Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Nípìn-ín Nínú Ayọ̀ Tó Wà Nínú Fífúnni!

Nípìn-ín Nínú Ayọ̀ Tó Wà Nínú Fífúnni!

Nípìn-ín Nínú Ayọ̀ Tó Wà Nínú Fífúnni!

“Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.”—ÌṢE 20:35.

1. Báwo ni Jèhófà ṣe fi hàn pé ayọ̀ wà nínú fífúnni?

 AYỌ̀ mímọ òtítọ́ àti ìbùkún tó máa ń tibẹ̀ jáde jẹ́ ẹ̀bùn ṣíṣeyebíye látọ̀dọ̀ Ọlọ́run. Àwọn tó mọ Jèhófà ní ọ̀pọ̀ ìdí láti máa yọ. Ṣùgbọ́n, bí ayọ̀ ṣe wà nínú rírí ẹ̀bùn gbà, bẹ́ẹ̀ náà layọ̀ tún wà nínú fífúnni ní ẹ̀bùn. Jèhófà ni Olùfúnni ní “gbogbo ẹ̀bùn rere àti gbogbo ọrẹ pípé,” òun sì ni “Ọlọ́run aláyọ̀.” (Jákọ́bù 1:17; 1 Tímótì 1:11) Ó ń gbin ẹ̀kọ́ tó yè kooro sọ́kàn gbogbo ẹni tó fetí sílẹ̀, inú rẹ̀ sì máa ń dùn nígbà tí àwọn tó kọ́ bá ṣègbọràn, gẹ́gẹ́ bí àwọn òbí ṣe máa ń yọ̀ nígbà táwọn ọmọ bá fi ìtọ́ni onífẹ̀ẹ́ wọn sílò.—Òwe 27:11.

2. (a) Kí ni Jésù sọ nípa fífúnni ní nǹkan? (b) Ayọ̀ wo la máa ń rí nígbà táa bá kọ́ àwọn ẹlòmíràn ní òtítọ́ Bíbélì?

2 Bákan náà, nígbà tí Jésù wà lórí ilẹ̀ ayé, inú rẹ̀ máa ń dùn nígbà táwọn èèyàn bá tẹ́wọ́ gba ẹ̀kọ́ rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ṣàyọlò ọ̀rọ̀ tí Jésù sọ pé: “Ayọ̀ púpọ̀ wà nínú fífúnni ju èyí tí ó wà nínú rírígbà lọ.” (Ìṣe 20:35) Ayọ̀ táa máa ń ní nígbà táa bá kọ́ àwọn ẹlòmíràn ní òtítọ́ Bíbélì kì í wulẹ̀ ṣe ti pé inú wa dùn pé ẹnì kan fara mọ́ ẹ̀sìn wà nìkan ni. Ohun tó ju ìyẹn lọ fíìfíì ni ayọ̀ mímọ̀ pé a ń fi ohun kan tó jẹ́ ojúlówó, tó sì máa wà pẹ́ títí tọrẹ. Nípa fífúnni nípa tẹ̀mí, a lè ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti ṣe ara wọn láǹfààní nísinsìnyí àti títí ayérayé.—1 Tímótì 4:8.

Fífúnni Ń Máyọ̀ Wá

3. (a) Báwo ni àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù àti Jòhánù ṣe fi ayọ̀ tí wọ́n ní nínú ríran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ nípa tẹ̀mí hàn? (b) Èé ṣe tí gbígbin òtítọ́ Bíbélì sọ́kàn àwọn ọmọ wa fi jẹ́ fífi ìfẹ́ hàn sí wọn?

