Ayọ̀ Mí Kún, Ẹnu Mi Ò Sì Gbọpẹ́, Láìka Àdánù Ńláǹlà Sí
Ìtàn Ìgbésí Ayé
Ayọ̀ Mí Kún, Ẹnu Mi Ò Sì Gbọpẹ́, Láìka Àdánù Ńláǹlà Sí
GẸ́GẸ́ BÍ NANCY E. PORTER ṢE SỌ Ọ́
June 5, 1947 ni, ní ìrọ̀lẹ́ ọjọ́ kan tí ooru mú ní Bahamas, ìyẹn àwọn erékùṣù tó wà ní ìpẹ̀kun etíkun gúúsù ìlà oòrùn Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Òṣìṣẹ́ kan láti ilé iṣẹ́ tí ń rí sí ọ̀ràn ìṣíwọ̀lú bá èmi àti George, ọkọ mi lálejò láìrò tẹ́lẹ̀. Ó fún wa ní lẹ́tà kan tó sọ pé wọn ò fẹ́ ká wà ní erékùṣù yẹn mọ́ àti pé a “gbọ́dọ̀ fi àgbègbè àdádó yẹn sílẹ̀ ní kíá mọ́sá!”
ÈMI àti George ni míṣọ́nnárì àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó kọ́kọ́ wá sí Nassau, ìlú tó tóbi jù lọ ní Bahamas. Ìgbà táa kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì kẹjọ ti Gilead, tó jẹ́ ilé ẹ̀kọ́ àwọn míṣọ́nnárì níhà àríwá New York ni wọ́n yàn wá síbí. Kí la wá ṣe tí wọ́n fi rorò sí wa báyẹn lẹ́yìn táa lo oṣù mẹ́ta péré níbẹ̀? Báwo ló tún ṣe jẹ́ tí mo ṣì wà níbẹ̀ ní ohun tó lé ní àádọ́ta ọdún lẹ́yìn ìgbà yẹn?
Ìdánilẹ́kọ̀ọ́ fún Iṣẹ́ Òjíṣẹ́
Bàbá mi, Harry Kilner, ní ipa tó lágbára lórí bí mo ṣe lo ìgbésí ayé mi. Ó fi àpẹẹrẹ tó tayọ lọ́lá lélẹ̀ fún mi, ó fi ọ̀pọ̀ nǹkan du ara rẹ̀ kó lè di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé aláìlera ni, síbẹ̀ ṣàṣà ni òpin ọ̀sẹ̀ tí kì í lọ wàásù, tó ń fi ire Ìjọba náà sí ipò kìíní tìtaratìtara. (Mátíù 6:33) Tálákà ni wá o, àmọ́ ṣọ́ọ̀bù tí bàbá mi ti ń tún bàtà ṣe jẹ́ ibùdó ìgbòkègbodò tẹ̀mí ní Lethbridge, Alberta, Kánádà, ní àwọn ọdún 1930. Àwọn ohun tí mo rántí nípa ìgbà ọmọdé mi ni àwọn òjíṣẹ́ alákòókò kíkún ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, táa ń pè ní aṣáájú ọ̀nà, tí wọ́n máa ń wá sílé wa, tí wọ́n sì máa ń sọ àwọn ìrírí fún wa.
Ní 1943, mo bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìsìn aṣáájú ọ̀nà nítòsí Fort Macleod àti Claresholm, Alberta. Wọ́n fòfin de iṣẹ́ ìwàásù wa nígbà yẹn ní Kánádà nítorí ẹ̀sùn èké táwọn alátakò fi kàn wá nígbà Ogun Àgbáyé Kejì. Ìpínlẹ̀ wa nasẹ̀ tó ọgọ́rùn-ún kìlómítà láti ìkángun kan sí ìkejì, ṣùgbọ́n nítorí pé ẹ̀jẹ̀ ọ̀dọ́ ṣì wà lára wa, tí a sì ń ta kébékébé, a ò kọ̀ láti gun kẹ̀kẹ́ tàbí ká fẹsẹ̀ rìn lọ sí àwọn abúlé kéékèèké àti àwọn oko tó wà lágbègbè náà. Láàárín àkókò yìí, mo láǹfààní àtibá àwọn kan tó ti kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Gilead sọ̀rọ̀, ìrírí wọn sì ru ìfẹ́ ọkàn mi sókè láti di míṣọ́nnárì.
