Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Báwo Lo Ṣe Lè Ní Èrò Tó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì Nípa Owó?

Báwo Lo Ṣe Lè Ní Èrò Tó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì Nípa Owó?

Báwo Lo Ṣe Lè Ní Èrò Tó Wà Níwọ̀ntúnwọ̀nsì Nípa Owó?

Ìfẹ́ owó àti fífẹ́ láti kó ọrọ̀ àlùmọ́nì jọ kì í ṣe ohun tuntun; bẹ́ẹ̀ ni Bíbélì ò sì yéé sọ nípa wọn, nítorí wọn kì í ṣe ìṣẹ̀lẹ̀ mérìíyìírí tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọjú. Wọ́n ti wà tipẹ́. Nínú Òfin, Ọlọ́run pàṣẹ fún àwọn ọmọ Ísírẹ́lì pé: “Ojú rẹ kò gbọ́dọ̀ wọ ilé ọmọnìkejì rẹ . . . tàbí ohunkóhun tí ó jẹ́ ti ọmọnìkejì rẹ.”—Ẹ́kísódù 20:17.

ÌFẸ́ owó àti ọrọ̀ àlùmọ́nì pọ̀ gan-an láyé Jésù. Ẹ jẹ́ ká gbé ìròyìn nípa ìfọ̀rọ̀wérọ̀ tó wáyé láàárín Jésù àti ọ̀dọ́kùnrin kan tó ní “ọrọ̀ gan-an” yẹ̀ wò. “Jésù wí fún un pé: ‘Ohun kan ṣì wà tí o ṣaláìní: Ta gbogbo ohun tí o ní, kí o sì pín in fún àwọn òtòṣì, ìwọ yóò sì ní ìṣúra ní ọ̀run; sì wá di ọmọlẹ́yìn mi.’ Nígbà tí ó gbọ́ èyí, ó wá ní ẹ̀dùn-ọkàn gidigidi, nítorí ó ní ọrọ̀ gan-an.”—Lúùkù 18:18-23.

Èrò Tó Yẹ Ká Ní Nípa Owó

Yóò jẹ́ àṣìṣe láti parí èrò sí pé Bíbélì ka owó fúnra rẹ̀ tàbí ohunkóhun táa bá lè lò ó fún léèwọ̀. Bíbélì fi hàn pé owó máa ń gbani lọ́wọ́ ipò òṣì àti àwọn ìṣòrò mìíràn tó máa ń bá ipò òṣì rìn, ó sì ń jẹ́ kéèyàn ní àwọn nǹkan tó jẹ́ kòṣeémánìí. Sólómọ́nì Ọba kọ̀wé pé: “Ọgbọ́n jẹ́ fún ìdáàbòbò, gẹ́gẹ́ bí owó ti jẹ́ fún ìdáàbòbò.” Àti pé: “Oúnjẹ wà fún ẹ̀rín àwọn òṣìṣẹ́, wáìnì sì ń mú kí ìgbésí ayé kún fún ayọ̀ yíyọ̀; ṣùgbọ́n owó ní ń mú ìdáhùn wá nínú ohun gbogbo.”—Oníwàásù 7:12; 10:19.

Ọlọ́run fọwọ́ sí lílo owó lọ́nà tó dára. Fún àpẹẹrẹ, Jésù sọ pé: “Ẹ yan àwọn ọ̀rẹ́ fún ara yín nípasẹ̀ ọrọ̀ àìṣòdodo.” (Lúùkù 16:9) Dídáwó fún ìlọsíwájú ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ wà lára èyí, nítorí ó dájú pé àá fẹ́ kí Ọlọ́run jẹ́ Ọ̀rẹ́ wa. Sólómọ́nì alára, tó tẹ̀ lé àpẹẹrẹ Dáfídì, baba rẹ̀, fi owó tó pọ̀ gan-an àti àwọn ohun iyebíye mìíràn ṣètìlẹyìn fún kíkọ́ tẹ́ńpìlì Jèhófà. Ohun mìíràn tó tún jẹ́ àìgbọdọ̀máṣe fún àwọn Kristẹni ni pé kí wọ́n fi ohun ìní ṣèrànwọ́ fún àwọn aláìní. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Ẹ máa ṣe àjọpín pẹ̀lú àwọn ẹni mímọ́ ní ìbámu pẹ̀lú àwọn àìní wọn.” Ó fi kún un pé: “Ẹ máa tẹ̀ lé ipa ọ̀nà aájò àlejò.” (Róòmù 12:13) Èyí sábà máa ń ná èèyàn lówó. Àmọ́, ìfẹ́ owó wá ńkọ́?