3 Bẹ́ẹ̀ ni o, bí Jèhófà àti Jésù ṣe máa ń yọ̀ nígbà tí wọ́n bá fúnni ní ẹ̀bùn tẹ̀mí náà làwọn Kristẹni ṣe máa ń yọ̀. Inú àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù dùn nígbà tó rí i pé òun ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ó kọ̀wé sí ìjọ tó wà ní Tẹsalóníkà pé: “Kí ni ìrètí tàbí ìdùnnú tàbí adé ayọ̀ ńláǹlà wa—họ́wù, ní ti tòótọ́, kì í ha ṣe ẹ̀yin ni bí?—níwájú Jésù Olúwa wa nígbà wíwàníhìn-ín rẹ̀? Dájúdájú, ẹ̀yin ni ògo àti ìdùnnú wa.” (1 Tẹsalóníkà 2:19, 20) Bákan náà, nígbà tí àpọ́sítélì Jòhánù ń sọ̀rọ̀ nípa àwọn ọmọ rẹ̀ tẹ̀mí, ó kọ̀wé pé: “Èmi kò ní ìdí kankan tí ó tóbi ju nǹkan wọ̀nyí lọ fún ṣíṣọpẹ́, pé kí n máa gbọ́ pé àwọn ọmọ mi ń bá a lọ ní rírìn nínú òtítọ́.” (3 Jòhánù 4) Tún wá ronú nípa ayọ̀ táa máa ń ní nígbà táa bá ran àwọn ọmọ tiwa fúnra wa lọ́wọ́ láti di ọmọ wa nípa tẹ̀mí! Títọ́ àwọn ọmọ dàgbà nínú “ìbáwí àti ìlànà èrò orí Jèhófà,” jẹ́ ọ̀nà kan táwọn òbí lè gbà fi ìfẹ́ hàn. (Éfésù 6:4) Àwọn òbí ń tipa bẹ́ẹ̀ fi hàn pé àwọn ń ṣàníyàn nípa ire ayérayé àwọn ọmọ wọn. Nígbà táwọn ọmọ náà bá sì tẹ́wọ́ gbà á, ó máa ń fún àwọn òbí ní ayọ̀ ńlá àti ìtẹ́lọ́rùn.

4. Ìrírí wo ló fi ayọ̀ tó wà nínú fífúnni nípa tẹ̀mí hàn?

4 Aṣáájú ọ̀nà alákòókò kíkún ni Dell, ìyá ọlọ́mọ márùn-ún sì ni. Ó sọ pé: “Mo lóye ọ̀rọ̀ àpọ́sítélì Jòhánù yẹn dáadáa nítorí mo ń dúpẹ́ gan-an pé mẹ́rin nínú àwọn ọmọ mi ń ‘rìn nínú òtítọ́.’ Mo mọ̀ pé ó máa ń fi ògo àti ọlá fún Jèhófà nígbà tí ìdílé bá wà níṣọ̀kan nínú ìjọsìn tòótọ́, nítorí náà, ọkàn mi balẹ̀ gan-an bí mo ṣe ń rí ìbùkún Jèhófà lórí ìsapá tí mo ṣe láti gbin òtítọ́ sọ́kàn àwọn ọmọ mi. Ìfojúsọ́nà àgbàyanu ti wíwàláàyè títí láé nínú Párádísè pẹ̀lú ìdílé mi jẹ́ kí n nírètí, ó sì ń jẹ́ kí n lè ní ìfaradà láìka àwọn ìṣòro àti ìdènà sí.” Ó bani nínú jẹ́ pé wọ́n yọ ọ̀kan lára àwọn ọmọbìnrin Dell lẹ́gbẹ́ nítorí pé ó ṣe nǹkan kan tí kò yẹ kí Kristẹni ṣe. Síbẹ̀, Dell kò jẹ́ kíyẹn ba ayọ̀ òun jẹ́. Ó sọ pé: “Ìrètí mi ni pé níjọ́ ọjọ́ kan, ọmọ mi yóò fi tìrẹ̀lẹ̀tìrẹ̀lẹ̀ àti tọkàntọkàn padà sọ́dọ̀ Jèhófà. Ṣùgbọ́n mo dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run pé èyí tó pọ̀ jù lọ lára àwọn ọmọ mi ló ń fi òtítọ́ sìn ín nìṣó. Ayọ̀ tí mo ní jẹ́ orísun okun ńláǹlà fún mi.”—Nehemáyà 8:10.

