Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

“Ṣé Òótọ́ Ni Ọlọ́run Ń Finá Sun Àwọn Èèyàn Ní Ọ̀run Àpáàdì?”

“Ṣé Òótọ́ Ni Ọlọ́run Ń Finá Sun Àwọn Èèyàn Ní Ọ̀run Àpáàdì?”

“Ṣé Òótọ́ Ni Ọlọ́run Ń Finá Sun Àwọn Èèyàn Ní Ọ̀run Àpáàdì?”

“Ṣé iléèwé ẹ̀kọ́ ìsìn lẹ̀ ń lọ ni?”

Ìbéèrè yìí bá Joel àti Carl lójijì. Ńṣe làwọn ọ̀dọ́kùnrin méjèèjì yìí—tí wọ́n ti yọ̀ǹda ara wọn láti sìn ní orílé iṣẹ́ àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà ní Brooklyn, New York—ń yẹ àwọn ìwé wò nínú ilé ìtàwé kan nítòsí. Bí Joel ṣe ń yẹ àwọn ìwé atọ́ka Bíbélì wò, Carl ń sọ fún un nípa ìjíròrò kan tó gbádùn nínú iṣẹ́ ìwàásù. Ọ̀rọ̀ wọn ń ta sí ọkùnrin kan tó wà nítòsí létí, bó ṣe wá bá wọn nìyẹn.

Àmọ́ ohun tó ń jẹ ọkùnrin náà lọ́kàn kì í ṣọ̀ràn bóyá àwọn ọ̀dọ́kùnrin wọ̀nyí ń lọ sí iléèwé ẹ̀kọ́ ìsìn tàbí bẹ́ẹ̀ kọ́. Ó ṣàlàyé pé: “Júù ni mí, àwọn ọ̀rẹ́ mi kan tí wọ́n jẹ́ Kristẹni sì ń sọ fún mi pé inú iná ọ̀run àpáàdì ni mò ń lọ, wọ́n ní torí pé àwọn Júù kọ Jésù sílẹ̀. Ọ̀rọ̀ yìí dà mí lọ́kàn rú gan-an ni. Kí Ọlọ́run onífẹ̀ẹ́ máa firú ìyà yẹn jẹni kò bọ́ sí i rárá o. Ṣé òótọ́ ni Ọlọ́run ń finá sun àwọn èèyàn ní ọ̀run àpáàdì?”

Joel àti Carl sọ fún ọkùnrin olóòótọ́ ọkàn yìí pé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tọkàntọkàn làwọn. Wọ́n fi hàn án nínú Ìwé Mímọ́ pé àwọn òkú kò mọ nǹkan kan, wọ́n kàn ń sùn nínú ikú ni, àjíǹde ni wọ́n ń dúró dè. Nítorí náà, kò sẹ́ni tó ń dá wọn lóró, wọn ò sì sí nínú ọ̀run àpáàdì olóró. (Sáàmù 146:3, 4; Oníwàásù 9:5, 10; Dáníẹ́lì 12:13; Jòhánù 11:11-14, 23-26) Lẹ́yìn tí wọ́n parí ìjíròrò tó gba ìṣẹ́jú márùndínláàádọ́ta náà, ọkùnrin yìí fún Joel àti Carl ní àdírẹ́sì rẹ̀, ó sì béèrè fún ìsọfúnni púpọ̀ sí i nípa kókó náà.

Ká ní ibi ìjoró nínú iná ni ọ̀run àpáàdì ni, ǹjẹ́ ẹnikẹ́ni á jẹ́ sọ pé kí wọ́n jẹ́ kí òun lọ síbẹ̀? Ṣùgbọ́n Jóòbù baba ńlá náà, tó fẹ́ bọ́ nínú wàhálà rẹ̀, bẹ̀bẹ̀ pé: “A! iwọ iba fi mi pamọ ni ipo-okú [ọ̀run àpáàdì], ki iwọ ki o fi mi pamọ, titi ibinu rẹ yio fi rekọja.” (Jóòbù 14:13, Bibeli Mimọ) Ó dájú pé Jóòbù kò gbà pé ibi ìdálóró ni ọ̀run àpáàdì jẹ́. Kàkà bẹ́ẹ̀, ààbò ló fẹ́ wá lọ síbẹ̀. Ikú jẹ́ ṣíṣàìsí, isà òkú aráyé sì ni ọ̀run àpáàdì tí Bíbélì sọ̀rọ̀ nípa rẹ̀.

Tóo bá fẹ́ mọ̀ sí i nípa ohun tó ń ṣẹlẹ̀ sí wa nígbà táa bá kú àti ìrètí tí ń bẹ lẹ́yìn ikú, àá fẹ́ kóo tẹ́wọ́ gba àǹfààní táa nawọ́ rẹ̀ sí gbogbo èèyàn nísàlẹ̀ yìí.