Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Ìmọ̀ Jèhófà

Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Ìmọ̀ Jèhófà

Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Ìmọ̀ Jèhófà

“Aláyọ̀ ni àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́!”—LÚÙKÙ 11:28.

1. Ìgbà wo ni Jèhófà bẹ̀rẹ̀ sí bá ẹ̀dá ènìyàn sọ̀rọ̀?

 JÈHÓFÀ nífẹ̀ẹ́ ìran ènìyàn, ire wọ́n sì jẹ ẹ́ lọ́kàn gan-an. Abájọ tó fi ń bá wọn sọ̀rọ̀. Ìbánisọ̀rọ̀ yìí bẹ̀rẹ̀ nínú ọgbà Édẹ́nì. Gẹ́gẹ́ bí Jẹ́nẹ́sísì 3:8 ti sọ, ní àkókò kan “ní nǹkan bí ìgbà tí atẹ́gùn máa ń fẹ́ yẹ́ẹ́ ní ọjọ́,” Ádámù àti Éfà “gbọ́ ohùn Jèhófà Ọlọ́run.” Àwọn kan sọ pé èyí fi hàn pé ó jẹ́ àṣà Jèhófà láti máa bá Ádámù sọ̀rọ̀ lákòókò yìí, bóyá lójoojúmọ́ pàápàá. Ohun yòówù kó jẹ́, Bíbélì mú un ṣe kedere pé yàtọ̀ sí pé Ọlọ́run fún ọkùnrin àkọ́kọ́ nítọ̀ọ́ni, ó tún kọ́ ọ ní ohun tó yẹ kó mọ̀ kó bàa lè ṣe ojúṣe rẹ̀.—Jẹ́nẹ́sísì 1:28-30.

2. Báwo ni tọkọtaya àkọ́kọ́ ṣe ya ara wọn kúrò lábẹ́ ìdarí Jèhófà, kí sì ni àbájáde rẹ̀?

2 Jèhófà fún Ádámù àti Éfà ní ìyè, ọlá àṣẹ lórí àwọn ẹranko àti lórí gbogbo ayé. Kìkì ohun kan ṣoṣo ló kà léèwọ̀ fún wọn—wọn ò gbọ́dọ̀ jẹ èso igi ìmọ̀ rere àti búburú. Sátánì sún Ádámù àti Éfà ṣàìgbọràn sí àṣẹ Ọlọ́run. (Jẹ́nẹ́sísì 2:16, 17; 3:1-6) Wọ́n yàn láti ṣe ohun tó wù wọ́n, wọ́n ń fúnra wọn pinnu ohun tí ó tọ́ àti ohun tí kò tọ́. Nípa ṣíṣe bẹ́ẹ̀, wọ́n fi ìwà òmùgọ̀ ya ara wọn kúrò lábẹ́ ìdarí Ẹlẹ́dàá wọn onífẹ̀ẹ́. Àbájáde rẹ̀ burú jáì fún àwọn fúnra wọn àti fún àtọmọdọ́mọ wọn tí wọn kò tíì bí. Ádámù àti Éfà darúgbó, ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀ wọ́n kú láìsí ìrètí àjíǹde. Àwọn àtọmọdọ́mọ wọn jogún ẹ̀ṣẹ̀ àti ikú tó jẹ́ àbájáde rẹ̀.—Róòmù 5:12.

3. Èé ṣe tí Jèhófà fi bá Kéènì sọ̀rọ̀, kí sì ni ìṣarasíhùwà Kéènì?

3 Láìka ìṣọ̀tẹ̀ tó wáyé ní Édẹ́nì sí, Jèhófà ń bá a lọ láti máa bá àwọn ẹ̀dá ènìyàn tó dá sọ̀rọ̀. Ìgbà kan wà tí ẹ̀ṣẹ̀ fẹ́ lé Kéènì, tó jẹ́ àkọ́bí Ádámù àti Éfà, bá. Jèhófà kìlọ̀ fún un pé wàhálà ló ń fà lẹ́sẹ̀ yẹn, ó sì gbà á nímọ̀ràn pé kó “yíjú sí ṣíṣe rere.” Kéènì kọ ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ yìí sílẹ̀, ó sì pa arákùnrin rẹ̀. (Jẹ́nẹ́sísì 4:3-8) Bí àwọn mẹ́tẹ̀ẹ̀ta tó kọ́kọ́ wà lórí ilẹ̀ ayé ṣe kọ ìtọ́sọ́nà tó ṣe kedere látọ̀dọ̀ ẹni tó fún wọn ní ìyè sílẹ̀ nìyẹn o, ìyẹn Ọlọ́run tó ń fún àwọn ènìyàn rẹ̀ nítọ̀ọ́ni kí wọ́n lè ṣe ara wọn láǹfààní. (Aísáyà 48:17) Á mà dun Jèhófà o!

