Ẹ Jẹ́ Òṣìṣẹ́ Tí Ń fi Tayọ̀tayọ̀ Kórè!
Ẹ Jẹ́ Òṣìṣẹ́ Tí Ń fi Tayọ̀tayọ̀ Kórè!
“Ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.”—MÁTÍÙ 9:37, 38.
1. Kí ló ń jẹ́ kó ṣeé ṣe fún wa láti máa bá ṣíṣe ìfẹ́ Ọlọ́run nìṣó?
NÍGBÀ táa bá rántí ọjọ́ táa ṣe ìrìbọmi gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ Jèhófà, ì báà jẹ́ ní ọdún díẹ̀ tàbí ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn, bí àná ló máa ń rí. Yíyin Jèhófà wá di ohun àkọ́múṣe nínú ìgbésí ayé wa táa yà sí mímọ́ fún un. Iṣẹ́ ìsìn aláyọ̀ sí Jèhófà wá di ohun tó wà ní góńgó ẹ̀mí wa, báa ṣe ń ra àkókò tó rọgbọ padà ká lè ran àwọn ẹlòmíì lọ́wọ́ láti gbọ́ ìhìn rere Ìjọba náà kí wọ́n sì tẹ́wọ́ gbà á, tó bá ṣeé ṣe. (Éfésù 5:15, 16) Lóde òní, a rí i pé àkókò máa ń sáré tete nígbà tí ọwọ́ wa bá dí, báa ti ń “ní púpọ̀ rẹpẹtẹ láti ṣe nígbà gbogbo nínú iṣẹ́ Olúwa.” (1 Kọ́ríńtì 15:58) Bó tiẹ̀ jẹ́ pé a máa ń bá ìṣòro pàdé nígbà míì, ayọ̀ táa ń ní nínú ṣíṣe ìfẹ́ Jèhófà kì í jẹ́ kó sú wa, kì í jẹ́ kó rẹ̀ wá.—Nehemáyà 8:10.
2. Kí ló ń fún wa láyọ̀ nínú iṣẹ́ ìkórè ìṣàpẹẹrẹ náà?
2 Gẹ́gẹ́ bíi Kristẹni, iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí là ń ṣe. Jésù Kristi fi kíkó àwọn èèyàn jọ fún ìyè àìnípẹ̀kun wé ìkórè. (Jòhánù 4:35-38) Níwọ̀n bí a ti ń kópa nínú irú iṣẹ́ ìkórè bẹ́ẹ̀, ṣíṣàyẹ̀wò ayọ̀ àwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ tí wọ́n jẹ́ olùkórè yóò fún wa níṣìírí. A óò ṣàtúnyẹ̀wò kókó mẹ́ta tó ń fún wa láyọ̀ nínú iṣẹ́ ìkórè tòde òní. Kókó wọ̀nyí ni (1) iṣẹ́ ìrètí tí à ń jẹ́, (2) báa ṣe ń ṣàṣeyọrí nínú wíwá àwọn èèyàn kàn, àti (3) ẹ̀mí àlàáfíà táwa olùkórè ní.
A Rán Wa Jáde Láti Lọ Kórè
3. Ọ̀nà wo làwọn ọmọlẹ́yìn Jésù àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ fi jẹ́ aláyọ̀?
3 Ìgbésí ayé àwọn olùkórè àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀—pàápàá jù lọ àwọn àpọ́sítélì Jésù mọ́kànlá tó jẹ́ olóòótọ́—mà kúkú yí padà lọ́jọ́ náà ní ọdún 33 Sànmánì Tiwa o, nígbà tí wọ́n lọ pàdé Kristi lórí òkè kan ní Gálílì lẹ́yìn àjíǹde rẹ̀! (Mátíù 28:16) Àwọn tó pésẹ̀ síbi ìpàdé ọ̀hún á máa lọ sí “èyí tí ó ju ẹ̀ẹ́dẹ́gbẹ̀ta àwọn ará.” (1 Kọ́ríńtì 15:6) Gbọnmọgbọnmọ ni iṣẹ́ tí Jésù gbé lé wọn lọ́wọ́ ń ró létí wọn. Ó sọ fún wọn pé: “Ẹ lọ, kí ẹ sì máa sọ àwọn ènìyàn gbogbo orílẹ̀-èdè di ọmọ ẹ̀yìn, ẹ máa batisí wọn ní orúkọ Baba àti ti Ọmọ àti ti ẹ̀mí mímọ́, ẹ máa kọ́ wọn láti máa pa gbogbo ohun tí mo ti pa láṣẹ fún yín mọ́.” (Mátíù 28:19, 20) Láìfi àtakò gbígbóná janjan pè, ayọ̀ wọn kún nínú iṣẹ́ ìkórè náà bí wọ́n ti ń rí i tí a ń dá ìjọ àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi sílẹ̀ lọ́tùn-ún lósì. Láìpẹ́, ‘wọ́n ti ń wàásù ìhìn rere náà nínú gbogbo ìṣẹ̀dá tí ń bẹ lábẹ́ ọ̀run.’—Kólósè 1:23; Ìṣe 1:8; 16:5.