Yíyan Ọ̀rẹ́ Tó Máa Wà Títí Láé

5. Báa ṣe ń fi gbogbo ara wa ṣe iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, kí ló ń fún wa láyọ̀?

5 Jésù pàṣẹ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé kí wọ́n máa sọ àwọn èèyàn di Kristẹni ọmọ ẹ̀yìn, kí wọ́n sì máa kọ́ wọn nípa Jèhófà àtàwọn ohun tó béèrè lọ́wọ́ wa. (Mátíù 28:19, 20) Jèhófà àti Jésù ti fi àìmọtara ẹni nìkan ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa ọ̀nà òtítọ́. Nítorí náà báa ṣe ń fi gbogbo ara wa ṣe iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, ayọ̀ ń kún inú wa nítorí pé a ń ṣe àfarawé àpẹẹrẹ Jèhófà àti ti Jésù, bí àwọn Kristẹni ìjímìjí ti ṣe. (1 Kọ́ríńtì 11:1) Nígbà táa bá fọwọ́ sowọ́ pọ̀ báyẹn pẹ̀lú Ọlọ́run Olódùmarè àti Ọmọ rẹ̀ ọ̀wọ́n, ìgbésí ayé wa máa ń nítumọ̀ gidi. Ìbùkún ńlá ló mà jẹ́ o, láti wà lára àwọn “alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run”! (1 Kọ́ríńtì 3:9) Ǹjẹ́ kò sì múnú wa dùn pé àwọn áńgẹ́lì pàápàá ń kópa nínú ìgbòkègbodò wíwàásù ìhìn rere náà?—Ìṣípayá 14:6, 7.

6. Àwọn wo ló ń di ọ̀rẹ́ wa báa ṣe ń nípìn-ín nínú fífúnni nípa tẹ̀mí?

6 Ká sọ tòótọ́, báa ti ń kópa nínú iṣẹ́ fífúnni nípa tẹ̀mí yìí, kì í ṣe pé a óò jẹ́ alábàáṣiṣẹ́pọ̀ pẹ̀lú Ọlọ́run nìkan ni—a tún lè di ọ̀rẹ́ rẹ̀ títí ayé. Nítorí ìgbàgbọ́ Ábúráhámù la ṣe pè é ní ọ̀rẹ́ Jèhófà. (Jákọ́bù 2:23) Báa ṣe ń sapá láti ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, àwa náà lè di ọ̀rẹ́ Ọlọ́run. Báa bá ṣe bẹ́ẹ̀, a tún di ọ̀rẹ́ Jésù nìyẹn. Ó sọ fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Mo pè yín ní ọ̀rẹ́, nítorí pé gbogbo nǹkan tí mo ti gbọ́ láti ọ̀dọ̀ Baba mi ni mo ti sọ di mímọ̀ fún yín.” (Jòhánù 15:15) Ọ̀pọ̀ ni inú wọn máa ń dùn láti jẹ́ ọ̀rẹ́ àwọn èèyàn jàǹkànjàǹkàn, tàbí àwọn tó wà nípò gíga, àmọ́ a lè di ọ̀rẹ́ àwọn ẹni méjì tó tóbi jù lọ lọ́run òun ayé!

7. (a) Báwo ni obìnrin kan ṣe ní ojúlówó ọ̀rẹ́? (b) Ǹjẹ́ o nírìírí tó jọ bẹ́ẹ̀ rí?

7 Síwájú sí i, nígbà táa bá ran àwọn èèyàn lọ́wọ́ láti mọ Ọlọ́run, àwọn náà di ọ̀rẹ́ wa nìyẹn, èyí sì ń fún wa ní ayọ̀ kan tó jẹ́ àrà ọ̀tọ̀. Joan tó ń gbé ní Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà, bẹ̀rẹ̀ sí bá obìnrin kan tórúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Thelma ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìdílé Thelma tako ìkẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀, síbẹ̀ ó fara dà á, ó sì ṣe batisí ní ọdún kan lẹ́yìn náà. Joan kọ̀wé pé: “Àjọṣe wa kò parí síbẹ̀; dípò ìyẹn, ó ti jẹ́ ká di ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ láti nǹkan bí ọdún márùndínlógójì báyìí. A jọ máa ń lọ sóde ẹ̀rí àtàwọn àpéjọpọ̀. Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, mo kó lọ sílé tuntun tó jẹ́ nǹkan bí ẹgbẹ̀rin kìlómítà sí tirẹ̀. Ṣùgbọ́n, Thelma ń bá a lọ láti máa kọ àwọn lẹ́tà onífẹ̀ẹ́, tó ń mọ́kàn yọ̀ gidigidi sí mi, ó máa ń sọ fún mi pé inú òun máa ń dùn yàtọ̀ nígbà tóun bá ń ronú nípa mi, ó sì ń dúpẹ́ lọ́wọ́ mi fún jíjẹ́ tí mo jẹ́ ọ̀rẹ́ àti àpẹẹrẹ fún òun, àti fún kíkọ́ tí mo fi òtítọ́ inú Bíbélì kọ́ òun. Níní irú ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́, tó sì jẹ́ ẹni ọ̀wọ́n bẹ́ẹ̀ jẹ́ èrè ńlá fún ìsapá tí mo ṣe láti ràn án lọ́wọ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ nípa Jèhófà.”

