Fún Ìgbẹ́kẹ̀lé Rẹ Nínú Jèhófà Lókun
Fún Ìgbẹ́kẹ̀lé Rẹ Nínú Jèhófà Lókun
Àwọn kan ti dìtẹ̀ láti pa ẹnì kan. Gbogbo àwọn onípò àṣẹ gíga-gíga lórílẹ̀-èdè náà ti gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n sì ti gbé àbádòfin tuntun kan jáde. Wọ́n fẹ́ sọ ìjọsìn tí Ìjọba kò bá fọwọ́ sí di ẹ̀ṣẹ̀ tó la ikú lọ.
ǸJẸ́ ìtàn yìí jọ èyí tóo ti gbọ́ rí? Àpẹẹrẹ àwọn èèyàn tí ń fi òfin dáná ìjàngbọ̀n pọ̀ nínú ìtàn. Ìṣẹ̀lẹ̀ táa mẹ́nu kàn lókè yìí wáyé ní Ilẹ̀ Ọba Páṣíà nígbà ayé wòlíì Dáníẹ́lì. Òfin náà, tí Dáríúsì Ọba fìdí rẹ̀ múlẹ̀, sọ pé: “Ẹnì yòówù tí ó bá ṣe ìtọrọ lọ́wọ́ ọlọ́run tàbí ènìyàn èyíkéyìí láàárín ọgbọ̀n ọjọ́ bí kò ṣe lọ́wọ́ . . . ọba ni kí a sọ sínú ihò kìnnìún.”—Dáníẹ́lì 6:7-9.
Kí ni kí Dáníẹ́lì wá ṣe báyìí, tí ẹ̀mí rẹ̀ wà nínú ewu? Ṣé ó ṣì máa gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, Ọlọ́run rẹ̀, tàbí ṣé á juwọ́ sílẹ̀, kí ó sì tẹ̀ lé òfin ọba ni? Àkọsílẹ̀ náà sọ fún wa pé: “Gbàrà tí Dáníẹ́lì mọ̀ pé a ti fọwọ́ sí ìwé náà, ó wọnú ilé rẹ̀ lọ, fèrèsé ìyẹ̀wù òrùlé rẹ̀ wà ní ṣíṣí fún un síhà Jerúsálẹ́mù, àní ní ìgbà mẹ́ta lójúmọ́, ó ń kúnlẹ̀ lórí eékún rẹ̀, ó ń gbàdúrà, ó sì ń bu ìyìn níwájú Ọlọ́run rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí ó ti máa ń ṣe déédéé ṣáájú èyí.” (Dáníẹ́lì 6:10) A mọ ìyókù ìtàn náà bí ẹní mowó. Wọ́n sọ Dáníẹ́lì sínú ihò kìnnìún nítorí ìgbàgbọ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n Jèhófà “dí ẹnu àwọn kìnnìún,” ó sì gba ìránṣẹ́ rẹ̀ adúróṣinṣin.—Hébérù 11:33; Dáníẹ́lì 6:16-22.
Àkókò fún Yíyẹ Ara Ẹni Wò
Lónìí, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń gbé nínú ayé tó kórìíra wọn, ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn èèyàn ń dún mọ̀huru-mọ̀huru mọ́ wọn, nípa tara àti nípa tẹ̀mí. Fún àpẹẹrẹ, ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí ni wọ́n ti pa ní àwọn orílẹ̀-èdè kan nígbà tí ìkórìíra kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà dá rúgúdù sílẹ̀. Ní àwọn ibòmíràn, àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń fojú winá àìtó oúnjẹ, ìṣòro ìṣúnná owó, ìjábá, àìsàn burúkú, àtàwọn ìṣòro míì tó lè gbẹ̀mí èèyàn. Kò mọ síbẹ̀ o, wọ́n tún ń fàyà rán inúnibíni, wàhálà níbi iṣẹ́, àti onírúurú àdánwò láti ṣe ohun tí kò tọ́, gbogbo èyí ló sì lè fi ipò tẹ̀mí wọn sínú ewu. Àní, Sátánì, olórí Elénìní náà, ti múra tán láti rẹ́yìn àwọn ìránṣẹ́ Jèhófà, ó ní ohun tó bá gbà lòun máa fún un.—1 Pétérù 5:8.
