Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Ìrètí Ìjọba Náà!

Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Ìrètí Ìjọba Náà!

Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Ìrètí Ìjọba Náà!

NǸKAN ayọ̀ ló mú kí èèyàn ẹgbọ̀kàndínlọ́gbọ̀n ó dín mẹ́rìndínlógún [5,784] pé jọ ní March 10, 2001, síbi mẹ́ta tó wà ní Ìpínlẹ̀ New York tí ìdílé ńlá Bẹ́tẹ́lì ń lò. Ó jẹ́ ìgbà ayẹyẹ ìkẹ́kọ̀ọ́yege kíláàsì àádọ́fà ti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì fún àwọn míṣọ́nnárì.

Carey Barber, tí í ṣe mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, kí gbogbo èèyàn káàbọ̀, ó sì ṣí ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà, nípa sísọ pé: “Inú wa dùn láti mọ̀ pé a ti fún kíláàsì àádọ́fà ti àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Gílíádì ní ìdálẹ́kọ̀ọ́ báyìí kí wọ́n lè di míṣọ́nnárì, kí a sì yàn wọ́n síṣẹ́ ní igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé.”

Bí A Ò Ṣe Ní Pàdánù Ayọ̀ Wa

Lẹ́yìn tí ọ̀rọ̀ àkọ́sọ látẹnu Arákùnrin Barber parí, Don Adams bá àwùjọ àtàwọn akẹ́kọ̀ọ́ méjìdínláàádọ́ta tó kẹ́kọ̀ọ́ yege sọ̀rọ̀ lórí kókó náà “Ìbùkún Jèhófà Ní Í Sọ Wá Di Ọlọ́rọ̀.” Ìwé Òwe 10:22 ló gbé ọ̀rọ̀ rẹ̀ kà. Ó rán àwùjọ létí pé Jèhófà máa ń mẹ́sẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ dúró, ó sì máa ń bù kún wọn nígbà tí wọ́n bá fi ire Ìjọba náà sípò àkọ́kọ́ nínú ìgbésí ayé wọn. Ó rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà pé irú ẹ̀mí ìmúratán tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ní nígbà táa ké sí i pé kó ‘ré kọjá sí Makedóníà láti wá ṣèrànwọ́,’ ni kí wọ́n fi tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ táa ṣẹ̀ṣẹ̀ yàn fún wọn. (Ìṣe 16:9) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn ìṣòro ń bẹ tí Pọ́ọ̀lù ní láti borí, mímúra tó múra tán láti lọ wàásù níbi táa rán an lọ yọrí sí ọ̀pọ̀ ìbùkún aláyọ̀.

Àwọn mẹ́ńbà kíláàsì tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ti parí ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi oṣù márùn-ún kọ́ nínú Bíbélì, wọ́n sì ti parí ìdánilẹ́kọ̀ọ́ tí yóò mú wọn gbára dì fún iṣẹ́ míṣọ́nnárì. Síbẹ̀, Daniel Sydlik, tí í ṣe mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n máa kẹ́kọ̀ọ́ nìṣó. Nígbà tó ń sọ̀rọ̀ lórí ẹṣin ọ̀rọ̀ náà, “Ẹ Jẹ́ Ọmọ Ẹ̀yìn Tòótọ́,” ó sọ pé: “Jíjẹ́ ọmọ ẹ̀yìn túmọ̀ sí ṣíṣègbọràn sí ọ̀rọ̀ Jésù nígbà gbogbo. Ó wé mọ́ mímúra tán nígbà gbogbo láti fetí sí ọ̀rọ̀ rẹ̀, ìsọfúnni tó ń fi ṣọwọ́ sí wa, àti ẹ̀kọ́ tó ń kọ́ wa.” Ó ṣàlàyé pé àwọn ọmọ ẹ̀yìn Kristi kì í ṣe ìpinnu láìfetí sí ohùn Ọ̀gá wọn; torí pé inú ìgbésí ayé Kristi la ti lè rí ọgbọ́n Ọlọ́run. (Kólósè 2:3) Kò sí ìkankan lára wa tó lè sọ pé ẹ̀ẹ̀kan ṣoṣo tóun gbọ́ ọ̀rọ̀ Jésù lòun ti mọ gbogbo ohun tó yẹ ní mímọ̀ nípa rẹ̀, nítorí náà Arákùnrin Sydlik rọ àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege náà pé kí wọ́n máa bá a lọ ní kíkẹ́kọ̀ọ́, kí wọ́n máa fi òtítọ́ Kristẹni tó ń fúnni lómìnira sílò, kí wọ́n sì máa fi kọ́ni.—Jòhánù 8:31, 32.