4. Báwo ni ipò nǹkan ṣe rí nígbà táa rán àwọn ọmọlẹ́yìn Kristi jáde?
4 Láìpẹ́ lẹ́yìn tí Jésù bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ ní Gálílì, ó pe àwọn àpọ́sítélì rẹ̀ méjìlá, ó sì dìídì rán wọn pé kí wọ́n lọ máa kéde pé: “Ìjọba ọ̀run ti sún mọ́lé.” (Mátíù 10:1-7) Òun alára ti “mú ọ̀nà rẹ̀ pọ̀n nínú ìrìn àjò ìbẹ̀wò sí gbogbo àwọn ìlú ńlá àti àwọn abúlé [Gálílì], ó ń kọ́ni nínú àwọn sínágọ́gù wọn, ó sì ń wàásù ìhìn rere ìjọba náà, ó sì ń ṣe ìwòsàn gbogbo onírúurú òkùnrùn àti gbogbo onírúurú àìlera ara.” Àánú àwọn ogunlọ́gọ̀ náà ṣe Jésù, “nítorí a bó wọn láwọ, a sì fọ́n wọn ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́ àgùntàn.” (Mátíù 9:35, 36) Ọ̀ràn náà ká a lára débi pé ó sọ fáwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ pé: “Bẹ́ẹ̀ ni, ìkórè pọ̀, ṣùgbọ́n díẹ̀ ni àwọn òṣìṣẹ́. Nítorí náà, ẹ bẹ Ọ̀gá ìkórè [Jèhófà Ọlọ́run] láti rán àwọn òṣìṣẹ́ jáde sínú ìkórè rẹ̀.” (Mátíù 9:37, 38) Ojú tí Jésù fi wo bó ṣe jẹ́ kánjúkánjú tó láti rí àwọn olùkórè púpọ̀ sí i kò yí padà rárá ní Jùdíà nígbà tó ku oṣù mẹ́fà péré kó parí iṣẹ́ òjíṣẹ́ rẹ̀ orí ilẹ̀ ayé. (Lúùkù 10:2) Ìgbà méjèèjì yìí ló rán àwọn ọmọlẹ́yìn rẹ̀ jáde gẹ́gẹ́ bí olùkórè.—Mátíù 10:5; Lúùkù 10:3.
Iṣẹ́ Ìrètí Tí À Ń Jẹ́
5. Irú iṣẹ́ wo là ń jẹ́?
5 Àwa ìránṣẹ́ Jèhófà òde òní ń fi tayọ̀tayọ̀ dáhùn sí ìpè náà fún àwọn olùkórè púpọ̀ sí i. Kókó kan tó ń fún wa ní ayọ̀ ńláǹlà ni pé a ń jẹ́ iṣẹ́ ìrètí fáwọn oníròbìnújẹ́ ọkàn àtàwọn tó sorí kọ́. Gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù ọ̀rúndún kìíní, ẹ ò rí i pé àǹfààní ńlá la ní láti máa polongo ìhìn rere—ìyẹn iṣẹ́ ìrètí tòótọ́—fáwọn ‘táa bó láwọ, táa sì fọ́n ká bí àwọn àgùntàn tí kò ní olùṣọ́’!