Pẹ̀lú ipò wọ̀nyí tó dojú kọ wá, kí la lè ṣe? Bó tilẹ̀ jẹ́ pé kì í ṣe ohun àjèjì láti máa bẹ̀rù nígbà tí ẹ̀mí èèyàn bá wà nínú ewu, síbẹ̀ a lè fi ọ̀rọ̀ ìfinilọ́kànbalẹ̀ àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ́kàn, pé: “[Jèhófà] ti wí pé: ‘Dájúdájú, èmi kì yóò fi ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà tàbí kọ̀ ọ́ sílẹ̀ lọ́nàkọnà.’ Kí a lè jẹ́ onígboyà gidi gan-an, kí a sì sọ pé: ‘Jèhófà ni olùrànlọ́wọ́ mi; èmi kì yóò fòyà. Kí ni ènìyàn lè fi mí ṣe?’” (Hébérù 13:5, 6) Ọkàn wa balẹ̀ pé ojú kan náà ni Jèhófà fi ń wo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ òde òní. Àmọ́ o, ọ̀tọ̀ ni pé ká mọ ìlérí Jèhófà, ọ̀tọ̀ pátápátá sì ni pé kó dá wa lójú pé òun yóò gbégbèésẹ̀ fún ire wa. Nítorí náà, ó ṣe pàtàkì gidigidi pé ká ṣàyẹ̀wò ohun táa gbé ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Jèhófà kà, ká sì sa gbogbo ipá wa láti fún ìgbẹ́kẹ̀lé yẹn lókun, ká má sì jẹ́ kó yingin. Bí a bá ṣe bẹ́ẹ̀, “àlàáfíà Ọlọ́run tí ó ta gbogbo ìrònú yọ yóò sì máa ṣọ́ ọkàn-àyà [wa] àti agbára èrò orí [wa] nípasẹ̀ Kristi Jésù.” (Fílípì 4:7) Bí àdánwò bá wá dé, yóò ṣeé ṣe fún wa láti ronú lọ́nà tó ṣe tààrà, ká sì fi òye kojú rẹ̀.
Ohun Táa Gbé Ìgbẹ́kẹ̀lé Wa Nínú Jèhófà Kà
Ó dájú pé a ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìdí láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, Ẹlẹ́dàá wa. Èyí àkọ́kọ́ lára ìdí wọ̀nyẹn ni òtítọ́ náà pé Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ tó ń fi tinútinú tọ́jú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Àìmọye àpẹẹrẹ ló wà nínú Bíbélì tó sọ nípa bí Jèhófà ti ń fi tìfẹ́tìfẹ́ tọ́jú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Nígbà tí Mósè ń ṣàlàyé bí Jèhófà ṣe bá Ísírẹ́lì, àyànfẹ́ rẹ̀ lò, ó kọ̀wé pé: “Ó rí i ní ilẹ̀ aginjù, àti nínú aṣálẹ̀ tí ó ṣófo, tí ń hu. Ó sì bẹ̀rẹ̀ sí yí i ká, láti tọ́jú rẹ̀, láti fi ìṣọ́ ṣọ́ ọ bí ọmọlójú ojú rẹ̀.” (Diutarónómì 32:10) Lóde òní, Jèhófà ń bá a nìṣó ní títọ́jú àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, lápapọ̀ àti lẹ́nì kọ̀ọ̀kan. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí ìyàn burúkú mú àwọn Ẹlẹ́rìí kan nígbà ogun abẹ́lé tó jà ní Bosnia, Jèhófà rí i dájú pé àwọn ohun tí wọ́n nílò tẹ̀ wọ́n lọ́wọ́ nípasẹ̀ ìsapá alákíkanjú àwọn ará wọn láti Croatia àti Austria, ìyẹn àwọn tó fẹ̀mí ara wọn wewu láti rìnrìn àjò gba ìpínlẹ̀ eléwu kọjá, kí wọ́n lè kó ohun àfiṣèrànwọ́ wá fáwọn ará wọn. a
Níwọ̀n bí Jèhófà Ọlọ́run ti jẹ́ Alágbára Ńlá Gbogbo, ó dájú pé ó lè dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ lábẹ́ ipòkípò. (Aísáyà 33:22; Ìṣípayá 4:8) Ṣùgbọ́n kódà nígbà tí Jèhófà bá yọ̀ǹda kí àwọn kan lára ìránṣẹ́ rẹ̀ fi hàn pé àwọn jẹ́ olóòótọ́ dójú ikú, ó ṣì ń mẹ́sẹ̀ wọn dúró, ó ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti pa ìwà títọ́ mọ́, ó ń fún wọn lágbára láti dúró ṣinṣin, láti jẹ́ aláyọ̀, láìmikàn títí dópin. Fún ìdí yìí, ọkàn àwa náà lè balẹ̀ bíi ti onísáàmù náà tó sọ pé: “Ọlọ́run jẹ́ ibi ìsádi àti okun fún wa, ìrànlọ́wọ́ tí a lè rí tìrọ̀rùn-tìrọ̀rùn nígbà wàhálà. Ìdí nìyẹn tí àwa kì yóò bẹ̀rù, bí ilẹ̀ ayé tilẹ̀ yí padà, bí àwọn òkè ńláńlá tilẹ̀ ta gbọ̀n-ọ́n gbọ̀n-ọ́n wọ àárín alagbalúgbú òkun.”—Sáàmù 46:1, 2.