“Nínífẹ̀ẹ́ Fàdákà”

Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé tó kún rẹ́rẹ́ lórí “ìfẹ́ owó”—tàbí ní ṣangiliti, “nínífẹ̀ẹ́ fàdákà”—nígbà tó ń kọ̀wé sí Tímótì, tó jẹ́ Kristẹni ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ tí kò tó o lọ́jọ́ orí. A lè rí ìṣílétí Pọ́ọ̀lù nínú 1 Tímótì 6:6-19. Ó sọ̀rọ̀ nípa “ìfẹ́ owó” gẹ́gẹ́ bí apá pàtàkì lára àlàyé tó ń ṣe lórí nǹkan ìní ti ara. Ì bá dára ká fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ ọ̀rọ̀ onímìísí tí Pọ́ọ̀lù sọ, nítorí bí ọ̀rọ̀ owó ṣe ká àwọn ènìyàn lára lóde òní. Irú àyẹ̀wò bẹ́ẹ̀ ṣàǹfààní gan-an nítorí pé ó ń jẹ́ kí a mọ bí a ṣe “lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.”

Pọ́ọ̀lù kìlọ̀ pé: “Ìfẹ́ owó ni gbòǹgbò onírúurú ohun aṣeniléṣe gbogbo, àti nípa nínàgà fún ìfẹ́ yìí, a ti mú àwọn kan ṣáko lọ kúrò nínú ìgbàgbọ́, wọ́n sì ti fi ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìrora gún ara wọn káàkiri.” (1 Tímótì 6:10) Ẹsẹ Ìwé Mímọ́ yìí kò sọ pé owó fúnra rẹ̀ burú—kò sì sí ẹsẹ Ìwé Mímọ́ mìíràn tó sọ bẹ́ẹ̀. Àpọ́sítélì ọ̀hún ò sì sọ pé owó ni lájorí ohun tó ń fa “ohun aṣeniléṣe” tàbí pé owó ló ń fa gbogbo ìṣòro. Kàkà bẹ́ẹ̀, ìfẹ́ owó lè jẹ́ ọ̀kan lára ohun tó ń fa onírúurú “ohun aṣeniléṣe”—tí kì í bá tiẹ̀ ṣe òun nìkan ló ń fà á.

Yẹra fún Ìwọra

Òkodoro òtítọ́ náà pé Ìwé Mímọ́ kò ka owó léèwọ̀ kò ní ká má kọbi ara sí ìkìlọ̀ Pọ́ọ̀lù. Àwọn Kristẹni tó nífẹ̀ẹ́ owó lè tètè kó sínú onírúurú ìṣòro, èyí tó burú jù lọ níbẹ̀ ni kéèyàn ṣáko kúrò nínú ìgbàgbọ́. Ọ̀rọ̀ tí Pọ́ọ̀lù sọ fún àwọn Kristẹni tó wà ní Kólósè túbọ̀ tẹnu mọ́ òtítọ́ yìí, ó ní: “Nítorí náà, ẹ sọ àwọn ẹ̀yà ara yín tí ń bẹ lórí ilẹ̀ ayé di òkú ní ti . . . ìfẹ́-ọkàn tí ń ṣeni lọ́ṣẹ́, àti ojúkòkòrò, tí í ṣe ìbọ̀rìṣà.” (Kólósè 3:5) Báwo ni ojúkòkòrò, ìwọra, tàbí “ìfẹ́ owó” ṣe lè jẹ́ ìbọ̀rìṣà? Ṣé èyí wá túmọ̀ sí pé ó burú kéèyàn wá bóun ṣe máa kọ́ ilé ńlá, tí òun máa ra ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́ tuntun, tàbí kéèyàn wáṣẹ́ tó túbọ̀ ń mówó wọlé? Rárá o, kò sí èyí tó burú nínú nǹkan wọ̀nyí fúnra wọn. Ìbéèrè náà ni pé: Kí ni ohun téèyàn ní lọ́kàn gan-an tó fi ń wá èyíkéyìí nínú àwọn nǹkan wọ̀nyí, ṣé ó nílò wọn ní ti gidi?