6. Iṣẹ́ wo làwọn àpọ́sítélì ń ṣe ní ọ̀rúndún kìíní?
6 Nígbà tó fi máa di àárín ọ̀rúndún kìíní, àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù ń bá iṣẹ́ ìwàásù ìhìn rere lọ ní pẹrẹu. Ó sì dájú pé iṣẹ́ ìkórè rẹ̀ kẹ́sẹ járí, torí pé nígbà tó ń kọ̀wé sáwọn Kristẹni ní Kọ́ríńtì ní nǹkan bí ọdún 55 Sànmánì Tiwa, ó sọ pé: “Ẹ̀yin ará, mo sọ ìhìn rere náà di mímọ̀ fún yín, èyí tí mo polongo fún yín, tí ẹ̀yin pẹ̀lú gbà, nínú èyí tí ẹ̀yin pẹ̀lú dúró.” (1 Kọ́ríńtì 15:1) Àwọn àpọ́sítélì àtàwọn Kristẹni àkọ́kọ́bẹ̀rẹ̀ yòókù ṣe gudugudu méje nínú iṣẹ́ ìkórè náà. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Bíbélì kò sọ iye àwọn àpọ́sítélì tó la àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ mánigbàgbé tó dé òtéńté rẹ̀ nígbà ìparun Jerúsálẹ́mù já ní ọdún 70 Sànmánì Tiwa, a mọ̀ pé àpọ́sítélì Jòhánù ṣì ń wàásù ní nǹkan bí ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n lẹ́yìn náà.—Ìṣípayá 1:9.
7, 8. Kí ni ìhìn tó kún fún ìrètí táwọn ìránṣẹ́ Jèhófà ń polongo lọ́nà kánjúkánjú ju ti tẹ́lẹ̀ rí lọ?
7 Ẹ̀yìn ìgbà náà ló wá kan àwọn ọ̀rúndún táwọn àlùfáà Kirisẹ́ńdọ̀mù, ìyẹn àwọn apẹ̀yìndà “ọkùnrin oníwà àìlófin,” fi jẹ gàba. (2 Tẹsalóníkà 2:3) Àmọ́, nígbà tí ọ̀rúndún kọkàndínlógún ń parí lọ, àwọn tó fẹ́ máa gbé ìgbésí ayé wọn níbàámu pẹ̀lú ẹ̀sìn Kristẹni ìpilẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìhìn tó ń fúnni ní ìrètí náà kiri, wọ́n ń polongo Ìjọba náà. Àní látìgbà tí ẹ̀dà ìwé ìròyìn yìí kọ́kọ́ jáde (ní July 1879) ni àwọn ọ̀rọ̀ bíi “Tí Ń Pòkìkí Wíwàníhìn-ín Kristi,” tàbí “Tí Ń Pòkìkí Ìjọba Kristi,” tàbí “Tí Ń Kéde Ìjọba Jèhófà” ti wà lára àkọlé rẹ̀.
8 Ọdún 1914 la fìdí Ìjọba ọ̀run ti Ọlọ́run múlẹ̀ ní ọwọ́ Jésù Kristi, a sì ń pòkìkí ìhìn tó kún fún ìrètí náà lọ́nà kánjúkánjú báyìí ju ti tẹ́lẹ̀ rí lọ. Èé ṣe? Nítorí pé ara ìbùkún tí Ìjọba Ọlọ́run yóò mú wá ni òpin tó rọ̀ dẹ̀dẹ̀ báyìí sórí ètò àwọn nǹkan búburú yìí. (Dáníẹ́lì 2:44) Ìhìn wo ló tún dára jùyẹn lọ? Kí ló sì lè fún wa láyọ̀ tó nínípìn-ín nínú kíkéde Ìjọba náà kí “ìpọ́njú ńlá” tó bẹ́ sílẹ̀?—Mátíù 24:21; Máàkù 13:10.
A Ń Wá Wọn Kàn
9. Ìtọ́ni wo ni Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀, kí sì ni ìṣarasíhùwà àwọn èèyàn sí ìhìn rere Ìjọba náà?
9 Kókó míì tó ń fún àwa olùkórè láyọ̀ ni pé a ń wá àwọn tó fẹ́ di ọmọ ẹ̀yìn kàn, wọ́n sì ń dara pọ̀ mọ́ wa nínú iṣẹ́ ìkórè náà. Lẹ́yìn lọ́hùn-ún lọ́dún 31 àti 32 Sànmánì Tiwa, Jésù fún àwọn ọmọ ẹ̀yìn rẹ̀ ní ìtọ́ni pé: “Ìlú ńlá tàbí abúlé èyíkéyìí tí ẹ bá wọ̀, ẹ wá ẹni yíyẹ inú rẹ̀ kàn.” (Mátíù 10:11) Kì í ṣe gbogbo èèyàn lẹni yíyẹ, gẹ́gẹ́ bó ṣe hàn nínú ìhà tí wọ́n kọ sí ìhìn rere Ìjọba náà. Síbẹ̀síbẹ̀, àwọn ọmọ ẹ̀yìn Jésù fìtara wàásù ìhìn rere náà níbikíbi tí wọ́n bá ti rí àwọn èèyàn.
