Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Dán Jèhófà Wò

A Dán Jèhófà Wò

Ìtàn Ìgbésí Ayé

A Dán Jèhófà Wò

GẸ́GẸ́ BÍ PAUL SCRIBNER ṢE SỌ Ọ́

“Ẹ káàárọ̀ o, Ìyáàfin Stackhouse. Mo ní kí n wá béèrè iye kéèkì tí àwọn èèyàn máa fẹ́ kí n bá àwọn gbà wá fún Ọdún Àjíǹde ni o, ó sì dá mi lójú pé ẹ̀yin náà á fẹ́ kí n bá ìdílé yín gba kéèkì.” Ìyẹn wáyé lọ́dún 1938, nígbà táa ṣẹ̀ṣẹ̀ ń wọ ìgbà ìrúwé. Mo wà nílùú Atco, ní Ìpínlẹ̀ New Jersey, ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà nígbà yẹn. Ọ̀kan lára àwọn oníbàárà mi àtàtà tí mo sábà máa ń gbé ọjà wá fún láti iléeṣẹ́ General Baking Company sì ni mò ń bá sọ̀rọ̀. Ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ fún mi pé Ìyáàfin Stackhouse sọ pé rárá.

Ó NÍ: “Mi ò fẹ́. A kì í ṣọdún Àjíǹde.”

Ọkàn mi kàn dà rú ni. Wọn kì í ṣọdún Àjíǹde kẹ̀? Bó ti wù kó rí, òfin kìíní nínú ọjà títà ni pé a kì í bá oníbàárà jiyàn. Kí ni kí n wá ṣe báyìí o? Mo wá mọ́kàn, mo ní: “Tóò, kéèkì ọ̀hún dáa gan-an o, mo sì mọ̀ pé ẹ máa ń gbádùn kéèkì wa. Bí ẹ kì í tilẹ̀ẹ́ ṣe, ẹm-ẹm, Ọdún Àjíǹde, ṣé ẹ ò rò pé ìdílé yín máa gbádùn ẹ̀ ni?”

Ó fèsì pé: “Mi ò rò bẹ́ẹ̀. Ọ̀rọ̀ kan tiẹ̀ wà tí mo ti fẹ́ bá yín sọ tipẹ́, Ọ̀gbẹ́ni Scribner, ó sì jọ pé àkókò tó máa dáa jù láti sọ ọ́ rèé.” Ìjíròrò tó máa yí ìgbésí ayé mi padà pátápátá nìyẹn o! Ìyáàfin Stackhouse tó jẹ́ mẹ́ńbà Ẹgbẹ́ (ìyẹn, ìjọ) Berlin, New Jersey, ti àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà, ṣàlàyé ibi tí ọdún Àjíǹde ti wá, ó sì fún mi ní ìwé pẹlẹbẹ mẹ́ta. Àkọlé wọn ni Ãbò, Àṣíri Tú, àti Protection. Mo kó àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà dání lọ sílé, mo fẹ́ mọ fìn-ín ìdí kókó, àmọ́ àyà mi ń já díẹ̀díẹ̀. Ó jọ pé mo ti gbọ́ ohun tí Ìyáàfin Stackhouse sọ yìí rí, bí ẹni pé mo gbọ́ ọ nígbà tí mo wà ní kékeré.

Ìgbà Tí Mo Kọ́kọ́ Bá Àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Pàdé

January 31, 1907 la bí mi. Àrùn jẹjẹrẹ pa bàbá mi ní 1915, nígbà tí mo ṣì jẹ́ ọmọ ọdún mẹ́jọ. Ìdí nìyẹn témi àti màmá mi fi lọ ń gbé lọ́dọ̀ àwọn òbí rẹ̀ nínú ilé ńlá kan ní Malden, Massachusetts. Ọ̀gbẹ́ni Benjamin Ransom, tó jẹ́ iyèkan màmá mi, àti ìyàwó rẹ̀ ń gbé níbẹ̀ pẹ̀lú, ní àjà kẹta. Kí ọ̀rúndún ogún tó bẹ̀rẹ̀ ni Ọ̀gbẹ́ni Ben ti ń dara pọ̀ mọ́ àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kárí Ayé, ìyẹn orúkọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà nígbà yẹn. Mo fẹ́ràn Ọ̀gbẹ́ni Ben gan-an ni, ṣùgbọ́n gbogbo ìdílé màmá mi, tí wọ́n jẹ́ Mẹ́tọ́díìsì, ló gbà pé nǹkan kan ń ṣe ọkùnrin yìí. Ní ọ̀pọ̀ ọdún lẹ́yìn náà, kí ìyàwó rẹ̀ tó kọ̀ ọ́ sílẹ̀, ìyàwó ọ̀hún rí sí i pé ó ṣe ọjọ́ mélòó kan ní ibi tí wọ́n ti ń wo wèrè, nítorí ọ̀ràn ẹ̀sìn yìí náà ni! Níwọ̀n bí àwọn dókítà tó wà ní ọsibítù náà ti tètè rí i pé ọpọlọ Ọ̀gbẹ́ni Ben pé pérépéré, wọ́n tú u sílẹ̀, tí wọ́n sì tọrọ àforíjì.

