Àwọn Igi Tó Rọ́kú
Àwọn Igi Tó Rọ́kú
Ibi gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ kì í ṣe ibi tó dáa láti kọ́lé sí, àgàgà tó bá jẹ́ orí àpáta gàǹgà. Àmọ́ ṣá o, láìka gbogbo ìṣòro rẹ̀ sí, orí irú àpáta gàǹgà bẹ́ẹ̀ làwọn igi jẹ́gẹ́dẹ́ kan fìdí múlẹ̀ gbọn-in sí, tí wọ́n ń la ìgbà òtútù tó tutù bíi yìnyín já, tí wọn ò sì ní gbẹ dà nù lákòókò ọ̀dá ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn.
ÀWỌN igi tí ara wọn gbàyà yìí kì í sábàá tóbi ràgàjì bí àwọn ẹ̀yà wọn tó wà ní pẹ̀tẹ́lẹ̀. Ara igi wọ̀nyí lè rí ṣágiṣàgi, kí wọ́n lọ́ bìrìpà, kí wọ́n sì rí kúńtá ní ìdúró. Ipò ojú ọjọ́ líle koko àti erùpẹ̀ tí kò tó nǹkan ni kò jẹ́ kí wọ́n tóbi jù bẹ́ẹ̀ lọ.
Níwọ̀n bó ti jẹ́ pé àyíká tí kò bára dé yìí ni igi wọ̀nyí wà lórí ilẹ̀ ayé, ńṣe lèèyàn á rò pé wọn kì í pẹ́ kú. Ṣùgbọ́n ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ o. Àwọn kan sọ pé igi tí wọ́n ń pè ní Mètúsélà, tó jẹ́ ẹ̀yà igi ahóyaya, tó wà níbi tó ga tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta mítà ní White Mountains ti California, ti pẹ́ tó ẹgbẹ̀rún ọdún márùn-ún ó dín ọ̀ọ́dúnrún [4,700] láyé. Ìwé The Guinness Book of Records 1997, sọ pé ẹ̀yà igi yìí ni igi tí ọjọ́ orí rẹ̀ pẹ́ jù lọ ní àgbáyé. Edmund Schulman, tó ṣèwádìí nípa àwọn igi tó ti pẹ́ yìí, ṣàlàyé pé: “Ó jọ pé ìyà . . . ló ń jẹ́ kí ẹ̀yà igi ahóyaya yìí dàgbà. Gbogbo ògbólógbòó [igi ahóyaya] tí ń bẹ ní White Mountains tó wà níbi tó fẹ́rẹ̀ẹ́ ga tó ẹgbẹ̀rún mẹ́ta mítà nínú aginjù olókùúta tó gbẹ́ háúháú.” Schulman tún ṣàwárí pé nínú ipò tí kò bára dé ni èyí tó dàgbà jù lọ nínú àwọn ẹ̀yà igi ahóyaya yòókù ti ń dàgbà.
Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìyà ń jẹ wọ́n gan-an, àwọn igi tó rọ́kú yìí ń lo àǹfààní méjèèjì tí wọ́n ní dé ẹ̀kúnrẹ́rẹ́. Nítorí pé wọ́n dá wà, láìsí koríko nítòsí, iná táwọn èèyàn fi ń sun igbó kì í sábàá dé ọ̀dọ̀ wọn, iná sì jẹ́ ọ̀kan lára ewu tó ga jù lọ fún igi. Àǹfààní kejì ni pé ńṣe ni gbòǹgbò wọn lẹ̀ típẹ́típẹ́ mọ́ àpáta débi pé ìsẹ̀lẹ̀ nìkan ló lè mì wọ́n.
A fi àwọn olóòótọ́ ìránṣẹ́ Ọlọ́run wé igi nínú Bíbélì. (Sáàmù 1:1-3; Jeremáyà 17:7, 8) Ìpọ́njú lè dé bá àwọn náà nítorí ipò tí wọ́n bá ara wọn. Inúnibíni, àìlera, tàbí ipò òṣì tí ń fojú ẹni gbolẹ̀ lè dán ìgbàgbọ́ wọn wò gidigidi, àgàgà bí àwọn ìdánwò náà ò bá dẹwọ́ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ọdún. Síbẹ̀síbẹ̀, Ẹlẹ́dàá, tó dá àwọn igi tó ń dàgbà nínú ipò tí kò bára dé yìí, fi àwọn tó ń sìn ín lọ́kàn balẹ̀ pé òun á tì wọ́n lẹ́yìn. Bíbélì ṣèlérí fún àwọn tó bá dúró láìyẹsẹ̀ pé: “[Òun] yóò fìdí yín múlẹ̀ gbọn-in gbọn-in, yóò sì sọ yín di alágbára.”—1 Pétérù 5:9, 10.
‘Dídúró láìyẹsẹ̀, fífẹsẹ̀ múlẹ̀ ṣinṣin, tàbí pípa nǹkan mọ́ra’ ni ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ ìṣe Gíríìkì táa sábà máa ń tú sí “fara dà” nínú Bíbélì. Gẹ́gẹ́ bó ti rí pẹ̀lú àwọn igi orí àpáta gàǹgà, gbòǹgbò tó fẹsẹ̀ múlẹ̀ dáadáa ló ń jẹ́ kí wọ́n rọ́kú. Nínú ọ̀ràn tàwọn Kristẹni, wọ́n gbọ́dọ̀ fi gbòǹgbò múlẹ̀ nínú Jésù Kristi kí wọ́n lè dúró gbọn-in. Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Bí ẹ ti tẹ́wọ́ gba Kristi Jésù Olúwa, ẹ máa bá a lọ ní rírìn ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú rẹ̀, kí ẹ ta gbòǹgbò, kí a sì máa gbé yín ró nínú rẹ̀, kí ẹ sì fẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́, gan-an gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ yín, kí ẹ máa kún fún ìgbàgbọ́ ní àkúnwọ́sílẹ̀ nínú ìdúpẹ́.”—Kólósè 2:6, 7.
Pọ́ọ̀lù mọ ìjẹ́pàtàkì níní gbòǹgbò tẹ̀mí tó fẹsẹ̀ múlẹ̀. Òun alára ń bá ‘ẹ̀gún kan nínú ẹran ara’ rẹ̀ yí, ó sì fara da inúnibíni rírorò látìbẹ̀rẹ̀ dópin iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀. (2 Kọ́ríńtì 11:23-27; 12:7) Ṣùgbọ́n ó rí i pé òun lè forí tì í lágbára Ọlọ́run. Ó kéde pé: “Mo ní okun fún ohun gbogbo nípasẹ̀ agbára ìtóye ẹni tí ń fi agbára fún mi.”—Fílípì 4:13.
Gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ Pọ́ọ̀lù ti fi hàn, ìfaradà Kristẹni títí dé òpin kò sinmi lórí àwọn ipò tó rọgbọ. Gẹ́gẹ́ bí àwọn igi jẹ́gẹ́dẹ́ orí àpáta gàǹgà tí ń dàgbà nínú ipò tí kò bára dé fún ọ̀pọ̀ ọ̀rúndún, àwa náà lè dúró gbọn-in báa bá fi gbòǹgbò múlẹ̀ nínú Kristi, táa sì gbára lé agbára tí Ọlọ́run ń fi fúnni. Láfikún sí i, báa bá fara dà á títí dé òpin, a ní ìrètí pé ìmúṣẹ ìlérí Ọlọ́run yóò ṣojú wa, pé: “Bí ọjọ́ igi ni ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí.”—Aísáyà 65:22; Mátíù 24:13.