10. Báwo ni Pọ́ọ̀lù ṣe tẹra mọ́ wíwá àwọn ẹni yíyẹ kàn?
10 Lẹ́yìn ikú àti àjíǹde Jésù, wíwá àwọn ẹni yíyẹ kàn ń bá a lọ kíkankíkan. Pọ́ọ̀lù ń bá àwọn Júù fèrò wérò nínú sínágọ́gù wọn, ó tún ń bá àwọn tó bá rí níbi ọjà ní Áténì fèrò wérò pẹ̀lú. Nígbà tó jẹ́rìí lórí òkè Áréópágù ní ìlú ńlá Gíríìkì yẹn, “àwọn ènìyàn kan dara pọ̀ mọ́ ọn, wọ́n sì di onígbàgbọ́, lára wọn pẹ̀lú ni Díónísíù, adájọ́ kan ní kóòtù Áréópágù, àti obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Dámárì, àti àwọn mìíràn ní àfikún sí wọn.” Gbogbo ibi tí Pọ́ọ̀lù lọ ló ti fi àpẹẹrẹ rere lélẹ̀ nínú wíwàásù “ní gbangba àti láti ilé dé ilé.”—Ìṣe 17:17, 34; 20:20.
11. Àwọn ọ̀nà wo la gbà ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ náà ní ọ̀pọ̀ ọdún sẹ́yìn?
11 Ní àwọn ẹ̀wádún díẹ̀ kí ọ̀rúndún kọkàndínlógún tó dópin, àwọn Kristẹni ẹni àmì òróró fi àìṣojo wá àwọn ẹni yíyẹ kàn. Nínú àpilẹ̀kọ kan táa pe àkòrí rẹ̀ ní “A Fòróró Yàn Wá Láti Wàásù,” Zion’s Watch Tower ti July/August 1881, [Gẹ̀ẹ́sì] sọ pé: “Iṣẹ́ wíwàásù ìhìn rere náà . . . ‘fún àwọn ọlọ́kàn tútù’ ń bá a nìṣó—ìyẹn àwọn tó fẹ́ gbọ́ tó sì lè gbọ́, láti lè rí àwọn ajùmọ̀jogún tí í ṣe ara Kristi ṣà lára wọn.” Àwọn tí ń kórè fún Ọlọ́run sábà máa ń lọ bá àwọn èèyàn bí wọ́n ti ń jáde ìsìn ní ṣọ́ọ̀ṣì, wọ́n sì máa ń fún wọn ní àwọn ìwé ìléwọ́ tí ìsọfúnni látinú Ìwé Mímọ́ wà nínú wọn, èyí táa kọ láti ru ìfẹ́ àwọn ẹni yíyẹ sókè. Lẹ́yìn táa fara balẹ̀ gbé ọ̀nà ìjẹ́rìí yìí yẹ̀ wò, láti mọ̀ bóyá ó gbéṣẹ́, Watch Tower May 15, 1903, [Gẹ̀ẹ́sì] rọ àwọn olùkórè pé kí wọ́n máa pín ìwé ìléwọ́ “láti ilé dé ilé, ní ìyálẹ̀ta lọ́jọọjọ́ Sunday.”