Ọ̀gbẹ́ni Ben máa ń mú mi dání lọ sípàdé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì Kárí Ayé ní Boston, àgàgà nígbà tí wọ́n bá ní alásọyé láti ibòmíì tàbí nígbà tí wọ́n bá fẹ́ ṣe nǹkan pàtàkì. Nígbà kan, Charles Taze Russell kan náà táa mọ̀ bí ẹní mowó, tó ń bójú tó iṣẹ́ ìwàásù ní ọjọ́ wọnnì, lẹni tó wá sọ àsọyé. Ní àkókò míì, ìṣẹ̀lẹ̀ pàtàkì tó wáyé ni ìgbà táa lọ wo “Photo-Drama of Creation [Àwòkẹ́kọ̀ọ́ Onífọ́tò Nípa Ìṣẹ̀dá].” Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọdún 1915 lọ́hùn-ún lọ́hùn-ún ni, títí di bí mo ṣe ń wí yìí, mo ṣì rántí dáadáa pé mo rí àwòrán ìgbà tí Ábúráhámù ń mú Ísákì lọ sórí òkè láti lọ fi í rúbọ. (Jẹ́nẹ́sísì, orí 22) Mo ṣì ń wo Ábúráhámù báyìí, àti Ísákì, bó ti ń mí hẹlẹhẹlẹ nígbà tó ń gun òkè yẹn, tòun ti ẹ̀rù igi lórí, tí Ábúráhámù sì gbé gbogbo ọkàn rẹ̀ lé Jèhófà. Níwọ̀n bí mo ti jẹ́ aláìníbaba, ibẹ̀ yẹn wọ̀ mí lọ́kàn gan-an.

Ẹ̀yìn ìgbà yẹn ni Ọ̀gbẹ́ni Ben àti ìyàwó rẹ̀ ṣí lọ sí Maine, màmá mi lọ fẹ́ ọkọ míì, a sì ṣí lọ sí New Jersey. Bí èmi àti Ọ̀gbẹ́ni Ben ò ṣe ríra mọ́ fúngbà pípẹ́ nìyẹn o. Nígbà tí mo ṣì jẹ́ ọ̀dọ́langba ní New Jersey, mo bá Marion Neff pàdé, ọ̀kan lára ọmọ mẹ́jọ nínú ìdílé ẹlẹ́sìn Presbyterian tí mo fẹ́ràn lílọ sílé wọn. Mo sábà máa ń wà pẹ̀lú ìdílé yẹn àti ẹgbẹ́ ọ̀dọ́ ìjọ wọn ní alaalẹ́ Sunday, nígbà tó sì yá, èmi alára di ẹlẹ́sìn Presbyterian. Ṣùgbọ́n, àwọn ohun tí mo kọ́ ní ìpàdé àwọn Akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kò kúrò lọ́kàn mi. Èmi àti Marion ṣègbéyàwó lọ́dún 1928, a sì bí Doris àti Louise, àwọn ọmọbìnrin wa, ní 1935 àti 1938. Nísinsìnyí táa ti ní ọmọ àfànítẹ̀tẹ́ àti ọmọ ọwọ́ jòjòló nínú ìdílé wa, àwa méjèèjì bẹ̀rẹ̀ sí rí i pé a nílò ìtọ́ni tẹ̀mí láti lè gbé ìdílé wa ró.

A Rí Òtítọ́ Nínú Ìwé Pẹlẹbẹ Wọ̀nyẹn

Èmi àti Marion ń wá ṣọ́ọ̀ṣì tí a óò máa lọ, a sì wá wéwèé nǹkan kan. A ṣètò pé bí ọ̀kan lára wa bá lọ ṣèbẹ̀wò sí ṣọ́ọ̀ṣì kan lọ́jọ́ Sunday yìí, ẹnì kejì á jókòó ti àwọn ọmọ. Lọ́jọ́ Sunday kan tó kan Marion láti jókòó sílé, mo sọ fún un pé kó máa lọ, màá bá a jókòó ti àwọn ọmọ. Ohun tó ṣẹlẹ̀ ni pé mo fẹ́ ráyè ka ìwé pẹlẹbẹ náà Ãbò, èyí àkọ́kọ́ lára ìwé mẹ́ta tí Ìyáàfin Stackhouse fún mi. Bí mo ṣe bẹ̀rẹ̀ sí kà á báyìí, kò mà ṣeé gbé jùúlẹ̀ mọ́! Ó wá túbọ̀ dá mi lójú dáadáa pé mo ti rí ohun tí mi ò lè rí nínú ṣọ́ọ̀ṣì kankan. Ohun kan náà ló ṣẹlẹ̀ lọ́sẹ̀ tó tẹ̀ lé e, mo gbà láti jókòó ti àwọn ọmọ kí n lè ráyè ka ìwé pẹlẹbẹ kejì náà, Àṣíri Tú. Ó wá jọ pé mo ti gbọ́ ohun tí mo ń kà yìí rí. Ṣé kì í ṣe ohun tí Ọ̀gbẹ́ni Ben gbà gbọ́ nìyí? Àwọn ẹbí wa sọ pé ẹ̀sìn àwọn ayírí lẹ̀sìn rẹ̀. Kí ni Marion máa sọ báyìí o? N bá mọ̀ kí n má da ara mi láàmú. Nígbà tí mo tibi iṣẹ́ dé lọ́jọ́ mélòó kan lẹ́yìn tí mo ka Àṣíri Tú, ìyàlẹ́nu gbáà ló jẹ́ nígbà tí Marion sọ fún mi pé, “Mo ti ka ìwé pẹlẹbẹ tóo kó wálé wọ̀nyẹn. Mo gbádùn wọn gan-an.” Ìgbà yẹn lọkàn mi ṣẹ̀ṣẹ̀ balẹ̀!