Ní 1945, mo fẹ́ George Porter, tó wá láti Saskatchewan, Kánádà. Àwọn òbí rẹ̀ ti jẹ́ Ẹlẹ́rìí onítara láti ọdún 1916, òun náà sì ti yan iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ ìgbésí ayé. Ibi tí wọ́n kọ́kọ́ yàn fún wa ni Àfonífojì Lynn rírẹwà tó wà ní Àríwá Vancouver, Kánádà. Kò pẹ́ lẹ́yìn náà tí wọ́n fi pè wá sí Gilead.
Ó ti pẹ́ tí mo ti máa ń bá àwọn tó gboyè jáde ní onírúurú ilé ẹ̀kọ́ àlùfáà jíròrò, mo sì ti rí i bí ẹ̀kọ́ tí wọ́n gbà níbẹ̀ ṣe máa ń ba ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nínú Ọlọ́run, àti èyí tí wọ́n ní nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ jẹ́. Ní ìyàtọ̀ sí ìyẹn, ńṣe ni ohun táa kọ́ ní Gilead mú kí agbára ìrònú wa túbọ̀ jí pépé sí i, àti lékè gbogbo rẹ̀, ó fún ìgbàgbọ́ wa nínú Jèhófà Ọlọ́run àti Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lókun. Wọ́n yan àwọn ọmọ kíláàsì wa sí China, Singapore, Íńdíà, àwọn orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà, Gúúsù Amẹ́ríkà àtàwọn ibòmíràn. Mo ṣì rántí bí inú wa ṣe dùn tó nígbà táa gbọ́ pé àwọn erékùṣù ilẹ̀ olóoru ti Bahamas ni wọ́n yàn wá sí.
Bí A Ṣe Lè Dúró
Táa bá fi ìrìn táwọn ọmọ kíláàsì wa máa rìn dé ibi táa yàn wọ́n sí wé tiwa, a óò rí i pé ìrìn àjò wa lọ sí Bahamas kò jìnnà rárá. Láìpẹ́, a ti ń gbádùn ojú ọjọ́ tó lọ́ wọ́ọ́rọ́, àwọsánmà aláwọ̀ búlúù, omi tó dúdú bí aró, àwọn ilé aláwọ̀ mèremère, àti àìmọye kẹ̀kẹ́. Àmọ́, ohun tó kọ́kọ́ jọ mi lojú jù lọ ni àwùjọ kékeré ti àwọn Ẹlẹ́rìí márùn-ún tó ń dúró dè wá nígbà tí ọkọ̀ wa gúnlẹ̀. Kò pẹ́ táa fi mọ̀ pé àṣà ìbílẹ̀ wọn yàtọ̀ pátápátá sí èyí tó ti mọ́ wa lára. Fún àpẹẹrẹ, wọ́n ní kí ọkọ mi yé pè mí ní olólùfẹ́ ní gbangba, nítorí pé àlè ni wọ́n máa ń lo èdè yẹn fún.
Láìpẹ́, àwùjọ àlùfáà, tí ọkàn wọn ò balẹ̀ mọ́ nítorí bí a ṣe ń rìn fàlàlà láàárín àwọn èèyàn náà, fi ẹ̀sùn èké kàn wá pé Kọ́múníìsì ni wá. Nítorí ìdí èyí, wọ́n pa á láṣẹ pé ká kúrò ní orílẹ̀-èdè náà. Àmọ́, lójú ẹsẹ̀ làwọn Ẹlẹ́rìí—tí wọn ò pé ogún láwọn erékùṣù náà láyé ìgbà yẹn—kọ ìwé ẹ̀bẹ̀ tí ẹgbẹẹgbẹ̀rún èèyàn fọwọ́ sí pé kí wọ́n jẹ́ ká dúró. Bí wọ́n ṣe yí àṣẹ tó sọ pé ká máa lọ padà nìyẹn.