12. Báwo la ṣe mú kí iṣẹ́ ìwàásù wa túbọ̀ gbéṣẹ́ sí i? Ṣàlàyé.
12 Ní àwọn ọdún àìpẹ́ yìí, a ti mú iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa gbòòrò sí i nípa lílọ bá àwọn èèyàn níbòmíràn yàtọ̀ sí ilé wọn. Èyí ti kẹ́sẹ járí gan-an ní àwọn orílẹ̀-èdè tí ipò ìṣúnná owó àti ìlépa fàájì kì í ti í jẹ́ ká bá àwọn èèyàn nílé láwọn àkókò táa sábà máa ń wá wọn lọ. Nígbà tí Ẹlẹ́rìí kan ní ilẹ̀ Gẹ̀ẹ́sì àti ẹnì kejì rẹ̀ ṣàkíyèsí pé ọ̀pọ̀ èrò máa ń wọ bọ́ọ̀sì padà sílé lẹ́yìn tí wọ́n wá gbafẹ́ ní etíkun, wọ́n lo ìgboyà, àwọn náà sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ àwọn bọ́ọ̀sì náà, wọ́n ń fi ẹ̀dà Ilé Ìṣọ́ àti Jí! lọ àwọn èrò inú ọkọ̀. Láàárín oṣù kan ṣoṣo, wọ́n pín igba ó lé mọ́kàndínlọ́gbọ̀n [229] ẹ̀dà. Wọ́n ròyìn pé: “Ẹ̀rù kì í bà wá láti jẹ́rìí létíkun tàbí lágbègbè okòwò, kò sì sí ìṣòro tó ń bà wá lẹ́rù, torí a mọ̀ pé Jèhófà kò fi wá sílẹ̀ rí.” Wọ́n ní àwọn èèyàn tí wọ́n lọ ń fún ní ìwé ìròyìn déédéé, wọ́n bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì kan, àwọn méjèèjì sì ti kópa nínú iṣẹ́ aṣáájú ọ̀nà olùrànlọ́wọ́.
13. Láwọn àgbègbè kan, ìyípadà wo ló yẹ ní ṣíṣe sí iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa?
13 Báa ṣe ń wá àwọn ẹni yíyẹ kiri, ó lè pọndandan ká fojú ṣùnnùkùn wo ọ̀nà táa gbà ń ṣe iṣẹ́ òjíṣẹ́ wa ní àwọn àgbègbè kan. Bó tiẹ̀ jẹ́ pé ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí ló ti mọ́ lára láti máa wàásù láti ilé dé ilé láràárọ̀ Sunday, ní àwọn àgbègbè kan wọ́n ń rí i pé lílọ bá àwọn èèyàn lọ́wọ́ àárọ̀ nínú ilé wọn kò fi bẹ́ẹ̀ gbéṣẹ́ mọ́, nítorí pé ojú oorun ni wọ́n ti ń bá àwọn onílé nígbà míì. Ọ̀pọ̀ Ẹlẹ́rìí ló ti yíwọ́ padà, tí wọ́n sì ń wá àwọn èèyàn lọ báyìí lọ́wọ́ ọ̀sán, bóyá lẹ́yìn àwọn ìpàdé Kristẹni. Ìsapá yìí sì ń sèso ní tòótọ́. Lọ́dún tó kọjá, iye àwọn olùpòkìkí Ìjọba náà kárí ayé fi ìpín méjì àti ẹ̀sún mẹ́ta nínú ọgọ́rùn-ún pọ̀ sí i. Èyí ń bọlá fún Ọ̀gá ìkórè, ó sì ń mú wa lọ́kàn yọ̀.
Máa Wá Àlàáfíà Nínú Iṣẹ́ Ìkórè Náà
14. Ẹ̀mí wo la fi ń bá àwọn èèyàn sọ̀rọ̀, èé sì ti ṣe?
14 Ìdí mìíràn táa fi ń láyọ̀ ní í ṣe pẹ̀lú ẹ̀mí àlàáfíà táa fi ń ṣe iṣẹ́ ìkórè náà. Jésù sọ pé: “Nígbà tí ẹ bá ń wọ ilé, ẹ kí agbo ilé náà; bí ilé náà bá sì yẹ, kí àlàáfíà tí ẹ fẹ́ fún un wá sórí rẹ̀.” (Mátíù 10:12, 13) Bí wọ́n ṣe ń kíni lédè Hébérù àti ọ̀rọ̀ tó bá a mu lédè Gíríìkì táa fi kọ Bíbélì ni ‘Àlàáfíà fún yín o.’ Ohun táa máa ń fi sọ́kàn nìyí nígbà táa bá ń wàásù ìhìn rere fáwọn èèyàn. Ìrètí wa ni pé wọ́n á tẹ́wọ́ gba ìhìn rere Ìjọba náà. Àwọn tó bá tẹ́wọ́ gbà á yóò ní ìrètí pípadà bá Ọlọ́run rẹ́, bí wọ́n bá ronú pìwà dà ẹ̀ṣẹ̀ wọn, tí wọ́n yí padà, tí wọ́n sì ṣe ìfẹ́ rẹ̀. Ẹ̀wẹ̀, níní àlàáfíà pẹ̀lú Ọlọ́run yóò yọrí sí ìyè àìnípẹ̀kun.—Jòhánù 17:3; Ìṣe 3:19; 13:38, 48; 2 Kọ́ríńtì 5:18-20.
