Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Níwọ̀n bí Jèhófà ti múra tán láti dárí ẹ̀ṣẹ̀ jini nípasẹ̀ ìtóye ẹbọ ìràpadà, èé ṣe tó fi ṣe pàtàkì kí àwọn Kristẹni jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wọn fáwọn àgbà ọkùnrin nínú ìjọ?

Gẹ́gẹ́ bí a ti lè rí i nínú ọ̀ràn ti Dáfídì àti Bátí-ṣébà, bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀ṣẹ̀ Dáfídì wúwo gan-an, síbẹ̀ Jèhófà dárí jì í nítorí pé Dáfídì ronú pìwà dà tọkàntọkàn. Nígbà tí Nátánì wòlíì tọ Dáfídì wá, ó jẹ́wọ́ ní tààràtà pé: “Èmi ti ṣẹ̀ sí Jèhófà.”—2 Sámúẹ́lì 12:13.

Àmọ́ o, kì í ṣe kìkì pé Jèhófà ń tẹ́wọ́ gba ìjẹ́wọ́ àtọkànwá, tó sì ń dárí ji ẹlẹ́ṣẹ̀ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó tún máa ń ṣe ètò onífẹ̀ẹ́ láti ran ẹlẹ́ṣẹ̀ náà lọ́wọ́ láti padà bọ̀ sípò nípa tẹ̀mí. Nínú ọ̀ràn ti Dáfídì, ìrànlọ́wọ́ náà wá nípasẹ̀ Nátánì wòlíì. Lónìí, àwọn àgbà ọkùnrin, tàbí àwọn alàgbà tó dàgbà dénú nípa tẹ̀mí ń bẹ nínú ìjọ Kristẹni. Jákọ́bù ọmọlẹ́yìn ṣàlàyé pé: “Ẹnikẹ́ni ha wà tí ń ṣàìsàn [nípa tẹ̀mí] láàárín yín bí? Kí ó pe àwọn àgbà ọkùnrin ìjọ wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀, kí wọ́n sì gbàdúrà lé e lórí, ní fífi òróró pa á ní orúkọ Jèhófà. Àdúrà ìgbàgbọ́ yóò sì mú aláàárẹ̀ náà lára dá, Jèhófà yóò sì gbé e dìde. Pẹ̀lúpẹ̀lù, bí ó bá ti dá ẹ̀ṣẹ̀, a óò dárí rẹ̀ jì í.”—Jákọ́bù 5:14, 15.

Àwọn alàgbà onírìírí lè ṣe púpọ̀ láti pẹ̀rọ̀ sí àròdùn ọkàn ẹlẹ́ṣẹ̀ kan tó ti ronú pìwà dà. Wọ́n ń sapá láti fara wé Jèhófà nínú bí wọ́n ṣe ń bá irú ẹlẹ́ṣẹ̀ bẹ́ẹ̀ lò. Wọn kì í gbójú mọ́ni, kódà bó tiẹ̀ jẹ́ pé ìbáwí mímúná ló tọ́ sí onítọ̀hún. Kàkà bẹ́ẹ̀, ṣe ni wọ́n ń fi tìyọ́nú-tìyọ́nú ronú lórí ohun tí ẹlẹ́ṣẹ̀ náà nílò, lọ́wọ́ tó wà yẹn. Wọ́n máa ń fi sùúrù tún ojú ìwòye ẹlẹ́ṣẹ̀ náà ṣe nípa lílo Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. (Gálátíà 6:1) Bí ẹnì kan kò bá tiẹ̀ fínnú fíndọ̀ jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ rẹ̀, a ṣì lè sún un ronú pìwà dà nígbà táwọn alàgbà bá tọ̀ ọ́ lọ, gẹ́gẹ́ bí Dáfídì ti ronú pìwà dà nígbà tí Nátánì tọ̀ ọ́ lọ. Ìtìlẹyìn táwọn alàgbà bá tipa bẹ́ẹ̀ ṣe lè ran ẹlẹ́ṣẹ̀ náà lọ́wọ́ láti yẹra fún títún ẹ̀ṣẹ̀ yẹn dá, kí ó sì wá yọrí sí dídi ẹni tó jingíri sínú ẹ̀ṣẹ̀ dídá.—Hébérù 10:26-31.

Ó dájú pé kò rọrùn láti jẹ́wọ́ àwọn nǹkan ìtìjú téèyàn ṣe fún ẹlòmíì, kí a sì wá tọrọ àforíjì. Ó gba okun inú. Àmọ́, ronú fún ìṣẹ́jú kan lórí ṣíṣàì ṣe bẹ́ẹ̀. Ọkùnrin kan tí kò jẹ́wọ́ ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo tó dá fáwọn alàgbà nínú ìjọ sọ pé: “Àròdùn ọkàn tí mo ní kò jẹ́ kí n gbádùn rárá. Mo wá bẹ̀rẹ̀ sí fi taratara kópa nínú iṣẹ́ ìwàásù, àmọ́ àròdùn ọ̀hún ò lọ.” Ó ronú pé jíjẹ́wọ́ fún Ọlọ́run nínú àdúrà ti tó, ṣùgbọ́n ó ṣe kedere pé kò tó, nítorí ìmí ẹ̀dùn rẹ̀ kò yàtọ̀ sí ti Dáfídì Ọba. (Sáàmù 51:8, 11) Ẹ wo bó ti dára tó láti tẹ́wọ́ gba ìrànlọ́wọ́ onífẹ̀ẹ́ tí Jèhófà pèsè nípasẹ̀ àwọn alàgbà!