A Forí Lé Ìpínlẹ̀ Tuntun
Kíá ni òtítọ́ Bíbélì gbèrú lọ́kàn àwọn tó nífẹ̀ẹ́ Ọlọ́run, nítorí náà wọ́n tún fi àwọn míṣọ́nnárì Gilead púpọ̀ sí i ránṣẹ́ sí Bahamas. Nígbà tó wá di 1950, a dá ẹ̀ka iléeṣẹ́ sílẹ̀ níbẹ̀. Ọdún mẹ́wàá lẹ́yìn náà ni Milton Henschel, tó jẹ́ mẹ́ńbà àwọn tó ń ṣiṣẹ́ ní orílé iṣẹ́ ní Brooklyn, New York, ṣèbẹ̀wò sí Bahamas, ó sì béèrè lọ́wọ́ àwa míṣọ́nnárì bóyá ẹnikẹ́ni nínú wa fẹ́ láti lọ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ ìwàásù ní erékùṣù mìíràn ní Bahamas. Èmi àti George yọ̀ǹda ara wa, báa ṣe bẹ̀rẹ̀ ohun tó mú ká gbé ní Long Island fún ọdún mọ́kànlá gbáko nìyẹn.
Erékùṣù yìí, tó jẹ́ ọkàn lára ọ̀pọ̀ tó para pọ̀ jẹ́ Bahamas, gùn ní ogóje kìlómítà, ó sì fẹ̀ ní kìlómítà mẹ́fà, láyé ìgbà yẹn sì rèé, kò sí ìlú gidi kankan níbẹ̀. Nǹkan bí àádọ́ta ilé ló wà ní Clarence Town tó jẹ́ olú ìlú rẹ̀. Kò sí àwọn nǹkan ìgbàlódé níbẹ̀—kò síná, kò sómi ẹ̀rọ, bẹ́ẹ̀ ni kò sí àwọn ohun èlò tó ṣeé fi dáná nínú ilé tàbí àwọn páìpù tí ń gbé omi kiri inú ilé. Nípa bẹ́ẹ̀, a ní láti jẹ́ kí ohun tí wọ́n ń pè ní ìgbésí ayé erékùṣù mọ́ wa lára. Níhìn-ín, ìlera àwọn èèyàn ni olórí kókó fún ìjíròrò. Wọ́n sọ fún wa pé ká máà máa fi ìbéèrè náà, “Báwo lára ti rí lónìí?” kún ìkíni wa, nítorí pé nígbà tí wọ́n bá máa dáhùn, ìtàn gbogbo ohun tó ti ń ṣe wọ́n pátá ni wọ́n máa kó balẹ̀.
Èyí tó pọ̀ jù nínú ìjẹ́rìí wa la máa ń ṣe láti ilé ìdáná kan sí òmíràn nítorí pé ilé ìdáná tí wọ́n ṣe síta, tí wọ́n fi koríko ṣe òrùlé rẹ̀, tó sì ní ojú ààrò tí wọ́n ti ń dáná igi, la ti sábà máa ń rí àwọn èèyàn. Àwùjọ náà kún fún àwọn tó jẹ́ tálákà, àmọ́ tí wọ́n jẹ́ àgbẹ̀ tàbí apẹja tó ṣèèyàn gan-an. Yàtọ̀ sí pé èyí tó pọ̀ jù lọ nínú wọn ní ẹ̀mí ìsìn, wọ́n tún nígbàgbọ́ nínú ohun asán pẹ̀lú. Àmì pé nǹkan kan fẹ́ ṣẹlẹ̀ ni wọ́n sábà máa ń kà á sí bí wọ́n bá rí àwọn nǹkan tó ṣàjèjì.
Àwọn àlùfáà kò rí ohun tó burú nínú kí wọ́n kàn já wọlé onílé, kí wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fa àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tí wọ́n gbà lọ́wọ́ wa ya. Wọn á wá dáyà fo àwọn tó jẹ́ ojo, àmọ́ kì í ṣe gbogbo èèyàn ni wọ́n ṣe báyẹn rí mú o. Fún àpẹẹrẹ, obìnrin kan tó jẹ́ ẹni àádọ́rin ọdún, tí ara rẹ̀ yá gágá, kò jẹ́ kí wọ́n kó jìnnìjìnnì bá òun. Ó fẹ́ lóye Bíbélì fúnra rẹ̀, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, òun àtàwọn bíi mélòó kan di Ẹlẹ́rìí. Báa ṣe túbọ̀ ń rí àwọn tó fìfẹ́ hàn lára àwọn èèyàn náà, George ní láti fi ọkọ̀ rin ìrìn nǹkan bí ọ̀ọ́dúnrún kìlómítà láwọn ọjọ́ Sunday kan, nígbà tó bá lọ ń gbé irú àwọn ẹni bẹ́ẹ̀ wá sípàdé.