8. Ẹ̀mí tó dára wo ló máa ràn wá lọ́wọ́ nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà?

8 Fífojúsọ́nà láti rí ẹnì kan tó máa fẹ́ láti kẹ́kọ̀ọ́ òtítọ́ lè ràn wá lọ́wọ́ láti máa fara dà á, kódà bí ọ̀pọ̀ lára àwọn táa ń bá pàdé kó tiẹ̀ fi bẹ́ẹ̀ nífẹ̀ẹ́ sí Ọ̀rọ̀ Jèhófà. Irú ẹ̀mí ìdágunlá bẹ́ẹ̀ lè fẹ́ jin ìgbàgbọ́ àti ìfaradà wa lẹ́sẹ̀. Síbẹ̀ níní ẹ̀mí tó dára lè ràn wá lọ́wọ́. Fausto, tó wá láti Guatemala, sọ pé: “Nígbà tí mo bá jẹ́rìí fún àwọn ẹlòmíràn, mo máa ń ronú nípa bó ṣe máa jẹ́ nǹkan àgbàyanu tó bí ẹni tí mò ń bá sọ̀rọ̀ bá lè di arákùnrin tàbí arábìnrin nípa tẹ̀mí. Mo máa ń ronú pé ó kéré tán kí ẹnì kan lára àwọn tí mo máa bá pàdé tẹ́wọ́ gba òtítọ́ Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀. Ìyẹn ló jẹ́ kí n máa tẹ̀ síwájú, tó sì ń fún mi láyọ̀.”

Títo Ìṣúra Jọ sí Ọ̀run

9. Kí ni Jésù sọ nípa títo ìṣúra jọ sí ọ̀run, ẹ̀kọ́ wo la sì lè rí kọ́ nínú èyí?

9 Sísọni di ọmọ ẹ̀yìn kì í sábà rọrùn, ì báà jẹ́ àwọn ọmọ wa ni o tàbí àwọn ẹlòmíràn. Ó lè gba àkókò, sùúrù, àti ìfaradà. Àmọ́ ṣá o, rántí pé ọ̀pọ̀ ni kò kọ̀ láti ṣiṣẹ́ àṣekára láti kó nǹkan tara rẹpẹtẹ jọ, àwọn nǹkan tí kì í sábà fún wọn láyọ̀, tí kì í sì í wà títí láé. Jésù sọ fún àwọn olùgbọ́ rẹ̀ pé, ó sàn láti ṣiṣẹ́ fún nǹkan tẹ̀mí. Ó sọ pé: “Ẹ dẹ́kun títo àwọn ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín lórí ilẹ̀ ayé, níbi tí òólá àti ìpẹtà ti ń jẹ nǹkan run, àti níbi tí àwọn olè ti ń fọ́lé, tí wọ́n sì ń jalè. Kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ to ìṣúra jọ pa mọ́ fún ara yín ní ọ̀run, níbi tí òólá tàbí ìpẹtà kò lè jẹ nǹkan run, àti níbi tí àwọn olè kò lè fọ́lé, kí wọ́n sì jalè.” (Mátíù 6:19, 20) Nípa lílépa góńgó tẹ̀mí—tí nínípìn-ín nínú iṣẹ́ pàtàkì ti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn wà lára rẹ̀—ọkàn wa lè balẹ̀ pé à ń ṣe ìfẹ́ Ọlọ́run, a sì mọ̀ pe yóò sán èrè fún wa. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ọlọ́run kì í ṣe aláìṣòdodo tí yóò fi gbàgbé iṣẹ́ yín àti ìfẹ́ tí ẹ fi hàn fún orúkọ rẹ̀.”—Hébérù 6:10.