Jèhófà Fara Rẹ̀ Han Àwọn Ọkùnrin Ìgbàanì

4. Kí ló dá Jèhófà lójú nípa àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù, ìhìn tó ń fúnni nírètí wo ló sì tìtorí ìyẹn fúnni?

4 Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jèhófà lẹ́tọ̀ọ́ láti pa àwọn èèyàn tì, kó má tiẹ̀ bá wọn sọ̀rọ̀ mọ́, síbẹ̀ kò ṣe bẹ́ẹ̀. Ó dá a lójú pé àwọn tó bá gbọ́n lára àwọn àtọmọdọ́mọ Ádámù yóò tẹ̀ lé ìmọ̀ràn Òun. Fún àpẹẹrẹ, nígbà tí Jèhófà ń dá Ádámù àti Éfà lẹ́jọ́, ó sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa dídé “irú ọmọ” kan tí yóò ko Ejò náà, Sátánì Èṣù, lójú. Níkẹyìn, a óò fọ́ orí Sátánì túútúú. (Jẹ́nẹ́sísì 3:15) Ìhìn ayọ̀ tó ń fúnni nírètí ni àsọtẹ́lẹ̀ yìí jẹ́ fún “àwọn tí ń gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, tí wọ́n sì ń pa á mọ́.”—Lúùkù 11:28.

5, 6. Àwọn ọ̀nà wo ni Jèhófà gbà bá àwọn ènìyàn rẹ̀ sọ̀rọ̀ ṣáájú ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, báwo sì lèyí ṣe ṣe wọ́n láǹfààní?

5 Jèhófà sọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ fún àwọn baba ńlá tí wọ́n jẹ́ olóòótọ́ láyé ọjọ́un, àwọn bíi Nóà, Ábúráhámù, Ísákì, Jékọ́bù, àti Jóòbù. (Jẹ́nẹ́sísì 6:13; Ẹ́kísódù 33:1; Jóòbù 38:1-3) Lẹ́yìn náà, ó tipasẹ̀ Mósè kọ àkójọ òfin kan fún orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì. Òfin Mósè náà ṣe wọ́n láǹfààní lọ́nà púpọ̀. Nípa pípa á mọ́, a ya Ísírẹ́lì sọ́tọ̀ kúrò lára gbogbo orílẹ̀-èdè yòókù, wọ́n sì di ènìyàn Ọlọ́run lákànṣe. Ọlọ́run mú un dá àwọn ọmọ Ísírẹ́lì lójú pé bí wọ́n bá ṣègbọràn sí Òfin náà, òun yóò bù kún wọn, kì í ṣe nípa tara nìkan, bí kò ṣe nípa tẹ̀mí pẹ̀lú, nípa fífi wọ́n ṣe ìjọba àwọn àlùfáà, orílẹ̀-èdè mímọ́. Òfin náà tiẹ̀ tún ní àwọn ìlànà nípa oúnjẹ jíjẹ àti ìmọ́tótó nínú, èyí tó lè ṣàlékún ìlera ara. Àmọ́, Jèhófà tún kìlọ̀ nípa àbájáde bíburú tí yóò tẹ̀yìn ṣíṣe àìgbọràn jáde.—Ẹ́kísódù 19:5, 6; Diutarónómì 28:1-68.

