Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

‘Ìbùkún Wà Fún Olódodo’

‘Ìbùkún Wà Fún Olódodo’

‘Ìbùkún Wà Fún Olódodo’

DÁFÍDÌ onísáàmù sọ ní ọjọ́ ogbó rẹ̀ pé: “Èmi ti jẹ́ ọ̀dọ́ rí, mo sì ti darúgbó, síbẹ̀síbẹ̀, èmi kò tíì rí i kí a fi olódodo sílẹ̀ pátápátá, tàbí kí ọmọ rẹ̀ máa wá oúnjẹ kiri.” (Sáàmù 37:25) Jèhófà Ọlọ́run fẹ́ràn àwọn olódodo, ó sì ń tọ́jú wọn gidigidi. Nínú Bíbélì, Ọ̀rọ̀ rẹ̀, ó rọ àwọn olùjọsìn tòótọ́ pé kí wọ́n máa wá òdodo.—Sefanáyà 2:3.

Jíjẹ́ olódodo túmọ̀ sí títẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run tó sọ pé ohun kan jẹ́ rere tàbí búburú. Orí kẹwàá ìwé Òwe inú Bíbélì rọ̀ wá pé ká máa gbé níbàámu pẹ̀lú ìfẹ́ Ọlọ́run, ó sì tọ́ka sí àwọn ìbùkún tẹ̀mí yanturu tí àwọn tó ń ṣe bẹ́ẹ̀ ń gbádùn. Lára ìbùkún wọ̀nyí ni ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí tó dọ́ṣọ̀, iṣẹ́ tí ń mérè wá tó sì ń tẹ́ni lọ́rùn, àti àjọṣe tó gbámúṣé pẹ̀lú Ọlọ́run àtàwọn èèyàn. Nítorí náà, ẹ jẹ́ ká gbé Òwe 10:1-14 yẹ̀ wò.

Ohun Ìwúrí Ńláǹlà

Ọ̀rọ̀ táa kọ́kọ́ kà ní orí yìí jẹ́ ká mọ ẹni tó kọ apá tó tẹ̀ lé e nínú ìwé Òwe. Ó kà pé: “Òwe Sólómọ́nì.” Nígbà tí Sólómọ́nì Ọba Ísírẹ́lì ìgbàanì ń sọ ohun tí yóò fún wa níṣìírí láti tọ ipa ọ̀nà títọ́, ó sọ pé: “Ọlọ́gbọ́n ọmọ ni ẹni tí ń mú kí baba yọ̀, arìndìn ọmọ sì ni ẹ̀dùn-ọkàn ìyá rẹ̀.”Òwe 10:1.

Ẹ wo bí inú àwọn òbí ṣe máa ń bà jẹ́ tó, nígbà tí ọ̀kan lára àwọn ọmọ wọn bá fi ìjọsìn Ọlọ́run tòótọ́ àti alààyè sílẹ̀! Ẹ̀dùn ọkàn ìyá nìkan ni ọlọgbọ́n ọba náà mẹ́nu kàn, ó ṣeé ṣe kó jẹ́ nítorí pé ẹ̀dùn ọkàn tìyá máa ń pọ̀ ju ti bàbá lọ. Bó ṣe rí gẹ́lẹ́ nìyẹn nínú ọ̀ràn Doris. a Ó ròyìn pé: “Nígbà tí ọmọkùnrin wa ẹni ọdún mọ́kànlélógún kúrò nínú òtítọ́, ìbànújẹ́ dorí èmi àti Frank, ọkọ mi, kodò. Ìmí ẹ̀dùn tèmi pọ̀ ju ti Frank lọ. Ọgbẹ́ náà ò sì tíì lọ, kódà lẹ́yìn tí ọdún méjìlá ti kọjá.”

Ohun tí àwọn ọmọ ṣe lè kó ìbànújẹ́ bá bàbá wọn, ó sì lè kó ẹ̀dùn ọkàn bá ìyá wọn. Ǹjẹ́ ká hùwà ọlọgbọ́n, ká sì mú inú àwọn òbí wa dùn. Àní jù bẹ́ẹ̀ lọ, ẹ jẹ́ ká múnú Jèhófà, Baba wa ọ̀run dùn.

