Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìyípadà Nínú Ìlànà Ìwà Híhù Ti Fa Àìfọkàntánni

Ìyípadà Nínú Ìlànà Ìwà Híhù Ti Fa Àìfọkàntánni

Ìyípadà Nínú Ìlànà Ìwà Híhù Ti Fa Àìfọkàntánni

Nígbà ayé Ọba Henry Kìíní ti ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì (ọdún 1100 sí 1135), ìwọ̀n yáàdì kan jẹ́ “láti ṣóńṣó igi imú Ọba títí dé ṣóńṣó àtàǹpàkò ọwọ́ rẹ̀ nígbà tó bá nawọ́ síwájú.” Báwo ni ọ̀pá ìdiwọ̀n àwọn ọmọ abẹ́ Ọba Henry ṣe gún régé tó? Ó jọ pé èèyàn gbọ́dọ̀ lọ rí ọba kí ó tó lè ní ọ̀pá ìdiwọ̀n tó gún régé.

ÌLÀNÀ táa fi ń díwọ̀n nǹkan lóde òní gún régé ju tìgbà yẹn lọ. Nítorí náà, ohun tí mítà jẹ́ ni bí ìmọ́lẹ̀ ti ń rìn jìnnà tó nínú àlàfo ní ìdá 299,792,458 ìṣẹ́jú àáyá kan. Ní pàtó, ìgbì ìmọ́lẹ̀ táa ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ yìí kì í yí padà, àkànṣe ẹ̀rọ kan ló sì ń tú u jáde. Bí àwọn èèyàn níbi gbogbo bá ní ẹ̀rọ tó ní ọ̀pá ìdiwọ̀n yẹn, wọn lè mọ̀ bóyá ìwọ̀n tí wọ́n fi ń díwọ̀n bí nǹkan ṣe gùn tó bá ti gbogbo ayé mu.

Àmọ́ o, bí ọ̀pá ìdiwọ̀n bá yí padà, bó ti wù kí ìyípadà ọ̀hún kéré mọ, ó lè dá iyèméjì sílẹ̀. Ìyẹn ni wọ́n fi ń sapá gidigidi láti rí i pé ọ̀pá ìdiwọ̀n wà bó ṣe wà. Fún àpẹẹrẹ, ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ọ̀pá ìdiwọ̀n tí wọ́n ń tẹ̀ lé fún dídíwọ̀n bí nǹkan ṣe wúwo tó ni irin nínípọn kan tí ìwọ̀n rẹ̀ jẹ́ kìlógíráàmù kan. Ibi Ìwádìí Nípa Ìmọ̀ Ìjìnlẹ̀ Tó Jẹ́ Ti Ìjọba ni wọ́n gbé irin yìí sí. Àwọn nǹkan tí ọkọ̀ ilẹ̀ àti ọkọ̀ òfuurufú tí ń kọjá ń tú sínú afẹ́fẹ́ ń mú kí ọ̀pá ìdiwọ̀n kìlógíráàmù yìí wúwo sí i lójoojúmọ́. Àmọ́ irin yìí jẹ́ ẹ̀dà ọ̀pá tí wọ́n ń lò kárí ayé, èyí táa gbé sábẹ́ ohun èlò onírìísí aago kan tó wà nínú àjàalẹ̀ ní Iléeṣẹ́ Tó Ń Bójú Tó Ọ̀ràn Ìwọ̀n àti Òṣùwọ̀n Lágbàáyé nílùú Sèvres, ní ilẹ̀ Faransé. Síbẹ̀ náà, ìwọ̀n irin yìí ń yí padà nítorí àwọn ìdọ̀tí tíntìntín tí kò ṣeé fojú rí. Di báa ti ń wí yìí, àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n nípa òṣùwọ̀n lágbàáyé kò tíì hùmọ̀ ọ̀pá ìdiwọ̀n tí kì í yí padà.

Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìyípadà pẹ́ẹ́pẹ̀ẹ̀pẹ́ lè má dà bí nǹkan bàbàrà lójú àwọn kan, àmọ́ ìyípadà pátápátá nínú ọ̀pá ìdiwọ̀n lè fa ìdàrúdàpọ̀. Ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, ìyípadà kúrò nínú lílo ìwọ̀n ti tẹ́lẹ̀ (pọ́n-ùn àti ounce) sí èyí tí wọ́n ń lò báyìí (kìlógíráàmù àti gíráàmù) jẹ́ kí ara bẹ̀rẹ̀ sí fu àwọn èèyàn gan-an, ó sì nídìí tó fi rí bẹ́ẹ̀. Ìdí ni pé àwọn ọlọ́jà tó jẹ́ onímàgòmágó bẹ̀rẹ̀ sí rẹ́ àwọn èèyàn jẹ nítorí pé ìwọ̀n tuntun náà ò yé wọn, fún ìdí yìí wọn kì í kó ṣéńjì pé fáwọn oníbàárà wọn.