6 Bí àkókò ti ń lọ, a wá fi àwọn ìwé onímìísí mìíràn kún ìwé inú Bíbélì. Ìtàn sọ nípa bí Jèhófà ṣe bá àwọn orílẹ̀-èdè àtàwọn èèyàn lò. Àwọn ìwé ewì ṣàpèjúwe àwọn ànímọ́ rẹ̀ lọ́nà tó wúni lórí. Àwọn ìwé àsọtẹ́lẹ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí ìfẹ́ Jèhófà yóò ṣe di ṣíṣe. Àwọn ọkùnrin olóòótọ́ ìgbàanì fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ àwọn àkọsílẹ̀ onímìísí wọ̀nyí, wọ́n sì fi wọ́n sílò. Ọ̀kan kọ̀wé pé: “Ọ̀rọ̀ rẹ jẹ́ fìtílà fún ẹsẹ̀ mi, àti ìmọ́lẹ̀ sí òpópónà mi.” (Sáàmù 119:105) Jèhófà pèsè ẹ̀kọ́ àti ìlàlóye fáwọn tó múra tán láti fetí sílẹ̀.

Ìmọ́lẹ̀ Náà Túbọ̀ Mọ́lẹ̀ Sí I

7. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Jésù ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu, kí làwọn èèyàn máa ń pè é, kí sì nìdí?

7 Nígbà tó fi máa di ọ̀rúndún kìíní, àwùjọ àwọn onísìn Júù ti fi àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ ẹ̀dá ènìyàn kún Òfin náà. Wọ́n ṣi Òfin náà lò, dípò tí ì bá fi jẹ́ orísun ìlàlóye, ó di ẹrù ìnira nítorí àwọn àṣà àtọwọ́dọ́wọ́ wọ̀nyẹn. (Mátíù 23:2-4) Àmọ́, nígbà tó di ọdún 29 Sànmánì Tiwa, Jésù tó jẹ́ Mèsáyà náà dé. Kì í ṣe pé kí ó lè fi ìwàláàyè rẹ̀ rúbọ nítorí ìran ènìyàn nìkan ló ṣe wá, àmọ́ ó tún wá láti “jẹ́rìí sí òtítọ́.” Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ṣe àwọn iṣẹ́ ìyanu, ohun tí wọ́n mọ̀ ọ́n sí gan-an ni “Olùkọ́.” Ẹ̀kọ́ rẹ̀ dà bí ìmọ́lẹ̀ tó ń tàn sínú òkùnkùn tẹ̀mí tó bo èrò ọkàn àwọn èèyàn mọ́lẹ̀. Jésù fúnra rẹ̀ là á mọ́lẹ̀ pé: “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.”—Jòhánù 8:12; 11:28; 18:37.

8. Àwọn ìwé onímìísí wo la kọ ní ọ̀rúndún kìíní Sànmánì Tiwa, báwo ni wọ́n sì ṣe ṣàǹfààní fáwọn Kristẹni ìjímìjí?

8 Ẹ̀yìn ìyẹn la wá fi àwọn ìwé Ìhìn Rere kún un, mẹ́rin tó jẹ́ ìtàn nípa ìgbésí ayé Jésù, àti ìwé Ìṣe, tó jẹ́ ìtàn nípa bí ìsìn Kristẹni ṣe tàn kálẹ̀ lẹ́yìn ikú Jésù. Àwọn lẹ́tà onímìísí tí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù kọ tún wà, àti ìwé Ìṣípayá tó kún fún àsọtẹ́lẹ̀. Àwọn ìwé wọ̀nyí pa pọ̀ mọ́ Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù ló para pọ̀ jẹ́ odindi Bíbélì. Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àkójọ ìwé táa mí sí yìí, àwọn Kristẹni “pẹ̀lú gbogbo ẹni mímọ́ . . . lè fi èrò orí mòye ní kíkún ohun tí ìbú àti gígùn àti gíga àti jíjìn” òtítọ́ jẹ́. (Éfésù 3:14-18) Wọ́n sì lè ní “èrò inú ti Kristi.” (1 Kọ́ríńtì 2:16) Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ yẹn kò lóye gbogbo ète Jèhófà ní kíkún. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé sí àwọn onígbàgbọ́ ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ pé: “Nísinsìnyí àwa ń ríran nínú àwòrán fírífírí nípasẹ̀ dígí tí a fi irin ṣe.” (1 Kọ́ríńtì 13:12) Àwòrán irú dígí bẹ́ẹ̀ máa ń ṣe bàìbàì, kì í hàn ketekete. Lílóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní kíkún ṣì wà níwájú.

9. Ìlàlóye wo ló ti wáyé ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn”?