‘A Óò Tẹ́ Ọkàn Olódodo Lọ́rùn’

Ọba náà sọ pé: “Àwọn ìṣúra ẹni burúkú kì yóò ṣàǹfààní, ṣùgbọ́n òdodo ni yóò dáni nídè lọ́wọ́ ikú.” (Òwe 10:2) Ó yẹ kí ọ̀rọ̀ yìí ró kìì lọ́kàn àwọn Kristẹni tòótọ́ tí ń gbé ní apá ìparí àkókò òpin. (Dáníẹ́lì 12:4) Ìparun ayé aláìṣèfẹ́ Ọlọ́run yìí ti sún mọ́lé. Kò sí ètò ààbò kankan téèyàn lè ṣe—ì báà jẹ́ ti dúkìá, ti owó, tàbí ti ológun—tí yóò lè dáàbò boni nígbà “ìpọ́njú ńlá” tí ń bọ̀. (Ìṣípayá 7:9, 10, 13, 14) Kìkì “àwọn adúróṣánṣán ni àwọn tí yóò máa gbé ilẹ̀ ayé, àwọn aláìlẹ́bi sì ni àwọn tí a óò jẹ́ kí ó ṣẹ́ kù sórí rẹ̀.” (Òwe 2:21) Nítorí náà, ǹjẹ́ kí a máa bá a nìṣó ní “wíwá ìjọba náà àti òdodo [Ọlọ́run] lákọ̀ọ́kọ́.”—Mátíù 6:33.

Kì í ṣe ìgbà tí ayé tuntun táa ṣèlérí bá dé nìkan làwọn ìránṣẹ́ Jèhófà yóò tó bẹ̀rẹ̀ sí gbádùn ìbùkún Ọlọ́run. “Jèhófà kì yóò jẹ́ kí ebi pa ọkàn olódodo, ṣùgbọ́n ìfàsí-ọkàn àwọn ẹni burúkú ni yóò tì kúrò.” (Òwe 10:3) Jèhófà ti pèsè ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí nípasẹ̀ “ẹrú olóòótọ́ àti olóye.” (Mátíù 24:45) Dájúdájú, olódodo ní ìdí láti “fi ìdùnnú ké jáde nítorí ipò rere ọkàn-àyà.” (Aísáyà 65:14) Ìmọ̀ ń dùn mọ́ ọkàn rẹ̀. Inú rẹ̀ máa ń dùn sí wíwá àwọn ìṣúra tẹ̀mí. Ẹni burúkú kò ní irú ayọ̀ yẹn.

‘Jíjẹ́ Aláápọn Ń Sọni Di Ọlọ́rọ̀’

A tún ń bù kún olódodo lọ́nà mìíràn. “Ẹni tí ń fi ọwọ́ dẹngbẹrẹ ṣiṣẹ́ yóò jẹ́ aláìnílọ́wọ́, ṣùgbọ́n ọwọ́ ẹni aláápọn ni yóò sọni di ọlọ́rọ̀. Ọmọ tí ń fi ìjìnlẹ̀ òye hùwà ń kó jọ ní ìgbà ẹ̀ẹ̀rùn; ọmọ tí ń hùwà lọ́nà tí ń tini lójú sùn lọ fọnfọn nígbà ìkórè.”Òwe 10:4, 5.

Ọ̀rọ̀ tí ọba sọ yìí nítumọ̀ gan-an fáwọn òṣìṣẹ́, àgàgà nígbà ìkórè. Ìgbà ìkórè kì í ṣe ìgbà ṣíṣe ìmẹ́lẹ́. Ìgbà iṣẹ́ àṣekára, iṣẹ́ àṣeṣúlẹ̀ ni. Àní sẹ́, àkókò kánjúkánjú ni.

