Lọ wo ohun tó wà nínú rẹ̀

Lọ wo àwọn ohun tó wà

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ìbéèrè Láti Ọwọ́ Àwọn Òǹkàwé

Ibo ni Dáníẹ́lì wà nígbà táwọn Hébérù mẹ́ta ń fojú winá àdánwò níwájú èrè gàgàrà tí Nebukadinésárì gbé sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà?

Bíbélì kò sọ, fún ìdí yìí kò sí ẹnikẹ́ni lóde òní tó lè sọ ibi tí Dáníẹ́lì wà ní pàtó nígbà àdánwò yẹn.

Àwọn kan ti dá a lábàá pé oyè tàbí ipò tí Nebukadinésárì fún Dáníẹ́lì ju ti Ṣádírákì, Méṣákì, àti Àbẹ́dínígò lọ, wọ́n ní ìyẹn ni kò jẹ́ kó di dandan fún un láti lọ sí pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà. Dáníẹ́lì 2:49 fi hàn pé fún sáà kan, ó ní ipò tó ga ju tàwọn alábàákẹ́gbẹ́ rẹ̀ mẹ́tẹ̀ẹ̀ta. Ṣùgbọ́n a kò ní ẹ̀rí láti fi hàn pé èyí ni kò jẹ́ kó bá àwọn yòókù pé jọ síwájú ère náà.

Àwọn míì tó ń gbìyànjú láti ṣàlàyé ìdí tí Dáníẹ́lì ò fi sí níbẹ̀ sọ pé bóyá iṣẹ́ ìlú ló bá lọ síbì kan tàbí kó jẹ́ pé ara rẹ̀ kò yá, tí kò sì wá ṣeé ṣe fún un láti wá síbẹ̀. Àmọ́, Bíbélì kò sọ bẹ́ẹ̀. Ohun yòówù kó jẹ́, ipa ọ̀nà tí Dáníẹ́lì tọ̀ kò ní àríwísí nínú rárá, torí ká ní ó gbé ìgbésẹ̀ tó kù díẹ̀ káàtó ni, ó dájú pé àwọn ìjòyè Bábílónì ì bá fìyẹn wé ẹ̀sùn mọ́ ọn lẹ́sẹ̀. (Dáníẹ́lì 3:8) Ṣáájú àti lẹ́yìn ìṣẹ̀lẹ̀ yìí, Dáníẹ́lì fi hàn pé òun jẹ́ olùpàwàtítọ́mọ́, tó dúró ṣinṣin ti Ọlọ́run lábẹ́ ìdánwò èyíkéyìí. (Dáníẹ́lì 1:8; 5:17; 6:4, 10, 11) Nítorí náà, bí Bíbélì kò tiẹ̀ sọ ìdí tí Dáníẹ́lì kò fi sí ní pẹ̀tẹ́lẹ̀ Dúrà, ó dá wa lójú pé ìṣòtítọ́ rẹ̀ sí Jèhófà Ọlọ́run kò yingin.—Ìsíkíẹ́lì 14:14; Hébérù 11:33.