15. Báwo la ò ṣe ní pàdánù àlàáfíà wa nígbà táwọn èèyàn ò bá tẹ́wọ́ gbà wá?
15 Báwo la ò ṣe ní pàdánù àlàáfíà wa nígbà táwọn èèyàn ò bá tẹ́wọ́ gbà wá? Ohun tí Jésù ní ká ṣe ni pé: “Bí [ilé náà] kò bá yẹ, kí àlàáfíà láti ọ̀dọ̀ yín padà sọ́dọ̀ yín.” (Mátíù 10:13) Àkọsílẹ̀ Lúùkù nípa rírán tí Jésù rán àwọn àádọ́rin ọmọ ẹ̀yìn jáde fi gbólóhùn Jésù yìí kún un pé: “Bí ọ̀rẹ́ àlàáfíà bá sì wà níbẹ̀, àlàáfíà yín yóò bà lé e. Ṣùgbọ́n bí kò bá sí, yóò padà sọ́dọ̀ yín.” (Lúùkù 10:6) Nígbà táa bá mú ìhìn rere náà tọ àwọn èèyàn lọ, ẹ̀mí rere àti ẹ̀mí àlàáfíà la fi ń mú un tọ̀ wọ́n lọ. Bí onílé bá fi wá pegi, tàbí tó ń ráhùn, tàbí tó tiẹ̀ sọ̀rọ̀ kòbákùngbé sí wa, ṣe ni gbogbo ìyẹn kàn ń jẹ́ kí ìhìn àlàáfíà táa mú wá ‘padà sọ́dọ̀ wa.’ Ṣùgbọ́n kò sí èyíkéyìí nínú nǹkan wọ̀nyí tó lè mú wa pàdánù àlàáfíà wa, tí í ṣe èso ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà.—Gálátíà 5:22, 23.
Ohun Rere Tí Àwọn Olùkórè Ń Lépa
16, 17. (a) Kí ni ohun tí à ń lépa nígbà táa bá ń ṣe ìpadàbẹ̀wò? (b) Báwo la ṣe lè ran àwọn tó ní ìbéèrè látinú Bíbélì lọ́wọ́?
16 Gẹ́gẹ́ bí olùkórè, inú wa dùn pé a láǹfààní láti kópa nínú iṣẹ́ kíkó àwọn èèyàn jọ fún ìyè àìnípẹ̀kun. Ẹ sì wo bí ayọ̀ wa ṣe ń pọ̀ tó nígbà tí ọ̀rọ̀ wa bá wọ ẹni táa wàásù fún létí, tó fẹ́ mọ̀ sí i, tó sì wá di “ọ̀rẹ́ àlàáfíà”! Bóyá ó ní ọ̀pọ̀ ìbéèrè látinú Bíbélì, tí kò sì ṣeé ṣe fún wa láti dáhùn gbogbo rẹ̀ ní ìjókòó ẹ̀ẹ̀kan. Níwọ̀n bí jíjókòó pẹ́ nígbà ìbẹ̀wò àkọ́kọ́ ti lè máà bójú mu, kí la wá lè ṣe o? Ohun tí à ń lépa ni irú ohun táa dámọ̀ràn ní nǹkan bí ọgọ́ta ọdún sẹ́yìn.
17 “Gbogbo ẹlẹ́rìí Jèhófà gbọ́dọ̀ múra tán láti darí àwọn ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì tó jẹ́ àwòkọ́ṣe.” Gbólóhùn yẹn wà nínú apá kẹta ìwé Model Study tí í ṣe àwọn ìwé ìtọ́ni táa tẹ̀ jáde láti 1937 sí 1941. Ó sọ síwájú sí i pé: “Gbogbo akéde [Ìjọba náà] gbọ́dọ̀ máa fi aápọn ṣe gbogbo ìrànwọ́ tó bá wà níkàáwọ́ wọn fáwọn ẹni ìtẹ́wọ́gbà tó bá nífẹ̀ẹ́ sí ìhìn rere Ìjọba náà. A gbọ́dọ̀ máa padà lọ bẹ àwọn èèyàn wọ̀nyí wò, ká máa dáhùn onírúurú ìbéèrè tí wọ́n bá ní . . . , ká sì wá bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ àwòkọ́ṣe . . . gbàrà tí àǹfààní rẹ̀ bá ti yọ.” Bẹ́ẹ̀ ni o, ohun tí à ń lépa nígbà táa bá lọ ṣe ìpadàbẹ̀wò ni láti bẹ̀rẹ̀ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé, ká sì máa darí rẹ̀ déédéé. a Ìwà bí ọ̀rẹ́ àti aájò àtọkànwá fún olùfìfẹ́hàn náà yóò jẹ́ ká múra sílẹ̀ dáadáa, ká sì darí ìkẹ́kọ̀ọ́ náà lọ́nà tó gbéṣẹ́.