Ìyàtọ̀ tó wà láàárín kéèyàn kan nífẹ̀ẹ́ sí nǹkan àti kéèyàn jẹ́ oníwọra la lè fi wé ìyàtọ̀ tó wà láàárín iná kékeré táa dá láti fi se oúnjẹ àti iná tó ń jó wòwò, tó ń jó igbó run. Ìfẹ́ ọkàn tó dára tó sì bójú mu lè ṣàǹfààní. Ó ń sún wa láti ṣe iṣẹ́ àṣekára, ká sì ṣe é láṣeyege. Òwe 16:26 sọ pé: “Ọkàn òṣìṣẹ́ kára ti ṣiṣẹ́ kára fún un, nítorí pé ẹnu rẹ̀ ti sún un tipátipá.” Àmọ́, ìwọra léwu, ó sì ń ba nǹkan jẹ́. Ìfẹ́ ọkàn tí kò ṣeé ṣàkóso ni.

Ìkóra-ẹni-níjàánu ni olórí ọ̀ràn náà. Ṣé àwa ni yóò máa ṣàkóso owó tàbí àwọn nǹkan ìní ti ara táa ń kó jọ, tàbí owó ni yóò máa ṣàkóso wa? Ìdí nìyẹn tí Pọ́ọ̀lù fi sọ pé jíjẹ́ “oníwọra . . . túmọ̀ sí jíjẹ́ abọ̀rìṣà.” (Éfésù 5:5) Láti jẹ́ oníwọra fún ohun kan ní ti gidi túmọ̀ sí pé a yọ̀ǹda ara wa fún un—ìyẹn ni pé a sọ ọ́ di ọ̀gá wa, ọlọ́run wa, ohun táa ń sìn. Ní ìyàtọ̀ pátápátá sí ìyẹn, Ọlọ́run là á mọ́lẹ̀ pé: “Ìwọ kò gbọ́dọ̀ ní àwọn ọlọ́run èyíkéyìí mìíràn níṣojú mi.”—Ẹ́kísódù 20:3.

Jíjẹ́ oníwọra tún túmọ̀ sí pé a kò nígbẹ̀ẹ́kẹ̀lé pé Ọlọ́run yóò mú ìlérí rẹ̀ ṣẹ láti fún wa ní ohun táa nílò. (Mátíù 6:33) Nítorí náà, ìwọra túmọ̀ sí yíyíjú kúrò lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Lọ́nà yìí pẹ̀lú, “ìbọ̀rìṣà” ni. Abájọ tí Pọ́ọ̀lù fi kìlọ̀ nípa rẹ̀ láìfọ̀rọ̀ sábẹ́ ahọ́n sọ rárá!

Jésù tún fúnni ní ìkìlọ̀ tó sọjú abẹ níkòó nípa ìwọra. Ó pàṣẹ fún wa láti yẹra fún fífi torí tọrùn wá ohun tí a kò ní: “Ẹ la ojú yín sílẹ̀, kí ẹ sì máa ṣọ́ra fún gbogbo onírúurú ojúkòkòrò, nítorí pé nígbà tí ẹnì kan bá tilẹ̀ ní ọ̀pọ̀ yanturu pàápàá, ìwàláàyè rẹ̀ kò wá láti inú àwọn ohun tí ó ní.” (Lúùkù 12:15) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí àyọkà yìí wí, àti àkàwé tí Jésù ṣe tẹ́lẹ̀, ìwọra túmọ̀ sí fífi ìwà òmùgọ̀ gbà gbọ́ pé ohun tó ṣe pàtàkì jù lọ nínú ìgbésí ayé ni bí ohun téèyàn ní ṣe pọ̀ tó. Ó lè jẹ́ owó, ipò, agbára, tàbí àwọn nǹkan mìíràn tó fara pẹ́ ẹ. Ó ṣeé ṣe kéèyàn ní ìwọra fún ohunkóhun tó ṣeé ní sọ́wọ́. A lè ronú pé níní nǹkan yẹn yóò fún wa nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Àmọ́, gẹ́gẹ́ bí ohun tí Bíbélì wí, àti ohun táwọn èèyàn ti nírìírí rẹ̀, Ọlọ́run nìkan ṣoṣo ló lè tẹ́ ohun tó jẹ́ àìní wa lọ́rùn ní ti gidi, ó sì máa ṣe bẹ́ẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Jésù ṣe sọ fún àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀.—Lúùkù 12:22-31.