Kì í ṣe kíkórè ọkà, bí kò ṣe kíkórè àwọn èèyàn ni Jésù ní lọ́kàn nígbà tó sọ fáwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ pé: “Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè [Jèhófà Ọlọ́run] láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Mátíù 9:35-38) Lọ́dún 2000, àwọn tó wá sí Ìṣe Ìrántí ikú Jésù lé ní mílíọ̀nù mẹ́rìnlá—wọ́n pọ̀ ju ìlọ́po méjì iye àwọn Ẹlẹ́rìí Jèhófà. Ta ló wá lè jiyàn pé ‘àwọn pápá kò tíì funfun fún ìkórè’? (Jòhánù 4:35) Àwọn olùjọsìn tòótọ́ ń bẹ Ọ̀gá ìkórè fún òṣìṣẹ́ púpọ̀ sí i, ṣùgbọ́n láàárín àkókò kan náà, wọ́n ń sa gbogbo ipá wọn nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn níbàámu pẹ̀lú àdúrà wọn. (Mátíù 28:19, 20) Ẹ sì wo bí Jèhófà ti bù kún ìsapá wọn tó! Ní ọdún iṣẹ́ ìsìn 2000, àwọn ẹni tuntun táa batisí lé ní ọ̀kẹ́ mẹ́rìnlá [280,000]. Àwọn wọ̀nyí pẹ̀lú ń làkàkà láti di olùkọ́ni ní Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ǹjẹ́ kí a ní ayọ̀ àti ìtẹ́lọ́rùn ní sáà ìkórè yìí nípa jíjẹ́ kí ọwọ́ wa dí nínú iṣẹ́ sísọni di ọmọ ẹ̀yìn.

‘Ìbùkún Wà fún Orí Rẹ̀’

Sólómọ́nì ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ìbùkún wà fún orí olódodo, ṣùgbọ́n ní ti ẹnu àwọn ẹni burúkú, ó ń bo ìwà ipá mọ́lẹ̀.”Òwe 10:6.

Ìwà ẹni mímọ́ àti olódodo ní ọkàn-àyà máa ń fi hàn pé olódodo ni lóòótọ́. Ọ̀rọ̀ ẹnu rẹ̀ jẹ́ ti ọmọlúwàbí ó sì ń gbéni ró, ìṣesí rẹ̀ dára, ó sì jẹ́ ọ̀làwọ́. Adùn-únbárìn ni. Ẹni iyì—ìyẹn, ẹni ìbùkún—ni irú ẹni bẹ́ẹ̀, ní ti pé àwọn èèyàn ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ ní rere.

Àmọ́, olubi èèyàn jẹ́ oníkèéta tàbí onínú burúkú, bó sì ṣe máa ta jàǹbá fáwọn ẹlòmíì ló ń bá kiri. Ọ̀rọ̀ rẹ̀ lè dùn, ó sì lè “bo ìwà ipá mọ́lẹ̀” nínú ọkàn rẹ̀, ṣùgbọ́n bó pẹ́ bó yá, ó máa yọwọ́ ìjà ṣáá ni, ì báà jẹ́ gídígbò tàbí ọ̀rọ̀ kòbákùngbé. (Mátíù 12:34, 35) Tàbí lọ́nà míì, “ìwà ipá ni yóò bo ẹnu ènìyàn búburú [tàbí pa ènìyàn búburú lẹ́nu mọ́].” (Òwe 10:6, àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé, NW) Èyí túmọ̀ sí pé irú ìwà tí olubi ń hù làwọn èèyàn á máa hù sí i, ìyẹn ni pé wọ́n á sọ ọ́ dọ̀tá. Èyí á wá pa á lẹ́nu mọ́, tí kò fi ní lẹ́nu ọ̀rọ̀. Ìbùkún wo ni irú ẹni bẹ́ẹ̀ lè retí látọ̀dọ̀ àwọn ẹlòmíì?

Ọba Ísírẹ́lì kọ̀wé pé: “Ìrántí olódodo ni a ó bù kún, ṣùgbọ́n orúkọ àwọn ẹni burúkú yóò jẹrà.” (Òwe 10:7) Àwọn ẹlòmíì, pàápàá jù lọ Jèhófà Ọlọ́run, máa ń rántí olódodo sí rere. Nítorí pé Jésù ṣòtítọ́ dójú ikú, ó “jogún orúkọ tí ó ta” tàwọn áńgẹ́lì “yọ.” (Hébérù 1:3, 4) Lónìí, àwọn Kristẹni tòótọ́ ń rántí àwọn ọkùnrin àtobìnrin olóòótọ́ tó gbé ayé kí ẹ̀sìn Kristẹni tó dé gẹ́gẹ́ bí àwọn ẹni yíyẹ láti fara wé. (Hébérù 12:1, 2) Ẹ wo bí èyí ṣe yàtọ̀ sí orúkọ àwọn ẹni burúkú tó, èyí tó máa ń di ohun ìríra, táwọn èèyàn kì í fẹ́ gbọ́ sétí! Bẹ́ẹ̀ ni o, “orúkọ ni ó yẹ ní yíyàn dípò ọ̀pọ̀ yanturu ọrọ̀; ojú rere sàn ju fàdákà àti wúrà pàápàá.” (Òwe 22:1) Ǹjẹ́ ká ní orúkọ rere lọ́dọ̀ Jèhófà àtàwọn èèyàn ẹlẹgbẹ́ wa.