Bíbélì tún ṣí i payá pé Ọlọ́run òtítọ́ ni Jèhófà. Èyí túmọ̀ sí pé ìlérí rẹ̀ kò lè ṣákìí láé. Àní, Bíbélì pè é ní Ọlọ́run “tí kò lè purọ́.” (Títù 1:2) Níwọ̀n bí Jèhófà ti sọ ọ́ léraléra pé òun múra tán láti dáàbò bo àwọn ìránṣẹ́ òun, kí òun sì gbà wọ́n là, ọkàn wa lè balẹ̀ pátápátá pé kì í ṣe kìkì pé ó lè mú àwọn ìlérí rẹ̀ ṣẹ nìkan ni, ṣùgbọ́n ó ti múra tán láti mú wọn ṣẹ.—Jóòbù 42:2.
Àwọn Ọ̀nà Táa Lè Gbà fún Ìgbẹ́kẹ̀lé Wa Lókun
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdí púpọ̀ ló wà tó fi yẹ ká gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, kò yẹ ká retí pé wẹ́rẹ́ ni ìgbẹ́kẹ̀lé ọ̀hún yóò wá. Ìdí ni pé ayé ní gbogbo gbòò kò fi bẹ́ẹ̀ nígbàgbọ́ nínú Ọlọ́run, irú ẹ̀mí yẹn sì lè tètè sọ ìgbẹ́kẹ̀lé táa ní nínú Jèhófà di ahẹrẹpẹ. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ó yẹ ká làkàkà láti fún ìgbẹ́kẹ̀lé yẹn lókun, kí ó má sì yingin. Jèhófà mọ èyí dáadáa, ó sì ti pèsè àwọn ọ̀nà táa fi lè ṣe bẹ́ẹ̀.
Lákọ̀ọ́kọ́ ná, ó ti pèsè Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀ táa kọ sílẹ̀, èyí tó ṣàkọsílẹ̀ ọ̀pọ̀ iṣẹ́ àrà tó gbé ṣe fún ire àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀. Sáà ronú ná, irú ìgbẹ́kẹ̀lé wo lo lè ní nínú ẹnì kan tó jẹ́ pé orúkọ rẹ̀ nìkan lo mọ̀? Bóyá lo máa ní ìgbẹ́kẹ̀lé kankan nínú onítọ̀hún. O ní láti mọ àwọn ọ̀nà àti ìṣesí rẹ̀ kóo tó lè gbẹ́kẹ̀ lé e, àbí bẹ́ẹ̀ kọ́? Báa ṣe ń ka irú ìtàn bẹ́ẹ̀ nínú Bíbélì, táa sì ń ṣàṣàrò lé wọn lórí, ṣe ni ìmọ̀ wa nípa Jèhófà àtàwọn ọ̀nà àgbàyanu rẹ̀ á máa jinlẹ̀ sí i, a ó sì túbọ̀ wá mọ bó ṣe jẹ́ ẹni tó ṣeé gbẹ́kẹ̀ lé tó. Bí ìgbẹ́kẹ̀lé táa ní nínú rẹ̀ ṣe ń lágbára sí i nìyẹn. Onísáàmù náà fi àpẹẹrẹ títayọ lélẹ̀ nígbà tó gba àdúrà àtọkànwá yìí sí Ọlọ́run, pé: “Èmi yóò rántí àwọn iṣẹ́ Jáà; nítorí ó dájú pé èmi yóò rántí ìṣe ìyanu rẹ ti ìgbà pípẹ́ sẹ́yìn. Dájúdájú, èmi yóò máa ṣe àṣàrò lórí gbogbo ìgbòkègbodò rẹ, ṣe ni èmi yóò sì máa dàníyàn nípa ìbálò rẹ.”—Sáàmù 77:11, 12.