18. Báwo la ṣe lè ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn Jésù Kristi?
18 Pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ ìwé Ìmọ̀ Tí Ń Sinni Lọ sí Ìyè Àìnípẹ̀kun, àti àwọn ìwé pẹlẹbẹ bíi Kí Ni Ọlọrun Ń Béèrè Lọ́wọ́ Wa?, a lè darí ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé lọ́nà tó gbéṣẹ́, ká sì tipa bẹ́ẹ̀ kópa nínú ríran àwọn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń fìfẹ́ hàn lọ́wọ́ láti di ọmọ ẹ̀yìn. Báa ti ń gbìyànjú láti fara wé Jésù Kristi, Olùkọ́ Ńlá náà, ó ṣeé ṣe kí irú àwọn akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì bẹ́ẹ̀ rí ẹ̀kọ́ kọ́ nínú ẹ̀mí àlàáfíà àti ayọ̀ táa ní, àti òótọ́ inú wa, àti ojú ribiribi táa fi ń wo àwọn ìlànà àti ìtọ́sọ́nà Jèhófà. Nígbà táa bá ran àwọn ẹni tuntun lọ́wọ́ láti rí ìdáhùn sí ìbéèrè wọn, ẹ jẹ́ ká sapá láti kọ́ wọn bí àwọn náà ṣe lè máa dá àwọn tó bá bi wọ́n ní ìbéèrè lóhùn. (2 Tímótì 2:1, 2; 1 Pétérù 2:21) Gẹ́gẹ́ bí olùkórè tẹ̀mí, ó dájú pé inú wa dùn pé ìpíndọ́gba 4,766,631 ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé la ṣe kárí ayé ní ọdún iṣẹ́ ìsìn tó kọjá yìí. Ayọ̀ wa á túbọ̀ kún, bí a bá wà lára àwọn olùkórè tó ń nípìn-ín nínú iṣẹ́ ìkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì inú ilé.
Ẹ Máa Yọ̀ Nínú Iṣẹ́ Ìkórè Náà
19. Kí ni àwọn ìdí pàtàkì fún ayọ̀ yíyọ̀ nínú iṣẹ́ ìkórè náà nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù àti kété lẹ́yìn náà?
19 Ìdí fún ayọ̀ yíyọ̀ pọ̀ rẹpẹtẹ nínú iṣẹ́ ìkórè náà nígbà iṣẹ́ òjíṣẹ́ Jésù àti kété lẹ́yìn náà. Ọ̀pọ̀ èèyàn ló tẹ́wọ́ gba ìhìn rere náà nígbà yẹn. Ayọ̀ ọ̀hún wá pọ̀ jọjọ ní Pẹ́ńtíkọ́sì ọdún 33 Sànmánì Tiwa, nítorí pé nǹkan bí ẹgbẹ̀rún mẹ́ta èèyàn ló tẹ̀ lé ìtọ́ni Pétérù nígbà náà, tí ẹ̀mí mímọ́ Jèhófà bà lé wọn, tí wọ́n sì di ara orílẹ̀-èdè Ísírẹ́lì tẹ̀mí ti Ọlọ́run. Àní, ṣe ni wọ́n ń pọ̀ sí i níye, tí ìdùnnú ń ṣubú layọ̀, nítorí pé “Jèhófà ń bá a lọ láti mú àwọn tí a ń gbà là dara pọ̀ mọ́ wọn lójoojúmọ́.”—Ìṣe 2:37-41, 46, 47; Gálátíà 6:16; 1 Pétérù 2:9.
