẹ́lẹ̀ lẹ́sẹẹsẹ. Dípò ìyẹn, ṣe ló kọ ọ́ lọ́nà tó mórí yá gágá pẹ̀lú àwọn àpèjúwe tó tani jí, tó mú kí àwọn òǹkàwé máa wá ọgbọ́n.

Orí kẹsàn-án ìwé Òwe inú Bíbélì bẹ̀rẹ̀ pẹ̀lú ọ̀rọ̀ tó sọ pé: “Ọgbọ́n tòótọ́ ti kọ́ ilé rẹ̀; ó ti gbẹ́ ọwọ̀n rẹ̀ méjèèje.” (Òwe 9:1) Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan dá a lábàá pé ọ̀rọ̀ náà, ‘ọwọ̀n méje,’ ń “ṣàpèjúwe ilé ńlá kan tó ní àgbàlá, òpó mẹ́ta mẹ́ta ló gbé ilé náà ró lẹ́gbẹ̀ẹ́ kọ̀ọ̀kan, ó sì tún ní òpó kan tó gbé e ró láàárín, ní apá ibi tó dojú kọ ibi gbalasa tó jẹ́ ọ̀nà àbáwọlé.” Bó ti wù kó rí, ọgbọ́n tòótọ́ ti kọ́lé tó fìdí múlẹ̀ gbọn-in kí ó lè ríbi gba ọ̀pọ̀ àlejò sí.

Ohun gbogbo ti wà ní sẹpẹ́ fún àsè. Ẹran wà ńbẹ̀, wáìnì náà kò gbẹ́yìn. Ọgbọ́n ti fúnra rẹ̀ bójú tó bí wọ́n ṣe gbọ́ oúnjẹ náà àti bí wọ́n ṣe tẹ́ tábìlì. “Ó ti ṣètò ẹran pípa rẹ̀; ó ti ṣe àdàlù wáìnì rẹ̀; ju èyíinì lọ, ó ti ṣètò tábìlì rẹ̀.” (Òwe 9:2) Ó hàn gbangba pé oúnjẹ tẹ̀mí téèyàn gbọ́dọ̀ jẹ ní àjẹkúnná ti wà ní sẹpẹ́ lórí tábìlì ìṣàpẹẹrẹ yìí.—Aísáyà 55:1, 2.

Àwọn wo la pè síbi àsè tí ọgbọ́n tòótọ́ sè yìí? “Ó ti rán àwọn ẹmẹ̀wà rẹ̀ obìnrin jáde, kí ó lè ké jáde ní orí àwọn ibi gíga ìlú pé: ‘Ẹnì yòówù tí ó bá jẹ́ aláìní ìrírí, kí ó yà síhìn-ín.’ Ẹnì yòówù tí ọkàn-àyà bá kù fún-ó wí fún un pé: ‘Ẹ wá, ẹ fi oúnjẹ mi bọ́ ara yín, kí ẹ sì ṣàjọpín nínú mímu wáìnì tí mo ti dà lù. Ẹ fi àwọn aláìní ìrírí sílẹ̀, kí ẹ sì máa wà láàyè nìṣó, kí ẹ sì máa rìn tààrà ní ọ̀nà òye.’”Òwe 9:3-6.

Ọgbọ́n ti rán àwọn omidan rẹ̀ jáde láti lọ pe àwọn èrò. Wọ́n ti lọ sí àwọn ibi tí èrò ń pọ̀ sí, tí wọ́n ti lè rí èrò púpọ̀ pè. Gbogbo ènìyàn ni wọ́n pè—àwọn tí “ọkàn-àyà kù fún,” tàbí ẹni tí kò ní òye, títí kan àwọn tí kò ní ìrírí. (Òwe 9:4) Ó sì tún nawọ́ ìlérí ìyè sí wọn. Ó dájú pé ọgbọ́n tó wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, títí kan èyí tó wà nínú ìwé Òwe wà lárọ̀ọ́wọ́tó olúkúlùkù. Lóde òní, àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà, táa jẹ́ ońṣẹ́ fún ọgbọ́n tòótọ́, ń ké sí àwọn èèyàn, níbikíbi táa bá ti rí wọn, pé kí wọ́n wá kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Ní ti tòótọ́, gbígba ìmọ̀ yìí lè yọrí sí ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòhánù 17:3.