10. (a) Kí nìdí tí Jésù fi ní àwọn ìṣúra tẹ̀mí? (b) Báwo ni Jésù ṣe fi ara rẹ̀ fúnni, kí sì ni àǹfààní ńlá tó jẹ́ fún àwọn ẹlòmíràn?

10 Táa bá fi taápọntaápọn ṣiṣẹ́ láti sọni di ọmọ ẹ̀yìn, a jẹ́ pé a ń to “ìṣúra” jọ fún ara wa “ní ọ̀run” nìyẹn, ní ìbámu pẹ̀lú ohun tí Jésù sọ. Èyí yóò fún wa ní ayọ̀ rírí gbà. Bí a bá ń fi àìmọtara ẹni nìkan fúnni ní nǹkan, àwa náà ò ní ṣàìjèrè rẹ̀ níkẹyìn. Jésù alára ti fi ìṣòtítọ́ sin Jèhófà fún àìmọye bílíọ̀nù ọdún. Ronú nípa ìṣúra tó ti tò jọ ní ọ̀run! Síbẹ̀síbẹ̀, Jésù kò wá ire ti ara rẹ̀. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “[Jésù] fi ara rẹ̀ fúnni nítorí àwọn ẹ̀ṣẹ̀ wa, kí ó lè dá wa nídè kúrò nínú ètò àwọn nǹkan burúkú ìsinsìnyí gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọ́run àti Baba wa.” (Gálátíà 1:4) Kì í ṣe pé Jésù fara jin iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà nìkan ni, àmọ́ ó tún fi ẹ̀mí ara rẹ̀ lélẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ìràpadà kí àwọn ẹlòmíràn lè láǹfààní láti to ìṣúra jọ ní ọ̀run.

11. Kí nìdí tí àwọn ẹ̀bùn tẹ̀mí fi dára ju tara lọ?

11 Nípa kíkọ́ àwọn èèyàn nípa Ọlọ́run, a ń ràn wọ́n lọ́wọ́ láti rí i bí àwọn náà ṣe lè to ìṣúra tẹ̀mí tí kò lè díbàjẹ́ pa mọ́. Ẹ̀bùn wo lo tún lè fúnni tó máa tóbi jùyẹn lọ? Tóo bá fún ọ̀rẹ́ rẹ ní aago olówó ńlá, ọkọ̀ ayọ́kẹ́lẹ́, tàbí ilé pàápàá, ó dájú pé ọ̀rẹ́ náà yóò kún fún ìmoore, inú rẹ̀ yóò sì dùn, ìwọ náà yóò sì ní ayọ̀ fífúnni. Àmọ́, kí ni ẹ̀bùn yẹn máa dà lẹ́yìn ogún ọdún? Lẹ́yìn igba ọdún ńkọ́? Lẹ́yìn ẹgbàá ọdún ńkọ́? Ní òdì kejì ẹ̀wẹ̀, bóo bá ran ẹnì kan lọ́wọ́ láti sin Jèhófà, irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè jàǹfààní ẹ̀bùn yẹn títí láé.