Lára èèpo ẹ̀yìn àwọn ìwé pẹlẹbẹ náà, a rí ìsọfúnni nípa ìwé kan tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ mú jáde, tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Awọn Ọta, inú rẹ̀ ni wọ́n ti tú àṣírí ẹ̀sìn èké pátápátá. A pinnu pé a óò wá ìwé yẹn kàn. Àmọ́ kó tó di pé a kọ̀wé láti béèrè fún un, Ẹlẹ́rìí kan kanlẹ̀kùn wa, ó sì fún wa ní ìwé ọ̀hún. Ó tán o! A jáwọ́ nínú bíbẹ àwọn ṣọ́ọ̀ṣì wò, a sì bẹ̀rẹ̀ sí lọ sípàdé ní Ìjọ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà tó wà ní Camden, New Jersey. Ní kìkì oṣù díẹ̀ lẹ́yìn náà, lọ́jọ́ Sunday ní July 31, 1938, àwa bí àádọ́ta pàdé ní ẹ̀yìnkùlé Arábìnrin Stackhouse—ní ilé tí mo ti fẹ́ wá ta kéèkì Ọdún Àjíǹde ní ọjọ́un àná—a sì gbọ́ àsọyé lórí ìrìbọmi tí wọ́n ti gba ohùn rẹ̀ sílẹ̀ lẹ́nu Judge Rutherford. Lẹ́yìn náà la wá pààrọ̀ aṣọ nínú ilé náà, mọ́kàndínlógún lára wa sì ṣèrìbọmi nínú odò kan tó wà nítòsí.

Ìpinnu Mi Ni Láti Jẹ́ Aṣáájú Ọ̀nà

Láìpẹ́ lẹ́yìn tí mo ṣèrìbọmi, arábìnrin kan nínú ìjọ sọ fún mi nípa àwọn tí wọ́n ń pè ní aṣáájú ọ̀nà, tó jẹ́ pé iṣẹ́ òjíṣẹ́ fún gbogbo èèyàn ni olórí iṣẹ́ wọn. Ojú ẹsẹ̀ ni mo fẹ́ mọ púpọ̀ sí i nípa rẹ̀, kò sì pẹ́ tí mo wá mọ odindi ìdílé kan tó jẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Arákùnrin àgbàlagbà kan, tó ń jẹ́ Konig, àtìyàwó rẹ̀, àti ọmọbìnrin rẹ̀ tó ti dàgbà, gbogbo wọn ló ń ṣe aṣáájú ọ̀nà nínú ìjọ kan nítòsí wa. Gẹ́gẹ́ bíi bàbá tó ṣẹ̀ṣẹ̀ di onídìílé, ayọ̀ jíjinlẹ̀ tí ìdílé Konig ní nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà wú mi lórí gan-an. Mo máa ń gbé ọkọ̀ tí mo fi ń ta kéèkì yà sọ́dọ̀ wọn, tí màá sì bá wọn kópa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé. Kò pẹ́ tí èmi náà fi fẹ́ di aṣáájú ọ̀nà. Ṣùgbọ́n báwo? Èmi àti Marion ní ọmọ wẹ́wẹ́ méjì, iṣẹ́ mi sì ń mu mí lómi. Àní, bí Ogun Àgbáyé Kejì ṣe bẹ̀rẹ̀ ní Yúróòpù, tí àwọn ọ̀dọ́kùnrin púpọ̀ sí i ń wọṣẹ́ ológun ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, ńṣe ni iṣẹ́ túbọ̀ ń wọ àwa táa ṣẹ́ kù sẹ́nu iṣẹ́ tí kì í ṣe ti ológun lọ́rùn. Wọ́n tún wá sọ pé kí n fi kún iye àwọn oníbàárà tí mo ń gbé ọjà lọ sọ́dọ̀ wọn, mo sì mọ̀ pé mi ò lè ṣe aṣáájú ọ̀nà láé bíṣẹ́ yẹn bá ń bá a lọ bẹ́ẹ̀.