Àwọn Kristẹni gbọ́dọ̀ fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ gba ìbáwí tí ọgbọ́n ń fúnni. Èyí ṣe pàtàkì gan-an fáwọn ọ̀dọ́ àtàwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà. Nítorí pé ìrírí tí wọ́n ní nínú títọ ọ̀nà Ọlọ́run kò tó nǹkan, wọ́n lè jẹ́ ẹni tí “ọkàn-àyà kù fún.” Kì í ṣe pé gbogbo èrò inú wọn burú, àmọ́ ó gba àkókò àti ìsapá kí ọkàn èèyàn tó lè di èyí tó ń múnú Jèhófà Ọlọ́run dùn ní ti gidi. Èyí béèrè pé kí wọ́n mú èrò, ìfẹ́ ọkàn, ìfẹ́ni, àti àwọn góńgó wọn bára mu pẹ̀lú àwọn ohun tí Ọlọ́run tẹ́wọ́ gbà. Ó ṣe pàtàkì gan-an pé kí wọ́n “ní ìyánhànhàn fún wàrà aláìlábùlà tí ó jẹ́ ti ọ̀rọ̀ náà.”—1 Pétérù 2:2.

Ní ti tòótọ́, ǹjẹ́ kò yẹ kí gbogbo wa kẹ́kọ̀ọ́ kí ó ré kọjá “àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ ẹ̀kọ́”? Dájúdájú, ó yẹ ká nífẹ̀ẹ́ sí “àwọn ohun ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run,” ká sì máa gba okun láti inú oúnjẹ líle tó wà fún àwọn tó dàgbà dénú. (Hébérù 5:12–6:1; 1 Kọ́ríńtì 2:10) “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye,” tí Jésù Kristi fúnra rẹ̀ ń darí, ń fi taápọntaápọn pèsè oúnjẹ tẹ̀mí tó bọ́ sí àsìkò fún gbogbo wa. (Mátíù 24:45-47) Ǹjẹ́ kí a máa jẹun lórí tábìlì ọgbọ́n nípa fífi aápọn kẹ́kọ̀ọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run àti àwọn ìtẹ̀jáde táa gbé ka Bíbélì, èyí tí ẹgbẹ́ ẹrú náà ń pèsè.

“Má Ṣe Bá Olùyọṣùtì Wí”

Ẹ̀kọ́ tí ọgbọ́n fi ń kọ́ni tún ní ìbáwí nínú. Kì í ṣe gbogbo èèyàn ló ń gba ìbáwí tí ọgbọ́n ń fúnni yìí. Ìdí nìyẹn tí ìparí apá àkọ́kọ́ nínú ìwé Òwe fi ṣe kìlọ̀kìlọ̀ pé: “Ẹni tí ó bá ń tọ́ olùyọṣùtì sọ́nà ń gba àbùkù fún ara rẹ̀, ẹni tí ó bá sì ń fún ẹni burúkú ní ìbáwí àfitọ́nisọ́nà—àbùkù ni fún un. Má ṣe bá olùyọṣùtì wí, kí ó má bàa kórìíra rẹ.”Òwe 9:7, 8a.

Ńṣe ni olùyọṣùtì máa ń kórìíra ẹni tó fẹ́ gbìyànjú láti ràn án lọ́wọ́ láti mú ipa ọ̀nà rẹ̀ tọ́. Ẹni ibi kì í mọyì ìbáwí rárá. Ẹ ò rí i pé kò bọ́gbọ́n mu rárá láti máa fi òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tó gbayì kọ́ ẹni tó kórìíra òtítọ́ tàbí tó wulẹ̀ ń wá ọ̀nà láti pẹ̀gàn òtítọ́! Nígbà tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń wàásù ní Áńtíókù, ó bá ẹgbẹ́ àwọn Júù kan tó kórìíra òtítọ́ pàdé. Wọ́n gbìyànjú láti mú un wọnú àríyànjiyàn nípa títa kò ó lọ́nà ìsọ̀rọ̀ òdì, àmọ́ ohun tí Pọ́ọ̀lù kàn fi dá wọn lóhùn ni pé: “Níwọ̀n bí ẹ ti ń sọ́gọ [ọ̀rọ̀ Ọlọ́run] dànù kúrò lọ́dọ̀ yín, tí ẹ kò sì ka ara yín yẹ fún ìyè àìnípẹ̀kun, wò ó! a yíjú sí àwọn orílẹ̀-èdè.”—Ìṣe 13:45, 46.