Láàárín àwọn oṣù táa kọ́kọ́ débẹ̀, nígbà tí kò
sí Ẹlẹ́rìí mìíràn yàtọ̀ sí èmi àti George, a ò jẹ́ kí ipò tẹ̀mí wa yingin níwọ̀n bí a ti ń ṣe gbogbo àwọn ìpàdé Kristẹni déédéé. Ní àfikún sí i, a ń tẹ̀ lé ìtòlẹ́sẹẹsẹ tí kì í yẹ̀, ti kíkẹ́kọ̀ọ́ àpilẹ̀kọ inú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ àti ti kíká Bíbélì wa ní gbogbo alẹ́ Monday. A tún máa ń ka gbogbo ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! ní gbàrà táa bá ti gbà wọ́n.Ìgbà táa wà ní Long Island ni bàbá mi kú. Ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn tó tẹ̀ lé e, ní 1963, a ṣètò pé kí Màmá wá máa gbé nítòsí ilé wa. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ti di arúgbó, síbẹ̀ ó jẹ́ kí ara òun mọlé, ó sì gbé Long Island títí ó fi kú ní 1971. Lónìí, Long Island ti ní ìjọ kan pẹ̀lú Gbọ̀ngàn Ìjọba tuntun kan.
Ìṣòro Tó Mọ́kàn Mi Gbọgbẹ́
Ní 1980, George rí i pé ara òun kò le mọ́. Bí ìrírí tó nira jù lọ nínú ìgbésí ayé mi ṣe bẹ̀rẹ̀ nìyẹn—bí mo ti ń wo ọkọ mi olùfẹ́ ọ̀wọ́n, alábàáṣiṣẹ́pọ̀ mi, àti alábàákẹ́gbẹ́ mi tí àrùn ọdẹ orí abọ́jọ́-ogbó-rìn ń pa á kú lọ. Gbogbo ìwà àti ìṣe rẹ̀ pátá ló yí padà. Apá tó kẹ́yìn tó sì bani nínú jẹ́ jù lọ níbẹ̀ ṣe é fún nǹkan bí ọdún mẹ́rin ṣáájú ikú rẹ̀ ní 1987. Ó máa ń bá mi lọ sóde ẹ̀rí àti ìpàdé nígbà tágbára rẹ̀ bá gbé e, bó tilẹ̀ jẹ́ pé lọ́pọ̀ ìgbà bó ṣe ń tiraka máa ń pa mí lẹ́kún. Ìfẹ́ táwọn Kristẹni arákùnrin fi hàn lẹ́yìn ikú rẹ̀ ti jẹ́ ojúlówó ìtùnú fún mi, àmọ́ àárò rẹ̀ ṣì máa ń sọ mí gan-an ni.
Ọ̀kan lára àwọn apá tó wúni lórí jù lọ nínú ìgbéyàwó èmi àti George ni báa ṣe máa ń ní ìjùmọ̀sọ̀rọ̀ tó gbádùn mọ́ni ní gbogbo ìgbà. Nísinsìnyí tí George ti lọ, mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Jèhófà ju ti ìgbàkígbà rí lọ, pé ó ké sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ láti “máa gbàdúrà láìdabọ̀,” láti “máa ní ìforítì nínú àdúrà,” àti láti máa lo “gbogbo oríṣi àdúrà.” (1 Tẹsalóníkà 5:17; Róòmù 12:12; Éfésù 6:18) Ó ń tuni nínú gan-an láti mọ̀ pé Jèhófà ń ṣàníyàn nípa ire wa. Mo wá ní irú ìmọ̀lára tí onísáàmù náà ní nígbà tó kọ ọ́ lórin pé: “Ìbùkún ni fún Jèhófà, ẹni tí ń bá wa gbé ẹrù lójoojúmọ́.” (Sáàmù 68:19) Bí n kì í ṣe é ṣàníyàn nípa ọ̀la, tí mo mọ̀wọ̀n ara mi, tí mo sì ń dúpẹ́ fún ìbùkún tí ọjọ́ kọ̀ọ̀kan ń mú wá, bí Jésù ṣe gbà wá níyànjú, ni ọ̀nà tó dára jù lọ láti gbé ìgbésí ayé.—Mátíù 6:34.
