Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Origen—Báwo Ni Ẹ̀kọ́ Rẹ̀ Ṣe Nípa Lórí Ṣọ́ọ̀ṣì?

Origen—Báwo Ni Ẹ̀kọ́ Rẹ̀ Ṣe Nípa Lórí Ṣọ́ọ̀ṣì?

Origen—Báwo Ni Ẹ̀kọ́ Rẹ̀ Ṣe Nípa Lórí Ṣọ́ọ̀ṣì?

“Aṣáájú títóbi lọ́lá jù lọ tí Ṣọ́ọ̀ṣì ní lẹ́yìn àwọn Àpọ́sítélì.” Bí Jerome, olùtumọ̀ Bíbélì Vulgate lédè Látìn, ṣe gbóríyìn fún Origen, ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn ọ̀rúndún kẹta nìyẹn. Àmọ́ kì í ṣe gbogbo èèyàn ló ṣe báyẹn gbé Origen gẹ̀gẹ̀. Àwọn kan kà á sí olubi tí àdámọ̀ bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ rẹ̀. Nínú ọ̀rọ̀ òǹkọ̀wé kan ní ọ̀rúndún kẹtàdínlógún, àwọn tí ń bẹnu àtẹ́ lu Origen kéde pé: “Ọ̀pọ̀ jù lọ lára ẹ̀kọ́ rẹ̀ ni kò bọ́gbọ́n mu rárá, tó sì ń pani lára, panipani oró Ejò tó pọ̀ sínú ayé ni wọ́n.” Àní sẹ́, aládàámọ̀ ni wọ́n pe Origen ní nǹkan bí ọ̀rúndún mẹ́ta lẹ́yìn ikú rẹ̀.

ÈÉ ṢE tí Origen fi di ẹni táwọn kan ń kan sáárá sí, táwọn mìíràn tún ń ṣe kèéta rẹ̀? Ipa wo ló ní lórí bí àwọn ẹ̀kọ́ ṣọ́ọ̀ṣì ṣe ń tẹ̀ síwájú?

Ìtara fún Ṣọ́ọ̀ṣì

Wọ́n bí Origen ní nǹkan bí ọdún 185 Sànmánì Tiwa ní Alẹkisáńdíríà, tó jẹ́ ìlú ńlá kan nílẹ̀ Íjíbítì. Ó gba ẹ̀kọ́ tó yè kooro nípa àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Gíríìkì, àmọ́ Leonides, bàbá rẹ̀, rọ̀ ọ́ láti lo ìsapá kan náà nínú kíkẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì. Nígbà tí Origen pé ọmọ ọdún mẹ́tàdínlógún, olú ọba Róòmù gbé àṣẹ kan jáde tó sọ pé yíyí ẹ̀sìn ẹni padà jẹ́ ìwà ọ̀daràn. Wọ́n ju bàbá Origen sẹ́wọ̀n nítorí pé ó di Kristẹni. Nítorí ìtara ọ̀dọ́ tí Origen ní, ó pinnu láti lọ bá bàbá rẹ̀ nínú ẹ̀wọ̀n kí wọ́n sì jọ kú pọ̀. Nígbà tí ìyá Origen rí èyí, ó kó aṣọ rẹ̀ pa mọ́, kí ó má bàa jáde nílé. Nínú lẹ́tà tí Origen kọ, ó rọ bàbá rẹ̀ pé: “O ò gbọ́dọ̀ tìtorí tiwa yíhùn padà o.” Leonides mú ìdúró rẹ̀, wọ́n sì yẹgi fún un, ó fi ìdílé rẹ̀ sílẹ̀ nínú ipò òṣì. Àmọ́, Origen ti lọ jìnnà nínú ẹ̀kọ́ rẹ̀ débi pé ó lè gbọ́ bùkátà ìyá rẹ̀ àtàwọn àbúrò rẹ̀ ọkùnrin mẹ́fẹ̀ẹ̀fà nípa kíkọ́ni ní àṣà ìṣẹ̀dálẹ̀ Gíríìkì.