Ká má bàa pàdánù ayọ̀ wa nínú iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run, a gbọ́dọ̀ múra tán láti gba ìbáwí àti ìtọ́sọ́nà. “Ṣé Kíndìnrín Rẹ Á Tọ́ Ẹ Sọ́nà?” ni ìbéèrè tí Lawrence Bowen, ọ̀kan lára àwọn olùkọ́ ní Gílíádì béèrè. Ó fi hàn pé nínú Bíbélì kíndìnrín ṣàpẹẹrẹ èrò àti ìmí ẹ̀dùn wa tó jinlẹ̀ jù lọ. Kíndìnrín lè tọ́ wa sọ́nà, bí ìmọ̀ràn táa mí sí látinú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run bá dé inú wa lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún. (Sáàmù 16:7; Jeremáyà 17:10) Ipa ọ̀nà ìṣòtítọ́ wa tilẹ̀ lè ní ipa jíjinlẹ̀ lórí Jèhófà. Lẹ́yìn tí olùbánisọ̀rọ̀ náà ka Òwe 23:15, 16, ó wá béèrè pé: “Ṣé kíndìnrín rẹ á tọ́ ẹ sọ́nà?” Ó fi kún un pé: “Àdúrà wa ni pé kí ó tọ́ ẹ sọ́nà, wàá sì tipa bẹ́ẹ̀ mú kí inú Jèhófà dùn lọ́nà kíkọyọyọ. Wàá ru ìmọ̀lára rẹ̀ àtọkànwá sókè. Àní sẹ́, wàá jẹ́ kí kíndìnrín Ọlọ́run yọ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀, bóo ti fi ìṣòtítọ́ dúró sí ibi táa yàn ọ́ sí.”

Mark Noumair, tó sìn gẹ́gẹ́ bíi míṣọ́nnárì ní Kẹ́ńyà kó tó wá di olùkọ́ ní Gílíádì, ló sọ ọ̀rọ̀ àsọkágbá nínú apá yìí nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Àkòrí ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni, “Fífi Ojú Rí Ló Sàn Jù,” ó sì tẹnu mọ́ ìjẹ́pàtàkì níní ìtẹ́lọ́rùn. Níbàámu pẹ̀lú Oníwàásù 6:9, Arákùnrin Noumair dámọ̀ràn pé: “Má ṣe kọjá agbára rẹ. Ohun tí ‘fífi ojú rí’ túmọ̀ sí nìyẹn. Dípò gbígbé ara rẹ gẹṣin aáyán, kóo máa ronú nípa ohun tóo fẹ́ ṣe ṣùgbọ́n tí apá rẹ ò ká, gbájú mọ́ ṣíṣe gbogbo ohun tí apá rẹ ká nínú ipò tóo wà báyìí. Gbígbé ara rẹ gẹṣin aáyán, nínàgà sí ohun tí ọwọ́ rẹ kò lè tó, tàbí fífi ojoojúmọ́ ayé ronú nípa àwọn ohun tí kò wù ọ́ nípa ibi táa yàn ọ́ sí yóò wulẹ̀ sọ ẹ́ di aláìnítẹ̀ẹ́lọ́rùn àti olùráhùn ni.” Ká sòótọ́, ibi yòówù káa wà, tàbí ipòkípò táa bára wa, níní ìtẹ́lọ́rùn nínú ipò táa wà nítorí àjọṣe wa pẹ̀lú Ọlọ́run ni yóò jẹ́ ká máa láyọ̀ nínú iṣẹ́ ìsìn wa sí Ẹlẹ́dàá wa Atóbilọ́lá.

Àwọn Ìrírí Aláyọ̀ Nínú Iṣẹ́ Ìsìn Ìjọba Náà àti ní Gílíádì

Lẹ́yìn ìmọ̀ràn tó wúlò táa gbọ́ nínú ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn, àwọn akẹ́kọ̀ọ́ wá sọ díẹ̀ lára ìrírí tí wọ́n ní bí wọ́n ti ń wàásù láàárín oṣù márùn-ún tí wọ́n fi kẹ́kọ̀ọ́. Lábẹ́ ìdarí Wallace Liverance, tí ń forúkọ akẹ́kọ̀ọ́ sílẹ̀ ní Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì, àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege yìí ṣàlàyé bí wọ́n ṣe fi ara wọn hàn gẹ́gẹ́ bí òjíṣẹ́ Ọlọ́run. (2 Kọ́ríńtì 4:2) Wọ́n ti ta ẹ̀rí ọkàn tí Ọlọ́run fún àwọn kan jí. Ìrírí àwọn akẹ́kọ̀ọ́ náà fi hàn bí wọ́n ṣe bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn olóòótọ́ ọkàn tí wọ́n bá pàdé lójú pópó, nínú iṣẹ́ ilé dé ilé, àti láwọn ibòmíràn. Ọ̀pọ̀ ìgbà làwọn tó fìfẹ́ hàn sọ pé inú àwọn ìwé tí ètò Jèhófà ń tẹ̀ jáde, táa gbé ka Bíbélì, ni òtítọ́ wà. Onílé kan nífẹ̀ẹ́ gidigidi sí ẹsẹ Bíbélì kan pàtó. Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà sì ti ń kọ́ obìnrin náà lẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì báyìí.