Èrè Tí Ń Fúnni Láyọ̀ Nínú Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Náà
Mímú kí ọwọ́ mi dí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ Kristẹni ti ràn mí lọ́wọ́ láti má ṣe ronú púpọ̀ lórí ohun tó ti kọjá. Nípa bẹ́ẹ̀, ó ṣeé ṣe fún mi láti borí irú ìmọ̀lára tó lè yọrí sí ìsoríkọ́. Kíkọ́ àwọn ẹlòmíràn ní òtítọ́ Bíbélì ti jẹ́ orísun ayọ̀ fún mi lọ́nà àkànṣe. Ó jẹ́ kí n ní ìgbòkègbodò Fílípì 3:16.
tẹ̀mí tó wà létòlétò, èyí tó jẹ́ kí ìgbésí ayé mi nítumọ̀, kí ó sì lójú.—Nígbà kan, obìnrin kan tí mo bá sọ̀rọ̀ nípa ìhìn Ìjọba náà ní nǹkan bí ọdún mẹ́tàdínláàádọ́ta sẹ́yìn tẹ̀ mí láago. Ọmọ ọkùnrin táa kọ́kọ́ bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì nígbà táa dé sí Bahamas ní 1947 ni. Ìyá rẹ̀, bàbá rẹ̀, àtàwọn ẹ̀gbọ́n àtàbúrò rẹ̀ lọ́kùnrin lóbìnrin, títí kan ọ̀pọ̀ jù lọ àwọn ọmọ àti ọmọ ọmọ wọn ló ti di Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Àní, ó lé ní ọgọ́ta ènìyàn tó ti di Ẹlẹ́rìí lára àwọn mẹ́ńbà ìdílé obìnrin yìí. Ṣùgbọ́n òun fúnra rẹ̀ kò fìgbà kan tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Bíbélì rí. Àmọ́, níkẹyìn, ó ti ṣe tán láti di ìránṣẹ́ Jèhófà Ọlọ́run báyìí. Ayọ̀ ńlá ló mà jẹ́ o, láti rí àwọn Ẹlẹ́rìí tí kò ju kéréje ní Bahamas nígbà tí èmi àti George dé síbẹ̀, tí wọ́n ti wá lé ní egbèje [1,400] báyìí!
Àwọn èèyàn máa ń bi mí nígbà mìíràn bóyá mo kábàámọ̀ pé mi ò ní àwọn ọmọ tó jẹ́ tèmi. Lóòótọ́, níní ọmọ lè jẹ́ ìbùkún. Síbẹ̀, ìfẹ́ tí àwọn ọmọ mi, àwọn ọmọ ọmọ mi, àtàwọn àtọmọdọ́mọ mi nípa tẹ̀mí ń fi hàn sí mi ní gbogbo ìgbà jẹ́ ìfẹ́ tó jẹ́ pé bóyá ni gbogbo àwọn tó jẹ́ òbí ní ti gidi máa ń rí irú rẹ̀. Ní ti tòótọ́, àwọn tó ń “ṣe rere” tí wọ́n sì “jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà” ni àwọn tó ní ayọ̀ jù lọ. (1 Tímótì 6:18) Ìdí nìyẹn tí mo fi jẹ́ kí ọwọ́ mi dí nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà dé ibi tí ìlera mi bá lè gbé e dé.
Ní ọjọ́ kan ní ọ́fíìsì oníṣègùn eyín, ọ̀ṣọ́ọ́rọ́ obìnrin kan wá bá mi, ó sì sọ pé, “Ẹ ò mọ̀ mí o, ṣùgbọ́n mo mọ̀ yín, mo sì fẹ́ kí ẹ mọ̀ pé mo nífẹ̀ẹ́ yín.” Ìgbà yẹn ló wá ń ṣàlàyé bí òun ṣe mọ òtítọ́ látinú Bíbélì àti bí òun ṣe mọrírì wíwá tí àwọn míṣọ́nnárì wá sí Bahamas.
Ó tún ṣẹlẹ̀ nígbà kan tí mo dé láti ibi tí mo ti lọ lo ìsinmi, mo bá òdòdó róòsì kan ní ẹnu ilẹ̀kùn ibi tí mò ń gbé báyìí ní ẹ̀ka iléeṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Nassau. Mo rí ìwé kékeré kan tí wọ́n kọ sí i lára pé, “A dúpẹ́ pé ẹ lọ ọ re, ẹ bọ̀ ọ re.” Ọkàn mi kún fún ọpẹ́, ó sì jẹ́ kí n nífẹ̀ẹ́ Jèhófà gan-an nígbà tí mo rí irú àwọn èèyàn tí Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ètò àjọ rẹ̀, àti ẹ̀mí rẹ̀ ń mú jáde! Ní ti tòótọ́, ọwọ́ Jèhófà tí ń gbéni ró sábà máa ń fara hàn nípasẹ̀ àwọn tó yí wa ká.