Ohun tó wà lọ́kàn olú ọba yẹn ni láti tẹ ẹ̀sìn Kristẹni rì. Nígbà tó sì jẹ́ pé àti akẹ́kọ̀ọ́ àti olùkọ́ ni òfin yẹn kàn, bí gbogbo àwọn tí ń kọ́ni nípa ẹ̀sìn Kristẹni ṣe sá kúrò ní Alẹkisáńdíríà nìyẹn. Nígbà tí àwọn tí kì í ṣe Kristẹni ń wá ìtọ́ni Ìwé Mímọ́, wọ́n wá bẹ Origen kó ran àwọn lọ́wọ́, ó sì fayọ̀ tẹ́wọ́ gba iṣẹ́ yìí, ó kà á sí iṣẹ́ tó ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá. Ọ̀pọ̀ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ni wọ́n pa nítorí ìgbàgbọ́ wọn, wọ́n tiẹ̀ pa àwọn kan kí wọ́n tó parí ẹ̀kọ́ wọn pàápàá. Origen fẹ̀mí ara rẹ̀ wewu gidigidi nípa gbígba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ níyànjú ní gbangba, yálà wọ́n wà níwájú adájọ́, nínú ẹ̀wọ̀n, tàbí nígbà tí wọ́n bá fẹ́ pa wọ́n. Òpìtàn ọ̀rúndún kẹrin nì, Eusebius, ròyìn pé nígbà tí wọ́n bá ń mú wọn lọ síbi tí wọ́n ti fẹ́ pa wọ́n, Origen, “á fìgboyà sún mọ́ wọn, á sì fẹnu kò wọ́n lẹ́nu.”

Ọ̀pọ̀ àwọn tí kì í ṣe Kristẹni ló bínú sí Origen. Wọ́n ní òun ló jẹ́ kí àwọn ọ̀rẹ́ wọn yí ẹ̀sìn padà, tó sì mú kí wọ́n rí ikú he. Àìmọye ìgbà ló jẹ́ pé díẹ̀ ló kù kí ọwọ́ àwọn èèyànkéèyàn tẹ̀ ẹ́, tí ì bá sì ti kú ikú gbígbóná. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé ó ní láti máa ti ilé kan bọ́ sí òmíràn kó lè bọ́ lọ́wọ́ àwọn tó ń wá a kiri, síbẹ̀ Origen kò jáwọ́ nínú iṣẹ́ olùkọ́ tó ń ṣe. Irú àìbẹ̀rù àti ìfọkànsìn bẹ́ẹ̀ wú Demetrius, bíṣọ́ọ̀bù Alẹkisáńdíríà, lórí. Ìyẹn ló fi jẹ́ pé ẹni ọdún méjìdínlógún péré ni Origen nígbà tí Demetrius yàn án ṣe olórí iléèwé nípa ẹ̀kọ́ ẹ̀sìn ní Alẹkisáńdíríà.

Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, Origen di gbajúgbajà ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ àti akọ̀wé-kọwúrà. Àwọn kan sọ pé ó kọ ẹgbàáta [6,000] ìwé, ó ṣeé ṣe kíyẹn jẹ́ àsọdùn ṣá o. Ohun tó sọ ọ́ di olókìkí jù lọ ni ìwé ńlá tó ṣe, tó pè ní Hexapla, tó jẹ́ ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ Lédè Hébérù tó ní àádọ́ta ìdìpọ̀ nínú. Origen ṣètò Hexapla náà sí òpó mẹ́fà tó wà lẹ́gbẹ̀ẹ́ ara wọn, àwọn ni: (1) Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù àti ti Árámáíkì, (2) Ìwé Mímọ́ kan náà yẹn táa wá fi ááfábẹ́ẹ̀tì èdè Gíríìkì kọ, (3) ìtumọ̀ tí Aquila ṣe sí èdè Gíríìkì, (4) ìtumọ̀ tí Symmachus ṣe sí èdè Gíríìkì, (5) ẹ̀dà ti Septuagint lédè Gíríìkì, tí Origen tún ṣe kó lè túbọ̀ bá Ìwé Mímọ́ lédè Hébérù mu, àti (6) ìtumọ̀ tí Theodition ṣe sí èdè Gíríìkì. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́ Bíbélì jinlẹ̀ nì, John Hort kọ̀wé pé: “Nípasẹ̀ àpapọ̀ àwọn ẹ̀dà Ìwé Mímọ́ yìí, Origen fẹ́ kí òǹkàwé túbọ̀ ní òye kíkún lórí ọ̀pọ̀ ẹsẹ Ìwé Mímọ́ lédè Gíríìkì tó ṣòroó lóye tàbí tó tiẹ̀ lè ṣì í lọ́nà pàápàá, tó bá jẹ́ pé kìkì ẹ̀dà ti Septuagint ló gbé lọ́wọ́.”

‘Lílọ Ré Kọjá Ohun Tí A Kọ̀wé Rẹ̀’

Síbẹ̀síbẹ̀, ìdàrúdàpọ̀ nínú ọ̀ràn ẹ̀sìn ní ọ̀rúndún kẹta nípa tó lágbára lórí bí Origen ṣe ń fi Ìwé Mímọ́ kọ́ni. Bó tilẹ̀ jẹ́ pé Kirisẹ́ńdọ̀mù ṣì jẹ́ tuntun nígbà yẹn, àwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu ti sọ ọ́ dìbàjẹ́, onírúurú ẹ̀kọ́ sì ni àwọn ṣọ́ọ̀ṣì rẹ̀ tó fọ́n káàkiri fi ń kọ́ni.

Origen tẹ́wọ́ gba àwọn kan lára àwọn ẹ̀kọ́ tí kò bá Ìwé Mímọ́ mu wọ̀nyí, ó pè wọ́n ní ẹ̀kọ́ àwọn àpọ́sítélì. Àmọ́ kò rí nǹkan kan tó burú nínú míméfò lórí àwọn ìbéèrè mìíràn. Ọ̀pọ̀ lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ni ẹ̀kọ́ ọgbọ́n orí tó gbòde kan nígbà yẹn ń jà gùdù nínú wọn. Kí Origen lè ràn wọ́n lọ́wọ́, ó fara balẹ̀ kẹ́kọ̀ọ́ nípa onírúurú ìmọ̀ ọgbọ́n orí tó ti gba àwọn ọ̀dọ́ akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ lọ́kàn. Ó bá múra láti fún àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ní ìdáhùn tó máa tẹ́ wọn lọ́rùn sí àwọn ìbéèrè nípa ìmọ̀ ọgbọ́n orí tí wọ́n ń gbé dìde.

Níbi tí Origen ti ń gbìyànjú láti jẹ́ kí Bíbélì àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí bára mu, ló ti bẹ̀rẹ̀ sí gbé ìtumọ̀ Ìwé Mímọ́ gbòdì. Ó gbà pé Ìwé Mímọ́ sábà máa ń ní ìtumọ̀ tẹ̀mí, àmọ́ kò gbà pé ìtumọ̀ rẹ̀ sábà máa ń jẹ́ báa ṣe sọ ọ́ gẹ́lẹ́. Ọ̀mọ̀wé akẹ́kọ̀ọ́jinlẹ̀ kan sọ pé, èyí fún Origen láyè “láti máa túmọ̀ Bíbélì sí èrò èyíkéyìí tí kò bá Bíbélì mu, tó bá sáà ti bá ọ̀nà tó gbà ń kọ́ni lẹ́kọ̀ọ́ tirẹ̀ mu, lẹ́sẹ̀ kan náà tó ń sọ pé òun jẹ́ onítara gidi (kò sì sí àní-àní pé tinútinú ló fi ń fojú inú wo ara rẹ̀ bẹ́ẹ̀) àti ẹni tó ń fi òtítọ́ inú túmọ̀ àwọn ohun tí ń bẹ nínú Bíbélì.”