Lẹ́yìn èyí ni Joel Adams fọ̀rọ̀ wá àwọn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ yege ní Gílíádì lọ́pọ̀ ọdún sẹ́yìn lẹ́nu wò. Ẹṣin ọ̀rọ̀ rẹ̀ ni, “Má Ṣe Ṣíwọ́ Ẹ̀kọ́ Kíkọ́, Má Ṣe Ṣíwọ́ Sísin Jèhófà.” Àwọn táa fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò gba àwọn míṣọ́nnárì tuntun nímọ̀ràn tó bọ́ sákòókò. Harry Johnson rántí ìgbà tóun jẹ́ mẹ́ńbà kíláàsì kẹrìndínlọ́gbọ̀n ti Gílíádì, ó sì sọ pé: “Wọ́n kọ́ wa pé ìgbà gbogbo ni Jèhófà ń darí àwọn èèyàn rẹ̀, yóò sì máa darí wọn nìṣó. Ìdánilójú yẹn ń fúnni níṣìírí bí ọdún ti ń gorí ọdún.” William Nonkes, tó jẹ́ mẹ́ńbà kíláàsì kẹtàléláàádọ́ta ti ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì, gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́yege nímọ̀ràn pé: “Lékè gbogbo rẹ̀, ẹ máa rántí àwọn ìlànà Bíbélì, ẹ máa fi wọ́n sílò nínú gbogbo ìpinnu tí ẹ ó ṣe nínú ìgbésí ayé yín nísinsìnyí àti títí láé. Bí ẹ bá ń ṣe bẹ́ẹ̀, ẹ ò ní fi iṣẹ́ táa yàn fún yín sílẹ̀, Jèhófà yóò sì rọ̀jò ìbùkún sórí yín.”

“A Fún Wa Lókun Láti Ṣe Ìfẹ́ Jèhófà” ni ẹṣin ọ̀rọ̀ tí Richard Rian yàn láti sọ̀rọ̀ lé lórí nígbà tí ọ̀rọ̀ kàn án nínú ìtòlẹ́sẹẹsẹ náà. Ọ̀kan lára àwọn tó fọ̀rọ̀ wá lẹ́nu wò ni John Kurtz, tó kẹ́kọ̀ọ́ yege ní kíláàsì ọgbọ̀n, tó sì ṣe iṣẹ́ míṣọ́nnárì ní Sípéènì fún ohun tó lé ní ọdún mọ́kànlélógójì. Nígbà tí wọ́n bi Arákùnrin Kurtz nípa ẹ̀kọ́ tí wọ́n fi ń kọ́ni ní Gílíádì, ó sọ pé: “Bíbélì ni lájorí ìwé tí wọ́n fi ń kọ́ wa lẹ́kọ̀ọ́. A tún ní àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́ tó ń jẹ́ ká lóye Bíbélì. Gbogbo èèyàn ló sì ní wọn lọ́wọ́. Kò sí ìsọfúnni ìkọ̀kọ̀ ní ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì. N kì í yéé tẹnu mọ́ kókó yìí nítorí pé gbogbo Ẹlẹ́rìí ni nǹkan táa fi ń kọ́ni ní Gílíádì wà lárọ̀ọ́wọ́tó wọn.”

Arákùnrin Gerrit Lösch, tí í ṣe mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ Olùṣàkóso ti Àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ló kádìí ìtòlẹ́sẹẹsẹ tẹ̀mí náà nílẹ̀ nípa sísọ̀rọ̀ lórí kókó náà “Rírọ̀ Mọ́ àti Wíwà Lábẹ́ Ìyẹ́ Apá Jèhófà.” Ó ṣàlàyé bí Bíbélì ṣe fi ìyẹ́ idì ṣàpèjúwe ààbò àti ìtìlẹyìn tí Ọlọ́run ń fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́. (Diutarónómì 32:11, 12; Sáàmù 91:4) Nígbà míì, ẹyẹ idì tó ti dàgbà máa ń na ìyẹ́ apá rẹ̀ fún ọ̀pọ̀ wákàtí láti fi ràdọ̀ bo àwọn ọmọ rẹ̀. Nígbà míì sì rèé, ìyá idì tilẹ̀ lè fi ìyẹ́ rẹ̀ dáàbò bo àwọn ọmọ rẹ̀ lọ́wọ́ ẹ̀fúùfù tó ń fa òtútù. Lọ́nà kan náà àti níbàámu pẹ̀lú ète Jèhófà, ó lè ran àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ olóòótọ́ lọ́wọ́, àgàgà nígbà tí wọ́n bá dojú kọ ìdánwò tẹ̀mí. Jèhófà kì í jẹ́ ká dán àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wò kọjá ibi tí agbára wọ́n mọ, ṣùgbọ́n yóò ṣe ọ̀nà tí wọn yóò fi lè fara dà á fún wọn. (1 Kọ́ríńtì 10:13) Arákùnrin Lösch kádìí ọ̀rọ̀ rẹ̀ báyìí: “Ká lè wà lábẹ́ ààbò tẹ̀mí, a gbọ́dọ̀ wà lábẹ́ ìyẹ́ apá Jèhófà. Èyí túmọ̀ sí pé a ò níí ní ẹ̀mí aṣèyówùú. Ẹ jẹ́ ká rọ̀ mọ́ Jèhófà àti ètò rẹ̀ tó dà bí ìyá, ká má kọ ìtọ́sọ́nà àti ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ wọn.”