Ní àfikún sí Bíbélì, ètò Jèhófà ń pèsè ọ̀pọ̀ oúnjẹ tẹ̀mí jaburata fún wa nínú àwọn ìtẹ̀jáde táa gbé ka Bíbélì. Ara àwọn ohun tó wà nínú ìtẹ̀jáde wọ̀nyí ni àwọn ìtàn tí ń wúni lórí nípa àwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run lóde òní, àwọn ìtàn tí ń fi hàn bí Jèhófà ṣe pèsè ìrànlọ́wọ́ àti ìtura nígbà tí wọ́n bá ara wọn nínú ipò àìnírètí. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí Martin Poetzinger, tó wá di mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà lẹ́yìn-ọ̀-rẹyìn, ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà ní àwọn àgbègbè Yúróòpù tó jìnnà sí ilẹ̀ ìbílẹ̀ rẹ̀, àìsàn burúkú kan kọlù ú. Kò ní kọ́bọ̀ lọ́wọ́, kò sì sí dókítà tó fẹ́ tọ́jú rẹ̀. Ṣùgbọ́n Jèhófà kò kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Níkẹyìn, wọ́n kàn sí àgbà dókítà tó wà ní ọsibítù àdúgbò náà. Nítorí pé ọkùnrin onínúure yìí gba Bíbélì gbọ́ gidigidi, ó tọ́jú Arákùnrin Poetzinger bí ọmọ ara rẹ̀, láìgba kọ́bọ̀. Ó dájú pé kíka irú ìrírí bẹ́ẹ̀ lè fún ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Baba wa ọ̀run lókun.
Ìrànlọ́wọ́ oníyebíye míì tí Jèhófà ń pèsè láti fún ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú rẹ̀ lókun ni àǹfààní iyebíye ti gbígbàdúrà. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù fi tìfẹ́tìfẹ́ sọ fún wa pé: “Ẹ má ṣe máa ṣàníyàn nípa ohunkóhun, ṣùgbọ́n nínú ohun gbogbo nípasẹ̀ àdúrà àti ìrawọ́ ẹ̀bẹ̀ pa pọ̀ pẹ̀lú ìdúpẹ́ kí ẹ máa sọ àwọn ohun tí ẹ ń tọrọ di mímọ̀ fún Ọlọ́run.” (Fílípì 4:6) “Ohunkóhun” lè jẹ́ ìmọ̀lára, àìní, ìbẹ̀rù, àti àníyàn wa. Bí àdúrà wa bá ti ń ṣe lemọ́lemọ́ tó, tó sì jẹ́ àtọkànwá tó, bẹ́ẹ̀ náà ni ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Jèhófà yóò ṣe lágbára tó.
Nígbà tí Jésù Kristi wà lórí ilẹ̀ ayé, nígbà míì ó máa ń lọ síbi àdádó láti lọ gbàdúrà níbi tí ẹnikẹ́ni kò ti ní yọ ọ́ lẹ́nu. (Mátíù 14:23; Máàkù 1:35) Kí ó tó ṣe àwọn ìpinnu kan tó ṣe pàtàkì gan-an, ó tiẹ̀ fi gbogbo òru gbàdúrà sí Baba rẹ̀. (Lúùkù 6:12, 13) Abájọ tí ìgbẹ́kẹ̀lé tí Jésù ní nínú Jèhófà fi lágbára tó bẹ́ẹ̀ gẹ́ẹ́ tó fi fara da ìdánwò tó le koko jù lọ nínú ìrírí ẹ̀dá ènìyàn. Ọ̀rọ̀ tó sọ gbẹ̀yìn lórí igi oró ni pé: “Baba, ọwọ́ rẹ ni mo fi ẹ̀mí mi lé.” Ọ̀rọ̀ ìfọkàntánni yìí fi hàn pé ìgbẹ́kẹ̀lé tó ní nínú Baba rẹ̀ kò yingin títí dópin, bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà kò gbà á lọ́wọ́ ikú.—Lúùkù 23:46.