Lẹ́tà kan tí Origen kọ sí ọ̀kan lára àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ ló jẹ́ ká mọ èrò rẹ̀. Origen là á mọ́lẹ̀ pé wúrà àwọn ará Íjíbítì làwọn ọmọ Ísírẹ́lì fi ṣe àwọn ohun èlò sínú tẹ́ńpìlì Jèhófà. Ó ní ìyẹn náà ló fà á tóun fi ń fi ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì kọ́ni ní ẹ̀sìn Kristẹni. Ó kọ̀wé pé: “Ohun tí àwọn ọmọ Ísírẹ́lì kó wá láti Íjíbítì mà wúlò fún wọn o, àwọn ohun tí àwọn ará Íjíbítì ò lò bó ṣe tọ́ àti bó ṣe yẹ, àmọ́ tí àwọn Hébérù, tí ọgbọ́n Ọlọ́run darí, wá lò fún iṣẹ́ ìsìn Ọlọ́run.” Origen wá tipa bẹ́ẹ̀ gba àwọn akẹ́kọ̀ọ́ rẹ̀ níyànjú láti “mú ohunkóhun tó bá ṣe kókó láti inú ìmọ̀ ọgbọ́n orí àwọn Gíríìkì, ìyẹn ohun tí wọ́n lè lò fún ìkẹ́kọ̀ọ́ tàbí gẹ́gẹ́ bí irinṣẹ́ ẹ̀sìn Kristẹni.”

Ọ̀nà tó gbà ń túmọ̀ Bíbélì láìní ààlà yìí mú kó ṣòro láti mọ ìyàtọ̀ tó wà láàárín ẹ̀kọ́ Kristẹni àti ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì. Fún àpẹẹrẹ, nínú ìwé rẹ̀, tó pè ní On First Principles, Origen pe Jésù ní ‘Ọmọ bíbí kan ṣoṣo, tí a bí, ṣùgbọ́n tí kò níbẹ̀rẹ̀.’ Ó sì fi kún un pé: ‘Láti ayérayé àìnípẹ̀kun la ti bí i. Kì í ṣe nípa gbígba èémí ìyè ló fi di Ọmọ, kì í ṣe nípa ohun táa lè fojú rí, bí kò ṣe nípa ẹ̀dá Ọlọ́run fúnra rẹ̀.’

Inú Bíbélì kọ́ ni Origen ti rí ẹ̀kọ́ yìí, nítorí pé Ìwé Mímọ́ kọ́ni pé Ọmọ bíbí kan ṣoṣo Jèhófà ni “àkọ́bí nínú gbogbo ìṣẹ̀dá” àti “ìbẹ̀rẹ̀pẹ̀pẹ̀ ìṣẹ̀dá láti ọwọ́ Ọlọ́run.” (Kólósè 1:15; Ìṣípayá 3:14) Gẹ́gẹ́ bí ohun tí òpìtàn nípa ìsìn nì, Augustus Neander, wí, “ẹ̀kọ́ nípa ìmọ̀ ọgbọ́n orí tí Origen lọ gbà nílé ẹ̀kọ́ Plato” ló sún un dórí èròǹgbà “jíjẹ́ ẹni ayérayé.” Origen tipa bẹ́ẹ̀ rú ìlànà pàtàkì tó wà nínú Ìwé Mímọ́ pé: “Má ṣe ré kọjá àwọn ohun tí a ti kọ̀wé rẹ̀.”—1 Kọ́ríńtì 4:6.