9 Lónìí, a ń gbé ní àkókò táa pè ní “àwọn ọjọ́ ìkẹyìn,” tó jẹ́ sáà “àwọn àkókò lílekoko tí ó nira láti bá lò.” (2 Tímótì 3:1) Wòlíì Dáníẹ́lì sọ àsọtẹ́lẹ̀ pé ní àkókò yìí, “ìmọ̀ tòótọ́ yóò . . . di púpọ̀ yanturu.” (Dáníẹ́lì 12:4) Nípa bẹ́ẹ̀, Jèhófà, Olùbánisọ̀rọ̀ Ńlá náà ti ran àwọn olóòótọ́ inú lọ́wọ́ láti lóye Ọ̀rọ̀ rẹ̀. Ògìdìgbó èèyàn ló ti wá mọ̀ báyìí pé a ti gbé Kristi Jésù gorí ìtẹ́ lájùlé ọ̀run láti ọdún 1914. Wọ́n tún mọ̀ pé láìpẹ́ yóò mú òpin bá gbogbo ìwà ibi, yóò sì sọ ayé yìí di Párádísè. Apá pàtàkì yìí nínú ìhìn rere Ìjọba náà la ń wàásù rẹ̀ jákèjádò ayé nísinsìnyí.—Mátíù 24:14.

10. Jálẹ̀ àwọn ọ̀rúndún, ojú wo làwọn èèyàn fi ń wo ìmọ̀ràn Jèhófà?

10 Bẹ́ẹ̀ ni o, jálẹ̀ ìtàn ni Jèhófà ti sọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ àti ète rẹ̀ fáwọn èèyàn orí ilẹ̀ ayé. Àkọsílẹ̀ Bíbélì ṣàpèjúwe ọ̀pọ̀ tó fetí sílẹ̀, tí wọ́n mú ọgbọ́n Ọlọ́run lò, táa sì tìtorí bẹ́ẹ̀ bù kún wọn. Ó sọ nípa àwọn mìíràn tí wọ́n kọ ìmọ̀ràn onífẹ̀ẹ́ látọ̀dọ̀ Ọlọ́run sílẹ̀, tí wọ́n tẹ̀ lé ipa ọ̀nà ìparun tí Ádámù àti Éfà tọ̀. Jésù ṣàpèjúwe ipò yìí nígbà tó sọ̀rọ̀ nípa ọ̀nà ìṣàpẹẹrẹ méjì. Ọ̀kan lọ sí ìparun. Ìyẹn ni ọ̀nà fífẹ̀ tó sì láyè gbígbòòrò tí ọ̀pọ̀lọpọ̀ tó kọ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ń tọ̀. Ọ̀nà kejì lọ sí ìyè àìnípẹ̀kun. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó há, òun ni ọ̀nà tí àwọn kéréje tó tẹ́wọ́ gba Bíbélì pé ó jẹ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run tí wọ́n sì ń gbé níbàámu pẹ̀lú rẹ̀ ń tọ̀.—Mátíù 7:13, 14.

Mímọyì Ohun Táa Ní

11. Ìmọ̀ àti ìgbàgbọ́ tí a ní nínú Bíbélì jẹ́ ẹ̀rí kì ni?

11 Ǹjẹ́ o wà lára àwọn tó ti yan ọ̀nà tó lọ sí ìyè? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, ó dájú pé wàá fẹ́ máa tọ ọ̀nà yẹn nìṣó. Báwo lo ṣe máa ṣe èyí? Máa ṣàṣàrò déédéé, kóo sì máa fi ìmọrírì hàn fún àwọn ìbùkún tí òtítọ́ Bíbélì tóo mọ̀ ti mú wá sínú ìgbésí ayé rẹ. Pé o tiẹ̀ tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà jẹ́ ẹ̀rí pé Ọlọ́run ń bù kún ọ. Jésù fi èyí hàn nígbà tó gbàdúrà sí Baba rẹ̀ báyìí pé: “Mo yìn ọ́ ní gbangba, Baba, Olúwa ọ̀run àti ilẹ̀ ayé, nítorí pé ìwọ ti fi nǹkan wọ̀nyí pa mọ́ kúrò lọ́dọ̀ àwọn ọlọ́gbọ́n àti àwọn amòye, o sì ti ṣí wọn payá fún àwọn ìkókó.” (Mátíù 11:25) Àwọn apẹja àtàwọn agbowó orí lóye ẹ̀kọ́ Jésù, níbi táwọn aṣáájú ìsìn kò ti lóye rẹ̀. Jésù tún sọ síwájú sí i pé: “Kò sí ènìyàn kankan tí ó lè wá sọ́dọ̀ mi láìjẹ́ pé Baba, tí ó rán mi, fà á.” (Jòhánù 6:44) Bóo bá ti mọ Bíbélì, tóo gba ẹ̀kọ́ rẹ̀ gbọ́, tóo sì ń tẹ̀ lé e, èyí jẹ́ ẹ̀rí kedere pé Jèhófà ti fà ọ́. Ohun ayọ̀ lèyí.

