Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ṣé Èèyàn Máa Ń Wà Láàyè Lẹ́yìn Ikú?

Ṣé Èèyàn Máa Ń Wà Láàyè Lẹ́yìn Ikú?

Ṣé Èèyàn Máa Ń Wà Láàyè Lẹ́yìn Ikú?

“BÍ ABARAPÁ ènìyàn bá kú, ó ha tún lè wà láàyè bí?” Ohun tí Jóòbù, baba ńlá ìgbàanì béèrè ní nǹkan bí ẹgbẹ̀rún ọdún mẹ́ta àtààbọ̀ [3,500] sẹ́yìn nìyẹn. (Jóòbù 14:14) Fún ẹgbẹẹgbẹ̀rún ọdún ni ìbéèrè yìí ti ń da ìran èèyàn láàmú. Jálẹ̀ ọ̀pọ̀ ọdún ni àwọn èèyàn níbi gbogbo ti ronú lórí kókó yìí, tí wọ́n sì ti gbé onírúurú àbá jáde.

Ọ̀pọ̀ àwọn aláfẹnujẹ́ Kristẹni ló gbà gbọ́ pé ọ̀run rere àti ọ̀run àpáàdì wà. Àwọn ẹlẹ́sìn Híńdù ní tiwọn gba àtúnwáyé gbọ́. Nígbà tí baálẹ̀ náà, Muawiyah, tó jẹ́ olùrànlọ́wọ́ ní ibùdó ẹ̀kọ́ nípa ẹ̀sìn Ìsìláàmù kan, ń ṣàlàyé èrò àwọn Mùsùlùmí, ó sọ pé: “Àwa gbà gbọ́ pé ọjọ́ ìdájọ́ kan yóò wà lẹ́yìn ikú, nígbà tí a máa wá síwájú Ọlọ́run, ìyẹn Allah, tí yóò sì dà bí ìgbà tí a wọ kóòtù.” Gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ ẹ̀sìn Ìsìláàmù, ṣe ni Allah yóò gbé ìgbésí ayé olúkúlùkù yẹ̀ wò, tí yóò sì yan onítọ̀hún sí àlùjánnà tàbí sínú iná àjóòkú.

Ní Sri Lanka, ṣe ni àwọn ẹlẹ́sìn Búdà àti Kátólíìkì máa ń ṣí gbogbo ilẹ̀kùn àti fèrèsé sílẹ̀ gbayawu nígbà tí ẹnì kan bá kú nínú agboolé wọn. Wọ́n á tan àtùpà kan, wọ́n á sì tẹ́ òkú náà sínú pósí, wọ́n á kọ ẹsẹ̀ rẹ̀ síhà ẹnu ọ̀nà àbájáde. Ìgbàgbọ́ wọn ni pé ṣíṣe báyìí yóò mú kó rọrùn fún ẹ̀mí òkú náà láti jáde.

Gẹ́gẹ́ bí Ronald M. Berndt, ti Yunifásítì Western Australia, ti sọ, àwọn Atẹ̀lúdó ará Ọsirélíà gbà gbọ́ pé, “a kò lè pa ẹ̀mí àwọn èèyàn run.” Àwọn ẹ̀yà kan nílẹ̀ Áfíríkà gbà gbọ́ pé, lẹ́yìn ikú, ṣe ni àwọn èèyàn yẹpẹrẹ máa ń di àkúdàáyà, ṣùgbọ́n àwọn gbajúmọ̀ a di òòṣà àkúnlẹ̀bọ tí a ń ké pè gẹ́gẹ́ bí ẹ̀dá ẹ̀mí tí ó jẹ́ aṣáájú àgbègbè náà.

Ní àwọn ilẹ̀ kan, ìgbàgbọ́ tí wọ́n ní nípa ipò tí àwọn òkú wà jẹ́ àyípọ̀ àṣà ìbílẹ̀ àti ti àwọn aláfẹnujẹ́ Kristẹni. Fún àpẹẹrẹ, ó wọ́pọ̀ láàárín àwọn ẹlẹ́sìn Kátólíìkì àti ti Pùròtẹ́sítáǹtì ní Ìwọ̀ Oòrùn Áfíríkà, pé kí a fi nǹkan bo àwọn dígí nígbà tí ẹnì kan bá kú kí ẹnikẹ́ni má bàa wò ó kí ó sì lọ rí ẹ̀mí ẹni tí ó kú náà.

Ní ti gidi, ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni báwọn èèyàn ṣe ń dáhùn ìbéèrè tó sọ pé, ‘Kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà táa bá kú?’ Síbẹ̀, ìdáhùn táa sábà máa ń gbọ́ ni pé: Nǹkan kan lára èèyàn jẹ́ aláìleèkú, ó sì ń wà láàyè lẹ́yìn ikú. Àwọn kan gbà gbọ́ pé ẹ̀mí ni “nǹkan” náà. Fún àpẹẹrẹ, ní àwọn apá ibì kan ní Áfíríkà àti ní Éṣíà àti jákèjádò àgbègbè Pàsífíìkì ní Polynesia, Melanesia, àti Micronesia, ọ̀pọ̀ èèyàn gbà gbọ́ pé ẹ̀mí ló jẹ́ aláìleèkú, kì í ṣe ọkàn. Àní, àwọn èdè kan kò tiẹ̀ ní ọ̀rọ̀ fún “ọkàn.”

Ǹjẹ́ ohun kan táa ń pè ní ẹ̀mí wà nínú alààyè? Ṣé lóòótọ́ ni ẹ̀mí yẹn ń fi ara sílẹ̀ nígbà téèyàn bá kú? Tó bá rí bẹ́ẹ̀, kí ló ń ṣẹlẹ̀ sí ẹ̀mí náà? Ìrètí wo ló sì wà fún àwọn òkú? A ò gbọ́dọ̀ dágunlá sí ìbéèrè wọ̀nyí. Ohun yòówù kí àṣà tàbí ẹ̀sìn rẹ jẹ́, kò sẹ́ni wà tí ikú kò lè pa. Ìdí nìyẹn tí ọ̀ràn náà fi kàn ọ́ gbọ̀ngbọ̀n. A gbà ọ́ níyànjú láti gbé ọ̀ràn náà yẹ̀ wò.