Ẹjọ́ Aládàámọ̀ Ni Wọ́n Dá A

Láàárín àwọn ọdún tó ṣẹ̀ṣẹ̀ bẹ̀rẹ̀ iṣẹ́ olùkọ́ tó ń ṣe, Ẹgbẹ́ Alákòóso Ìsìn kan ní Alẹkisáńdíríà yọ Origen kúrò nípò àlùfáà. Ó jọ pé ohun tó fà á ni pé Bíṣọ́ọ̀bù Demetrius ń jowú òkìkí Origen tó ń kàn. Origen wá ṣí lọ sí Palẹ́sìnì, níbi táwọn èèyàn ti ń kan sáárá sí i lọ́tùn-ún lósì, tí wọ́n kà á sí ẹni tó ń fi òtítọ́ inú gbèjà ẹ̀kọ́ Kristẹni, bó ṣe rọra dúró síbẹ̀ nìyẹn tó ń báṣẹ́ àlùfáà rẹ̀ lọ. Àní, nígbà tí ọ̀rọ̀ nípa “àdámọ̀” bẹ̀rẹ̀ ní apá Ìlà Oòrùn, òun ni wọ́n bẹ̀ pé kó wá yí àwọn bíṣọ́ọ̀bù tó ti ṣáko lọ lérò padà, kí wọ́n lè padà sínú ẹ̀sìn tí gbogbo gbòò ń ṣe. Lẹ́yìn ikú Origen ní 254 Sànmánì Tiwa, orúkọ rẹ̀ di èyí tí wọ́n bà jẹ́ pátápátá. Kí nìdí?

Nígbà tí ẹ̀sìn àwọn aláfẹnujẹ́ Kristẹni ti wá gbòde kan, wọ́n wá ṣe àtúnyẹ̀wò ohun tí ṣọ́ọ̀ṣì gbà gẹ́gẹ́ bí ẹ̀kọ́ gbogbo gbòò. Nípa bẹ́ẹ̀, àwọn ẹlẹ́kọ̀ọ́ ìsìn tó ṣẹ̀ṣẹ̀ ń yọjú kò wá tẹ́wọ́ gba ọ̀pọ̀ lára àwọn àbá àtàwọn èròǹgbà tí Origen kàn gbé kalẹ̀ mọ́. Àwọn ẹ̀kọ́ rẹ̀ wá ń fa àríyànjiyàn líle koko nínú ṣọ́ọ̀ṣì. Kí wọ́n lè yanjú awuyewuye tó wà nílẹ̀ wọ̀nyí, kí ìjọ má sì tú ká, ṣọ́ọ̀ṣì wá là á mọ́lẹ̀ pé aládàámọ̀ ni Origen.

Origen nìkan kọ́ ló ṣìnà. Ká sọ tòótọ́, Bíbélì ti sọ àsọtẹ́lẹ̀ nípa bí àwọn èèyàn ṣe máa yapa kúrò nínú ojúlówó ẹ̀kọ́ Kristi. Ìpẹ̀yìndà yìí ti bẹ̀rẹ̀ sí tàn kálẹ̀ láti ìparí ọ̀rúndún kìíní, lẹ́yìn tí àwọn àpọ́sítélì Jésù kú tán. (2 Tẹsalóníkà 2:6, 7) Ní àsẹ̀yìnwá àsẹ̀yìnbọ̀, àwọn kan tí wọ́n pe ara wọn ní Kristẹni wá gbé ara wọn kalẹ̀ bí “ẹlẹ́sìn tí gbogbo gbòò tẹ́wọ́ gbà,” wọ́n sì sọ pé gbogbo àwọn tó kù pátá ni “aládàámọ̀.” Àmọ́ ní ti tòótọ́, ṣe ni Kirisẹ́ńdọ̀mù yapa pátápátá kúrò nínú ìsìn Kristẹni tòótọ́.