Níbi táa ti ń gbìyànjú láti mú ìhìn rere Ìjọba náà dé ọ̀dọ̀ àwọn olóòótọ́ ọkàn, ǹjẹ́ kí a máa ṣọ́ra láti má ṣe kó wọnú iyàn jíjà pẹ̀lú àwọn olùyọṣùtì, tàbí ká máa bá wọn fa ọ̀rọ̀. Kristi Jésù pa á láṣẹ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Nígbà tí ẹ bá ń wọ ilé, ẹ kí agbo ilé náà; bí ilé náà bá sì yẹ, kí àlàáfíà tí ẹ fẹ́ fún un wá sórí rẹ̀; ṣùgbọ́n bí kò bá yẹ, kí àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ yín padà sọ́dọ̀ yín. Ibi yòówù tí ẹnikẹ́ni kò bá ti gbà yín wọlé tàbí fetí sí ọ̀rọ̀ yín, nígbà tí ẹ bá ń jáde kúrò ní ilé yẹn tàbí ìlú ńlá yẹn, ẹ gbọn ekuru ẹsẹ̀ yín dànù.”—Mátíù 10:12-14.

Ojú tí ọlọgbọ́n èèyàn fi ń wo ìbáwí yàtọ̀ pátápátá sí ti olùyọṣùtì. Sólómọ́nì sọ pé: “Fún ọlọ́gbọ́n ní ìbáwí àfitọ́nisọ́nà, òun yóò sì nífẹ̀ẹ́ rẹ. Fi fún ọlọ́gbọ́n, òun yóò sì túbọ̀ gbọ́n sí i.” (Òwe 9:8b, 9a) Ọlọgbọ́n èèyàn mọ̀ pé “kò sí ìbáwí tí ó dà bí ohun ìdùnnú nísinsìnyí, bí kò ṣe akó-ẹ̀dùn-ọkàn-báni; síbẹ̀ nígbà tí ó bá yá, fún àwọn tí a ti kọ́ nípasẹ̀ rẹ̀, a máa so èso ẹlẹ́mìí àlàáfíà, èyíinì ni, òdodo.” (Hébérù 12:11) Bí ìbáwí náà tiẹ̀ dà bí èyí tó dunni, èé ṣe tí a ó fi máa ṣàwáwí tàbí kí a máa wí àwíjàre bí gbígbà á yóò bá mú wa gbọ́n sí i?

Ọlọgbọ́n ọba náà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Fi ìmọ̀ fún olódodo, òun yóò sì pọ̀ sí i ní ẹ̀kọ́.” (Òwe 9:9b) Kò sẹ́ni tó ti gbọ́n kọjá ẹ̀kọ́ kíkọ́, kò sì sẹ́ni tó ti dàgbà jù ú lọ. Ẹ wò bínú wa ṣe máa ń dùn tó nígbà táa bá rí àwọn tó jẹ́ arúgbó pàápàá tí wọ́n ń tẹ́wọ́ gba òtítọ́, tí wọ́n sì ń ya ara wọn sí mímọ́ fún Jèhófà! Ǹjẹ́ kí àwa náà làkàkà láti máa nífẹ̀ẹ́ sí ẹ̀kọ́ kíkọ́ kí èrò inú wa lè máa jí pépé.

