Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ọgbẹ́ Ọ̀rẹ́”

“Ọgbẹ́ Ọ̀rẹ́”

“Ọgbẹ́ Ọ̀rẹ́”

ÀPỌ́SÍTÉLÌ Pọ́ọ̀lù rí i pé ó ṣe pàtàkì láti tọ́ àwọn Kristẹni, tó wà ní Gálátíà ní ọ̀rúndún kìíní, sọ́nà. Bóyá torí pé kí wọ́n máà bínú ló ṣe béèrè pé: “Tóò, nígbà náà, mo ha ti di ọ̀tá yín nítorí pé mo sọ òtítọ́ fún yín bí?”—Gálátíà 4:16.

Pọ́ọ̀lù kò di ọ̀tá wọn nítorí pé ó ‘sọ òtítọ́ fún wọn.’ Ní ti gidi, ó ṣe ohun tó wà ní ìbámu pẹ̀lú ìlànà Bíbélì tó sọ pé: “Otitọ li ọgbẹ ọrẹ́.” (Òwe 27:6, Bíbélì Mímọ́) Ó mọ̀ pé irú àwọn tó ṣisẹ̀ gbé bẹ́ẹ̀ lè pàdánù iyì tí wọ́n ní. Ṣùgbọ́n ó mọ̀ pé kíkọ̀ láti fún ẹlẹ́ṣẹ̀ kan ní ìbáwí tí ó tọ́ sí i lè túmọ̀ sí pé ńṣe lèèyàn ò fẹ́ kí onítọ̀hún jàǹfààní látinú ìfẹ́ tí Jèhófà Ọlọ́run ní sí irú ẹni bẹ́ẹ̀. (Hébérù 12:5-7) Nítorí náà, níwọ̀n bí Pọ́ọ̀lù ti jẹ́ ọ̀rẹ́ tòótọ́, tó sì pẹ́ tó ti nífẹ̀ẹ́ tó jinlẹ̀ fún ìjọ náà, kò fà sẹ́yìn láti fún wọn ní ìmọ̀ràn tí yóò mú wọn ṣàtúnṣe.

Lóde òní, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ń mú àṣẹ tí a pa fún wọn ṣẹ ‘láti máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, . . . kí wọ́n máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí [Jésù Kristi] ti pa láṣẹ mọ́.’ Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, àwọn Kristẹni olóòótọ́ wọ̀nyí kì í fi òtítọ́ Bíbélì báni dọ́rẹ̀ẹ́, ìyẹn òtítọ́ tó ń tú ẹ̀kọ́ èké àti àwọn ìwà tí kò bá ìlànà Kristẹni mu fó, wọ́n sì ń dá a lẹ́bi. (Mátíù 15:9; 23:9; 28:19, 20; 1 Kọ́ríńtì 6:9, 10) Dípò káwọn èèyàn kà wọ́n sí ọ̀tá tí wọn ò fẹ́ rí sójú, ìfẹ́ tí ojúlówó ọ̀rẹ́ máa ń ní ni wọ́n ń fi hàn.

Onísáàmù náà fi ìjìnlẹ̀ òye tí Ọlọ́run mí sí kọ̀wé pé: “Bí olódodo bá gbá mi, yóò jẹ́ inú-rere-onífẹ̀ẹ́; bí ó bá sì fi ìbáwí tọ́ mi sọ́nà, yóò jẹ́ òróró ní orí, èyí tí orí mi kì yóò fẹ́ láti kọ̀.”—Sáàmù 141:5.