12. Àwọn ọ̀nà wo ni Bíbélì gbà ń lani lóye?

12 Òtítọ́ ti ń sọni dòmìnira tó sì ń lani lóye wà nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Àwọn tó ń gbé níbàámu pẹ̀lú ìmọ̀ Bíbélì bọ́ lọ́wọ́ ìgbàgbọ́ nínú ohun asán, ẹ̀kọ́ èké, àti àìmọ̀kan tó jọba lórí ìgbésí ayé ọ̀kẹ́ àìmọye ènìyàn. Fún àpẹẹrẹ, mímọ òtítọ́ nípa ọkàn sọ wá dòmìnira kúrò nínú ẹ̀rù pé àwọn òkú lè pa wá lára tàbí ká máa bẹ̀rù pé àwọn olólùfẹ́ wa tó ti kú ń jìyà. (Ìsíkíẹ́lì 18:4) Mímọ òtítọ́ nípa àwọn áńgẹ́lì burúkú ń ràn wá lọ́wọ́ láti yẹra fún ewu ìbẹ́mìílò. Ẹ̀kọ́ àjíǹde jẹ́ ìtùnú fáwọn tó ti pàdánù àwọn olólùfẹ́ wọn nínú ikú. (Jòhánù 11:25) Àwọn àsọtẹ́lẹ̀ Bíbélì ń jẹ́ ká mọ ibi tí ọjọ́ ti dé, ó sì ń fi wá lọ́kàn balẹ̀ nípa àwọn ìlérí Ọlọ́run fún ọjọ́ iwájú. Wọ́n tún ń fún ìrètí táa ní láti wà láàyè títí láé lókun.

13. Báwo ni pípa Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run mọ́ ṣe ń ṣe ara wa láǹfààní?

13 Àwọn ìlànà Ọlọ́run tó wà nínú Bíbélì ń kọ́ wa láti máa gbé lọ́nà tó máa ṣe wá láǹfààní nípa tara. Fún àpẹẹrẹ, a máa ń yẹra fún àwọn àṣà tó ń sọ ara wa di ẹlẹ́gbin, irú bíi lílo tábà àti àwọn oògùn mìíràn nílòkulò. A ń sá fún mímu ọtí líle lámujù. (2 Kọ́ríńtì 7:1) Ṣíṣègbọràn sí àwọn òfin Ọlọ́run lórí ọ̀ràn ìwà rere ń dáàbò bò wá lọ́wọ́ àwọn àrùn tí ìbálòpọ̀ ń ta àtaré rẹ̀. (1 Kọ́ríńtì 6:18) Nípa títẹ̀lé ìmọ̀ràn Ọlọ́run tó sọ pé ká yẹra fún ìfẹ́ owó, a ò ní gbéra wa lọ́kàn sókè, bí ọ̀pọ̀ èèyàn ti ń ṣe, níbi tí wọ́n ti ń lépa àtidi ọlọ́rọ̀. (1 Tímótì 6:10) Àwọn ọ̀nà wo lo ti jàǹfààní nípa tara nítorí pé ó fi Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run sílò nínú ìgbésí ayé rẹ?