Wíwá Àwọn Tó Fẹ́ Òtítọ́ Rí

12. Báwo làwọn kan ṣe yọ̀ǹda ara wọn láti ran àwọn ẹlòmíràn lọ́wọ́?

12 Láti nípìn-ín nínú ayọ̀ fífúnni nípa tẹ̀mí, àwọn èèyàn Jèhófà ti dé igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin ayé. Ẹgbẹẹgbẹ̀rún ti fi ilé, àti ẹbí sílẹ̀ láti lọ ṣe iṣẹ́ ìsìn míṣọ́nnárì ní àwọn orílẹ̀-èdè tí wọ́n ti ní láti kọ́ èdè àti àṣà tuntun. Àwọn mìíràn ti kó lọ sí àwọn àgbègbè tí wọ́n ti nílò àwọn olùpòkìkí Ìjọba náà ní orílẹ̀-èdè tiwọn. Síbẹ̀ àwọn mìíràn ti kọ́ èdè àjèjì, tó ń fún wọn láǹfààní àtibá àwọn àjèjì tó ń kó wá sí àgbègbè wọn sọ̀rọ̀. Fún àpẹẹrẹ, lẹ́yìn tí tọkọtaya kan ní New Jersey, Orílẹ̀-Èdè Amẹ́ríkà ti tọ́ àwọn ọmọ wọn méjì tó ń ṣiṣẹ́ ní orílé iṣẹ́ àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà báyìí dàgbà, wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ṣe aṣáájú ọ̀nà, wọ́n sì kọ́ èdè Chinese. Láàárín ọdún mẹ́ta, wọ́n darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì pẹ̀lú àwọn mẹ́rìnléláàádọ́rin tó ń sọ èdè Chinese, tí wọ́n wà ní ilé ẹ̀kọ́ gíga kan tó wà nítòsí. Ǹjẹ́ ó ṣeé ṣe fún ọ láti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ gbòòrò sí i láwọn ọ̀nà kan, kóo lè túbọ̀ ní ayọ̀ nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn?

13. Kí lo lè ṣe tóo bá fẹ́ kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ túbọ̀ méso jáde?

13 Bóyá o ń hára gàgà láti darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì, ṣùgbọ́n tí kò tíì ṣeé ṣe fún ọ láti ṣe bẹ́ẹ̀. Àwọn orílẹ̀-èdè kan wà tó ti ṣòro láti rí olùfìfẹ́hàn. Bóyá àwọn tóo ń bá pàdé kò nífẹ̀ẹ́ sí Bíbélì. Tọ́rọ̀ bá rí bẹ́ẹ̀, á dáa kóo túbọ̀ mẹ́nu kan ohun tó jẹ́ ẹ̀dùn ọkàn rẹ nínú àdúrà, níwọ̀n bí Jèhófà àti Jésù Kristi ti nífẹ̀ẹ́ jíjinlẹ̀ sí iṣẹ́ náà, wọ́n sì lè darí rẹ sọ́dọ̀ àwọn ẹni bí àgùntàn. Gba ìmọ̀ràn lọ́dọ̀ àwọn tó nírìírí jù ọ́ lọ nínú ìjọ tàbí àwọn tí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn túbọ̀ ń méso jáde. Lo àwọn ẹ̀kọ́ àti ìmọ̀ràn táa ń gbà láwọn ìpàdé Kristẹni. Jàǹfààní látinú ìmọ̀ràn àwọn alábòójútó arìnrìn-àjò àtàwọn ìyàwó wọn. Lékè gbogbo rẹ̀, má juwọ́ sílẹ̀. Ọlọgbọ́n ọkùnrin náà kọ̀wé pé: “Ní òwúrọ̀, fún irúgbìn rẹ àti títí di ìrọ̀lẹ́, má ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ sinmi; nítorí ìwọ kò mọ ibi tí èyí yóò ti ṣe àṣeyọrí sí rere.” (Oníwàásù 11:6) Ní báyìí ná, rántí àwọn ọkùnrin olóòótọ́ bíi Nóà àti Jeremáyà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ̀nba díẹ̀ làwọn tó fetí sí ìwàásù wọn, síbẹ̀ àwọn kan fetí sílẹ̀, iṣẹ́ òjíṣẹ́ wọn sì kẹ́sẹ járí. Ju gbogbo rẹ̀ lọ, inú Jèhófà dùn sí iṣẹ́ náà.