Nígbà tí mo sọ fún Arákùnrin Konig pé mo fẹ́ ṣe aṣáájú ọ̀nà, ó sọ pé: “Sáà máa ṣiṣẹ́ kára nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà, kí o sì máa sọ ohun tí ò ń lépa fún un nínú àdúrà. Yóò ṣọ̀nà bí ọwọ́ rẹ yóò ṣe tẹ̀ ẹ́.” Ó lé ní ọdún kan tí mo fi ń ṣe bẹ́ẹ̀ gẹ́lẹ́. Mo máa ń ronú nígbà gbogbo lórí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bíi Mátíù 6:8, tó mú un dá wa lójú pé Jèhófà mọ àwọn ohun táa nílò kí a tó béèrè lọ́wọ́ rẹ̀ rárá. Mo sì ń gbìyànjú láti tẹ̀ lé ìmọ̀ràn tó wà nínú Mátíù 6:33, láti máa wá Ìjọba Ọlọ́run àti òdodo rẹ̀ lákọ̀ọ́kọ́. Arákùnrin Melvin Winchester, tó jẹ́ alábòójútó àyíká, tún fún mi níṣìírí.

Mo bá Marion sọ̀rọ̀ nípa ohun tí mò ń lépa. A jùmọ̀ sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọ̀rọ̀ inú Málákì 3:10, tó rọ̀ wá pé ká dán Jèhófà wò, kí a sì wò ó bóyá kò ní tú ìbùkún dà sórí wa. Èsì Marion wú mi lórí gan-an, ó ní: “Bóo bá fẹ́ ṣe aṣáájú ọ̀nà, má tìtorí tèmi fà sẹ́yìn o. Mo lè tọ́jú àwọn ọmọ wa bí o bá ṣe ń ṣe aṣáájú ọ̀nà. A ò kúkú nílò ohun púpọ̀ nípa tara.” Lẹ́yìn ọdún méjìlá táa ti ṣègbéyàwó, mo mọ̀ pé ìyàwó ilé tó ń ṣún nǹkan lò, tó sì ń lo ìṣọ́ra gidigidi ni Marion. Láti gbogbo ọdún wọ̀nyí wá, ó ti jẹ́ ẹnì kejì rere nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Ọ̀kan lára ìdí tó sì fi ṣeé ṣe fún wa láti máa bá a lọ nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún fún nǹkan bí ọgọ́ta ọdún báyìí jẹ́ nítorí pé nǹkan tara díẹ̀ táa ní ti tẹ́ ẹ lọ́rùn.

Nígbà tó fi máa di ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn ọdún 1941, lẹ́yìn ọ̀pọ̀lọpọ̀ oṣù àdúrà àti ìwéwèé, èmi àti Marion ti ní owó díẹ̀ nípamọ́, a sì ra ọkọ̀ àfiṣelé kan tó gùn ní mítà márùn-ún ààbọ̀, èyí tí ìdílé wa yóò máa gbé inú rẹ̀. Mo fi iṣẹ́ mi sílẹ̀, mo sì di aṣáájú ọ̀nà déédéé ní July 1941, mo sì ti wà nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún látìgbà yẹn. Ibi táa kọ́kọ́ yàn fún mi pé kí n ti ṣiṣẹ́ ni ibùdókọ̀ mẹ́wàá lójú ọ̀nà Route 50 láti New Jersey sí St. Louis, Missouri, níbi tí a ó ti ṣe àpéjọpọ̀ lọ́dún yẹn níbẹ̀rẹ̀ oṣù August. Wọ́n fi orúkọ àti àdírẹ́sì àwọn ará tó wà lágbègbè yẹn ránṣẹ́ sí mi, mo sì kọ̀wé sí wọn pé kí wọ́n máa retí mi nígbà báyìí-báyìí. Nígbà táa bá dé àpéjọpọ̀ náà, màá wá ẹ̀ka iṣẹ́ tí ń bójú tó iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà kàn, wọ́n á sì yàn mí sí ibòmíì.

‘Mo Fẹ́ Dán Jèhófà Wò’

A kó ìwé kún inú ọkọ̀ àfiṣelé wa kékeré, a sì bá àwọn ará ní Camden ṣe ìpàdé àṣegbẹ̀yìn, a sì kí wọ́n pé ó dìgbóṣe. Pẹ̀lú àwọn ọmọbìnrin kékeré méjì táà ń tọ́ lọ́wọ́, láìní ibì kan pàtó lọ́kàn táa fẹ́ forí lé lẹ́yìn àpéjọpọ̀ náà, gbogbo ìwéwèé wa kò ṣàì dà bí ohun tí kò mọ́gbọ́n dání lójú àwọn kan nínú àwọn ará. Mélòó kan nínú wọn tiẹ̀ sọ pé: “Ẹ ò ní pẹ́ padà.” Mo rántí pé mo sọ pé: “Hẹn, mi ò fẹ̀ẹ̀kàn sọ pé a ò ní padà. Jèhófà sọ pé òun á tọ́jú mi, mo sì fẹ́ dán Jèhófà wò.”

Lẹ́yìn ọgọ́ta ọdún lẹ́nu iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní ogún ìlú láti Massachusetts sí Mississippi, a lè sọ pé Jèhófà ti ṣe ju ohun tó ṣèlérí. Òjò ìbùkún tó ti rọ̀ sórí èmi àti Marion, àtàwọn ọmọbìnrin wa méjèèjì, ti pọ̀ gidigidi ré kọjá ohun tí mo fojú sí nígbà yẹn lọ́hùn-ún ní 1941. Ara ìbùkún náà ni pé àwọn ọmọbìnrin wa ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà olóòótọ́ ní àwọn ìjọ tó wà nítòsí, (nígbà táa sì kà á gbẹ̀yìn) a ti ní nǹkan bí ọgọ́rùn-ún ọmọ tẹ̀mí ní gbogbo Etíkun Ìlà Oòrùn Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà. Lára àwọn tí mo bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́, méjìléláàádọ́ta ló ti ya ìgbésí ayé wọn sí mímọ́ fún Jèhófà Ọlọ́run, méjìdínláàádọ́ta sì ti ṣe bẹ́ẹ̀ lára àwọn tí Marion ti bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́.