‘A Ó Fi Ọ̀pọ̀ Ọdún Ìwàláàyè Kún Un fún Ọ’

Nígbà tí Sólómọ́nì ń sọ̀rọ̀ nípa kókó pàtàkì inú ẹ̀kọ́ tí a ń gbé yẹ̀ wò yìí, ó fi ohun tó pọndandan kéèyàn ṣe kó tó lè ní ọgbọ́n kún un. Ó kọ̀wé pé: “Ìbẹ̀rù Jèhófà ni ìbẹ̀rẹ̀ ọgbọ́n, ìmọ̀ Ẹni Mímọ́ Jù Lọ sì ni ohun tí òye jẹ́.” (Òwe 9:10) Kò sí bí a ṣe lè ní ọgbọ́n Ọlọ́run láìjẹ́ pé a ní ọ̀wọ̀ jíjinlẹ̀ fún Ọlọ́run tòótọ́. Èèyàn lè ní èrò inú tó kún fún ìmọ̀, ṣùgbọ́n bí kò bá ní ìbẹ̀rù Jèhófà, irú ẹni bẹ́ẹ̀ kò ní lo ìmọ̀ yẹn lọ́nà tó bọlá fún Ẹlẹ́dàá. Ó tiẹ̀ lè máa parí èrò rẹ̀ sí ohun tó lòdì sí ohun tí gbogbo èèyàn mọ̀, kó wá jẹ́ kí àwọn èèyàn máa fojú òmùgọ̀ wo òun. Ní àfikún sí i, ìmọ̀ Jèhófà, Ẹni Mímọ́ Jù Lọ, ṣe pàtàkì láti jèrè òye tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn ànímọ́ pàtàkì tí ọgbọ́n ní.

Èso wo ni ọgbọ́n ń mú jáde? (Òwe 8:12-21, 35) Ọba Ísírẹ́lì náà sọ pé: “Nípasẹ̀ mi ni ọjọ́ rẹ yóò fi di púpọ̀, a ó sì fi ọ̀pọ̀ ọdún ìwàláàyè kún un fún ọ.” (Òwe 9:11) Ọjọ́ gígùn àti ọ̀pọ̀ ọdún ìwàláàyè ni àbájáde bíbá ọgbọ́n rìn. Bẹ́ẹ̀ ni o, “ọgbọ́n máa ń pa àwọn tí ó ni ín mọ́ láàyè.”—Oníwàásù 7:12.

Ojúṣe ẹnì kọ̀ọ̀kan wa ni láti sapá ká lè jèrè ọgbọ́n. Nígbà tí Sólómọ́nì ń tẹnu mọ́ kókó yìí, ó ní: “Bí o bá ti di ọlọ́gbọ́n, o ti di ọlọ́gbọ́n fún ire ara rẹ; bí o bá sì ti yọ ṣùtì, ìwọ ni yóò rù ú, ìwọ nìkan ṣoṣo.” (Òwe 9:12) Ẹni tí ó jẹ́ ọlọgbọ́n, gbọ́n fún àǹfààní ara rẹ̀, olùyọṣùtì sì ni yóò dá ni ẹ̀bi ìyà rẹ̀. Láìsí àní-àní, ohun tí a bá gbìn la óò ká. Nítorí ìdí èyí, ẹ jẹ́ ká ‘dẹ etí wa sí ọgbọ́n.’—Òwe 2:2.

“Dìndìnrìn Obìnrin Jẹ́ Aláriwo Líle”

Ní òdìkejì, Sólómọ́nì wá sọ pé: “Dìndìnrìn obìnrin jẹ́ aláriwo líle. Òpè ni, kò sì mọ nǹkan kan rárá. Ó jókòó sí ẹnu ọ̀nà ilé ara rẹ̀, sórí ìjókòó, ní àwọn ibi gíga ìlú, láti nahùn pe àwọn tí ń kọjá lọ ní ọ̀nà, àwọn tí ń lọ tààrà ní ipa ọ̀nà wọn, pé: ‘Ẹnì yòówù tí ó bá jẹ́ aláìní ìrírí, kí ó yà síhìn-ín.’”—Òwe 9:13-16a.

A fi ìwà dìndìnrìn wé obìnrin tó jẹ́ aláriwo, tí kò lẹ́kọ̀ọ́, tó sì jẹ́ aláìmọ̀kan. Òun náà ti kọ́ ilé kan. Ó sì ti gbà á gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ láti máa ké sí ẹnikẹ́ni tó bá jẹ́ aláìní ìrírí. Nítorí náà, àwọn tó ń kọjá lè yan ohun tó wù wọ́n. Ṣé ìpè ọgbọ́n ni kí wọ́n jẹ́ ni, tàbí ti dìndìnrìn?