Sa Gbogbo Ipá Rẹ

14. Ojú wo ni Jèhófà fi ń wo àwọn tó ti di arúgbó nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀?

14 Ó ṣeé ṣe kó jẹ́ pé ipò tóo wà kò fún ọ láǹfààní láti ṣe bóo ṣe fẹ́ ṣe tó nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà. Fún àpẹẹrẹ, ọjọ́ ogbó lè dín ohun tóo lè ṣe nínú iṣẹ́ ìsìn Jèhófà kù. Síbẹ̀, rántí ohun tí ọlọgbọ́n ọkùnrin náà kọ: “Orí ewú jẹ́ adé ẹwà nígbà tí a bá rí i ní ọ̀nà òdodo.” (Òwe 16:31) Inú Jèhófà máa ń dùn gan-an sí ìgbésí ayé táa bá lò nínú iṣẹ́ ìsìn rẹ̀. Ìwé Mímọ́ sì sọ pé: “Àní títí di ọjọ́ ogbó ènìyàn, Ẹnì kan náà ni mí [Jèhófà]; àti títí di ìgbà orí ewú ènìyàn, èmi fúnra mi yóò máa rù ú. Dájúdájú, èmi yóò gbé ìgbésẹ̀, kí èmi fúnra mi lè gbé, kí èmi fúnra mi sì lè rù, kí n sì pèsè àsálà.” (Aísáyà 46:4) Baba wa ọ̀run onífẹ̀ẹ́ ṣèlérí láti mẹ́sẹ̀ àwọn adúróṣinṣin dúró àti láti tì wọ́n lẹ́yìn.

15. Ǹjẹ́ o gbà gbọ́ pé Jèhófà lóye ipò rẹ? Kí nìdí?

15 Bóyá o ń fara da àìsàn, àtakò látọ̀dọ̀ ọkọ tàbí aya tó jẹ́ aláìgbàgbọ́, ẹrù iṣẹ́ tó wúwo nínú ìdílé, tàbí àwọn ìṣòro líle koko mìíràn. Jèhófà mọ ibi tágbára wa mọ, ó sì mọ ipò táa wà, ó sì nífẹ̀ẹ́ wa nítorí ìsapá àtọkànwá táa ń ṣe láti sìn ín. Àní ó nífẹ̀ẹ́ wa, kódà bí ohun táa bá lè ṣe tiẹ̀ kéré sí ohun táwọn ẹlòmíràn ń ṣe. (Gálátíà 6:4) Jèhófà mọ̀ pé aláìpé ni wa, kì í sì í retí pé ká ṣe ju agbára wa lọ. (Sáàmù 147:11) Bí a bá sa gbogbo ipá wa, a lè ní ìdánilójú pé a ṣe iyebíye lójú Ọlọ́run, àti pé kò ní gbàgbé àwọn ohun táa fi ìgbàgbọ́ ṣe.—Lúùkù 21:1-4.

16. Ọ̀nà wo ni gbogbo ìjọ gbà ń kópa nínú sísọni di ọmọ ẹ̀yìn?

16 Tún rántí pé iṣẹ́ àjùmọ̀ṣe ni iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn jẹ́. Kò sí ẹnì kan ṣoṣo tó lè dá sọni di ọmọ ẹ̀yìn, bí ẹ̀kán omi òjò kan ṣoṣo kò ṣe lè mú kí irúgbìn kan dàgbà. Lóòótọ́, ó lè jẹ́ Ẹlẹ́rìí kan ló bá olùfìfẹ́hàn kan pàdé, tó sì bá a ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Àmọ́, gbàrà tí ẹni tuntun yẹn bá ti wá sí Gbọ̀ngàn Ìjọba ni gbogbo ìjọ ti ń ràn án lọ́wọ́ láti mọ òtítọ́. Ọ̀yàyà ẹgbẹ́ àwọn ará ń fi ipa tí ẹ̀mí Ọlọ́run ń kó hàn. (1 Kọ́ríńtì 14:24, 25) Àwọn ọmọdé àtàwọn ọ̀dọ́langba ń sọ̀rọ̀ tó ń tani jí, tó ń jẹ́ kí ẹni tuntun náà rí i pé àwọn ọ̀dọ́ tiwa yàtọ̀ sí àwọn ọ̀dọ́ tó wà nínú ayé. Àwọn tó ń ṣàìsàn, àwọn tó jẹ́ aláìlera, àtàwọn arúgbó tó wà nínú ìjọ ń kọ́ àwọn ẹni tuntun ní ohun tó túmọ̀ sí láti ní ìfaradà. Láìka ọjọ́ orí tàbí ibi tí agbára wa mọ sí, gbogbo wa ló ń kó ipa pàtàkì nínú ríran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ bí ìfẹ́ tí wọ́n ní fún Bíbélì ṣe ń jinlẹ̀ sí i, tí wọ́n sì ń tẹ̀ síwájú dórí ṣíṣe batisí. Gbogbo wákàtí táa bá lò nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà, gbogbo ìpadàbẹ̀wò táa bá ṣe, gbogbo ìjíròrò táa bá ní pẹ̀lú olùfìfẹ́hàn kan ní Gbọ̀ngàn Ìjọba lè dà bí ohun tí kò já mọ́ nǹkan kan, àmọ́ ó jẹ́ ara iṣẹ́ ńláǹlà tí Jèhófà ń ṣe àṣeparí rẹ̀.