“Ohun Tí A Fi Èké Pè Ní ‘Ìmọ̀’”

Pẹ̀lú gbogbo bí Origen ṣe méfò tó, àwọn ohun tó ṣàǹfààní wà nínú àwọn ìwé rẹ̀. Fún àpẹẹrẹ, orúkọ Ọlọ́run tí wọ́n kọ ní lẹ́tà Hébérù mẹ́rin, táa ń pè ní Tetragrammaton wà nínú Hexapla rẹ̀. Èyí fúnni ní ẹ̀rí pàtàkì náà pé àwọn Kristẹni ìjímìjí mọ orúkọ Ọlọ́run sí Jèhófà, wọ́n sì lò ó. Síbẹ̀síbẹ̀, olórí ṣọ́ọ̀ṣì ní ọ̀rúndún kárùn-ún tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Theophilus fìgbà kan sọ pé: “Àwọn ìwé Origen dà bí ilẹ̀ eléwéko tútù, tí ó ní onírúurú òdòdó nínú. Bí mo bá rí òdòdó tó rẹwà níbẹ̀, màá já a; àmọ́ bí mo bá rí ohunkóhun tó dà bí ègún níbẹ̀, màá yàgò fún un bí mo ṣe máa yàgò fún nǹkan olóró.”

Bí Origen ṣe pa ẹ̀kọ́ Bíbélì pọ̀ mọ́ ti ìmọ̀ ọgbọ́n orí Gíríìkì, mú kí ẹ̀kọ́ rẹ̀ di èyí tó kún fún ìṣìnà, àbájáde rẹ̀ sì burú jáì fún Kirisẹ́ńdọ̀mù. Fún àpẹẹrẹ, bó tilẹ̀ jẹ́ pé wọn kò tẹ́wọ́ gba èyí tó pọ̀ jù lọ nínú ìméfò Origen, síbẹ̀ èròǹgbà Origen pé “ẹni ayérayé” ni Kristi ló ràn wọ́n lọ́wọ́ láti fi ìpìlẹ̀ lélẹ̀ fún ẹ̀kọ́ Mẹ́talọ́kan tí kò bá Bíbélì mu. Ìwé náà The Church of the First Three Centuries sọ pé: “Ìfẹ́ fún ìmọ̀ ọgbọ́n orí [tó bẹ̀rẹ̀ látọ̀dọ̀ Origen] kò lè tètè kásẹ̀ nílẹ̀.” Kí wá ni àbájáde rẹ̀? “Ẹ̀kọ́ Kristẹni tó ṣe tààrà wá di èyí tí wọ́n sọ dìbàjẹ́, bí ìṣìnà tí kò lóǹkà ṣe wọnú Ṣọ́ọ̀ṣì nìyẹn.”

Ní ti Origen, ó yẹ kó ti tẹ̀ lé ìṣílétí àpọ́sítélì Pọ́ọ̀lù, kó sì yẹra fún dídákún ìpẹ̀yìndà yìí nípa ‘yíyẹra fún àwọn òfìfo ọ̀rọ̀ tí ó máa ń fi àìmọ́ ba ohun mímọ́ jẹ́ àti fún àwọn ìtakora ohun tí a fi èké pè ní “ìmọ̀.”’ Kàkà bẹ́ẹ̀, nípa gbígbé èyí tó pọ̀ jù lọ lára ẹ̀kọ́ rẹ̀ ka irú “ìmọ̀” yẹn, Origen “yapa kúrò nínú ìgbàgbọ́.”—1 Tímótì 6:20, 21; Kólósè 2:8.

[Àwòrán tó wà ní ojú ìwé 31]

“Hexapla” tí Origen kọ fi hàn pé wọ́n lo orúkọ Ọlọ́run nínú Ìwé Mímọ́ Kristẹni lédè Gíríìkì

[Credit Line]

A gbé e jáde nípasẹ̀ ìyọ̀ǹda Syndics of Cambridge University Library, T-S 12.182

[Àwòrán Credit Line tó wà ní ojú ìwé 29]

Àwọn Fọ́tò Culver