Ọpẹ́ Mi Kò Lópin
Nǹkan kò f ìgbà gbogbo rọrùn fún mi o, àwọn apá kan sì wà nígbèésí ayé mi tí kò rọrùn di báa ti ń sọ̀rọ̀ yìí. Ṣùgbọ́n mo ní ọ̀pọ̀ ohun tí mo lè máa dúpẹ́ fún—ayọ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́, ìfẹ́ àti aájò ọ̀pọ̀ Kristẹni arákùnrin àti arábìnrin, ìtọ́jú onífẹ̀ẹ́ ètò àjọ Jèhófà, òtítọ́ tó gbayì látinú Bíbélì, ìrètí wíwà pẹ̀lú àwọn olólùfẹ́ nígbà tí wọ́n bá jíǹde, àti ìrántí ọdún méjìlélógójì tí mo fi wà nínú ìdè ìgbéyàwó pẹ̀lú olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà. Kó tó di pé a ṣègbéyàwó ni mo ti gbàdúrà pé kí n lè jẹ́ olùrànlọ́wọ́ fún ọkọ mi nígbà gbogbo, kó lè máa bá iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún tó nífẹ̀ẹ́ sí gan-an nìṣó. Jèhófà sì fi inú rere dáhùn àdúrà yẹn. Nítorí náà mo fẹ́ dúpẹ́, kí n sì tọ́pẹ́ dá lọ́wọ́ Jèhófà nípa jíjẹ́ olóòótọ́ sí i ní gbogbo ìgbà.
Bahamas jẹ́ orílẹ̀-èdè tó lókìkí fún àwọn arìnrìn-àjò afẹ́, àwọn tó máa ń ná ẹgbẹẹgbẹ̀rún dọ́là láti wá gbádùn ilẹ̀ olóoru yìí. Níwọ̀n bí mo ti yàn láti sin Jèhófà níbikíbi tí ètò àjọ rẹ̀ bá ní kí n lọ, mo ti ní ìrírí aláyọ̀ ti rírin ìrìn àjò láti ìkángun kan sí ìkángun kejì erékùṣù wọ̀nyí, tí mò ń kéde ìhìn rere Ìjọba Ọlọ́run. Àmọ́, èyí tó ṣe pàtàkì jù lọ ni pé mo ti wá rí ìfẹ́ àwọn ará Bahamas tí wọ́n níwà bí ọ̀rẹ́ jù lọ, mo sì mọyì ìfẹ́ yẹn gan-an ni.
Mo dúpẹ́ púpọ̀ lọ́wọ́ àwọn tó mú òtítọ́ wá sọ́dọ̀ àwọn òbí mi, tí wọ́n sì tún gbin ìfẹ́ jíjinlẹ̀ láti kọ́kọ́ máa wá Ìjọba Ọlọ́run sọ́kàn àti èrò inú mi láti kékeré. Àwọn ọ̀dọ́ tó jẹ́ ìránṣẹ́ Jèhófà lónìí pẹ̀lú lè rí ọ̀pọ̀ ìbùkún gbà bí wọ́n bá gba “ilẹ̀kùn ńlá” náà wọlé, èyí tí ń ṣamọ̀nà sí ọ̀pọ̀ àǹfààní kíkọyọyọ láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn gbòòrò sí i. (1 Kọ́ríńtì 16:9) Ọpẹ́ tìrẹ náà kò ní lópin, bóo bá lo ìgbésí ayé rẹ láti bọlá fún Jèhófà “Ọlọ́run àwọn ọlọ́run.”—Diutarónómì 10:17; Dáníẹ́lì 2:47.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
A wà lẹ́nu iṣẹ́ ojú pópó ní Victoria, B.C., lọ́dún 1944
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 24]
Nígbà tí èmi àti George wà ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gilead ní 1946
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]
Èmi àti George rèé níwájú ilé àwọn míṣọ́nnárì ní Nassau, Bahamas, ní 1955
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]
Ilé àwọn míṣọ́nnárì tó wà ní Deadman’s Cay, níbi táa ti sìn láti ọdún 1961 sí 1972