Alága ka àwọn wáyà tí wọ́n tẹ̀ ránṣẹ́ àtàwọn lẹ́tà a-báa-yín-yọ̀ láti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé. Ó wá tó àkókò wàyí láti fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ ní ìwé ẹ̀rí dípúlọ́mà. Ìgbà tí Ilé Ẹ̀kọ́ Gílíádì bẹ̀rẹ̀, ète tí wọ́n fi dá a sílẹ̀ ni láti wulẹ̀ ṣètò ìwọ̀nba kíláàsì mélòó kan fún ọdún márùn-ún. Ṣùgbọ́n Jèhófà ti rí sí i pé ilé ẹ̀kọ́ náà kò kógbá sílé láti ọdún méjìdínlọ́gọ́ta báyìí. Gẹ́gẹ́ bí Arákùnrin Barber ti wí nínú ọ̀rọ̀ àkọ́sọ rẹ̀: “Àwọn tó ti kẹ́kọ̀ọ́ yege láti Gílíádì ti ṣe gudugudu méje yààyàà mẹ́fà láti 1943 táa ti dá ilé ẹ̀kọ́ Gílíádì sílẹ̀! Akitiyan wọn ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún lọ́nà ọgọ́rọ̀ọ̀rún àwọn ọlọ́kàn tútù ilẹ̀ ayé láti rọ́ wá sínú ètò ológo Jèhófà.” Dájúdájú, ilé ẹ̀kọ́ míṣọ́nnárì yìí ti jẹ́ kó ṣeé ṣe fún àràádọ́ta ọ̀kẹ́ láti máa yọ̀ nínú ìrètí Ìjọba náà.

[Àpótí tó wà ní ojú ìwé 24]

ÌSỌFÚNNI ONÍṢIRÒ NÍPA KÍLÁÀSÌ

Iye àwọn orílẹ̀-èdè táa ṣojú fún: 8

Iye àwọn orílẹ̀-èdè táa yàn wọ́n sí: 18

Iye àwọn akẹ́kọ̀ọ́: 48

Ìpíndọ́gba ọjọ́ orí: 34

Ìpíndọ́gba ọdún nínú òtítọ́: 18

Ìpíndọ́gba ọdún nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ alákòókò kíkún: 13

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Kíláàsì Àádọ́fà Tó Kẹ́kọ̀ọ́ Yege Nílé Ẹ̀kọ́ Watchtower Bible School of Gilead

Nínú ìlà àwọn orúkọ tí ń bẹ nísàlẹ̀ yìí, nọ́ńbà kọ̀ọ̀kan jẹ́ láti iwájú lọ sẹ́yìn, a sì to orúkọ láti ọwọ́ òsì sí ọwọ́ ọ̀tún lórí ìlà kọ̀ọ̀kan.

(1) Vacek, E.; Madelin, L.; Evans, G.; Watanabe, K. (2) Trafford, P.; Turfa, J.; Wilson, P.; Williams, R.; Weber, A. (3) Johnson, T.; Hanau, K.; Mourlhou, F.; Charpentier, F.; Peckham, R.; Androsoff, P. (4) Seegers, T.; Seegers, D.; Bailey, P.; Bailey, M.; Madelin, K.; Lippold, E.; Lippold, T. (5) Evans, N.; Gold, R.; Bollmann, I.; Vacek, R.; Oundjian, J.; Wilson, N. (6) Turfa, J.; Zuidema, L.; Zuidema, R.; Bengtsson, C.; Bengtsson, J.; Galano, M.; Galano, L. (7) Peckham, T.; Mourlhou, J.; Charpentier, C.; Gold, M.; Bollmann, R.; Oundjian, F. (8) Weber, R.; Johnson, B.; Hanau, D.; Watanabe, Y.; Williams, R.; Trafford, G.; Androsoff, T.