‘Olùpàwàtítọ́mọ́ Yóò Máa Rìn Nínú Ààbò’

Sólómọ́nì fi ìyàtọ̀ tó wà láàárín ọlọgbọ́n àti òmùgọ̀ hàn, ó ní: “Ẹni tí ó gbọ́n ní ọkàn-àyà yóò tẹ́wọ́ gba àwọn àṣẹ, ṣùgbọ́n ẹni tí ó jẹ́ òmùgọ̀ ní ètè rẹ̀ ni a ó tẹ̀ mọ́lẹ̀.” (Òwe 10:8) Ẹni tó gbọ́n mọ̀ pé “kì í ṣe ti ènìyàn tí ń rìn àní láti darí àwọn ìṣísẹ̀ ara rẹ̀.” (Jeremáyà 10:23) Ó mọ ìjẹ́pàtàkì wíwá ìtọ́sọ́nà Jèhófà, ó sì ń fi tọkàntọkàn tẹ̀ lé àwọn àṣẹ Ọlọ́run. Àmọ́, òye òtítọ́ pàtàkì yìí kò yé ẹni tó jẹ́ òmùgọ̀ ní ètè. Ọ̀rọ̀ òpònú tó ń sọ kiri ló máa kó bá a.

Olódodo tún ní irú ààbò kan tí olubi kò ní. “Ẹni tí ó bá ń rìn nínú ìwà títọ́ yóò máa rìn nínú ààbò, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ń ṣe àwọn ọ̀nà ara rẹ̀ ní wíwọ́ yóò sọ ara rẹ̀ di mímọ̀. Ẹni tí ń ṣẹ́jú yóò ṣokùnfà ìrora, ẹni tí ó sì jẹ́ òmùgọ̀ ní ètè rẹ̀ ni a ó tẹ̀ mọ́lẹ̀.”Òwe 10:9, 10.

Olùpàwàtítọ́mọ́ kì í ṣàbòsí. Ẹni iyì ni lójú àwọn èèyàn, wọ́n sì gbẹ́kẹ̀ lé e. Òṣìṣẹ́ tí kì í ṣe màgòmágó làwọn èèyàn ń fẹ́, irú ẹni bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń fún ní ọ̀pọ̀ ẹ̀rù iṣẹ́. Mímọ̀ táwọn èèyàn mọ̀ ọ́n sí aláìlábòsí kò ní jẹ́ kí iṣẹ́ bọ́ lọ́wọ́ ẹ̀, àtiríṣẹ́ kò sì ní ṣòro fún un kódà nígbà tíṣẹ́ bá wọ́n lóde. Jù bẹ́ẹ̀ lọ, ìwà àìlábòsí rẹ̀ ń jẹ́ kí ilé rẹ̀ tù ú lára, kí ó sì tòrò. (Sáàmù 34:13, 14) Àjọṣe tó dán mọ́rán wà láàárín òun àtàwọn aráalé rẹ̀. Ní tòótọ́, ìwà títọ́ ń dáàbò boni.

