Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

A Nílò Ìrànlọ́wọ́ Láti Lóye Bíbélì

A Nílò Ìrànlọ́wọ́ Láti Lóye Bíbélì

A Nílò Ìrànlọ́wọ́ Láti Lóye Bíbélì

BÍBÉLÌ jẹ́ ìwé tí kò lẹ́gbẹ́. Àwọn tó kọ ọ́ sọ pé Ọlọ́run ló mí sí àwọn, ọ̀rọ̀ tó sì wà nínú rẹ̀ jẹ́rìí sí i gidigidi pé bẹ́ẹ̀ gan-an ló rí. (2 Tímótì 3:16) Ara ohun tí Bíbélì sọ fún wa ni ibi táa ti wá, ìdí táa fi wà níhìn-ín, àti ibi táa ń lọ. Dájúdájú, ìwé tá ò gbọ́dọ̀ má kà ni!

Bóyá o ti gbìyànjú láti ka Bíbélì ṣùgbọ́n tí òye rẹ̀ ò yé ọ. Bóyá o ò mọ ibi tóo máa ṣí láti rí ìdáhùn sáwọn ìbéèrè rẹ. Bí bẹ́ẹ̀ bá ni, kì í ṣe ìwọ nìkan nirú ẹ̀ ń ṣe. Ipò tóo wà yìí dà bíi ti ọkùnrin kan tó gbáyé ní ọ̀rúndún kìíní. Ó ń fi kẹ̀kẹ́ ẹṣin rìnrìn àjò láti Jerúsálẹ́mù lọ sí Etiópíà, orílẹ̀-èdè rẹ̀. Ketekete ni onípò àṣẹ ará Etiópíà yìí ń ka ìwé Aísáyà, tó jẹ́ ìwé àsọtẹ́lẹ̀ kan nínú Bíbélì. A kọ ọ́ ní ohun tó lé ní ọgọ́rùn-ún ọdún méje ṣáájú.

Gbígbé tó máa gbójú sókè, ọkùnrin kan wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ kẹ̀kẹ́ ẹṣin rẹ̀ tó ń bá a sọ̀rọ̀. Fílípì, tí í ṣe ọmọlẹ́yìn Jésù, lọkùnrin ọ̀hún, ó sì bi ará Etiópíà náà pé: “Ní ti gidi, ìwọ ha mọ ohun tí o ń kà bí?” Ará Etiópíà náà fèsì pé: “Ní ti tòótọ́, báwo ni mo ṣe lè ṣe bẹ́ẹ̀, láìjẹ́ pé ẹnì kan fi mí mọ̀nà?” Ó wá ní kí Fílípì máa bọ̀ nínú kẹ̀kẹ́ ẹṣin náà. Fílípì ṣàlàyé ohun tí ọkùnrin náà kà fún un, ó sì tẹ̀ síwájú láti polongo “ìhìn rere nípa Jésù fún un.”—Ìṣe 8:30-35.

Gẹ́gẹ́ bí Fílípì ṣe ran ará Etiópíà yẹn lọ́wọ́ láti lóye Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run níjelòó, bẹ́ẹ̀ náà làwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà ṣe ń ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì lónìí. Inú wọn yóò dùn láti ran ìwọ náà lọ́wọ́. Ó sábà máa ń dára jù lọ láti kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì ní ṣísẹ̀-n-tẹ̀-lé, kéèyàn fi àwọn ìpìlẹ̀ ẹ̀kọ́ Ìwé Mímọ́ bẹ̀rẹ̀. (Hébérù 6:1) Bóo ti ń tẹ̀ síwájú, wàá lóye ohun tí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù pè ní “oúnjẹ líle”—ìyẹn, àwọn òtítọ́ jíjinlẹ̀. (Hébérù 5:14) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ẹ̀kọ́ inú Bíbélì lò ń kọ́, àwọn ìtẹ̀jáde míì—tí ń ranni lọ́wọ́ láti lóye Bíbélì—lè ràn ọ́ lọ́wọ́ láti mọ àwọn ibi tí Bíbélì ti sọ̀rọ̀ nípa ọ̀kan-ò-jọ̀kan kókó ọ̀rọ̀, kí o sì lóye àwọn kókó náà.

A lè ṣètò ìkẹ́kọ̀ọ́ sí àkókò àti ibi tí yóò rọ̀ ọ́ lọ́rùn. Àwọn kan tiẹ̀ ń kẹ́kọ̀ọ́ lórí tẹlifóònù. Ìkẹ́kọ̀ọ́ yìí kò dà bí ìgbà téèyàn wà nínú kíláàsì; kì í ṣe lójú gbogbo ayé, yóò sì jẹ́ lọ́nà tó bá ipò tóo wà mu, títí kan irú ipò tó yí ọ ká àti bóo ṣe kàwé sí. O ò ní sanwó fún irú ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ́ẹ̀. (Mátíù 10:8) O ò ní ṣèdánwò kankan, a ò sì ní fi ẹ́ wọ́lẹ̀. A óò dáhùn àwọn ìbéèrè rẹ, wàá sì mọ bóo ṣe lè sún mọ́ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n, èé ṣe tó fi yẹ kóo kẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì? Gbé àwọn ìdí kan yẹ̀ wò tí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì fi lè mú kí ìgbésí ayé rẹ túbọ̀ láyọ̀.