Ní August 1941, a dé sí St. Louis, ibẹ̀ ni mo sì ti pàdé Arákùnrin T. J. Sullivan tó wá láti Bẹ́tẹ́lì. Ó mú lẹ́tà táa fi yàn mí síṣẹ́ dání wá, mo sì nílò rẹ̀ nítorí ogun tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀, àti nítorí pé wọ́n ń fi tipátipá mú àwọn èèyàn wọṣẹ́ ológun. Mo sọ fún Arákùnrin Sullivan pé iye àkókò tí ìyàwó mi ń lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ kò yàtọ̀ sí tèmi, ó sì fẹ́ kí èmi àtòun jọ máa ṣe aṣáájú ọ̀nà. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé nígbà yẹn kò tíì sí ẹ̀ka iṣẹ́ tí ń bójú tó iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà ní àpéjọpọ̀ yẹn, ojú ẹsẹ̀ ni Arákùnrin Sullivan fọwọ́ síwèé aṣáájú ọ̀nà Marion, ó sì bi wá pé: “Níbo lẹ ti fẹ́ máa ṣe aṣáájú ọ̀nà lẹ́yìn àpéjọpọ̀?” A ò mọ ibì kankan. Ó wá sọ pé: “Tóò, ẹ má ṣèyọnu. Ó yẹ kẹ́ẹ lè bá ẹnì kan pàdé ní àpéjọpọ̀ yìí, tí yóò wá láti àgbègbè kan tó nílò àwọn aṣáájú ọ̀nà, ìyẹn á sì yanjú ìṣòro náà. Ẹ sáà kọ̀wé sí wa, kẹ́ẹ sọ ibi tẹ́ẹ wà, a ó sì yàn yín síbẹ̀.” Ohun tó sì ṣẹlẹ̀ nìyẹn. Ó ṣẹlẹ̀ pé Arákùnrin Jack DeWitt, tó jẹ́ alábòójútó àyíká tẹ́lẹ̀ rí, mọ àwọn èèyàn kan ní New Market, Virginia, tó ní ibùgbé fáwọn aṣáájú ọ̀nà, tí wọ́n sì nílò àwọn aṣáájú ọ̀nà mélòó kan sí i. Nítorí náà, a forí lé New Market lẹ́yìn àpéjọpọ̀ náà.

Ńṣe ni ìdùnnú ṣubú layọ̀ ní New Market. Ẹnì kan wá láti Philadelphia láti wá dara pọ̀ mọ́ wa nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà. Ta sì ni bí kò ṣe Benjamin Ransom? Ọ̀gbẹ́ni Ben kúkú ni. Ẹ wo bí inú wa ti dùn tó láti bá a ṣiṣẹ́ pọ̀ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ ilé dé ilé lẹ́yìn ohun tó ju ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n tó ti gbin irúgbìn òtítọ́ sọ́kàn mi ní Boston! Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ ọdún làwọn ẹbí fi pa á tì, tí wọ́n ń fi í ṣẹ̀sín, tí wọ́n tilẹ̀ ṣe inúnibíni sí i, síbẹ̀ gbogbo rẹ̀ kò paná ìfẹ́ tí Ọ̀gbẹ́ni Ben ní fún Jèhófà àti fún iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà.

A gbádùn oṣù mẹ́jọ táa fi wà ní ibùgbé àwọn aṣáájú ọ̀nà ní New Market. Láàárín àkókò yẹn, ara ohun táa kọ́ ni bí wọ́n ṣe ń fi adìyẹ àti ẹyin ṣe pàṣípààrọ̀ àwọn ìwé ìkẹ́kọ̀ọ́. Nígbà náà ni wọ́n wá ní kí èmi àti Marion àti Ọ̀gbẹ́ni Ben, àtàwọn mẹ́ta mìíràn lọ ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe ní Hanover, Pennsylvania—èyí jẹ́ àkọ́kọ́ lára ibi mẹ́fà tí wọ́n yàn fún wa láti ṣiṣẹ́ ní Pennsylvania láti 1942 sí 1945.