Ọ̀ràn ò rí bẹ́ẹ̀ fẹ́ni tó di oníjìbìtì nítorí èrè onímọtara-ẹni-nìkan. Ẹlẹ́tàn lè gbìyànjú láti fi ọ̀rọ̀ àrékérekè tàbí ìfarasọ̀rọ̀ tan àwọn èèyàn kí wọ́n má bàa mọ̀ pé irọ́ lòun ń pa. (Òwe 6:12-14) Bó ṣe ń ṣẹ́jú wìíwìí, pẹ̀lú inú burúkú tàbí ètekéte, lè kó àwon tó tàn jẹ sí yọ́ọ́yọ́ọ́. Àmọ́ bó pẹ́ bó yá, àṣírí ìwà màgòmágó rẹ̀ á tú. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Ẹ̀ṣẹ̀ àwọn kan a máa fara hàn gbangba, ní ṣíṣamọ̀nà sí ìdájọ́ ní tààràtà, ṣùgbọ́n ní ti àwọn ẹlòmíràn, ẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹ̀lú a máa fara hàn kedere lẹ́yìn-ọ̀-rẹ̀yìn. Lọ́nà kan náà pẹ̀lú, àwọn iṣẹ́ àtàtà a máa fara hàn gbangba, àwọn tí kò sì jẹ́ bẹ́ẹ̀ ni a kò lè fi pa mọ́.” (1 Tímótì 5:24, 25) Ẹni yòówù kó máa ṣe irú nǹkan bẹ́ẹ̀—ì báà jẹ́ òbí, ọ̀rẹ́, ọkọ tàbí aya ẹni, tàbí ojúlùmọ̀—kò lè mú un jẹ, àṣírí alábòsí náà máa tú ṣáá ni. Ta ló lè fọkàn tán alábòsí èèyàn?

‘Ẹnu Rẹ̀ Jẹ́ Orísun Ìyè’

Sólómọ́nì sọ pé: “Ẹnu olódodo jẹ́ orísun ìyè; ṣùgbọ́n ní ti ẹnu àwọn ẹni burúkú, ó ń bo ìwà ipá mọ́lẹ̀.” (Òwe 10:11) Ọ̀rọ̀ ẹnu lè woni sàn, ó sì lè ba tẹni jẹ́. Ó lè tuni lára, kí ó sì múni lórí wú, tàbí kí ó múni sorí kodò.

Ọba Ísírẹ́lì ṣàlàyé ẹ̀mí tó wà nídìí ọ̀rọ̀ tó ń tẹnu wa jáde, ó ní: “Ìkórìíra ní ń ru asọ̀ sókè, ṣùgbọ́n ìfẹ́ a máa bo gbogbo ìrélànàkọjá pàápàá mọ́lẹ̀.” (Òwe 10:12) Ìkórìíra máa ń fa asọ̀ láàárín ẹgbẹ́ òun ọ̀gbà, ó máa ń fa gbọ́nmi-si omi-ò-to. Àwọn tó fẹ́ràn Jèhófà gbọ́dọ̀ fa ìkórìíra tu kúrò nínú ìgbésí ayé wọn. Báwo? Nípa fífi ìfẹ́ rọ́pò rẹ̀. “Ìfẹ́ a máa bo ògìdìgbó ẹ̀ṣẹ̀ mọ́lẹ̀.” (1 Pétérù 4:8) Ìfẹ́ a máa “mú ohun gbogbo mọ́ra,” ìyẹn ni pé “ó ń bo ohun gbogbo mọ́lẹ̀.” (1 Kọ́ríńtì 13:7; Kingdom Interlinear) Ìfẹ́ tí Ọlọ́run fẹ́ kí a ní kì í retí ìjẹ́pípé látọ̀dọ̀ ẹ̀dá aláìpé. Kàkà tí a ó fi máa polongo àṣìṣe àwọn ẹlòmíì, irú ìfẹ́ yẹn yóò ràn wá lọ́wọ́ láti gbójú fo àṣìṣe wọn, àfi tó bá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ wíwúwo. Àní ìfẹ́ máa ń jẹ́ ká ní àmúmọ́ra nígbà tí wọ́n bá hùwà àìdáa sí wa nínú iṣẹ́ òjíṣẹ́ pápá, níbi iṣẹ́ wa, tàbí níléèwé.

Ọlọgbọ́n ọba náà ń bá ọ̀rọ̀ rẹ̀ lọ pé: “Ètè olóye ni a ti ń rí ọgbọ́n, ṣùgbọ́n ọ̀pá ni fún ẹ̀yìn ẹni tí ọkàn-àyà kù fún.” (Òwe 10:13) Ọgbọ́n tí olóye ní ń tọ́ ìṣísẹ̀ rẹ̀. Ọ̀rọ̀ tí ń gbéni ró tó ń tẹnu rẹ̀ jáde ń ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti rìn ní ọ̀nà òdodo. Kò dìgbà táa bá fi ipá—ìyẹn ọ̀pá ìbáwí—mú òun àtàwọn tó ń fetí sí i, kí wọ́n tó mọ̀ pé ó yẹ káwọn máa tọ ọ̀nà títọ́.