Ìlànà Ìdílé àti Ìlànà Ìwà Rere

Ìyípadà nínú ìlànà ìdílé àti ìlànà ìwà rere ńkọ́? Ìyọrísí irú ìyípadà bẹ́ẹ̀ kì í bímọ re rárá. Àwọn ìròyìn lọ́ọ́lọ́ọ́ nípa àwọn ìdílé tí ń tú ká, ìwà ìṣekúṣe, àti híhùwà àìdáa sáwọn ọmọdé ti jẹ́ kí ara ọ̀pọ̀ èèyàn bù máṣọ, ó sì ti fi hàn kedere pé ìlànà ìwà híhù ti dìdàkudà láyé táa wà yìí. Àwọn ìdílé olóbìí kan, àwọn ọmọ tí “àwọn òbí” abẹ́yà-kan-náà-lò-pọ̀ tọ́ dàgbà, àti fífi ìbálòpọ̀ fìtínà àwọn ọmọ tí àwọn aláṣẹ àdúgbò ń tọ́jú, ń wáyé nítorí pé àwọn èèyàn ti pa ìwà ọmọlúwàbí tì. Ńṣe làwọn èèyàn túbọ̀ ń di “olùfẹ́ ara wọn, . . . aláìní ìfẹ́ni àdánidá, . . . aláìní ìfẹ́ ohun rere, . . . olùfẹ́ adùn dípò olùfẹ́ Ọlọ́run,” bí Bíbélì ti sọ ní nǹkan bí ẹgbàá ọdún sẹ́yìn.—2 Tímótì 3:1-4.

Ìlọsílẹ̀ nínú ìlànà ìwà híhù ló ń fa àìfọkàntánni tó kún fún ìwà ìkà. Lẹ́nu àìpẹ́ yìí, pípa ìlànà ìwà rere tì pátápátá nínú iṣẹ́ ìṣègùn hàn sójútáyé ní Hyde, ìlú kan ní àríwá ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì, níbi tí àwọn aráàlú ti ń sọ àṣírí ara wọn fún àwọn dókítà ìdílé “tí wọ́n bọ̀wọ̀ fún tí wọ́n sì fọkàn tán.” Ṣùgbọ́n ó ṣeni láàánú pé wọ́n ti dalẹ̀ wọn báyìí. Lọ́nà wo? Àwọn ìròyìn tó jáde nígbà ìgbẹ́jọ́ kan fi hàn pé dókítà ìdílé kan ló fa ikú ó kéré tán mẹ́ẹ̀ẹ́dógún lára àwọn obìnrin tó sọ pé òun ń tọ́jú. Àní, èyí wá sún àwọn ọlọ́pàá láti tún padà lọ ṣàyẹ̀wò àwọn èèyàn tó lé ní àádóje [130] tó tọwọ́ dókítà náà kú. Ibi tí ìwà ọ̀dàlẹ̀ náà burú dé wá ṣe kedere nígbà tí wọ́n dá dókítà náà lẹ́bi, tí wọ́n sì sọ ọ́ sẹ́wọ̀n. Àwọn òṣìṣẹ́ méjì lọ́gbà ẹ̀wọ̀n náà tó jọ pé dókítà yìí ló pa màmá wọn ni wọ́n wá iṣẹ́ mìíràn fún, kí ó máà tún lọ jẹ́ pé àwọn ni yóò máa tọ́jú ẹlẹ́wọ̀n burúkú yìí. Abájọ tí ìwé ìròyìn The Daily Telegraph fi pe ọ̀daràn dókítà yìí ní “‘Èṣù’ dókítà” nígbà tó ń ròyìn nípa ẹjọ́ yìí.

Lójú àwọn ìlànà tó ń yí padà, tó sì ń dìdàkudà láwọn apá púpọ̀ nínú ìgbésí ayé, ta ni o lè fi gbogbo ara gbẹ́kẹ̀ lé? Ibo lo ti lè rí àwọn ìlànà tí kì í yí padà, tó sì ní ọlá àṣẹ tó ǹ mú kí àwọn èèyàn tẹ̀ lé wọn? Àpilẹ̀kọ tó tẹ̀ lé e yóò dáhùn ìbéèrè wọ̀nyí.