14. Ipa wo ni ẹ̀mí mímọ́ ń ní lórí ìgbésí ayé wa?

14 Bí a bá ń gbé níbàámu pẹ̀lú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, a óò máa rí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà gbà. A óò máa mú ìwà bíi ti Kristi dàgbà, èyí tí àwọn ànímọ́ rere bí àánú àti ìyọ́nú jẹ́ apá pàtàkì rẹ̀. (Éfésù 4:24, 32) Ẹ̀mí Ọlọ́run tún ń fi àwọn èso rẹ̀ hàn lára wa—ìfẹ́, ìdùnnú, àlàáfíà, ìpamọ́ra, inú rere, ìwà rere, ìgbàgbọ́, ìwà tútù, ìkóra-ẹni-níjàánu. (Gálátíà 5:22, 23) Àwọn ànímọ́ wọ̀nyí ń jẹ́ ká ní ayọ̀ àti àjọṣe tó gbámúṣé pẹ̀lú àwọn ẹlòmíràn títí kan àwọn mẹ́ńbà ìdílé wa. A ń jèrè okun inú tó ń ràn wá lọ́wọ́ láti fìgboyà kojú ìṣòro. Ǹjẹ́ o ń ṣàkíyèsí bí ẹ̀mí mímọ́ ti ṣe mú kí ìgbésí ayé rẹ túbọ̀ sunwọ̀n sí i?

15. Báa ṣe ń mú ìgbésí ayé wa bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, àǹfààní wo là ń jẹ?

15 Bí a bá mú kí ìgbésí ayé wa bá ìfẹ́ Ọlọ́run mu, a jẹ́ pé a ń fún àjọṣe wa pẹ̀lú Jèhófà lókun nìyẹn. Ọkàn wa sì túbọ̀ balẹ̀ pé ó lóye wa, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa pẹ̀lú. Ìrírí ti jẹ́ ká mọ̀ pé ó ń tì wá lẹ́yìn láwọn àkókò ìṣòro. (Sáàmù 18:18) A mọ̀ pé ó ń gbọ́ àwọn àdúrà wa ní tòótọ́. (Sáàmù 65:2) A wá gbára lé ìtọ́ni rẹ̀, nítorí a mọ̀ dájú pé ìtọ́ni rẹ̀ yóò ṣe wá láǹfààní. A sì ní àgbàyanu ìrètí náà pé bí àkókò bá tó, Ọlọ́run yóò mú àwọn olóòótọ́ wá sí ìjẹ́pípé, yóò si fi ẹ̀bùn ìyè àìnípẹ̀kun jíǹkí wọn. (Róòmù 6:23) Ọmọ ẹ̀yìn náà Jákọ́bù kọ̀wé pé: “Ẹ sún mọ́ Ọlọ́run, yóò sì sún mọ́ yín.” (Jákọ́bù 4:8) Ǹjẹ́ o ti rí i pé àjọṣe tóo ní pẹ̀lú Jèhófà ti lágbára sí i bí o ṣe ń sún mọ́ ọn?

Ìṣúra Tí Kò Láfiwé

16. Àwọn ìyípadà wo làwọn Kristẹni kan ṣe ní ọ̀rúndún kìíní?

16 Pọ́ọ̀lù rán àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró ọ̀rúndún kìíní létí pé àwọn kan lára wọn ti fìgbà kan jẹ́ àgbèrè, panṣágà, ọkùnrin tí ń bá ọkùnrin dà pọ̀, olè, oníwọra, ọ̀mùtípara, olùkẹ́gàn, àti alọ́nilọ́wọ́gbà. (1 Kọ́ríńtì 6:9-11) Òtítọ́ Bíbélì jẹ́ kí wọ́n ṣe ìyípadà ńláǹlà; a ‘wẹ̀ wọ́n mọ́.’ Fojú inú wo bí ìgbésí ayé rẹ ì bá ti rí láìsí òtítọ́ tó ń sọni dòmìnira tóo kọ́ nínú Bíbélì. Dájúdájú, òtítọ́ jẹ́ ìṣúra tí kò láfiwé. Inú wa mà dùn o, pé Jèhófà ń bá wa sọ̀rọ̀!