Àwa Aṣáájú Ọ̀nà Àkànṣe Nígbà Ogun Àgbáyé Kejì

Àwọn àkókò kan wà nígbà Ogun Àgbáyé Kejì tí wọ́n dojú ìjà kọ wá nítorí ìdúró àìdásí tọ̀túntòsì wa, àmọ́ Jèhófà kò padà lẹ́yìn wa rí. Nígbà kan ní Provincetown, Massachusetts, ògbólógbòó ọkọ̀ Buick wa dẹnu kọlẹ̀. Ó wá di dandan pé kí n rin ìrìn kìlómítà mélòó kan gba àdúgbò àwọn Kátólíìkì agbawèrèmẹ́sìn kọjá, láti lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò kan. Mo gba ẹ̀gbẹ́ àwọn jàǹdùkú kan kọjá, wọn mọ ẹni tí mo jẹ́, wọ́n sì figbe bọnu. Mo wá bẹ́sẹ̀ mi sọ̀rọ̀, òkò sì ń fò kọjá lẹ́gbẹ̀ẹ̀gbẹ́ etí mi, mo wá ń fọkàn gbàdúrà pé kí àwọn ọ̀dọ́ náà má bẹ̀rẹ̀ sí lé mi. Mo délé olùfìfẹ́hàn náà láìfarapa. Ṣùgbọ́n olùfìfẹ́hàn náà, tó jẹ́ abẹnugan nínú Ẹgbẹ́ Àwọn Ajagunfẹ̀yìntì Ilẹ̀ Amẹ́ríkà, bẹ̀ mí pé: “Mi ò lè ráyè nírọ̀lẹ́ yìí nítorí mo gbàgbé pé à ń lọ wo sinimá nígboro.” Àyà mi já, bí mo ṣe rántí àwọn agánnigàn ẹ̀dá wọ̀nyẹn tí ń ju òkò ní kọ̀rọ̀, tí wọ́n ń retí ìgbà tí màá padà. Àmọ́ mo tújú ká nígbà tí ọkùnrin ọmọlúwàbí náà sọ pé: “A ò ṣe kúkú jọ máa rìn lọ? Ká máa sọ̀rọ̀ lọ lójú ọ̀nà.” Ìyẹn jẹ́ kó ṣeé ṣe fún mi láti jẹ́rìí fún un, mo sì gba ibi wàhálà yẹn kọjá láìfarapa.

Bíbójútó Ọ̀ràn Ìdílé àti Iṣẹ́ Òjíṣẹ́ Pa Pọ̀

Lẹ́yìn ogun náà, wọ́n rán wa lọ sáwọn ibi mélòó kan ní Virginia, títí kan ọdún mẹ́jọ táa fi ń ṣe iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà àkànṣe àti aṣáájú ọ̀nà déédéé ní Charlottesville. Nígbà tó máa di 1956, àwọn ọmọbìnrin wa ti dàgbà, wọ́n sì ti lọ sílé ọkọ. Bí èmi àti Marion tún ṣe gbéra nìyẹn, táa lọ ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà ní Harrisonburg, Virginia, tí a sì lọ sìn lẹ́yìn náà gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe ní Lincolnton, North Carolina.

Ní 1966, wọ́n yàn mí sí iṣẹ́ àyíká, kí n máa lọ láti ìjọ dé ìjọ láti máa fún àwọn ará níṣìírí, gan-an gẹ́gẹ́ bí Arákùnrin Winchester ṣe fún mi níṣìírí nígbà yẹn lọ́hùn-ún ní New Jersey láwọn ọdún 1930. Ọdún méjì ni mo fi bẹ àwọn ìjọ tó wà ní àyíká kan ní Tennessee wò. Lẹ́yìn ìyẹn wọ́n wá ní kí èmi àti Marion padà sẹ́nu iṣẹ́ táa fẹ́ràn jù lọ, èyíinì ni aṣáájú ọ̀nà àkànṣe. Láti 1968 sí 1977, a ń sìn gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà àkànṣe ní Ìhà Gúúsù Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, láti Georgia títí lọ dé Mississippi.

Ní Eastman, Georgia, wọ́n yàn mí ṣe alábòójútó ìjọ (táa ń pè ní alábòójútó olùṣalága báyìí), láti rọ́pò Powell Kirkland, arákùnrin àgbàlagbà kan tó jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n, ẹni tó sìn fún ọ̀pọ̀ ọdún gẹ́gẹ́ bí alábòójútó àyíká, ṣùgbọ́n tí ara rẹ̀ ò le mọ́. Ó mọrírì rẹ̀ gan-an ni, ó sì tì mí lẹ́yìn gbágbáágbá. Ìtìlẹyìn rẹ̀ ṣe pàtàkì nítorí pé ìyapa wà nínú ìjọ yẹn, àwọn mélòó kan tó jẹ́ ògúnnágbòǹgbò ló sì wà nídìí ọ̀ràn náà. Ọ̀ràn náà di iṣu-ata-yán-anyàn-an, ọ̀pọ̀lọpọ̀ àkókò sì ni mo fi ń gbàdúrà sí Jèhófà. Mo rántí àwọn ẹsẹ Ìwé Mímọ́ bí Òwe 3:5, 6, tó kà pé: “Fi gbogbo ọkàn-àyà rẹ gbẹ́kẹ̀ lé Jèhófà, má sì gbára lé òye tìrẹ. Ṣàkíyèsí rẹ̀ ní gbogbo ọ̀nà rẹ, òun fúnra rẹ̀ yóò sì mú àwọn ipa ọ̀nà rẹ tọ́.” Nípa ṣíṣiṣẹ́ kára láti jẹ́ kí ọ̀nà ìjùmọ̀sọ̀rọ̀pọ̀ ṣí sílẹ̀, ó ṣeé ṣe fún wa láti mú kí ìjọ náà wà ní ìrẹ́pọ̀, ó sì ṣe gbogbo wa láǹfààní.