“Fi Ìmọ̀ Ṣúra”

Kí ló ń jẹ́ kí ọ̀rọ̀ wa jẹ́ ‘omi jíjìn ti ọgbọ́n,’ dípò ọ̀gbàrá ẹjọ́ wẹ́wẹ́? (Òwe 18:4) Sólómọ́nì dáhùn, ó ní: “Àwọn ọlọ́gbọ́n ni ó ń fi ìmọ̀ ṣúra, ṣùgbọ́n ẹnu òmùgọ̀ sún mọ́ ìparun.”Òwe 10:14.

Ohun àkọ́kọ́ táa gbọ́dọ̀ ṣe ni pé èrò inú wa gbọ́dọ̀ kún fún ìmọ̀ Ọlọ́run tí ń gbéni ró. Ibì kan ṣoṣo la ti lè rí ìmọ̀ yẹn. Àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù kọ̀wé pé: “Gbogbo Ìwé Mímọ́ ni Ọlọ́run mí sí, ó sì ṣàǹfààní fún kíkọ́ni, fún fífi ìbáwí tọ́ni sọ́nà, fún mímú àwọn nǹkan tọ́, fún bíbániwí nínú òdodo, kí ènìyàn Ọlọ́run lè pegedé ní kíkún, tí a mú gbára dì pátápátá fún iṣẹ́ rere gbogbo.” (2 Tímótì 3:16, 17) A gbọ́dọ̀ fi ìmọ̀ ṣúra, ká sì walẹ̀ jìn nínú Ọ̀rọ̀ Ọlọ́run, bí ìgbà téèyàn ń wá ìṣúra tó fara sin. Ẹ wo bí ìwákiri yẹn ṣe ń mórí yá, tó sì lérè nínú tó!

Kí ọ̀rọ̀ ọgbọ́n lè máa tẹnu wa jáde, ìmọ̀ Ìwé Mímọ́ gbọ́dọ̀ dé inú ọkàn wa pẹ̀lú. Jésù sọ fáwọn tó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ rẹ̀ pé: “Ẹni rere a máa mú ohun rere jáde wá láti inú ìṣúra rere ọkàn-àyà rẹ̀, ṣùgbọ́n ẹni burúkú a máa mú ohun tí í ṣe burúkú jáde wá láti inú ìṣúra burúkú rẹ̀; nítorí lára ọ̀pọ̀ yanturu tí ń bẹ nínú ọkàn-àyà ni ẹnu rẹ̀ ń sọ.” (Lúùkù 6:45) Nítorí náà, gbogbo ìgbà la gbọ́dọ̀ máa ṣàṣàrò lórí ohun tí à ń kọ́. Òótọ́ ni pé ẹ̀kọ́ kíkọ́ àti àṣàrò ṣíṣe gba ìsapá, ṣùgbọ́n irú ìkẹ́kọ̀ọ́ bẹ́ẹ̀ mà ń ṣeni láǹfààní nípa tẹ̀mí o! Kò sídìí tó fi yẹ kí ẹnikẹ́ni tọ ọ̀nà ìparun tí ọlọ́rọ̀ wótòwótò ń tọ̀.

Dájúdájú, ọlọgbọ́n ń ṣe ohun tó tọ́ lójú Ọlọ́run, ó sì ń ní ipa rere lórí àwọn ẹlòmíràn. Ó ń rí ọ̀pọ̀ yanturu oúnjẹ tẹ̀mí jẹ, ó sì ń ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nínú iṣẹ́ Olúwa tó lérè nínú. (1 Kọ́ríńtì 15:58) Nítorí pé ó jẹ́ olùpàwàtítọ́mọ́, ààbò wà lórí rẹ̀, ó sì rí ojú rere Ọlọ́run. Ní tòótọ́, ìbùkún olódodo pọ̀. Ǹjẹ́ kí a máa wá òdodo nípa títẹ̀ lé ìlànà Ọlọ́run tó sọ pé ohun kan jẹ́ rere tàbí búburú.

[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]

a A ti yí orúkọ náà padà.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 25]

Jíjẹ́ aláìlábòsí ń jẹ́ ká ní ìdílé aláyọ̀

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 26]

‘Àwọn ọlọgbọ́n a máa fi ìmọ̀ ṣúra’