Àṣà ká máa ta ohun kan ká sì máa ra òmíràn tó gbòde lónìí ló ń mú kí ẹ̀mí ìwọra túbọ̀ máa peléke sí i. Ọ̀pọ̀ tó jẹ́ pé àwọn ọ̀nà tí wọn ò tètè fura sí, àmọ́ tó jẹ́ èyí tó lágbára ni wọ́n fi di ẹni tó ní ẹ̀mí ìwọra, gbà gbọ́ pé kò sí ohun táwọn ní tó lè tó àwọn. Wọ́n ń wá ohun púpọ̀ sí i, wọ́n ń wá èyí tó tóbi sí i, tó sì tún dára ju ti tẹ́lẹ̀ lọ. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a ò lè yí ayé tó yí wa ká padà, báwo làwa lẹ́nì kọ̀ọ̀kan ṣe lè yẹra fún àṣà yìí?

Ìtẹ́lọ́rùn àti Ìwọra

Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa ohun tó jẹ́ òdìkejì ìwọra, ìyẹn ni ìtẹ́lọ́rùn. Ó sọ pé: “Nítorí náà, bí a bá ti ní ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ, àwa yóò ní ìtẹ́lọ́rùn pẹ̀lú nǹkan wọ̀nyí.” (1 Tímótì 6:8) Báa ṣe ṣàpèjúwe gbogbo ohun táa dìídì nílò yìí—ìyẹn “ohun ìgbẹ́mìíró àti aṣọ”—lè dún bí ọ̀rọ̀ yẹpẹrẹ tàbí bí ọ̀rọ̀ tí kò ní láárí. Ọ̀pọ̀ èèyàn ni orí wọn máa ń wú nígbà tí wọ́n bá ń wo àwọn ètò orí tẹlifíṣọ̀n, nínú èyí tí àwọn òǹwòran ti máa ń rí àwọn gbajúgbajà tó ń gbé inú àwọn ilé olówó iyebíye. Ọ̀nà téèyàn fi ń ní ìtẹ́lọ́rùn kọ́ nìyẹn.

Àmọ́ ṣá o, a ò sọ pé káwọn ìránṣẹ́ Ọlọ́run mọ̀ọ́mọ̀ fi ara wọn sínú ipò òṣì o. (Òwe 30:8, 9) Àmọ́, Pọ́ọ̀lù rán wa létí ohun tí ipò òṣì túmọ̀ sí ní ti gidi, èyíinì ni: àìní oúnjẹ, aṣọ, àti ibùgbé tó dára tí ẹnì kan lè gbé. Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, bí a bá ní àwọn nǹkan wọ̀nyẹn, a ti ní ohun tó yẹ kó fún wa nítẹ̀ẹ́lọ́rùn nìyẹn.

Ṣé lóòótọ́ ni pé àwọn ohun tí Pọ́ọ̀lù sọ yẹn ni ohun tó ṣe pàtàkì láti lè ní ìtẹ́lọ́rùn? Ǹjẹ́ lóòótọ́ ló ṣeé ṣé kéèyàn nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú kìkì àwọn ohun tó jẹ́ kòṣeémánìí—ìyẹn oúnjẹ, aṣọ, àti ibùgbé? Ó yẹ kí Pọ́ọ̀lù mọ̀. Òun fúnra rẹ̀ ti gbádùn ọrọ̀ àti àwọn àǹfààní ipò gíga nínú àwùjọ àwọn Júù àti ti ọmọ ìbílẹ̀ Róòmù. (Ìṣe 22:28; 23:6; Fílípì 3:5) Pọ́ọ̀lù tún jìyà bí ẹní máa kú nínú iṣẹ́ míṣọ́nnárì rẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 11:23-28) Nínú gbogbo rẹ̀ pátá, ó kọ́ àṣírí kan tó ràn án lọ́wọ́ láti nítẹ̀ẹ́lọ́rùn. Àṣírí wo nìyẹn?

“Mo Ti Kọ́ Àṣírí” Náà

Pọ́ọ̀lù ṣàlàyé nínú ọ̀kan lára àwọn lẹ́tà rẹ̀ pé: “Ní tòótọ́, mo mọ bí a ṣe ń wà pẹ̀lú àwọn ìpèsè bín-ín-tín, ní tòótọ́ mo mọ bí a ṣe ń ní ọ̀pọ̀ yanturu. Nínú ohun gbogbo àti nínú ipò gbogbo, mo ti kọ́ àṣírí bí a ti ń jẹ àjẹyó àti bí a ti ń wà nínú ebi, bí a ti ń ní ọ̀pọ̀ yanturu àti bí a ti ń jẹ́ aláìní.” (Fílípì 4:12) Ọkàn Pọ́ọ̀lù mà balẹ̀ o, ó sì lẹ́mìí nǹkan yóò dára! A lè ronú pé nǹkan rọ̀ṣọ̀mù fún un nígbà tó kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, àmọ́ ọ̀rọ̀ ò rí bẹ́ẹ̀. Ọgbà ẹ̀wọ̀n ló wà ní Róòmù!—Fílípì 1:12-14.