17, 18. (a) Yàtọ̀ sí kíkópa nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, báwo la ṣe lè nípìn-ín nínú ayọ̀ tó wà nínú fífúnni? (b) Nígbà táa bá kópa nínú ayọ̀ tó wà nínú fífúnni, ta là ń fara wé?

17 Àmọ́ ṣá o, yàtọ̀ sí kíkópa nínú iṣẹ́ pàtàkì ti sísọni di ọmọ ẹ̀yìn, àwa gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni tún máa ń nípìn-ín nínú ayọ̀ fífúnni láwọn ọ̀nà mìíràn. A lè ya àwọn owó kan sọ́tọ̀ láti fi ṣètìlẹ́yìn fún ìjọsìn mímọ́ àti láti fi ran àwọn aláìní lọ́wọ́. (Lúùkù 16:9; 1 Kọ́ríńtì 16:1, 2) A lè wá àwọn àǹfààní táa fi lè fi ẹ̀mí aájò àlejò hàn sí àwọn ẹlòmíràn. (Róòmù 12:13) A lè làkàkà láti “ṣe ohun rere sí gbogbo ènìyàn, ṣùgbọ́n ní pàtàkì sí àwọn tí ó bá wa tan nínú ìgbàgbọ́.” (Gálátíà 6:10) Àti pé, a lè fún àwọn ẹlòmíràn ní nǹkan láwọn ọ̀nà kéékèèké àmọ́ tó ṣe pàtàkì—bíi lẹ́tà, ká tẹ̀ wọ́n láago, ká fún wọn lẹ́bùn, ká bá wọn ṣe àwọn iṣẹ́ kan, tàbí ká fún wọn ní ọ̀rọ̀ ìṣírí.

18 Nípa fífúnni, a ń fi hàn pé a ń fara wé Baba wa ọ̀run. A tún ń fi ìfẹ́ ará táa ní hàn, èyí tó jẹ́ àmì táa fi ń dá àwọn Kristẹni tòótọ́ mọ̀. (Jòhánù 13:35) Rírántí àwọn nǹkan wọ̀nyí lè ràn wá lọ́wọ́ láti nípìn-ín nínú ayọ̀ tó wà nínú fífúnni.

Ǹjẹ́ O Lè Ṣàlàyé?

• Báwo ni Jèhófà àti Jésù ṣe fi àpẹẹrẹ fífúnni nípa tẹ̀mí lélẹ̀?

• Báwo la ṣe lè ní àwọn ọ̀rẹ́ tó máa wà títí ayérayé?

• Àwọn ìgbésẹ̀ wo la lè gbé láti mú kí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa túbọ̀ kẹ́sẹ járí?

• Báwo ni gbogbo àwọn tó wà nínú ìjọ ṣe lè kópa nínú ayọ̀ tó wà nínú fífúnni?

[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]

Nígbà táwọn ọmọ bá gba ẹ̀kọ́, àwọn òbí máa ń ní ayọ̀ ńláǹlà àti ìtẹ́lọ́rùn

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 15]

Àwọn tí a bá sọ di ọmọ ẹ̀yìn lè di ojúlówó ọ̀rẹ́

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 16]

Jèhófà ń bá wa ru ẹrù wa ní ọjọ́ ogbó

[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 17]

A máa ń ní ayọ̀ tó wà nínú fífúnni láwọn ọ̀nà kéékèèké, àmọ́ tó ṣe pàtàkì