“Omi Tí A Jí Dùn”

Àtọgbọ́n àti ìwà dìndìnrìn ló ń ké sí àwọn olùgbọ́ wọn láti “yà síhìn-ín.” Àmọ́, ohun tí wọ́n ń pe èrò sí yàtọ̀ síra o. Ọgbọ́n ń pe àwọn èèyàn wá síbi àsè wáìnì, ẹran, àti oúnjẹ. Òòfà tí dìndìnrìn ń lò ní tirẹ̀ rán wa létí àwọn ọ̀nà obìnrin aláìmọ́. Sólómọ́nì sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ọkàn-àyà bá sì kù fún—ó wí fún un pẹ̀lú pé: ‘Omi tí a jí dùn, oúnjẹ tí a sì jẹ ní ìkọ̀kọ̀—ó dùn mọ́ni.’”Òwe 9:16b, 17.

Dípò àdàlù wáìnì, “dìndìnrìn obìnrin” pèsè omi tí a jí. (Òwe 9:13) Nínú Ìwé Mímọ́, níní ìbálòpọ̀ pẹ̀lú aya tó jẹ́ olùfẹ́ ọ̀wọ́n la fi wé mímu omi tí ń tuni lára. (Òwe 5:15-17) Omi tí a jí mu la fi wé ìbálòpọ̀ oníṣekúṣe tí a ṣe ní ìkọ̀kọ̀. Irú omi bẹ́ẹ̀ máa ń dà bí èyí tó dùn—bíi pé ó dára ju wáìnì lọ pàápàá—nítorí pé jíjí ni a jí i, tó sì wá dà bíi pé a ṣe ohun kan ní àṣegbé. Oúnjẹ tí a jí jẹ ní ìkọ̀kọ̀ lè dà bí èyí tó dùn mọ́ni ju oúnjẹ àti ẹran tí ọgbọ́n pèsè nítorí pé ọ̀nà àìṣòótọ́ ni a gbà rí i. Ìwà arìndìn ni kéèyàn máa fojú tó dáa wo ohun táa kà léèwọ̀, táa sì wá ń jí ṣe ní ìkọ̀kọ̀.

Nígbà tí ìkésíni ọgbọ́n wé mọ́ ìlérí ìyè, dìndìnrìn obìnrin kò sọ ohun tó máa jẹ́ àbájáde títẹ̀ lé àwọn ọ̀nà tirẹ̀. Àmọ́, Sólómọ́nì kìlọ̀ pé: “Kò mọ̀ pé àwọn tí ó jẹ́ aláìlè-ta-pútú nínú ikú ń bẹ níbẹ̀, pé àwọn tí obìnrin náà pè wọlé ń bẹ ní àwọn ibi rírẹlẹ̀ Ṣìọ́ọ̀lù.” (Òwe 9:18) Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan kọ̀wé pé: “Ilé [dìndìnrin obìnrin] kì í ṣe ilé téèyàn ń gbé bí kò ṣe ìyẹ̀wù òkú. Bí o bá wọ inú rẹ̀, o ò ní jáde láàyè.” Gbígbé ìgbésí ayé oníwà pálapàla kò bọ́gbọ́n mu rárá; ikú lòpin rẹ̀.

Jésù Kristi sọ pé: “Ẹ gba ẹnubodè tóóró wọlé; nítorí fífẹ̀ àti aláyè gbígbòòrò ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìparun, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn tí ń gbà á wọlé; nígbà tí ó jẹ́ pé, tóóró ni ẹnubodè náà, híhá sì ni ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè, díẹ̀ sì ni àwọn tí ń rí i.” (Mátíù 7:13, 14) Ǹjẹ́ kí a máa jẹun lórí tábìlì ọgbọ́n, kí a sì wà lára àwọn tó wà ní ojú ọ̀nà tí ó lọ sínú ìyè.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Ọlọgbọ́n ènìyàn ń gba ìbáwí

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

Níní ọgbọ́n jẹ́ ẹrù iṣẹ́ ẹni kọ̀ọ̀kan wa