17. Báwo la ṣe bọ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà yó nípa tẹ̀mí láwọn ìpàdé Kristẹni?

17 Síwájú sí i, ronú nípa ìbùkún táa ní nínú ẹgbẹ́ àwọn ará tó kún fún onírúurú ẹ̀yà! “Ẹrú olóòótọ́ àti olóye” ń pèsè oúnjẹ tẹ̀mí ní àkókò yíyẹ, títí kan àwọn Bíbélì, àwọn ìwé ìròyìn, àtàwọn ìtẹ̀jáde mìíràn ní ọ̀pọ̀ èdè. (Mátíù 24:45-47) Láwọn ìpàdé ìjọ táa ṣe láàárín ọdún 2000, àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní ọ̀pọ̀ ilẹ̀ ṣàgbéyẹ̀wò àwọn kókó pàtàkì látinú àwọn ìwé ńláńlá mẹ́jọ nínú Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù. Wọ́n ṣàṣàrò lórí ìgbésí ayé ogójì ènìyàn lára àwọn ẹni ìtàn inú Bíbélì táa jíròrò nípa wọn nínú ìwé Insight on the Scriptures. Wọ́n gbé nǹkan bí ìdámẹ́rin ìwé Ọkunrin Titobilọla Julọ Ti O Tii Gbé Ayé Rí yẹ̀ wò, wọ́n sì fẹ́rẹ̀ẹ́ ka ìwé Kíyè sí Àsọtẹ́lẹ̀ Dáníẹ́lì! tán lọ́dún yẹn. Àwọn àpilẹ̀kọ bíi mẹ́rìndínlógójì ni wọ́n gbé yẹ̀ wò látinú ìwé ìròyìn Ilé Ìṣọ́ láfikún sí àpilẹ̀kọ fún ìkẹ́kọ̀ọ́ méjìléláàádọ́ta tó wà níbẹ̀. Láfikún sí i, a fi àwọn ẹ̀dà méjìlá Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Ìjọba Wa àti àwọn àsọyé ọ̀sọ̀ọ̀sẹ̀ fún gbogbo èèyàn lórí onírúurú àwọn kókó inú Bíbélì bọ́ àwọn ènìyàn Jèhófà ní àbọ́yó. Ìmọ̀ tẹ̀mí tí à ń rí gbà mà kúkú pọ̀ jaburata o!

18. Àwọn ọ̀nà wo la ti ń rí ìrànlọ́wọ́ gbà nínú ìjọ Kristẹni?

18 Jákèjádò ayé ni àwọn ìjọ tó lé ní ẹgbẹ̀rún lọ́nà mọ́kànléláàádọ́rùn-ún ti ń pèsè ìtìlẹ́yìn àti ìṣírí nípasẹ̀ àwọn ìpàdé àti ìbákẹ́gbẹ́pọ̀ tó lárinrin. A tún ń gbádùn ìtìlẹ́yìn àwọn Kristẹni ẹlẹgbẹ́ wa tó dàgbà dénú, àwọn tó múra tán láti ràn wá lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí. (Éfésù 4:11-13) Dájúdájú, a ti jàǹfààní lọ́pọ̀lọpọ̀ nípa gbígba ìmọ̀ òtítọ́. Ayọ̀ ńlá ló jẹ́ láti mọ Jèhófà ká sì máa sìn ín. Ẹ ò rí i pé òótọ́ ni ọ̀rọ̀ onísáàmù tó kọ̀wé pé: “Aláyọ̀ ni àwọn ènìyàn tí Jèhófà jẹ́ Ọlọ́run wọn!”—Sáàmù 144:15.

Ǹjẹ́ O Rántí?

• Àwọn wo ni Jèhófà bá sọ̀rọ̀ kí ẹ̀sìn Kristẹni tóo dé?

• Báwo ni ìmọ́lẹ̀ tẹ̀mí ṣe túbọ̀ mọ́lẹ̀ sí i ní ọ̀rúndún kìíní? Lóde òní náà ńkọ́?

• Àwọn ìbùkún wo ló ń wá látinú gbígbé níbàámu pẹ̀lú ìmọ̀ Jèhófà?

• Èé ṣe táa fi ń yọ̀ pé a ní ìmọ̀ Ọlọ́run?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 8, 9]

Jèhófà sọ ohun tó jẹ́ ìfẹ́ rẹ̀ fún Mósè, Nóà, àti Ábúráhámù

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 9]

Ní ọjọ́ wa, Jèhófà ti tan ìmọ́lẹ̀ sórí Ọ̀rọ̀ rẹ̀

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 10]

Ronú nípa ìbùkún táa ní nínú ẹgbẹ́ àwọn ará tó kún fún onírúurú ẹ̀yà!