20. Kí ló ń fún wa ní ayọ̀ púpọ̀ jọjọ nínú iṣẹ́ ìkórè wa?
20 Àsọtẹ́lẹ̀ Aísáyà ń ní ìmúṣẹ nígbà yẹn, pé: “Ìwọ [Jèhófà] ti sọ orílẹ̀-èdè náà di púpọ̀ sí i; o ti sọ ayọ̀ yíyọ̀ di púpọ̀ fún un. Wọ́n ń yọ̀ níwájú rẹ gẹ́gẹ́ bí a ti ń yọ̀ ní àkókò ìkórè, gẹ́gẹ́ bí àwọn tí ó kún fún ìdùnnú nígbà tí wọ́n ń pín ohun ìfiṣèjẹ.” (Aísáyà 9:3) Bó tilẹ̀ jẹ́ pé lọ́wọ́ táa wà yìí ‘orílẹ̀-èdè púpọ̀’ ti àwọn ẹni àmì òróró ti fẹ́rẹ̀ẹ́ pé, síbẹ̀ ayọ̀ wa kún bí a ti ń rí i tí iye àwọn olùkórè mìíràn ń pọ̀ sí i lọ́dọọdún.—Sáàmù 4:7; Sekaráyà 8:23; Jòhánù 10:16.
21. Kí la óò jíròrò nínú àpilẹ̀kọ tó kàn?
21 Ó dájú pé a nídìí tó ṣe gúnmọ́ láti máa yọ̀ nínú iṣẹ́ ìkórè náà. Iṣẹ́ ìrètí tí à ń jẹ́, wíwá tí à ń wá àwọn ẹni yíyẹ kàn, àti ẹ̀mí àlàáfíà táa ní—gbogbo nǹkan wọ̀nyí ló ń fún àwa olùkórè láyọ̀. Ṣùgbọ́n, ó ń bí ọ̀pọ̀ èèyàn nínú. Ohun tójú àpọ́sítélì Jòhánù náà rí nìyẹn. Wọ́n sọ ọ́ sẹ́wọ̀n ní erékùṣù Pátímọ́sì “nítorí sísọ̀rọ̀ nípa Ọlọ́run àti jíjẹ́rìí Jésù.” (Ìṣípayá 1:9) Báwo wá la ò ṣe ní pàdánù ayọ̀ wa nígbà táa bá dojú kọ inúnibíni àti àtakò? Kí ni yóò ràn wá lọ́wọ́ láti fara da sísé tí ọ̀pọ̀ àwọn tí a ń wàásù fún ti sé ọkàn wọn le? Àpilẹ̀kọ wa tó kàn yóò ràn wá lọ́wọ́ láti rí ìdáhùn sí ìbéèrè wọ̀nyí látinú Ìwé Mímọ́.
[Àlàyé ìsàlẹ̀ ìwé]
a Àwọn ibi táa ti kọ́kọ́ ń ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ ni ibi tí àwọn olùfìfẹ́hàn lè kóra jọ sí. Àmọ́, láìpẹ́ a tún bẹ̀rẹ̀ sí ṣe ìkẹ́kọ̀ọ́ pẹ̀lú ẹnì kọ̀ọ̀kan àti pẹ̀lú ìdílé kọ̀ọ̀kan.—Wo Jehovah’s Witnesses—Proclaimers of God’s Kingdom, ojú ìwé 574, tí àwa Ẹlẹ́rìí Jèhófà tẹ̀ jáde.
Báwo Ni Wàá Ṣe Dáhùn?
• Kí ni iṣẹ́ ìkórè tẹ̀mí náà jẹ́?
• Irú iṣẹ́ wo là ń jẹ́?
• Èé ṣe tó fi ń ṣeé ṣe fún wa láti wá àwọn ọmọ ẹ̀yìn kàn?
• Báwo la ṣe ń wá àlàáfíà nínú iṣẹ́ ìkórè náà?
• Èé ṣe tá ò fi pàdánù ayọ̀ wa nínú iṣẹ́ ìkórè náà?
[Ìbéèrè fún Ìkẹ́kọ̀ọ́]
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 12, 13]
Wíwàásù ní ọ̀rúndún kìíní àti ọ̀rúndún ogún
[Àwọn àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Bíi ti Pọ́ọ̀lù, àwọn olùkórè òde òní ń gbìyànjú láti dé ọ̀dọ̀ àwọn èèyàn níbi gbogbo
[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 13]
Máa fi ẹ̀mí rere pòkìkí ìhìn rere náà