Nígbà tó fi máa di 1977, ara ti bẹ̀rẹ̀ sí di ara àgbà, wọ́n sì dá wa padà ságbègbè Charlottesville, níbi táwọn ọmọ wa méjèèjì ń gbé pẹ̀lú ìdílé wọn. Fún ọdún mẹ́tàlélógún tó ti kọjá, ó ti jẹ́ ayọ̀ wa láti ṣiṣẹ́ ní àgbègbè yìí, níbi táa ti ṣèrànwọ́ láti dá ìjọ Ruckersville, ní Virginia, sílẹ̀, táa sì ń rí bí àwọn ọmọ àti ọmọ-ọmọ àwọn táa bá ṣèkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ṣe ń dàgbà, tí wọ́n sì ń di alàgbà nínú ìjọ, aṣáájú ọ̀nà, àti mẹ́ńbà ìdílé Bẹ́tẹ́lì. Èmi àti Marion ṣì ń lọ sóde ẹ̀rí déédéé, mo sì láǹfààní sísìn gẹ́gẹ́ bí alàgbà nínú Ìjọ East ní Charlottesville, mo ń darí ìkẹ́kọ̀ọ́ ìwé ìjọ, mo sì máa ń sọ àsọyé fún gbogbo ènìyàn.

Láàárín àwọn ọdún wọ̀nyí tó ti kọjá, a ti ní àwọn ìṣòro tí kò yàtọ̀ sí èyí táwọn ẹlòmíì ń ní. Fún àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé a sapá gidigidi, síbẹ̀, Doris jó àjórẹ̀yìn nípa tẹ̀mí ní sáà kan, nígbà tó ń sún mọ́ ẹni ogún ọdún, ó sì lọ fẹ́ ọkùnrin kan tí kì í ṣe Ẹlẹ́rìí. Ṣùgbọ́n ìfẹ́ fún Jèhófà kò fẹ̀ẹ̀kàn kúrò lọ́kàn rẹ̀ pátápátá. Bill ọmọkùnrin rẹ̀ sì ti ń sìn fún ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún báyìí ní Bẹ́tẹ́lì ní Wallkill, New York. Doris àti Louise ti di opó báyìí, ṣùgbọ́n wọ́n ń sìn tayọ̀tayọ̀ nítòsí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà.

Àwọn Ẹ̀kọ́ Táa Ti Kọ́ Láwọn Ọdún Tó Ti Kọjá

Mo ti kọ́ láti máa lo àwọn ìlànà mélòó kan tó rọrùn, tó jẹ́ kí n kẹ́sẹ járí nínú sísin Jèhófà: Má walé ayé máyà. Jẹ́ àpẹẹrẹ rere nínú gbogbo ohun tí ò ń ṣe, títí kan ohun tí ò ń ṣe nínú kọ̀rọ̀ ilé rẹ. Máa tẹ̀ lé ìtọ́ni “ẹrú olóòótọ́ àti olóye” náà nínú ohun gbogbo.—Mátíù 24:45.

Marion ti ṣe àkọsílẹ̀ àwọn àbá ṣókí tó gbéṣẹ́ láti kẹ́sẹ járí gẹ́gẹ́ bí aṣáájú ọ̀nà nígbà téèyàn bá ń tọ́mọ lọ́wọ́: Ṣètò ìtòlẹ́sẹẹsẹ tó ṣeé tẹ̀ lé. Sọ iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà rẹ di iṣẹ́ ìgbésí ayé. Máa jẹ oúnjẹ tó ṣara lóore. Máa ní ìsinmi tí ó tó. Má ṣe eré ìtura láṣejù. Jẹ́ kí òtítọ́, títí kan gbogbo apá iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, gbádùn mọ́ àwọn ọmọ rẹ. Jẹ́ kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà jẹ́ orísun ayọ̀ fún wọn nígbà gbogbo.

A ti lé lẹ́ni àádọ́rùn-ún ọdún báyìí. Ọdún méjìlélọ́gọ́ta ti kọjá látìgbà táa gbọ́ ọ̀rọ̀ ìrìbọmi wa lẹ́yìnkùlé Stackhouse, a sì ti lo ọgọ́ta ọdún nínú iṣẹ́ ìsìn alákòókò kíkún. Èmi àti Marion lè sọ tòótọ́tòótọ́ pé ìpín tiwa nínú ìgbésí ayé tẹ́ wa lọ́rùn gan-an. Mo dúpẹ́, mo tún ọpẹ́ dá, fún ìṣírí tí mo rí gbà nígbà tí mo ṣẹ̀ṣẹ̀ di bàbá ọlọ́mọ, pé kí n fi àwọn góńgó tẹ̀mí sípò àkọ́kọ́, kí n sì máa lépa irú góńgó bẹ́ẹ̀. Mo sì dúpẹ́ lọ́wọ́ Marion, ìyàwó mi àtàtà, mo tún dúpẹ́ lọ́wọ́ àwọn ọmọbìnrin mi fún ìtìlẹyìn tí wọ́n ṣe ní gbogbo ọdún wọ̀nyí wá. Bí a kò tilẹ̀ ní ọrọ̀ nípa tara, mo máa ń lo ọ̀rọ̀ Oníwàásù 2:25 fún ara mi, pé: “Ta ni ó ń jẹ, ta sì ni ó ń mu ohun tí ó dára tó tèmi?”

