Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ǹjẹ́ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì—Wúlò Fún Ọ?

Ǹjẹ́ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì—Wúlò Fún Ọ?

Ǹjẹ́ Ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì—Wúlò Fún Ọ?

“A Ò gbọ́dọ̀ kà á láìjẹ́ pé àlùfáà wà nítòsí.” Ìkìlọ̀ yìí fara hàn ní ìbẹ̀rẹ̀ àwọn Bíbélì kan tó jẹ́ ti Kátólíìkì. Kay Murdy tó ń bá Àjọ Kátólíìkì Tí Ń Rí sí Ọ̀ràn Nípa Bíbélì ní Los Angeles ṣiṣẹ́ sọ pé: “Gẹ́gẹ́ bíi Kátólíìkì, ó pẹ́ kí ojú wa tó bẹ̀rẹ̀ sí là sí Bíbélì, ṣùgbọ́n ìyẹn ti ń di ohun àná báyìí.” Obìnrin yìí sọ pé gbàrà tí àwọn Kátólíìkì rí bí Ìwé Mímọ́ ṣe lè tún ayé wọn ṣe, “ni wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí yán hànhàn fún Bíbélì.”

Nítorí ìyípadà yìí ni ìwé ìròyìn U.S. Catholic ṣe fa ọ̀rọ̀ olùdarí ẹ̀kọ́ ìsìn kan yọ, tó sọ pé àwọn Kátólíìkì tó ń lọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì mọ̀ pé “wọ́n ti fi ọ̀pọ̀ nǹkan du àwọn tí àwọn jẹ́ Kátólíìkì, wọ́n tún rí i pé ọrọ̀ tẹ̀mí pọ̀ nínú Bíbélì. Wọ́n fẹ́ jèrè lára ọrọ̀ tẹ̀mí wọ̀nyẹn tí wọ́n mọ̀ pé àwọn ti pàdánù.”

Bó ti wù kó rí, “ọrọ̀” wo ló wà nínú Bíbélì tí ẹni tó ń kẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lè jèrè? Rò ó wò ná: Ṣé wàá fẹ́ mọ bóo ṣe lè kojú àwọn àníyàn ojoojúmọ́? Báwo lo ṣe lè jẹ́ kí àlàáfíà wà láàárín agbo ìdílé? Kí ló dé tí ìwà àìlọ́wọ̀ àti ìwà jàgídíjàgan fi pọ̀ tó báyìí láwùjọ? Kí ló ń fa ìwà ipá láàárín àwọn èwe ìwòyí? A lè rí ìdáhùn tó tẹ́ni lọ́rùn sí ìbéèrè wọ̀nyí àtàwọn ìbéèrè míì tó ń jà gùdù lọ́kàn wa nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, wọn yóò sì jẹ́ “ọrọ̀” gidi, kì í wáá ṣe fún àwọn Kátólíìkì tàbí Pùròtẹ́sítáǹtì nìkan, ṣùgbọ́n pẹ̀lúpẹ̀lù fún àwọn ẹlẹ́sìn Búdà, Híńdù, Mùsùlùmí, Ṣintó, àti fáwọn tí kò gbà pé Ọlọ́run wà àtàwọn tó gbà gbọ́ pé Ọlọ́run kò ṣeé mọ̀ pàápàá. Gẹ́gẹ́ bí onísáàmù náà ti wí, ‘ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ni fìtílà fún ẹsẹ̀ rẹ̀, òun sì ni ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà rẹ̀.’ Ó lè jẹ́ bẹ́ẹ̀ fún ìwọ náà.—Sáàmù 119:105.