Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ó Kú Nítorí Ìlànà

Ó Kú Nítorí Ìlànà

Ó Kú Nítorí Ìlànà

“A RÁNTÍ August Dickmann (tí wọ́n bí ní 1910), tó jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà.” Bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ ohun tí wọ́n kọ sára àmì ẹ̀yẹ kan (táa fi hàn níhìn-ín), èyí tí wọ́n ṣí aṣọ kúrò lójú rẹ̀ lẹ́nu àìpẹ́ yìí ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Sachsenhausen tẹ́lẹ̀, nìyẹn. Èé ṣe tí ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà fi ní láti gba irú àmì ẹ̀yẹ bẹ́ẹ̀? Ìyókù ohun tí wọ́n kọ síbẹ̀ sọ ìtàn náà: “Àwọn SS yìnbọn pa [á] ní gbangba ní September 15, 1939, nítorí ohun tí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀ mú kí ó kọ̀ láti ṣe.”

August Dickmann wà ní àkámọ́ ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ ti Sachsenhausen ní ọdún 1937. Ọjọ́ mẹ́ta lẹ́yìn tí Ogun Àgbáyé Kejì bẹ̀rẹ̀ ni 1939 ni wọ́n pàṣẹ fún un pé kó fọwọ́ sí ìwé tó fi máa wọṣẹ́ ológun. Nígbà tó kọ̀ láti ṣe bẹ́ẹ̀ ni ọ̀gá ibùdó náà kàn sí Heinrich Himmler, tó jẹ́ olórí àwọn SS (Schutzstaffel, àwọn ẹ̀ṣọ́ fún Hitler), tó sì gbàṣẹ láti yìnbọn pa Dickmann níṣojú gbogbo àwọn ẹlẹ́wọ̀n tó wà ní àgọ́ náà. Ní September 17, 1939, ìwé ìròyìn The New York Times ròyìn láti Jámánì pé: “August Dickmann, ẹni ọdún mọ́kàndínlọ́gbọ̀n, . . . ni a ti fi ẹ̀yìn rẹ̀ tàgbá, tí a sì yìnbọn pa níhìn-ín.” Ìwé ìròyìn náà sọ pé, òun ni ọmọ ilẹ̀ Jámánì àkọ́kọ́ tó lòdì sí ogun yẹn nítorí ẹ̀rí ọkàn rẹ̀.

Ọgọ́ta ọdún lẹ́yìn náà, ní September 18, 1999, Àjọ Aṣèrántí ti Brandenburg ṣe ìrántí ikú Dickmann, àmì ẹ̀yẹ ìrántí náà ló wá ń rán àwọn àlejò létí ìgboyà àti ìgbàgbọ́ lílágbára tó ní. Àmì ẹ̀yẹ kejì tí wọ́n lẹ̀ mọ́ ògiri ìta àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ tẹ́lẹ̀ náà rán àwọn òǹwòran létí pé Dickmann wulẹ̀ jẹ́ ọ̀kan lára àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà bí ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀rún tó jìyà ní Sachsenhausen nítorí ìgbàgbọ́ wọn ni. Ọ̀pọ̀ àwọn mìíràn ló jìyà láwọn àgọ́ mìíràn. Bẹ́ẹ̀ ni o, kódà lábẹ́ ipò búburú tí wọ́n wà ní àgọ́ ìṣẹ́niníṣẹ̀ẹ́ yẹn, ọ̀pọ̀ ló dúró gẹ́gẹ́ bí olóòótọ́ sí àwọn ìlànà Ọlọ́run.

Lójú àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ojúṣe Kristẹni ni láti “wà lábẹ́ àwọn aláṣẹ [ìjọba] onípò gíga.” (Róòmù 13:1) Àmọ́, nígbà tí ìjọba bá gbìyànjú láti mú wọn ré òfin Ọlọ́run kọjá, wọ́n máa ń tẹ̀ lé àpẹẹrẹ àwọn àpọ́sítélì Kristi, tó sọ pé: “Àwa gbọ́dọ̀ ṣègbọràn sí Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí olùṣàkóso dípò àwọn ènìyàn.” (Ìṣe 5:29) Nítorí ìdí èyí, nínú ayé kan tí ìṣọ̀tá láàárín ẹ̀yà àti ìkórìíra kẹ́lẹ́yàmẹ̀yà ti fa ìwà ìkà bíburú jáì, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà níbi gbogbo ṣì ń lépa àlàáfíà bíi ti August Dickmann. Wọ́n ń tẹ̀ lé ọ̀rọ̀ ìyànjú tó wà nínú Bíbélì pé: “Má ṣe jẹ́ kí ibi ṣẹ́gun rẹ, ṣùgbọ́n máa fi ire ṣẹ́gun ibi.”—Róòmù 12:21.