Ká sòótọ́, nínú ọ̀ràn tiwa, Jèhófà ti mú ìlérí rẹ̀ tó wà nínú Málákì 3:10 ṣẹ lọ́pọ̀lọpọ̀. Àní sẹ́, ó ti ‘tú ìbùkún dà sórí wa títí kò fi sí àìní mọ́’!

[Àpótí/Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 29]

ÀWỌN OHUN TÁA RÁNTÍ NÍPA ÀWỌN ỌDÚN OGUN

Ní ohun tó fẹ́rẹ̀ẹ́ tó ọgọ́ta ọdún lẹ́yìn ogun náà, ìdílé wa ṣì rántí àwọn ohun tó ṣẹlẹ̀ lọ́dún wọnnì dáadáa.

Doris rántí pé: “Pennsylvania mà máa ń tutù o. Lóru ọjọ́ kan, ó fi ìwọ̀n 35 dín sí oódo lórí òṣùwọ̀n Celsius.” Louise fi kún un pé, “Èmi àti Doris á wá jókòó sórí ẹsẹ̀ ara wa ní ìjókòó ẹ̀yìn nínú ògbólógbòó ọkọ̀ Buick wa, kí ẹsẹ̀ wa má bàa tutù.”

Doris sọ pé: “Àmọ́ òṣì ò ta wá rí, ìyà ò sì jẹ wá rí. A mọ̀ pé a ń ṣí kiri ju ọ̀pọ̀ jù lọ èèyàn, ṣùgbọ́n oúnjẹ ò wọ́n wa, a sì ní àwọn aṣọ tó dáa, tó fẹ́rẹ̀ẹ́ jẹ́ tuntun, táwọn ọ̀rẹ́ tó ní àwọn ọmọbìnrin tó fi díẹ̀ dàgbà jù wá lọ láti Ohio fi ránṣẹ́ sí wa.”

Louise sọ pé: “Mọ́mì àti Dádì sábà máa ń jẹ́ ká mọ̀ pé àwọn nífẹ̀ẹ́ wa, àti pé àwọn mọrírì wa, a sì ń lo àkókò púpọ̀ pẹ̀lú wọn nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Èyí jẹ́ kí a gbà pé ọmọ àtàtà ni wá, a sì sún mọ́ wọn tímọ́tímọ́.”

Pọ́ọ̀lù rántí pé: “Mo ní Àkànṣe Ọkọ̀ Buick kan tí wọ́n ṣe ní 1936, ọ̀pá irin tí ń gbé ọwọ́ mọ́tò náà kì í sì í pẹ́ yawọ́. Mo rò pé agbára ẹ́ńjìnnì yẹn ti pọ̀ jù fún ọkọ̀ náà. Ó jọ pé òru tó bá tutù jù lóṣù ló máa ń kọṣẹ́, màá sì wá gbọ̀nà ibi tí wọ́n ń kó òkú ọkọ̀ sí láti lọ wá ọ̀pá míì. Mo wá di ògbógi nínú yíyọ wọ́n síra.”

Marion sọ pé: “Má gbàgbé àwọn káàdì táa fi lọ ń gba àwọn nǹkan tí ìjọba ń pín fáwọn èèyàn. Gbogbo nǹkan ni wọ́n ń pín lé wa lọ́wọ́—ì báà jẹ́ ẹran, tàbí epo mọ́tò, táyà mọ́tò, ohun yòówù ó jẹ́. Gbogbo ìgbà táa bá dé ibi tuntun tí wọ́n yàn fún wa láti ṣiṣẹ́ ni a lọ máa ń béèrè fún káàdì tuntun lọ́dọ̀ ìjọba ìbílẹ̀. Ó lè gba ọ̀pọ̀ oṣù kí wọ́n tó fún wa, ó sì sábà máa ń ṣẹlẹ̀ pé ìgbà táa bá rí káàdì wa gbà tán, ni wọ́n á yan ibòmíì fún wa, iyán á wá di àtúngún, ọbẹ̀ á sì di àtúnsè. Ṣùgbọ́n Jèhófà kì í ṣàì tọ́jú wa.”

[Àwòrán]

Èmi àti Marion pẹ̀lú Doris (lápá òsì) àti Louise, lọ́dún 2000

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Èmi àti màmá mi ní 1918, nígbà tí mo jẹ́ ọmọ ọdún mọ́kànlá

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Èmi àti Louise, Marion, àti Doris ní 1948 nígbà táwọn ọmọbìnrin wa ṣèrìbọmi

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Fọ́tò ìgbéyàwó wa, October 1928

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

Èmi àtàwọn ọmọbìnrin mi (ní òsì pátápátá àti ọ̀tún pátápátá) ní Pápá Ìṣiré Yankee, 1955