Ọ̀nà míì táa lè fi gbé ìgbẹ́kẹ̀lé ró nínú Diutarónómì 31:12; Hébérù 10:24, 25) Irú ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ bẹ́ẹ̀ ń fún ìgbẹ́kẹ̀lé wọn nínú Jèhófà lókun, ó ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wọn láti fara da àwọn ìdánwò ìgbàgbọ́ líle koko. Ní orílẹ̀-èdè kan ní Áfíríkà níbi tí wọ́n ti fòfin de iṣẹ́ ìwàásù náà, wọn ò jẹ́ kí àwọn ọlọ́pàá dáàbò bo àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, wọn ò fún wọn ní ìwé àṣẹ ìrìn àjò, wọn ò fún wọn ní ìwé ẹ̀rí ìgbéyàwó, wọn ò jẹ́ kí wọ́n gba ìtọ́jú ní ọsibítù, wọn ò sì gbà wọ́n síṣẹ́. Nígbà tí ogun abẹ́lé bẹ́ sílẹ̀ lágbègbè kan, nǹkan bí oṣù mẹ́rin ni àwọn mọ́kàndínlógójì, títí kan àwọn ọmọdé, nínú ìjọ kan tó wà nítòsí, fi ń gbé lábẹ́ afárá rírẹlẹ̀ kan ní aṣálẹ̀, kí wọ́n lè mórí bọ́ lọ́wọ́ òjò bọ́ǹbù tí wọ́n ń rọ̀ sórí ìlú wọn. Lábẹ́ irú ipò tó burú jáì bẹ́ẹ̀, ìjíròrò ẹsẹ Bíbélì ojoojúmọ́ àtàwọn ìpàdé míì ló fún wọn lókun ńlá. Ìyẹn ni wọ́n fi lè fara da ìrírí líle koko náà, tí wọ́n sì mú ìdúró wọn nípa tẹ̀mí. Ìrírí yìí fi hàn kedere pé ó ṣe pàtàkì gan-an láti máa pésẹ̀ sípàdé déédéé pẹ̀lú àwọn èèyàn Jèhófà.
Jèhófà ni bíbá àwọn tó fi tọkàntọkàn gbẹ́kẹ̀ lé e kẹ́gbẹ́. Jèhófà pàṣẹ fáwọn èèyàn rẹ̀ láti máa pàdé pọ̀ déédéé láti lè kẹ́kọ̀ọ́ sí i nípa òun, kí wọ́n sì lè fún ara wọn níṣìírí lẹ́nì kìíní kejì. (Boríborí rẹ̀, láti fún ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Jèhófà lókun, a gbọ́dọ̀ máa wàásù Ìjọba náà déédéé, ká máa múra tán nígbà gbogbo láti wàásù ìhìn rere náà fáwọn ẹlòmíràn. A rí ẹ̀rí èyí nínú ìrírí wíwọni lọ́kàn ti ọ̀dọ́ akéde onítara kan ní Kánádà, ẹni ti àrùn leukemia ti sìn dé bèbè ikú. Láìka àìsàn tí kò gbóògùn náà sí, ó fẹ́ di aṣáájú ọ̀nà déédéé, ìyẹn, òjíṣẹ́ alákòókò kíkún. Ní sáà ráńpẹ́ kan tí àìsàn náà fi í lọ́rùn sílẹ̀ díẹ̀, ara rẹ̀ le débi pé ó ṣe aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́ fún oṣù kan. Lẹ́yìn náà ni àìsàn náà tún burú sí i, ó sì kú ní oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà. Ṣùgbọ́n ó dúró ṣinṣin nípa tẹ̀mí títí dópin, ìgbẹ́kẹ̀lé tó ní nínú Jèhófà kò sì yingin fún ìṣẹ́jú kan. Màmá rẹ̀ rántí pé: “Títí dé òpin, ọ̀ràn àwọn èèyàn ló ń jẹ ẹ́ lọ́kàn, kì í ṣe tara rẹ̀. Ó máa ń fún wọn níṣìírí láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, á sì sọ fún wọn pé, ‘A ó pàdé ní Párádísè.’”