Táa bá ronú jinlẹ̀ lórí kókó tó gbèrò yìí, a óò rí i pé àyọkà yìí sọ̀rọ̀ tó lágbára lórí bí kò ṣe jẹ́ pé kìkì ọrọ̀ àlùmọ́nì ló lè féèyàn nítẹ̀ẹ́lọ́rùn, bí kò ṣe irú ipò téèyàn bá tún wà. Níní ọrọ̀ ní àníjù tàbí jíjẹ́ tálákà paraku lè jẹ́ ká mọ ohun táa kà sí pàtàkì jù lọ. Pọ́ọ̀lù sọ̀rọ̀ nípa àwọn nǹkan tẹ̀mí tó mú kó ṣeé ṣe fún un láti nítẹ̀ẹ́lọ́rùn láìka ipò tó wà nípa tara sí, ó ní: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye [Ọlọ́run] tí ń fi agbára fún mi.” (Fílípì 4:13) Dípò tí Pọ́ọ̀lù ì bá fi gbára lé àwọn ohun ìní rẹ̀, yálà wọ́n pọ̀ ni o tàbí wọ́n kéré, tàbí kí ó gbára lé ipò tó wà, yálà ó dára tàbí kó dára, Ọlọ́run ló gbẹ́kẹ̀ lé láti tẹ́ àìní rẹ̀ lọ́rùn. Ìtẹ́lọ́rùn ni àbájáde rẹ̀.

Àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù ṣe pàtàkì gan-an fún Tímótì. Àpọ́sítélì náà gba ọ̀dọ́kùnrin náà níyànjú láti gbé ìgbésí ayé tó fi ìfọkànsin Ọlọ́run àti níní àjọṣe tímọ́tímọ́ pẹ̀lú Ọlọ́run ṣáájú ọrọ̀. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Àmọ́ ṣá o, ìwọ, ènìyàn Ọlọ́run, sá fún nǹkan wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n máa lépa òdodo, fífọkànsin Ọlọ́run, ìgbàgbọ́, ìfẹ́, ìfaradà, inú tútù.” (1 Tímótì 6:11) Òótọ́ ni pé Tímótì la darí àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyẹn sí, àmọ́ ẹnikẹ́ni tó bá fẹ́ bọlá fún Ọlọ́run, tó sì fẹ́ gbé ìgbésí ayé aláyọ̀ ní ti gidi lè fi wọ́n sílò.

Tímótì ní láti ṣọ́ra fún ìwọra bíi ti àwọn Kristẹni yòókù. Ó hàn gbangba pé àwọn onígbàgbọ́ tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ wà nínú ìjọ Éfésù, níbi tó wà nígbà tí Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí i. (1 Tímótì 1:3) Pọ́ọ̀lù ti mú ìhìn rere Kristi wá sínú ìlú aláásìkí tó jẹ́ ibùdó ìṣòwò yìí, ó sì ti yí àwọn tó pọ̀ lọ́kàn padà. Kò sí àní-àní pé àwọn mélòó kan lára àwọn wọ̀nyí jẹ́ ọlọ́rọ̀, bí àwọn kan ṣe jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú ìjọ Kristẹni ti òde òní.

Ìbéèrè tó wá dìde, àgàgà lójú ẹ̀kọ́ tí 1 Tímótì 6:6-10 fi kọ́ wa, ni pé: Kí ló yẹ kí àwọn tó rí já jẹ ṣe tí wọ́n bá fẹ́ bọlá fún Ọlọ́run? Pọ́ọ̀lù sọ pé kí wọ́n bẹ̀rẹ̀ nípa yíyẹ irú ẹ̀mí tí wọ́n ní wò. Owó máa ń jẹ́ kéèyàn ní ẹ̀mí ohun-moní tómi. Pọ́ọ̀lù sọ pé: “Fún àwọn ọlọ́rọ̀ nínú ètò àwọn nǹkan ìsinsìnyí ní àṣẹ ìtọ́ni láti má ṣe jẹ́ ọlọ́kàn-gíga, kí wọ́n má ṣe gbé ìrètí wọn lé ọrọ̀ àìdánilójú, bí kò ṣe lé Ọlọ́run, ẹni tí ń pèsè ohun gbogbo fún wa lọ́pọ̀ jaburata fún ìgbádùn wa.” (1 Tímótì 6:17) Àwọn tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ ní láti kọ́ bí wọ́n á ṣe máa wò kọjá owó tí wọ́n ní; wọ́n gbọ́dọ̀ máa wo Ọlọ́run, ẹni tó jẹ́ orísun ọrọ̀ èyíkéyìí.