Fífi Hàn Pé A Gbẹ́kẹ̀ Lé Jèhófà
“Gẹ́gẹ́ bí ara láìsí ẹ̀mí ti jẹ́ òkú, bẹ́ẹ̀ pẹ̀lú ni ìgbàgbọ́ láìsí àwọn iṣẹ́ jẹ́ òkú.” (Jákọ́bù 2:26) Ohun tí Jákọ́bù sọ nípa ìgbàgbọ́ nínú Ọlọ́run tún kan ìgbẹ́kẹ̀lé nínú Rẹ̀. Bó ti wù ká fẹnu sọ pé a gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run tó, òtúbáńtẹ́ ni, bí ìṣesí wa ò bá fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé e. Ábúráhámù gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà pátápátá, ó sì fi ẹ̀rí ìgbẹ́kẹ̀lé yẹn hàn nípa ṣíṣègbọràn láìṣiyèméjì sí àwọn àṣẹ rẹ̀, àní ó múra tán láti fi Ísáákì, ọmọ rẹ̀ rúbọ. Nítorí ìgbẹ́kẹ̀lé àti ìgbọràn títayọ yẹn, Ábúráhámù di ẹni táa mọ̀ sí ọ̀rẹ́ Jèhófà.—Hébérù 11:8-10, 17-19; Jákọ́bù 2:23.
Kò dìgbà tí ìdánwò líle koko dé bá wa ká tó fi hàn pé a gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà. Jésù sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Ẹni tí ó bá jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ olùṣòtítọ́ nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú, ẹni tí ó bá sì jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tí ó kéré jù lọ jẹ́ aláìṣòdodo nínú ohun tí ó pọ̀ pẹ̀lú.” (Lúùkù 16:10) A gbọ́dọ̀ kẹ́kọ̀ọ́ láti gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà nínú gbogbo ohun tí à ń ṣe lójoojúmọ́, ká máa ṣègbọràn sí i nínú àwọn ọ̀ràn tó kéré lójú wa pàápàá. Nígbà táa bá rí àwọn àǹfààní tí ń tinú irú ìgbọràn bẹ́ẹ̀ wá, ìgbẹ́kẹ̀lé wa nínú Baba wa ọ̀run yóò túbọ̀ fẹsẹ̀ múlẹ̀, yóò sì fún wa lókun láti dojú kọ àwọn àdánwò tó tún le sí i.
Bí ayé yìí ti ń lọ sópin, kò sí báwọn èèyàn Jèhófà ò ṣe ní fojú winá àdánwò àti ewu púpọ̀ sí i. (Ìṣe 14:22; 2 Tímótì 3:12) Nípa níní ìgbẹ́kẹ̀lé tó lágbára tó sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú Jèhófà nísinsìnyí, a lè máa wọ̀nà fún lílà á já sínú ayé tuntun tó ṣèlérí—yálà nípa líla ìpọ́njú ńlá já tàbí nípa níní àjíǹde. (2 Pétérù 3:13) Ǹjẹ́ kí a má ṣe jẹ́ kí àìnígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé ba àjọṣe oníyebíye tó wà láàárín àwa àti Jèhófà jẹ́. Nígbà náà, a ó sọ ohun kan náà tí a sọ nípa Dáníẹ́lì lẹ́yìn tó jáde láàyè kúrò nínú ihò kìnnìún nípa wa, pé: “Kò sì sí ọṣẹ́ kankan rárá lára rẹ̀, nítorí pé ó gbẹ́kẹ̀ lé Ọlọ́run rẹ̀.”—Dáníẹ́lì 6:23.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Fún ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ àlàyé, wo Ilé Ìṣọ́, November 1, 1994, ojú ìwé 23 sí 27.
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]
Kíka ìtàn àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Jèhófà, bíi Martin Poetzinger, ń fún ìgbàgbọ́ lókun