Àmọ́, irú ẹ̀mí téèyàn ní kò yanjú gbogbo ọ̀rọ̀ tó wà nílẹ̀ yìí. Bópẹ́ bóyá, àwọn Kristẹni tó jẹ́ ọlọ́rọ̀ gbọ́dọ̀ kọ́ bí wọn ó ṣe lo ọrọ̀ wọn lọ́nà tó dára. Pọ́ọ̀lù ṣíni létí pé: ‘Máa ṣe rere, jẹ́ ọlọ́rọ̀ nínú àwọn iṣẹ́ àtàtà, jẹ́ aláìṣahun, múra tán láti ṣe àjọpín.’—1 Tímótì 6:18.

“Ìyè Tòótọ́”

Kókó inú ìmọ̀ràn Pọ́ọ̀lù ni pé a gbọ́dọ̀ máa rán ara wa létí ibi tí àwọn ohun ìní ti ara ṣe pàtàkì mọ. Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sọ pé: “Àwọn nǹkan tí ó níye lórí tí ó jẹ́ ti ọlọ́rọ̀ ni ìlú lílágbára rẹ̀, wọ́n sì dà bí ògiri adáàbòboni nínú èrò-ọkàn rẹ̀.” (Òwe 18:11) Bẹ́ẹ̀ ni o, àfọkànrò lásán ni ààbò tí ọrọ̀ lè fúnni máa já sí níkẹyìn, ìtànjẹ sì ni ní ti gidi. Kò tọ̀nà láti gbé ìgbésí ayé wa karí wọn dípò tí à bá fi gbé e karí rírí ojú rere Ọlọ́run.

Àìdánilójú ọrọ̀ àlùmọ́nì jẹ́ kó dà bí ohun kan tó jẹ́ ẹlẹgẹ́ gan-an jù èyí táa lè gbé ìrètí wa kà. Ojúlówó ìrètí gbọ́dọ̀ jẹ́ èyí táa gbé ka ohun kan tó lágbára, tó nítumọ̀, tó sì lè wà pẹ́ títí. Ìrètí Kristẹni jẹ́ èyí táa gbé ka Ẹlẹ́dàá wa, Jèhófà Ọlọ́run, àti ìlérí ìyè àìnípẹ̀kun tó ṣe. Níwọ̀n bó ti jẹ́ òótọ́ ni pé owó kò lè ra ayọ̀, ó tiẹ̀ tún wá jẹ́ òótọ́ pọ́ńbélé pé owó kò lè ra ìgbàlà. Kìkì ìgbàgbọ́ táa ní nínú Ọlọ́run ló lè fún wa ní irú ìrètí bẹ́ẹ̀.

Nítorí náà, yálà a jẹ́ olówó tàbí tálákà, ẹ jẹ́ ká máa lépa ọ̀nà ìgbésí ayé tí yóò jẹ́ ká “ní ọrọ̀ síhà ọ̀dọ̀ Ọlọ́run.” (Lúùkù 12:21) Kò sí ohun tó ṣeyebíye tó kéèyàn mú ìdúró rere tí Ẹlẹ́dàá tẹ́wọ́ gbà. Gbogbo ìsapá láti máa bá ṣíṣe bẹ́ẹ̀ lọ ń fi kún bí a ṣe ń ‘to ìṣúra ìpìlẹ̀ tí ó dára lọ́pọ̀lọpọ̀ jọ fún ara wa de ẹ̀yìn ọ̀la, kí a lè di ìyè tòótọ́ mú gírígírí.’—1 Tímótì 6:19.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 7]

Pọ́ọ̀lù kọ́ àṣírí níní ìtẹ́lọ́rùn

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8]

A lè láyọ̀, ká sì nítẹ̀ẹ́lọ́rùn pẹ̀lú ohun táa ní